Orin Dafidi 72:1-19

Lesson 248 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Olubukún li OLUWA Ọlọrun, Ọlọrun Israẹli, ẹnikanṣoṣo ti nṣe ohun iyanu” (Orin Dafidi 72:18).
Cross References

I Ijọba Ainipẹkun

1 Onipsalmu fẹ ki a fi ododo ati idajọ Ọlọrun fun Ọmọ Ọba, Orin Dafidi 72:1; Isaiah 59:16, 17; Jeremiah 23:5, 6

2 Ọba yoo ṣe idajọ awọn eniyan pẹlu ododo ati ẹtọ, Orin Dafidi 72:2-4; Isaiah 11:2-5; 9:7; 32:1

3 Ijọba yii ki yoo nipẹkun, Orin Dafidi 72:5-7; Daniẹli 2:44; Luku 1:32, 33; Mika 4:7

4 Ijọba Rẹ yoo bori ohun gbogbo, Orin Dafidi 72:8-11; 59:13; 103:19; Daniẹli 7:14; Ifihan 21:24-26

5 Ọba yoo gbọ yoo si dahun igbe awọn alaini, talaka ati awọn ti a n nilara, Orin Dafidi 72:12-14; Isaiah 2:4; Hosea 2:18; Mika 4:3, 4; Isaiah 60:1-22

6 A o gbe Ọba naa ga, a o si bu ọlá fun Un, Orin Dafidi 72:15-20; Isaiah 2:1-3; Mika 4:1, 2; Luku 1:32, 33; Filippi 2:9, 11; Ifihan 19:12, 16

Notes

Ọmọ Ọba

Adura Dafidi ti a kọ silẹ fun wa ninu Bibeli ninu Orin Dafidi kejilelaadọrin tayọ adura. Ijẹwọ igbagbọ ati asọtẹlẹ nipa Messia ni ọna ti o daju ni. Oye yé Dafidi nipa eto igbala Ọlọrun; bi imọ ati oye Dafidi ti pọ to nipa Ijọba Ọlọrun si fi ara hàn fun ni ninu adura yii.

O hàn daju pé adura Dafidi pée ki idajọ ati ododo Ọlọrun ki o le jẹ ti Ọmọ Ọba ki i ṣe ni pato fun Sọlomọni ọmọ rè̩. Ijọba Sọlomọni kún fun alaafia ati ibukun ti kò lẹgbẹ ninu itan igbesi-aye awọn Ọmọ Israẹli ṣaaju ati lẹyin eyi. Sibẹsibẹ ijọba Sọlomọni kò to nnkan lara Ijọba ti Ẹmi Mimọ n tọka si lati ẹnu Dafidi. Dafidi ki i ṣe ope nipa Olugbala ati Ọba rè̩ ti n bọ wa, kò si ṣe aibikita si alaafia ati ọpọ ibukún ti yoo jẹ apa kan Ijọba ti a o gbe kalẹ nigbooṣe ninu aye. Adura rè̩ jẹ eyi ti o kún fun imisi Ọlọrun ti o rú ifẹ rè̩ soke lati beere pe ki Ijọba naa tete de.

Dafidi nikan kọ ni ẹni ti Ọlọrun fi diẹ ninu ogo Ijọba Ọmọ Rè̩ hàn. Isaiah sọ asọtẹlẹ nipa Jesu Kristi ati Ijọba Rẹ: “A bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rè̩: a o si ma pe orukọ rè̩ ni Iyanu, Oludamọran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia” (Isaiah 9:6).

A ti yàn Kristi lati jọba lati ipilẹṣẹ aye. (Wo I Peteru 1:20). Onipsalmu wi pe, “Lati igba atijọ li a ti fi idi ité̩ rẹ kalẹ, ati aiye-raiye ni Iwọ” (Orin Dafidi 93:2).

Johannu Apọsteli ni erekuṣu Patmo, ri Ẹni ti yoo jọba, o si gbọ ti ọpọlọpọ eniyan wi pe: “Yiyẹ li Ọdọ-agutan na ti a ti pa, lati gbà agbara, ati ọrọ, ati ọgbọn, ati ipá, ati ọlá, ati ogo, ati ibukún. Gbogbo ẹda ti o si mbẹ li ọrun, ati lori ilẹ aiye, ati nisalẹ ilẹ, ati irú awọn ti mbẹ ninu okun, ati gbogbo awọn ti mbẹ ninu wọn, ni mo gbọ ti nwipe, Ki a fi ibukún ati ọlá, ati ogo, ati agbara, fun Ẹniti o joko lori ité̩ ati fun Ọdọ-Agutan na lai ati lailai” (Ifihan 5:12, 13).

Ijọba Ododo

Nipa ẹtọ, Jesu Kristi ni Alakoso Ijọba yi, Oun yoo si jọba ni ododo. A kà ni ibi pupọ ninu Iwe Mimọ nipa ododo ati ẹwa idajọ Ọba naa. “Olododo ni iwọ, OLUWA, ati diduro-ṣinṣin ni idajọ rẹ” (Orin Dafidi 119:137); “Ododo rẹ ododo lailai ni” (Orin Dafidi 119:142); ati “Ododo ati idajọ ni ibujoko ité̩ rè̩” (Orin Dafidi 97:2). Ododo ni aṣẹ Rẹ, idajọ ati ọrọ Rẹ (Wo Orin Dafidi 119:172; 19:9; 119:123). “Olododo li OLUWA li ọna rè̩ gbogbo, ati alānu ni iṣẹ rè̩ gbogbo” (Orin Dafidi 145:17). A tun kà pe, “Yio fi ododo ṣe idajọ aiye, ati ti enia ni yio fi otitọ rè̩ ṣe” (Orin Dafidi 96:13). Iba diẹ ninu awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti o sọ nipa ijọba ododo Ọba naa ni awọn wọnyi.

Ilẹ Ẹwa

Woli Isaiah sọ ni iwọn iba ọrọ diẹ ṣoki gẹgẹ bi Ijọba Ọlọrun ninu aye yii yoo ti gbilẹ to. “Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun” (Isaiah 9:7). A kà ninu ori ẹkọ wa yii pe, “On o rọ si ilẹ bi òjo si ori koriko iré̩-mọlẹ: bi ọwọ òjo ti o rin ilẹ. Li ọjọ rè̩ li awọn olododo yio gbilẹ: ati ọpọlọpọ alafia niwọn bi òṣupa yio ti pẹ to.” Awọn ẹsẹ miiran ti o fara jọ ẹkọ wa wá si iranti. “On o si ṣe idajọ lārin ọpọlọpọ enia, yio si bá alagbara orilẹ-ède rére wi; nwọn o si fi idà wọn rọ ọbẹ -- plau, ati ọkọ wọn rọ dojé: orilẹ-ède kì yio gbe idà si orilẹ-ède, bḝni nwọn kì yio kọ ogun jijà mọ. S̩ugbọn nwọn o joko olukuluku labẹ ajara rè̩ ati labẹ igi ọpọtọ rè̩; ẹnikan kì yio si daiya fò wọn” (Mika 4:3, 4).

Ẹsẹ wura miiran ninu Ọrọ Ọlọrun sọ fun wa nipa alaafia Ijọba Ọlọrun ninu aye: “Nwọn o si kọ ile, nwọn o si gbe inu wọn; nwọn o si gbìn ọgba àjara, nwọn o si jẹ eso wọn. Nwọn kì yio kọ ile fun ẹlomiran igbe, nwọn ki yio gbìn fun ẹlomiran ijẹ; nitori gẹgẹ bi ọjọ igi li ọjọ awọn enia mi ri, awọn ayanfẹ mi yio si jìfà iṣẹ ọwọ wọn. Nwọn ki yio ṣiṣẹ lasan, nwọn ki yio bimọ fun wahala: nitori awọn ni iru alabukun OLUWA ati iru-ọmọ wọn pẹlu wọn. Yio si ṣe, pe, ki nwọn ki o to pè, emi o dahùn; ati bi nwọn ba ti nsọrọ lọwọ, emi o gbọ” (Isaiah 65:21-24).

Ijọba gbogbo Agbaye

Nigba ijọba Sọlomọni orilẹ-ède Israẹli di olokiki laaarin awọn orilẹ-ède. Awọn orilẹ-ède aye a maa mu ọja wọn wa si ilẹ Israẹli, wọn a si maa mu ẹbun iyebiye wa fun Sọlomọni ọba ni imoore ati iyin fun ọgbọn rè̩. Ayaba S̩eba wa lati ọna jijin lati bẹ Sọlomọni wo; o si sọ bayi nipa aafin ati awọn iranṣẹ rè̩ ati nipa ọna ijọsin rè̩ pé, “Kiyesi i, a kò rò idaji titobi ọgbọn rẹ fun mi; nitori ti iwọ kọja òkiki ti mo ti gbọ. Ibukún ni fun awọn enia rẹ, ibukún si ni fun awọn iranṣẹ rẹ wọnyi, ti nduro nigbagbogbo niwaju rẹ, ti o si ngbọ ọgbọn rẹ” (II Kronika 9:6, 7).

Eyi jẹ apẹẹrẹ bi awọn ọba aye yoo ti maa wa lati sin ati lati wári fun Ọmọ Ọba nigba Ijọba Rè̩. A ka ninu ori ẹkọ wa pe “Awọn ọba Tarṣiṣi, ati ti awọn erekuṣu yio mu ọrẹ wá; awọn ọba S̩eba ati ti Seba yio mu è̩bun wá. Nitõtọ, gbogbo awọn ọba ni yio wolẹ niwaju rè̩: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma sin i.”

Ijọba Sọlomọni bori gbogbo awọn orilẹ-ède ti o wà nigba aye rè̩, ṣugbọn Ijọba Ọlọrun lori ilẹ aye yoo de gbogbo opin aye. Ọpa irin ni Kristi yoo fi ṣe akoso; awọn keferi yoo jẹ ini Rè̩, gbogbo opin aye yoo si jẹ ti Rè̩ ni ini (Ka Orin Dafidi 2:8, 9).

A fi iran ikẹyin ọjọ hàn Daniẹli, o si kọ akọsilẹ yii pe, “Mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹnikan bi Ọmọ enia wá pẹlu awọsanma ọrun, o si wá sọdọ Ẹni-àgba ọjọ na, nwọn si mu u sunmọ iwaju rè̩. A si fi agbara Ijọba fun u, ati ogo, ati ijọba, ki gbogbo enia, ati orilẹ, ati ède, ki o le ma sin i; agbara ijọba rè̩ si jẹ agbara ijọba ainipẹkun, eyiti a ki yio rekọja, ati ijọba rè̩, eyiti a ki yio le parun” (Daniẹli 7:13, 14).

Ijuba Gbogbo Aye

“Nitori tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu li awọn ọba yio ma mu ọrẹ fun ọ wá” (Orin Dafidi 68:29). Ori ẹkọ wa sọ bayii, “On li a o si fi wura S̩eba fun” (Orin Dafidi 72:15). Asọtẹlẹ Isaiah sọ nipa awọn ti yoo wa lati juba Ọba naa pe, “Awọn Keferi yio wá si imọlẹ rẹ, ati awọn ọba si titàn yiyọ rẹ.” “Ọpọlọpọ rakunmi yio bò ọ mọlẹ, awọn ọmọ rakunmi Midiani on Ẹfa; gbogbo wọn o wá lati S̩eba: nwọn o mu wura ati turari wá; nwọn o fi iyìn OLUWA hàn sode. A o ṣà gbogbo ọwọ-ẹran Kedari jọ sọdọ rẹ, awọn àgbo Nebaioti yio ṣe iranṣẹ fun ọ; nwọn o goke wá si pẹpẹ mi pẹlu itẹwọgba, emi o si ṣe ile ogo mi li ogo” (Isaiah 60:3, 6, 7).

Orukọ Ayeraye

Ọpọlọpọ orilẹ-ède ni o ti paré̩, ogunlọgọ eniyan ni o si ti di ẹni igbagbe ninu iboji. Aimoye awọn ọba ati ijoye ni o ti fi ilẹ bora ti ẹnikẹni kò tun ri wọn tabi gbọ nipa wọn mọ. Orukọ wọn ti di igbagbe; iba diẹ ni a kọ silẹ nipa wọn ninu iwe itan.

S̩ugbọn Ọba ti yoo jẹ lori gbogbo ilẹ aye ni orukọ kan ti a kò ti i gbagbe, ti a kò si ni gbagbe titi aye ailopin. Bi ọdun ti n yi lu ọdun ni ogo orukọ Rè̩ n tan siwaju ati siwaju. Abawọn kan kò ba le orukọ Rè̩ ri lati ipilẹṣẹ, ogo rè̩ yoo si maa tàn titi lae. “Orukọ rè̩ yio wà titi lai: orukọ rè̩ yio ma gbilẹ niwọn bi ôrun yio ti pẹ to: nwọn o si ma bukún u fun ara wọn nipasẹ rè̩; gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma pè e li alabukúnfun” (Orin Dafidi 72:17).
Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ta ni Ọmọ Ọba?

  2. 2 Bawo ni a ṣe mọ pe ki i ṣe Sọlomọni ni Dafidi n gbadura fun ninu Psalmu yii?

  3. 3 Ki ni yoo jẹ aalà Ijọba yii?

  4. 4 S̩e apejuwe iru ijọba ti yoo gbilẹ nigba Ijọba Ọmọ Ọba naa.

  5. 5 Ki ni ṣe ti gbogbo awọn ọba miiran ati orilẹ-ède yoo maa juba Ọba yii?

  6. 6 Ki ni ṣe ti a kì yoo gbagbe orukọ Ọba yii?