Johannu 14:1-14

Lesson 235 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ máṣe jẹ ki ọkàn nyin daru, ẹ má si jẹ ki o warìri” (Johannu 14:27).
Notes

ẹyin Ajọ Irekọja

Jesu ati awọn ọmọ-ẹyin rè̩ ti pa Ajọ Irekoja mọ. Lẹyin ounjẹ alẹ, Jesu ba wọn sọrọ nipa ohun ti yoo ṣẹlẹ ni lọwọlọwọ. Akoko sisẹ Jesu ati ikú Rè̩ sún mọ tosi, Jesu si n sọ ọrọ imulọkanle fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩.

Jesu kilọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ki wọn má ṣe jẹ ki ọkàn wọn dàru. Ni tootọ ọpọlọpọ iṣẹlẹ ni o ti ṣẹlẹ ti o le mu ọkàn wọn rẹwẹsi, ti o si le dan igbagbọ ati igbẹkẹle wọn wò. Lai si aniani ọkàn wọn wuwo nitori Judasi Iskariotu ẹni ti o fi ẹgbẹ wọn silẹ lẹyin ounjẹ alẹ nì ti o si ti jade lọ loru. Jesu kò ha ti sọ pe ẹni kan ninu wọn yoo fi Oun hàn? Jesu kò ha ti fi okele run ọbẹ ti O si ti fi i fun Judasi Iskariotu? Ki ni itumọ gbogbo eyi? Ọkan ninu awọn mejila yoo ha fi Kristi rè̩ hàn?

Boya wọn bẹrẹsi rò nipa Peteru ẹni ti o n fẹ lati fi ẹmi rè̩ lelẹ nitori Kristi. Peteru ti wi pe oun ki yoo kọsẹ nitori Kristi, bi gbogbo awọn iyoku tilẹ kọsẹ (Matteu 26:33). Jesu kò yin Peteru fun iru ọrọ ijolootọ bẹẹ, bẹẹ ni kò si ba a wi pe o jọ ara rè̩ loju. Jesu wi fun Peteru pe: “Li oru yi ki akukọ ki o to kọ iwọ o sé̩ mi nigba mẹta” (Matteu 26:34).

Ikilọ Tẹlẹ

Jesu ti kilọ fun wọn nipa ikú Rè̩, pe a o “gbé mi soke . . . o nṣapẹrẹ irú ikú ti on o kú” (Johannu 12:32, 33). Aṣaaju wọn yoo ha fi wọn silẹ? A o ha fi wọn silẹ ki ireti wọn si ja si imulẹmofo?

Ju bẹẹ lọ, a o sọ fun awọn ọmọ-ẹyin nipa iyà ti wọn o jẹ lẹyin ti Kristi ba ti fi wọn silẹ (Johannu 16:2). Wọn o gbọ nipa ẹgàn ti o n bọ, ati pe ayé yoo korira wọn nitori pe wọn ti korira Kristi (Johannu 15:18).

Ọrọ Itunu

Ẹkọ wa jẹ apa kan ọrọ ikẹyin ti Jesu ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ sọ ki a to bẹrẹ si yẹ ẹjọ Rẹ wo, awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ti o ṣọwọn pupọ fun ẹmi Rè̩. Lati ran wọn lọwọ lati tu ọkàn wọn ti o daamu ninu, Jesu sọ ọrọ itunu wọnyi: “Ẹ máṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ, ẹ gbà mi gbọ pẹlu.” Ki i ṣe awọn ọmọ-ẹyin Jesu ni igba naa nikan ni ọrọ wọnyi jẹ itunu fun, ṣugbọn o ti jẹ itunu fun ọpọlọpọ awọn ọmọlẹyin Jesu lati igba naa wa. Ọrọ Kristi ti ran wọn lọwọ lati pa igbagbọ ati igbẹkẹle wọn ninu Rè̩ mọ.

“Ẹ máṣe jẹ ki ọkàn nyin daru.” Awọn ẹlomiran le wà ninu idaamu nipa ohun ti wọn ni lati gbagbọ tabi ẹni ti wọn ni lati gbẹkẹle. S̩ugbọn ni pataki awọn ọmọ-ẹyin Jesu kò ni lati daamu tabi ki wọn ni aibalẹ ọkàn nipa ọjọ ọla. Pẹlu igbẹkẹle wọn ninu Oluwa, awọn ọmọ-ẹyin Kristi le bori idojukọ ati idanwo ti o wu ki o le de.

Pẹlu Ọkàn

Jesu kò wi pe wọn kò gbọdọ ni idaamu ninu ero wọn. O ni ki wọn má ṣe jẹ ki ọkàn wọn dàrú! Ọkàn wa ni a fi n gbẹkẹle Ọlọrun, ki i ṣe pẹlu ero wa. Igbala ki i ṣe ti ero; o jẹ iriri ti a n ni nigba ti ọkàn wa ba ṣe deedee pẹlu Ọlọrun. “Ọkàn li a fi igbagbọ si ododo; ẹnu li a si fi ijẹwọ si igbala” (Romu 10:10). Nigba ti ọkàn eniyan ba sinmi le Oluwa, ero rè̩ ki i dàrú rara. Paulu kọwe si awọn ara Filippi pe “alafia Ọlọrun, ti o jù imọran gbogbo lọ, yio ṣọ ọkàn ati ero nyin ninu Kristi Jesu” (Filippi 4:7).

Loni, a kò mọ ohun ti o wà niwaju fun wa, ṣugbọn igbagbọ wa kò gbọdọ mi. Igbẹkẹle wa wà ninu Ọlọrun. A mọ pe “ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun” (Romu 8:28). Onipsalmu sọ nipa ẹni ti o bẹru Ọlọrun ti o si n pa ofin Rè̩ mọ: “Kì yio bè̩ru ihìn buburu: aiya rè̩ ti mu ọna kan, o gbẹkẹle OLUWA” (Orin Dafidi 112:7). A kà ninu Iwe Owe “Jù gbogbo ohun ipamọ, pa aiya rẹ mọ; nitoripe lati inu rè̩ wá ni orisun iye” (Owe 4:23).

Igbagbọ

Gbigbà Ọlọrun gbọ a maa gba eniyan lọwọ wiwà ninu idaamu. Dafidi ni oun i ba ti dákú bi kò ba ṣe pe oun ti gbagbọ. (Orin Dafidi 27:13). Eniyan le ni ẹdùn lọkàn, iwuwo ati idanwo, ṣugbọn ọkàn ti o gbẹkẹle Ọlọrun kò ni de ipo ainireti ati ijọgọnù. Onipsalmu wi pe: “Ẽṣe ti ori rẹ fi tè̩ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun” (Orin Dafidi 42:5).

Igbẹkẹle

Jesu n fẹ ki awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni igbẹkẹle kan naa ninu Oun gẹgẹ bi wọn ti ni ninu Ọlọrun. O fé̩ ki wọn gbà Oun gbọ. Ohun pataki ni o jẹ fun wa loni pẹlu pe ki a gbà Jesu gbọ. Ọpọlọpọ ni o wi pe wọn gba Ọlọrun gbọ gẹgẹ bi awọn Ju ti igbà Majẹmu Titun, ṣugbọn a ni lati gba Jesu gbọ pẹlu ki a to le ni iye ainipẹkun (Johannu 3:16). Nipa gbigba Oluwa Jesu Kristi gbọ ni igbala ti i wá (Iṣe Awọn Aposteli 16:31). A ni lati gbagbọ pe Jesu ni Ọmọ Ọlọrun.

Pipese Ayè Kan Silẹ

Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe Oun n lọ. Idi kan wà fun lilọ Rè̩. O ni iṣẹ lati ṣe. O ni Oun yoo pese àyè silẹ fun wọn. Ni Ọrun, nibi ti Ọlọrun Baba wà, àyè wa fun ọpọlọpọ eniyan. Jesu wà nibẹ nisisiyi O n pese àyè silẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩. Bi o ba ti ri igbala, Jesu n pese àyè silẹ fun ọ.

A ti sọ pe gẹgẹ bi igbesi-aye ti a gbe nihin yii ba ti ri ni ohun-elo ibugbe wa lọhun yoo ti ri. Irú ohun-elo wo ni iwọ n fi ranṣẹ fun ipese silẹ ile rẹ - “wura, fadaka, okuta-iyebiye, igi, koriko, akekù koriko?” (Ka I Kọrinti 3:11-15). Gẹgẹ bi ohun ti iwọ n ṣe, n jẹ o ro pe o lẹtọ si ile daradara ti o si tobi? Boya eyi ti o san ju bẹẹ lọ yoo jẹ ti rẹ nipa ṣiṣe iṣẹ si i fun Jesu ati awọn ẹlomiran.

Ipadabọ Rè̩

Jesu tu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ninu nipa sisọ pe bi Oun ba lọ Oun o tun pada wá. Oun yoo pada wá mu awọn eniyan Rè̩ ki wọn ba le wa pẹlu Rè̩. Awa mọ pe ni tootọ ni Jesu lọ. A kà ninu Iṣe Awọn Apọsteli nipa igoke-re-Ọrun Rè̩. “Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, bi nwọn ti nwò, a gbé e soke; awọsanma si gbà a kuro li oju wọn” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:9). Bẹẹ gẹgẹ ni Jesu yoo tun pada wa. Jesu wi pe, “Emi o tún pada wá.” Lẹyin ti Jesu ti goke re Ọrun, awọn ọkunrin meji ninu aṣọ funfun sọ fun awọn eniyan naa pe, “Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bḝ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o n lọ si ọrun” (Iṣe Awọn Aposteli 1:11).

Eredi Ipadabọ Rè̩

Ki ni ṣe ti Jesu tun n pada bọ? O n pada bọ fun awọn eniyan Rè̩, fun awọn ti o ti mura silẹ ti wọn n ṣọna. O n pada bọ fun awọn ti o ti mura silẹ lati gbe ni ibi ti a ti pese silẹ ni Ọrun.

Bibọ Jesu sun mọ etile. A ni lati mura silẹ, nitori pe kò ni si àyè lati ṣe imurasilẹ nigba ti ipè ba dún. Ẹpisteli Jakọbu kilọ fun wa bayi pe “Ẹ mu sụru; ẹ fi ọkàn nyin balè̩: nitori ipadawa Oluwa kù si dẹdẹ” (Jakọbu 5:8).

Nigba bibọ Jesu, a o kó gbogbo awọn eniyan Rè̩ “lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun ọrun kan lọ de ikangun keji” (Matteu 24:31), “bḝli awa ó si ma wà titi lai lọdọ Oluwa” (I Tẹssalonika 4:17).

Ibeere

Awọn kan ninu awọn ọmọ-ẹyin ni ibeere lati beere. Tọmasi beere nipa ọna naa. Lai si aniani o rò pe Jesu n lọ si ile nla kan ninu aye yii ni, nitori pe awọn ọmọ-ẹyin ti ni ireti pe Jesu yoo gbe ijọba ti ẹda kalẹ ni ayé ni akoko naa. Eyi ni idahun ti Jesu fi fun un: “Emi li ọna, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi.”

Ọna, Otitọ ati Iye

Jesu ni Ọna wa si Ọrun ati Amọna wa si iye ainipẹkun. “Kò si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là” (Iṣe Awọn Apọsteli 4:12). Nipa titẹle apẹẹrẹ ati ẹko Jesu ni a fi n ri ọna si Ọrun, a o si ni iye ainipẹkun. Ẹjẹ Jesu nikan ni o le wẹ è̩ṣẹ wa nu ki o si pese wa silẹ fun Ọrun. Jesu ni Ọna tootọ ati iye, “Ọna iwa-mimọ; alaimọ kì yio kọja nibẹ . . . ṣugbọn awọn ti a ràpada ni yio ma rìn nibẹ” (Isaiah 35:8, 9).

Ibeere Filippi

Filippi beere pe ki a fi Baba hàn wọn. Filippi ti ri Jesu nigba pupọ. Oun ni o n ba sọrọ yii. Jesu ni “aworan Ọlọrun” (II Kọrinti 4:4), “aworan on tikararè̩” (Heberu 1:3). Niwọn igba ti Filippi ti ri Jesu, o yẹ ki Filippi ti mọ Baba nipa igbesi-aye Jesu. Filippi fi oju ri Jesu ninu ara, ṣugbọn awa n ri I nisisiyi nipa igbagbọ. Jesu wi pe a ni lati gba Ọrọ ti Oun sọ gbọ nitori pe ọrọ Rè̩ ati iṣẹ Rè̩ fi hàn pe Ọlọrun n ṣiṣẹ ninu Rè̩.

Ju wọnyi lọ, Jesu wi pe awọn ti o gbagbọ yoo ni agbara lati ṣe iṣẹ nla fun Ọlọrun lẹyin ti Jesu ba lọ. Jesu sọ pe wọn o ni agbara lati ṣe iṣẹ ti o tobi ju eyi ti Oun ti ṣe lọ. S̩iwaju akoko yii, Jesu ti fun wọn ni agbara lati ṣe iṣẹ iyanu. O ti ran awọn mejila jade lati waasu pe, “Ijọba ọrun kù si dè̩dẹ.” Jesu sọ fun wọn pẹlu pe ki wọn “mā ṣe dida ara fun awọn olokunrùn, ẹ sọ awọn adẹtè̩ di mimọ, ẹ si jí awọn okú dide, ki ẹ si mā lé awọn ẹmi èṣu jade ” (Matteu 10:7, 8). Nitootọ wọn si “lé ọpọ awọn ẹmi èṣu jade, nwọn si fi oróro kùn ọpọ awọn ti ara wọn ṣe alaida, nwọn si mu wọn larada” (Marku 6:13).

Ipese Ọlọrun

Lẹyin ti Jesu lọ sọdọ Baba Rè̩, awọn ọmọ-ẹyin Rẹ bẹrẹ si i tan Ihinrere kalẹ. Ọlọrun ti ṣe ipese silẹ pe lẹyin ti Jesu ba ti lọ, Oun yoo fun wọn ni “Olutunu miran” (Johannu 14:16) ẹni ti yoo maa ba wọn gbe ti yoo si maa gbe ninu wọn lati fun wọn ni agbara (Johannu 14:17). Awọn ọmọ-ẹyin yoo ṣe iṣẹ iyanu, wọn o si tan Ihinrere kalẹ. Awọn ọmọ-ẹyin ni lati maa ba Jesu sọrọ nipa adura. Wọn o maa ṣe iṣẹ-iyanu nipa adura ati igbagbọ ninu agbara Ọlọrun. Jesu kọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe agbara wà ninu adura. Ohunkohun ti wọn ba beerè ni orukọ Jesu, Oun yoo ṣe e.

Lẹyin ti Jesu ti fi awọn ọmọ-ẹyin silẹ, ọpọlọpọ iṣẹ-iyanu ni a ṣe nipa agbara Ọlọrun. A ranti pe obinrin kan ti ri imularada nipa fifi ọwọ tọ iṣẹti aṣọ Jesu (Matteu 9:20-22). Iṣẹ-iyanu ti o tilẹ ju eyi lọ ni awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ yoo ṣe lẹyin ti wọn ba ri ileri Baba gbà (Iṣe Awọn Apọsteli 1:4; Johannu 14:12), eyi ti wọn ri gba ni ọjọ Pẹntekọsti (Iṣe Awọn Apọsteli 2:1-4). “Ọlọrun si ti ọwọ Paulu ṣe ìṣẹ aṣẹ akanṣe: tobè̩ ti a fi nmu gèle ati ibanté̩ ara rè̩ tọ awọn olokunrun lọ, arùn si fi wọn silẹ, ati awọn ẹmi buburu si jade kuro lara wọn” (Iṣe Awọn Apọsteli 19:11, 12). Awọn miiran ti o n ṣaisan ni a té̩ si ẹba ọna fun imularada, pe bi Peteru ba n kọja ki ojiji rè̩ tilẹ le ṣiji bò wọn (Iṣe Awọn Apọsteli 5:15). Lẹyin ọkan ninu awọn iwaasu Peteru, ogunlọgọ eniyan ni o yipada. “Awọn ti o si fi ayọ gbà ọrọ rè̩ a baptisi wọn: li ọjọ na a si kà ìwọn ẹgbẹdogun ọkàn kún wọn” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:41).

Irú agbara bayi ni Ọlọrun ti pese silẹ fun awọn eniyan Rè̩ ni ayé. Ni Ọrun Jesu n pese ibugbe silẹ fun wọn. Ọlọrun ṣe ipese silẹ fun awọn eniyan Rè̩ ni ayé ati ni Ọrun. O n fi agbara fun ni fun ọjọ kọọkan ati ireti ti o logo ti iye ainipẹkun fun ọjọ ti n bọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Darukọ diẹ ninu awọn nnkan ti o daamu awọn ọmọ-ẹyin.

  2. 2 Ki ni ṣe ti eniyan ni lati gbà Ọlọrun ati Jesu gbọ?

  3. 3 Ki ni ṣe ti Jesu fi awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ silẹ?

  4. 4 Nibo ni O lọ?

  5. 5 Bawo ni a ṣe mọ pe Jesu tun n pada bọ?

  6. 6 Awọn wo ni O n bọ wa fun?

  7. 7 Ki ni Jesu ṣeleri fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ nipa adura?

  8. 8 Ki ni ohun ti a ṣeleri fun awọn ọmọ-ẹyin ki wọn ba le ṣe iṣẹ-iyanu ti o tilẹ tobi ju eyi ti Jesu ṣe?

  9. 9 Ki ni ohun ti Ọlọrun ti pese silẹ fun awọn eniyan Rè̩ ni ayé?

  10. 10 Ki ni Jesu n pese silẹ ni Ọrun fun awọn eniyan Rè̩?