Johannu 15:1-27

Lesson 236 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Eyi li ofin mi, pe ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin, gẹgẹ bi mo ti fẹràn nyin” (Johannu 15:12).
Notes

A So Wa Pọ

Jesu mọ wi pe lai pẹ Oun yoo fi awọn ọmọ-ẹyin Oun silẹ Oun yoo si pada lọ si Ọrun. Oun kò fẹ ki wọn maa ronu pe a fi awọn nikan silẹ nigba ti wọn kò ba ri I, nitori bẹẹ O pa owe kan fun wọn lati fi hàn wọn pe Oun yoo maa wà ni tosi wọn – Oun o sun mọ wọn timọtimọ gẹgẹ bi igi ajara ti ri si awọn ẹka rè̩. O si fi hàn wọn pe Ọlọrun kò jinna pẹlu. Ọlọrun jẹ oloootọ oluṣọ ọgba ajara kan, O si n fi pẹlẹpẹlẹ ṣe abojuto ajara naa ati awọn ẹka rè̩ alailagbara. Ifẹ Ọlọrun ni o so gbogbo wa pọ -- Ọlọrun Baba (Oluṣọgba) Jesu (Ajara tootọ), ati awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ tootọ (ẹka) – sinu irẹpọ timọtimọ.

Awọn Apọsteli mọ pe Ọlọrun fẹran Jesu. Ninu wọn ti gbọ ohùn Rè̩ lati Ọrun wi pe, “Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi” (Matteu 17:5). Wọn si ti gbọ nigba ti Jesu gbadura bayi: “Baba, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti iwọ gbọ ti emi. Emi si ti mọ pe, iwọ a ma gbọ ti emi nigbagbogbo” (Johannu 11:41, 42). Nitootọ ifẹ nla ti o wà laaarin Baba ati Ọmọ ni o mu iru igboya bayi wá!

Jesu wa sọ fun awọn Apọsteli pe, “Gẹgẹ bi Baba ti fẹ mi, bẹli emi si fẹ nyin.” Wo ifẹ iyanu si eniyan ẹlẹran ara! N jẹ iwọ le rò pe Jesu fẹran wa, awa ọmọ Rè̩ oloootọ, gẹgẹ bi Baba Rè̩ ti fẹran Rè̩?

O Gbọran Titi de Oju Iku

Idi kan ti Ọlọrun fi fẹran Jesu ni pe O yọọda lati kú fun awọn ẹlẹṣẹ. Nigba ti Ọlọrun bojuwo ilẹ sori aye è̩ṣẹ yi ti O si ri i pe ọkàn awọn eniyan jẹ kiki ibi nigba gbogbo, O kede ni Ọrun pe gbogbo awọn eniyan wọnyi ni yoo ṣegbe dandan ti iya yoo si jẹ wọn lọpọlọpọ, ayafi ti ẹni kan ti kò ni è̩ṣẹ ba yọọda lati kú ni ipo wọn. Jesu tẹti silẹ nigba ti Baba Rè̩ n sọrọ, O si dahun wi pe Oun yoo lọ, gẹgẹ bi a ti pinnu rè̩ lati ipilẹṣẹ aye wa (Ifihan 13:8). O yọọda lati fi Ọrun silẹ nibi ti gbogbo wọn fẹran Rè̩, ti wọn si n juba Rè̩, O si wa gbe ninu aye nibi ti O mọ pe wọn o korira Oun ki wọn si kàn Oun mọ agbelebu, ki iwọ ati emi ba le ri igbala. O yọọda lati jiya fun wa ati lati ru è̩ṣẹ wa lori Oun tikara Rè̩. “O rè̩ ara rè̩ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú, ani ikú ori agbelebu. Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbé e ga gidigidi, o si ti fi orukọ kan fun u, ti o bori gbogbo orukọ” (Filippi 2:8, 9). Jesu kú fun ogo Ọlọrun, ati nitori pe O fẹran ẹlẹṣẹ to bẹẹ ti O fi rà wọn fun ara Rè̩ pẹlu Ẹjẹ ti Rè̩.

Ifẹ Si Ẹni Keji

Ọlọrun Baba, ati Ọlọrun Ọmọ nikan kọ ni awọn ti o ni ifẹ. Nisisiyi Jesu pa aṣẹ yi, “Ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin, gẹgẹ bi mo ti fẹran nyin.” O wi pe, “Kò si ẹnikan ti o ni ifẹ ti o tobi jù eyi lọ, pe ẹnikan fi ẹmi rè̩ lelẹ nitori awọn ọré̩ rè̩.” O fẹ ki awa naa ni iru ifẹ bayi.

Nigba ti Paulu Apọsteli kọwe si awọn ara Filippi, o wi pe, “Ẹ ni ero yi ninu nyin, eyi ti o ti wà pẹlu ninu Kristi Jesu.” Bi Jesu ba yọọda lati fi ẹmi Rè̩ lelẹ lati gbà ọkàn wa la, o yẹ ki awa naa yọọda lati fi ẹmi wa lelẹ lati ran Jesu lọwọ lati gbà awọn ọkàn miiran la pẹlu.

Kò si ẹni kan ti o le ri igbala lai si Ẹjẹ Jesu, nitori bẹẹ, bi a ba tilẹ kú fun ẹnikẹni, a kò le gbà a la funra wa. S̩ugbọn Jesu n fẹ ki a fi aye wa rubọ lati ran An lọwọ lati tàn ihin igbala kaakiri gbogbo aye. Nipa wiwà laaye fun Jesu o le jẹ pe a le wulo fun Un ju pe ki a fi ẹmi wa lelẹ lọ. S̩ugbọn ohun ti o gbọdọ ṣe pataki ju lọ ninu igbesi-aye wa ni ijolootọ wa si Ọlọrun ati ijọsin wa fun Un. A ki i ṣe aniyan pupọ nipa ibi ti a n gbe, ohun ti a n jẹ, tabi aṣọ ti a n wọ, to bi a ti n ṣe nipa jijere ọkàn ti o n ṣegbe fun Jesu. A fẹran gbogbo eniyan to bẹẹ ti o fi jẹ pe a fẹ ki wọn lọ si Ọrun ki wọn si maa wà lọdọ Jesu titi lae; a si ṣetan lati ṣiṣẹ karakara lati ran wọn lọwọ.

Ki Ọrọ Rè̩ maa Gbe Inu Wa

Jesu wi pe “Ọrẹ mi li ẹnyin iṣe, bi ẹ ba ṣe ohun ti emi palaṣẹ fun nyin.” N jẹ o mọ awọn aṣẹ Rè̩? O mọ diẹ ninu wọn. S̩ugbọn bawo ni o ti fi ara balẹ to lati ka Bibeli to bẹẹ ti iwọ o fi mọ gbogbo ọrọ Jesu? Ninu Ihinrere ti Matteu, Marku, Luku, ati Johannu ni a kọ awọn ọrọ ti Jesu sọ gan an nigba ti o wà ninu aye si. S̩ugbọn nigba melo ni o maa n kiyesi lati le mọ wọn? O le ti kà wọn ri, ṣugbọn o kò le ranti gbogbo wọn tán. A ni lati maa yẹ inu Ọrọ nì wo lojoojumọ ki a ba le ni idaniloju pe ohun ti Jesu palaṣẹ ni a n ṣe. Ọrọ Rè̩ ni lati maa gbe inu wa.

Jesu wi fun awọn akọwe ati awọn Farisi pe, “Ẹnyin nwá inu iwe-mimọ nitori ẹnyin rò pe ninu wọn li ẹnyin ni iye ti ko nipẹkun.” S̩e o tẹ ọ lọrun lati rò pe o ni iye ti kò nipẹkun nitori pe nigba kan ri o ti ni igbala, isọdimimọ, ati Ifiwọ-ni-Ẹmi-Mimọ? Tabi lojoojumọ ni o n yẹ Ọrọ Rè̩ wò lati ni idaniloju pe o wà ni imurasilẹ lati pade Jesu?

Iwẹnumọ nipa Ọrọ Naa

Jesu wi pe, “Ẹnyin mọ nisisiyi nitori ọrọ ti mo ti sọ fun nyin.” Dajudaju a ni lati jẹ mimọ ki a tó le wà ni imurasilẹ lati pade Jesu; bẹẹ ni a si ni lati maa wẹ ẹni kọọkan wa mọ nipa fifi “ọrọ wẹ ẹ mọ ninu agbada omi” lẹyin ti a ba tilẹ ti ri isọdimimọ. Bi a ti ntè̩ siwaju lati maa kà ọrọ Jesu, a o maa ri ohun titun ti O n fẹ ki a ṣe, a o si maa ran wa leti awọn nnkan miiran ti a ti mọ tẹlẹ ṣugbọn ti a ti ṣai kà si. Bi a o ba maa gbe ninu Ajara tootọ, a ni lati jẹ ki Ọrọ Ọlọrun maa gbe inu wa.

“Bi ẹnyin ba ngbé inu mi, ti ọrọ mi ba si ngbé inu nyin, ẹ o bère ohunkohun ti ẹ ba fẹ, a o si ṣe e fun nyin.” Bi a kò ba ri idahun si adura wa, o ṣanfaani lati yẹ ọkàn wa wò lati mọ boya ọrọ Jesu “ngbe” inu wa. Awọn ileri ti O fun wa kò le yè̩. Otitọ ni O n sọ nigba ti O wi pe Oun yoo dahun adura wa. Nitori naa bi Oun kò ba gbọ ti wa nigba ti a ba gbadura, o yẹ ki a yẹ Ọrọ naa wo lati kiyesi boya aṣẹ kan wà ti a ti ṣe ainaani rè̩ tabi ti a ti gboju fò dá. È̩ṣẹ tilẹ le ti yọ wọ inu eniyan ti o ti jẹ Onigbagbọ ri, ti oun kò tilẹ mọ nitori ainaani rè̩ titi oun fi wo inu Ọrọ naa ti o si ri ofin kan ti o ti rú. Bi irú ẹni bẹẹ kò ba yẹ ọrọ Ọlọrun wo, o le má ri ikuna rè̩ lae.

Ọrọ Naa ni yoo S̩e Idajọ

Njẹ a mọ riri Ọrọ Ọlọrun? Nipasẹ rè̩ ni a o ti da araye lẹjọ ninu idajọ nla nì. Jesu wi pe, “Ọrọ ti mo ti sọ, on na ni yio ṣe idajọ rè̩ ni igbẹhin ọjọ.” Bi o ba jẹ lati inu Bibeli ni a o ti ṣe idajọ wa, njẹ o kò ro wi pe o wa ṣe danindanin fun wa lati ka a lẹsọlẹsọ, ki a ba le mọ ohun ti o n wi? A maa n kọ ẹkọ wa ni ile-iwe bi o ti tọ, ṣugbọn o tilẹ ṣe pataki pupọ lati mọ Ọrọ Ọlọrun ju lati mọ ẹni ti o kọkọ jẹ aarẹ orilẹ-ede wa, ipinlẹ melo ni o para pọ di orilẹ-ède wa, iye ogun ti orilẹ-ède wa ti jà, tabi awọn orilẹ-ède wo ni o lagbara ju lọ ninu ayé. Bi a ba fi akoko ti a n lo nile lati ṣiṣẹ ti wọn fun wa lati ile iwe ṣe odiwọn, iba akoko melo ni a n lo lati fi kẹkọọ Ọrọ Ọlọrun?

Eso Ọpọlọpọ

Awa, gẹgẹ bi Onigbagbọ, jé̩ ẹka lara Jesu, Ẹni ti o jé̩ Ajara, o si yẹ ki a so eso ọpọlọpọ fun Un. Eso diẹ kò le tẹ Ẹ lọrun – o ni lati pọ. A le maa so eso ki a si maa rò pe a n ṣe ifẹ Ọlọrun – nigba naa awọn idanwo kan yoo de ti yoo jẹ iyalẹnu fun wa. Jesu wi pe, “Gbogbo ẹká ti o ba si so eso, on a wè̩ ẹ mọ, ki o le so eso si i.” Nipa iwẹnumọ naa (awọn iyiiriwo) a o ri i pe awọn nnkan miiran wà ti a le kọ, bi i suuru, iwa-tutu, ipamọra, ati iṣoore, awọn nnkan ti yoo ṣe wa ni Onigbagbọ daradara si i.

Jẹ ki a sọ nipa inunibini. Boya iwa ti a o kọkọ hù ni lati bá olukuluku ẹni ti o ba sọrọ odi si wa jà. O le jẹ nitori naa ni Oluwa ṣe jẹ ki o wá – lati fi hàn wa pe a kò ni ifẹ ọmọnikeji tó bi a ti ro pé a ni in. Ifẹ jẹ ọkan ninu awọn eso ti Jesu n fẹ ki a so, lati fẹran awọn ọrẹ wa nikan kò si to. “Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin” (Matteu 5:44). Fifẹran awọn ọrẹ rẹ yoo jé̩ eso diẹ, ṣugbọn fifẹran awọn ọta rẹ yoo jé̩ eso ti o pọ lọpọlọpọ.

A le ti rò pé iṣẹ wa fun Jesu nikan ni eso. A le rò pé a n so eso lọpọlọpọ nitori pe a n kọrin a si n jẹri fun Jesu; a maa lọ n bẹ awọn ti kò ni ọrẹ wo a si lọ n ki awọn alaisan; a si n ran awọn ẹlomiran lọwọ ninu wahala wọn, a si n yọọda ara wa fun iṣẹ-isin. S̩ugbọn Bibeli sọ fun wa pé awọn eso ti Ẹmi ni “Ifẹ, ayọ, alafia, ipamọra, ìwa pẹlẹ, iṣore, igbagbọ, iwa tutù, ati ikora-ẹni-nijanu” (Galatia 5:22, 23). Peteru Apọsteli tun ka awọn eso miiran si i fun wa: “Ki gbogbo nyin ṣe oninu kan, ẹ mā ba ara nyin kẹdun, ẹ ni ifẹ ará, ẹ mā ṣe iyọnú, ẹ ni ẹmi irẹlẹ” (I Peteru 3:8). Hihu iwa ọmọluwabi paapaa jẹ eso kan, bi a ba ṣe e bi si Oluwa. Awon eso ti o yẹ ki a ni lọpọlọpọ ti o si yẹ ki a fi kún ni wọnyi.

O le gbà pe ki a la iyà ati ipọnju kọja ki a ba le kọ ipamọra, iṣoore, ati iwa pẹlẹ sii; ṣugbọn bi a ba fara dà a pẹlu ero wi pe lati ọdọ Ọlọrun wá ni, ati fun ire wa, a o gbadun ere siso “eso ọpọlọpọ.” “Gbogbo ibawi kò dabi ohun ayọ nisisiyi, bikoṣe ibanujẹ; ṣugbọn nikẹhin a so eso alafia fun awọn ti a ti tọ nipa rè̩, ani eso ododo” (Heberu 12:11). Bi a ba ni eso rere yii ninu ọkàn wa, awọn iṣẹ oore ti a n ṣe fun awọn ẹlomiran kò le ṣai sun jade.

Olutunu

Ẹkọ miiran wà ti Jesu n fẹ ki awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ fi sọkàn. O ti tẹnumọ bi Ọrọ Rè̩ ti ṣe danindanin to, ṣugbọn ki wọn má ba gbagbe nipa rè̩ lẹyin ti Oun ba ti lọ, O ṣeleri lati ran Olutunu, ti i ṣe Ẹmi-Mimọ lati maa ran wọn leti gbogbo Ọrọ Rè̩. “On na ni yio jẹri mi.” Ni akoko miiran O wi pe, “Nigbati on, ani Ẹmi otitọ ni ba de, yio tọ nyin si ọna otitọ gbogbo; nitori kì yio sọ ti ara rè̩ . . . On o ma yin mi logo” (Johannu 16:13, 14).

Nigba ti a ba fi Ẹmi Mimọ wọ wa, Ẹmi naa a si maa kọ wa ni otitọ; Oun a maa jẹri nipa Jesu pẹlu. A ha n jẹ ki O tipa wa sọrọ bi? A ha njé̩ ki araye mọ wi pe Onigbagbọ ni wa? A ha n ṣamọna awọn ẹlomiran wa sọdọ Jesu? Iṣẹ ti Ẹmi n ṣe ni yii; bi O ba si wa ninu wa, iṣẹ ti awa naa n ṣe ni yii – pipolowo Jesu.

Ọrọ ikẹyin ti Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni pé: “Ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmi Mimọ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalẹmu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8). Awon ti wọn ṣe ẹlẹri olóòótọ fun Jesu ni ẹka rere naa, ti wọn n gbe inu Ajara tootọ.

A o Ké Ẹka Alaileso Kuro

A ti sọrọ pupọ lori awọn ẹka ti n so eso. Awọn ti kò ba so eso n kọ? Jesu wi pe a o ké wọn kuro. Wọn kò ni si lara Ajara tootọ mọ; wọn kò ni ni ipin pẹlu Jesu. Siwaju si i a o jẹ wọn niya wọn ó si ṣegbe titi lae ti wọn kò ba ronupiwada, ki won si pada sọdọ Jesu – ki a le tun wọn lọ si ara ajara lẹẹkan si i.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ta ni Ajara tootọ?

  2. 2 Awọn wo ni ẹka?

  3. 3 Ipa wo ni Ọlọrun kó nipa Ajara ati awọn ẹka?

  4. 4 Sọ diẹ ninu awọn eso rere.

  5. 5 Ki ni Ọlọrun maa n ṣe si awọn ẹka ti n so eso?

  6. 6 Bawo ni eso wa ti ni lati pọ to?

  7. 7 Ninu Iwe wo ni a ti n ri è̩kọ ti o ṣe pataki ju lọ fun igbesi-aye wa?

  8. 8 Fun idi wo ni a ṣe ran Olutunu, ani Ẹmi Mimọ, wa sinu aye yii?

  9. 9 Ki ni o yẹ ki a maa ṣe fun Oluwa?

  10. 10 Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ẹka ti kò ba so eso?