Lesson 237 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Nigbati on, ani Ẹmi otitọ ni ba de, yio tọ nyin si ọna otitọ gbogbo” (Johannu 16:13).Notes
Ikilọ Kan
Eyi ni iwaasu idagbere Jesu fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩. O kilọ fun wọn nipa inunibini ti wọn kò le ṣai là kọja. Nitori naa nigba ti ijiya naa ba dé, ki wọn ma ṣe bẹru ki o má si ṣe ya wọn lẹnu. Awọn ẹlomiran yoo pa awọn ọmọ-ẹyin lara wọn a si rò pe awọn n ṣe iṣẹ isin fun Ọlọrun. Wọn yoo ṣe bẹẹ nitori pe wọn kò gba Jesu gbọ. Wọn gba Ọlọrun gbọ -- ṣugbọn wọn kò gbà Jesu gbọ.
Saulu
Akọsilẹ kan ti o wu ni lori wà nipa ẹni kan bẹẹ, ti o ṣe inunibini si awọn Onigbagbọ ti o si ro pe oun n ṣe iṣẹ-isin fun Ọlọrun. Orukọ rè̩ ni Saulu ara Tarsu, ẹni ti a wa mọ ni Paulu nikẹyin. Bi Saulu ti n rin irin-ajo lọ si Damasku pẹlu iwe aṣẹ lati fi ọmọ-ẹyin Jesu ti o ba ri sinu tubu, Oluwa fi ara Rè̩ hàn fun un (Iṣe Awọn Apọsteli 26:15). Imọlẹ nla kan lati Ọrun tàn si i to bẹẹ ti Saulu kò fi riran fun ọjọ mẹta. Oluwa pe e ni orukọ, Saulu si dahun pe “Oluwa, kini iwọ nfẹ ki emi ki o ṣe?” (Iṣe Awọn Apọsteli 9:6). Saulu tẹle aṣẹ Oluwa. O gbadura o si ri igbala. Saulu di ajihinrere ati ẹlẹri nla si agbara Ọlọrun.
Jesu Yoo Fi Wọn Silẹ
Nigba ti Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe Oun ni lati lọ, ọkàn wọn kún fun ibanujẹ. Jesu wi pe “Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ è̩wẹ, ẹ ó si ri mi, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.” Oye ohun ti Jesu n sọ kò yé awọn ọmọ-ẹyin Rè̩. O ṣe alaye fun wọn pe wọn yoo ni ibanujẹ fun saa kan nigba ti aye yoo maa yọ. S̩ugbọn akoko ẹkún kì yoo pẹ lọ titi. Igbà kan yoo de ti yoo jẹ igbà ayọ nlá nlà. Jesu yoo fi wọn silẹ, wọn o si kún fun ibanujẹ nigba naa; ṣugbọn Jesu yoo tun fara hàn fun wọn lẹẹkan si i, yoo si mu ayọ nla ba wọn.
Olutunu Kan
Pẹlu awọn ọrọ imulọkanle, Jesu fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni ileri iyanu kan pe Olutunu yoo tọ wọn wá lẹyin ti Jesu ba ti lọ. Ta nì Olutunu naa? Olutunu naa ni Ẹmi Mimọ (Johannu 14:26), Ẹni ti i ṣe Ẹni kan ninu Mẹtalọkan. O jé̩ ọkan ninu awọn Mẹta ti “o njẹri li ọrun, Baba, Ọrọ, ati Ẹmi Mimọ: awọn mẹtẹta yi si jasi ọkan” (I Johannu 5:7). Ki, ni Olutunu naa yoo ṣe? Yoo tọ awọn ọmọ-ẹyin sinu otitọ gbogbo, nitori Oun ni “Ẹmi otitọ” (Johannu 16:13). Yoo mu ohun gbogbo ti Jesu ti sọ fun wọn wa si iranti wọn ati awọn ohun ti wọn ko mọ tẹlẹ (Johannu 14:26).
Itunu ati Iranwọ
Jesu kì yoo fi awọn ọmọ-ẹyin nikan silẹ lati tan Ihinrere kalẹ. Jesu ni Oun yoo gbadura si Baba yoo si rán Olutunu. Ẹmi Mimọ naa yoo tù wọn ninu yoo si ràn wọn lọwọ. Yoo ràn wọn lọwọ lati mọ otitọ. Yoo kọ awọn ọmọ-ẹyin. “Nitori Ẹmi Mimọ yio kọ nyin . . . li ohun ti o yẹ ki ẹ wi” (Luku 12:12).
Ẹlẹri
Iṣẹ miiran ti Ẹmi Mimọ yoo ṣe ni lati jẹri ati lati ṣe ẹlẹri nipa Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹyin. Nipa ṣiṣe bẹẹ, Ẹmi Mimọ yoo yin Jesu logo. Oluwa ti sọ fun awọn ọmọ-ẹyin pe wọn o lagbara lati ṣe iṣẹ ti o tobi ju eyi ti Oun ti ṣe lọ (Johannu 14:12). “S̩ugbọn ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmi Mimọ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8).
Idalẹbi
Jesu sọ pe Ẹmi Mimọ yoo fi oye ye araye ni ti è̩ṣẹ. Gẹgẹ bi Ẹmi otitọ, Oun yoo fi otitọ ipo ti awọn eniyan wa hàn wọn. Nipa mimọ otitọ, wọn o ni anfaani lati ronupiwada ki wọn si ri igbala. “Otitọ yio si sọ nyin di ominira” (Johannu 8:32). Ẹmi Mimọ a maa da eniyan lẹbi fun è̩ṣẹ rè̩. Idalẹbi a maa yọri si ironupiwada ati igbala. Eniyan ni lati mọ pe ẹlẹṣẹ ni oun ki o to le tọ Ọlọrun lọ fun idariji è̩ṣẹ.
Apẹẹrẹ kan wa ninu igbesi-aye Peteru pé Ẹmi Mimọ a maa dani lẹbi fun è̩ṣẹ. Lẹyin ti Peteru ti ri Ẹmi Mimọ gbà ni Ọjọ Pẹntekọsti o waasu fun ọpọlọpọ eniyan. Nigba ti awọn eniyan gbọ ọrọ Peteru, “ọkàn wọn gbọgbẹ, nwọn si sọ fun Peteru ati awọn Apọsteli iyokù pe “Ará, kini ki awa ki o ṣe?” Ẹmi Mimọ ti da wọn lẹbi fun ẹṣẹ wọn. Peteru sọ fun wọn pe ki wọn ronupiwada. Ọpọlọpọ gbà ọrọ rè̩ gbọ, ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan ni o si yipada ni ọjọ naa (Iṣe Awọn Apọsteli 2:37-41).
Ni ọjọ kan Feliksi, baalẹ, ranṣẹ pe Paulu, “o si gbọ ọrọ lọdọ rè̩ nipa igbagbọ ninu Kristi Jesu.” Bi o ti n gbọ ọrọ Paulu, Ẹmi Mimọ mu idalẹbi wọnu ọkàn Feliksi. “Bi o si ti n sọ asọye nipa ti ododo ati airekọja ati idajọ ti mbọ, ẹru ba Feliksi” (Iṣe Awọn Apọsteli 24:24, 25). Kò ronupiwada. O ni ki Paulu maa lọ, ṣugbọn Ẹmi otitọ ti jẹ olóòótọ lati dá ọkàn rè̩ lẹbi.
Ododo
Jesu wi pe Ẹmi Mimọ yoo fi oye ye ni ni ti ododo. Jesu yoo ti lọ. Awọn eniyan kò tun ni le ri apẹẹrẹ ododo ti o wà ninu igbesi-aye Jesu mọ. S̩ugbọn kò si ẹni ti yoo ri awawi ṣe, nitori pe Ẹmi otitọ yoo maa fi oye yé ni ni ti igbesi-aye ododo, yoo si mu ki awọn eniyan mọ pé wọn ni lati gbe igbesi-aye iwa titọ. Ki i ṣe pe Jesu fi apẹẹrẹ lelẹ nikan ṣugbọn o fun ni lagbara lati gbe igbesi aye iwa titọ. Nipasẹ Jesu ati ododo Rè̩ nikan ṣoṣo ni a le di olododo (II Kọrinti 5:21). Nitori pe Jesu gbọran paapaa titi de fifi ẹmi Rè̩ lelẹ ati kikú fun wa, a le sọ wa di olododo nipa Ẹjẹ Rè̩ (Romu 4:25; 5:19).
Apa kan iṣẹ Ẹmi Mimọ yoo jẹ lati fi oye yé awọn eniyan nipa ododo. Ọranyan ni fun wa lati gbe igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun, mimọ, ati ti ododo bi a o ba wọ Ọrun. Nigba ti Jesu n ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ sọrọ O ni, “Bikoṣepe ododo nyin ba kọja ododo awọn akọwe ati ti awọn Farisi, ẹnyin kì yio le de ilẹ-ọba ọrun bi o ti wù ki o ri” (Matteu 5:20). Awọn akọwe ati awọn Farisi jé̩ ẹlẹsin, ṣugbọn Jesu n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ gbe igbesi-aye ti o tayọ ti ẹlẹsìn lasan lọ. A n beere lọwọ awọn ọmọ-ẹyin Jesu lati gbe igbesi-aye ododo. A sọ fun wa ki a gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ, apa kan eyi ti i ṣe “igbaiya ododo” (Efesu 6:14). A kilọ fun wa pe ki a yẹra fun ohun ti i ṣe ibi ki a si “mā lepa ododo, iwa-bi-Ọlọrun, igbagbọ, ifẹ, sru, iwa-tutu. Mā ja ija rere ti igbagbọ, di iye ainipẹkun mu” (I Timoteu 6:11, 12).
Idajọ
Ẹmi Mimọ yoo fi hàn pẹlu pe idajọ wà. Satani, gẹgẹ bi ọmọ-alade aye yii, ni a ti da lẹjo; ṣugbọn bẹẹ ni olukuluku eniyan yoo duro niwaju Onidajọ gbogbo aye; “Nitoripe gbogbo wa kò le ṣaima fi ara hàn niwaju ité̩ idajọ Kristi; ki olukuluku ki o le gbà nkan wọnni ti o ṣe ninu ara, gẹgẹ bi eyiti o ti ṣe, ibā ṣe rere ibā ṣe buburu” (II Kọrinti 5:10).
Olutunu Naa
Ẹmi Mimọ, ẹni ti yoo maa tù ni ninu ti yoo si maa ran ni lọwọ, ni araye kò le gbà (Johannu 14:17). Jesu ṣeleri pe Ọlọrun yoo ran Olutunu naa si awọn ọmọ-ẹyin Rè̩. Awọn wo ni ọmọ-ẹyin Jesu? Awọn ni awọn ti a ti gbala, ti wọn si n tẹle Jesu. O ni “Bi ẹnyin ba duro ninu ọrọ mi, nigbana li ẹnyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitõtọ” (Johannu 8:31).
Jesu sọ ọna ti awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ le gbà ri Olutunu naa gbà fun wọn. Jesu wi pe, “Bi ẹnyin ba fẹran mi, ẹ ó pa ofin mi mọ” (Johannu 14:15). Ọna lati mọ pe ni tootọ ni wọn fẹran Jesu ni pipa ofin Rè̩ mọ, ati gbigbọran si gbogbo ọrọ Rè̩. Jesu kò kọ wọn nipa isọdi-mimọ nikan, ṣugbọn O fi apẹẹrẹ naa lelẹ pẹlu “ki a le sọ awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ pẹlu di mimọ” (Johannu 17:19).
Isọdimimọ, iṣẹ oore-ọfẹ keji, jẹ iriri ti o wà fun awọn ti a ti gbala. A maa wẹ abinibi è̩ṣẹ nù kuro ninu ọkàn, a si maa mu gbongbo ohun buburu kuro. Eyi a maa ṣẹlẹ nigba ti eniyan ba gbadura ti o si fi ara rè̩ rubọ fun Ọlọrun ni kikún ju ti atẹyinwa lọ. Ifẹ Ọlọrun ni pe ki awọn ọmọ-ẹyin Jesu ni isọdimimọ. “Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimọ nyin” (I Tẹssalonika 4:3). Eniyan ni lati ṣe ifẹ Ọlọrun ki o ba le jé̩ ọmọ-ẹyin. Iriri meji – igbala ati isọdimimọ -- ni a ni lati kọ ni ṣaaju Ẹmi Mimọ, wọn si jẹ ọranyan lati ṣe eniyan yẹ fun riri Olutunu nì gbà.
A sọ fun awọn ọmọ-ẹyin pé Olutunu naa yoo de lati wà pẹlu wọn titi. Kì i ṣe pe yoo maa ba wọn gbe nikan, tabi ki o kàn wá bè̩ wọn wo, yoo ṣe ju eyi paapaa lọ. Yoo maa gbe inu wọn (Johannu 14:17). Eyi ni a muṣe ni Ọjọ Pẹntekọsti ni yara oke kan ni Jerusalẹmu nibi ti awọn ọmọ-ẹyin Jesu ti n gbadura. “Gbogbo wọn si kún fun Ẹmi Mimọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:4). Kì i ṣe awọn ọmọ-ẹyin Jesu ti i ṣe Ju nikan ni a fi Ẹmi Mimọ fun. Lẹyin eyi “a tu ẹbun Ẹmi Mimọ sori awọn Keferi pẹlu” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:45).
Ileri fun Ọjọ Oni
Ileri Olutunu yii wà fun awa naa lonii, awa ti a jẹ ọmọ-ẹyin Jesu ti a si n gbọran si Ọrọ Rè̩. “Nitori fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jina rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:39). Nigba ti a ba rò nipa ohun ti Olutunu ti a ṣeleri yii yoo ṣe fun wa, njẹ gbogbo wa kì yoo ha fẹ lati ni In ni igbesi-aye wa? Njẹ o ti ri Olutunu nì gbà -- Ẹmi Mimọ?
Aṣẹ Jesu
Ọkan ninu aṣẹ ikẹyin ti Jesu pa ni “Ẹ joko, . . . titi a o fi fi agbara wọ nyin lati oke ọrun wá” (Luku 24:49). Jesu paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe ki wọn “duro de ileri Baba, . . . nitori nitõtọ ni Johannu fi omi baptisi; ṣugbọn a o fi Ẹmi Mimọ baptisi nyin” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:4, 5). Iwọ ko i ti pa gbogbo aṣẹ Rè̩ mọ bi o kò ba ti ri Ẹmi Mimọ gbà. Gbadura ki o si fi aye rẹ rubọ fun Ọlọrun, titi iwọ naa yoo fi ri ẹbun yii gbà. Jesu wi pe, “ohunkohun ti ẹnyin ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, on o fifun nyin” (Johannu 16:23).
Ileri Naa
Jesu tù awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ninu pẹlu ileri Ẹmi Mimọ, ati nipa fifi alaafia Rè̩ fun wọn. Ki Jesu to fi wọn silẹ, Jesu wi pe, “Ninu aiye, ẹnyin o ni ipọnju: ṣugbọn ẹ tújuka; mo ti ṣẹgun aiye” (Johannu 16:33). Nitori pe Jesu ti ṣẹgun aye, awa pẹlu le jẹ aṣẹgun. “Eyi si ni iṣẹgun ti o ṣẹgun aiye, ani igbagbọ wa. Tani ẹniti o ṣẹgun aiye, bikoṣe ẹniti o gbagbọ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu iṣe?” (I Johannu 5:4, 5).
Questions
AWỌN IBEERE1 Ta ni a ṣeleri Olutunu fun?
2 Sinu ki ni Ẹmi otitọ yoo ṣe amọna awọn ọmọ-ẹyin?
3 Ki ni yoo mu wá si iranti wọn?
4 Nibo ni Ẹmi Mimọ yoo maa gbe?
5 Ta ni yoo fun awọn ọmọ-ẹyin ni agbara lati jẹ ẹlẹri fun Jesu?
6 Bi a ba fẹran Jesu, ki ni a o pamọ?
7 Ta ni ri Ẹmi Mimọ gbà ni igbà awọn Apọsteli?
8 Ta ni le ri Ẹmi Mimọ gbà ni ọjọ oni?
9 Bawo ni a ṣe n ri Olutunu gbà?
10 Ki ni ṣe ti a gbọdọ ri Ẹmi Mimọ gbà sinu igbesi-aye wa?