Lesson 238 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Gẹgẹ bi iwọ ti rán mi wá si aiye, bḝ li emi si rán wọn si aiye pẹlu” (Johannu 17:18).Notes
Adura S̩e Danindanin
Adura ni Jesu fi pari ọrọ Rè̩ ikẹyin pẹlu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩. Njẹ o ti ṣakiyesi pe nigba pupọ ni Jesu n gbadura? O jé̩ Ọmọ Ọlọrun, Ẹni keji ninu Mẹtalọkan Mimọ; O si ni agbara lati fun ni ni iye ainipẹkun, lati wo alaisan san, lati ji oku dide, ati lati dari ẹṣẹ ji ni. Gbogbo nnkan wọnyi ni O le ṣe nitori pe ọkan ni Oun ati Ọlọrun já si. S̩ugbọn bi o ti jé̩ Ọlọrun nì, O jé̩ eniyan pẹlu; O si maa n gba ipa ati agbara Rè̩ lati Ọrun wá nipa adura. Nigba ti oye wa kere pupọ lati mọ bi a ti gbọdọ maa gbadura to, Jesu mọ pe Oun ni lati maa gbadura lọpọlọpọ.
Oru pupọ ni Jesu fi nikan wà lẹba oke ti O si n gbadura – adura agbamọju. Nigba pupọ ni O maa n dide ni kutukutu owurọ lati lọ dá gbadura. Alẹ ikẹyin ti O gbadura gidigidi ni ọgba Getsemane kọ ni igbá kin-in-ni ti O lọ sibẹ. Iwe Mimọ sọ fun wa pe Judasi mọ ibi ti wọn ti le ri I, nitori “nigba-pupọ ni Jesu ima lọ sibẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rè̩” (Johannu 18:2).
Bi Jesu, Ọmọ Ọlọrun, bá mọ aini Rè̩ ni bibá Ọlọrun sọrọ, ti O si n gbadura fun iranwọ Ọlọrun, bawo ni o ṣe jẹ kò ṣe é maṣe fun wa tó! Jesu n fẹ ki a maa sọ ibeere wa di mimọ nipa adura, bi o tilẹ jẹ pe Oun ti mọ aini wa naa. Nipa adura ni a si maa n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ohun ti O ti ṣe fun wa sẹyin. Nigba gbogbo ni o yẹ ki adura iyin ati ọpẹ maa rú soke lati inu ọkàn wa si Ẹni ti O ti fi Ẹjẹ Rè̩ iyebiye rà wá.
A S̩e Ọmọ Logo
Jesu bẹrẹ adura Rè̩ pẹlu ọrọ wọnyi: “Baba, wakati na de; yin Ọmọ rẹ lọgo, ki Ọmọ rẹ ki o le yin ọ logo pẹlu.” Iṣẹ nlá nlà ni Jesu wa ṣe laye. O ni iṣẹ pataki kan lati ṣe. Ni igba aye Rè̩ O ṣe ọpọlọpọ iṣẹ iyanu, O si pe awọn eniyan lati maa tọ Oun lẹyin. S̩ugbọn wakati ti Oun ni lati ṣe iṣẹ Rè̩ ti o lagbara ju lọ, kiku lori agbelebu nitori ẹṣẹ wa ti dé. Eyi ni iṣẹ ti Ọlọrun fifun Un lati ṣe; O wa wi pe o ti pari. O ṣi n lọ kú ni, ṣugbọn ọkàn Rè̩ ti pinnu tan; O si ni idaniloju pe Oun yoo mu un ṣẹ jálè̩ to bẹẹ ti O fi n sọrọ bi ẹni pé ohun ti o ti kọja ni.
Nigba ti Jesu wà ni Ọrun, ki O to wa sinu aye yii, awọn angẹli n juba Rè̩, wọn si n sìn In, nitori pe Oun jẹ Ọmọ Ọlọrun. O jẹ ọkan pẹlu Ọlọrun ni igba dida aye, “lẹhin rè̩ a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da” (Johannu 1:3). Sibẹ O bọ ogo yii sapakan lati wá si aye gẹgẹ bi eniyan, lati kọ ni bi o ti yẹ ki a huwa, lati mọ irora wa, ati nikẹyin lati fi ẹmi Rè̩ ṣe irapada fun wa.
Njẹ wakati naa tun n bọ nigba ti a o tun ṣe E logo – ogo naa yoo tilẹ ju ti iṣaaju lọ gidigidi, nitori pe O ti fi ara Rè̩ ṣe ẹbọ nlá nlà fun è̩ṣẹ araye. “O rè̩ ara rè̩ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú, ani ikú ori agbelebu. Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbé e ga gidigidi, o si ti fi orukọ kan fun u ti o bori gbogbo orukọ; pe, li orukọ Jesu ni ki gbogbo ẽkun ki o mā kunlẹ, awọn ẹniti mbẹ li ọrun, ati awọn ẹniti mbẹ ni ilẹ, ati awọn ẹniti mbẹ nisalẹ ilẹ; ati pe ki gbogbo ahọn ki o mā jẹwọ pe, Jesu Kristi ni Oluwa, fun ogo Ọlọrun Baba”
(Filippi 2:8-11).Jesu pada lọ si Ọrun lẹyin ti O jinde kuro ninu okú, O si joko lori Itẹ Rè̩ pẹlu agbara nla, ni ọwọ ọtun Ọlọrun, lati maa bẹbẹ fun wa. Akoko n bọ ti gbogbo eniyan ati gbogbo nnkan inu aye yii yoo wà labẹ agbara Rè̩. Gbogbo eniyan ni yoo gbọ ti Rè̩. Ni akoko naa ni ododo yoo bo ilẹ, awọn eniyan Ọlọrun yoo si jọba pẹlu Rè̩ ninu ijọba alaafia.
Adura fun Awọn ti Rè̩
Ninu adura yii Jesu n gbadura fun awọn eniyan ti Rè̩. O mọ pe ọjọ wahala wà niwaju fun wọn. Oyé kò yé wọn pe Oun kò le ṣai má kú nigba ti Oun jẹ ọmọ kekere to bẹẹ -- ọmọ ọdun mẹtalelọgbọn pere. Wọn fẹran Rè̩, idaamu pupọ yoo si ba wọn nigba ti wọn ko ba ri I mọ. Siwaju si i, a o pọn wọn loju nitori igbagbọ wọn ninu Rè̩. S̩ugbọn Jesu mọ pe nikẹyin wọn o ṣe olóòótọ. O wa n gbadura si Baba pe ki O le fun wọn ni oore-ọfẹ lati jẹ olóòótọ, bi o ti wu ki a fi iya jẹ wọn to; O si mọ wi pe Ọlọrun maa n dahun adura Oun nigba gbogbo.
Pupọ ninu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni yoo di ajẹrikú. Wọn o kan Peteru mọ agbelebu; wọn o bé̩ ori Jakọbu; ori Erekuṣu Patmo ni wọn o ta Johannu nù si; ìnà ati ọkọ rìrì ni yoo jẹ ipin ti Paulu ki wọn to bé̩ ẹ lori nikẹyin. Awọn ẹlomiran yoo ba ara wọn ninu iho apata, nibi ti wọn o maa gbe ti wọn o si maa jọsin, ki ọwọ awọn alaṣẹ Romu má ba tè̩ wọn. S̩ugbọn a ni ọrọ iṣiri yii lati ẹnu Paulu Apọsteli pe: “Bi awa ba farada, awa o si ba a jọba” (II Timoteu 2:12). Awọn eniyan wọnyi fi ọkàn wọn si ogo ti Jesu ti sọ fun wọn nipa rè̩, wọn kò si ka iyà ti wọn jẹ si nnkankan rara. Peteru wi pe oun ti jẹ ẹlẹri iyà Kristi (Nitori eyiti a ṣe E logo), ati pe oun pẹlu yoo jẹ “alabapin ninu ogo ti a o fihan” (I Peteru 5:1). Oun kò wi pe oun naa ti jìyà. Eyi kò jẹ nnkan loju rè̩. Ohun ti o ṣe pataki fun un ni pe a o ṣe oun logo pẹlu Jesu.
Nipa nnkan kan naa ni Paulu Apọsteli n sọ nigba ti o n sọ, ninu Heberu 11, nipa awọn akọni nipa igbagbọ. Abrahamu ti rìn kaakiri lori ilẹ, o si n gbe inu agọ, laibikita pe oun kò ni ile ninu eyi ti oun le maa gbe. Gbogbọ ohun ti o n rò ninu ọkàn rè̩ ni ilu ọrun nì nibi ti oun gbe maa gbadun nigba ti oun ba fi aye yii silẹ. “Awọn ẹlomiran si ri idanwò ti ẹsín, ati ti inà, ati ju bḝ lọ ti ìde ati ti tubu: a sọ wọn li okuta, a fi ayùn ré̩ wọn meji, a dán wọn wò, a fi idà pa wọn: nwọn rìn kákiri ninu awọ agutan ati ninu awọ ewurẹ; nwọn di alaini, olupọnju, ẹniti a nda loro” (Heberu 11:36, 37). S̩ugbọn njẹ wọn ka a si? Wọn gbagbọ pe ibugbe wọn n duro de wọn ni Ọrun, nibi ti wọn o maa gbe lae ati laelae. Igbesi-aye wa nihin kuru ti a ba fi wé ayeraye; ohun ti o si ṣe pataki jù lọ ninu aye wa yii ni lati wà ni imurasilẹ ki a ba le jẹ igbadun ogo ti Jesu ti pese silẹ fun wa.
Lọdọ Jesu
Nigba ti Jesu n gbadura, O wi pe: “Baba, emi fẹ ki awọn ti iwọ fifun mi, ki o wà lọdọ mi, nibiti emi gbé wà; ki nwọn le mā wò ogo mi, ti iwọ ti fifun mi.” Jesu n fẹ ki a wà lọdọ Oun! O le dabi ẹni pé a ṣa wa tì nihin yii nigba miiran, ki a si ro pe kò si ẹni ti o bikita fun wa; ṣugbọn Jesu n fẹ ri wa. O n fẹ ri wa loke lọhun nibi ti awọn angẹli ti n juba Rè̩, nibi ti O gbe joko lori itẹ pẹlu Ọlọrun Baba, ati nibi ti gbogbo ogun ọrun ti n wolẹ niwaju Rè̩. O n fẹ ki a wà nibẹ lọdọ Oun titi ayeraye.
Jesu ti yan awọn nnkan alailera ayé lati fi daamu awọn ọlọgbọn. O wi pe kì i ṣe ọpọ awọn ẹni nla ninu aye ni yoo fẹ maa ṣe ọmọ-ẹyin Rè̩, ṣugbọn pe awọn otoṣi yoo fi ayọ gbọ ti Rè̩. Nigba ti Isaiah n nawọ ipe Ihinrere, o wi pe, “Njẹ gbogbo ẹniti ongbẹ ngbẹ, ẹ wá sibi omi, ati ẹniti kò li owo; ẹ wá, ẹ rà, ki ẹ si jẹ” (Isaiah 55:1). Ti pe a jẹ talaka ati ẹni ti aye kò kà si kò sọ pe Jesu gboju fo wa da. Gbogbo eniyan ni O n pe lati wa sọdọ Rè̩ lati pin ninu ibukun Rè̩ ti kò loṣuwọn – alaafia ninu ọkàn nihin, ati igbadun ayeraye lẹyin aye yii.
A Pa Wọn Mọ ninu Aye Yii
Nigba ti Jesu n sọ nipa ogo ti yoo wà ni Ọrun, dajudaju awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ i ba fẹ ba A lọ lẹsẹkẹsẹ. Nigba miiran aayun Ọrun a maa yun wa nigba ti a ba ri wahala aye yii, ọkàn wa a si maa poungbẹ fun ogo ti o n duro de wa. S̩ugbọn Jesu gbadura si Baba pe: “Emi kò gbadura pe, ki iwọ ki o mu wọn kuro li aiye, ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn mọ kuro ninu ibi.” Wọn ni iṣẹ lati ṣe. Jesu yoo ran wọn jade lati jẹ ajihinrere fun Un lati jẹ ki gbogbo ayé mọ pe Jesu yoo gbà wọn là kuro ninu è̩ṣẹ wọn. S̩ugbọn o kù awọn nnkan kan ti o yẹ ki wọn ni ki wọn ba le jẹ ẹlẹri daradara. Ọkan ninu rè̩ ni isọdimimọ.
A Sọ Wọn Di Mimọ ninu Otitọ
Awọn wọnyi ti Jesu n gbadura fun gbagbọ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe, nitori naa iye ainipẹkun ti bẹrẹ ninu ọkàn wọn. “Iye ainipẹkun na si li eyi, ki nwọn ki o le mọ ọ, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹniti iwọ rán.” Kì i ṣe pe ki wọn kan mọ wọn, ṣugbọn ki wọn mọ wọn gẹgẹ bi Ẹmi ti fi hàn. O yẹ ki a sọ wọn di mimọ. Nitori naa Jesu gbadura wi pe, “Sọ wọn di mimọ ninu otitọ: otitọ li ọrọ rẹ.” O yẹ ki a sọ ọkàn wọn di funfun, eyi ti o maa n ṣẹlẹ nipa isọdimimọ.
Jesu gbadura fun awa ti a ti ri igbala pẹlu. O wi pe: “Kì si iṣe kiki awọn wọnyi ni mo ngbadura fun, ṣugbọn fun awọn pẹlu ti yio gbà mi gbọ nipa ọrọ wọn.” Awa ti o gba ohun ti wọn waasu gbọ -- awọn ohun ti a kọ sinu Majẹmu Titun – le ri isọdimimọ pẹlu, bi a ba fi gbogbo igbesi-aye wa rubọ fun Jesu ti a si gba ileri Rè̩ fun wa gbọ.
Isọdimimọ yoo fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lokun. Idi miiran wà ti o fi yẹ ki a sọ wọn di mimọ. Yoo mu ki wọn jẹ ọkan pẹlu Jesu. Isọdimimọ maa n mu iṣọkan igbagbọ wá. Jesu n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ gbà gbogbo Ọrọ Rè̩ gbọ; nigba ti wọn ba si ṣe bẹẹ wọn a jẹ ọkan naa pẹlu awọn ti o gbagbọ, ati ọkan pẹlu Rè̩.
O tun kù idi miiran ti awọn ọmọ-ẹyin fi gbọdọ ni isọdimimọ. Jesu fẹ ki ayé mọ pe ọmọlẹyin Oun ni wọn jẹ. O fẹ ki awọn eniyan Rè̩ ri bi Oun ti ri to bẹẹ ti araye yoo fi mọ pe Onigbagbọ ni wọn. A maa n di mimọ nigba ti a ba ri isọdimimọ, a si maa n gba aworan Ọlọrun pada ti Adamu ati Efa sọnu ni igba ti wọn dẹṣẹ ninu ọgba nì. A o dabi Ọlọrun ni ododo ati ni iwa mimọ. O yẹ ki a maa ranti pe a ni lati ni aworan Ọlọrun ninu wa, ki iwa wa si jẹ eyi ti yoo mu ki araye ri Jesu ninu igbesi-aye wa.
Nigba ti a ba n gbe igbesi-aye wa fun Jesu, ti iwa wa si jẹ mimọ, a maa n tipa bẹẹ fi han pe Ọlọrun ran Ọmọ Rè̩ lati wá kú fun wa. Ko ṣe e ṣe fun wa lati gbe igbesi-aye mimọ lai yẹsẹ, bi ko ba ṣe pe Ẹjẹ Jesu ba mu aworan è̩ṣẹ kuro ninu ọkàn wa. O ṣe pataki pe ki igbesi-aye wa fi hàn pe Kristiani ni wa. A fẹ jẹ imọlẹ lati ṣamọna awọn ẹlomiran wa si Ijọba Ọlọrun, ki i ṣe okuta idigbolu lati dè wọn lọna.
Questions
AWỌN IBEERE1 Bawo ni Jesu ṣe pari ọrọ Rè̩ ikẹyin si awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ṣaaju ikú Rè̩?
2 Sọ diẹ ninu awọn akoko ti Jesu gbadura.
3 Awọn wo ni Jesu gbadura fun ni akoko yii?
4 Ki ni Jesu gbadura fun?
5 Ki ni ṣe ti Jesu fi wá si aye?
6 Ileri wo ni Jesu ṣe fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ bi wọn ba ṣe olóòótọ?
7 Sọ idi mẹta ti o fi yẹ ki a sọ awọn Onigbagbọ di mimọ.
8 Aworan wo ni o gbọdọ wà ni ọkàn awọn Onigbagbọ?
9 Nibo ni Jesu n fẹ ki awọn ọmọ Rè̩ wà?