Orin Dafidi 32:1-11

Lesson 239 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi o ma fi oju mi tọ ọ” (Orin Dafidi 32:8).
Notes

È̩ṣẹ Ninu Igbesi-aye Rè̩

Dafidi Onipsalmu sọ nipa iriri rè̩ ninu Psalmu yii, o sọ ohun ti o mu inu didun, ayọ, ati ibukun wá sinu igbesi-aye rè̩. O mọ pe oun ni ojurere Ọlọrun ninu aye oun nigba ti a dari è̩ṣẹ rè̩ ji i. Dafidi ti ré ofin Oluwa kọja. O ti rú ofin Ọlọrun, è̩ṣẹ si wà ninu aye rè̩. Ọkàn Dafidi kò balẹ, bẹẹ ni ko ni inudidun nigba ti o n gbe iru igbesi-aye bayi; ibanujẹ ati idalẹbi ni ó ní. Dafidi mọ nipa è̩ṣẹ ti o wà ninu aye rè̩ yii, ṣugbọn fun saa kan kò jẹwọ rè̩. Dafidi dakẹ lati fi idalẹbi ọkàn rè̩ pamọ. Awọn miiran ti wọn ni idalẹbi ninu ọkàn wọn a maa gbiyanju lati maa gbokẹ-gbodo nigba gbogbo ni ireti pé wọn kò tilẹ ni ri aye lati ronu ati lati yẹ ọna wọn wo.

Idalẹbi pọ ninu ọkàn Dafidi fun è̩ṣẹ ti o wà ni igbesi-aye rè̩ to bẹẹ ti egungun rè̩ dabi ẹni pe wọn di gbigbo. Kì ì ṣe pe Dafidi n ni idalẹbi yii lẹkọọkan, ṣugbọn ni gbogbo ọjọ ni idalẹbi yii fi wà ninu ọkàn rè̩.

Imọ È̩ṣẹ

Dafidi kò layọ nigba ti o n gbiyanju lati bo è̩ṣẹ mọlẹ ninu aye rè̩. Kò si si ẹni ti o le ni ayọ niwọn igba ti o n gbiyanju lati fi è̩ṣẹ ti ó mọ pe ó wà ninu igbesi-aye rè̩ pamọ. Nigba gbogbo ni ẹrù yoo maa ba a pe a o fi è̩ṣẹ oun hàn, ati pe ẹni kan yoo mọ nipa rè̩.

Idalẹbi

Mimọ pe è̩ṣẹ wa ninu igbesi-aye ẹni jẹ iṣisẹ kan ti n mu ni lọ si ironupiwada. Eniyan ni lati mọ pe oun jẹ ẹlẹṣẹ ki o to le ronupiwada. Nipa dida Dafidi lẹbi è̩ṣẹ rè̩, Oluwa n mu Dafidi lọ si ironupiwada ki a le dari è̩ṣẹ rè̩ jì. Gbogbo ọsan ati oru Dafidi ni o kún fun aisimi nitori pe Ọlọrun n ba ọkàn rẹ lo. Irora ọkàn Dafidi dabi ọdá ẹẹrun. Ko ha si itura bi?

Ironupiwada

Itura dé fun Dafidi nigba ti o jẹwọ awọn è̩ṣẹ rè̩ ti o si yipada kuro ninu wọn. Ninu ifẹ ati aanu ni Ọlọrun fi è̩ṣẹ ti o wà ninu igbesi-aye Dafidi han an ki Dafidi ba le ronupiwada ki o si ni itunu dipo aibalẹ-aya. Nigba ti Dafidi jẹwọ awọn irekọja rè̩ Ọlọrun dariji i. Dafidi kò tun gbiyanju lati bo è̩ṣẹ ti o wà ni igbesi-aye rè̩ mọlẹ mọ. Dafidi gba pe ẹlẹṣẹ ni oun, o si jẹwọ è̩ṣẹ rè̩ ni kọọkan fun Oluwa. O ri idariji ti o n fẹ gbà. Kì i tun ṣe ẹni ti kò nireti ati ẹni ti ara rè̩ kò lelẹ mọ. Igbesi-aye rè̩ si yatọ. Ọwọ Ọlọrun ti mu Dafidi wá si ironupiwada nipa mimu idalẹbi fun è̩ṣẹ wọ inu ọkàn rè̩.

Awọn Alabukunfun

Dafidi le jẹri pe oun jẹ ọkan ninu awọn alabukunfun. Dafidi fi hàn pe “olododo li on lati dari ẹṣẹ wa ji wa” bi a ba jẹwọ wọn. (I Johannu 1:9). A dari irekọja Dafidi ji i. È̩ṣẹ rè̩ ti rekọja lọ. Ọna kan ṣoṣo ti o le gbà ni alaafia ninu ẹri-ọkàn rè̩ ni yii.

Ki i ṣe Dafidi nikan ni Oluwa ti mu wa si ironupiwada ati idaniloju pe a dari awọn è̩ṣẹ wọn ji wọn. Ọpọlọpọ eniyan, lọmọde ati lagba wà ninu awọn ti a bukun fun nitori pe è̩ṣẹ wọn ti rekọja. Awọn naa, gẹgẹ bi Dafidi, ti dé ipo inu didun ati itunu nigbà ti a dari awọn è̩ṣẹ wọn ji wọn.

Wọn jẹwọ è̩ṣẹ wọn; wọn kò tun gbiyanju lati fi wọn pamọ mọ. Wọn gbà pe ẹlẹṣẹ ni awọn i ṣe, wọn si beere fun idariji. Nigba ti wọn ronupiwada, a dari irekọja wọn ji. Wọn gba ileri Ọlọrun gbọ pe wọn o ri aanu gba. “Ẹniti o bo è̩ṣẹ rè̩ mọlẹ ki yio ṣe rere; ṣugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ ọ silẹ yio ri ānu” (Owe 28:13). Nigba ti è̩ṣẹ wọn rekọja, wọn ri isimi ati itura ti Jesu ṣeleri gbà nigba ti O wi pe, “Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ, ti a si di ẹrù wuwo le lori, emi o si fi isimi fun nyin” (Matteu 11:28). A wẹ wọn ninu Ẹjẹ Jesu kuro ninu è̩ṣẹ wọn (Ifihan 1:5). Oluwa pa irekọja wọn ré̩, ki yoo si ranti è̩ṣẹ wọn mọ (Isaiah 43:25). A kò tun ka è̩ṣẹ si wọn lọrun mọ. Oluwa fun wọn ni ododo nitori igbagbọ wọn (Romu 4:6).

Iwọ ha pẹlu awọn alabukun-fun -- awọn ti o layọ? A ha ti dari è̩ṣẹ rẹ ji ọ, a ha wẹ ọ mọ ninu Ẹjẹ Jesu?

Kò Si Olutọni

Iyatọ nla wa ninu igbesi-aye Dafidi ki o to gbadura ati lẹyin ti o ti ri idariji gbà. Kò tun si idalẹbi mọ (Romu 8:1). Kò tun si ẹtàn mọ. Ko tun si ohun ti o n bo mọlẹ mọ -- awọn è̩ṣẹ rè̩ ti rekọja. Kò tun ṣe agabagebe pe oun layọ mọ -- o wà laaarin awọn alabukunfun. Oun kò tun pa ẹnu rè̩ mọ -- o ni, “ẹ si ma kọrin fun ayọ.” Wọnyi jẹ ninu awọn iyipada ti Oluwa ṣe ninu igbesi-aye Dafidi nigba ti Dafidi ri igbala.

Gbigbadura ni Akoko

Dafidi sọ nipa bi gbigbadura ni akoko ti a le ri Oluwa ti ṣe danin-danin to. Woli Isaiah sọ iru ọrọ bẹẹ: “Ẹ wá OLUWA nigbati ẹ le ri i, ẹ pè e nigbati o wà nitosi” (Isaiah 55:6). O le yé wa lati inu awọn ọrọ wọnyi pe igbà kan le wà nigba ti Oluwa kì yoo si ni tosi ati ti a kì yoo le ri I. Dafidi kò duro di igba ti yoo ti pẹ ju lati gbadura. O gbadura, o si wa Ọlọrun nigba ti ọwọ Oluwa “wuwo” si i lara.

Nigba ti eniyan ba gbadura ni akoko, nigba naa ni yoo wà ni imurasilẹ fun awọn nnkan ti yoo de ba a. Dafidi sọ pe ninu iṣan-omi nla, wọn kì yoo sun mọ ọdọ rè̩ nitori pe o ti gbadura agbayọri si iṣẹgun nipa ti ẹmi. Awọn ẹlomiran a maa duro titi di igba wahala, iṣan-omi wahala, ki wọn to ké pe Oluwa. Nigba naa wọn kò ni idaniloju pe awọn yoo ni àayè tabi agbara lati gba adura ti Ọlọrun yoo gbọ. Wọn a dede ro lọkàn wọn pe awọn o ri I, ati pe yoo wa ni tosi wọn nigba ti wọn ba n fẹ iranlọwọ Rè̩. Wo iru igbẹkẹle ti Dafidi ni pe Ọlọrun yoo daabo bo oun ati pe yoo tọ oun sọna! “Iwọ ni ibi ipamọ mi: iwọ o pa mi mọ kuro ninu iṣé̩; iwọ o fi orin igbala yi mi kakiri.” Abajọ ti Dafidi fi n yọ ti o si ni inudidun ninu Oluwa!

Ọkunrin Ọlọgbọn Kan

Ninu Majẹmu Titun, Jesu kọ ni pe ẹnikẹni ti o ba tọ Oun wá, ti o ba gbọ ọrọ Oun, ti o si n ṣe wọn ni a o fi we ọkunrin ọlọgbọn kan, ti o kọ ile kan, lẹyin ti o ti walẹ jin ti o si fi ipilẹ rẹ sọlẹ lori apata. Lẹhin naa nigba ti kikún omi dé, igbi si dé, ile naa kò si wó lulẹ bẹẹ yni kò si mì (Luku 6:48). Bakan naa ni Jesu tun kọ ni pe ẹni ti o ba gbọ ọrọ Oun ti kò si gbọran ni a fi wé ọkunrin aṣiwere kan ti o kọ ile rè̩ si ori iyanrin (Matteu 7:26). Ojo si rọ, ikún-omi si dé, iji si ja – ile naa si wó lulẹ!

Dafidi kọ ile ẹmi rè̩ si ori apata, o si duro gbọnin – nigba ti wahala ati ewu de gẹgẹ bi ikún-omi nla.

Olutọni

Nigba ti eniyan ba gbọran si aṣẹ Ọlọrun, nigba naa Ọlọrun ni Aṣiwaju ati Oluranlọwọ rè̩. Oluwa wi pe, “Emi o fi ẹsẹ rẹ le ọna, emi o si kọ ọ li ọna ti iwọ o rìn; emi o ma fi oju mi tọ ọ” (Orin Dafidi 32:8). Jesu wa “Lati fi imọlẹ fun awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ati lati fi ẹsẹ wa le ọna alafia” (Luku 1:79).

Amọna ni ẹni ti o n fi ọna han ni nipa biba ni rin tabi nipa lilọ niwaju. Mejeeji ni Oluwa maa n ṣe – A maa ba awọn eniyan Rè̩ lọ, A si maa lọ niwaju awọn eniyan Rè̩, Oluwa yoo wà pẹlu awọn eniyan Rè̩, nitori “on tikalarè̩ ti wipe, Emi kò jẹ fi ọ silẹ, bẹni emi kò jẹ kọ ọ silẹ” (Heberu 13:5). “Kristi pẹlu jiya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mā tọ ipasẹ rè̩” (I Peteru 2:21). O ti lọ siwaju lati tọka ọna ti a o tọ fun wa. O jẹ imọlẹ lati fi ọna han wa. Ọlọrun sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe nigba ti wọn ba yi si apa ọtun tabi ti wọn ba yi si apa osi, wọn o gbọ ọrọ wọnyi: “Eyiyi li ọna, ẹ ma rin ninu rè̩” (Isaiah 30:21).

Titẹle Aṣiwaju

Boya awọn miiran ninu yin ti ṣire lọ si ọna ti o jin, ni oju-ọna ti ẹ kò mọ ri. Ohun pataki ni fun yin lati ni aṣiwaju tabi amọna lati fi ọna han yin. Ẹ gbẹkẹle amọna naa. Ẹ ni igbẹkẹle ninu rè̩ nitori pe o mọ ọna naa o si ti rin nibẹ ri. Iwọ kò jẹ rò lati gba ọna miiran, tabi gba ọna kọrọ tabi ọna abuja, ki a ma ba ya ọ nipa kuro lọdọ awọn iyoku ki o si sọnu. O mọ pe o ni lati tẹle amọna naa bi o ba n fẹ lati de ile ni alaafia, iwọ yoo si ka ẹnikẹni ti o ba fẹ gba ọna miiran si ẹni ti o huwa aṣiwere.

Ọna-abuja

Awọn miiran wà ti wọn kò kiyesara to nipa kikuna lati tẹle Amọna ti ẹmi. Oluwa n lọ ṣiwaju wa ati pẹlu wa ni ọna naa, ṣugbọn awọn miiran a maa gba ẹtàn Satani lati gba abuja ọna si ọwọ osi tabi si ọwọ ọtun. A ti yà wọn nipa kuro lọdọ Ọlọrun ati awọn eniyan Rè̩. O ṣe e ṣe lẹyin naa ki wọn tun pada si ibi ti wọn gbe ti yà kuro loju ọna, ṣugbọn wọn le ṣai tun ri ọna ti o lọ si Ile ọrun ati iye ainipẹkun mọ.

Onipsalmu wi pe “ki ẹnyin ki o maṣe dabi ẹṣin tabi ibaka.” Pẹlu ijánu ni ẹnu wọn ati okùn iṣakoso ni ori wọn ni a maa n fi ṣakoso ti a si maa n dari awọn ẹranko wọnyi si ọna ti o tọ. A mọ ibaka fun orikunkun, nigba pupọ ni kì i fẹ rìn ayafi ti o ba fẹ bẹẹ, a si lọ si ibi ti o ba wu u. A ti gba pe awọn ẹṣin ati ibaka a maa huwa bẹẹ nitori pe “nwọn kò ni iyè ninu.” Awa, gẹgẹ bi ọkunrin, obinrin, ati ọmọde kò fẹ lati maa huwa bi awọn ẹranko wọnyi.

Ẹ jẹ ki a pinnu ninu ọkàn wa lati tẹle Oluwa ni ọna tooro nì, ki a má si ṣe feti si Satani ti o n fẹ dari wa lọ si ọna gbooro ti o lọ si ibi iparun (Matteu 7:13). Ẹ jẹ ki a tẹle Oluwa nigba gbogbo ki a má si ṣe lọ si ọna miran eyi ti o le dàbi ẹni pe o dara loju wa ṣugbọn “opin rè̩ li ọna ikú” (Owe 14:12).

Aṣiwaju Wa

Igba miiran wa ti a maa n pe Oluwa ni Amọna wa, nipa lilo awọn orukọ miiran. Jesu wi pe, “Emi ni oluṣọ-agutan rere, mo si mọ awọn temi, awọn temi si mọ mi” (Johannu 10:14). Oluṣọ-agutan a maa tọ, a si maa dari agbo agutan. A maa mu wọn lọ si papa nibi ti ounjẹ ati omi wà fun wọn. A maa daabo bo wọn kuro ninu ìji ati lọwọ ọta, a si fi wọn wọ si ibuwọ ni alẹ. “OLUWA li Oluṣọ-agutan mi; emi ki yio ṣe alaini” (Orin Dafidi 23:1). “Nigbati o si mu awọn agutan tirè̩ jade, o ṣiwaju wọn, awọn agutan si n tọ ọ lẹhin: nitori ti nwọn mọ ohùn rè̩” (Johannu 10:4).

Awọn ọmọ Juda wi pe, “Si kiyesi i, Ọlọrun tikararè̩ si wà pẹlu wa li Olori wa” (II Kronika 13:12). Ninu Majẹmu Titun a ka pe Jesu ni Balogun igbala wa (Heberu 2:10). Nigba miiran a maa n kọrin nipa Balogun wa ti kò ti i sọ ogun kan nù ri.

A baa pe ni Amọna, Balogun, Oluṣọ-agutan tabi orukọ miiran, ẹ jẹ ki a tẹle Amọna tootọ, Oluwa wa. Ẹ jẹ ki adura wa dàbi ti Dafidi: “Sin mi li ọna otitọ rẹ, ki o si kọ mi: nitori iwọ li Ọlọrun igbala mi” (Orin Dafidi 25:5). “Kọ mi li ọna rẹ, OLUWA, ki o si tọ mi li ọna titọ” (Orin Dafidi 27:11). “Kọ mi lati ṣe ohun ti o wù ọ: nitori iwọ li Ọlọrun mi: jẹ ki ẹmi rẹ didara fà mi lọ ni ilẹ ti o tẹju” (Orin Dafidi 143:10).

Ninu Orin Dafidi 32, Dafidi ti fi igbesi-aye isimi, inudidun, ati aabo eyi ti i maa wà pẹlu aanu Ọlọrun fun awọn ti a dari è̩ṣẹ wọn jì ti wọn si gbẹkẹle itọsọna Oluwa hàn. Dafidi tun sọ nipa ibanujẹ, ewu ati wahala ti o n de bá awọn eniyan buburu ti o gbẹkẹle ara wọn. Ẹgbẹ wo ni iwọ wà ninu awọn mejeeji wọnyi?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni ṣe ti Dafidi fi dakẹ?

  2. 2 Ki ni yi igbesi-aye rè̩ pada?

  3. 3 Ta ni alabukun-fun?

  4. 4 Bawo ni eniyan ṣe le di alabukun-fun?

  5. 5 Ki ni ṣe ti eniyan ni lati wá Ọlọrun nisisiyi?

  6. 6 Ni igba wahala, ki ni Ọlọrun maa n ṣe fun awọn eniyan Rè̩?

  7. 7 Bawo ni Ọlọrun ṣe n tọ awọn eniyan Rè̩?

  8. 8 Fi igbesi-aye eniyan buburu wé igbesi-aye olododo.