Orin Dafidi 10:1-18; 14:1-7; 36:1-12

Lesson 240 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Aṣiwere wi li ọkàn rè̩ pe, Ọlọrun kò si” (Orin Dafidi 14:1).
Notes

Ipinya kuro Lọdọ Ọlọrun

Ọlọrun mi si Dafidi lati kọ awọn Psalmu wọnyi. Wọn n sọ fun ni bi è̩ṣẹ ti buru to. Bi Satani ba n fẹ mu wa gbà pe è̩ṣẹ kò buru to bẹẹ, jẹ ki a ranti pe Satani ki i sọ otitọ. Ẹṣẹ kan ṣoṣo ni igbesi-aye eniyan sọ oluwarè̩ di eniyan buburu. Kò di igba ti eniyan ba dá è̩ṣẹ ti a n pe ni è̩ṣẹ nla ki o to pẹlu ẹgbẹ buburu. Bẹẹ ni ko di igba ti eniyan ba di agbalagba. “Iṣe ọmọde pāpa li a fi imọ ọ, bi ìwa rè̩ ṣe rere ati titọ” (Owe 20:11). Lati ṣe ainaani igbala, lati ṣaigbọran si Ọlọrun ati lati kunà lati mu ọkàn wa tọ niwaju Ọlọrun yoo yà wa kuro lọdọ Ọlọrun.

Awọn ti a yà nipa kuro lọdọ Ọlọrun ni awọn eniyan buburu. È̩ṣẹ kan ṣoṣo a maa pin wa niyà pẹlu Ọlọrun. Woli Isaiah sọ fun awọn eniyan wi pe, “Aiṣedede nyin li o yà nyin kuro lọdọ Ọlọrun nyin, ati è̩ṣẹ nyin li o pa oju rè̩ mọ kuro lọdọ nyin” (Isaiah 59:2). Sọlomọni wi pe, “OLUWA jina si awọn enia-buburu” (Owe 15:29).

Gbigbadura

Nitori pe a kò jẹ awọn eniyan ni iyà lẹsẹkẹsẹ ti wọn ba dẹṣẹ kò fi hàn pe Ọlọrun kò ri wọn tabi pe Oun kò mọ nipa è̩ṣẹ wọn. Loju Dafidi o dàbi ẹni pe Ọlọrun ko ṣakiyesi iwa ti o buru jai ti o wà ni igbesi-aye awọn eniyan. Dafidi ba Ọlọrun sọrọ nipa awọn eniyan buburu bi ẹni pe o n fi wọn sùn. Dafidi gbadura gẹgẹ bi eniyan kan ti o ni è̩dùn lori awọn ọkàn ti n ṣegbe, ti o si n fẹ ki wọn yipada kuro ninu iwa buburu wọn. Awọn Psalmu wọnyi dàbi adura ti a gbà si Ọlọrun.

Dafidi ba Ọlọrun sọrọ nipa awọn iwa è̩ṣẹ ti o ri ni igbesi-aye awọn eniyan. Awọn kan a maa lọ sọ fun ẹlomiran nipa ẹsẹ ti wọn ri. Awọn miiran a maa ṣe òfófó kiri. Dafidi gbadura. Ẹ jẹ ki a tẹle apẹẹrẹ Dafidi nipa sisọ awọn ẹṣẹ ti o wà ninu igbesi aye awọn ẹlomiran fun Jesu ninu adura.

Ọkàn Buburu

Awọn Psalmu wọnyi n fi han bi iwa eniyan ti n ri nigba ti ọkan rè̩ kò ba ṣe deedee pẹlu Ọlọrun. Pupọ ninu awọn ẹlẹṣẹ kò ni fẹ ki a pe wọn ni eniyan buburu. Wọn le wi pe igbesi-aye awọn kò buru pupọ. S̩ugbọn ọkàn kọọkan ti a kò ba paarọ ki a si fi ifẹ Ọlọrun kún, ọkàn buburu ni. Woli Jeremiah sọ pe, “Ọkàn enia kún fun è̩tan ju ohun gbogbo lọ, o si buru jayi!” (Jeremiah 17:9).

Awọn ẹlẹṣẹ miiran le wà ti wọn ki i sọrọ ibi pupọ ti wọn si maa n kó ara wọn ni ijánu, ṣugbọn nitori pe è̩ṣẹ wa ninu ọkàn wọn, ẹni ẹbi ati egbe ni wọn jẹ niwaju Ọlọrun. Inu ọkàn ni Ọlọrun maa n wò (I Samuẹli 16:7). Awọn miiran wà ti wọn kò fẹ sọrọ ibi, bẹẹ ni wọn kò fẹ huwa ibi, ṣugbọn wọn kò le gba ara wọn silẹ nitori pe è̩ṣẹ wà ninu ọkàn wọn. Paulu Apọsteli jẹri wi pe ki oun to ri igbala oun jẹ ẹni oṣi to bẹẹ ti oun kò fi le ṣe rere ti oun fẹ lati ṣe, ṣugbọn buburu ti oun kò fẹ ṣe gan an ni oun maa n ṣe (Romu 7:19). Nigba ti Paulu ri igbala, igbesi-aye rè̩ yipada gidigidi. Bi Paulu ti n ba ẹri rè̩ lọ o wi pe Jesu Kristi ti da oun ni idè, ati pe agbara wà fun ẹni ti o ba n sin Ọlọrun; o si le sọ wi pe kò si ohun ti o le yà oun kuro ninu ifẹ Kristi (Romu 8:35-39). Paulu wi pe, “S̩ugbọn ninu gbogbo nkan wọnyi awa ju ẹniti o ṣẹgun lọ nipa ẹniti o fẹ wa.” Paulu fi ọpẹ fun Ọlọrun “ẹniti o fi iṣẹgun fun wa nipa Oluwa wa Jesu Kristi” (I Kọrinti 15:57). Lẹyin ti Paulu ri igbala, igbesi-aye rè̩ yatọ. È̩ṣẹ ko bori rè̩ mọ, o ni iṣẹgun lori è̩ṣẹ.

Igberaga

Pupọ ninu awọn Psalmu naa n sọ fun ni nipa awọn eniyan buburu, bi wọn ti n huwa si Ọlọrun, ati iru iha ti Ọlọrun kọ si wọn. È̩ṣẹ jẹ ohun irira niwaju Ọlọrun. Oluwa kò ni inudidun si awọn eniyan buburu (Orin Dafidi 5:4). Oluwa korira awọn oniṣẹ è̩ṣẹ (Orin Dafidi 11:5; 5:5). “Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn O nfi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ” (I Peteru 5:5).

Dafidi fi awọn eniyan buburu sùn pe wọn gberaga. Jẹ ki a wo ohun ti igberaga yoo ṣe fun eniyan. Igberaga a maa mu ki eniyan maa ro nipa ara rè̩ dipo ki o rò nipa Ọlọrun ki o si ṣe afẹri Ọlọrun (Orin Dafidi 10:4). A maa sọ eniyan di anikan-jọpọn, a si maa mu ki eniyan lo ipo lori awọn ẹlomiran lati fi ré̩ wọn jẹ (Orin Dafidi 10:2). Igberaga a maa mu ki eniyan maa ṣogo ninu ifẹ ọkàn rè̩ dipo ninu ifẹ Ọlọrun (Orin Dafidi 10:3). Dafidi jẹ apẹẹrẹ Onigbagbọ. O wi pe, “Ọkàn mi yio ma ṣogo rè̩ niti OLUWA” (Orin Dafidi 34:2).

Igberaga a maa mu ki eniyan buburu ṣe gbogbo nnkan wọnni ti inu Ọlọrun kò dun si. Awọn eniyan buburu rò pe awọn ti to tan ninu ara wọn, wọn si n foju di wahala (Orin Dafidi 10:6). Wọn jọ ara wọn loju, wọn si n ṣogo ninu ọna ara wọn. Wọn n pọn ara wọn niwaju ara wọn (Orin Dafidi 36:2). Wọn ni ireti lori asan pe awọn “ki yio si ninu ipọnju.” Awọn eniyan buburu kò ni ifẹ rara lati ṣe afẹri Ọlọrun, tabi lati rò nipa Rè̩ (Orin Dafidi 10:4). Ẹrù Ọlọrun kò si niwaju wọn (Orin Dafidi 36:1). Awọn eniyan buburu a maa tako idajọ Ọlọrun wọn a si maa sure fun awon ẹni ti Ọlọrun korira (Orin Dafidi 10:3). Wọn a maa gbiro ika, wọn a si maa fẹran iwa ibi (Orin Dafidi 36:4). Awọn eniyan buburu ti fi ọwọ rọ idajọ sẹyin wọn si rò pe Ọlọrun ti gbagbe tabi kò ri è̩ṣẹ wọn (Orin Dafidi 10:11). Igberaga jẹ è̩ṣẹ nitori pe o jẹ idakeji irẹlẹ, iwa tutu, ati iwa pẹlẹ eyi ti Jesu fi kọ ni ti o si fi han ninu igbesi-aye Rè̩ gẹgẹ bi apẹẹrẹ fun awọn ti o gbagbọ. Jesu wi pe: “Ẹ gbà àjaga mi si ọrụn nyin, ki ẹ si mā kọ ẹkọ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan li emi; ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin” (Matteu 11:29).

Inunibini

Dafidi sọ nnkan miiran ti o saba maa n wà ninu iwa awọn eniyan buburu -- ifẹ lati ṣe inunibini si awọn olododo, awọn eniyan Ọlọrun. Awọn kan wà ninu awọn eniyan buburu ti wọn kò fẹ Ọlọrun ti wọn kò si fẹ ki ẹlomiran tẹle Ọlọrun ki o si ni awọn ibukun Rè̩. Awọn eniyan buburu dàbi ẹranko buburu – bi kiniun ti i maa ṣọ anfaani ti yoo fi le bé̩ sori ohun-ọdẹ rè̩. Oju wọn “nṣọ” awọn olododo, ni ibi ikọkọ ni wọn lumọ lati mu awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun.

Jesu fara da iru inunibini bẹẹ. “Nwọn nwá ọna ati gbé ọwọ le e” (Matteu 21:46). Wọn “gbìmọ bi nwọn o ti ṣe ri ọrọ gbámọ ọ li ẹnu” (Matteu 22:15). Wọn ṣọ Jesu, wọn si ran awọn amí “lati fi ọrọ rè̩ mu u” ki wọn ki o ba le fi I le awọn alaṣẹ lọwọ (Marku 12:13; Luku 20:20).

Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe a o ṣe inunibini si wọn (Matteu 5:11, 44). A fi ẹsùn eke sùn awọn ọmọ-ẹyin a si sọ wọn sinu tubu (Iṣe Awọn Apọsteli 5:17-20; 12:3-5; 16:19-24). Pupọ ninu awọn ọmọlẹyin Kristi ni wọn di ajẹriku ti wọn si fi ẹmi wọn lelẹ nitori ti Kristi ati Ihinrere Rè̩. Awọn eniyan wọnyi ka a si anfaani lati fi ẹmi wọn lelẹ nitori ti Kristi, ikú wọn si jẹ ẹri iyanu nipa ifẹ Jesu ati oore-ọfẹ ati agbara Ọlọrun ti o wà ninu ọkàn wọn. Bi o tilẹ jẹ pe a pa awọn Onigbagbọ wọnyi, wọn pa igbagbọ wọn mọ; eyi ti o ṣe iyebiye ju lọ, nitori pe ẹmi wọn yoo wà ninu alaafia titi aye ainipẹkun. Jesu sọ fun awọn eniyan Rè̩ pe ki wọn má ṣe foya awọn ẹni ti o le pa ara, ṣugbọn ti wọn kò le pa ọkàn. O yẹ ki eniyan bè̩ru Ọlọrun, nitori è̩ṣẹ ati aigbọran si ofin Rè̩ yoo mu ki ọkàn oluwarè̩ ṣegbe ninu ọrun apaadi titi lae (Matteu 10:28).

Otoṣi ni Ẹmi

Aya ti o kun fun è̩ṣẹ a maa mu ki ẹnu sọ ẹtàn ati iwa-ika paapaa si awọn eniyan Ọlọrun. Awọn talaka ti Dafidi n sọ nipa rè̩ ni awọn wọnni ti wọn jẹ onirẹlẹ ati “otoṣi li ẹmi.” Jesu sọ wi pe awọn wọnyi pẹlu awọn alabukun-fún (Matteu 5:3). È̩ṣẹ ninu ọkàn a maa mu ki eniyan fi awọn ti o gbẹkẹle Ọlọrun ṣẹsin (Orin Dafidi 14:6). Nipa sisọrọ lọna ẹtàn ati arekereke, o bo ikorira rè̩ mọlẹ (Owe 26:26). Pẹlu iwa agabagebe ati ẹtàn o gbiyanju lati bori awọn eniyan Ọlọrun. Ifẹ awọn eniyan buburu ni lati tan ni jẹ ati lati pa ni run (Orin Dafidi 14:4; 10:8).

Awọn eniyan buburu a maa gbero ibi si awọn olododo. Nigba miiran, ni oru, wọn a maa ṣe aisun lati gbiro ibi si awọn eniyan Ọlọrun (Orin Dafidi 36:4). Ninu iwa buburu ti wọn n pete naa ni a ti n mu wọn (Orin Dafidi 10:2; 9:16). Dafidi wi pe, “Ninu àwọn ti nwọn dẹ silẹ li ẹsẹ ara wọn kọ” (Orin Dafidi 9:15). Ninu Owe a ka pe, “Ẹnikẹni ti o ba wà ihò yio ṣubu sinu rè̩: ẹniti o ba si nyi okuta, on ni yio pada tọ” (Owe 26:27).

Ninu Iwe Esteri a ri apẹẹrẹ ọkunrin kan ti a mu “ninu arekereke” ti o n pete rè̩. Ọkunrin buburu kan ti o n jẹ Hamani korira awọn Ju nitori pe Mordekai ṣe olóòótọ si Ọlọrun ko si jẹ kunlẹ fun Hamani (Esteri 3:2). Hamani dá ọgbọn kan nipasẹ eyi ti o ro pe a o fi Mordekai kọ sori igi. Hamani tilẹ ti mu ki a ri igi naa silẹ de Mordekai. S̩ugbọn gbogbo nnkan yọri si odi keji ohun ti o ti pete rè̩. Ahaswerusi ọba gbọ nipa bi Hamani ti korira Mordekai ọkunrin “ti o ti sọ ọrọ rere fun ọba” (Esteri 7:9). Ọla ati ọrọ ti Hamani ti n reti lati gba ni Ahaswerusi fi san iwa ìjólóòótọ Mordekai fun un. Ọba paṣẹ pe ki a pa Hamani run, ọkunrin ti o kún fun imọ-ti-ara-ẹni-nikan ati ijọ-ara-ẹni-loju, ti ọkàn rè̩ si korò si awọn eniyan Ọlọrun. “Bḝni nwọn so Hamani rọ sori igi ti o ti rì fun Mordekai” (Esteri 7:10).

Lai ni Oyé

Dafidi fi iwa aṣiwere ti ẹlẹṣẹ n hù hàn. O jẹ alailọgbọn nipa ṣiṣiyemeji iṣakoso Ọlọrun ati agbara Rè̩ lori ohun gbogbo, nitori pe ọjọ kan n bọ ti gbogbo eekún yoo wolẹ fun orukọ Oluwa, ti gbogbo ahọn yoo si jẹwọ pe Kristi ni Oluwa (Isaiah 45:23; Filippi 2:9-11).

Awọn eniyan buburu sọ wi pe awọn kò bẹru Ọlọrun (Orin Dafidi 36:1). Wọn tilẹ ṣe ju bẹẹ lọ; wọn wi pe Ọlọrun kò si. Awọn ti n ṣiyemeji ti wọn si n sé̩ Ọlọrun n ṣe bẹẹ nitori pe o wu wọn pe ki o má si Ọlọrun ni, nitori iwa wọn buru. “Gbogbo awọn ti nṣiṣẹ è̩ṣẹ kò ha ni imọ?” Iwa wọn jẹ aṣiwere ati alailọgbọn, nitori pe ẹnikẹni ti o ba fẹ le ṣiro ki o si ni idaniloju funra rè̩ pe Ọlọrun wà. Kò si ọna ti a le gba fi idi rè̩ mulẹ pe eyi kì i ṣe otitọ, ṣugbọn awọn eniyan buburu yọọda lati ro bẹẹ ati lati tan ara wọn jẹ ati lati yan ara wọn jẹ. Ẹni irira ni awọn eniyan buburu jẹ, wọn n gbe igbesi aye ibajẹ ati ẹgbin (Orin Dafidi 14:1, 3). Igbesi-aye wọn kò wulo fun Ọlọrun, wọn kò bu ọla fun Un, bẹẹ ni wọn kò tilẹ ṣe ara wọn ni ire kan lọ titi.

Ewu

Leke hihuwa buburu ati iwa aṣiwere, ẹlẹṣẹ wà ninu ewu nla. Awọn ẹlẹṣẹ le wi pe è̩ru kò ba awọn, ṣugbọn eyi kò din ibawi ati ijiya ti yoo de ba awọn ti o ba kuna lati ba Ọlọrun laja kù. Wọn fi awọn ohun rere ti o dara ju lọ laye du ara wọn – ani awọn ohun rere ti Ọlọrun ti pese silẹ fun awọn ti o gbẹkẹle le E -- wọn si n fa iparun wá sori ara wọn. “Ori awọn enia buburu li a o dà si ọrun apadi, ati gbogbo orilẹ-ède ti o gbagbe Ọlọrun” (Orin Dafidi 9:17).

Dafidi fi iyatọ han laaarin ipin eniyan buburu ati ibukún ti o jẹ ti awọn ti o gbẹkẹle Ọlọrun. Ko si aanu fun awọn wọnni ti kò jẹ ronupiwada, ṣugbọn “ānu OLUWA lati aiyeraiye ni lara awọn ti o bè̩ru rè̩,” bẹẹ si ni “Ẹniti o ba gbẹkẹle OLUWA, ānu ni yio yi i ka kiri” (Orin Dafidi 103:17; 32:10). Iwa buburu ati arekereke wà ninu è̩ṣẹ; ṣugbọn iwa-mimọ ati oore Ọlọrun wà fun awọn eniyan Rè̩. Igbesi-aye ẹlẹṣẹ kún fun ibinu ati ijatilẹ, ṣugbọn Onigbagbọ a maa ni suuru ati itẹlọrun.

Ọlọrun a maa tọju awọn eniyan Rè̩. A maa fi ọrọ ti ẹmi ati ẹkunrẹrẹ ibukún – “ororo ile rẹ” ati “odò ifẹ rẹ” tẹ wọn lọrun (Orin Dafidi 36:8). Wọn a maa gbẹkẹle Ọlọrun lati pese fun wọn ati lati daabo bo wọn. Wọn a maa “gbẹkẹ wọn le abẹ ojiji iyẹ-apa rẹ” (Orin Dafidi 36:7; 91:1; Deuteronomi 32:11, 12).

Nipa sisin Oluwa ati gbigbẹkẹ le E ati le ofin Rè̩ nikan ni a fi le ni iye nipa ti ẹmi pẹlu ẹkunrẹrẹ ibukun Rè̩ nihin ati alaafia ayeraye ni aye ti n bọ. “Nitori pe pẹlu rẹ li orisun iye wà: ninu imọlẹ rẹ li awa o ma ri imọlẹ.” Ka ohun ti Jesu sọ nipa imọlẹ ati iye ninu Johannu 8:12 ati Johannu 10:10.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Awọn wo ni eniyan buburu?

  2. 2 Inu Ọlọrun ha dùn si awọn eniyan buburu?

  3. 3 Ki ni pa aala laaarin awọn eniyan buburu ati Ọlọrun?

  4. 4 Darukọ diẹ ninu awọn ohun ti igberaga ninu ọkàn maa n fà.

  5. 5 Awọn wo ni n ṣe inunibini si awọn eniyan Ọlọrun?

  6. 6 Ki ni inunibini?

  7. 7 Bawo ni a ṣe mọ pe Ọlọrun wà?

  8. 8 Ki ni ṣe ti awọn kan fi wi pe Ọlọrun kò si?

  9. 9 Fi igbesi-aye ẹlẹṣẹ wé igbesi-aye Onigbagbọ.

  10. 10 Ni ọna wo ni ayeraye yoo fi yatọ fun ẹni ti o gbagbọ ati fun eniyan buburu?