Lesson 241 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Emi dubulẹ, mo si sùn; mo si ji; nitori ti OLUWA ti mi lẹhin” (Orin Dafidi 3:5).Notes
Arẹwa Ọmọ-ọba Kan
Dafidi ṣe akoso gbogbo ijọba Israẹli o si ṣe rere lọpọlọpọ fun ọdun pupọ, ṣugbọn bẹẹ ni awọn akoko ibanujẹ wà ni igbà ijọba rè̩. Ọrọ ibanujẹ nla kan ṣẹlẹ ni igbesi-aye rè̩ nigba ti ọmọ oun tikara rè̩, Absalomu, ṣọtẹ si i ti o si gbidanwo lati gbà ijọba lọwọ rè̩.
Awọn Ọmọ Israẹli a maa fi igba gbogbo yé̩ ọmọ-ọba arẹwa yii si, nitori naa kò ṣoro fun un lati fa ọkàn wọn sọdọ ara rè̩. Oun a maa gun kẹkẹ rè̩ ti awọn ẹṣin daradara n fa pẹlu awọn ọmọ-ẹyin rè̩ la igboro Jerusalẹmu já, ọpọlọpọ awọn iranṣẹ a si maa sare lọ niwaju rè̩ lati pa ọna mọ fun un ati lati kede pé o n bọ. Dajudaju ọpọlọpọ eniyan ni yoo pejọ pọ lati wò o bi o ti n kọja lọ, wọn a si maa ju ọwọ si i, wọn a si maa ké si i pe: “Ki ọmọ-ọba ki o pẹ!”
S̩ugbọn okiki yii kò to fun Absalomu! O fẹ lati jẹ ọba ki gbogbo ogo ti iru ipo bẹẹ le jẹ ti rè̩. Oun ni o dagba ju lọ ninu awọn ọmọ Dafidi ti o wa laaye, oun ni o si kàn lati jọba lẹyin baba rè̩; ṣugbọn o ṣe e ṣe ki o ro pe Ọlọrun yoo yàn ẹlomiran lati jọba, tabi ki o jẹ aile mu suuru titi baba rè̩ yoo fi kú ni o fa a. Nitori naa Absalomu bẹrẹ si gbimọ lati gba ité̩ lọwọ Dafidi Ọba.
Iditẹ Naa
Tẹlẹ ri, iṣe awọn adajọ ati awọn agba Israẹli ni lati joko ni ẹnu bode awọn ilu nla wọn ati ilu wọn iyoku lati tẹti si gbogbo wahala ati iṣoro awọn eniyan wọn. Nipa bayii wọn a ni anfaani lati mọ nipa awọn eniyan ti wọn n ṣakoso le lori, wọn a si le pari ede-aiyede ti o wa laaarin wọn ki awọn eniyan ba le maa gbe pọ ni irè̩pọ. Ipo yii ni Absalomu fi ara rè̩ si. Nigbakuugba ti awọn eniyan ba n bọ wa si ilu lati ri ọba, Absalomu a lọ pade wọn ni ẹnu bode a si ni ki wọn sọ wahala wọn fun oun. A fi ibakẹdun pupọ han a si sọ fun ẹni ti o mu ọrọ naa wa pe oun ni o jare.
Oṣelu gidi ni Absalomu i ṣe, o si mọ bi a ti i fi ọgbọn ẹwẹ fà ọkàn awọn eniyan mọra. O mu ki awọn Ọmọ Israẹli rò pe ọba kò naani wọn, a si fẹrẹ sọkun nigba ti o ba n wi pe: “A ba jẹ fi mi ṣe onidajọ ni ilẹ yi! ki olukuluku ẹniti o ni ẹjọ tabi ọran kan ba le ma tọ mi wa, emi iba si ṣe idajọ otitọ fun u!” Awọn ti o tilẹ n fẹ lati tẹriba fun un, ni o maa n fi ẹnu kò ni ẹnu. Awọn eniyan n fẹ agbọrandun, lọna bayii ni Absalomu fi fa ọkàn awọn eniyan kuro lọdọ baba rè̩ sọdọ ara rè̩.
Ọtè̩
Ọdun gori ọdun titi ọjọ naa to ti Abasalomu rò pe oun ni agbara tó lati bi ijọba baba rè̩ wó. Ni ọjọ kan o tọ Dafidi lọ o si wi fun un pe oun n fẹ lọ si Hebroni lati san ẹjẹ kan. Baba rè̩ kò fura si iwa arekereke rè̩, o si sọ pe ki o maa lọ ni alaafia.
Nigba ti Absalomu n fi Jerusalẹmu silẹ o mu igba ọkunrin pẹlu ara rè̩ o si ran awọn amí jakejado gbogbo ilẹ Israẹli lati sọ fun won pe akoko to fun ọtè̩ naa. Nigba ti wọn ba gbọ iro ipè ki wọn mọ pe Absalomu ti di alakoso ni Israẹli. Lati fi iṣora kún arekereke rè̩, Absalomu ti mu Ahitofeli, olori igbimọ Dafidi ọba pẹlu rè̩. Ahitofeli ti jé̩ eniyan Ọlọrun ri, ọrọ ti o ba si sọ jẹ eyi ti a ti ọdọ Ọlọrun dari rè̩. Pẹlu ọkàn Absalomu ti o kún fun è̩ṣẹ bayii o tun n fẹ iranlọwọ Ọlọrun ninu iṣọtẹ rè̩.
Gbogbo ipinnu Absalomu ni o dabi ẹni pe o yọri si rere bi o ti n fẹ, ẹgbẹ ọmọ-ogun nla si pejọ si ọdọ rè̩ ni Hebroni, wọn si mura lati ba Dafidi jà ni Jerusalẹmu.
Sisalọ Dafidi
Inu Dafidi bajẹ gidigidi nigba ti o gbọ ohun ti ọmọ rè̩ ọwọn ti ṣe. Ọkan ninu ẹbi rè̩ ti tan an jẹ o si ti kẹyin si i!
Dafidi mọ pe aabo kò si fun oun ni Jerusalẹmu, nitori naa o kó awọn ọmọ-ọdọ rè̩ ti o pọ sọdọ ara rè̩, o si mura lati fi ilu silẹ. Ta ni o ro pe o ba a lọ? Ki i ṣe awọn Ọmọ Israẹli ti o ti ṣe ohun ti o pọ to bẹẹ fun, ṣugbọn awọn ara Peleti ati Kereti, awọn Filistini, awọn ara Giti ti o ṣẹṣẹ de si Jerusalẹmu. Dafidi sọ fun aṣaaju wọn, Ittai pé oun ati awọn eniyan rè̩ ko gbọdọ fi ẹmi wọn wewu lati ran oun lọwọ, ṣugbọn Ittai dahun pe, “Bi OLUWA ti mbẹ lāye, ati bi oluwa mi ọba ti mbẹ lāye, nitotọ nibikibi ti oluwa mi ọba ba gbe wà, ibakàn ṣe ninu ikú, tabi ninu iye, nibẹ pẹlu ni iranṣẹ rẹ yio gbe wà.” Ọrọ rè̩ ran wa leti ọrọ ti Rutu, ara Moabu sọ fun iya-ọkọ rè̩: “Ibiti iwọ ba lọ, li emi o lọ; ibi ti iwọ ba si wọ, li emi o wọ: awọn enia rẹ ni yio ma ṣe enia mi, Ọlọrun rẹ ni yio si ma ṣe Ọlọrun mi” (Rutu 1:16).
Ikọsilẹ Awọn Ju
Ọlọrun ti pe orilẹ-ède Israẹli lati jẹ eniyan ọtọ fun ara Rè̩. S̩ugbọn wọn kọ lati sin In, awọn Keferi si ri i pe igbala jẹ ti awọn naa pẹlu. Ọpọlọpọ wọn ni o mọ riri rè̩ wọn si wa sọdọ Oluwa. Keferi ni Rutu i ṣe; bẹẹ si ni awọn Filistini yii ti o duro ti Dafidi. Wọn ri ibukún Ọlọrun gbà nipa diduro ti awọn eniyan Rè̩.
Nigba ti awọn Ju kọ Kristi silẹ, O sọkun lori Jerusalẹmu. Ki ni ṣe ti wọn kò gba ihin igbala ti O mu wa? I ba ṣe pe wọn mọ idajọ ti o n duro de wọn, dajudaju wọn i ba kigbe tọ Ọ wa pe ki o gbà wọn. S̩ugbọn dipo eyi, wọn kan An mọ agbelebu.
Lẹba oke yii kan naa, nibi ti Dafidi n rin nisisiyi ni Jesu tú ẹmi Rè̩ jade ninu irora nla ni alẹ ọjọ ti o kẹyin nì fun awọn eniyan Rè̩ alaigbagbọ wọnni. Dafidi ati awọn ọmọ-ẹyin rè̩ n rin lọ ni aiwọ bata, pẹlu ori titẹba, wọn n sọkun bi wọn ti n lọ. Awọn eniyan wọn ti kọ wọn silẹ.
Awọn Ọrẹ Dafidi
Bi awọn ti o n fi ilu silẹ yii ti n ba ọna wọn lọ ni aginju ni wọn n ri awọn diẹ nihin ati lọhun ti kò tẹle Absalomu. Ninu wọn ni Huṣai, ẹni ti i ṣe ọrẹ ati oludamọran fun Dafidi. Dafidi ran Huṣai si aafin Absalomu lati lọ ṣe amí, ati lati lọ fi amọran eke fun Absalomu. Nipasẹ awọn alufaa ti o duro ni Jerusalẹmu ni a o ti mu ihin wa fun Dafidi.
Awọn ọmọ Lefi ti fẹ lati tẹle Dafidi nigba ti o n jade ni ilu, ki wọn si gbe Apoti-ẹri Ọlọrun. S̩ugbọn Dafidi ti sọ fun wọn pe ki wọn pada si Agọ Ajọ ki wọn si duro nibẹ, nitori pe dajudaju Ọlọrun yoo daabo bo Apoti Rè̩. Bi ọtẹ yii ki ba i ṣe ẹbi Dafidi, Ọlọrun yoo mu un pada ni alaafia pẹlu. S̩ugbọn bi Dafidi ba ti dẹṣẹ, ti wahala yii si de gẹgẹ bi ijiya, oun kò fẹ ki Apoti-ẹri Ọlọrun jiya pẹlu oun.
Igbẹkẹle Dafidi
Ninu gbogbo akoko iṣoro yii, Dafidi gbẹkẹle Ọlọrun sibẹ. Ni akoko yii ni o kọ Orin Dafidi 3. Ẹru kò ba a nitori awọn ẹgbẹẹgbẹrun ti o n fẹ gbogun ti i; laaarin gbogbo irukerudo, ọtẹ ati rikiṣi yii, o le wi pe, ”Emi dubulẹ, mo si sàn; mo si ji; nitori ti Oluwa ti mi lẹhin” (Orin Dafidi 3:5).
Absalomu ni Jerusalẹmu
Lẹsẹ kan naa ti Absalomu gbọ pe Dafidi ti fi ilu silẹ, oun ati awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun rè̩ ṣí wa si Jerusalẹmu. Nibẹ ni o bẹrẹsi mura silẹ lati lọ ba baba rè̩ jagun. Ahitofeli damọran pe aarẹ yoo mu Dafidi ati awọn ti o wà pẹlu rè̩ nitori irin ti wọn rin, ati pe akoko yii ni o dara lati kọlu wọn ki a si ṣẹgun wọn kiakia.
Absalomu tun beere amọran lọwọ Huṣai. Aye ṣi silẹ nisisiyi fun Huṣai lati ran Dafidi ọrẹ rè̩ lọwọ. O sọ asọyé pe Dafidi ati awọn ti o wà pẹlu rè̩ yoo wà ninu ikoro ọkàn nitori iwa-ika ti a hu si wọn, wọn o si kún fun ibinu kikoro bi abo amọtẹkun ti a gbà ni ọmọ. Ati pe Absalomu ni lati mọ pe baba rè̩ jẹ jagunjagun alagbara sibẹsibẹ, ati pe ki i ṣe ohun ti o rọrun lati ṣẹgun rè̩. Huṣai damọran pe ki Absalomu fara balẹ titi irunu Dafidi yoo fi tutu, ṣugbọn ni akoko yii ki o gbá ẹgbẹ ogun ti o pọ lọpọlọpọ jọ lati inu gbogbo ẹya Israẹli ki iṣẹgun ba le daju ninu ogun naa. Ọlọrun ni o ran awọn amọran yii wá lati bi ogun Absalomu wó, ṣugbọn Absalomu gbà a, ko si jade lọ lẹsẹkẹsẹ lati ba Dafidi ja.
Inu bi Ahitofeli pe a ko ka amọran oun si to bẹẹ ti o fi lọ si ile rè̩, o fi ohun gbogbo seto, o si pa ara rè̩. Oun ti jẹ ẹni kan ti o ti maa n tẹti si ọgbọn Ọlọrun, ṣugbọn lẹyin igba ti o ti kè̩yìn si ọna otitọ ti o si ti ta ara rè̩ fun è̩ṣẹ, o di alainireti o si kú iku ẹni ti o pa ara rè̩. Eyi jẹ ikilọ gidigidi fun wa ki a má ṣe yipada kuro lọdọ Ọlọrun ki a si pè̩yìndà. O ṣe e ṣe ki a má tun ni anfaaani lati ronupiwada mọ. Wo ọran ibanujẹ nlá nlà ti yoo jẹ lati jẹ ẹni ti o ti mọ ifẹ Ọlọrun tẹlẹ ri, lẹyin eyi ki a si tun ṣegbe laelae!
Ogun Pade Ogun
Jagunjagun ti o mọ iwewe ogun yékéyéké ni Dafidi i ṣe sibẹ, o pin awọn ọmọ-ogun rè̩ si ẹgbẹ mẹta wọn si mura silẹ de Absalomu. Pápá ité̩gun jẹ ilẹ ti kò tẹju ati igbo didi. Ni ọjọ kin-in-ni, ọkẹ kan (20,000) eniyan ni o ṣẹgbé, “igbógàn na si pa ọpọ enia jù eyi ti idà pa lọ li ọjọ na.”
Laaarin ogun naa Absalomu pinya pẹlu awọn ọmọ-ogun rè̩, bi o si ti n gun ibaka rè̩ lọ, ori rè̩ kọ awọn ẹka igi kan ti o di i mu ṣinṣin. Ibaka naa si n sare lọ lofo lai si Absalomu lori rè̩.
Nibẹ ni Absalomu sorọ si lori igi naa, ọkan ninu awọn ọmọ-ogun Dafidi si ri i. O mu ihìn naa tọ olori ogun rè̩, Joabu lọ, Joabu si beere idi rè̩ ti kò fi pa Absalomu. Ọmọ-ogun naa wi pe oun ti gbọ nigba ti Dafidi n ba awọn eniyan rè̩ sọrọ pe ki wọn ṣe inurere si Absalomu, nitori naa ni oun kò tilẹ gbero lati pa a lara.
S̩ugbọn ero ọkàn Joabu yatọ si eyi. O ka Absalomu si ọlọtẹ si ijọba ti o tọna; i baa jẹ ọmọ ọba tabi bẹẹ kọ a gbọdọ pa a run. O mu ọkọ mẹta ni ọwọ rè̩ o si fi gun Absalomu ni ọkàn, oun ati awọn ọkunrin rè̩ si ké e lulẹ wọn si sin in sinu iho kan. Wọn si kó okuta pupọ jọ si i lori.
Bayii ni ọtè̩ ti o dide si ijọba Dafidi dopin, awọn ọmọ-ogun rè̩ si pada si ile.
Ibanujẹ Dafidi
Awọn meji ti n sare mu ihin iṣẹgun naa tọ Dafidi wa. Ohun kin-in-ni ti Dafidi beere ni bi Absalomu ba wà lai lewu. Ọkan ninu awọn ti n sare dahun pe: “Ki awọn ọta oluwa mi ọba, ati gbogbo awọn ti o dide si ọ ni ibi, ri bi ọmọdekunrin na.” O ye Dafidi pe ọmọ oun ti kú, o si wọ inu yara rè̩ lọ oun nikan lati ṣọfọ rè̩: “Ọmọ mi Absalomu, ọmọ mi, ọmọ mi Absalomu! ā! ibaṣepe emi li o kú ni ipò rẹ, Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!”
Awọn eniyan Israẹli ti o ti tẹle Dafidi banujẹ lọpọlọpọ. Wọn rò pe awọn jẹ olóòótọ si Dafidi nipa gbigbé e nija ni didoju kọ onikupani rè̩; nisisiyi o dàbi ẹni pe ohun ti o lodi ni wọn ti ṣe. Pẹlu igboya ni Joabu tọ Dafidi lọ, o si kilọ fun un pe ki o fi imoore hàn fun awọn eniyan Israẹli ti o ti gbè e nija, bi kò ba ṣe bẹẹ gbogbo wọn o dide si i. Dafidi woye, o mọ ojuṣe rè̩ si awọn eniyan rè̩, o si pa ẹdùn ọkàn rè̩ tì si apakan o si lọ joko ni ẹnu-bode ilu lati tù awọn eniyan ninu.
Ọmọ-ọba ni Absalomu i ṣe, pẹlu gbogbo anfaani aye yii. Ọlọrọ ni, o si lẹwa lati wo. O ti mọ nipa Ọlọrun o si ti wà ni ojurere awọn eniyan pẹlu. S̩ugbọn dipo ti i ba fi lo awọn anfaani yii lati fi ran awọn eniyan lọwọ, imọti-ara-ẹni-nikan mu ki o maa rò nipa ti ara rè̩ nikan ṣoṣo. O mu itiju bá baba rè̩, o ṣe aika Ọlọrun si, ati nitori eyi o lọ si isa-oku ninu itiju, o si ṣegbe laelae. “Ikú li ère è̩ṣẹ” (Romu 6:23).
Questions
AWỌN IBEERE1 Ta ni Absalomu i ṣe?
2 S̩e apejuwe ifarahan rè̩ ati iṣe rè̩ ti o mu ki awọn eniyan fẹran rè̩.
3 Ki ni ohun ti Absalomu n fẹ?
4 Bawo ni o ṣe mu ipinnu rè̩ ṣẹ?
5 Ki ni Dafidi ṣe nigba ti o gbọ nipa wahala naa?
6 Bawo ni a ṣe mu Absalomu ti a si pa a?
7 Ki ni èrè è̩ṣẹ?