Lesson 242 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Yio farahan nigbakeji laisi è̩ṣẹ fun awọn ti nwo ọna rè̩ fun igbala” (Heberu 9:28).Notes
Iditẹ Absalomu
Absalomu ti fà ifẹ ọpọlọpọ ni Israẹli sọdọ ara rè̩, o si gbe ọtẹ nla dide si baba rè̩, ẹni ti i ṣe ọba ti o lọla ju lọ ni Israẹli. Dafidi ti sa kuro ni Jerusalẹmu, o si ti fara pamọ jinna rere ninu iju nigba ti ọmọ rè̩ n gbidanwo lati jọba lori awọn Ọmọ Israẹli. Awọn ti wọn dide si Dafidi rò pe ohun gbogbo yoo maa lọ deedee nisisiyi ti ọmọ-ọba arẹwa ọkunrin ti gba ijọba, nitori pe o ṣeleri lati ṣe itọju wọn daradara ati pe oun yoo ri si i pe a ṣe idajọ wọn gẹgẹ bi wọn ti n fé̩.
S̩ugbọn ofo ni ifunnu Absalomu. O ti ṣeleri ọpọlọpọ nnkan ti kò le mu ṣẹ. Lai pẹ jọjọ a pa a loju ogun, awọn Ọmọ Israẹli si wà lai ni ọba. Wọn dàbi agutan ti kò ni oluṣọ. Lai si ẹni kan ti yoo ṣe akoso ki o si maa dari ohun ti awọn eniyan n ṣe, orilẹ-ède naa wà ninu idaamu.
Ninu ipọnju wọn, awọn Ọmọ Israẹli bẹrẹsi i rò nipa Dafidi. Nibo ni o wà? Kò ha le gbà won ninu ipo yii? Wọn ranti pe o ti sin wọn fun ọjọ pipẹ pẹlu ifẹ, ati pe ọpọlọpọ igba ni o ti gbà wọn lọwọ awọn Filistini. Ki ni ṣe ti a kò fi mu Dafidi pada bọ si Jerusalẹmu lati jẹ alakoso wọn?
Ibanujẹ Dafidi
Dafidi kò sare pada wa si Jerusalẹmu lẹsẹkẹsẹ ti o gbọ nipa ikú ọmọ rè̩. O kọkọ fẹ mọ bi wọn ba n fẹ ki oun pada. O ti fẹran awọn eniyan rè̩ lọpọlọpọ, inu rè̩ si bajẹ rekọja nigba ti wọn ṣọtẹ si i. Ni ọjọ buruku naa ti o gbọ pe a ti fi Absalomu jọba, pẹlu itẹriba lai wọ bata, ni o bẹrẹ si i gun oke lọ bi o ti n rin jade kuro ni ilu.
A bi Juda Leere
Akoko kọja lọ, Dafidi si n poungbẹ lati pada lati lọ ran awọn eniyan rè̩ lọwọ. O ti dari iṣọtẹ wọn ji wọn, o si ṣetan lati gbagbe iwa aimoore ti wọn hu si i. Nikẹyin o wa gburo pe awọn eniyan n sọrọ laaarin awọn ẹya Israẹli nipa pipè e pada bọ sori itẹ; ṣugbọn lati ọdọ è̩yà oun tikara rè̩, è̩yà Juda, a kò gbọ nnkankan.
Ni ọjọ kan Dafidi sọ fun awọn alufa (awọn ti wọn ti wà ni ihà ti rè̩) lati lọ sọdọ awọn agba Israẹli ki wọn si bi wọn leere: “Ẽ ṣe ti ẹnyin fi kẹhin lati mu ọba pada wá si ile rè̩? Ọrọ gbogbo Israẹli si ti de ọdọ ọba ani ni ile rè̩. Ẹnyin li ará mi, ẹnyin li egungun mi, ati ẹran ara mi: ẽsi ti ṣe ti ẹnyin fi kẹhin lati mu ọba pada wá?”
Ki i ṣe wi pe Dafidi n fẹ dari iṣọtẹ wọn ji wọn nikan, ṣugbọn o ṣeleri ipo giga fun awọn miiran ninu agbala rè̩ bi wọn ba pe oun pada. Awọn ọkunrin Juda bẹrẹsi i ro nipa iranlọwọ ti Dafidi jẹ fun wọn, wọn si ranṣẹ yii si i lati pe e; “Iwọ pada ati gbogbo iranṣẹ rẹ.” Ọkàn wọn tun pada sọdọ Dafidi ọba wọn ọwọn.
Ipadabọ Naa
Ayọ nla ni o gba agọ Dafidi kan nigba ti a mu irohin naa de. Lẹsẹkẹsẹ ni Dafidi ati gbogbo awọn eniyan ti o wà pẹlu rè̩ bẹrẹ irinajo pada si odo Jọrdani ati olu-ilu nì. Awọn ọkunrin Juda ti jade wá lati pade wọn pẹlu ikini kaabọ fun ọba, pẹlu ẹyẹ ni wọn si mu ẹgbé̩ ọba rekọja odo Jọrdani. Wọn gbà Dafidi ni ọba wọn, wọn si tun jẹjẹ lati maa sin in.
Ifojusọna Kristi fun awọn Eniyan Rè̩
A le fi ifojusọna Dafidi lati tun wà pẹlu awọn eniyan rè̩ we ifojusọna Kristi fun Ijọ Rè̩ tootọ -- Iyawo Kristi. Nisinsinyi O wà ni “ilu okere nì” eyi ti O sọ nipa rè̩ ninu owe kan (Matteu 21:33-41); O si n duro de awọn eniyan Rè̩ lati mura silẹ lati wà pẹlu Rè̩ ninu Ile Rè̩ loke.
Jesu n fẹ lati wá mu awọn eniyan Rè̩ lati wà pẹlu Rè̩, lati maa wò O ninu ogo Rè̩, ki wọn maa ṣakoso ki wọn si maa jọba pẹlu Rè̩. Njẹ awa fẹ ki O de?
Njẹ a n ṣe ohunkohun ti yoo mu ki Jesu pada wa? Oun ki yoo de titi Iyawo Rè̩ yoo fi mura tan lati pade Rè̩. Angẹli nì sọ fun Johannu ni Erekuṣu Patmo pe ikede Ase Alẹ Igbeyawo Ọdọ-agutan yoo jẹ: “Ẹ jẹ ki a yọ, ki inu wa ki o si dùn gidigidi, ki a si fi ogo fun u: nitoripe igbeyawo Ọdọ-Agutan de, aya rè̩ si ti mura tan” (Ifihan 19:7).
Ijọ tootọ ni Iyawo Kristi. Iṣẹ wa nihin, gẹgẹ bi Onigbagbọ ni lati mura silẹ gẹgẹ bi iyawo fun ọkọ rè̩. Jesu ni Ọkọ-iyawo fun ọkàn wa.
Imurasilẹ
Ninu imurasilẹ a o gbé ọṣọ ti ẹmí wọ. Orukọ ọtọtọ ni a fi n pe e. Aṣọ ọgbọ wiwẹ ni ododo awọn eniyan mimọ. “On ni a si fifun pe ki o wọ aṣọ ọgbọ wiwẹ ti o funfun gbõ: nitoripe aṣọ ọgbọ wiwẹ nì ni iṣe ododo awọn enia mimọ” (Ifihan 19:8).
“Ninu aṣọ iṣẹ ọnà abẹrẹ li a o mu u tọ ọba wá” (Orin Dafidi 45:14). Awọn oore-ọfẹ Onigbagbọ ni iṣẹ-ọna abẹrẹ yii eyi ti i ṣe ẹwa Iyawo nì. Oun n gbe igbesi-aye rè̩ gẹgẹ bi ẹkọ Bibeli, o si lẹwa ni oju Oluwa. Ọṣọ rè̩ ni “ẹmí irẹlẹ ati ẹmí tutù, eyiti iṣe iyebiye niwaju Ọlọrun” (I Peteru 3:4).
Fifojusọna fun Oluwa Wa
Nigba ti a ba ti gbé gbogbo ọṣọ wọnni wọ, ọkàn wa yoo maa poungbẹ gidigidi lati ri Ọkọ-iyawo, Ọmọ Ọlọrun. Iru oungbẹ yii ni o wà lọkàn Dafidi nigba ti o gbadura bayii: “Tani mo ni li ọrun bikoṣe iwọ? kò si si ohun ti mo fẹ li aiye pẹlu rẹ” (Orin Dafidi 73:25).
Lẹhin ti a ba ti fi Ẹmi Mimọ wọ wa, Ẹmi Ọlọrun yoo maa gbe inu wa. Oun a si maa ba wa sọrọ nipa Jesu; bi a si ti n tẹti si ohun kẹlẹkẹlẹ ti O n fọ si wa nipa ifẹ Jesu fun wa, oungbẹ ọkàn wa lati ri Jesu yoo maa pọ si i.
Ẹmi Mimọ a maa ṣe alaye Ọrọ Iwe Mimọ fun wa eyi ti o n sọ fun wa nipa Ile daradara ti Jesu ti lọ pese silẹ fun Iyawo Rè̩. Oun a maa sọ fun wa ti anfaani ti a o ni nigba ti a ba wà pẹlu Rè̩: “Ẹniti o ba ṣẹgun li emi o fifun lati joko pẹlu mi lori ité̩ mi, bi emi pẹlu ti ṣẹgun, ti mo si joko pẹlu Baba mi lori ité̩ rè̩” (Ifihan 3:21). O ṣe alaye ohun ti iṣẹ wa yoo jẹ nigba ti a ba lọ lati ba Oluwa gbe: “Olubukun ati mimọ ni ẹniti o ni ipa ninu ajinde ekini na: lori awọn wọnyi ikú ekeji kò li agbara, ṣugbọn nwọn o jẹ alufa Ọlọrun ati ti Kristi, nwọn o si mā jọba pẹlu rè̩ li ẹgbè̩run ọdún” (Ifihan 20:6). Eyi yoo jẹ ijọba ododo lori ilẹ aye yii nigba Ijọba Ẹgbè̩run Ọdun.
Iwọ ha n foju sọna fun bibọ Jesu? Tabi ọràn igbesi-aye rẹ ti gba ọ lọkàn to bẹẹ ti kò fi si aye fun ọ lati rò nipa rè̩? Ta ni ẹni ti o kọkọ n ro nipa rè̩ nigba ti o ba ji ni owurọ? Njẹ ireti rẹ ha ni pe, “Jesu le de loni?” Ta ni ẹni pataki ju lọ ni igbesi-aye rẹ? Njẹ o ka a si ohun pataki ju lọ lati wu Jesu, Ọkọ ẹmi rẹ, ju lati wu awọn ọrẹ rẹ ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ?
Ti Rè̩ nipa Irapada
Jesu ti fi Ẹjẹ Rè̩ iyebiye rà wa. Ti Rè̩ ni awa i ṣe a si ṣọwọn ni oju Rè̩. O fẹran wa to bẹẹ ti O fi kú fun wa, ati nipa Ẹjẹ Rè̩ ni a si ti gba wa là. “Ati bi ọkọ iyawo ti iyọ si iyawo, bḝni Ọlọrun rẹ yio yọ si ọ” (Isaiah 62:5). Bawo ni ifẹ wa si I ti to nigba ti a ba fi wé ifẹ Rè̩ si wa? A ha fi ayé wa fun iṣẹ-isin Rè̩? N jẹ a le kú fun Un bi o ba ṣẹlẹ pe o ni lati ri bẹẹ?
Bi a ba bi ara wa leere awọn ibeere wọnyi, nigba naa ni a o mọ bi a ba n wọna fun bibọ Ọba wa tabi bẹẹ kọ. Ọpọlọpọ ẹlẹṣẹ lode oni ni o mọ pe Jesu n bọ lai pẹ. Awọn eniyan ti Rè̩ n kọ? N jẹ wọn ha n wi fun Ọba pe ki O pada wa, ki wọn si maa reti lati ri I lai pẹ? Ọpọlọpọ ti wọn n sọ pe ti Jesu ni awọn kò fi ara fun mimurasilẹ lati pade Rè̩. Wọn n fi hàn nipa bi wọn ti n gbé igbesi-aye wọn pe wọn ko ṣe aapọn rara lati ri I. Bawo ni inu Rè̩ yoo ti bajẹ to lati ri aibikita wọn!
Ipe Ihinrere
Ọkan ninu awọn iṣẹ Iyawo Kristi ni lati rọ awọn ẹlẹṣẹ lati ri igbala ki o to pẹ jù. Ẹ jẹ ki a beere lọwọ ara wa, “A ha ni itara fun ọkàn?” Njẹ a ni itara lati ri i pe Ihinrere tan kalẹ ni gbogbo aye, ki ọkẹ aimoye awọn eniyan ti kò tilẹ ti i gbọ nipa Jesu ba le ri igbala?
Angẹli nì sọ fun Johannu ni Erekuṣu Patmo pe, “Ati Ẹmi ati iyawo wipe, Mā bọ” (Ifihan 22:17). Nitori naa bi a ba jẹ Iyawo Kristi, a o maa wi pe, “Mā bọ.” Nipa gbigbe igbesi-aye wa fun Jesu, nipa gbigbadura gidigidi, nipa ẹri wa, a n rọ ẹni ti kò i ti ri igbala lati fi ọkàn rè̩ fun Jesu ki oun paapaa ba le di Iyawo Kristi.
Bi a ba n sa gbogbo ipa wa fun Jesu, a le ba Johannu Apọsteli sọ bayii pe: “Mā bọ, Jesu Oluwa” (Ifihan 22:20).
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni ṣe ti a le Dafidi jade kuro ni ilu?
2 Ki ni ipo ti Israẹli wà lẹyin ti a pa Absalomu?
3 Ki ni ṣe ti Dafidi fi duro fun igba diẹ ki o to pada si Jerusalẹmu?
4 Ta ni fun Dafidi ni ìpè ti o n fẹ?
5 Ta ni Ọba wa?
6 Ki ni ṣe ti Onigbagbọ n fẹ ki O pada wa?
7 Bawo ni a ti ṣe le mura silẹ lati pade Ọba wa?
8 Ki ni diẹ ninu awọn iṣẹ Iyawo Kristi?
9 Ta ni sọ awọn ohun ti n sọ ọkàn ji fun wa nipa Jesu?