II Samuẹli 21:1-22

Lesson 243 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Awa ti fi OLUWA, Ọlọrun Israẹli, bura fun wọn: njẹ nitorina awa kò le fọwọkàn wọn” (Jọṣua 9:19).
Notes

Gbigbadura

Ni akoko ti Dafidi jẹ ọba lori awọn Ọmọ Israẹli, iyan kan mú. Fun ọdun mẹta, lati ọdun dé ọdun ni ìyàn naa fi mú. Ni akoko yii ti ounjẹ ṣọwọn boya ti ebi si n pa awọn eniyan, Dafidi gbadura. O beere lọdọ Oluwa ohun ti o fa a ti iyan naa fi pé̩ to bẹẹ. Dafidi huwa ọlọgbọn nipa biba Oluwa sọrọ nipa ohun ti o ṣẹlẹ yii. Akoko aini ni, Dafidi kò si mọ ọna ti oun le gbà lati mu ipọnju naa kuro. Dafidi ba Ọlọrun sọrọ, ani Ẹni kan ṣoṣo naa ti o le sọ idi rè̩ fun Dafidi. Ohun ti o tọ lati ṣe nigba gbogbo ni lati gbadura.

Dafidi le pe awọn oludamọran rè̩. Boya awọn kan le daba pe ki wọn ṣe ohun kan; awọn miiran si le damọran ohun miiran. S̩ugbọn nipa titọ Ọlọrun lọ ninu adura, a sọ ohun naa gan an ti o fa ìyàn yii fun Dafidi. Dafidi kò gbadura pẹ titi ki idahun naa to dé.

Igba pupọ ni awọn eniyan maa n jiya nitori pe wọn kò mu ọrọ wọn tọ Ọlọrun lọ ninu adura. Igba miiran si wa ti Ọlọrun maa n fi àyè silẹ fun idajọ lati wa sori awọn eniyan nitori pe è̩ṣẹ wà ninu igbesi-aye wọn. Ninu ifẹ ati aanu Rè̩, Ọlọrun yoo sun wọn de ipo kan ti yoo mu wọn gbadura lati beere lọdọ Rè̩, ṣugbọn wọn kò ni gbadura. Wahala le maa gori wahala fun wọn, sibẹ wọn kò ni wá Ọlọrun. Nipa jijafara lati gbadura wọn a maa dù ara wọn ni anfaani ibukun ati iranlọwọ Ọlọrun. Awọn miiran a maa lọ, lati ọdun de ọdun, ninu wahala, ninu ipọnju, ati ninu è̩ṣẹ, lai wá Ọlọrun. Nipa fifi adura jafara ati sisún akoko ati gbadura siwaju, ẹni naa yoo maa wà ninu aimọkan, ninu è̩ṣẹ ati aṣiṣe. A le bọ lọwọ ibanujẹ pupọ nipa gbigbadura lakoko.

Awọn ara Gibeoni

Ọlọrun sọ fun Dafidi pe ohun ti o fa ìyàn naa ni pe Saulu pa ninu awọn ara Gibeoni. Awọn eniyan wọnyi ki i ṣe awọn Ọmọ Israẹli, bi o tilẹ jẹ pe wọn ti n gbe laaarin wọn fun ọpọlọpọ ọdun. Awọn ara Gibeoni ti n gbe ni ilẹ Kenaani tẹle ri, awọn Ọmọ Israẹli kò si pa wọn run nigba ti awọn Ọmọ Israẹli kọkọ de ilẹ naa. Awọn Ọmọ Israẹli ti da majẹmu lati dá awọn ara Gibeoni si; nitori pe awọn ara Gibeoni ti mu ki awọn Ọmọ Israẹli dá majẹmu yii nipa ifarahan è̩tàn ati ọrọ eké. Awọn Ọmọ Israẹli kò beere amọran lọdọ Ọlọrun nigba naa, ṣugbọn niwọn bi wọn ti dá majẹmu yii Ọlọrun n beere pe ki wọn pa a mọ.

Majẹmu Kan

Awọn Ọmọ Israẹli mọ iwuwo majẹmu ti wọn ti da. Wọn wi pe: “Awa ti fi OLUWA Ọlọrun Israẹli, bura fun wọn: njẹ nitorina awa kò le fọwọkàn wọn . . . awa o da wọn si, ki ibinu ki o má ba wà lori wa, nitori ibura ti a bura fun wọn” (Joṣua 9:19, 20).

Awọn ara Gibeoni ti wa laaarin awọn Ọmọ Israẹli ju irinwo (400) ọdun lọ ki Saulu, gẹgẹ bi ọba, to pa ninu wọn. Ninu itara rè̩, Saulu ti ba majẹmu naa jẹ. Ki i ṣe oun ni o ba wọn dá majẹmu yii, ṣugbọn Ọlọrun kà a si eyi ti o ti fidi mulẹ fun Israẹli, O si fẹ ki Saulu ka a si. Kì i ṣe awọn ara Gibeoni ni o mu è̩sùn naa wa; Ọlọrun ni o sọrọ fun wọn.

O Jẹbi

Dafidi ti jọba fun ọdun melo kan nigba ti ìyàn yii de. Kò si akọsilẹ kan pe Saulu pa awọn ara Gibeoni; a kò mọ akoko ti nnkan yii ṣẹlẹ gan an. S̩ugbọn ijọba Saulu ti dopin ṣiwaju akoko yii nitori naa ìyàn yii jẹ ijiya fun ohun ti o ti ṣẹlẹ ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin. O dabi ẹni pe awọn ẹlomiran rò pe igba a maa bò è̩ṣẹ mọlẹ, ṣugbọn eyi kò ṣe deedee pẹlu Ọrọ Ọlọrun. Boya a kò sọ ohunkohun nipa è̩ṣẹ naa nigba ti a pa awọn eniyan wọnyi, ṣugbọn akoko dé ti Ọlọrun n beere rè̩. “Ẹnyin dé̩ṣẹ si OLUWA, ki o si dá nyin loju pe, è̩ṣẹ nyin yio fi nyin hàn” (Numeri 32:23). “Bi a tilẹ fi ọwọ so ọwọ, enia buburu ki yio lọ laijiya” (Owe 11:21). Gbogbo orilẹ-ède naa ni o jiya nitori è̩ṣẹ Saulu.

Nigba ti awọn eniyan ba ṣaigbọran si Ọlọrun, wọn a fa iya wá sori ara wọn ati sori awọn ẹlomiran pẹlu. Bi ẹni kan ninu ile kan ba huwa aitọ kan, gbogbo ile naa ni yoo kàn lara. Bi ẹni kan ninu ijọ ba kuna niwaju Ọlọrun, ipinya naa yoo mu ibanujẹ ba awọn ti o kù. A jẹ ẹni kan niya fun è̩ṣẹ rè̩, ṣugbọn è̩ṣẹ naa yoo mu ki awọn ẹlomiran jiya pẹlu. A ti kẹkọọ nipa apẹẹrẹ miiran ti o fi otitọ yii han. (Wo Ẹkọ 172). A ṣẹgun awọn Ọmọ Israẹli ni Ai nigba ti Akani dẹṣẹ (Jọṣua 7:4). Ki i ṣe gbogbo wọn ni o jiya gẹgẹ bi Akani, ṣugbọn gbogbo wọn ni a pọn loju nitori rè̩.

È̩san

Dafidi mọ pe è̩ṣẹ ni è̩gàn ati itiju orilẹ-ède (Owe 14:34). Dafidi n fẹ lati san eyi ti o tọ fun iwa buburu ti a hu si awọn ara Gibeoni. O beere ohun ti wọn gbọdọ ṣe. Wọn kò fẹ ki a fi owo san ẹsan fun wọn. Ki i ṣe igba gbogbo ni wura ati fadaka le san ẹsan fun ipalara ti a ṣe si awọn eniyan. Ẹmi ẹni kan ni Israẹli ko tilẹ tó lati san an paapaa. Ninu irú ọràn bayi, gẹgẹ bi ofin, tita ẹjẹ ẹni ti o paniyan naa silẹ nikan ni o le mu ẹbi kuro lori orilẹ-ede naa (Numeri 35:33).

Saulu ti kú ni akoko yii, ṣugbọn Dafidi gbà pe ki a fi meje ninu awọn ọmọkunrin ninu ẹbi Saulu le awọn ara Gibeoni lọwọ. A le gbagbọ pe awọn ọmọkunrin wọnyi ti ni ipin ninu pipa awọn eniyan wọnyi pẹlu baba wọn. Ofin kọ ni pe “a kò gbọdọ pa awọn baba nitori è̩ṣẹ awọn ọmọ, bḝni a kò gbọdọ pa awọn ọmọ nitori awọn baba: olukuluku enia li a o pa nitori è̩ṣẹ rè̩” (Deuteronomi 24:16).

Jesu, Alailẹbi

Akọsilẹ kan ṣoṣo ni o wa ninu Bibeli eyi ti a beere pe ki alaiṣẹ kan kú ki o ba le ṣetutu fun è̩ṣẹ awọn ti o jẹbi. Alailẹṣẹ naa ni Jesu, Ọmọ kan ṣoṣo ti Ọlọrun, Ẹni ti o fi ẹmi Rè̩ lelẹ ki a ba le dari è̩ṣẹ wa ji wa ati lati san igbese wa. “Nitori nigbati awa jẹ alailera, li akokò ti o yẹ, Kristi kú fun awa alaiwabi-Ọlọrun” (Romu 5:6). “Bḝni Kristi pẹlu lẹhin ti a ti fi rubọ lḝkanṣoṣo lati ru è̩ṣẹ ọpọlọpọ; yio farahan nigbakeji laisi è̩ṣẹ fun awọn ti nwo ọna rè̩ fun igbala” (Heberu 9:28). “Nitoriti Kristi pẹlu jiya lḝkan nitori è̩ṣẹ wa, olõtọ fun awọn alaiṣõtọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun” (I Peteru 3:18).

Ikú

Dafidi ṣọra ki o má ba ba majẹmu miiran jẹ eyi ti o ṣe pẹlu ọmọ Saulu, Jonatani (I Samuẹli 18:3). Nitori adehun yii Dafidi dá ẹmi Mefiboṣeti si, ṣugbọn awọn meje miiran ni o kú fun didà majẹmu ti a ba awọn ara Gibeoni dá.

Iya awọn meji ninu wọn pohun réré ẹkun o si ṣọfọ fun ikú wọn. O fi ifẹ rè̩ si wọn han nipa didaabo bò okú wọn lọwọ ooru ati awọn ẹranko. Kò sun awọn ara Gibeoni lẹsun pé wọn huwa buburu. Kò ba Dafidi sọ pe oun ni o fi aye silẹ fun eyi ti o ṣẹlẹ si awọn ọmọ rè̩. Kò ji okú wọn gbé lọ, ṣugbọn o fi aye silẹ fun idajọ ti a ṣe. Ikú wọn jẹ ere è̩ṣẹ (Romu 6:23).

Isinkú

Nigba ti ojo de, Dafidi sinkú wọn daradara pẹlu ọwọ fun Saulu ẹni ti o jọba ṣiwaju rè̩. Dafidi sin wọn sinu iboji Kiṣi baba Saulu, pẹlu Saulu ati Jonatani egungun awọn ẹni ti awọn ọkunrin Jabeṣi-gileadi ti ṣe itọju rè̩.

Bi o tilẹ jẹ pe wọn jẹ ọmọ-ọba, a beere ẹjẹ wọn fun è̩ṣẹ naa. Nipa bayii a yi ibinu Oluwa kuro lori ilẹ naa, ìyàn naa si dopin.

Ogun Kan pẹlu awọn Òmìrán

Eyi ki i ṣe opin gbogbo wahala fun Dafidi. Awọn Filistini, awọn ọta orilẹ-ède wọn lati ibẹrẹ wa tun gbogun ti i. A ranti pe ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin, Dafidi ti pa ọkan ninu wọn, Goliati, omiran. O dabi ẹni pe awọn ara ile Goliati kò gbagbe.

Dajudaju, Dafidi ti bẹrẹ si di arugbo, bẹẹ ni kò si le ṣe aapọn ogun jija mọ. Bi o tilẹ jẹ pe o rẹ Dafidi oun ko sá. Nigba ti o “rè̩ Dafidi” Abiṣai fi ẹmi ara rè̩ wewu nipa ṣiṣe iranlọwọ lati gba Dafidi silẹ. Abiṣai pa omiran naa ti o gbero lati pa Dafidi.

Awọn Ọmọ Israẹli fi ọwọ fun Dafidi gẹgẹ bi ọba wọn. Wọn kò tun gba a laaye lati lọ si ogun mọ. Wọn bu ọlá fun Dafidi fun ipo ti o wa niwaju Oluwa. Awọn ọmọ-ogun Dafidi lọ si ogun lati ba awọn omiran Filistini ja. Oluwa ran awọn Ọmọ Israẹli lọwọ lati pa awọn ti o foju di Ọlọrun ati Israẹli bi Goliati ti ṣe tẹlẹ ri, ki a yo ṣẹgun rẹ. Ni akoko yii Ọlọrun ran awọn Ọmọ Israẹli lọwọ lati pa òmìrán mẹrin -- ọkan ninu wọn ni ìka mẹfa ni ọwọ kọọkan, ati ọmọ-ẹsẹ mẹfa ni ẹsẹ kọọkan. Ọlọrun wà pẹlu awọn Ọmọ Israẹli, agbara awọn omiran naa si di asan. Bayii ni awọn Ọmọ Israẹli ni iṣẹgun patapata lori awọn Filistini, awọn ọta wọn.

Ọkàn ti o Yatọ

A ranti ihin buburu awọn ami mẹwaa nì. Awọn eniyan naa bẹru awọn omiran ati ilu olodi Kennani (Numeri 13:28). S̩ugbọn Kalebu ni “ọkàn ti o yatọ” ti o ni igbagbọ ninu Oluwa. Ni ọdun marunlelogoji lẹyin eyi, nigba ti o n beere fun ilu awọn òmìrán fun ilẹ ini rè̩, Kalebu wi pe, “Boya OLUWA yio wà pẹlu mi, emi o si lé wọn jade” (Jọṣua 14:12). Pẹlu iranlọwọ OLUWA, Hebroni di ilẹ-ini Kalebu nitori ti o tọ Oluwa Ọlọrun Israẹli lẹyin patapata (Jọṣua 14:14).

Pẹlu igbẹkẹle wọn ninu Ọlọrun, Dafidi ati awọn eniyan rè̩ ni iṣẹgun patapata lori awọn òmìrán Gati ati lori awọn Filistini. Nipa gbigbẹkẹle Ọlọrun ati gbigbọran si Ọrọ Rè̩, awa paapaa le ni iṣẹgun lori gbogbo omiran ọta ti o le doju kọ wa.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Bawo ni Dafidi ṣe mọ ohun ti o fa ìyàn naa?

  2. 2 Bawo ni ìyàn naa ti pé̩ to?

  3. 3 Ta ni awọn ara Gibeoni i ṣe?

  4. 4 Majẹmu wo ni a ba wọn dá?

  5. 5 Ki ni ṣe ti a so meje ninu awọn ọmọkunrin Saulu rọ?

  6. 6 Ki ni ṣe ti a dá Mefiboṣeti si?

  7. 7 Awọn omiran melo ni a pa ni akoko yii?

  8. 8 Ki ni ṣe ti awọn Filistini ba Dafidi jà?

  9. 9 Ta ni ni iṣẹgun ni ikẹyin ninu awọn ogun laaarin Dafidi ati awọn Filistini?