II Samuẹli 22:1-51

Lesson 244 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitori nipa rẹ li emi ti là arin ogun kọja: nipa Ọlọrun mi emi ti fò odi kan” (II Samuẹli 22:30).
Notes

Orin Imoore

Dafidi fi imoore hàn si Ọlọrun fun ọpọlọpọ ọrọ ibukun Rè̩. Dafidi mọ pe lai si iranlọwọ Oluwa oun jẹ alaini iranlọwọ. O ti ja ọpọlọpọ ogun ti o le nigba ti awọn ọta ni agbara pupọ ju awọn ọmọ-ogun tirè̩ lọ; bi ko ba ṣe pe Oluwa wà ni iha tirè̩ ni, kì ba ti ṣe e ṣe fun un lati ni iṣẹgun. Ayà Dafidi kún nipa agbara ti Ọlọrun ti fi fun un to bẹẹ ti o fi kigbe wi pe, “Nipa rẹ li emi ti là arin ogun kọja: nipa Ọlọrun mi emi ti fò odi kan.”

Dafidi ranti lati fi ọpẹ fun Ọlọrun fun iranlọwọ yii. Ọpọlọpọ ninu awọn Psalmu ni o jẹ orin iyin Dafidi si Ọga Ogo ju lọ ti O bojuwo awọn onirẹlẹ ti o si n ran iranlọwọ si wọn.

Dafidi kò rò pe Ọlọrun ti jinna pupọ ju lati gbọ adura oun. Ni Ọrun loke lọhun, Ọlọrun gbọ O si dahun. Sọlomọni ọba ni iru igbagbọ kan naa nigba ti o gbadura bayi: “Ki o si gbọ li ọrun, ibugbe rẹ! gbọ, ki o si dariji” (I Awọn Ọba 8:30). Johannu Apọsteli sọ pe bi a ba gbagbọ pe Jesu n gbọ ti wa, a o fi idahun adura wa fun wa (I Johannu 5:15).

Awọn Ogun ti Ọlọrun Jà

Bawo ni Ọlọrun ti ṣe n ja ogun Israẹli? Ni Egipti O ran ajakalẹ-àrun si awọn eniyan ilẹ na, lati fi agbara mu ki wọn ba le jọwọ awọn Ọmọ Israẹli lati fi ilẹ naa silẹ. Ọlọrun ṣe awọn ohun ti eniyan kò le ṣe. O sọ omi odo Nile di ẹjẹ to bẹẹ ti ẹnikẹni ko ri omi mu. Lẹyin naa O tun sọ ọ di omi pada. O ran ina-ori ati ọpọlọ lati yọ awọn ara Egipti lẹnu, ati ni oru ọjọ ti o buru ju lọ fun awọn ara Egipti, O pa akọbi ọkunrin ninu ile awọn ara Egipti kọọkan.

Lẹyin ti awọn Ọmọ Israẹli ti jade ni Egipti ti wọn si ri i pe a se wọn mọ laaarin oke ati okun, ti awọn ọta si n bọ lẹyin, Ọlọrun bi omi sẹyin O si mu ki awọn Ọmọ Israẹli lọ lori iyangbẹ ilẹ. Nigba ti awọn ara Egipti gbiyanju lati tẹle wọn, Ọlọrun mu ki omi naa pada, gbogbo wọn si rì. Ko ṣe e ṣe fun eniyan lati gbà awọn Ọmọ Israẹli lọwọ awọn ọta wọn, ṣugbọn Ọlọrun ṣe e.

Lati ṣẹgun Kenaani, Ọlọrun mu ki odi Jẹriko wó lulẹ, ki awọn Ọmọ Israẹli le wọ ilu naa. Nigba kan o ran agbọn lati ta awọn eniyan naa lati mu ki wọn sá niwaju awọn Ọmọ Israẹli. Nigba miiran nigba ti awọn ẹgbẹ ogun nla de lati ba wọn ja ti o pọ pupọ ju fun wọn lati ṣẹgun nipa agbara wọn, Ọlọrun rán yinyin nlá nlá sọkalẹ; “awọn irawọ ni ipa wọn bá Sisera jà,” ẹni ti i ṣe ọta Israẹli.

Nigba ti Jonatani ati ẹni ti n ru ihamọra rè̩ lọ si ibudo awọn Filistini lai si ẹlomiran pẹlu wọn -- ọkunrin meji doju kọ ẹgbẹ ogun kan -- Ọlọrun ran isẹlẹ lati fun wọn ni iṣẹgun.

Ẹjẹ Jesu Igbala Wa

Ninu gbogbo wahala Dafidi, Ọlọrun ni O n gba a silẹ. O gbe igbesi-aye rè̩ lati wu Ọlọrun. A ti dari è̩ṣẹ rè̩ ji i, kò si tun ni lati bè̩ru nipa idajọ. Bẹẹ gẹgẹ ni awa naa bi a ba ti sọ pe ki Jesu dari è̩ṣẹ wa ji wa ki O si fi Ẹjẹ Rẹ wẹ wọn nù. Nipa rironupiwada è̩ṣẹ wa, a ran wọn siwaju nisisiyi si idajọ; nigba ti Jesu ba si wa ṣe idajọ aye a o le wi pe, “A ti gba wa la nipa Ẹjẹ Ẹni ti a kan mọ ‘gi.”

Dafidi wi pe, “O gbà mi, nitoriti inu rè̩ dùn si mi.” Inu Ọlọrun ko dùn si Dafidi nigba ti o jẹ ẹlẹṣẹ; ṣugbọn lẹyin ti a ti dariji i ti o si fẹran Ọlọrun pẹlu gbogbo ọkàn rè̩, nigba naa ni inu Ọlọrun dùn si ohun ti o n ṣe.

N jẹ Ọlọrun ni inudidun ninu ohun ti a n ṣe? Igbesi-aye wa ha wu U? N jẹ a ranti pe Ọlọrun n kiyesi ohun gbogbo ti a n ṣe? N jẹ a n ṣe e lati fi ọlá fun Un? Nigba ti a ba n ṣe bẹẹ, a le nireti pe ki Oluwa ki o gbọ ti wa nigba ti a ba gbadura, ki O si fun wa ni ọpọlọpọ ohun rere. Johannu kọwe pe, “ohunkohun ti awa ba bère, awa nri gbà lọdọ rè̩, nitoriti awa npa ofin rè̩ mọ, awa si nṣe nkan wọnni ti o dara loju rè̩” (I Johannu 3:22). Bi a ko ba dahun adura wa, ẹ jẹ ki a wadi ayé wa ki a si wò bi a ba n ṣe ohunkohun ti kò dara loju Rè̩.

A Pa Ọrọ naa Mọ ninu Ọkàn

Dafidi le wi pe oun ti pa ọna Oluwa mọ oun si ti gbọran si ilana Rè̩. Nigba kan o sọ pe, “Inu mi dùn lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun mi, nitõtọ, ofin rẹ mbẹ li aiya mi” (Orin Dafidi 40:8).

A ni lati mọ ifẹ Ọlọrun, Ọrọ Rè̩, ki a to le pa a mọ ni aya wa. A gbọdọ fara balẹ ka Bibeli ki a ba le ranti ohun ti Ọlọrun n fẹ ki a ṣe. Awọn akọwe ati awọn Farisi ni akoko Jesu rò pe awọn ti mọ Ofin daradara, sibẹ Jesu wi fun wọn pe ki wọn wa inu Iwe Mimọ wò ki wọn ba le ni idaniloju pe wọn o lọ si Ọrun. Wọn ni ero ti wọn lọkàn nipa ohun ti o jẹ lati jẹ ẹni rere, wọn kò si fẹ kọ nipa aanu ati ifẹ fun awọn alaini ati awọn ti a n ni lara, gẹgẹ bi Jesu ti kọ ni.

Wọn rò pe o ti tó lati fẹran awọn ọrẹ wọn ki wọn si korira awọn ọta wọn; ṣugbọn Jesu sọ pe, “Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin” (Matteu 5:44). Wọnyi jẹ ohun ti o ṣoro lati ṣe; ṣugbọn bi a ba fẹran Jesu ni tootọ, Oun yoo ran wa lọwọ lati ṣe wọn.

Aanu fun Alaaanu

Bi a ba fi aanu hàn fun awọn ẹlomiran, Ọlọrun yoo fi aanu hàn fun wa. Dafidi mọ eyi o si kọ akọsilẹ bayi pe, “Fun alānu ni iwọ o fi ara rẹ hàn li alānu, ati fun ẹni-iduro-ṣinṣin li ododo ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni iduro-ṣinṣin li ododo.” Jesu ti ṣeleri lati dariji wa bi a ba dariji awọn ẹlomiran.

A o ri i pe a ni ọpọlọpọ ọrẹ si i bi a ba ṣe oninu rere si awọn eniyan ti a si fi hàn fun wọn pe a fẹran wọn gẹgẹ bi Jesu ti n fẹ ki a ṣe. Igbà pupọ ni o jẹ pe awọn eniyan yoo ṣe si wa gẹgẹ bi a ti ṣe si wọn; bi a ba si jẹ amọ-ti-ara-ẹni-nikan ti a si kun fun ikorira, wọn o ṣe bẹẹ gẹgẹ pẹlu.

A sọ itan kan nipa ọmọde kan ti o n gbe ni ẹba igbo kan; ni ọjọ kan o jade si gbangba o si kigbe pe, “Pẹlẹ o.” O gbọ gbohungbohun kan pé “Pẹlẹ o.” O ro pe ọmọdekunrin miiran ni o da oun lohun, nitori naa o tun kigbe pe, “Ọmọ buburu ni ọ!” Gbohungbohun tun da esi pada pe, “Ọmọ buburu ni ọ!” O tun kigbe wi pe, “Wa nihin, ng o si lu ọ!” Idahun naa tun pada pe, “Wa nihin, ng o si lu ọ!” “Mo mbọ.” “Mo mbọ.”

Ọmọdekunrin naa sare wọ inu ile o si sọ fun iya rẹ pe “Ọmọ buburu kan wa ninu igbo ti o wa lẹba ile wa yii o si n fẹ nà mi.” Iya rè̩ da a lohun pe, “Bẹkọ, nkò ro pe ọmọ buburu ni. O kò sọrọ si i bi o ti yẹ. Bi o ba fi iyọnú sọrọ si i on na i ba ti fi inu rere hàn si ọ. Lọ gbiyanju lẹkan si i.” Ọmọdekunrin naa tun jade si gbangba o wi pe “Pẹlẹ o.” O gbọ gbohungbohun wi pe “Pẹlẹ o.” Nigba yii o ni “Ọmọ rere ni ọ!” idahun si de, “Ọmọ rere ni ọ!” “Mo fẹran rẹ” -- bẹẹ ni gbohungbohun naa si dahun, “Mo fẹran rẹ”. O sare lọ sinu ile, o si wi pe, “Iya, ọmọdekunrin rere ni.”

A o ni ọrẹ pupọ bi a ba huwa ọrẹ si awọn eniyan. Nigba pupọ ni a le tipasẹ inurere yi awọn ti wọn ti huwa aitọ si wa pada. Eniyan a maa layọ si i nigba ti o ba n huwa rere si awọn ẹlomiran dipo ki o maa tẹnu mọ eyi ti o rò pe o tọ ni oju ara rè̩.

Alagbara ninu Ogun

Iṣẹ Dafidi ni lati pa awọn ọta Israẹli run. Iru awọn eniyan bẹẹ jẹ ọta Ọlọrun, o si tọ pe ki a ṣẹgun wọn. Ọlọrun mu ki Dafidi di alagbara ninu ogun ki o ba le mu gbogbo ifẹ Ọlọrun ṣẹ.

A Pe Awọn Orilẹ-ède Miiran

Awọn Ọmọ Israẹli jẹ ayanfẹ Ọlọrun, bẹẹ ni O si ba wọn lò ni ọna ti o yatọ, O fun wọn ni anfaani lati ni imọ nipa Rè̩. O fun wọn ni ohun gbogbo ti wọn n fẹ nigba ti wọn ba sin In pẹlu gbogbo ọkàn wọn. S̩ugbọn, gẹgẹ bi orilẹ-ède wọn ti yipada kuro lẹyin Ọlọrun wọn si n sin awọn ọlọrun miiran.

Ninu ẹkọ wa a sọ fun wa pe Dafidi sọ asọtẹlẹ nipa igba kan ti awọn eniyan miiran ti ki i ṣe awọn Ọmọ Israẹli yoo wa sin Ọlọrun; “Awọn alejo yio fi è̩tan tẹriba fun mi: bi nwọn ba ti gbọ iró mi, nwọn o si gbọ ti emi.”

Bakan naa ni Isaiah ni imisi lati kọ akọsilẹ pe: “Kiyesi i, iwọ o pe orilẹ-ède ti iwọ kò mọ, ati orilẹ-ède ti kò mọ ọ yio sare wá sọdọ rẹ” (Isaiah 55:5). Awọn wọnyi ni awọn Keferi, awọn orilẹ-ède miiran lẹyin awọn Ju, ti wọn n fi ọkàn wọn fun Ọlọrun ti wọn si n sin In. Wò o bi ayọ wa ti pọ to pe ifẹ Ọlọrun kà wa mọ wọn.

A Da a lati maa Yin In

Ọlọrun da eniyan lati maa yin In. “Nitori mo ti dá a fun ogo mi” (Isaiah 43:7). O si n fẹ ki a jẹ gbogbo igbadun ayeraye pẹlu Rè̩. S̩ugbọn wo bi eniyan ti ja Ọlọrun tilẹ to! Ọpọlọpọ eniyan ni kò fẹran Ọlọrun; dipo eyi wọn yipada kuro lọdọ Rè̩ wọn si n huwa buburu.

Jesu n na ọwọ Rè̩ jade O si n wi pe “Ẹ wá sodọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ, ti a si di ẹrù wuwo le lori, emi o si fi isimi fun nyin” (Matteu 11:28). S̩ugbọn eniyan dahun pe, “Bẹkọ, emi ki yio wá.” Jesu wi pe ẹnikẹni ti o ba fẹ lé wa. O n pe olukuluku eniyan lati wa jẹ ajumọjogun “ohun gbogbo” pẹlu Rẹ -- ohun gbogbo ti eniyan le ro -- ṣugbọn ọpọlọpọ eniyan ni o n wi pe, “Bẹẹkọ, mo fẹ gbe igbesi-aye temi.”

Ẹ jẹ ki awa ti a mọ Ọn fẹran Rè̩ pẹlu gbogbọ ọkàn wa. Ẹ si jẹ ki a sọ bẹẹ fun Un. Ẹ jẹ ki a gbiyanju lati dí aye ti awọn ti o kọ lati feti si ti Rè̩ fi silẹ. Ẹ jẹ ki a maa kọrin nigba gbogbo, ninu ọkàn wa bi a kò tilẹ kọ ọ jade, gẹgẹ bi Dafidi ti ṣe: “Nitorina emi o fi ọpẹ fun ọ Oluwa, larin awọn ajeji orilẹ-ède: emi o si kọrin si orukọ rẹ.” Má ṣe tiju Jesu lae, ṣugbọn jẹ ẹlẹri fun Un nibi gbogbo ti o ba fun ọ ni anfaani lati lo ayé rẹ fun Un ati lati sọ nipa Rè̩. Ki imoore wa ati ifẹ wa si Ọlorun maa ru soke ninu ọkàn wa titi!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni mu ki Dafidi jẹ alagbara ninu ogun?

  2. 2 Bawo ni Ọlọrun ti ṣe jà fun Israẹli?

  3. 3 Idi wo ni Dafidi sọ fun iranlọwọ Ọlọrun ti o ri gba?

  4. 4 Bawo ni a ṣe le fẹ awọn ọta wa?

  5. 5 Sọ ọna kan ti a le gbà fi ni ọrẹ.

  6. 6 Bawo ni a ṣe mọ pe awọn Keferi pẹlu awọn ti a pe sinu ifẹ Ọlọrun?

  7. 7 Ki ni Ọlọrun da eniyan fun?

  8. 8 Iru ogún wo ni Jesu ni fun awọn ti o fẹ Ẹ?