Orin Dafidi 23:1-6; 27:1-14

Lesson 245 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA li Oluṣọ-agutan mi; emi ki yio ṣe alaini. O mu mi dubulẹ ninu papa-oko tutù; o mu mi lọ si iha omi didakẹ rọrọ. O tù ọkàn mi lara; o mu mi lọ nipa ọna ododo nitori orukọ rè̩. Nitõtọ, bi mo tilẹ nrin larin afonifoji ojiji ikú, emi ki yio bè̩ru ibi kan; nitori ti Iwọ pẹlu mi; ọgọ rẹ ati ọpá rẹ nwọn ntù mi ninu. Iwọ té̩ tabili onjẹ silẹ niwaju mi li oju awọn ọta mi; iwọ dà ororo si mi li ori; ago mi si kún akúnwọsilẹ. Nitotọ, ire ati ānu ni yio ma tọ mi lẹhin li ọjọ aiye mi gbogbo; emi o si ma gbe inu ile OLUWA lailai” (Orin Dafidi 23:1-6).
Notes

Orin Daradara Kan

A kọ awọn Psalmu (Orin Dafidi) fun kíkọ gẹgẹ bi orin iyin si Ọlọrun. Kò si orin daradara kan ti o dàbi Orin Dafidi ikẹtalelogun. Awọn eniyan ti kò ka Bibeli ri ti ka a ninu awọn iwe akewi, ọpọ eniyan ni o si n fi ọrọ inu rè̩ ṣe ọrọ sọ. Awọn ọrọ inu rè̩ ni ẹwà nitori pe wọn kò ṣoro lati mọ, itunu ati agbara wà ninu awọn ileri ti Ọlọrun pese silẹ fun awọn eniyan Rè̩, ireti iye ainipẹkun si wà ninu rè̩ pẹlu.

Ẹmi Ọlọrun ti tipasẹ awọn ọrọ rè̩ bá ọkàn awọn eniyan sọrọ, awọn ti i ba ṣoro fun lati yipada si Oluwa fun iranlọwọ lọnakọna. Igba pupọ ni o jẹ pe ọrọ inu rè̩ ni a kọkọ fi n kọ awọn ọmọde, ati ọrọ ikẹyin ti a maa n sọ kẹlẹkẹlẹ si eti awọn olufẹ ti o n rekọja lọ si ayeraye.

Oluṣọ-agutan Rere

Wo o bi ọkàn Dafidi yoo ti kún to bi o ti n ro ọrọ yii pe: “OLUWA li Oluṣọ-agutan mi!” Orukọ ti o tobi jù lọ ti a fi n pe Ọlọrun ni o lo: Jehofa, Ẹni nla nì ti n jẹ EMI NI, Ọlọrun ayeraye, Alakoso gbogbo agbaye. N jẹ o le ṣe e ṣe pe ki O jẹ Oluṣọ-agutan eniyan kan?

Jesu wi pe, “Emi ni Oluṣọ-agutan rere, mo si mọ awọn temi, awọn temi si mọ mi” (Johannu 10:14); nitori naa ọrọ Dafidi tọna nigba ti o wi pe Oluwa ni Oluṣọ-agutan oun. Paulu Apọsteli pe E ni “Oluṣọ-agutan nla ti awọn agutan” (Heberu 13:20); Peteru si pe E ni “Olori Oluṣọ-agutan” (I Peteru 5:4).

Ayọ Dafidi

Ayọ Dafidi ni lati mọ pe Oluwa rè̩ wà ni tosi. Oun ni ọba Israẹli ti o lọla ju lọ, ṣugbọn ayọ ti o ni kì i ṣe nitori pe o n gbe inu aafin daradara, bẹẹ ni kì i ṣe nitori ọpọlọpọ awọn iranṣẹ ti n fi tifẹtifẹ duro niwaju rè̩ lati sin in, tabi nitori awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun rè̩ nla ti n pa gbogbo aṣẹ rè̩ mọ. Ninu ọkan ninu awọn orin rè̩ si Oluwa, o wi pe “Ni iwaju rẹ li ẹkún ayọ wà: li ọwọ ọtún rẹ ni didùn-inu wà lailai” (Orin Dafidi 16:11).

O le jẹ pe nigba ti Dafidi n ṣe oluṣọ-agutan nigba ti o wà ni ọdọmọkunrin ni o kọ Psalmu kẹtalelogun yii; tabi laaarin gbogbo ogo ati ẹrù iṣẹ aafin rè̩ ni o wá aye lati wà pẹlu Ọlọrun nikan lati ṣe àṣàrò lori ifẹ ati itọju Rè̩ si i gẹgẹ bi Oluṣọ-agutan rè̩.

Oluṣọ-agutan Mi

Fun Dafidi, Oluwa sun mọ tosi ju Oluṣọ-agutan gbogbo Israẹli lọ. O ni “OLUWA li Oluṣọ-agutan mi.” Gbogbo awa ti a ti tun bí ni o le wi bi ti Dafidi pe Oluwa ni “Oluṣọ-agutan mi.” Nigba ti a bà wá sọdọ Rè̩ pẹlu ironupiwada ati igbagbọ, Ẹjẹ Rè̩ a wè̩ è̩ṣẹ wa nù, a o si jẹ ti Rè̩. Nipa bayii a ni ipin lọdọ Rẹ.

Dafidi ranti ifẹ rè̩ si awọn agutan rè̩ nigba ti o n ṣe itọju wọn ni ẹba oke. O ti mura tan lati ba kiniun ati amọtẹkun jà lati gba awọn ọdọ agutan rè̩ kékèké lọwọ awọn ẹranko ti o yẹhanna fun ebi yii. O mọ pe oluṣọ-agutan rere kò jẹ fi awọn agutan rè̩ silẹ lai ni aabo. Bi o ti n ro nipa ifẹ Ọlọrun si i o ranti olóòótọ oluṣọ-agutan ẹni ti o fẹ lati fi ẹmi rè̩ lelẹ nitori awọn agutan rè̩. Eyi ni ohun ti Jesu ṣe nigba ti O wa si aye. O wi fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe, “Mo si fi ẹmi mi lelẹ nitoriti awọn agutan” (Johannu 10:15).

Kò si Aini

Dafidi le sọ pẹlu idaniloju pe, “Emi kì yio ṣe alaini.” Nipasẹ iriri o mọ pe Ọlọrun yoo pese fun gbogbo aini oun. Bi a ba gbe igbesi-aye ti o wu Oluwa, a o ni igbẹkẹle bẹẹ gẹgẹ pe a ki yoo ṣe alai ni ohun ti o dara. Paulu Apọsteli kọ akọsilẹ yii pe, “Ọlọrun mi yio pèse ni kikún fun gbogbo aini nyin, gẹgẹ bi ọrọ rè̩ ninu ogo ninu Kristi Jesu” (Filippi 4:19).

Jesu fẹ ki awọn eniyan Rè̩ gbẹkẹle Oun ki wọn si gba awọn ileri Oun gbọ. Bi a kò ba n ri awọn ohun ti a gbadura fun gbà, o le jẹ pe a n fẹ ohun ti kò dara fun wa ni. Ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe, “Bi a ba si li onjẹ ati aṣọ iwọnyi yio té̩ wa lọrùn” (I Timoteu 6:8).

Lẹba Omi Tutu

Ẹ jẹ ki a ro o ninu ọkàn wa pe a n wo agbo agutan ti o dubulẹ labẹ ojiji awọn igi nla kan lẹba iṣan omi kan. Wọn ti jẹ ninu eweko tutù yọyọ titi o fi té̩ wọn lọrun, nitori pe agutan ti ebi n pa kò jé̩ dubulẹ. Oluṣọ-agutan ni o fara balẹ wa ibi ti o fa ni mọra yii nitori pe igba ooru a maa gbona nibi ti Dafidi n gbe, awọn agutan ti o si wà ni aṣalẹ le kún fun oungbẹ tabi ki wọn kú nipa gbigbona imooru ọjọ. Oluṣọ-agutan rere mu awọn agutan rè̩ lọ si iha omi didakẹrọrọ, nibi ti wọn gbe le jẹun ki wọn si ni itẹlọrun, ti wọn si le dubulẹ lati sinmi.

Idakẹrọrọ yii ni Dafidi n rò nipa rè̩ bi o ti n ṣe aṣaro nipa Oluṣọ-agutan rè̩. Isaiah wi pe, “Iṣẹ ododo yio si jẹ alafia, ati eso ododo yio jẹ idakẹjẹ on ābo titi lai” (Isaiah 32:17). “Alafia pupọ li awọn ti o fẹ ofin rè̩ ni: kò si si ohun ikọsẹ fun wọn” (Orin Dafidi 119:165). “OLUWA yio fi agbara fun awọn enia rè̩; OLUWA yio fi alafia busi i fun awọn enia rè̩” (Orin Dafidi 29:11). “O nfi ire fun olufẹ rè̩ loju orun” (Orin Dafidi 127:2).

Ọna Olokuta

Nigba ti awọn agutan ba ti jẹ gbogbo koriko ibujẹ kan tan, wọn ni lati ṣi lọ si ibomiran, boya ni ipa ọna okuta ati ọna tooro la oke ja. S̩ugbọn olusọ-agutan wọn n lọ ṣiwaju wọn lati daya kọ wahala oju ọna naa; bi awọn miiran ba si jẹ alailera lati gbesẹ ba wọn, yoo gbe wọn. Woli Isaiah paapaa, ri aworan Olugbala gẹgẹ bi Oluṣọ-agutan, o si kọ akọsilẹ pe: “On o bọ ọwọ-ẹran rè̩ bi oluṣọ-agùtan: yio si fi apá rè̩ ko awọn ọdọ-agutan, yio si ko wọn si aiya rè̩, yio si rọra dà awọn ti o loyun” (Isaiah 40:11).

Onigbagbọ yoo la iyiiriwo kọja ti yoo dabi ipa ọna okuta fun un. S̩ugbọn bi igbẹkẹle rè̩ ba wa ninu Oluwa, yoo jade pẹlu iṣẹgun. Dafidi wi pe “O tù ọkàn mi lara.” Bi aarẹ ba mu wa nipa idanwo wa, tabi bi a ba rẹwẹsi diẹ nitori aisan wa, Oun yoo tu ọkàn wa lara bi a ba gbé oju wa soke si I.

Irẹpọ Timọtimọ si I

Ninu awọn ẹsẹ kin-in-ni Psalmu yii, Dafidi n sọ nipa Oluṣọ-agutan ti o n ṣamọna rè̩; ṣugbọn nigba ti o n sọrọ nipa lila afonifoji ojiji ikú kọja, Oluwa gan an ni o n ba sọrọ. “Iwọ pẹlu mi; ọgọ rẹ ati ọpá rẹ nwọn ntu mi ninu.” Oluwa ti ṣeleri pe, “Emi kò jẹ fi ọ silẹ, bẹni emi kò jẹ kọ ọ silẹ” (Heberu 13:5).

Fun Onigbagbọ imọlẹ didan wa lẹyin ikuuku. Jesu kú fun wa O si mu oro ikú kuro. Ni wakati naa ti kò si ọrẹ ayé ti o le ba wa lọ, Oluwa yoo wà timọtimọ ni ẹgbẹ wa. Ọna tooro si Ilẹ Ologo nì ni ikú jẹ. Ẹni ti o ti ba Ọlọrun laja le sọ pẹlu Dafidi pe, “Emi ki yio bè̩ru ibi kan.”

“Ibẹru kò si ninu ifẹ; ṣugbọn ifẹ ti o pé nlé ibẹru jade” (I Johannu 4:18). O le gbiyanju lati jẹ onigboya, ki o si fi è̩ru rẹ rẹrin; ṣugbọn wọn o wà sibẹ afi bi o ba gbẹkẹle Ọlọrun. Bi a ba fi gbogbo ọkàn wa fẹran Rè̩, Oun yoo mu ibè̩ru wa kuro.

Awọn Ọrẹ

Bi a ti n ṣe aṣaro lori awọn ẹsẹ wọnyi, a ti ro nipa ara wa, bi Dafidi ti ṣe, gẹgẹ bi agutan ti Oluṣọ-agutan nla nì n ṣamọna rè̩ lọ. Ninu awọn ẹsẹ ti o tẹle e a tun ri aworan miiran; ọkunrin kan ti o n ba ọrẹ rè̩ jẹun. Awa ni alejo Oluwa, ti n jẹun ni tabili Rè̩. “Iwọ té̩ tabili onjẹ silẹ niwaju mi.”

Ami ti o tobi ju lọ lati fi iṣọrẹ hàn ni Ila-oorun ni fun awọn eniyan lati ba ara wọn jẹun. Jesu wi pe “Kiyesi i, mo duro li ẹnu ilẹkun, mo si nkànkun, bi ẹnikan ba gbọ ohùn mi, ti o si ṣi ilẹkun, emi o si wọle tọ ọ wá, emi o si ma ba a jẹun, ati on pẹlu mi” (Ifihan 3:20). Oun o ba wa jẹun ati awa naa yoo si ba A jẹun! A kò ni pupọ ti a le fi fun Un, ṣugbọn Oun ni ohun gbogbo lati fi fun wa. Nigba ti O ba tú ibukun Rè̩ jade, ago wa yoo si kún akúnwọsilẹ. O n fẹ lati maa ba wa rin, ki O si maa ba wa sọrọ, ki O si fun wa ni ọpọlọpọ ohun rere. “Kò si ohun rere ti yio fà sẹhin lọwọ awọn ti nrìn dede” (Orin Dafidi 84:11).

Bawo ni Oluwa ti ṣe n té̩ tabili ounjẹ silẹ niwaju wa ni oju awọn ọta wa? A le jẹ ẹni kan ṣoṣo laaarin awọn ẹlẹṣẹ, ki ọrọ ti wọn n sọ ati iwa wọn mu ibanujẹ ba ọkàn wa. Wọn le ṣalai jẹ ọta wa ṣugbọn niwọn igba ti a kò ti gba ọkàn wọn la ọta Ọlọrun ni wọn. Laaarin gbogbo ayika yii Oluwa le bukún wa, ki O si fi Ọrọ Rè̩ bọ wa titi ao fi ro pe O té̩ tabili ounjẹ silẹ niwaju wa. Awọn ọdọmọkunrin Onigbagbọ ti o sin orilẹ-ède wọn nigba ogun ṣe ẹlẹri eyi nigba pupọ. Laaarin è̩ṣẹ ati ogun, Oluwa yoo sun mọ tosi, A si fi Ọrọ Rè̩ bọ wọn.

Lori Okun China, lori ọkọ oju omi kan ti i maa gbé awọn ọkọ ofuurufu, awọn ẹgbẹ atukọ kan n ṣe isin Aisun Ọdun Titun. Ọlọrun bukún ọkàn wọn nibẹ laaarin ogun pẹlu ọrọ aiku Onipsalmu yii, “Iwọ té̩ tabili onjẹ silẹ niwaju mi li oju awọn ọta mi.”

A Da Ororo Si i Lori

Ami ọyàyà ni ni Ilẹ Mimọ (ti a n pe ni Palẹstini) lati da ororo sori alejo. A ranti ohun ti o ṣẹlẹ nigba ti Jesu jẹ alejo fun Simoni, Farisi, ti a ko si fi iké̩ pupọ hàn fun Un. Nigba ti obinrin nì de pẹlu kolobo ororo ikunra ti o si fi kùn ẹsẹ Jesu, O ba Farisi naa wi pe, “Iwọ kò fi oróro pa mi li orí: ṣugbọn on ti fi ororo pa mi li ẹsẹ” (Luku 7:46). Nitori ifẹ rè̩ fun Jesu, O dari è̩ṣẹ rè̩ ji i; ṣugbọn Simoni ti kò ni ẹmi ikẹni bẹẹ, ti kò si ronupiwada wà ni ẹlẹṣẹ sibẹ. Dafidi le sọ pe Oluwa fi ìké̩ ṣe itọju oun: “Iwọ dà ororo si mi li ori.”

Itumọ ti o tun jinlẹ ju eyi lọ wà fun ami ororo yii. Awa gẹgẹ bi Onigbagbọ ti a sọ di mimọ, ni anfaani lati ni ifororoyàn ti Ẹmi Mimọ. Apẹẹrẹ eyi ni a fi hàn ninu isin Agọ nipa titá ororo si awọn alufaa lori. A kilọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe ororo naa jẹ mimọ. “A ko gbọdọ dà a si ara enia, bḝli ẹnyin kò gbọdọ ṣe irú rè̩ . . . mimọ ni, yio si ma ṣe mimọ fun nyin” (Ẹksodu 30:32).

Bi a ti joko nibi tabili Rè̩, Oluwa fi ororó Ẹmi Mimọ kún wa ki a ba le jẹ ọba ati alufaa fun Ọlọrun Ọga Ogo ju lọ.

Idi Kan

Bi Dafidi ti boju wo ẹyin wo ayé rè̩, o ri i pe Oluwa ni o ti ṣe amọna oun, o si ni idaniloju pe Oluwa yoo si maa ṣe amọna oun titi de opin. Ipinnu kan ni o sa wà ninu ọkàn rè̩ -- lati maa gbe inu Ile Oluwa laelae. Ni gbogbo ọjọ aye rè̩ o fẹ lati wà lọdọ Ọrẹ ati Olugbala rè̩, ki o si maa jọsin ninu Agọ Rè̩. Nigba naa, nigba ti aye yii ba dopin, yoo ni idaniloju ile kan ni Ọrun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ta ni Dafidi fi Oluwa wé?

  2. 2 Ki ni mu inu Dafidi dùn?

  3. 3 Nibo ni Oluṣo-agutan rere tọ awọn agutan Rè̩ lọ?

  4. 4 Irú ifararubọ wo ni oluṣọ-agutan le ṣe fun awọn agutan rè̩?

  5. 5 Ta ni n fun wa ni ohun gbogbo ti a ṣe alai ni bi a ba gbẹkẹle E?

  6. 6 Ki ni oluṣọ-agutan n ṣe fun awọn agutan rè̩ nigba ti ọna kò ba tẹjú?

  7. 7 Irú irẹpo wo ni Dafidi tun sọ nipa rè̩ laaarin oun ati Oluwa?

  8. 8 Ki ni ohun ti o n sọ nipa rè̩ nigba ti o wi pe, “Iwọ dà ororo si mi li ori?”

  9. 9 Ki ni ilepa ti o ga ju lọ ni igbesi-aye Dafidi?