Orin Dafidi 25:1-22; 94:1-23

Lesson 246 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Gbogbo ipa OLUWA li ānu ati otitọ, fun irú awọn ti o pa majẹmu rè̩ ati ẹri rè̩ mọ” (Orin Dafidi 25:10).
Notes

Awọn Ibukun

Awọn ohun rere ti o si dara wà ni aye ti awọn olododo ati awọn alaiṣododo jumọ n gbadun rè̩. Ọlọrun gba gbogbo eniyan laaye lati gbadùn ohun ti O dá ati awọn iṣẹ-ọwọ Rè̩. Ọpọlọpọ eniyan ni o maa n ri ibukun ati imisi gbà nigba ti wọn ba wo irisi ti o lẹwa lara oke, omi, yinyin ti o bọ silẹ, ilẹ aṣálè̩ tabi awọn àwọ oju ọrun. Ayọ maa n gba ọkàn awọn ẹlomiran kan lati ri ẹranko igbẹ tabi ìtànná igbẹ laaarin ayika rè̩. Ọpọlọpọ eniyan ti wọn kì i ro nipa Ọlọrun ni nnkan n lọ deedee fun, ti wọn n ṣe aṣeyọri, wọn n ni ilera, wọn n ni inudidun nipa awọn nnkan ti aye yii. Wọn n jẹ igbadun awọn nnkan ti Ọlọrun ti pese silẹ fun awọn eniyan, bi afẹfẹ, oorun, ounjẹ, omi ati awọn nnkan ti ara ti o jẹ kò ṣeé-má-ni fun igbesi-aye itura. Wọnyi ni awọn ibukun ti awọn eniyan n ri gba lojoojumọ. S̩ugbọn awọn ọtọtọ ibukun wà ti Ọlọrun ti yà sọtọ fun awọn eniyan ti Rè̩. Awọn ibukun kan wa ti Ọlọrun n tú jade sori awọn olododo nikan.

Ifọkantan

Dafidi Onipsalmu sọ nipa igbẹkẹle ti oun ni ninu Ọlọrun. O sọ nipa idaniloju ti oun ni ninu Ọlọrun lati dahun adura. Ohun ti Dafidi n beere ti o si n reti lọdọ Ọlọrun ni awọn ibukun ti o wà fun gbogbo awọn olododo. Kì i ṣe pe Dafidi jẹ ẹni kan ti a ṣe ojusaju fun ju awọn iyoku lọ. Ohun ti Dafidi ri gbà lọdọ Ọlọrun, olukuluku Onigbagbọ ni o le ri gbà bẹẹ gẹgẹ!

Dafidi sọ pe “OLUWA iwọ ni mo gbé ọkàn mi soke si.” Dafidi gbadura; o gbẹkẹle Ọlọrun; o mu ara rè̩ lọkàn le ninu Oluwa. A mu ọkàn Dafidi wá si ibi giga ju ti atẹyinwa lọ nitori pe igbẹkẹle rè̩ wa ninu Ọlọrun. Ẹ jẹ ki ọrọ Dafidi mu wa gbadura ju bẹẹ lọ, lati gbé ọkàn wa soke si Oluwa ju bi a ti n ṣe tẹlẹ ri lọ. Woli Jeremiah ninu Ẹkun rè̩ wi pe, “Jẹ ki a gbe ọkàn ati ọwọ wa soke si Ọlọrun li ọrun” (Ẹkun Jeremiah 3:41).

Eniyan le gbe ọkàn rè̩ soke si asan (Orin Dafidi 24:4), ati si igberaga (I Timoteu 3:6); ṣugbọn eyi yoo mu idalẹbi ati fifa sẹyin ibukun Ọlọrun wá. Ẹ jẹ ki a gbe ọkàn ati aya wa soke ninu adura ati isin si Ọlọrun!

Igbẹkẹle ninu Ọlọrun

Awọn olododo ni igbẹkẹle ati igbagbọ ninu Ọlọrun. Kò si ohun aye yii ti a le fi wé igbẹkẹle wọn. Igbà pupọ ni o jẹ pe awọn alaiwabi-Ọlọrun n fi igbẹkẹle wọn sinu owo, sinu awọn ọrẹ, sinu agbara wọn ati ẹkọ wọn, tabi iṣẹ wọn. S̩ugbọn kò si idaniloju pe awọn nnkan wọnyi kì yoo kùna. Iriri ti fi hàn pe gbogbo nnkan aye wọnyi ni o n kùna.

Nigba ti eniyan ba fi igbẹkẹle ati igbagbọ rè̩ sinu Ọlọrun ati Ọrọ Rè̩, ẹni naa gbẹkẹle Ẹni kan ani Ẹni kan ṣoṣo naa ti kò le kuna. Mose sọ Ọrọ Ọlọrun fun awọn Ọmọ Israẹli pe Ọlọrun ki yoo ja wọn tilẹ bẹẹ ni ki yoo kọ wọn silẹ (Deuteronomi 31:6). Mose sọ fun Jọṣua pe: “S̩e giri ki o si mu àiya le . . . Ati Oluwa on li o nlọ ṣaju rẹ; on ni yio pẹlu rẹ, on ki yio fi ọ silẹ, bḝni ki yio kọ ọ: máṣe bè̩ru, bḝni ki àiya ki o máṣe fò ọ” (Deuteronomi 31:7, 8). Ọlọrun wà pẹlu Jọṣua ati awọn Ọmọ Israẹli. A kà a pe: “Ohunkohun kò tase ninu ohun rere ti Oluwa ti sọ fun ile Israẹli; gbogbo rè̩ li o ṣẹ” (Jọṣua 21:45).

Ọlọrun ati Ọrọ Rè̩ kò le kùna; Ọrọ Rè̩ a maa ṣẹ dandan ni. A le gbẹkẹ wa le awọn ileri Rè̩ ki a si mọ pe wọn daju (Ka Isaiah 34:16; 40:8; Matteu 24:35; Luku 16:17; ati I Peteru 1:25). Awọn alaiwabi-Ọlọrun kò ni irú nnkan bẹẹ lati gbẹkẹle pẹlu idaniloju pe yoo ṣẹ.

Oju Kò Le Ti i Lae

Nigba ti eniyan ba fi igbẹkẹle rè̩ sinu Ọlọrun, kò tun si ohun ti yoo mu ki oju ki o ti i. Ọpọlọpọ awọn alaiwabi-Ọlọrun ni oju maa n ti nipa igbesi-aye wọn. È̩ṣẹ wọn a maa mu itiju ba wọn. Onigbagbọ ti sọ fun Ọlọrun pe ki o mu è̩ṣẹ oun kuro ki O si fun oun lagbara lojoojumọ lati gbe igbesi-aye ti kò lè̩ṣẹ. Igbesi-aye ẹlẹṣẹ kún fun itiju, ṣugbọn Onigbagbọ a maa duro de Oluwa lati tọ ọ ni ọna ti o tọ. Onipsalmu wi pe, “Nigbana li oju kì yio ti mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo” (Orin Dafidi 119:6). Nigba ti eniyan ba gbọran si Ọrọ Ọlọrun, yoo gbe igbesi-aye rere ati ododo, kò tun ni tiju ohunkohun ninu igbesi-aye rè̩.

Ọlọrun ṣe ileri kan fun awọn eniyan Rè̩ -- awọn ti o duro de E – pe oju kì yoo ti wọn. A ṣe ileri yii fun awọn Ọmọ Israẹli ati gbogbo awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ tootọ. “Ẹnyin o si mọ pe, emi wà lārin Israeli, ati pe: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, kì iṣe ẹlomiràn: oju kì yio si ti awọn enia mi lai” (Joẹli 2:27). “Kiyesi i, emi o gbe ọwọ mi soke si awọn Keferi, emi o si gbe ọpágun mi soke si awọn enia . . . iwọ o si mọ pe emi li OLUWA; nitori oju kì yio tì awọn ti o ba duro dè mi” (Isaiah 49:22, 23). Wo o bi o ti yatọ pupọ fun awọn ti è̩ṣẹ wà ni igbesi-aye wọn! Wọn a maa gbiyanju lati bò è̩ṣẹ wọn mọlẹ. Wọn a maa yẹra kuro lọdọ awọn olododo nitori awọn è̩ṣẹ wọnnì. Wọn ni idalẹbi ati è̩rù lọkan wọn pe boya a o fi ẹṣẹ wọn han. Onigbagbọ a maa ni ẹri ọkàn ti o mọ, kò si ni ohun ti yoo mu ki oju ti i.

Itọsọna

Dafidi gbadura pe ki Ọlọrun kọ oun ki O si tọ oun ni ọna Oluwa. Dafidi mọ bi o ti ṣe ohun pataki to fun eniyan lati rin ni ọna Oluwa dipo ki o rin ni ọna ti ara rè̩. “Ọna kan wà ti o dabi ẹni pe o dara li oju enia, ṣugbọn opin rè̩ li ọna ikú” (Owe 14:12).

Kiki nipa titẹle Oluwa nikan ni eniyan le ni ireti lati lọ si Ọrun. Jesu wi pe, “Emi li ọna, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi” (Johannu 14:6). Woli Isaiah sọ nipa “Ọna iwa-mimọ” ninu eyi ti awọn ẹni-irapada yoo rin ati ninu eyi ti alaimọ ki yoo kọja (Isaiah 35:8, 9). A sọrọ ibukún ti yoo jẹ ti awọn ti o n rin ni ọna Oluwa (Orin Dafidi 128:1). Ibukun kan wà ni aye yii ati ni aye ti n bọ. Nipa wiwà ni oju ọna tooro ati hiha ni eniyan yoo ni iye-ainipẹkun (Matteu 7:14).

Aanu ati Otitọ

Dafidi gbadura pe ki Ọlọrun tọ oun, nitori pe o mọ pe ọna Oluwa n mu ni lọ si Ọrun. Nigba ti eniyan ba yàn ọna tirè̩, kòtò, ohun ikọsẹ, ikẹkùn, ati abuja ọna yoo wà, eyi ti yoo mu un lọ sinu iparun. Nigba ti eniyan ba tẹle ọna ti Oluwa, a o kilọ fun un niti ewu; yoo ni Oluwa fun iranlọwọ rè̩ nigba ti ọna kò ba tẹjú; Oluwa yoo “yọ” ẹsẹ rè̩ kuro ninu àwọn; ọna ti o hàn gbangba ni ọna ti o lọ si iye-ainipẹkun. “Bi o ṣe ti Ọlọrun ni, ọna rè̩ pé” (Orin Dafidi 18:30). Oluwa a maa ṣamọna awọn ti o n pa aṣẹ Rè̩ mọ nipa aanu ati otitọ. Eniyan ni lati ni irẹlẹ, ki o si jẹ ẹni ti o n fẹ itọni Ọlọrun. Oluwa ki i tọ alaiṣododo ati agberaga, nitori pe wọn kò fẹ ki Ọlọrun tọ wọn. N jẹ a le sọ bi ti Onipsalmu pe: “Emi ti yàn ọna otitọ: idajọ rẹ ni mo fi lelẹ niwaju mi” (Orin Dafidi 119:30)? Ẹ jẹ ki adura wa dàbi ti Dafidi. “Kọ mi li ọna rẹ, OLUWA, ki o si tọ mi li ọna titọ” (Orin Dafidi 27:11).

Idariji

Awọn olododo ti ri ibukún miiran gbà, eyi ni idariji awọn è̩ṣẹ wọn. A dariji wọn nitori pe wọn ronupiwada wọn si sọ pe ki Ọlọrun gba wọn la. Dafidi gbadura bayi pe: “Dari è̩ṣẹ mi ji mi . . . ki o si ṣanu fun mi; . . . ki o si dari gbogbo è̩ṣẹ mi ji mi.” Dafidi rán Ọlọrun leti aanu Rè̩ ati iṣeun-ifẹ Rè̩ ti o ni irọnu ti o si duro titi lae. Dafidi mọ pe kò si ẹni ti o yẹ lati ni alaafia Ọlọrun; a ti dari ẹṣẹ rè̩ ji i nitori pe Ọlọrun jẹ alaaanu. Kiki nipa inurere Ọlọrun ni a fi n sọ eniyan di olododo, ki i ṣe nipa ohun rere kan ti ẹnikẹni le ṣe.

Awọn alaiwabi-Ọlọrun kò ni ibukun imọ idariji è̩ṣẹ yii, nitori pe wọn kò ronupiwada ki wọn si beere fun aanu lọdọ Ọlọrun. Oluwa nikan ṣoṣo ni o le dari è̩ṣẹ ji. O le mu awọn è̩ṣẹ eniyan kuro ki O si pa oluwarè̩ mọ kuro ninu didá è̩ṣẹ. Dafidi gbadura pe: “Pa ọkàn mi mọ.” A ni lati ri igbala, ki a si duro ninu iriri igbala naa, bi a ba n fẹ ki a kà wa mọ awọn olododo.

Lẹyin imukuro è̩ṣẹ, ati pipa ara ẹni mọ kuro ninu è̩ṣẹ, Oluwa ki i tun ranti awọn è̩ṣẹ ti a ti dariji mọ. Oluwa wi pe, “Emi o dari aiṣedede wọn ji, emi ki o si ranti è̩ṣẹ wọn mọ” (Jeremiah 31:34; Heberu 8:12; 10:17).

È̩ṣẹ Igbà Ewe

Dafidi beere ni pataki pe ki Ọlọrun má ṣe ranti è̩ṣẹ igbà ewe oun. Dafidi mọ pe olukuluku ọmọde lẹyin ti o ba ti to ọjọ ori ti o le dahun fun iwa aye rè̩ -- nigba ti o mọ rere yatọ si buburu – ni o ti dẹṣẹ ti o si ni lati tọrọ idariji è̩ṣẹ. Dafidi kò ṣe awawi fun è̩ṣẹ rè̩ bi awọn ẹlomiran ti maa n ṣe. Dafidi kò wi pe ọdọ ni oun ati ọmọ kekere. Dafidi mọ pe awọn iwa aitọ igbà ewe oun jẹ è̩ṣẹ, o si beere pe ki Ọlọrun dari wọn ji.

Pé eniyan jẹ ọmọde tabi ọdọ kò gba ni láàyè lati dẹṣẹ. Ọlọrun yoo dariji awọn ọmọde bi wọn ba ronupiwada. Ọlọrun yoo mu è̩ṣẹ wọn kuro yoo si fun wọn ni agbara lati gbé igbesi-aye ailẹṣẹ.

Idajọ

Awọn alaiwabi-Ọlọrun yoo fẹ lati rò pe Ọlọrun kò gbọ nigba ti wọn ba n sọrọ buburu. Wọn a fẹ lati rò pe Ọlọrun kò ri wọn nigba ti wọn n dẹṣẹ. Ọlọrun ti o dá eti a maa gbọ. Ọlọrun ti o dá oju a maa riran. Ni akoko ti o tọ, a o mu ijiya wá sori alaiṣododo, Ọlọrun yoo si gbẹsan lara awọn ti o huwa ibi si awọn eniyan Rè̩.

Awọn alaiwa-bi-Ọlọrun n fi ibukun ti Ọlọrun n fi fun awọn eniyan Rè̩ du ara wọn. Ju gbogbo eyi lọ, ni ọjọ idajọ a o ranti è̩ṣẹ awọn alaiwa-bi-Ọlọrun; a o mú olukuluku è̩ṣẹ wá si imọlẹ a ki yoo si bò wọn mọlẹ. Dafidi mọ ohun ti yoo wa sori awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn itunu ati iranlọwọ Dafidi wà ninu Oluwa. Dafidi ti mọ Ọlọrun nipa iriri. Oluwa ti gba Dafidi lọwọ awọn ọta rè̩, O si ti gbe e ró nigba ti ẹsẹ rè̩ yọ. Dafidi ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun fun ọjọ ti n bọ, nitori pe o ti gbẹkẹ rè̩ le Ọlọrun. Dafidi ni, “OLUWA li àbo mi; Ọlọrun mi si li apata àbo mi.” Ki ni iwọ fi ṣe igbẹkẹle rẹ?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Bawo ni eniyan ṣe le gbe ọkàn rè̩ soke si Oluwa?

  2. 2 Ninu ta ni igbẹkẹle Dafidi wà?

  3. 3 Ta ni n gbe igbesi-aye itiju?

  4. 4 Ta ni Dafidi n fẹ ki o ṣe olutọ oun?

  5. 5 Nibo ni ọna Ọlọrun n mu ni lọ?

  6. 6 Ta ni Dafidi sọ pe ki o dari è̩ṣẹ oun ji?

  7. 7 Ta ni le dari è̩ṣẹ ji ni?

  8. 8 Ti ta ni ẹsan?

  9. 9 Ta ni aabo ati apata Dafidi?

  10. 10 Darukọ diẹ ninu awọn ibukún olododo.