II Samuẹli 24:1-25

Lesson 247 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bḝli emi kì yio fi eyiti emi kò nawo fun, rú ẹbọ sisun si OLUWA Ọlọrun mi” (II Samuẹli 24:24).
Notes

A Dan an Wo Lati Dẹṣẹ

Akoko kan de, ni igba aye Dafidi ti awọn Ọmọ Israẹli ni lati jiya fun è̩ṣẹ kan. “Satani si duro ti Israẹli, o si ti Dafidi lati ka iye Israẹli” (I Kronika 21:1). Dafidi fara fun idanwo yii. O paṣẹ pe ki a ka iye awọn Ọmọ Israẹli ki oun ba le mọ iye wọn. Lẹẹkan ri a ti ka awọn Ọmọ Israẹli, ṣugbọn Ọlọrun ni o paṣẹ bẹẹ nigba naa (Ẹksodu 30:11-14).

Dafidi kò sọ idi kan fun kikà ti o ni ki a ka awọn eniyan naa. A kò le sọ boya igberaga ni o mu ki Dafidi fẹ mọ iye awọn eniyan ti oun n ṣe akoso le lori. A kò mọ boya Dafidi n gbẹkẹle iye awọn eniyan ti o ni ju gbigbẹkẹle agbara Oluwa lati ja ogun. Ohunkohun ti o wu ki o wà ninu ọkàn Dafidi fun fifẹ ti o n fẹ mọ iye awọn Ọmọ Israẹli, è̩ṣẹ ni.

Ikilọ

A kilọ fun Dafidi pe ki o má ṣe ṣe nnkan yii. Dafidi paṣẹ naa fun Joabu olori ogun rè̩. Joabu gbiyanju lati rọ Dafidi pe ki o máṣe ka wọn, nitori pe kò si idi kan fun ṣiṣe bẹẹ. Joabu wi pe “Ẽṣe ti oluwa mi fi mbère nkan yi? ẽṣe ti on o fi mú Israẹli jẹbi?” Joabu gbiyanju lati dá Dafidi lẹkun ṣiwaju didá è̩ṣẹ yii gẹgẹ bi Ẹmi Ọlọrun ti i maa jẹ olóòótọ lati kilọ fun wa, ati gẹgẹ bi ẹri-ọkàn eniyan ti i maa jẹ ki eniyan mọ ohun ti kò tọ.

Dafidi kò gbọran si ikilọ awọn ọrẹ rè̩ olóòótọ, Joabu ati awọn olori ogun. Dafidi ran awọn eniyan wọnyi lati ka iye awọn Ọmọ Israẹli. Wọn la gbogbo Israẹli ja (I Kronika 21:4). Wọn rekọja odo Jọrdani lọ si ilẹ ti Reubẹni ati Gadi duro si (Numeri 32:1-5). Wọn rin irin-ajo lọ si ariwa titi de eti okun Dan-jaani, Sidoni, ati Tire -- lẹyin eyi wọn lọ si guusu si Beerṣeba ati Juda, wọn si n ka awọn eniyan naa bi wọn ti n lọ.

Kò si Inudidùn

O le ni oṣu mẹsan ti awọn eniyan Dafidi fi wà lẹnu kika awọn eniyan naa. Iṣẹ naa kò layọ ninu, nitori pe wọn mọ pe kò tọ. Nikẹyin Joabu mu iye ti awọn eniyan naa jẹ wa fun Dafidi. A kò sọ fun wa pe inu Dafidi dùn, tabi pe o ni itẹlọrun, tabi pe iye awọn eniyan naa pọ to iye ti o n fi ọkàn si tẹlẹ.

Lai si aniani idalẹbi ti o wà ninu ọkàn Dafidi ti mu gbogbo inudidùn ti i ba ni kuro. Nigba ti eniyan ba pinnu lati ṣe ohun kan, ti o n fẹ ọna ti rè̩ ti o si n fi orikunkun kọ lati gba ikilọ, nigba miiran Ọlọrun a gba a làye lati mu ifẹ ọkàn rè̩ ṣẹ. S̩ugbọn ki i ṣe e ṣe fun iru ẹni bẹẹ lati ni inudidun ati itẹlọrun ti o ti n reti nipa ṣiṣe nnkan naa.

È̩ṣẹ ati Ironupiwada

Dafidi mọ pe oun ti dẹṣẹ. Ọkàn rè̩ da a lẹbi. Dafidi gbadura o si jẹwọ è̩ṣẹ rè̩. Dafidi sọ fun Oluwa pe: “Emi ṣè̩ gidigidi li eyi ti emi ṣe: ṣugbọn emi bè̩ ọ, OLUWA, fi è̩ṣẹ iranṣẹ rẹ ji i, nitori pe emi huwà aṣiwere gidigidi.” Dafidi ṣe ohun ti o tọ nipa titọ Ọlọrun lọ fun idariji. Bi eniyan ba fara fun idanwo Satani, ti o si dẹṣẹ, yoo padanu ibukun Ọlọrun. Nipa ironupiwada nikan ṣoṣo ni o le fi pada sinu ojurere pẹlu Ọlọrun. Nipa jijẹwọ ati kikọ è̩ṣẹ rè̩ silẹ, ati bibeere fun idariji ni o le ri idariji gbà lọdọ Ọlọrun. Ohun ti o dara ni lati wá Ọlọrun lẹsẹkẹsẹ dipo ki a sún ọjọ adura siwaju

Ijiya

Ni owurọ, ni idahun si adura Dafidi, Oluwa ran Gadi Woli si Dafidi. Ọrọ Oluwa niyii: “Emi fi nkan mẹta lọ ọ; yàn ọkan ninu wọn, emi o si ṣe e si ọ.” Ki i ṣe ohun ti i maa ṣẹlẹ pe ki a fun eniyan ni aye lati yàn ijiya, ṣugbọn Ọlọrun ṣe eyi nì fun Dafidi. Kò si ọna ti o rọrun ninu yiyan yii. Dafidi ti dẹṣẹ o si ni lati jiya bi o tilẹ jẹ pe o ti beere fun idariji.

A fun Dafidi laye lati yàn ninu ìyàn ọdun meje, ki o maa sa ni oṣu mẹta niwaju awọn ọta rè̩, tabi arun iparun ni ọjọ mẹta. Eyikeyi ninu awọn ijiya mẹta yii yoo mu ki iye awọn Ọmọ Israẹli din kù, ati ni opin Dafidi ki yoo le mọ iye awọn Ọmọ Israẹli mọ. Nipa è̩ṣẹ ọkunrin kan yii gbogbo awọn Ọmọ Israẹli yoo jiya.

Bi Dafidi ba yàn ìyàn ọdún meje dajudaju yoo bọ ninu rè̩, nitori pe o jẹ ọlọrọ, awọn eniyan naa i ba si rọgba yi ọba wọn ka lati ran an lọwọ. Bi o ba ṣe pe oṣu mẹta ogun jijà ni Dafidi yàn kò si idaniloju pe a o gba a laye lati lọ si ogun nitori pe awọn Ọmọ Israẹli ti sọ fun Dafidi pe: “Iwọ ki yio si tun ba wa jade lọ si ibi ija mọ, ki iwọ ki o máṣe pa iná Israẹli” (II Samuẹli 21:17). Ninu ọkan ninu awọn meji yii a ba dá ẹmi Dafidi si, ṣugbọn ọpọlọpọ ninu awọn eniyan naa ni i ba kú.

Ọlọrun Olododo

Dafidi yan eyi ti o tọ nigba ti o wi pe: “Jẹ ki a fi ara wa le OLUWA li ọwọ; nitoripe ānu rè̩ pọ: ki o má si ṣe fi mi le enia li ọwọ.” Dafidi mọ pe ọna Oluwa jẹ ododo ati otitọ (Ifihan 15:3). Nipa yiyàn ajakalẹ-arun, Dafidi yoo wà ninu ewu ikú pẹlu awọn Ọmọ Israẹli. Dafidi yàn lati fi ara rè̩ le Oluwa lọwọ, bi Ọlọrun ba si ri i pe o tọ ki o ri bẹẹ, ajakalẹ-arun naa yoo pa Dafidi.

Idajọ Ọlọrun yara kankan. O ti gba Joabu ati awọn iyoku rè̩ ni eyi ti o ju oṣu mẹsan lọ lati la ilẹ naa ja lati ka iye awọn eniyan naa, ṣugbọn laaarin wakati diẹ ajakalẹ-arun naa ti gba gbogbo ilẹ naa kan lati Dani titi de Beer-ṣeba – lati ariwa titi de guusu Kenaani. Ajakalẹ-arun naa bẹrẹ ni owurọ ọjọ naa, ọkẹ mẹta abọ (70,000) ninu awọn Ọmọ Israẹli ni o si kú, jakejado gbogbo ilẹ naa a fi kiki ni Jerusalẹmu. Ọlọrun da Dafidi ati gbogbo awọn agba Israẹli si (I Kronika 21:16).

Dafidi mọ pe nitori pe oun dẹṣẹ ni gbogbo awọn Ọmọ Israẹli wọnyi ṣe kú. Dafidi kún fun ibanujẹ, o si jiya lọpọlọpọ. Bayi ni o wi fun Oluwa: “Emi ti ṣè̩, emi si ti huwà buburu: ṣugbọn awọn agutan wọnyi, kini nwọn ha ṣe? jẹ ki ọwọ rẹ, emi bẹ ọ, ki o wà li ara mi.”

Pẹpẹ Kan

Gadi Woli sọ fun Dafidi pe ki o té̩ pẹpẹ kan fun Ọlọrun ni ilẹ-ipaka Arauna, ara Jebusi. Dafidi gbọran. O tọ Arauna lọ lati ra ilẹ-ipaka naa lati té̩ pẹpẹ naa fun Ọlọrun. Arauna fẹ lati fun ọba ni awọn nnkan yii. Arauna n fẹ lati fi awọn nnkan irubọ naa ati igi fun ẹbọ naa lelẹ pẹlu ilẹ naa lai gba ohunkohun. O fẹ fi wọn fun ọba.

Iye Rè̩ ni Kikún

Dafidi ra ilẹ-ipaka naa ati malu. O ni oun ki yoo fi eyi ti oun kò nawo fun rú ẹbọ sisun si Ọlọrun. Dafidi san iye owo rè̩ ni kikún. Wò o bi awọn ẹlomiran ti i maa ṣe loni. Wọn n fẹ lati ri ibukún Ọlọrun gba ṣugbọn wọn kò fẹ fi ohun ti o nilaari kan lelẹ fun Oluwa fun iye-ainipẹkun. Ikú ẹmi n duro de olukuluku ẹni ti o kọ lati ṣe irubọ ti o tọ fun Ọlọrun -- ẹbọ irobinujẹ ati irora aya (Orin Dafidi 51:17). Ọpọlọpọ eniyan loni ni kò fẹ lati san “iye ti o tọ ni ẹkunrẹrẹ” (I Kronika 21:24). Wọn kò fẹ fi ohun ti o ṣọwọn fun ọkàn wọn fun Ọlọrun. Wọn kò fẹ fi ohun ti o ná wọn ni iye kan fun Ọlọrun. Ibukún Ọlọrun jẹ ti awọn ti o fẹ lati kọ è̩ṣẹ wọn silẹ ki wọn si fun Ọlọrun ni eyi ti o dara ju lọ -- ti i ṣe aye wa, akoko wa, ati talẹnti wa.

Ọlọrun tẹwọ gba ẹbọ Dafidi; a dariji Dafidi; ajakalẹ-arun naa kò si pa awọn eniyan naa mọ. Ọlọrun yoo tẹwọ gba ẹbọ wa yoo si dahun adura wa bi a ba ṣe bi ti Dafidi, bi a ba sọ fun Un pe a o san iye rè̩ ni kikún, pe a ki yoo fi ohun ti i ṣe ti ẹlomiran ṣe irubọ, pe a ki yoo fi ohun ti kò ná wa ni ohunkohun rubọ si I. Eniyan kò le ba Ọlọrun dúna-durà. Ko si didin owo ọja tabi dúna-durà pẹlu Oluwa. Ihinrere Jesu Kristi Oluwa niyelori to lati gba gbogbo ifararubọ ti a ni lati ṣe ati gbogbo ipa ti a le sà. Anfaani ti a n ri gba tayọ gbogbo ipa ti a le sà lọ. (Ka Marku 10:28-30).

Ni Ibi Kan Naa

Ni ọpọlọpọ ọdun ṣiwaju eyi, Ọlọrun ti sọ fun Abrahamu pe ki o fi ọmọ rè̩, Isaaki, ru ẹbọ sisun (Gẹnẹsisi 22:1, 2). Gẹgẹ bi aṣẹ, wọn lọ si Moria, ilẹ kan naa nibi ti Dafidi ti ṣe irubọ nisisiyi ni ilẹ-ipaka Arauna. A ranti pé Ọlọrun pe Abrahamu bi o ti n fẹ pari irubọ naa. Ohun gbogbo ti wa leto o si ti ṣetan. Abrahamu ti tẹle aṣẹ Oluwa o si ti mura tan lati fi ọmọ rè̩ rubọ. Abrahamu n fẹ lati ṣe ohun ti Ọlọrun beere, Abrahamu ti gbọran si aṣẹ Ọlọrun ninu ọkàn rè̩. Ni tootọ Oluwa “tikalarè̩ ti pese ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun.” Agbo kan ti fi ori ha pantiri. Abrahamu si fi agbo naa “rubọ sisun ni ipò ọmọ rè̩” (Gẹnẹsisi 22:13).

Nigba kan lẹyin eyi, ni akoko ijọba Sọlomọni ọmọ Dafidi, ni ori ilẹ yii kan naa ni a kọ ile Oluwa si (II Kronika 3:1). Awọn iṣẹlẹ mẹta yii ni o ṣẹlẹ lori oke Moria.

Awọn Iriri ti Ẹmi

Awọn iṣẹlẹ mẹta wọnyi dabi iriri ti ẹmi ti eniyan le ri gbà. Ẹbọ Abrahamu lori oke Moria dabi igbala. Gẹgẹ bi o ti jé̩ pẹpẹ kin-in-ni ti a tẹ sibẹ, bẹẹ gẹgẹ ni igbala jẹ iṣisẹ kin-in-ni ninu awọn iriri mẹta ti Ẹmi. Ayé awa tikara wa kò le ṣetutu fun è̩ṣẹ wa. A ni lati gba Ẹbọ Ọlọrun, ani Ẹni Alailẹṣẹ naa ti o mura tan lati fi ara Rè̩ rọpo fun wa. Ọlọrun ti pese Ẹbọ kan -- Ọmọ Oun tikara Rẹ, Ẹjẹ Ẹni ti a ta silẹ ki a ba le ri idariji è̩ṣẹ wa gbà.

Pẹpẹ ti Dafidi tẹ ni ori Oke Moria dabi isọdimimọ, iṣẹ oore-ọfẹ keji. Iriri yii ni a maa n ni lẹyin igbala, nipasẹ iriri yii ni a fi n wẹ igbesi-aye eniyan mọ kuro ninu è̩ṣẹ abinibi. Iṣẹlẹ kẹta lori Oke Moria ni igba iyasimimọ Tẹmpili jẹ apẹẹrẹ ifi Ẹmi Mimọ wọni eyi ti a maa n ri gba lẹyin ti eniyan ba ti ri igbala ati isọdimimọ gbà. Nigba ti a ya Tẹmpili si mimọ fun Oluwa, a ṣe ẹbọ sisun ati irubọ pẹlu adura Sọlomọni (II Kronika 7:5). Ọlọrun dahun, ina lati Ọrun wa si jo ẹbọ sisun naa (II Kronika 7:1). Ifarahan Oluwa kún inu ile naa to bẹẹ ti awọn alufaa kò le ṣe iṣẹ-isin wọn.

Bi a ti n kọ ẹkọ Bibeli, a ri i pe a kọ ni lẹkọ nipa awọn iriri wọnyi ninu Majẹmu Titun a si ṣe apẹẹrẹ wọn ninu Majẹmu Laelae. A ki i ri wọn gba lẹsẹ kan naa. S̩ugbọn wọn jẹ iriri mẹta ọtọọtọ, gẹgẹ bi iṣẹlẹ mẹta ọtọọtọ wọnyi ninu Bibeli. Ọlọrun a maa fi wọn fun ni nigba ti eniyan ba n gbadura ti o si n ṣe ifararubọ igbesi-aye rè̩ fun Ọlọrun ti o si n ṣe irubọ si Oluwa. N jẹ o ti ri gbogbo awọn iriri mẹta ti Ẹmi wọnyi gba?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Bawo ni Dafidi ti ṣe mọ pe oun ti dẹṣẹ?

  2. 2 Ninu ohun mẹta wo ni a ni ki Dafidi yàn ijiya rè̩?

  3. 3 Ki ni ṣe ti Dafidi yàn ajakalẹ-arun?

  4. 4 Ki ni ṣe ti Dafidi yàn lati ṣubu si ọwọ Ọlọrun?

  5. 5 Melo ni awọn ti o kú ninu awọn Ọmọ Israẹli?

  6. 6 Awọn wo ni a da si?

  7. 7 Ki ni Dafidi n beere ilẹ-ipaka Arauna fún?

  8. 8 Ọna wo ni Dafidi gbà lati ni ilẹ-ipaka naa?

  9. 9 Ki ni ṣe ti Dafidi san iye owo rè̩?

  10. 10 Darukọ awọn iṣẹlẹ meji miiran ti o tun ṣẹlẹ nibẹ.