Orin Dafidi 72:1-19

Lesson 248 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “On o da talaka ati alaini si, yio si gbà ọkàn awọn alaini là” (Orin Dafidi 72:13).
Notes

Alaafia Eso Iwa Ododo

Dafidi ti ṣe akoso Israẹli daradara fun ọdun pupọ. Nisisiyi o ti di arugbo, ọmọ rè̩ ni yoo si gba ipo rè̩ lori itẹ. Ninu gbogbo ọdun wọnyi Dafidi ti fi hàn pe lati ọdọ Ọlọrun ni ipa ati agbara oun ti n wá, o si n fẹ ki ọmọ rè̩ jẹ anfaani ibukún kan naa ti oun ti ni. Nitori naa o gbadura pe, “Ọlọrun, fi idajọ rẹ fun ọba, ati ododo rẹ fun ọmọ ọba.”

Dafidi fẹ alaafia fun awọn Ọmọ Israẹli eniyan rè̩, o si mọ pe nipa ododo nikan ni a fi n ni alaafia. Woli Isaiah kọwe bayi: “Iṣẹ ododo yio si jẹ alafia, ati eso ododo yio jẹ idakẹjẹ on ābo titi lai” (Isaiah 32:17).

Ọlọrun ti ṣeleri fun Dafidi pe ẹni kan lati inu idile rè̩ yoo wa lori itẹ Israẹli titi lae. Dafidi ni oye, nipa Ẹmi ti o mi si i, wi pe ki i ṣe Sọlomọni ọmọ oun, tabi Rehoboamu ọmọ-ọmọ oun ni ẹni naa. Nipa igbagbọ o le fi oju si Igba Wura nigba ti Jesu tikara Rè̩ yoo wa sinu aye yii ti yoo si ṣe akoso ni ododo, ti alaafia yoo si wa ninu aye ati ifẹ inurere si gbogbo eniyan.

Dafidi sọ ninu awọn akọsilẹ rè̩ kan nipa akoko ti Jesu yoo wá gẹgẹ bi Ẹbọ fun è̩ṣẹ. Akoko wiwá Rè̩ lẹẹkinni ni eyi yoo jẹ, nigba ti Oun yoo maa gbe pẹlu irè̩lè̩ laaarin awọn eniyan, ti wọn o si korira Rè̩, ti wọn o bu U, nikẹyin ti wọn o si kan An mọ agbelebu. S̩ugbọn ninu ori kejilelaadọrin Psalmu yii Dafidi n sọ nipa bibọ Rè̩ lẹẹkeji, nigba ti Jesu yoo wa pẹlu awọn eniyan Rè̩ mimọ lati gbé ijọba ti Rẹ kalẹ ninu aye yii. Ohun ti o bẹrẹ gẹgẹ bi adura fun ọmọ rè̩ wa di asọtẹlẹ ologo nipa Igba Ijọba Ẹgbẹrun (1,000) Ọdun.

Ipoungbẹ fun Alaafia

Bẹrẹ lati akoko ti awọn Ọmọ Israẹli ti wà ni Egipti ti wọn si ti jiya labẹ paṣan akoniṣiṣẹ, wọn ti n poungbẹ ọjọ ti gbogbo ìṣé̩ wọn yoo pari, ti olukuluku yoo wa ni alaafia ati irọrun, ti kò si ni si ẹni ti yoo pa wọn lara tabi ti yoo ja ohun ini wọn gbà.

Iru igbesi-aye bayi ni Ọlọrun ti ṣeleri fun wọn bi wọn o ba gbọran si aṣẹ Rè̩. “Ibukún ni fun ọ ni ilu, ibukún ni fun ọ li oko.” “OLUWA yio mu awọn ọtá rẹ ti o dide si ọ di ẹni ikọlu niwaju rẹ.” “OLUWA yio paṣẹ ibukún sori rẹ ninu aká rẹ, ati ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ rẹ lé” (Deuteronomi 28:3, 7, 8). Gbogbo nnkan wọnyi ni i ba tan oungbẹ ti o wa ni ọkàn wọn bi o ba jẹ pe wọn ti gba ohun Ọlọrun gbọ, ṣugbọn wọn ti sọ anfaani yii nu nitori è̩ṣẹ wọn. Bi a ti n sọrọ yii ọkẹ aimoye awọn Ju ni o wa ninu ipọnju lọwọlọwọ bayii, idajọ ti o si wuwo ju bẹẹ lọ ni o n duro de wọn ki wọn to le kigbe pe Messia wọn, ki a si to le ko wọn jọ fun alaafia ẹgbẹrun (1,000) ọdun ninu aye yii.

Lati ọjọ iwà ni awọn ti a n pọn loju ti n kerora ninu ọkàn wọn fun igbesi-aye ti o san ju bẹẹ lọ. Lati igba de igba ni a n ri awọn eniyan diẹ ti wọn jẹ ọlọrọ pupọ, ti a si n ri awọn ogunlọgọ gẹgẹ bi talaka -- awọn talaka ni iya si n jẹ pupọ ju. Lati ọdọ awọn eniyan dudu ti a ko lọ ṣe ẹru ni Amẹrika, ti wọn si ti jiya lọwọ awọn oluwa onroro, ni a ti kọ pupọ ninu awọn orin ti a n kọ ti a si n gbadun lode oni. Wọn kigbe pe Oluwa pe ki O ran wọn lọwọ. “Jare wa, kẹkẹ idande, ko gbe mi re ‘le”, “Ko S’ẹni Mọ ’Hun T’oju Mi Nri” “A ko ni kọ Ogun Jija mọ,” jẹ gbigbin fun idasilẹ, wọn si n sọ nipa ireti akoko ti yoo san ju bẹẹ lọ.

Awọn orilẹ-ède ati awọn ẹgbẹ oṣelu ti gbiyanju lati wa ọna ti yoo fi ṣe e ṣe fun olukuluku eniyan lati ni gbogbo nnkan ti wọn n fẹ, ṣugbọn wọn kò beere lọwọ Ọlọrun ọna ti o yẹ ki wọn gbà. Awọn Ẹgbẹ Ani-ohun-gbogbo-ṣọkan ati awọn Ẹgbẹ Alafọwọ-so-wọ-pọ, ati ọpọlọpọ awọn ẹgbẹ miiran wà ti wọn n sọ pe o yẹ ki gbogbo eniyan ni ohun gbogbo ṣọkan; ṣugbọn pupọ ninu awọn olootu wọn jẹ ọlọkan buburu ti o jẹ wi pe ọrọ ati ipo ni wọn n lepa fun ara wọn. Labẹ ijọba wọn n ṣe ni awọn akuṣẹ tubọ n kuṣẹ si i ti ipọnju wọn si n ju bẹẹ lọ. Ni awọn orilẹ-ède miiran ọgọọrọ awọn talaka ilu kò ni ireti mọ fun ayé ti o san ju bẹẹ lọ.

Ọjọ Ọlọrun

S̩ugbọn ọjọ Ọlọrun n bọ. Awọn eniyan Rè̩ yoo gbadun ogún iyebiye ninu ayé yii kan naa. A maa n sọ pe a fẹ wà ni imurasilẹ lati ba Jesu gbe ni Ọrun; ṣugbọn bẹẹ ni a o wà ninu aye yii fun ẹgbẹrun (1,000) ọdun nigba ti Jesu yoo fi aanu ṣe akoso, awọn eniyan Rè̩ mimọ yoo si ba A jọba.

Majẹmu Laelae sọ pupọ nipa Igba Wura ninu aye yii ju nipa Ọrun lọ. Awọn woli sọ asọtẹlẹ rè̩, awọn Ọmọ Israẹli si poungbẹ fun ọjọ ti a o fi idà rọ ọbẹ-plau ti a o si fi ọkọ rọ dojé, ti awọn eniyan kò si ni kọ ogun jija mọ. O ti sú wọn lati maa fi igba gbogbo jà gẹgẹ bi o ti sú ọpọlọpọ loni. Wọn n ṣafẹri “alafia ni akoko wa” ki wọn ba le fi ọkàn balẹ tọ awọn ọmọ wọn dagba. Wọn kò ni inu didun lati maa ro wi pe gẹrẹ ti awọn ọdọmọkunrin wọn ba ti di géndé, wọn ni lati lọ soju ogun, boya ki wọn si kú ni kekere nitori ti orilẹ-ède wọn. Wọn fẹ lati maa gbe inu-ile ti wọn ti o ni ọgbà ati ayè fun awọn ọmọ wọn lati maa ṣire. Wọn ni ireti pé ọjọ kan n bọ nigba ti olukuluku eniyan yoo ni ounjẹ tó lati jẹ ati aṣọ lati wọ, ti ki yoo si talaka mọ.

Ni tootọ iru igba yii n bọ, gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ni yoo si gbadun rè̩. Awọn ẹranko buburu paapaa kò tilẹ ni pa wọn lara. “Ikõko pẹlu yio ma ba ọdọ-agutan gbe pọ, kiniun yio si dubulẹ pẹlu ọmọ ewurẹ; ati ọmọ malụ ati ọmọ kiniun ati ẹgbọrọ ẹran abọpa yio ma gbe pọ; ọmọ kekere yio si ma dà wọn” (Isaiah 11:6).

Awọn Ju, ti i ṣe iru-ọmọ awọn Ọmọ Israẹli ni a o mu pada wa si Ilẹ Mimọ, wọn o si maa gbe nibẹ ni alaafia. Awọn arugbo yoo lo ọjọ wọn pé, ọpọlọpọ ọmọde ni yoo si maa yọ ti wọn ko si ni mọ nnkankan nipa ogun ati wahala. Nipa akoko yii ni Woli Sẹkariah sọ nigba ti o wi pe: “Arugbo ọkunrin, ati arugbo obirin yio sa gbe igboro Jerusalemu ati olukuluku ti on ti ọpa li ọwọ rè̩ fun ogbó. Igboro ilu yio si kún fun ọmọdekunrin, ati ọmọdebirin, ti nṣire ni ita wọn” (Sẹkariah 8:4, 5).

Akoko yii ni Dafidi fi oju igbagbọ ri nigba ti o gbadura fun ọmọ rè̩. O sọ nipa Jesu nigba ti o wi pe: “On o ma fi ododo ṣe idajọ awọn enia rẹ, yio si ma fi ẹtọ ṣe idajọ awọn talaka rẹ.” Dajudaju, o nireti pe ọmọ oun naa yoo jẹ onidajọ rere ati olóòótọ.

Lati Okun de Okun

Ọba ti Dafidi sọ nipa rè̩ yoo jọba “lati okun de okun, ati lati odò ni de opin aiye.” Ni akoko ti wọn, wọn kò loye pupọ nipa bi ilẹ aye ti fè̩ to. Okun Mẹditerranean ni wọn n pè ni Okun Nla; ibugbe wọn kò si jinna si Okú Okun oniyọ. Awọn baba-nla wọn ti la Okun Pupa kọja. Gbogbo agbajọ omi ti wọn mọ kò ju iwọnyi lọ. Wọn wà ninu ohun ti Ọlọrun ti ṣeleri fun Abrahamu, Sọlomọni yoo si jọba lori gbogbo agbegbe yii. S̩ugbọn Dafidi wa sọ siwaju wi pe, “Lati odo nì (eyini ni Odo Euferate) de opin aiye.” Eyi pọ ju ohun ti o ti wà lọkàn awọn Ọmọ Israẹli tẹlẹ. Dajudaju Ọba ti o ju Sọlomọni lọ ni yoo ṣakoso lori ijọba ti o pọ to bayi.

Ọba awọn Ọba

Ọba yii ni gbogbo awọn ọba aye yoo wolẹ fun. Iwọ ro o wò! Gbogbo awọn alakoso ati alaṣẹ ode-oni ti wọn si ni agbara ti o rinlẹ lori ọpọlọpọ eniyan (boya lori ọkẹ aimoye enia) ni yoo wolẹ niwaju Ọba nla yii nigba ti O ba de lati jọba ni aye yii. Satani paapaa, tabi ẹnikẹni miiran kò ni le duro niwaju Rè̩. “Awọn ọta rè̩ yio si lá erupẹ ilẹ.”

Ki i ṣe pe awọn ọba aye yoo tẹriba niwaju Rè̩ nikan: wọn o mu ọrẹ fun Un wa lati gbogbo opin ilẹ aye. Gbogbo orilẹ-ède ni yoo sin Kabiyesi yii.

Oun yoo ha gberaga ninu ipo giga Rè̩? Yoo ha jẹ iba awọn olokiki inu aye ni yoo jẹ ọrẹ Rè̩? Jesu funra Rè̩ ni O ti wi pe: “Ọré̩ mi li ẹnyin iṣe, bi ẹ ba ṣe ohun ti emi palaṣẹ fun nyin” (Johannu 15:14). Gbogbo awa ti n gbọ ti Rẹ ni ọrọ yii wa fun. Ronu bi o ti jẹ pe awa le jẹ ọré̩ Ọba nla yii ẹni ti yoo fi ẹnu awọn ọba alaiwa-bi-Ọlọrun gbolẹ!

Jesu wi pe awọn ọlọkan tutu ni yoo jogun aye. “Yio gbà alaini nigbati o ba nke: talaka pẹlu, ati ẹniti kò li oluranlọwọ.”

Paulu Apọsteli kọwe pe Onigbagbọ tootọ jẹ ajumọjogun ohun gbogbo pẹlu Kristi. Ọlọrun sọ fun Ọmọ bayi, “Ité̩ rẹ, Ọlorun, lai ati lailai ni; ọpá alade ododo li ọpá alade ijọba rẹ” (Heberu 1:8). Awa Onigbagbọ atunbi si jẹ ọmọ Ọlọrun, “Bi awa ba si jẹ ọmọ, njẹ ajogun li awa; ajogun Ọlọrun, ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi; biobaṣepe awa bá a jiya, ki a si le ṣe wa logo pẹlu rè̩” (Romu 8:16, 17).

Iṣẹgun lori Iya

O ni iye igba ti aarè̩ mu Dafidi nitori awọn ọta ti o doju ija kọ ọ. O gbadura pe, “Emi o ti ma gbimọ li ọkàn mi pẹ to? ti emi o ma ni ibinujẹ li ọkàn mi lojojumọ? Ọta mi yio ti gberaga sori mi pẹ to?” (Orin Dafidi 13:2). S̩ugbọn igbagbọ rè̩ a tun sọji, oun a si kọrin pe, “S̩ugbọn emi o gbẹkẹle ānu rẹ; ọkàn mi yio yọ ni igbala rẹ” (Orin Dafidi 13:5). O fohun ṣọkan pẹlu Paulu, ẹni ti o wi pe, “Mo ṣiro rè̩ pe, iya igba isisiyi kò yẹ lati fi ṣe akawe ogo ti a o fihàn ninu wa” (Romu 8:18). “Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba” (II Timoteu 2:12).

Aye Atijọ ati Aye Titun

Nigba ti Johannu Apọsteli wà ni Erekuṣu Patmo, angẹli nì sọ fun un pe, “Olubukun ati mimọ ni ẹniti o ni ipa ninu ajinde ekini na: lori awọn wọnyi ikú ekeji kò li agbara, ṣugbọn nwọn o jẹ alufa Ọlọrun ati ti Kristi, nwọn o si mā jọba pẹlu rè̩ li ẹgbè̩run ọdun” (Ifihan 20:6). Lori aye yii ni eyi yoo jẹ, nigba ti a ba ti mu ègun kuro ti Jesu ba si de lati jẹ Ọba gbogbo agbaye. Angẹli naa tun wa sọ pe, “Nwọn o si mā jọba lai ati lailai” (Ifihan 22:5). Ki i ṣe iba ẹgbẹrun (1,000) ọdun ninu aye ogbologbo yii, ṣugbọn lae ati laelae ninu ayé titun.

Nigba ti Dafidi ṣiro gbogbo nnkan ologo wọnyi ti Ẹmi fi han an, kò le ṣe ju pe ki o maa yin Oluwa. “Orukọ rè̩ yio wà titi lai: orukọ rè̩ yio ma gbilẹ niwọn bi õrun yio ti pẹ to: nwọn o si ma bukún u fun ara wọn nipasẹ rè̩: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma pè e li alabukúnfun . . . ki gbogbo aiye ki o si kún fun ogo rè̩.” Eyi ni yoo jẹ imuṣẹ gbogbo ireti ati ifẹ ti o tobi ju lọ lọkàn Dafidi. Adura ti o gbà ti tó. “Adura Dafidi ọmọ Jesse pari.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ta ni ọmọ Dafidi?

  2. 2 Ki ni ṣe ti Dafidi gbadura fún un?

  3. 3 Ki ni adura Dafidi wa jasi gan an?

  4. 4 Nipa ki ni Dafidi n sọ ninu Psalmu yii?

  5. 5 Ta ni yoo jẹ Alakoso ninu ijọba ti o n sọ yii?

  6. 6 Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ọba aye ni akoko naa?

  7. 7 Bawo ni ijọba Rè̩ yoo ti pẹ to ninu aye?

  8. 8 Awọn wo ni yoo jẹ ọrẹ Ọba titun naa?

  9. 9 Bawo ni Ijọba Rè̩ yoo ti fè̩ tó?

  10. 10 Bawo ni ijọba inu aye titun naa yoo ti gùn tó?