Lesson 249 - Senior
Memory Verse
“Egbé ni fun aiye nitori ohun ikọsè̩! ohun ikọsè̩ ko le ṣe ki o ma de; ṣugbọn egbé ni fun oluwarè̩ na nipasẹ ẹniti ohun ikọsè̩ na ti wá!” (Matteu 18:7).Cross References
I Ọkunrin naa, Judasi Iskariọtu
1 A yàn án lati jẹ ọkan ninu awọn ọmọ-ẹyin mejila ati lati jẹ Apọsteli pẹlu, Matteu 10:1-5; 26:14; Marku 3:13-19; Luku 6:13-16; Iṣe Awọn Apọsteli 1:17, 25
2 O kùnà lati maa rin ni ọna ododo, o di oloju-kokoro ati ole pẹlu, laisi aniani, o ni ero ilepa ti ara nipa ijọba Kristi laye, Johannu 12:4-6
II Ifihan Jesu ati awọn Ohun ti o S̩iwaju Rè̩
1 Awọn woli Majẹmu Laelae sọ nipa iwa ti Judasi hù, Orin Dafidi 109:8; Iṣe Awọn Apọsteli 1:16, 17; Sekariah 11:12, 13
2 Jesu sọ asọtẹlẹ nipa iṣe Judasi, O pe e ni eṣu ati ọmọ ègbé, Johannu 6:70, 71; 13:18-30; 17:12
3 Sibẹsibẹ Judasi ṣe ohun ti o ti pinnu lati ṣe, Matteu 26:1-5, 14-16; Marku 14:10, 11; Luku 22:3, 6; Sekariah 11:12, 13
4 Judasi yàn ọna ara rè̩ lẹyin naa Satani si wọ inu rè̩, Luku 22:3; Johannu 13:2, 27
5 Gẹgẹ bi ọmọ egbé -- ki i tun ṣe ọmọ Ọlọrun mọ -- o rọrun fun un lati fi Ọmọ Ọlọrun hàn pẹlu ifẹnukonu, Marku 14:43-45; Luku 22:47, 48; Johannu 18:2-5
III Igbẹyin Kikoro Judasi
1 Nigba kin-in-ni ti Judasi ri gbogbo eso iṣẹ rè̩, abamọ gba ọkàn rè̩ kan, ṣugbọn kò ni ironupiwada ẹni iwa-bi-Ọlọrun, Matteu 27:3-5; Sekariah 11:12, 13; Orin Dafidi 94:20-23
2 O pa ara rè̩, Matteu 27:5; Iṣe Awọn Apọsteli 1:18, 19
3 Owo ti o gbà ti o si da pada ni a fi ra ilẹ amọkoko, Matteu 27:6-10; Sekariah 11:13
Notes
ALAYÉApẹẹrẹ Iwa Buburu
Ninu gbogbo iwa itiju ati iwa ọdalẹ ti a ṣe akọsilẹ rẹ fun wa ninu Iwe Mimọ ati ninu awọn iwe itan, kò si eyi ti o le buru kọja ti Judasi Iskariọtu. Orukọ rè̩ yoo wà ninu ẹgbẹ buburu yìí laelae, nitori ti o huwa ọdalẹ ati alailaanu ti o buru ju lọ laye yìí. O ṣe iranwọ o si mu ki o ṣe e ṣe fun awọn ọta ododo lati ki Ọmọ Ọlọrun mọlẹ nipasẹ ifẹnukonu ẹtàn ati agabagebe ti a n pe lọjọ oni ni “ifẹnukonu Judasi.” Awọn alaiwa-bi-Ọlọrun paapaa a maa tọka si iwa ti o hu yìí pẹlu è̩gan ati iyọṣuti si. Ohun ti o si tubọ mu ki iwa rè̩ yìí buru jai ni pe, ọgbẹni yìí ti jẹ ọkan ri ninu awọn ọmọ-ẹyin ati Apọsteli ti Ọmọ Ọlọrun yàn!
Iwe Mimọ kò sọ fun ni pato igbà ati ibi ti Judasi gbe gba adura agbayọri ti o si ri idariji è̩ṣẹ gbà eyi ti ọkunrin, obinrin ati ọmọde ni lati ri gba ki wọn to le ri Ọrun wọ. S̩ugbọn o dani loju gbangba pe kò ṣalai ṣe alabapin igbala, nitori pe Ọlọrun kò jẹ ran ẹlẹṣẹ lati lọ maa kede ihin igbala Rè̩.
Judasi jẹ ọkan ninu awọn ti a yàn ti a si ran jade, ni meji-meji lati lọ kede Ihinrere ti Ijọba Ọlọrun (Marku 6:7). O jẹ ọkan ninu awọn ti Jesu fi iṣẹ le lọwọ, ti O si fun ni agbara lati ṣe iṣẹ naa. Ni afikún, awọn ọmọ-ẹyin wọnyi ni lati maa ṣe “dida ara fun awọn olokunrùn, ẹ sọ awọn adẹtẹ di mimọ, ẹ si ji awọn okú dide, ki ẹ si mā lé awọn ẹmi èṣu jade;” Jesu si fi wọṅ lọkan balẹ wi pe a o pese fun aini wọn bi wọn ti n ṣiṣẹ fun Oun. Judasi jẹ ọkan ninu awọn ti Jesu ran jade gẹgẹ bi “agutan sārin ikõkò.”
Judasi jẹ ọkan ninu awọn wọnni ti Jesu wi pe Ẹmi Baba yoo maa gba ẹnu wọn sọrọ. O jẹ ọkan ninu awọṅ wọnni ti Jesu sọ wi pe aye yoo korira rè̩ nitori Oun, ati pe anfaani nlánlà ni yoo jẹ fun un lati fara da inunibini nitori Kristi. O jẹ ọkan ninu awọn ti Jesu n ba sọrọ nigba ti O sọ pe, gẹgẹ bi ọmọ-ẹyin ati iranṣẹ, wọn kò le tobi ju Oun ti i ṣe Oluwa wọn lọ.
Judasi jẹ ọkan ninu awọn wọnni ti Kristi sọ nipa ti wọn pe wọn yatọ, wọn ki i si ṣe ọkan naa pẹlu awọn iranṣẹ Beelsebubu. O wà lara awọn wọnni ti o yàn lati gbe agbelebu ati lati maa tọ Jesu lẹyin. O wà lara awọn wọnni pẹlu ti o pada tọ Jesu wa ti wọn si wa royin “ohun gbogbo ti wọn ti ṣe fun un, ati ohun gbogbo ti wọn ti kọ ni,” ti wọn si ba A lọ si ibi idakẹjẹ lati lọ sinmi lẹyin ti wọn ti ṣiṣẹ fun Un. (Ka Matteu 10:1-42 ati Marku 6:7-13, 30-32).
O ha tọ fun ẹnikẹni nigba naa lati wi pe ẹlẹṣẹ ni ẹni bẹẹ i ṣe ni gbogbo akoko ti Jesu fi n lo o ninu iṣẹ otitọ ati ododo? Ẹnikẹni ha le wi pe, Ọlọrun ti o mọ opin lati ibẹrẹ ṣe alainaani ofin ara Rè̩ ti o kọ fun ni lati mu ọgbẹri, alaiwa-bi-Ọlọrun, tabi alaimọ eniyan lo ninu iṣẹ iranṣẹ, ki O si wa mu Judasi lo fun ipe giga ati iṣẹ ti o ni ipin ninu rè̩, ni ipa kin-in-ni ninu iṣẹ iranṣẹ Jesu – laidi atunbi? Ẹnikẹni ha le wi pe ẹni ti a pe ti a si yàn si ipo ọmọ-ẹyin, ti a tun yàn gẹgẹ bi Apọsteli, ẹni ti o si ni ipin ninu iṣẹ ọmọ-ẹyin -- ayè ẹni ti o ṣe pataki to bẹẹ ti awọn Apọsteli mọkanla iyoku pinnu pe a kò gbọdọ lọra lati yàn ẹlomiran dipo rè̩ -- kò mọ adun idariji è̩ṣẹ tabi agbara igbesi-aye titun ti a n fi fun ẹnikẹni ti o ba di ẹda titun ninu Kristi Jesu?
Lootọ ni Jesu pe Judasi ni èṣù nigba kan, O si tun pe e ni ọmọ-egbé nigba miiran. Lootọ ni awọn woli Majẹmu Laelae sọtẹlẹ nipa ipinnu ati iwa itiju rè̩. Bakan naa ni awọn woli Majẹmu Laelae wọnyi kọ akọsilẹ nipa ijiya Jesu. Wọn sọ nipa ikú ati ajinde Jesu. Wọn sọ nipa gbese ti O san fun wa. S̩ugbọn a sọ fun ni pe Jesu lagbara lati fi ẹmi Rè̩ lelẹ, O si tun lagbara lati gba a pada. O lagbara lati pe ẹgbẹ ogun awọn angẹli lati ba awọn ti o dide si I jà ki wọn si bori, ati pẹlu pe O lagbara lati sọkalẹ lati ori igi agbelebu ki O si kọ lati kú fun è̩ṣẹ awa ẹda.
S̩ugbọn Jesu fi tifẹtifẹ lọ sori igi agbelebu. O gba lati kú, bi o tilẹ jẹ pe O ni lati beere fun agbara lati fara da ibanujẹ ati irora akoko yii. O mu asọtẹlẹ awọn eniyan mimọ igba ni ṣẹ. Awọn asọtẹlẹ wọnyi kò jade gẹgẹ bi aṣẹ ti o jẹ dandan gbọn fun Jesu lati mu ṣẹ, wọn jẹ itàn ti a kọ silẹ ṣaaju akoko imuṣẹ wọn nipasẹ imisi Ẹmi Mimọ ti o mọ inu Ọlọrun, ti O ba Ọlọrun dọgba, ti O si ni awamaridi ọgbọn ati imọtẹlẹ Ọlọrun.
Judasi pẹlu mu asọtẹlẹ ṣẹ. A pe e ni “ọmọ ègbé” nitori ti o yan ipa ọna ti o sin in de ibi ti o gbe gba orukọ yii. A kò pe e ni ọmọ ègbé bi ẹni pe a ti yan an mọ ọn bẹẹ laisi ayipada. A pe e ni “eṣù” nitori pe o yan ipa ọna si okunkun ati iyapa kuro lọdọ Ọlọrun ati Ọrun. O mọọmọ yan èrè aiṣododo dipo èrè ti Ọlọrun. Nigba ti o si ri ere kikún ti oun yoo gbà fun iṣẹ ọwọ rè̩, laisi aniani, o huwa gẹgẹ bi ojo ti oun i ṣe, o ti ara rè̩ si ijiya ayeraye ninu eyi ti abayọ kò si. Asọtẹlẹ nipa Judasi kì ba ti jẹ mọ ọn rara bi o ba jẹ ti yàn ipa ọna rere dipo ọna ti o lọ si iparun ayeraye.
O yẹ ki awọn wọnni ti wọn wà labẹ aabo-eke ti ẹkọ odi nì, ti o kọ ni pe Onigbagbọ kò le ṣubu ṣọra gidigidi ki wọn si fi apẹẹrẹ ati opin ọkunrin yìí, ẹni ti Ọlọrun pè, ti O si yàn, ti a fun ni agbara ati aṣẹ, ti a si ran jade lati lọ kede Ihinrere ti Ijọba Ọlọrun ṣe arikọgbọn. O yẹ ki awọn wọnni ti wọn gba wi pe wọn wa lai lewu labẹ È̩jẹ nì, ti wọn jẹwọ pe a ta silẹ fun è̩ṣẹ wọn atẹyinwa, ti isisiyi ati ti ọjọ iwaju mọ daju pe Ẹjẹ naa ki yoo jamọ nnkan ayafi bi a ba mu un lo. Nigba ti a ba ronupiwada ti a si tọrọ idariji nipa igbagbọ pẹlu ipinnu tootọ lati kọ è̩ṣẹ silẹ nikan ni a si le mu un lo. O yẹ ki awọn wọnni ti o wi pe a o sọ wọn di mimọ ni akoko ikú lọ tun ọrọ Apọsteli Peteru kà, ti o sọ nipa Judasi pe, “a kà a kún wa, o si ni ipin ninu iṣẹ iranṣẹ yi,” ninu eyi ti o gbe “ṣubu nipa irekọja.” Peteru tun mẹnu kan pipa ti Judasi pa ara rè̩ ati ohun ti Onipsalmu sọ nipa rè̩ lati ran wa leti ègun ti o wà lori awọn ohun ini rè̩ ninu aye yii.
Njẹ ẹnikẹni ti o kọ ọna oore-ọfẹ silẹ ti o si ṣe aigbọran si ofin Ọlọrun nipa tità ati fifi Ẹni ti a ti paṣẹ fun wa lati fẹ pẹlu gbogbo ọkàn, àya ati ẹmi wa, le awọn eniyan buburu lọwọ, ha le lero pe oun yoo ri igbala? Njẹ ẹnikẹni ti o ti tẹ “ẹjẹ alaiṣẹ” nì mọlẹ labẹ ẹsẹ rè̩, nipa bẹẹ ti o ti se ilẹkun ireti rè̩ ninu Ẹjẹ nì fun iwẹnumọ è̩ṣẹ ha le ri igbala? Njẹ ẹni ti o dẹṣẹ nipa pipa oun tikara rè̩, ti o si ran ẹmi ara rè̩ lọ si ayeraye, nipa bẹẹ ti o sọ anfaani ikẹyin kan ṣoṣo ti o kù fun un lati ronupiwada nù ha le ni igbala? Lai si aniani, Ndao ni idahun kan ṣoṣo si awọn ibeere wọnyi! Onkawe, fara balẹ ki o si ronu lori nnkan wọnyi!
Ipa-ọna Iṣubu Judasi
A le beere pe: Anfaani wo ni o wà lati kẹkọọ nipa ọkunrin ti Ọlọrun ti kọ silẹ yii? Fun idi kan yìí pe, a le ri igbesẹ ti Judasi gbe, ti igbẹyin aye rè̩ fi yọri si ibi, a si ni lati kiyesara ki awa naa má ba tọ iru ipa ọna bẹẹ.
Ohun ti o gbẹyin è̩ṣẹ buru jai. Ni aye yìí paapaa, igbesi-aye ẹni ti o ba n huwa ibajẹ ti o si n jẹ aye ijẹkujẹ kò lere ninu. Arun ki i jẹ ki igbẹyin igbesi-aye awọn ti wọn ṣọtẹ si Ọlọrun gbadun. Ibalẹ ọkàn ti lọ jinna réré. Nigba pupọ ni ẹri-ọkan ẹni bẹẹ kò ni fun un ni isinmi. Ara riro kò si ni jẹ ki ara ti igbesi-aye è̩ṣẹ ti sọ di kẹgẹkẹgẹ gbadun mọ nigba ti oluwarè̩ tilẹ ti gbagbe gbogbo igbadun ati iwa ibajẹ atẹyinwa.
S̩ugbọn nigba ti eniyan ba ṣẹṣẹ bẹrẹ si i gbe igbesi-aye è̩ṣẹ èrè è̩ṣẹ kò ni tete fara han. Oofa è̩ṣẹ a maa saba fa ọkàn ati ifẹ awọn ọdọ mọra. O ṣe e ṣe ki ọna è̩ṣẹ ni adun ni akọkọ, ki o mu ayọ wa, ani ki o tilẹ kún fun afẹfẹ-yè̩yè̩ ni iwọn iba ti rè̩. S̩ugbọn titọ ipa ọna yìí yoo mu ki oluwarẹ kabamọ, nigba pupọ ni o si n mu aleebu ba ọkàn ati ara ẹni bẹẹ ti ohunkohun ki yoo le mu àpá rè̩ kuro patapata tabi ki oluwarẹ tun le ni ọkàn ti kò ni kọlọkọlọ bi iru eyi ti o ti ni tẹlẹ ri.
A kò gbọdọ ro pe igbadun diẹ ti è̩ṣẹ n fun ni le dabi èrè nla ti a n ri gba ninu aye ati eyi ti a o tun ri gba ni Ọrun lọhun bi a ba gbe igbesi aye iwa mimọ. Igbesi aye iwa-bi-Ọlọrun, akoso rere awọn eniyan ti o yi wọn ka, ati ipa ọna rere awọn olóòótọ ti sú awọn miiran, wọn si n wa ohun titun miiran ti o yatọ. Ibẹrẹ è̩ṣẹ dara loju wọn niwọn igba ti wọn ti yi ọkàn wọn pada kuro nibi Orisun alaafia ati ayọ tootọ.
Saulu, ọba kin-in-ni ni Israẹli bẹrẹ si jo ajorẹyin ti o yọri si pipa ara rè̩ nitori ti o gba igberaga láàyè lati wọ inu ọkàn rè̩ ti o ti kún fun irẹlẹ tẹlẹ ri. Oun naa ti mọ adun ati anfaani ti ó wà ninu ipe Ẹmi, o ti ni ọkàn titun ri, Ọlọrun si ti yan an. Atunbọtan Saulu buru jai to bẹẹ ti o fi pawọle ti Judasi. Gbigba igberaga láàyè diẹ kinun ninu ọkàn rè̩ ni o kọ bẹrẹ ipa ọna ti ọba yìí tọ ti Ọlọrun fi kọ ọ silẹ patapata nikẹyin.
Bakan naa ni iṣubu Judasi bẹrẹ pẹlu ohun ti ayé le pe ni ohun kekere ti o tilẹ yẹ ki a gboju fo dá. O bẹrẹ si ṣe ojukokoro. A fi aye pataki kan le e lọwọ laaarin awọn iba eniyan diẹ ti o n tọ Jesu lẹyin. S̩ugbọn a sọ fun ni pe o di ole. Ohun ti o ji, tabi ẹni ti o ni ohun ti o ji kò di mimọ fun ni. S̩ugbọn o hàn fun ni gbangba pe ole ni oun i ṣe.
Iṣisẹ ti o wà fun un lati gbe lati lọ dúna-dúra ki o si ṣe adehun pẹlu awọn ọta Kristi kuru lọpọlọpọ. Jesu kilọ fun un, ani titi de ibi ti o ni lati tọka si i pe oun ni yoo fi Oun hàn. S̩ugbọn Judasi kò ronupiwada tabi ki o yipada kuro ni ipa-ọna ti o pari si hihu iwa ọdalẹ ati ọdaran ti o buru ju lọ laye yìí.
Asọtẹlẹ awọn woli sọ ibi ti yoo gbẹyin rè̩ bi o ba ṣe ohun ti o pinnu lati ṣe. Kò ni ṣalai ni imọ ọrọ wọnni nitori pe kò pamọ fun Peteru, ẹni ti o ṣe e ṣe ki o má mọ iwe bi ti Judasi. Ki i ṣe lẹyin gbigba Olutunu --Ẹmi ti n tọ wa si otitọ gbogbo ti o si n fi ohun ti Ọrun hàn fun wa – ni Peteru tọka si ọrọ wọnni ti a ti sọ ninu asọtẹlẹ nipa Judasi. O kere tan o ni lati to ọjọ mẹwaa ṣaaju ọjọ Pẹntekọsti (Orin Dafidi 69:25; 94:20-23; 109:8; Iṣe Awọn Apọsteli 1:15-26). Nitori naa bi Judasi kò ba mọ, o yẹ ki o ti mọ. O gba idajọ ti o tọ. O yẹ ki awọn wọnni ti wọn ni igbagbọ ninu ẹkọ “aabo eke” (ti o n kọ ni wi pe a kò le ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ) ki o wo idalẹbi ti i ṣe ti Judasi ninu awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wọnni ti o sọ asọtẹlẹ nipa eyi. A ke e kuro ninu aiṣedeedee rè̩! Kò si si aniani wi pe o ti jẹ olododo nigba kan ri!
Lẹyin ti o ti kọ ikilọ ti a fi fun un, Judasi gba eṣu laaye lati fi ipinnu kan si i lọkàn lati lọ ṣe ohun naa gan an (Johannu 13:2). Judasi ti ba awọn ọta Kristi mọ pọ. O jọwọ ara rè̩ fun Satani nipa biba a jiroro nipasẹ awọn ẹmẹwa rè̩.
Ohun ti o tẹle e ni pe eṣu kó si i ninu, nitori a kọ ọ pe, “Lẹhin òkele na ni Satani wọ inu rè̩ lọ.” O wa di ọmọ egbé gan an wayii. O di iranṣẹ Satani patapata -- aṣodisi-Kristi ti aye igba nì -- o kọ igbagbọ ati Kristi silẹ patapata. Ina ireti ti o ti n tan ni ookan aya rè̩ ti dòkùnkùn: Ẹni ti o ti jẹ ohun-elo ninu iṣẹ Ijọba Kristi wa jọwọ ara rè̩ lọwọ lati di ẹru eṣu patapata ati lati di alabapin pẹlu rè̩ ninu ọrun egbe. Niwọn igba ti a mọ daju pe ayọ wà lọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti a ba le já gbà kuro labẹ ijọba okunkun ti a si mu un wa sinu Ijọba Imọlẹ, a le gba pẹlu pe ẹrin iyangi ati ayọ ifiniṣẹsin wà ni ọrun apaadi nigba ti Satani pari iṣẹ ibi naa.
Awọn iṣisẹ ti o tẹle e hàn gbangba. Judasi mu iṣẹ ibi yìí ṣe lai ronu ohun ti o le ti ìdi rè̩ jade. Iye rè̩ ti ra, ẹri ọkàn rè̩ si kú patapata nigba ti o fi ẹnu ko Kristi Ọba Ogo, Ẹni Mimọ ati Ẹni pipe lẹnu, ni fifi ifẹnukonu yìí fun awọn ọmọ ogun ti o wà nitosi ni àmi lati mọ pe Ẹni ti wọn ti n wa ni yìí. Kò si ifẹ ninu ifẹnukonu naa rara. Kò tilẹ si imoore ninu rẹ fun ohun wọnni ti Kristi ti ṣe fun un. Ẹmi afi-ni-hàn, ẹtan, onikupani ati ẹmi ojukokoro ti o ṣe tan lati ta Ọṣọ ti o niyelori ju lọ lode Ọrun fun ohun ti kò nilaari ni o wà nidi ifẹnukonu yìí. (Iye ti Judasi gbà fẹrẹ tó dọla mọkandinlogun, aabọ owo-ilẹ Amẹrika).
Iye owo ti Judasi beere fun nigba ti o n dúna-dura pẹlu awọn ọta Kristi jẹ eyi ti o ga ju lọ ti a le beere labẹ ofin, gẹgẹ bi iye owo ti ẹni ti a ba ṣeeṣi pa ọkan ninu awọn ẹrú rè̩ ti o san ju lọ le gba. Judasi gbee de oju rẹ wayi ni ti pe o kọ Ọlọrun ati Kristi Rè̩ silẹ to bẹẹ ti o le ta Oluwa rè̩ fun iye owo ti a n ta ẹrú lasan!
Judasi kabamọ, ṣugbọn kò ronupiwada. O mu “owo ẹjẹ” pada o si jẹwọ pe oun ti fi “ẹjẹ alaiṣẹ” hàn. Kò si ẹni ti o tun le gba orukọ yii jẹ afi Kristi. O ṣe e ṣe ki awọn eniyan kan wà ti a ti pa ti a si ri i pe wọn jẹ alaiṣẹ ninu awọn iwà-buburu kan tabi pe wọn kò dẹṣẹ ti a le foju ri gbangba, a si le sọ nipa ti wọn pe, a ti ta ẹjẹ alaiṣẹ silẹ. S̩ugbọn nigba ti o jẹwọ pe, “Mo fi ẹjẹ alaiṣẹ han,” eyi kò tọka si ẹlomiran bi kò ṣe Kristi, nitori pe Oun nikan ni Ẹni Alailẹṣẹ. Judasi gba pe oun dẹṣẹ ni fifi Ọmọ Ọlọrun hàn, ṣugbọn lati ri igbala gba ju pe ki a kan gbà pe ẹlẹbi ni wá.
Awọn ole mejeeji wọnni lori agbelebu ni wọn jẹbi, ṣugbọn ọkan ṣoṣo ni o ri igbala; idi rè̩ ti o fi ri igbala ni pe, o ké pe Ọlọrun fun aanu ati iranlọwọ, o si mọ ara rè̩ ni ẹlẹbi. Kò si igbala fun ẹni ti kò ba ronupiwada. Judasi kò yipada si Ọlọrun. O gbiyanju lati ṣe ilaja nipa rironupiwada sọdọ awọn olori alufa ati awọn alagba, ṣugbọn kò gbadura si Ọlọrun rara -- Ẹni kan ṣoṣo naa ti o le fi è̩ṣẹ ji.
Lẹyin ti Ọlọrun kọ ọ silẹ, ti awọn wọnni ti o ti ba dimọ pọ tẹlẹ kọ ọ, ti wọn si fi i ṣe ẹlẹya, ẹni ti o ti jẹ Apọsteli ati ọmọ-ẹyin Jesu nigba kan ri yìí gba ẹmi ara rè̩. A ti ri i pe o fi ọwọ ara rè̩ kó ara rè̩ sinu egbé titi ayeraye nitori pe o fi è̩ṣẹ dida pari ayé rè̩, nitori pe ninu iwa è̩ṣẹ ni o fi ayé silẹ lati duro niwaju Ọlọrun rè̩, pẹlu idalẹbi nitori è̩ṣẹ rè̩, lai ronupiwada ati lai ni ireti.
Questions
AWỌN IBEERE1 Iṣẹ wo ni a pe Judasi si? Ki ni orukọ ayè ti o dimu?
2 Ki ni ojuṣe rè̩ laaarin awọn Apọsteli mejila?
3 Ki ni ohun kin-in-ni ti i ṣe iyẹsẹ kuro lọna ododo ti a kọ ri lọwọ Judasi?
4 Lọna wo ni Judasi gba rú ofin nì ti o kọ ni pe olododo kò gbọdọ dapọ mọ aye tabi ki a ba awọn alaiwabi-Ọlọrun kẹgbẹ lọna ti kò nilaari?
5 Ikilọ wo ni Judasi ti gbà ti ó yẹ ki o ti ko o yọ kuro ninu ohun ti ó fọwọ fà yii?
6 Judasi ha ṣe ohun ti o ṣe yii nitori pe a ti kọwe rè̩ bẹẹ, kò si lagbara lati le yi i pada?
7 Nigba wo ni a le wi pe o di “ọmọ egbé” patapata?
8 Lọna wo ni ẹkọ yii gba lati tu aṣiiri ẹkọ “aabo eke” ti o wi pe onigbagbọ kò le ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ?
9 S̩e alaye iyatọ ti o wà ninu igboke-gbodo Satani nipa Judasi gẹgẹ bi a ti ka ninu Johannu 13:2 ati 27.
10 Ki ni iyatọ laaarin abamọ ati ironupiwada? Ewo ni Judasi ni ninu mejeeji? Judasi ha tun ri igbala nikẹyin?