Lesson 250 - Senior
Memory Verse
“Nitoriti iwọ ri mi ni iwọ ṣe gbagbọ: alabukun-fun li awọn ti kò ri, ti nwọn si gbagbọ” (Johannu 20:29).Cross References
I I Ifarahan Kristi ni Ọjọ Ajinde
1 Jesu fara han Maria Magdalene ni iboji, Marku 16:9-11; Johannu 20:11-18
2 Jesu fara han awọn obinrin miiran bi wọn ti n bọ lati iboji, Matteu 28:9, 10
3 Jesu fara han Simoni Peteru, Luku 24:34; I Kọrinti 15:5
4 Jesu fara han awọn ọmọ-ẹyin meji lọna Emmausi, Marku 16;12, 13; Luku 24:15-31
5 Jesu fara han awọn Apọsteli ati awọn miiran lai si Tọmasi nibẹ, Marku 16:14-18; Luku 24:36-48; Johannu 20:19-23
II Ifarahan Kristi Lẹyin Ọjọ Ajinde
1 Ni ọjọ Oluwa ti o tẹle Ajinde, Jesu fara han awọn Apọsteli, Tọmasi si wà pẹlu wọn, Johannu 20:26-29
2 Jesu fara han awọn ọmọ-ẹyin meje nigba ti wọn n pẹja ni okun Tiberia, Johannu 21:1-25
3 Jesu fara han awọn Apọsteli lori oke kan ni Galili, Matteu 28:16-20
4 Jesu fara han awọn arakunrin ti o ju ẹẹdẹgbẹta lọ, I Kọrinti 15:6
5 Jesu fara han Jakọbu, I Kọrinti 15:7
6 Jesu goke re Ọrun loju awọn Apọsteli ni Bẹtani, Marku 16:19; Luku 24:50; Iṣe Awọn Apọsteli 1:2-9; I Kọrinti 15:7
7 Jesu fara han Paulu, I Kọrinti 15:8
Notes
ÀLÀYÉIhin Ajinde
Ilẹ mi titi. Angẹli kan joko sori okuta ti o yi kuro lẹnu iboji. Ihin pe Kristi wà laaye ti angẹli naa ro fun awọn obinrin dabi ahesọ loju awọn ọmọ ẹyin. Wọn ro pe kò le ri bẹẹ. Peteru bẹrẹ mọlẹ o si wọ inu iboji ti o ṣi silẹ lọ. Awọn aṣọ ọgbọ nikan ni o wà nibẹ, ṣugbọn kò si oku nibẹ mọ. Ẹnu ya a si ohun ti o ṣẹlẹ yii.
Maria ri Jesu, ṣugbọn awọn Apọsteli kò gbagbọ pe Oun gan an ni. Awọn obinrin miiran ri Jesu -- ṣugbọn ihin wọn dabi ala ti a n rọ. Oluwa fi ara hàn fun Peteru, ihin naa si gba ẹnu wọn kan wi pe, “Oluwa jinde nitõtọ, o si ti fi ara hàn fun Simoni.” S̩ugbọn iyemeji wà lọkàn awọn ẹlomiran sibẹsibẹ. Lẹyin naa ni awọn ọmọ-ẹyin meji lati Emmausi wọle si aarin awọn ọmọ-ẹyin pẹlu ọrọ yii pe Jesu ti ba wọn rìn ni ọna o si di mimọ fun wọn pe Jesu ni, nigba ti o bu akara. Sibẹsibẹ awọn miiran ṣiyemeji.
Jesu Wọle
Lojiji ẹrù ba awọn ọmọ-ẹyin, aya wọn si ja nitori pe ẹni kan ti wọn ro pe i ṣe iwin duro laaarin wọn -- ṣugbọn Jesu ni! Sibẹsibẹ O fẹrẹ má le fi wọn lọkàn balẹ pe Oun gan an ni pẹlu gbogbo ọrọ ikiya ti O sọ fun wọn. “Ẹ wò ọwọ mi ati ẹsẹ mi,” ni ohun ti O sọ tẹle e. Apa iṣo si wà ni ọwọ ati ẹsẹ Rè̩. Jesu ni, Oluwa ati Ọrẹ wọn – ani Jesu, ti O ti ba wọn rìn ti O si ti ba wọn sọrọ!
Ki i ṣe Iwin, ṣugbọn Ẹni Ti A S̩e Logo Ni
Jesu fi ọkàn awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ balẹ pe Oun ni – ninu ara, bi O ti ṣe alaye fun wọn pe, “Iwin kò li ẹran on egungun lara.” Lati fi hàn wọn pe Oun jinde Oun si wa laaye sibẹ, O beere ohun jijẹ, O si jẹun loju wọn. Jesu mọ oriṣiriṣi ahesọ ati agala-maṣa ti ọta yoo maa tàn kaakiri lati sẹ otitọ ajinde Rè̩ kuro ninu oku; nitori naa O fi “ẹri pupọ ti o daju” silẹ fun wọn (Iṣe Awọn Apọsteli 1:3). Ki i ṣe pe O ni ẹran ati egungun lara nikan -- ṣugbọn apa iṣo wa lọwọ ati ẹsẹ Rè̩, apa ọkọ ti a fi gun Un wà ni iha rè̩, gẹgẹ bi ẹri lati fi idi rè̩ mulẹ pe ara ti Rè̩ gan an ni o jinde kuro ninu oku.
Ara Jesu, lẹyin ti O jinde yatọ si ara ti O gbe wọ ṣaaju ajinde, ni ti pe, pẹlu ara ti o jinde, O le wọ yara lọ bi a tilẹ “ti ilẹkun” (Johannu 20:26). “O si nù mọ wọn li oju” pẹlu (Luku 24:31). S̩ugbọn ki i ṣe iwin, O ni ara – ara ajinde, ani ara ologo. Gbogbo awọn Onigbagbọ ti wọn ba ṣẹgun ni a o palarada bakan naa ni akoko Ipalarada Ijọ Ọlọrun. “Gbogbo wa li a o palarada. Lọgan, ni iṣé̩ju, nigba ipè ikẹhin: nitori ipè yio dún, a o si ji awọn okú dide li aidibajẹ, a ó si pawalaradà” (I Kọrinti 15:51, 52). Jesu “yio sọ ara irẹlẹ wa di ọtun ki o le bá ara ogo rè̩ mu” (Filippi 3:21). A o gbé ara ologo ti o dabi ara wa isisiyi wọ. Eyi ni pe, ẹni kin-in-ni yoo mọ ẹni keji, ṣugbọn gbogbo aipe ti i ṣe abawọn ti ègùn è̩ṣẹ ki yoo si mọ, a o si wà laaye titi, a ki yoo kú mọ.
S̩iṣi Wọn Niye
“Nigbana li o ṣi wọn ni iyè, ki ìwe-mimọ ki o le yé wọn” (Luku 24:45). Lai si aniani, Jesu tọka si ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wọnni ti o wu ni lọpọlọpọ bi eyi ti o wi pe, “A ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ina alafia wa wà lara rè̩, ati nipa ina rè̩ li a fi mu wa lara da” (Isaiah 53:5). Bayii ni imọlẹ mọ si wọn, wọn si mọ pe Jesu ni.
Pataki Ajinde
Nigba ti ọpọ n ṣe atako pe Jesu ki i ṣe Ọmọ Ọlọrun ti ọpọ si n sẹ otitọ ajinde Rè̩ kuro ninu oku, Igbagbọ tootọ duro lori otitọ wọnyi pe, Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe ati pe O jinde kuro ninu oku. Bi a ba sẹ otitọ ajinde a sẹ igbagbọ wa pẹlu, a si ti sọ ireti wa nipa Ọrun nù. “Bi Kristi kò ba si jinde, njẹ asan ni iwāsu wa, asan si ni igbagbọ nyin pẹlu . . . Bi a kò ba si jí Kristi dide, asan ni igbagbọ nyin; ẹnyin wà ninu è̩ṣẹ nyin sibẹ. Njẹ awọn pẹlu ti o sùn ninu Kristi ṣegbé” (I Korinti 15:14, 17, 18). Abajọ ti Jesu fi fẹ ki awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ mọ daju pe Oun ni, ki i ṣe iwin. Igbala wa ati ireti iye ainipẹkun wa rọ mọ otitọ yii pe, a ji I dide kuro ninu oku.
O S̩oro lati mu un ki o Gbagbọ
Pẹlu gbogbo ẹri yii pe Kristi fi ara han fun awọn ọmọ-ẹyin lọtọọtọ nigba marun-un ni ọjọ ti O jinde, sibẹsibẹ iyemeji kò kuro lọkàn Tọmasi, ti i ṣe ọkan ninu awọn “mọkanla.” Tọmasi kò si nibẹ ni alẹ ọjọ ti Jesu yọ si awọn ọmọ-ẹyin iyoku. Tọmasi alaigbagbọ dahun wi pe, “Bikoṣepe mo ba ri àpá iṣo li ọwọ rè̩ . . . emi kì yio gbagbọ” (Johannu 20:25).
Oluwa mọ pe ọkàn Tọmasi atọpinpin kò ni gba itan atọwọdọwọ. Oluwa wa kò si fẹ ki Tọmasi wà ninu iyemeji sibẹ. Ni ọjọ kẹjọ, lẹyin eyi – ni ọjọ kin-in-ni ọsẹ -- Jesu fi ara han fun awọn ọmọ-ẹyin, bi O si ti duro laaarin wọn, O wi fun Tọmasi pe, “Mu ika rẹ wá nihin, ki o si wò ọwọ mi, si mu ọwọ rẹ wá nihin, ki o si fi si iha mi; ki iwọ ki o máṣe alaigbagbọ mọ, ṣugbọn jẹ onigbagbọ” (Johannu 20:27). Eyi yii to lati mu Tọmasi ti ki i tete gba nnkan gbọ gbagbọ ki o si kigbe wi pe, “Oluwa mi ati Ọlọrun mi.” Tọmasi paapaa ti o ṣoro fun lati gbagbọ mọ pe Jesu ni.
Imisi Ọlọrun
“Nitorina Jesu si tún wi fun wọn pe, Alafia fun nyin: gẹgẹ bi Baba ti rán mi, bḝli emi si rán nyin. Nigbati o si ti wi eyi tan, o mi si wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbà Ẹmi Mimọ” (Johannu 20:21, 22). Iru imisi bayii lati ọdọ Ọmọ Ọlọrun wá kò le ṣe alainilaari. Ni iṣẹdalẹ aye, Ọlọrun mi ẹmi iye si iho imu ọmọ eniyan, eniyan si di alaaye ọkàn (Gẹnẹsisi 2:7). Nigba ti Jesu mi si awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ti O ti yàn ti O si wi pe, “Ẹ gbà Ẹmi Mimọ,” o ṣe e ṣe ki o jẹ pe n ṣe ni O n ran Ẹmi Mimọ si wọn lati fi idi iriri isọdimimọ ti wọn ti ri ṣaaju akoko yii mulẹ. A mọ pe a ti sọ wọn di mimọ nipa Ẹjẹ Jesu ṣaaju Ọjọ Pẹntekọsti nitori pe gbogbo wọn wa ni ọkàn kan. Isọdimimọ ni o mu iṣọkan yii wa. “Sọ wọn di mimọ ninu otitọ . . . ki wọn ki o le jẹ ọkan gẹgẹ bi awa ti jẹ ọkan” (Johannu 17:17, 22).
Idariji È̩ṣẹ
“Ẹṣẹ ẹnikẹni ti ẹnyin ba fi ji, a fi ji wọn; è̩ṣẹ ẹnikẹni ti ẹnyin ba da duro, a da wọn duro” (Johannu 20:23). Aṣẹ ti a fi fun awọn Apọsteli yii gẹgẹ bi olupilẹṣẹ Ijọ fun wọn ni ẹtọ lati ni idapọ pẹlu awọn wọnni ti wọn kuna nipa igbagbọ ṣugbọn ti wọn tun ronupiwada, tabi lati yọ awọn wọnni kuro ti wọn kọ lati ronupiwada. Ilana yii fara jọ eyi ti o wà ninu Matteu 18:15-17 nibi ti a gbe ṣe alaye fun ni pe, bi arakunrin kan ba kọ lati gbọ ti Ijọ, jẹ ki o dabi “keferi si ọ ati agbowodè.” Paulu kọwe si awọn ara Tẹssalonika pe, “Awa si paṣẹ fun nyin, ará, li orukọ Jesu Oluwa wa, ki ẹnyin ki o yẹra kuro lọdọ olukuluku arakunrin, ti nrin ségesège, ti kì iṣe gẹgẹ bi ilana ti nwọn ti gbà lọwọ wa” (II Tẹssalonika 3:6). Aṣẹ ti Ijọ ni lati dariji ọmọ Ijọ kò yatọ si aṣẹ ti arakunrin kọọkan ni lati dariji ẹni ti o ba ṣẹ ẹ, “Bi arakunrin rẹ ba ṣè̩, ba a wi; bi o ba si ronupiwada, dari ji i” (Luku 17:3). Eyi kò fi hàn wi pe Ijọ tabi Popu, alufaa tabi ẹnikẹni le fi è̩ṣẹ ti a da si Ọlọrun ji. È̩ṣẹ si arakunrin jẹ è̩ṣẹ si Ọlọrun pẹlu. Ẹnikẹni ti o ba ti ṣè̩ ni lati ṣe atunṣe, ki i ṣe lọdọ arakunrin rè̩ nikan, bi kò ṣe lati ronupiwada niwaju Ọlọrun pẹlu nitori Ọlọrun nikan ni o le fi è̩ṣẹ ji.
Ọmọ Ọlọrun
“Ọpọlọpọ iṣẹ àmi miran ni Jesu ṣe niwaju awọn ọmọ-ẹhin rè̩, ti a kò kọ sinu iwe yi: ṣugbọn wọnyi li a kọ, ki ẹnyin ki o le gbagbọ pe, Jesu ni iṣe Kristi na, Ọmọ Ọlọrun: ati ni gbigbàgbọ, ki ẹnyin ki o le ni iye li orukọ rè̩” (Johannu 20:30, 31). Johannu ti fun ni ní awọn ẹri ti o daju pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe. Ọkẹ aimoye awọn Onigbagbọ ti wọn ti ri iye gbà nipasẹ Orukọ Rẹ, lati iṣẹdalẹ aye, jẹ ẹlẹrii si agbara ajinde Rè̩.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ọjọ wo ninu ọsẹ ni Jesu jinde kuro ninu oku?
2 Bawo ni o ti pẹ to lẹyin ti O jinde ki O to fi ara hàn fun awọn ọmọ-ẹyin ni igba kin-in-ni?
3 Sọ awọn ẹri ti Jesu fi hàn nipa ara Rè̩ ti o ji dide ninu okú.
4 Sọ oriṣiriṣi igba ti Jesu fi ara hàn lọjọ ajinde.
5 Wo awọn asọtẹle nipa iku ati ajinde Kristi.
6 Ọjọ wo ninu ọsẹ ni Jesu fi ara Rè̩ hàn fun awọn Apọsteli lẹẹkeji?
7 Ta ni kò si nibẹ nigba ti O kọ fi ara hàn?
8 Ki ni ṣe ti o fi ṣe danindanin lati ni ẹri pe ara-iyara Jesu ni o ji dide kuro ninu okú?
9 Sọ iwọn iba ohun ti o mọ nipa ara ologo.
10 Ọna wo ni ara ologo fi yatọ si ti iwin?