Johannu 21:1-25

Lesson 251 - Senior

Memory Verse
“Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jìya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mā tọ ipasẹ rè̩” (I Peteru 2:21).
Cross References

I Ifarahan Jesu ni Igba Kẹta fun awọn Apọsteli

1 Peteru ati awọn mẹfa miiran lọ pẹja ni okun Tiberia, wọn kò si ri ohun kan mú, Johannu 21:1-3

2 Jesu fara han leti okun, Johannu 21:4, 5

3 Ni igbọran si aṣẹ Rẹ, awọn ọmọ-ẹyin kó ẹja lọpọlọpọ, Johannu 21:6-11; Luku 5:4-11

4 “Ẹ wá jẹun owurọ” Johannu 21:12-14; Luku 1:53; Orin Dafidi 34:10

II Idanwo Peteru

1 “Iwọ fẹ mi jù awọn wọnyi lọ bi?” Johannu 21:15-17; Luku 14:26, 27, 33; 19:28-34; Filippi 3:8

2 A sọ asọtẹlẹ ikú Peteru, Johannu 21:18, 19; I Peteru 2:21

3 A ba Peteru wi fun ibeere rè̩ pe, “Eleyi ha nkọ?” Johannu 21:20-23

4 Johannu fi ẹsẹ otitọ gbogbo ẹri rè̩ nipa Jesu mulẹ, Johannu 21:24, 25; Luku 1:2; 24:48; Iṣe Awọn Apọsteli 1:21, 22; II Peteru 1:16

Notes
ALAYÉ

Igba Kin-in-ni ninu Igba Meji ti Awọn Kún fun Ẹja

Ni ibẹrẹ iṣẹ-iranṣẹ Jesu, ni nnkan bi ọdun mẹta aabọ ṣaaju ni ohun ti a mẹnu kan ninu ẹkọ wa oni ṣẹlẹ. Awọn ọgọọrọ eniyan ti o fẹ mọ ohun ti o n ṣẹlẹ bẹrẹ si sare soke-sodo leti ebute. Ọkọ ẹja kan n tẹ siwaju diẹ diẹ kuro ni ebute. O duro. Ohùn kan lati inu ọkọ fi opin si ariwo ati igbokegbodo wọn, awọn eniyan ti o wà ni ebute si tẹti lelẹ nigba ti Olugbala wa bẹrẹ si i kọ wọn ni Ọrọ Ọlọrun. Lẹyin eyi, Jesu yipada si Peteru, ẹni ti o ni ọkọ yii, O si wi pe, “Ti si ibu, ki o si jù àwọn nyin si isalẹ fun akopọ.” “Olukọni, gbogbo oru aná li awa fi ṣiṣẹ, awa kò si mu nkan: ṣugbọn nitori ọrọ rẹ emi ó jù àwọn na si isalẹ” (Luku 5:4, 5). Eyi ni ohun ti awọn apẹja fi da Jesu lohun. Nigba ti wọn si ṣe ohun ti Oluwa palaṣẹ, oju Peteru ri ohun ti o jẹ iyalẹnu ju lọ lati igba ti o ti wa nidi iṣẹ ẹja pipa. Nigba ti àwọn rè̩ bẹrẹ si ya nitori ẹja pupọ n bẹ ninu rè̩, o pe Jakọbu ati Johannu lati wa ṣe iranwọ. Wọn kún ọkọ mejeeji titi wọn fi bẹrẹ si ri -- sibẹ ẹja n bẹ nilẹ. Lai si aniani, Peteru ti ni iriri oriṣiriṣi nidi iṣẹ ẹja pipa, ṣugbọn kò si eyi ti a le fi iriri ti o ṣẹlẹ yii we.

Ipe Peteru

Iṣẹ iyanu yií fi igbagbọ nlánlà ninu Olukọni yii si ọkàn Peteru, o si ti pese ọkàn Peteru silẹ fun ipe ti a pe e wi pe, “Ẹ mā tọ mi lẹhin, emi ó si sọ nyin di apẹja enia” (Matteu 4:19). Peteru tẹle E. Ohun nla ni o gba Peteru ati awọn Apọsteli miiran lati fi ohun gbogbo silẹ ki wọn si maa tọ Jesu lẹyin. Wo awọn apẹja wọnyi ti kò ni òwò miiran lẹyin iṣẹ ẹja pipa. Lati fi awọn ọkọ wọnni silẹ, ati gbogbo irin-iṣẹ wọn, lati fi awọn ibi ti o ti gbadun mọ wọn silẹ, adagun daradara nì nibi ti wọn gbe n ṣe faaji ti wọn si gbe n wa ounjẹ oojọ wọn; lati fi ile ati ọna silẹ -- ki i ṣe ohun kekere. Awọn eniyan wọnyi bẹrẹ igbesi aye igbagbọ. S̩ugbọn ipe yii, wi pe “Mā tọ mi lẹhin” ki i ṣe ipe ti aye yii; ipe lati ọdọ Ọmọ Ọlọrun wa ni. Ileri ohun ti ayé yii kò pẹlu ipe yii ju eyi pe, “Emi ó si sọ nyin di apẹja enia.” Awọn apẹja wọnyi tọ Ọ lẹyin. Iyipada iyanu ti kò ṣe e royin wọ inu awọn eniyan wọnyi. Jesu sọ fun ni pe iyipada yii dabi afẹfẹ ti o n fẹ, “si ibi ti o gbé wù u, iwọ si ngbọ iró rè̩, ṣugbọn iwọ kò mọ ibi ti wá, ati ibi ti o gbé nlọ: gẹgẹ bḝni olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ẹmi” (Johannu 3:8). Lonii, iyipada ọkàn n jẹ ti awọn wọnni ti o ba ronupiwada ti wọn si yipada kuro ninu è̩ṣẹ wọn lati maa tọ Olugbala lẹyin.

Igbesẹ Igbagbọ

Peteru ni ọpọlọpọ iriri o si kẹkọọ pupọ lọdọ Oluwa laaarin ọdun mẹta aabọ wọnni ti o fi n tọ Jesu lẹyin. Nigba kan, a ran oun ati awọn Apọsteli iyoku jade, ni meji-meji lati waasu Ihinrere. Wọn kò gbọdọ mu ipaarọ aṣọ tabi ki wọn mu owo lọwọ ninu aṣuwọn wọn, ki wọn ba le kọ ẹkọ lati gbe igbesi aye igbagbọ. Lẹyin eyi Jesu beere ibeere yii lọwọ wọn nipa ijadelọ wọn yii pe “Nigbati mo rán nyin lọ laini aṣuwọn, ati àpo, ati bàta, ọdá ohun kan da nyin bi?” (Luku 22:35). Wọn si wi pe, “Ndao.” Eyi ṣẹlẹ ṣaaju igba ti a kan An mọ agbelebu. Iku Olugbala dabi ẹni pe o mu ireti awọn ọmọ-ẹyin ṣaki, paapaa ju lọ, Peteru. Wọn dabi ọmọde ti o ti igba ọdọ bọ si igbesi aye agbalagba lojiji. Wọn kò fẹ ki Olukọni wọn fi wọn silẹ. Lootọ ni ajinde tun fun wọn ni ayọ ati ireti diẹ, ṣugbọn sibẹsibẹ, ọkàn wọn daamu. Jesu ti fara han fun wọn nigba meji bi wọn ti pejọ, ṣugbọn nigba ti o ba fi wọn silẹ wọn kò mọ bi wọn yoo ti ṣe aye wọn si. Wọn ti gbe igbesi aye igbagbọ, ṣugbọn wọn mọ daju pe Oluwa wọn wà ni tosi.

Wọn Lọ Pẹja

Ninu idaamu wọn, Peteru wi pe, “Emi nlọ ipẹja.” Awọn mẹfa dahun pe, “Awa pẹlu mba ọ lọ” (Johannu 21:3). Peteru ati awọn ẹlẹgbẹ rè̩ wọnyi pada si iṣẹ wọn atijọ. Lati tun pada lọ ṣe iṣẹ wọn atijọ fun wọn ni ifọkanbalẹ diẹ nipa ti ara. Ni gbogbo oru naa wọn n sọ àwọn wọn sinu omi, wọn si n fa a ni afa-tunfa. S̩ugbọn wọn kò ri ẹja pa. Ilẹ bẹrẹ si mọ, wọn si n pada si ebute. S̩ugbọn Ẹni kan dá duro leti ebute lori iyanrin. Ohùn Rè̩ dún lori omi bi iro agogo wi pe, “Ẹnyin ọmọde, ẹ li onjẹ diẹ bi?” “Ndao.” “Ẹ sọ àwọn si apa ọtún ọkọ, ẹnyin ó si ri.” Pẹlu ikiya yii ati ireti kan ṣoṣo ti apẹja ti o fẹ ri ẹja pa, wọn gbọran. Wọn bẹrẹ si ja kita pẹlu àwọn wọn, ṣugbọn wọn kò le fa a nitori o kún fun ọpọlọpọ ẹja.

Johannu sọ fun Peteru pe, “Oluwa ni.” Lai ronu bi wọn yoo ti ṣe fa àwọn ati ẹja de ebute, Peteru bẹ sinu omi, o si n tọ Oluwa lọ. Lai si aniani, Peteru ranti igba ti o gbọ ipe Oluwa wi pe, “Mā tọ mi lẹhin, emi ó si sọ nyin di apẹja enia.” Gbogbo awọn Apọsteli ni o wà ninu ewu ṣiṣi oju wọn kuro ninu ipe ti Jesu pe wọn ati pipada si iṣẹ wọn atijọ.

Ọpọlọpọ lọjọ oni ni wọn ti kọ igbagbọ ati igbẹkẹle wọn ninu Jesu silẹ ti wọn si ti pada si igbesi aye wọn atijọ -- wọn n ṣiṣẹ tọsan toru --ṣugbọn wọn kò ri ohun kan mu bọ. Pẹlu àwọn ofifo ati ọkàn ti o ti joro wọn a maa ro wi pe, bi wọn ba gbiyanju diẹ si i, ọwọ wọn yoo tẹ nnkan. Pada sile, aṣako, pada si ibi ti ọkàn rẹ ti fẹ lati maa gbadura. Olugbala tun fẹ pe ọ lọtun wi pe, “Mā tọ mi lẹhin.” Gbọ idahun Rè̩ si ọkàn ti o ronupiwada: “A dari è̩ṣẹ rẹ ji ọ . . . mā lọ ni alafia.”

Tabili Oluwa

Awọn ọmọ-ẹyin ba ẹja ti a ti yan lori ẹyin ina. Oluwa okun kò ni duro woju awọn apẹja ki o to ri ẹja. Nipasẹ Rè̩ ni a ti da ohun gbogbo ati fun Un, O si pe gbogbo eniyan lati “wa jẹun.” Tabili Rè̩ kún fun ohun rere gbogbo. Ọna Rè̩ tayọ ọna ti wa. Ero Rè̩ ga ju ero wa. Iwọ ha le gbẹkẹ le E, Peteru?

Yiyàn

Jesu dahun pe, “Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi jù awọn wọnyi lọ bi?” (Johannu 21:15). Ẹja mẹtalelaadọjọ (153) ti o gbadun ni o wà ni ebute yii, àwọn ni yii lẹgbẹ wọn, ọkọ ti o si fẹrẹ gunlẹ si ebute ni yii loju omi, ohun ti yoo mu inu ẹnikẹni ti i ṣe apẹja dun, eyi si to lati fi gbọ bukata awọn eniyan wọnyi. “Iwọ fẹ mi jù awọn wọnyi lọ bi?” O fi oju kan wo ẹja wọnyi, o si foju keji wo Oluwa rè̩, lẹyin eyi, Peteru dahun wi pe, “Bḝni Oluwa; iwọ mọ pe, mo fẹràn rẹ.” Ẹmi Ọlọrun tubọ n wa inu ọkàn Peteru ri gẹgẹ bi Jesu ti tun beere nigba keji pe, “Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi bi?” Lai si aniani, pẹlu ifararubọ pe oun ki yoo da Oluwa mọ, Peteru dahun pe: “Bḝni Oluwa; iwọ mọ pe, mo fẹràn rẹ.” Ipenija ti o tẹle e ni pe, “Mā bọ awọn ọdọ agutan mi.”

Ọkàn Jesu kò kuro lara awọn agutan Rè̩. O ti fi Ọrọ Ọlọrun bọ wọn ninu iṣẹ iranṣẹ Rè̩, iṣẹ yii si wa di ti awọn ti O pè lati maa ba iṣẹ naa lọ wayi. Iṣẹ nlá nlà ni ipe Ọlọrun mu lọwọ. Ni ti Peteru, o ni lati waasu Ihinrere. Fun olukuluku ọkàn, ipe si iṣẹ gẹgẹ bi agbara ẹni kọọkan ba ti ri ni. Fun awọn diẹ, ipe lati fi gbogbo akoko wọn ṣiṣẹ iranṣẹ ni; fun awọn ẹlomiran, ipe lati maa gbe igbesi aye Onigbagbọ nibi iṣẹ wọn ki wọn si maa ṣe ohunkohun ti ọwọ wọn ba ri ṣe fun Oluwa lọjọọjọ ni.

Ni igba kẹta ibeere Oluwa tun tọ Peteru wa wi pe, “Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹràn mi bi?” Imọlẹ awamaridi Ẹmi Ọlọrun tun tan jinlẹ-jinlẹ sinu ọkàn ati aya Peteru titi a fi ṣe awari ero ati ète ọkàn rè̩ patapata. Pẹlu ibanujẹ ki o má ba jẹ pe Oluwa kò le fi ọkàn tan an mọ nitori ti o ti sẹ Ẹ nigba mẹta, ọrọ wọnyi jade lati inu odò ọkàn Peteru wa wi pe, “Oluwa, iwọ mọ ohun gbogbo; iwọ mọ pe, mo fẹràn rẹ.”

Ohun Ribiribi ti yoo Gba A

Lẹyin ijẹwọ yii, Jesu fi apẹẹrẹ “irú ikú ti yio fi yin Ọlọrun logo” hàn fun Peteru. Ni igba ogbo Peteru, a o ke si i lati fi ẹmi rè̩ lelẹ fun ijẹwọ igbagbọ rè̩. O le sọ pe, “Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jiya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mā tọ ipasẹ rè̩” (I Peteru 2:21). Peteru si tẹle apẹẹrẹ yii titi de opin.

“Eleyi ha nkọ?” Ibeere yii jade lati ẹnu Peteru atọpinpin, nipa Johannu, Oluwa si fi kọ Peteru ni ẹkọ ti o n bọ wa di mimọ fun un: “Kili eyi ni si ọ? iwọ mā tọ mi lẹhin.” O yẹ ki gbogbo ọkàn ti o ba fẹ iye ainipẹkun kọ ẹkọ yii pe, ohunkohun ti o wu ki ẹnikẹni le ṣe, iwọ le dopin ire-ije naa – o gbọdọ de opin ire-ije naa!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni awọn ohun wọnni ti o wà ninu ipe ti a kọ pe Peteru lati maa tọ Jesu lẹyin?

  2. 2 Lọna wo ni lilọ pa ẹja ti Peteru lọ pa ẹja lẹẹkeji fi yapa si ipe yii?

  3. 3 Ẹja melo ni awọn ọmọ-ẹyin pa ni oru ọjọ naa ki wọn to ri Jesu? Melo ni wọn pa lẹyin ti wọn ri I?

  4. 4 Awọn ọmọ-ẹyin melo ni wọn wà nibẹ nigba ti Jesu fi ara hàn fun wọn ni akọkọ?

  5. 5 Ta ni awọn ọmọ Sebede?

  6. 6 Ki ni iṣẹ ti wọn n ṣe ki Jesu to pe wọn?

  7. 7 Ki ni iwọ ro pe Jesu n tọka si nigba ti O wi pe, “Iwọ fẹ mi jù awọn wọnyi lọ bi?”

  8. 8 Ki ni Jesu sọ nipa igbẹyin Peteru?

  9. 9 Ki ni ero ọkàn Jesu ti O fi wi pe, “Bi emi ba fẹ ki O duro titi emi o fi de, ki li eyi ni si ọ?”

  10. 10 Ewo ni o pọ ju ni iye ninu iṣẹ Jesu ti a kọ silẹ ati eyi ti a kò kọ silẹ?