Luku 24:49-53; Matteu 28:16-20; Marku 16:15-20

Lesson 252 - Senior

Memory Verse
“Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ lọ; Li orukọ mi ni nwọn o ma lé awọn ẹmi èṣu jade; nwọn o si ma fi ède titun sọrọ; Nwọn o si ma gbé ejò lọwọ; bi nwọn ba si mu ohunkohun ti o li oró, ki yio pa wọn lara rara: nwọn o gbé ọwọ le awọn olokunrun, ara wọn ó da” (Marku 16:17, 18).
Cross References

I Ipade Pẹlu awọn Ọmọ-ẹyin

1. Awọn ọmọ-ẹyin lọ si Galili ni àṣẹ Jesu, Matteu 28:7, 10, 16; 26:32; Marku 16:7

2. Olugbala ti o ji dide fara hàn, awọn ọmọ-ẹyin wa fori balẹ fun Un, Matteu 28:17

3. Jesu wi pe, “Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi,” Matteu 28:18; Efesu 1:19-22; Kolosse 2:9, 10

II Aṣẹ Naa

1. A fi iṣẹ ribiribi le awọn ọmọ-ẹyin lọwọ ti i ṣe lati kọ orilẹ-ède gbogbo, Matteu 28:19; Marku 16:15; Luku 24:48

2. Awọn ti o yipada ni lati jẹwọ igbagbọ wọn ni gbangba nipa iribọmi, Matteu 28:19; Marku 16:16; Romu 6:3-6

3. A fi idi ẹkọ Mẹtalọkan Ọlọrun mulẹ ninu ilana iribọmi, Matteu 28:19

4. Amì ati iṣẹ iyanu yoo tẹle iwaasu ati gbigba Ọrọ naa gbọ, ṣugbọn kikọ Jesu Oluwa yoo fa iyà ainipẹkun, Marku 16:16-18; Johannu 3:16-18

III Ẹmi Mimọ ti n fi Agbara Fun Ni

1. Fun aṣeyọri Iṣẹ Nla naa, wọn ni lati gbẹkẹle agbara ti O n ti ọdọ Ọlọrun wa, Luku 24:49; Iṣe Awọn Apọsteli 1:8

2. Ẹmi Mimọ yoo mu gbogbo ẹkọ Jesu wa si iranti wọn; nnkan wọnyi ni wọn yoo si fi kọ araye, Johannu 14:26; Matteu 28:19, 20

3. Jesu goke lọ si ọwọ ọtun Ọlọrun, awọn ọmọ-ẹyin si jade lọ lati jiṣẹ naa, Marku 16:19, 20; Luku 24:50-53; Iṣe Awọn Apọsteli 1:9-14

Notes
ALAYÉ

Jesu Kristi Oluwa wa “Ẹniti a pinnu rè̩ lati jẹ pẹlu agbara Ọmọ Ọlọrun, gẹgẹ bi Ẹmi iwa mimọ, nipa ajinde kuro ninu okú” (Romu 1:3, 4).

Ayọ awọn ọmọ-ẹyin Jesu kò lopin nigba ti ọkàn ati iyè wọn ṣí nipa otitọ ti ajinde Olugbala ati Oluwa wọn. Lẹẹkan si, Oluwa ati Ọba wọn n ba wọn rin O si n ba wọn gbé. Ọkàn awọn ọmọ-ẹyin a maa kún fun ayọ ati ifẹ nigba ti wọn ba ri Jesu laaarin wọn lojiji, nigba ti wọn ba n ṣe ipade ninu ahamọ pẹlu ilẹkun ti a sé gbọningbọnin ki ẹnikẹni má baa le wa yọ wọn lẹnu. S̩ugbọn Jesu Kristi kò wa saarin wọn bi alatojubọ. O wa sọdọ awọn wọnni ti wọn fẹ ri I ti wọn si n ṣafẹri ibukun Rè̩.

Wọn N Kẹkọọ

S̩aaju igba ti wọn kan Jesu mọ agbelebu, Oun a maa tẹ ẹ mọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ leti lemọ-lemọ pé Ijọba Oun ki i ṣe ti aye yii, ati pe lai pẹ, Oun yoo pada sọdọ Baba Rè̩ ti o wà ni Ọrun. O sa ipa Rè̩ lati fi oye eto Ijọba Rè̩ ati ti igba Ihinrere yé awọn ọmọ-ẹyin, ṣugbọn iyè awọn eniyan wọnyi kò ṣi to lati mu ki oye gbogbo ilana Ọlọrun ki o ye wọn lẹẹkan ṣoṣo, bi o tilẹ jẹ pe wọn ti n tẹle Oluwa tọkàn-tọkàn. S̩ugbọn akoko igoke-re Ọrun Rè̩ kù si dẹdẹ, nitori naa O sọ ọrọ ikẹyin Rè̩ láyé fun awọn ọmọ-ẹyin, O si fi majẹmu Rè̩ le wọn lọwọ. Jesu sọ fun wọn tẹlẹ lati maa n ṣo si Galili, nibẹ, ti i ṣe ibi ti a gbe pe ọpọ ninu awọn ọmọ-ẹyin ni O gbé fi Iṣẹ Nla le wọn lọwọ, O si ṣe alaye yekeyeke nipa iṣẹ ti yoo gba gbogbo igbesi aye awọn ọmọ-ẹyin wọnni, awọn ti n bọ wa di ẹni ti yoo maa jà gidigidi fun Igbagbọ ati onigboya ọmọ-ogun ti Ihinrere Jesu Kristi.

Iṣẹ ti Jesu fi le awọn ọmọ-ẹyin lọwọ tobi lọpọlọpọ, ani o tobi to bẹẹ ti kò le ṣe e ṣe lai si agbara ati iranwọ Olutunu nì, Ẹni kẹta Mẹtalọkan, Ẹni ti Jesu ti ṣeleri lati ran lati Ọrun wa. Wọn ni lati kọkọ ni ohun kin-in-ni ná, nitori naa Jesu paṣẹ fun wọn lati duro ni Jerusalẹmu titi “a o fi fi agbara wọ nyin, lati oke ọrun wa.” Nigba ti wọn ba ti gba agbara Ẹmi Mimọ, awọn ọmọ-ẹyin yoo ni ihamọra tootọ lati ṣe iyoku iṣẹ wọn.

Ohun danindanin ni o jẹ fun awọn ọmọ-ẹyin lati ni ibarẹ ati ibalo Ọlọrun Baba nigba gbogbo. Ẹmi Mimọ ni yoo jẹ Agbọrọsọ, O si n ṣiṣẹ yii ati awọn iṣẹ miiran titi di oni-oloni. “Nigba ti on, ani Ẹmi otitọ ni ba de, yio tọ nyin si ọna otitọ gbogbo: nitori ki yio sọ ti ara rè̩; ṣugbọn ohunkohun ti o ba gbọ, on ni yio ma sọ: yio si sọ ohun ti mbọ fun nyin. On o ma yìn mi logo: nitoriti yio gbà ninu ti emi, yio si ma sọ ọ fun nyin” (Johannu 16:13, 14). Awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wọnyi fi hàn bi o ti ṣe danindanin tó lati gba Olutunu Mimọ naa sinu ọkàn lati maa tọ wa ati lati maa ṣe amọna wa. A ni lati maa tọ Ọ lẹyin bi a ba fẹ ṣe aṣeyọri rara ninu ire-ije igbagbọ.

Olugbala Alagbara

Gbolohun ti Jesu fi bẹrẹ ọrọ i sọ pẹlu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni Galili ṣe pataki, o si nipa lọpọlọpọ, nitori ti O sọ bayi pe, “Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi” (Matteu 28:18). Ọrọ yii nipọn gidigidi – gbogbo agbara ti a le wi pe Ọlọrun ni, Jesu paapaa ni i. Kò ni i ṣoro fun ọkàn ti o gbagbọ lati gba eyi gbọ, nitori ti Onigbagbọ tootọ mọ daju pe Ọmọ Ọlọrun ni Kristi i ṣe, O si ba Ọlọrun dọgba ninu agbara ati aṣẹ. Ki i ṣe pe Jesu ni agbara nikan, O fi diẹ ninu agbara yii wọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lati maa fi ṣiṣẹ ti Ijọba Ọlọrun, O si tun n fi agbara fun awọn ti “a pè, ti a yàn, ti o ṣe olóòótọ” lati maa ba iṣẹ Ijọba Ọlọrun lọ ni igba ti wa yii. Jesu ki i ṣe ojusaju eniyan. O pe ọkunrin, obinrin ati ọmọde lati maa ba A rin; Oun yoo gba wọn nigba ti wọn ba fi gbogbo ọkàn wọn jẹ ipe naa. Oun a maa fun wọn ni oore-ọfẹ, ogo ati agbara lati ran wọn lọwọ lati jẹ olóòótọ.

Bawo ni a ṣe ni lati lo agbara ti Ọlọrun fi fun awọn ọmọ-ẹyin wọnyi? Wọn ha gbọdọ maa fi ipa ṣe akoso Ijọ ati orilẹ-ède ti o ba wa labẹ wọn nipa iṣẹ iranṣẹ wọn? Rara o. Ohun ti wọn ni lati ṣe ni pe ki wọn lọ si gbogbo agbaye lati maa waasu Ihinrere ati lati maa kọ ni. Ẹkọ ti wọn ni lati fi kọ ni ni eyi ti awọn ọmọ-ẹyin ti kọ lọdọ Kristi, ẹkọ yii yoo si da awọn eniyan nide kuro ninu igbekun è̩ṣẹ. A kò fi le awọn ọmọ-ẹyin lọwọ lati kede Ihinrere fun awọn ọmọwe ki wọn si fi awọn ti kò mọwe silẹ; wọn kò gbọdọ bẹ awọn ilu ọlaju wo ki wọn si gbagbe awọn Keferi; a kò gba wọn laye lati lọ si awọn ilu wọnni ti o yá si wọn lẹsẹ nikan ki wọn si ṣe alainaani awọn ilu ti o ṣoro lati de. A paṣẹ fun wọn lati waasu fun gbogbo eniyan – nibikibi ti a gbe le ri wọn, lai naani ohunkohun ti yoo gbà wọn, i baa ṣe agbara, owo tabi ohunkohun miiran ti o wa ni ikawọ wọn.

Iṣẹ Onigbagbọ

I ha ṣe awọn ọmọ-ẹyin mọkanla wọnni nikan ni a fi iṣẹ yii le lọwọ, tabi iṣẹ naa ha i ṣe eyi ti o kan ẹni kọọkan ti i ṣe ọmọlẹyin Kristi? Lai si aniani ti gbogbo awọn ọmọlẹyin Kristi ni iṣẹ yii. Baba wa ati Olugbala wa mọ ibi ti ipa eniyan mọ, kò si jẹ beere pe ki a ṣe ohun ti kò ṣe e ṣe. A kò le nireti pe awọn eniyan mọkanla wọnyi pere yoo le waasu fun gbogbo eniyan ni gbogbo agbaye; ṣugbọn nigba ti a ba waasu Ihinrere tọkantọkan, a o ni awọn ọmọ ẹyin titun pẹlu ti yoo tun gba iṣẹ naa pẹlu, Ijọba naa yoo si maa dagba sii titi a o fi mu ipinnu ti o wà ninu aṣẹ yii ṣẹ patapata.

Jesu ṣeleri pe, “Kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye.” Awọn ọmọ-ẹyin kò ni wa laaye ninu aye titi laelae. Jesu ti mu idalẹbi è̩ṣẹ kuro ninu igbesi aye wọn, ṣugbọn idajọ ikú ti i ṣe ti gbogbo eniyan wa sibẹsibẹ. Ki ni itumọ ohun ti Jesu sọ nihin bi kò ṣe eyi pe, Iṣẹ Nla yii kan gbogbo iran Onigbagbọ? Iṣẹ yii jẹ ọranyan fun gbogbo awọn Ọmọ Ọlọrun lọjọ oni, bi o ti ri fun awọn ọmọ-ẹyin mọkanla wọnni lẹyin igoke-re-Ọrun Jesu.

“Ọlọrun kò ran awọn angẹl’

Lati waasu ’hinrere,

Awọn t’a gba lọwọ iku

L’O ran lati sọ ’tan ’yanu yi.

Kò yipada lat’ayeraye,

Awọn ẹgbẹ olootọ

L’o n sọ ’tan didun t’ifẹ Jesu,

At’ ọna ’rapada.”

Ihinrere ti O Lagbara

Ihinrere ti Ijọba Ọrun jẹ Ihinrere ti o lagbara. Jesu ni Olupilẹṣẹ ati Alaṣepe igbagbọ wa; igbagbọ tootọ ninu Ọmọ Ọlọrun yoo ṣe ohun ribiribi ati ohun iyanu pupọ. Jesu fi yé awọn ọmọ-ẹyin pe iṣẹ iyanu yoo maa ṣe bi wọn ti n waasu Otitọ. Li orukọ Jesu ni wọn yoo maa lé ẹmi èṣu jade kuro lara awọn eniyan; bi awọn ọmọ-ẹyin ba ṣeeṣi gbé ejò, tabi bi wọn ba ṣeeṣi mu ohun ti o ni oró, ki yoo le pa wọn lara. Pẹlupẹlu wọn yoo fi ède titun sọrọ, wọn yoo si gbe ọwọ le alaisan, “adura igbagbọ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide” (Jakobu 5:15). Iru agbara iṣẹ iyanu kan naa ti o fara hàn ninu Ọmọ Ọlọrun yoo fara hàn ninu awọn ọmọ-lẹyin Rè̩ tootọ.

Jesu Kristi, Ọkan naa lana, loni, ati titi lae; Ọrọ Rè̩ kò yipada, yoo si wa bẹẹ titi ayeraye. Awọn pupọ le fẹ ki a gbagbọ pe iṣẹ iyanu ti Ihinrere ti dasẹ nigba ti a fi ẹsẹ Ijọ ti iṣaaju mulẹ patapata – ati pe iṣẹ iyanu ṣe, a si fun wọn ni Agbara Ẹmi Mimọ lati le fi idi Ijọ akọkọ mulẹ daradara, ṣugbọn nisisiyi, iru nnkan bawọnni kò si mọ. Eyi lodi si otitọ patapata, nitori pe igbagbọ aaye tootọ ninu Ọlọrun yoo mu ki iru ohun kan naa ti o ṣẹlẹ ninu Ijọ igba nì ṣẹlẹ ni igbesi-aye awa naa pẹlu. A ti fi oju ri ọpọlọpọ iṣẹ iyanu ninu Ihinrere ti Arọkuro Ojo yii, iru eyi ti o tẹle iwaasu Ihinrere lẹyin ọjọ nla Pẹntekọsti, ani kò tilẹ lonkà. Bi eniyan ba ti gba Ọlọrun laaye to ni Ọlọrun yoo fi le ṣiṣẹ fun wọn to; nitori naa má ṣe diwọn agbara Ọlọrun tabi ti Ọmọ Rè̩.

Iribọmi

Iribọmi fun awọn wọnni ti a ti gbala kuro ninu è̩ṣẹ wọn atijọ wà ninu Iṣẹ Nla nì. Ilana yii ṣe apẹẹrẹ ikú, isinku ati ajinde ologo Jesu. (Wo Romu 6:3-6). Eyi jé̩ ijẹwọ ti ode gbangba nipa iṣẹ irapada oore-ọfẹ ti Ọlọrun ti ṣe ninu ọkàn. Awọn ti o ni iyipada ọkàn ni a n ṣe iribọmi fún. Isinkú fi hàn pe ẹni naa ti kú, a kò le sin ẹni ti kò ti i di okú si è̩ṣẹ pẹlu Kristi nipa iribọmi.

Ọna ti Bibeli là silẹ nipa iribọmi ni pe ki a rì wa sinu omi. Itumọ ọrọ ti a tumọ si baptismu ni pe ki a rì nnkan bọmi tabi ki a mookun. O ni lati jẹ pe Johannu Baptisi n rì awọn eniyan bọ omi ni, nitori pe o lọ si ẹkun Jẹriko nibi ti o gbe ri omi pupọ (Johannu 3:23). Johannu ni o rì Jesu bọ omi, a si ka a pe, “Nigbati a si baptisi Jesu tan, o jade lẹsẹkanna lati inu omi wá” (Matteu 3:16). Ki O to jade lati inu omi, eyi fi hàn pe O ti wọ inu omi lọ tẹlẹ.

O ni lati jẹ pe ilana ti awọn Apọsteli tẹlẹ ni pe ki a maa rì awọn eniyan sinu omi. Nigba ti Filippi ri iwẹfa ti o yipada nipasẹ iṣẹ iranṣẹ rè̩ bọ omi, “awọn mejeji si sọkalẹ lọ sinu omi, ati Filippi ati iwẹfa: o si baptisi rè̩” (Iṣe Awọn Apọsteli 8:38). Awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wọnyi kò ha tó lati fi idi rè̩ mulẹ pe rírìbọmi ni ọna ti o tọ lati gba ṣe baptismu?

Mẹtalọkan Mimọ

Otitọ Mẹtalọkan fara han kedere ninu ilana iribọmi. A paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹyin lati maa baptisi “li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ ati ni ti Ẹmi Mimọ” -- Ẹni Mẹta ninu Ọlọrun kan ṣoṣo, ṣugbọn baptismu kan ṣoṣo!

Nigba ti a baptisi Jesu, awọn Ẹni mẹta ti o wà ninu Mẹtalọkan ni o wà nibẹ. Jesu Kristi, ti i ṣe Ọmọ mu ilana naa ṣẹ; Baba ni Ọrun si jẹri si otitọ naa bayii pe, “Eyi ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi” (Matteu 3:17); Ẹmi Mimọ ti i ṣe Ẹmi Ọlọrun si sọkalẹ bi adaba, o si ba le Jesu (Matteu 3:16). Iribọmi Jesu ni apẹẹrẹ baptismu ti olukuluku Onigbagbọ ni lati tẹle, bi o tilẹ jẹ pe ẹni ti Ọlọrun gba ọkàn rè̩ là ti o si tẹle ilana yii le má fi oju ara ri ohun ribiribi kan, tabi ki o fi eti ti ara yii gbọ ohùn kan lati fọ si i, sibẹsibẹ Ọlọrun Mẹtalọkan ti jẹri si otitọ yii pe ẹni naa ti mu ilana yii ṣẹ. “Ẹni mẹta li o n jẹri li ọrun, Baba, Ọrọ ati Ẹmi Mimọ: awọn mẹtẹta yi si jasi ọkan” (I Johannu 5:7). Gbogbo Onigbagbọ ni o ni lati mu ilana iribọmi yii ṣẹ ni kete ti anfaani ba ṣi silẹ fun wọn lati ṣe bẹẹ, nitori pe bi eniyan ba fi ainaani mọọmọ fi eyikeyi ninu ofin Ọlọrun jafara, iyapa kuro lọdọ Ọlọrun ni yoo yọri si.

A fun ni ni Iṣẹ Nla yii lati ṣe ki Ihinrere Jesu Kristi le tàn jakejado gbogbo aye. Ki i ṣe gbogbo eniyan ni a pe lati tan Ihinrere kalẹ lọna kan naa, ṣugbọn nigba ti eniyan ba fi tinutinu rè̩ sin Ọlọrun pẹlu gbogbo ọkàn ati ayà rè̩, ọna ti yoo gba lati tan Ihinere kalẹ yoo hàn gbangba. Nigba ti ifẹ ati ọna Ọlọrun ba di mímọ, nigba naa yoo jẹ ayọ ati inu didun Onigbagbọ lati tẹle e.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nibo ni a fi adehun si fun awọn ọmọ-ẹyin lati pade Jesu lẹyin ajinde?
  2. Awọn wo ni a paṣẹ pe ki awọn ọmọ-ẹyin waasu fun?
  3. Ninu agbara wọn ni wọn ha ni lati ṣe eyi? Ki ni ṣe ti a paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹyin lati duro ni Jerusalẹmu?
  4. Awọn àmì wo ni n tẹle iwaasu Ọrọ naa?
  5. Ki ni itumọ Ilana Iribọmi? Awọn ta ni a ni lati ṣe e fun?
  6. Awọn ọmọ-ẹyin mọkanla igba nì nikan ni awọn Onigbagbọ ti a fi Aṣẹ Nla nì le lọwọ bi?
  7. Titi di igba wo ni Jesu ṣeleri lati wa pẹlu awọn ọmọ-ẹyin?
  8. Ki ni ṣẹlẹ lẹyin ti Jesu ti sure fun awọn ọmọ-ẹyin tan?