Iṣe Awọn Apọsteli 1:1-26

Lesson 253 - Senior

Memory Verse
Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bḝ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si ọrun” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:11).
Cross References

I Awọn Aṣẹ Ikẹyin ti Jesu fi Fun awọn Ọmọ-ẹyin

1. Ihinrere ti Luku sọ nipa ẹkọ Jesu ati iṣẹ Rè̩ titi de igba igoke-re-Ọrun Rè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 1:1, 2; Luku 1:3; Marku 16:19

2. Jesu fi ara Rè̩ hàn laaye fun ogoji ọjọ, O n ba awọn ọmọ-ẹyin sọrọ nipa Ijọba Ọlọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 1:3; Marku 16:14; Luku 24:36; Johannu 20:19

3 O paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹyin lati duro de ileri Baba, Iṣe Awọn Apọsteli 1:4, 5; Johannu 14:16

4 Awọn ọmọ-ẹyin beere nipa ijọba Israẹli, Iṣe Awọn Apọsteli 1:6; Matteu 24:3

5 A sọ fun awọn ọmọ-ẹyin pe Baba nikan ni o le sọ nipa ohun ti wọn n fẹ mọ, Iṣe Awọn Apọsteli 1:7; I Tẹssalonika 5:1; Marku 13:32

6 A o fi agbara fun awọn Ọmọ-ẹyin, wọn yoo si jẹ ẹlẹri fun Kristi, Iṣe Awọn Apọsteli 1:8; 2:1-4; Luku 24:48; Johannu 15:26, 27

II Igoke-Re-Ọrun Jesu

1. A gba Jesu lọ soke Ọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 1:9

2. Awọn angẹli meji sọ ileri ipadabọ Jesu lẹẹkeji, Iṣe Awọn Apọsteli 1:10, 11; Daniẹli 7:13; Matteu 24:30; Marku 13:26; Luku 21:27; Johannu 14:3; I Tẹssalonika 1:10; 4:16

III Yiyàn Apọsteli Kan

1. Lẹyin ipadabọ lati ori oke Olifi awọn ọmọ-ẹyin tẹra mọ adura ati ẹbẹ, Iṣe Awọn Apọsteli 1:12-14

2. A yàn Mattia lati gba ipo Judasi, Iṣe Awọn Apọsteli 1:15-26; Orin Dafidi 69:25; 109:8

Notes
ALAYÉ

Luku fun ni ni akọsilẹ kikun ninu Ihinrere ti o kọ nipa iṣẹ iyanu ati awọn ẹkọ Jesu lati igba ibi Rè̩ titi O fi goke re ọrun. S̩ugbọn ninu Iṣe Awọn Apọsteli, Luku bẹrẹ lati igoke-re-ọrun Jesu ati iṣẹ awọn Apọsteli.

Jesu ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pejọ pọ fun ogoji ọjọ lẹyin ajinde, O n ba wọn sọrọ, O si n ba wọn jẹun. O fi hàn dajudaju pe Oun wa laaye sibẹ lẹyin ikú oro Rè̩ lori igi agbelebu ati sisin ti a sin In sinu iboji. Nipa ohun ti Jesu ṣe ati awọn ọrọ ti O sọ lẹyin ajinde Rè̩, O mu gbogbo iyemeji kuro lọkàn awọn ọmọ-ẹyin, O si fidi rè̩ mulẹ pe Oluwa wọn ati Olugbala wọn ti o jinde ti a si ṣe logo wà laaye titi lae.

Ajinde kuro ninu okú ni koko pataki ti Ihinrere rọ mọ. Nipa ọpọlọpọ ifarahan fun awọn ọmọ-ẹyin, Kristi kọ otitọ ajinde si wọn lọkàn lọna ti kò le paré̩, to bẹẹ ti a mu gbogbo aigbagbọ kuro lọkàn wọn patapata. Otitọ ni o hàn si wọn kedere yii. Wọn ti ri I ni ojukoju. Wọn ri ami iṣo ni ọwọ ati ni ẹsẹ Rè̩, ati àpa ọkọ ni ẹgbẹ Rè̩. O ba wọn sọrọ. Wọn ri i pe Oun ni Jesu kan naa ti O bọ ọpọlọpọ eniyan, ti O ji okú dide, ti O wẹ adẹtẹ mọ kuro ninu ẹtè̩ wọn, ti O si la oju afọju. Nisisiyi O wà laaye titi laelae, ani Jesu kan naa ti n ṣiṣẹ iyanu.

Ọran Ijọba Ọrun

Lẹyin ajinde, o dabi ẹni pé oye otitọ Ihinrere tete yé awọn ọmọ-ẹyin. S̩ugbọn sibẹ, ero ijọba ti aye yii kò ti i kuro lọkàn wọn: pe ki a mu Israẹli pada bọ si ipo orilẹ--ède ti o di ominira, ki awọn paapaa tilẹ lè ni ipo kan ninu akoso ijọba naa.

Awọn ọmọ-ẹyin beere pe, “Iwọ ó ha mu ijọba pada fun Israẹli bi?” S̩ugbọn Jesu dahun wi pe, “Ki iṣe ti nyin lati mọ akoko tabi igba ti Baba ti yàn nipa agbara on tikararè̩.” O n tọka wọn si Ijọba tootọ, O n fa ọkàn wọn kuro ninu ohun ti aye si ohun ti ọrun, kuro ninu ijọba ti aye yii si Ijọba ti Ọrun.

Imurasilẹ Si i lati S̩iṣẹ

Aṣẹ ti Oluwa pa fun awọn ọmọ-ẹyin kẹyin ni pe ki wọn maṣe kuro ni Jerusalẹmu, ki wọn duro de ileri Baba ti yoo ba le wọn. Jesu fi ye wọn pe Oun n lọ, ati pe Olutunu n bọ wa. O wi fun wọn pe a o baptisi wọn pẹlu Agbara Ẹmi Mimọ ati iná lai pẹ jọjọ. O n fi wọn silẹ, ṣugbọn wọn yoo ni Olutunu miiran -- Ẹni ti yoo maa bá wọn gbe titi lae. Bi o ba ṣe danindanin fun awọn ọmọ-ẹyin ni ọjọ nla nì lati duro de ifiwọni agbara ti Baba ti ṣeleri, dajudaju o ṣe danindanin fun wa pẹlu pe ki a duro ki a si ṣafẹri rè̩ titi a o fi ni iru agbara kan naa ninu igbesi aye wa.

Awọn ojiyan diẹ n sọ fun ni pé awọn Ijọ igba nì nikan ni ifiwọni Ẹmi Mimọ wa fun. S̩ugbọn Iwe Mimọ sọ fun ni pe, “Fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jina rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè.” Nigba ti Peteru n waasu ni ọjọ Pẹntekọsti, o ka akọsilẹ ohun ti Joẹli sọ nipa pe Oluwa tikara Rè̩ ti ṣeleri lati tú Ẹmi Rè̩ jade sara eniyan gbogbo (Joẹli 2:28). Iwọ ha ti gba Olutunu nì lati igba ti iwọ ti gbagbọ?

Awọn Ẹlẹrii Kristi

“Ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmi Mimọ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalẹmu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye.” Jesu fi iṣẹ-iranṣẹ Rè̩ mọ ni ọdọ awọn Ju nikan, ki a ba le mu ipinnu Ọlọrun nipa wọn ṣẹ. S̩ugbọn awọn Ju, gẹgẹ bi orilẹ-ède kò gba A ati iṣẹ ti O mu wa pẹlu. S̩ugbọn O fun awọn ti o gba A ni aṣẹ lati lọ si gbogbo aye ki gbogbo eniyan – ati Ju ati Keferi – le gbọ Itàn ayọ naa.

Nigba ti a ran awọn aadọrin (70) jade, Jesu paṣẹ fun wọn ki wọn ki o má ṣe lọ si ọna awọn Keferi, wọn kò si gbọdọ lọ si ilu awọn ara Samaria. Idi rè̩ ni pe ki awọn Ju le ni anfaani lati gba Ihinrere ki wọn si duro ni àyè ti Ọlọrun ti pé wọn si. S̩ugbọn nisisiyi awọn ọmọ-ẹyin ri i pe iṣẹ ti a fi le wọn lọwọ ti tobi sii. Wọn ni lati lọ si gbogbo agbaye nisisiyi ki wọn si waasu Ihinrere fun gbogbo ẹda.

Awọn ọmọ-ẹyin lọ si ibi ti aye pẹkun si niwọn iba imọ ti wọn ni nigba naa nipa gbigbooro aye. Wọn jolootọ si iṣẹ ti a fi le wọn lọwọ. Iwe itan sọ fun ni pe ọpọlọpọ wọn ni o kú bi ajẹrikú ni ilu okeere ti o jinna réré si Jerusalẹmu. Ẹ wo bi eyi ti jẹ ẹri ti o daju tó nipa ifẹ gbigbona ati itara ti wọn ni lati mu aṣẹ Jesu ṣẹ patapata! Iru itara wo ni iwọ ni fun itankalẹ Ihinrere?

Igoke-Re-Ọrun

Lẹyin ti Jesu ti paṣẹ yii ti O si ti ṣeleri yii tán fun awọn ọmọ-ẹyin wi pe ki wọn duro ni Jerusalẹmu ki wọn gba ileri Baba ti O ti ṣeleri lati fi fun wọn, O gbe ọwọ Rè̩ soke, O si sure fun wọn. A kò sọ awọn ọrọ ti O fi sure ikẹyin yii fun ni, ṣugbọn o ni lati ṣọwọn fun wọn gidigidi. Eyi ni Amin ikẹyin si gbogbo ẹkọ Rè̩ ati awọn ọrọ ti O ti sọ. Bi O ti n súre fun wọn, ẹsẹ Rè̩ bẹrẹ si ká kuro nilẹ, O si bẹrẹ si goke lọ si Ọrun, eyi ni arimọ ti awọn ọmọ-ẹyin ri I ni gbogbo igbesi ayé wọn lori ilẹ aye.

Awọn ọmọ-ẹyin rii pe Jesu n goke lọ. Wọn tẹju mọ Ọn titi awọsanmọ fi gba A kuro ni oju wọn. Jesu kò nù mọ wọn loju bi Oun ti maa n ṣe lẹyin ajinde Rè̩ nigbakuugba ti o ba ṣe tan lati lọ lẹyin ti O fara han wọn. Ni akoko yii, O n lọ si Ọrun, ki i ṣe pe O nù mọ wọn loju lati tun fi ara hàn wọn nigba miiran. O ṣe pataki fun wọn lati ri I lojukoju bi O ti goke lọ fun ẹri ti o daju fun gbogbo iran ti o n bọ lẹyin. Iṣẹ ti Jesu wa ṣe laye tikara Rè̩ ti pari fun saa kan. O fi iṣẹ iyoku le awọn ọmọ-ẹyin lọwọ. Wọn tẹju mọ Ọn titi oju wọn ko fi ri I mọ -- wọn mọ wayii pe Oluwa wọn ti lọ.

S̩ugbọn lẹsẹkẹsẹ ni ohun iyanu miiran tun ṣẹlẹ. Awọn angẹli meji duro ti wọn, wọn si sọ fun wọn pe, “Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bḝ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si ọrun.” Jesu naa yii! Jesu kan naa ti wọn ti ba lo, ti wọn ti ba jẹ, ti wọn ti ba mu, yoo tun pada wa si aye yii!

Jesu Olugbala wa fi ẹsẹ mimọ Rè̩ kanlẹ leti Oke Olifi fun igba ikẹyin titi ọjọ ologo nì yoo fi de, nipa eyi ti Woli Sekariah sọ fun ni, ani nigba ti awọn ẹsẹ ologo Rè̩ yoo tun kanlẹ lori oke mimọ ti kò-ni-gbagbe yii, yoo si pin si meji, apa kan yoo sún si iha ariwa, apa keji yoo si sún si iha gusu. (Ka Sekariah 14:3-11).

“Jesu goke re Ọrun

Lati Oke Olifi

O w’ọnu awọsanma

Pẹl’ogo nla,

S̩ugbọn angẹl’ wa sọrọ

’Tunu yi pe,

Y’o tun padabọ bẹ

Gẹgẹ nigbooṣe.”

Ireti yii ti logo pọ to! Ireti yii ti dara pọ to! Itanṣan ireti yii ni o n jo geere-geere ninu ọkàn gbogbo Onigbagbọ tootọ ni ọjọ oni, eyi si jẹ orisun itunu ni ọkàn gbogbo Onigbagbọ (I Tẹssalonika 4:18).

Awọn Iṣẹlẹ Abami

Ohun iyanu pupọ ha kọ ni awọn ọmọ-ẹyin onirẹlẹ ara Nasarẹti yii ri laaarin ọjọ diẹ sẹyin! Wọn rii ti a kan Oluwa wọn mọ agbelebu. Ọwọ wọn ni wọn fi té̩ okú Rè̩ si iboji. Iyanu ni o jẹ fun wọn lati rii pe iboji ṣofo ni ọjọ kẹta. Lẹyin eyi, ẹru ba wọn bi O ti yọ saaarin wọn lojiji nigba ti ilẹkun wa ni titi. Nigba kan Jesu tilẹ duro si eti ebute ni afẹmọjumọ lẹyin ti awọn ọmọ-ẹyin ti ṣiṣẹ ni gbogbo oru ti wọn kò si ri ohunkohun pa, ti O si sọ fun wọn pe ki wọn sọ àwọn si apa ọtun ọkọ ti wọn si kó akopọ ẹja.

Ohun iyanu miiran, ti tun ṣẹlẹ loju wọn nisisiyi. Awọn ọmọ-ẹyin wà pẹlu Jesu lori Oke Olifi. O ti ba wọn sọrọ nipa Ijọba Ọrun ati nipa Ẹmi Mimọ ti O n bọ wa lati fun wọn ni agbara ati lati tọ wọn si otitọ gbogbo. Lojiji O gbe ọwọ Rè̩ soke O si sure fun wọn, lẹyin eyi, O si goke re Ọrun. Wọn n wo O bi O ti n goke lọ titi awọsanma fi gba A kuro ni oju wọn, lẹyin eyi wọn gbọ ohun ti awọn angẹli nì ti wọn duro nibẹ wi. Ireti ologo yii rú ifẹ ọkàn wọn soke, wọn si pada si Jerusalẹmu lati duro de agbara ti a ti ṣeleri rè̩ fun wọn.

Yiyan Arọpo Judasi

Awọn ọmọ-ẹyin wọ yara oke lọ ni Jerusalẹmu. O le jẹ pe nibẹ ni wọn gbe jẹ Ounjẹ -- Alẹ ikẹyin, ti Jesu si wẹ ẹsẹ wọn. Awọn Apọsteli mọkanla, ati Maria iya Jesu, ati awọn arakunrin Rè̩, ati awọn miiran -- wọn jẹ ọgọfa ni apapọ, awọn ti wọn fẹ Jesu ti wọn si ti n tọ Ọ lẹyin -- wà nibẹ. Wọn wà ninu ẹbẹ ati adura fun ọjọ mẹwaa.

Peteru woye pe o yẹ ki a yàn ẹni kan dipo Judasi, ẹni ti o ṣubu nipa irekọja. Ọrọ awọn woli nipa Judasi ni Peteru gun le. Bi oye wọn ti mọ nigba nì, awọn ọmọ-ẹyin yan eniyan meji, Barsaba ati Mattia, lẹyin ti wọn si ti gbadura ki Oluwa ki o tọ wọn lati yan, ki ifẹ Rè̩ ki o le ṣẹ, wọn si dibo. Ibo si mu Mattia.

Aye Judasi ṣofo, lai si aniani awọn ọmọ-ẹyin ni lati mọ ọn lara pe o tọ lati di afo yii. Judasi ni o n ṣe akapo wọn, ẹni kan si ni lati tun mu iṣẹ yii ṣe lati maa ṣe abojuto aini awọn eniyan Ọlọrun. S̩ugbọn a ri imuṣẹ ifẹ Ọlọrun nipa yiyan Paulu bi Apọsteli lati ọwọ Ọlọrun. Kò si iyemeji rara wi pe Apọsteli ni Paulu i ṣe nitori pe Ẹmi Mimọ jẹri si eyi nibi pupọ ninu awọn Episteli.

Bawo ni yoo ti dun to bi awọn eniyan ni orilẹ-ède wa ba le gbadura gẹgẹ bi awọn Mọkanla nì, ki wọn si beere pe ki Ọlọrun dari wọn nipa yiyan awọn oṣelu ati awọn aṣofin ilẹ wa! Bi gbogbo ayé tilẹ dimọ pọ, wọn ki yoo le bori wa nigba naa nitori pe ifẹ Ọlọrun ni a n ṣe. S̩ugbọn gẹgẹ bi ẹni kọọkan a ni lati rii pe a n gbadura, a si fara mọ Ọlọrun lati maa tọ iṣisẹ wa ninu ohun gbogbo ti a n ṣe lọjọọjọ bi o ti wu ki ohun naa kere to. Bi a ba ṣe bẹẹ Oun yoo maa tọ iṣisẹ wa, nitori pe “a ṣe ilana ẹsẹ enia lati ọwọ Oluwa wá” (Orin Dafidi 37:23).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nibo ni Jesu ati awọn ọmọ-ẹyin gbe pejọ pọ si ni akoko iṣẹlẹ ikẹyin yii?
  2. Ki ni ọrọ ti wọn sọ nigba yii duro le lori?
  3. Ki ni ohun ti awọn ọmọ-ẹyin beere? Ki ni a fi dá wọn lohun?
  4. Sọ nipa bi Jesu ti sure ikẹyin fun awọn ọmọ-ẹyin ati igoke-re-Ọrun Rè̩.
  5. Kọ ọrọ ti angẹli nì sọ sori.
  6. Lẹyin igoke-re-ọrun, nibo ni a o gbe waasu Ihinrere?
  7. Ta ni a yàn ni akoko yii gẹgẹ bi Apọsteli dipo Judasi? Ta ni Ọlọrun yan si aye yii nikẹyin?