I Awọn Ọba 1:5-53; 2:1-12

Lesson 254 - Senior

Memory Verse
“Ododo ni igbé orilẹ-ède leke; ṣugbọn è̩ṣẹ li è̩gan orilẹ-ède” (Owe 14:34).
Cross References

I Iṣọtẹ Adonijah

1. Ilepa Adonijah lati jọba nipo Dafidi lodi sí ofin, o si jẹ iwa ọdalẹ ju lọ, ati pẹlu, o jẹ iṣọtẹ si Ọlọrun, I Awọn Ọba 1:5-10; II Samuẹli 3:2-4; Owe 29:15; 25:27; Obadiah 4; Matteu 23:12

2. Bibẹ ti Natani ati Batṣeba bẹ Dafidi wo nigba aisan rẹ ṣe idiwọ fun iṣọtẹ rè̩, I Awọn Ọba 1:11-27

II Sọlomọni, Ọba ti Ọlọrun Yàn

1. O hàn gbangba pé yiyan Sọlomọni lati ọwọ Ọlọrun ti di mimọ fun awọn ẹlomiran ṣiwaju ọtẹ naa, I Awọn Ọba 1:9-12, 17, 26, 27; I Kronika 22:9, 10; 28:5-7

2. Dafidi, ni igbẹkẹle ileri Ọlorun ti o daju, ti ṣeleri fun Batṣeba pe ọmọ wọn yoo jọba, I Awọn Ọba 1:28-31

3. Dafidi fi Sọlomọni jọba gẹgẹ bi ofin ki Adonijah to fi idi ijọba rè̩ mulẹ, I Awọn Ọba 1:32-40; I Kronika 23:1

4. Igbesẹ ti Dafidi gbe yii, ni igbọran si ọrọ Ọlọrun, fi opin si iṣọtẹ naa, I Awọn Ọba 1:41-49

5. Ohun kin-in-ni ti Sọlomọni ṣe gẹgẹ bi ofin ni lati fi oju-aanu wo Adonijah ti o ronupiwada patapata, I Awọn Ọba 1:50-53; Owe 3:3; 11:17; Mika 6:8; Matteu 5:7; Luku 6:36; Jakọbu 2:13

III Awọn Ọjọ Ikẹyin Dafidi ati Aṣẹ Rè̩ si Sọlomọni

1. Dafidi gba Sọlomọni niyanju lati gbọran si ofin Ọlọrun, nipa bẹẹ ki ileri Ọlọrun le fi ẹsẹ mulẹ nipa ijọba naa, I Awọn Ọba 2:1-4; Jọṣua 1:8; II Samuẹli 7:12-16; I Kronika 22:11-13; Orin Dafidi 132:12; 89:29-32

2. Dafidi tun sọrọ nipa awọn ẹlẹgbé̩ rè̩, I Awọn Ọba 2:5-9; II Samuẹli 3:27; 16:5-7; 17:27-29; 20:10

3. Dafidi kú, Ọlọrun si fi idi Sọlomọni mulẹ ninu ijọba naa, I Awọn Ọba 2:10-12; I Kronika 29:20-30

Notes
ALAYÉ

Ẹmi Mimọ sọ fun ni nipa akọsilẹ Luku pe Dafidi mọ pe Ọlọrun yoo “mu Kristi wa ijoko lori itẹ rè̩” ati pe Dafidi sọ “ti ajinde Kristi pe, a kò fi ọkàn rè̩ silẹ ni ipò okú, bḝli ara rè̩ kò ri idibajẹ” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:29-31). A mọ pe otitọ ni eyi nipa idahun ti Dafidi fun Ọlọrun nigba ti o ba a da majẹmu nipa Ijọba ayeraye ti Kristi.

Nipasẹ awọn otitọ yii, o di mimọ fun ni pe ijọba lori itẹ Israẹli jẹ ohun pataki. A si mọ pe iyapa kuro ninu ilana Ọlọrun jé̩ iṣọtẹ si Ọlọrun tikara Rè̩, o si buru lọpọlọpọ.

Gbigbe Ara-ẹni Ga

Adonijah “gbe ara rè̩ ga.” Lai si aniani, igbekun ti iwa ti inu ara-ẹni fi de e niyi; iwa abinibi yii kò ṣee ṣakoso. Awọn obi rè̩ pẹlu kò ṣe abojuto rè̩ bi o ti tọ ati bi o ti yẹ nigba ti o wà labẹ akoso wọn. Igberaga jẹ è̩ṣẹ ti ọkàn ọpọlọpọ eniyan n tè̩ si, o si le kó ọpọlọpọ iyọnu ba awọn ti kò ba ṣe akoso ara wọn tabi ti kò gba Ẹmi Ọlọrun laye lati wẹ ẹ nù kuro ninu ọkàn wọn.

Iwe Mimọ kọ ni lati maa gbe Ọlọrun ga. A kọ ni lati bu ọla fun Un, ki a juba Rè̩ ki a si maa sin In. Awọn ti o ba gbe ara wọn ga kò ṣe eyikeyi ninu nnkan wọnyi. Ifẹ ọkàn iru awọn eniyan bayii ti ṣú wọn loju, wọn si jọ ara wọn loju. Wọn kò ni imọ pupọ nipa ohun ti i ṣe ti ayeraye, nitori ohun igba isisiyi ati imọ-tara-ẹni nikan ti kó wọn lẹrú. O yẹ ki o da wọn loju pe abayọrisi iwa wọn yoo yatọ si akọbẹrẹ tabi ohun ti wọn ro pe opin rè̩ yoo jẹ, nitori ti Iwe Mimọ kọ ni pe, “ẹnikẹni ti o ba si gbé ara rè̩ ga, li a o rè̩ silẹ” (Matteu 23:12).

Iṣubu Absalomu kò kọ Adonijah lọgbọn. O tẹle iṣisẹ arakunrin rè̩ ọlọtẹ. Adonijah tako ilana Ọlọrun, nitori pe ohun ti o ṣẹlẹ fi hàn wi pe eto Ọlọrun nipa ẹni ti yoo jọba di mimọ fun awọn ẹlomiran gẹgẹ bi o ti di mimọ fun Dafidi.

Ọdalẹ ni ẹnikẹni ti o ba tako ilana Ọlọrun. Igberaga ni o sún Adonijah si ipo buburu yii. O kọ bẹrẹ pẹlu jijọ ara rè̩ loju, nigba ti eyi si ti fidi mulẹ ninu ọkàn rè̩ nitori ti o gba a laye, kò ṣoro fun un mọ lati ka ara rè̩ si ju bi o ti yẹ lọ, ki o si maa gberaga si awọn ẹlomiran titi o fi gberaga si baba rè̩ paapaa -- ẹni ami-ororo Oluwa.

Adonijah ṣe arẹwa ọkunrin. O ni ọgbọn lati ṣe akoso. Ọlọrun i ba lo o gidigidi ninu ijọba ilẹ naa bi o ba ṣe pe o rè̩ ara rè̩ silẹ niwaju Ọlọrun ati eniyan. A ki ba ti le e kuro nibi ti o gbe le wulo fun Ọlọrun ati awọn eniyan rè̩ bi o ba ti rè̩ ara rè̩ silẹ niwaju Ọlọrun ninu ọran yii. S̩ugbọn Adonijah kò ṣetan lati tẹriba fun ifẹ ati iwù Ọlọrun mimọ ati pipé. O yàn lati gbe ara rè̩ ga, ati ni ṣiṣe eyi, o ṣọtẹ si Ọlọrun ati ẹni ti Oluwa yàn. Bi o ba ṣe pe o fi ọrọ rè̩ le Ọlọrun lọwọ ni, ki o si duro de akoko Ọlọrun, Ọlọrun i ba fi i si àye ti oun i ba jẹ ibukun ni orilẹ-ède Israẹli, dipo egún.

Ọna Ọlọrun ati Ọna Eniyan

“Ọna kan wà ti o dabi ẹnipe o dara li oju ọmọ enia . . .” Nigba pupọ ni ọna ti Ọlọrun yàn maa n lodi si ọgbọn ori ti ẹda. Ọlọrun a maa ṣe eto ti o wu U, a si maa mu eto naa ṣẹ gẹgẹ bi ifẹ ati ọgbọn awamaridi ara Rè̩. Olodumare ni Ọlọrun i ṣe, kò ni i fi imọran wa ṣe, bẹẹ ni kò si ohun ti o de E lati ṣiṣẹ Rè̩ lọna ti o dara loju wa, ki iṣẹ naa ba le yọri si rere. Igba pupọ ni o dabi ẹni pe ọna Ọlọrun lodi gidigidi si ọna eniyan, ki O le mu ifẹ ti Rè̩ ṣẹ ki O si le fi hàn wi pe Oun tayọ gbogbo eniyan ati ohun ti i ṣe ti ayé.

Akọbi ọmọkunrin ọba ni a n fi jọba lẹyin baba rè̩ ni ilẹ awọn keferi. Aṣa Israẹli, nipa akọbi ọmọkunrin ninu ẹbi ati awọn ẹtọ ti o ni le ti mu ki ọkàn ọpọlọpọ eniyan ni Israẹli maa rò pe ohun kan naa ni yoo ṣẹlẹ nipa ijọba nigba ti ẹni ti o wà lori oye ba kú. Ero ti ọmọ eniyan ni eyi, ohunkohun kò de Ọlọrun lati tẹle ọna yii tabi ki O fara mọ eto yii.

Nihinyii, Ọlọrun pa akọbi Dafidi ti, O si yan abikẹyin dipo. Ọlọrun mọ ohun ti o wà lọkàn Adonijah, bakan naa ni O mọ ọkàn Sọlomọni. Ọlọrun mọ ẹni ti Oun le fi ọkàn tán. O mọ pe ọkàn Adonijah ti kò ni akoso, ti a kò wẹ mọ -- ti kò si ni igbala-- kún fun iṣẹ ti ara ati igberaga, O si mọ pe Sọlomọni jẹ ẹni alaaafia ti kò ṣoro lati tù loju fun Ẹmi Mimọ.

Adonijah fi ara rè̩ jọba nigba ti o tọ loju ara rè̩; Ọlọrun fi ororo yan Sọlomọni ni ọba ni akoko ti o tọ loju Ọlọrun. Adonijah n wa ojurere eniyan, o fẹ lati fidi ara rè̩ mulẹ lọna ti ara rè̩ nipa pipese fun ifẹkufẹ ti ara; lai si iranlọwọ tabi agbara ti ẹda, a yan Sọlomọni ni ọba gẹgẹ bi eto Ọlọrun. Adonijah fẹ fa oju awọn eniyan Israẹli mọra lati ọdọ awọn olori wọn; Dafidi ati Sọlomọni fi ohun gbogbo le Ọlọrun lọwọ, nipa ṣiṣe bẹẹ, wọn rii pe, “oju gbogbo Israẹli” wà lara wọn ati pe, “Oluwa si gbé Sọlomọni ga gidigidi li oju gbogbo Israẹli, o si fi ọlá nla ọba fun u bi iru eyi ti kò wà fun ọba kan ṣaju rè̩ lori Israẹli” (I Kronika 29:25).

Kikó Ẹgbẹ Rere ṣe Pataki

Ki Adonijah ba le mu eto rè̩ ṣẹ, o pe awọn wọnni ti o rii pe wọn yoo jẹ olóòótọ si oun ninu iṣọtẹ rè̩; awọn ẹni iwabi-Ọlọrun, olóòótọ, ẹni rere ni Dafidi pe mọra, ohun ti a kò si gbọdọ gboju fo da ni pe, ọkàn Dafidi wà ni iṣọkan pẹlu awọn eniyan mimọ Ọlọrun wọnyi. O si daju pé Natani, eniyan Ọlọrun ni anfaani lati dé ọdọ ọba ni gbogbo akoko yii, ọba si fọkàn tan an patapata.

Eniyan bi Basillai kò si ninu awọn ti n tọ Adonijah lẹyin. Bẹẹ ni ẹni bi Natani kò si lọdọ rè̩ pẹlu. Awọn ọgbọn “akọni ọkunrin” ti wọn fi tọkantọkan sin Israẹli ni iran ti wọn bi o tilẹ mu iṣoro lọwọ wà pẹlu Dafidi -- wọn kò si lọdọ Adonijah.

S̩ugbọn a rii pe Joabu wà ninu ẹgbẹ Adonijah. A ti mọ Joabu ni eniyan ti o n ta ẹjẹ silẹ nigba alaaafia bi ẹni pe akoko ogun ni. O ti pa, o ti dè fun anfaani ohun aye yii. Nigba pupọ ni o n ṣe orikunkun, agidi ati aigbọran si aṣẹ ọba rè̩.

A si tun rii pe Abiatari wà lọdọ Adonijah. Abiatari ni ẹni kan ṣoṣo ti o kù ninu iran Eli, o si n jẹ igbadun anfaani pupọ bi o tilẹ jẹ pé egún wà lori idile Eli nitori è̩ṣẹ Eli. Abiatari ṣe olóòótọ fun iwọn igba diẹ ninu ijọba Dafidi, ṣugbọn o kuna lati “jade patapata,” nigbooṣe o jiya è̩ṣẹ rè̩. O di ẹni yẹpẹrẹ nitori pe a mu égun ti o wà lori ile Eli ṣẹ si i lara.

Iwe Mimọ kilọ fun ni gidigidi nipa ewu ti o wà ninu fifi ara mọ awọn alai-wa-bi-Ọlọrun jù bi o ti yẹ lọ. Ẹmi Mimọ ti ẹnu Paulu Apọsteli sọ fun ni wi pe, “Ẹ máṣe fi aidọgba dapọ pẹlu awọn alaigbagbọ” (II Kọrinti 6:14). Johannu Ayanfẹ sọ fun ni pe, “Bi ẹnikẹni bá tọ nyin wá, ti kò si mu ẹkọ yi wá, ẹ máṣe gbà a si ile, ki ẹ má si ṣe ki i” (II Johannu 10). Paulu Apọsteli tun sọ fun ni pe, “Ẹgbé̩ buburu bà iwa rere jẹ.” A kọ ni ni otitọ kan naa ninu Majẹmu Laelae, nitori pe a ri ohun pupọ ti o ṣẹlẹ ti o si jẹ ikilọ fun ni lọna kan naa.

Kò si awawi ti ẹnikẹni ti o ba kuna le ṣe, nitori pe ninu awọn iwe wọnni ti kì i tilẹ ṣe iwe lori ọran ẹsìn, a le ri ikilọ kan naa pẹlu. A ti fi lelẹ bẹẹ lati ayeraye. Ọjọgbọn kan sọ fun ni pe, “Sọ ẹni ti o n ba kẹgbẹ fun mi, n o sọ ẹni ti o jé̩ fun ọ.”

Igbọran Dafidi Lai Jafara

Nigba ti o di mimọ fun Dafidi pe ewu wà lati fi eto ti Ọlọrun ti ṣe nipa ẹni ti yoo jọba lẹyin rè̩ falẹ, Dafidi mu eto yii ṣẹ kánkán. Lai si aniani, o ṣe eto naa gẹgẹ bi imọran ti Natani eniyan Ọlọrun fi fun un. A yan Sọlomọni ni ọba gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun. Ọlọrun ni o yan an ti O si kede eto yii, O si jẹ ki o di mimọ nipasẹ eniyan Ọlọrun pe, ó tó akoko. Dafidi ṣe ohun ti o yẹ ni akoko ti o tọ -- akoko Ọlọrun – o si fi aye silẹ fun ọba titun ti o ṣẹṣẹ jẹ, o si sure fun ọdọmọkunrin yii.

Dafidi ṣe ikilọ kan fun Sọlomọni nigba ti o n sure fun un, ani o gbà a niyanju lati gbọran ati lati rin deedee ninu ofin Ọlọrun. Loju gbogbo awọn ọmọ alade Israẹli, Dafidi ṣe ilana nipa kikọ Tẹmpili, eto igbekalẹ isin ati iṣẹ Ọlọrun, ati bi iṣẹ akoso ilu yoo ṣe maa lọ deedee. O si ran ọba ti o ṣẹṣẹ jẹ yii leti nipa awọn ti o gbogun ti i ninu ijọba rè̩.

Gbogbo awọn ti o n ba Adonijah ṣe ariya fi ibẹru tuka mọ ọn lori lẹsẹkẹsẹ, wọn si ba ọna wọn lọ. Idalẹbi de ba wọn nitori ti wọn fara mọ ohun ti Ọlọrun kò lọwọ si. Wo iyatọ ti o wà ninu ọna ti Adonijah gbà ati ọna ti Dafidi gbà. Awọn ti o fara mọ Dafidi ati Sọlomọni sin Ọlọrun alaaye nitori pe wọn bọlá fun Ọlọrun, wọn si tẹle ọna Rè̩. Wọn ṣe irubọ; wọn fi iyin fun Ọlọrun; wọn jẹ, wọn si mu “niwaju OLUWA li ọjọ na pẹlu ayọ.” Ibẹru ati ijatilẹ ni ọna ọmọ eniyan n yọri si. Ọna Oluwa n fun ni ni ifọkanbalẹ ati iṣẹgun.

Èrè È̩ṣẹ

Bi a ba ka akọsilẹ ti o tẹle iṣẹlẹ yii, a o ri iru iha ti Sọlomọni kọ si awọn ti o jẹ alatako baba rè̩ ti wọn si dawọle e lati da eto Ọlọrun rú. A ri i pe nihin ni iwa ọlọgbọn ọba Israẹli yii ti o tayọ ninu imọ ati oye gbe bẹrẹ si fara hàn.

A kò pa Abiatari alufa nitori ti o duro ti Dafidi ni akoko ti a le e kuro laaarin ilu. S̩ugbọn a rọ ọ loye, a si mu ki o pada lọ si ilu rè̩ pẹlu itiju nitori ti kò jẹ ki ẹmi rere ti o ni tẹlẹ ri ṣakoso ọkàn rè̩ titi de opin aye rè̩.

Adonijah wolẹ nibi pẹpẹ o si di iwo pẹpẹ mu, ninu ẹri ọkàn kikoro o si mọ pe iru ijiya ti o wù ki o de ba oun jẹ eyi ti o tọ ti o si yẹ. Kò di igba ti o di iwo pẹpẹ mu ki o to ronupiwada. Ki i ṣe nitori eyi ni a ṣe fi iwo si ara pẹpẹ. Kò si ironupiwada ninu ọkàn Adonijah, iwa rè̩ kò tilẹ fi hàn bẹẹ. Ọna eke ni o gba – o yàn ọna ti ara dipo ọna Ọlọrun – lati da ẹmi rè̩ si ati lati wa ni ailewu ati pe, ki o le ri aanu gbà. Iwa ti o tun hù lẹyin eyi fi hàn pe oju rè̩ kò ṣi kuro ninu ọba jijẹ bi o tilẹ jẹ pe ifẹ Ọlọrun ti fi ara hàn, o si ti ṣẹ pẹlu. Ọna ti rè̩ jọ ọ loju dipo ọna Ọlọrun. Nitori naa ọlọtè̩ patapata si Ọlọrun ni oun i ṣe.

S̩imei jẹ apẹẹrẹ awọn wọnni ti n ronupiwada nitori ohun kan ti wọn ni lọkàn lati ri gbà, lati bọ kuro ninu ijiya ti è̩ṣẹ le mu wa ba wọn lẹsẹkẹsẹ. Iru awọn ẹni bẹẹ kì i fara mọ aṣẹ ti a ba pa fun wọn, wọn a maa ṣe eyi ti o wu wọn nigba ti wọn ba fẹ tè̩ si ọna ara wọn dipo ọna Ọlọrun.

Kò tọ fun S̩imei lati lọ si ẹyin odi ilu lati mu ijiya wa sori ara rè̩ nitori ti o ru ofin ti a fi fun un. O huwa aigbọran, o si jiya aigbọran rè̩.

Joabu pẹlu wa aabò ti kò tọ lọ si ile Ọlọrun. Kò lẹtọ lati wà ni ibi mimọ nì, niwọn igba ti kò ronupiwada è̩jẹ awọn alaiṣẹ ti o ta silẹ. Kò mu ẹbọ wa fun irekọja rè̩, kò kaanu fun è̩ṣẹ rè̩, kò ni igbọgbẹ ọkàn, kò si ronupiwada. Ohun ti o n fẹ ni pe ki a dá ẹmi rè̩ si, o si fi ilana Ọlọrun ṣe boju-boju lati mu ifẹ ọkàn rè̩ yii ṣẹ. O kọ ọna oore-ofẹ ti o ti wà tẹlẹ, o si fi orikunkun taku si ọna ara rè̩. Nitori naa a gbà ẹmi rè̩ niwaju pẹpẹ Ọlọrun. Ibi ti ọpọlọpọ gbe ni iranwọ ẹmi kò fun ọkàn rè̩ ni iru anfaani ijigiri bẹẹ. Ibẹ di ibi ti Joabu gbe ku ikú ti ara ti o ran an sinu ikú ti ẹmi laelae.

Ọpọlọpọ ni o ni ero pe wiwa si ile Ọlọrun nikan yoo dawọ ibinu ati idajọ Ọlọrun duro lori wọn. Ọpọlọpọ ni o ni ero pe idajọ Ọlọrun ki yoo wa sori wọn bi wọn ba le n bẹ awùjọ eniyan mimọ wo lẹẹkọọkan. S̩ugbọn igbagbọ wọn kì i ṣe iru igbagbọ ti o n fun ni ni aabo ati ifọkanbalẹ nigba ti a ba tú ago ibinu Ọlọrun ti o kún akunwọsile dà sori aye. Wọn yoo wa mọ pe idajọ Ọlọrun yoo sọkalẹ nibikibi ati sori ohunkohun ti o lodi si ilana Ọlọrun ti a kò si fi È̩jẹ mimọ nì wọn.

Ironupiwada ti o ba ni irobinujẹ ninu ti o si jẹ ojulowo nikan ni i ṣe ironupiwada tootọ. Kò si aabo nibikibi lẹyin aabo ti ó wà ninu È̩jẹ Majẹmu Ayeraye nì -- È̩jẹ È̩ni ti Dafidi fi oju ẹmi ri ni ọpọlọpọ ọdun ṣiwaju, bi Ẹni ti yoo wa jọba lori itẹ Israẹli lae ati laelae -- ijọba ti ọmọ rè̩ gba loju ẹmi rè̩ ni nnkan bi ẹgbẹẹdogun (3,000) ọdun sẹyin.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni Adonijah gun le lori lati maa rò pe oun ni yoo jẹ ọba Israẹli?
  2. Njẹ ọna ti o gbà dá ara rè̩ lọlá tọnà?
  3. Bawo ni iroyin rikiṣi yii ṣe de ọdọ Dafidi?
  4. Ki ni ṣe ti Dafidi fi taku bẹẹ pé Sọlomọni ni yoo jọba?
  5. Ka Iṣe Awọn Apọsteli 2:29-31 ati II Samuẹli 7:11-13, 16, 19. Bawo ni imọ Dafidi ti pọ to nipa Kristi ati wiwá sayé Rè̩?
  6. Ki ni iwa ara ti ó wà ninu Adonijah ti o ṣe okunfa iṣubu rè̩?
  7. Njẹ o di mimọ fun awọn miiran pe Ọlọrun ti yan ọba Israẹli?
  8. Sọ nipa iṣọkan ti ó wà laaarin Dafidi ati Woli Natani.
  9. Iru iha wo ni Sọlomọni kọ si Adonijah?
  10. Idọgba wo ni o wà laaarin 1 Awọn Ọba 1:52 ati Esekiẹli 18:4, 20? Sọ bi a ti mu otitọ yii ṣẹ ninu igbesi aye awọn diẹ ninu ẹkọ wa yii.