Lesson 255 - Senior
Memory Verse
“Gbẹkẹle OLUWA, ki o si ma ṣe rere; ma gbe ilẹ na, ki o si ma huwa otitọ” (Orin Dafidi 37:3).Cross References
I Ileri Oluwa ati Adura Sọlomọni
1. Ọlọrun ṣe ileri ti kò niwọn fun Sọlomọni, I Awọn Ọba 3:5; II Kronika 1:7
2. Awọn ileri Ọlọrun fun awọn Onigbagbọ ti ode oni kò niwọn, Johannu 15:7; Matteu 7:7, 8; Marku 11:24
3. Sọlomọni fi iwa irẹlẹ hàn gẹgẹ bi awọn eniyan Ọlọrun nla miiran, I Awọn Ọba 3:6-8; Jeremiah 1:6; Ẹksodu 4:10; Gẹnẹsisi 18:27; 32:10; Awọn Onidajọ 6:15; II Samuẹli 7:18
4. Sọlomọni beere ọgbọn lati ṣe akoso Israẹli, I Awọn Ọba 3:9, 10; Jobu 28:28; Jakọbu 1:5-7; I Kọrinti 1:23, 24; Kolosse 2:2, 3
5. Oluwa da Sọlomọni lohun, I Awọn Ọba 3:11-15; Matteu 6:33
II Ọrọ ati Ogo Ijọba Sọlomọni
1. A mu ileri nipa ti ara, ti a ṣe fun Abrahamu ṣẹ, I Awọn Ọba 4:21, 24, 25; Gẹnesisi 22:17; 15:18
2. Ọlọrun pese fun Sọlomọni lọpọlọpọ, I Awọn Ọba 4:22, 23, 26-28; Luku 6:38
3. Ọlọrun fun Sọlomọni ni ọgbọn, I Awọn Ọba 4:29-34; Matteu 12:42
Notes
ALAYÉỌdọmọkunrin ti a Gbala
“Sọlomọni si fẹ OLUWA.” Jesu wi pe ofin kin-in-ni ati eyi ti o tobi ju lọ ni pe, “Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fé̩ Ọlọrun Oluwa rẹ” (Matteu 22:37). Ibi titun si ododo nikan ni o maa n gbin iru ifẹ ti o jinlẹ báyìí sinu ọkàn. A kò mọ igbà ti Sọlomọni di atunbi, ṣugbọn o ṣe e ṣe ki o jẹ pe lati inu iriri ti oun tikara rè̩ ni o gbe sọ báyìí pe, “Ranti ẹlẹda rẹ nisisiyi li ọjọ ewe rẹ” (Oniwasu 12:1). O daju pe Sọlomọni ni igbala ni igbesi aye rè̩ nitori pe awọn iwe ti o kọ wà ninu Iwe Mimọ Ọlọrun. “Nitori asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ enia wá ri; ṣugbọn awọn enia mimọ Ọlọrun nsọrọ lati ọdọ Ọlọrun bi a ti ndari wọn lati ọwọ Ẹmi Mimọ wá” (II Peteru 1:21).
Sọlomọni kere pupọ nigba ti o bẹrẹsi jọba, ẹnu rè̩ ni ọrọ wọnyi ti jade, ”Ọmọ kekere ni mi” (I Awọn Ọba 3:7). Dafidi pe e ni ”ọmọde ati ẹni ti o rọ.” Ọpọ sọ pe o to ọmọ ogún (20) ọdun. Ohunkohun ti o wù ki ọjọ ori rè̩ le jẹ, ifẹ ti Sọlomọni ni si Ọlọrun ni o mu ki o ké si awọn olori-ogun, awọn adajọ ati awọn baalẹ lati ba oun lọ si Gibeoni. Nibẹ, lori pẹpẹ idẹ ti o wa niwaju Agọ-ajọ ti Mose pa, ni Sọlomọni gbe ru ẹgbẹrun (1000) ẹbọ sisun si Oluwa! (II Kronika 1:3, 6). Rò o wò -- ẹgbẹrun ẹbọ sisun! O fi han bi Sọlomọni ti lọrọ to. Inu Oluwa dùn si ọrẹ-ẹbọ sisun yii. Ni oru ọjọ naa ni Oluwa fara hàn Sọlomọni ninu ala ti O si wi pe, “Bère ohun ti emi o fi fun ọ” (I Awọn Ọba 3:5).
Awọn Ileri Ọlọrun
Ta ni ninu wa, ni akoko kan ni igbesi aye rè̩, ti inu rè̩ ki yoo dùn gidigidi bi a ba fun un ni iru anfaani ti kò loṣuwọn yii. Wo Sọlomọni ọmọde kekere, ọba lori ité̩, ti Ọlọrun ṣe irú ileri yii fun wi pe, “Bère ohun ti emi o fi fun ọ.” Wo ibukun ailopin ti o wà ni ikawọ Ọlọrun Ẹlẹda. Kò si ohun ti o ṣoro fun Ọlọrun. Ki ni iwọ yoo beere?
Boya iwọ le maa rò pe Sọlomọni ri ojurere pupọ lọdọ Ọlọrun lati ri irú ileri yii gbà lọdọ Rè̩. S̩ugbọn ẹ jẹ ki a yẹ ileri ti Ọlọrun ṣe fun awọn ti o gbagbọ lọjọ oni wò. “Bère, a o si fifun nyin; wá kiri, ẹnyin o si ri; kànkun, a o si ṣi i silẹ fun nyin. Nitori ẹnikẹni ti o bère nri gbà; ẹniti o ba si wá kiri nri; ẹniti o ba si nkankun, li a o ṣi i silẹ fun” (Matteu 7:7, 8). Ileri wọnyi ha lopin bi? Ọlọrun kan naa ha kọ ni a n sìn bi? Bi a ba beere fun ọgbọn gẹgẹ bi Sọlomọni ti ṣe, a ni idaniloju nipa eyi pe, “Bi o ba kù ọgbọn fun ẹnikẹni, ki o bère lọwọ Ọlọrun, ẹniti ifi fun gbogbo enia li ọpọlọpọ, ti ki isi iba-ni-wi; a o si fifun u” (Jakọbu 1:5). Jakọbu si fi eyi kun un: “S̩ugbọn ki o bère ni igbagbọ, li aiṣiyemeji rara. Nitori ẹniti o nṣiyemeji dabi igbi omi okun, ti nti ọwọ afẹfẹ bi siwa bi sẹhin ti a si nrú soke. Nitori ki iru enia bḝ máṣe rò pe, on yio ri ohunkohun gbà lọwọ Oluwa” (Jakọbu 1:6, 7).
Awọn Irubọ Labẹ Ofin
Lilọ ti Sọlomọni lọ si Gibeoni ni ibẹrẹ ijọba rè̩ ni lati ya ara rè̩ sọtọ ati lati fi ara rè̩ rubọ fun isin Ọlọrun. Ẹbọ ti o rú ni itumọ ti o ga nipa ti ẹmi. Wọn duro fun ifi-ara-rubọ ati ọpẹ si Ọlọrun. “Njẹ nipasẹ rè̩, ẹ jẹ ki a mā ru ẹbọ iyin si Ọlọrun nigbagbogbo, eyini ni eso ète wa, ti njẹwọ orukọ rè̩” (Heberu 13:15). Itumọ ẹbọ yii le tubọ ye wa sii nipa adura Dafidi, “Jẹ ki adura mi ki o wá si iwaju rẹ bi ẹbọ turari; ati igbé ọwọ mi soke bi ẹbọ aṣālẹ” (Orin Dafidi 141:2). Ọlọrun beere ifi-ara-rubọ lọwọ awọn eniyan ti o wà labẹ Majẹmu Titun gẹgẹ bi O ti beere lọwọ awọn ti o wà nigba Ofin.
Awọn Irubọ Labẹ Oore-ọfẹ
“Nitorina mo fi iyọnu Ọlọrun bè̩ nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ āye, mimọ, itẹwọgbà, eyi ni iṣẹ-isin nyin ti o tọna” (Romu 12:1). Ọlọrun kò jẹ beere ohun ti kò tọna lọwọ wa. O wà ni ipa wa lati ṣe; bi a ba si mọ eyi, yoo ran wa lọwọ ninu ifi-ara-rubọ wa. Nigba miiran awọn obi a maa beere ohun ti kò tọna lọwọ awọn ọmọ wọn, ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ beere ohun ti kò tọna lọwọ awọn ọmọ Rè̩. Ohunkohun gbogbo ti O ba beere ni o tọna, o si wà ni ipa wa lati ṣe nitori pe O ti pese iranwọ silẹ fun wa. Ọpọlọpọ eniyan ni kò fẹ sẹ ara wọn ninu ohunkohun. Sibẹsibẹ igbà pupọ ni awọn ohun ti o dabi ẹni pe o kere ti a fi dù ara wa le mu wa tubọ sunmọ Ọlọrun timọtimọ. Igba pupọ ni awọn eniyan maa n fẹ ki awọn ẹlomiran ba wọn rù agbelebu wọn, ṣugbọn Jesu wi pe, “Bi ẹnikan ba nfẹ lati tọ mi lẹhin, ki o sẹ ara rè̩, ki o si gbé agbelebu rè̩, ki o si mā tọ mi lẹhin” (Matteu 16:24).
Idupẹ ati Irẹlè̩
“Nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupẹ, ẹ mā fi ibere nyin hàn fun Ọlọrun” (Filippi 4:6). Lẹyin ti Sọlomọni ti ru ẹgbẹrun ẹbọ ni Ọlọrun to fara hàn an ti O si sọ fun un lati beere ohun ti o fẹ. Sọlomọni dahun pe, “Ọmọ kekere ni mi, emi kò si mọ jijade ati wiwọle” (I Awọn Ọba 3:7). Iru irẹlẹ bayii ni n fi awọn eniyan nla hàn. Ọrọ oun funra rè̩ wi pe, “S̩āju ọlá ni ìrẹlẹ” (Owe 15:33). Ọna miiran ti a tun le gbà fi wi pe “Ẹnikẹni ti o ba si rè̩ ara rè̩ silẹ li a o gbé ga” (Matteu 23:12) ni pe, “Irẹlẹ ni ọna si igbega.” Ibeere Sọlomọni fun ọgbọn ati oye dùn mọ Ọlọrun lọpọlọpọ, O si fun un ni ọgbọn ati oye.
Iṣura ti o Pamọ
Ọpọlọpọ le maa rò pe Sọlomọni di ẹni ti o lọgbọn jù lọ nigba ti o ji loju oorun rè̩. Lai si aniani eyi kò ri bẹẹ nitori ti o dabi ẹni pe ki a maa sọ pe ẹni kan ti o ni apoti ofifo ninu ile rè̩ lọ sun, ṣugbọn apoti naa ti kún ki o to ji ni owurọ ọjọ keji. Ọlọrun sọ fun ni, ninu awọn akọsilẹ Sọlomọni wi pe, a ni lati ṣe aapọn ni iṣẹ ṣiṣe ati ni fifi ọkàn wa si ipa ọgbọn. “Bi iwọ ba nke tọ imọ lẹhin, ti iwọ si gbé ohun rẹ soke fun oye; bi iwọ ba ṣafẹri rè̩ bi fadaka, ti iwọ si nwá a kiri bi iṣura ti a pamọ; nigbana ni iwọ o mọ ibè̩ru OLUWA, iwọ o si ri imọ Ọlọrun” (Owe 2:3-5). Ọlọrun fun wa ni ẹbun nipa ti ara, ṣugbọn a ni lati ṣaapọn bi a ba si fẹ ki ìmọ wa gbooro ki talẹnti wa si pọ sii. Ọlọrun a maa fun ni sii bi a ti n làkàkà nipasẹ ileri Rè̩. Bi a ba ti n lo agbara ti O fi fun wa, Oun yoo maa fun wa lókun siwaju ati siwaju; ṣugbọn O fẹ ki a maa lo wọn bi O ti n fun wa. Fun apẹẹrẹ, nigbà ti awọn Ọmọ Israẹli de Ilẹ Kenaani, Ọlọrun kò ran wahala si awọn Keferi ki O si pa wọn run ki awọn Ọmọ Israẹli to de ilẹ naa. O mu ki Israẹli lọ jagun. O si fun wọn ni iṣẹgun bi wọn ti n jà. Bi wọn kò ba jà, kò ni si iṣẹgun.
Awọn Ohun Àkọkọ
Adura Sọlomọni ṣe deedee pẹlu ọrọ Jesu: “Ẹ tète mā wá ijọba Ọlọrun na, ati ododo rè̩; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún u fun nyin” (Matteu 6:33). Kò wa ọrọ; kò wa ọlá; kò wa iṣẹgun loju ogun; kò wa agbara. Eyi yii fi igbesi aye adura hàn gbangba nipa ohun ti o wu Ọlọrun ati eyi ti kò wu U, nigba ti o ba di ọran adura. Ọlọrun fẹ ki a fi ohun kin-in-ni si ipo kin-in-ni nigbà ti a ba n gbadura. Ọlọrun fun Sọlomọni ni ohun ti kò beere, Oun yoo si ṣe bẹẹ fun ni bi a ba tete wa Ijọba Ọlọrun.
Ipinlè̩ Israẹli
“Sọlomọni si jọba lori gbogbo awọn ọba lati odò nì (Euferate) titi de ilẹ awọn ara Filistia, ati titi de eti ilẹ Egipti” (I Awọn Ọba 4:21). Nipa bayii ni Ọlọrun mu ileri ti o ti ṣe fun Abrahamu ṣẹ ni ọjọ aye Sọlomọni: “Irú-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yi fun, lati odo Egipti wá, titi o fi de odò nla nì, odò Euferate” (Gẹnẹsisi 15:18).
Ẹni Kan ti O Tobi Jù Sọlomọni Lọ
“Ọlọrun si fun Sọlomọni li ọgbọn ati oye li ọpọlọpọ, ati oye gbigboro, gẹgẹ bi iyanrin ti o wà leti okun” (I Awọn Ọba 4:29). “Ẹni pupọ si wá lati gbogbo orilẹ-ède lati gbọ ọgbọn Sọlomọni; ani lati ọdọ gbogbo awọn ọba aiye” (I Awọn Ọba 4:34). Wọn gbọ ọrọ Sọlomọni, ṣugbọn awa gbọ Ọrọ Ẹni kan ti o tobi jù Sọlomọni lọ -- Jesu Kristi, Oluwa.
Questions
AWỌN IBEERE- Nibo ni Agọ-Ajọ ati pẹpẹ idẹ wà nigba ti Sọlomọni bẹrẹ si i jọba?
- Nibo ni Apoti Majẹmu wà ni akoko yii?
- Sọ awọn ohun ti o fi hàn pe Sọlomọni ni igbala.
- Ki ni ṣẹlẹ ni ọjọ ti o ṣaaju ọjọ ti Ọlọrun fara han Sọlomọni?
- Sọ diẹ ninu awọn ileri nla Ọlọrun ti o wà fun awọn eniyan Rè̩ lọjọ oni.
- Sọ diẹ fun ni nipa ọna ti Sọlomọni kọ ni pe a le gbà ni ọgbọn.
- Lọna wo ni ibeere Sọlomọni fi fara jọ titete wa Ijọba Ọlọrun?
- Iwọ ha le sọ ileri kan ti a ṣe fun Sọlomọni lori adehùn pe bi o ba ṣe ohun kan (I Awọn Ọba 3) ti a kò si mu ṣẹ fun un?
- Ileri wo ni a ṣe fun Abrahamu ti a mu ṣẹ nigba ijọba Sọlomọni?
- Sọ awọn ọna diẹ ninu eyi ti a gbà fi ọgbọn Sọlomọni hàn.