Orin Dafidi 100:1-5; 150:1-6; Heberu 10:23-25

Lesson 256 - Senior

Memory Verse
“Ibukun ni fun awọn ti ngbe inu ile rẹ: nwọn o ma yìn ọ sibẹ” (Orin Dafidi 84:4).
Cross References

I Ipe si Iyìn

1. Gbogbo ilẹ, gbogbo eniyan ati ohun gbogbo ti o ni ẹmi ni a pè lati yìn Oluwa, Orin Dafidi 100:1; 150:6: 68:32; Romu 15:10, 11

2. Onipsalmu paṣẹ pe ki a sìn Oluwa pẹlu inudidùn, Orin Dafidi 100:2; Iṣe Awọn Apọsteli 2:46; Filippi 4:4; II Kronika 29:30; Isaiah 30:29; 35:10

3. Awọn eniyan Ọlọrun ni lati wá siwaju Rè̩ pẹlu orin, Orin Dafidi 100:2; 126:2; I Kronika 6:32; Isaiah 44:23; Efesu 5:19; Kolosse 3:16

4. A ni lati fi duru yìn Ọlọrun pẹlu gbogbo ohùn elo orin, Orin Dafidi 150:3-5; II Kronika 20:28; I Kronika 13:8; Ẹksodu 15:20; Ifihan 5:8; 14:2; 15:2

5. A ni anfaani lati sìn ati lati yìn Ọlọrun ni ibi mimọ Rè̩, Orin Dafidi 100:4; 150:1; Heberu 10:23-25; Deuteronomi 12:5; 16:16; Mika 4:2; Luku 4:16

6. Iyìn Ọlọrun ni otitọ ati ni ododo n jẹwọ oore nla Ọlọrun si awọn eniyan Rè̩, Orin Dafidi 100:3, 5; 150:2; 145:1-21; Ifihan 5:9-14; 15:3, 4

Notes
ALAYÉ

Ọpẹ si Oluwa

Otitọ ti o di mimọ kari gbogbo aye ni pe orin ati iyin kò ṣe e ya sọtọ ninu isin awọn Onigbagbọ si Ọlọrun. Gbogbo Onigbagbọ nibi gbogbo ni o mọ wi pe ọpẹ si Ọlọrun ati kikọrin iyin ni a n pe ni isin lẹmi ati lotitọ. Abayọrisi isìn lọna bayii ni ayọ ati alaafia bi a ba ṣe e ni ẹmi ati ni otitọ. Ọpẹ si Oluwa, Ẹlẹda Ọrun ati aye ati ohun gbogbo ti o wà ninu wọn, ni lati di ara fun Onigbagbọ bi eemi ti a n mi ti rọrun fun olukuluku eniyan. O ni lati maa yìn Olurapada rè̩ Nla nigba gbogbo, ẹni ti o gba a kuro lọwọ ẹbi ati ijiya è̩ṣẹ. Bi ọpẹ rè̩ ba jẹ atọkanwa, yoo goke gẹgẹ bi omi ti a fà lati inu ẹrọ afami, lai si idiwọ rara.

Ọkàn ti kò ba le rì sinu ibú isin Ọlọrun, ki o si yin Ọlọrun pẹlu ayọ kò mọ ayọ igbala. A sọ fun ni pe “Ẹnyin o si fi ayọ fà omi jade lati inu kanga igbala wá” (Isaiah 12:3). O di mimọ fun awọn ọmọ-ẹyin Jesu wi pe mimu lati inu kanga igbala a maa fun ni ni ayọ nlá nlà. Bi Jesu ti fi ayọ iṣẹgun wọ Jerusalẹmu, “awọn ọmọ-ẹhin rè̩ bè̩rẹ si iyọ, ati si ifi ohùn rara yin Ọlọrun, nitori iṣẹ nla gbogbo ti nwọn ti ri” (Luku 19:37). Nigba ti awọn Farisi fẹ ki Jesu ba wọn wi nitori pe wọn yìn In lọna bayii, Jesu dahun wi pe, “Bi awọn wọnyi ba pa ẹnu wọn mọ, awọn okuta yio kigbe soke” (Luku 19:40).

Iyìn Ayọ

Iyìn ti Ọlọrun yoo tẹwọ gbà lati ọdọ awọn eniyan Rè̩ kò ni lati jẹ afipaṣe bi kò ṣe pẹlu ayọ. “Ẹ fi ayọ sìn OLUWA” ni ọrọ iyanju ti o wà ninu ẹkọ wa yii, “isin ti o tọna” ati iṣẹ wa ni eyi. Ọlọrun kò fẹ awọn iranṣẹ ti n fajuro, ti kò layọ ninu iṣẹ-isìn Rè̩. Awọn ti n sìn Ọlọrun ni lati sìn In tifẹtifẹ, pẹlu ipinnu lati wu Ọlọrun ki i ṣe lati wu ara wọn nikan. (Ka I Tẹssalonika 4:1; II Timoteu 2:4). Jesu ṣe iṣẹ Baba Rè̩ tọkantọkan, nitori pe O sọ nipa ara Rè̩ bayii pe, “Emi nṣe ohun ti o wù u nigbagbogbo” (Johannu 8:29).

Dafidi wi pe, “Inu mi dùn nigbati nwọn wi fun mi pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ile OLUWA” (Orin Dafidi 122:1). Isin Ọlọrun kì i ṣe ohun inira fun Dafidi, kò si le jẹ ohun inira fun ẹnikẹni ti o ba n sìn Ọlọrun ni ẹmi ati ni otitọ.

Iyìn Yiyẹ

A kà ninu iwe ifihan nipa awọn ogun Ọrun yika itẹ Ọlọrun ti wọn n wi pe Jesu ni iyìn yẹ: “Yiyẹ li Ọdọ-Agutan na ti a ti pa, lati gbà agbara, ati ọrọ, ati ọgbọn, ati ipá, ati ọlá, ati ogo, ati ibukún” (Ifihan 5:12). Kì i ṣe pe o yẹ ki gbogbo ẹda alaaye fi iyin fun Ọlọrun nikan, ṣugbọn iyin Rè̩ tilẹ jù eyi ti ẹnu ọmọ eniyan le sọ lọ. Iyìn kò si ni ọkàn ẹlẹṣẹ si Ẹlẹda rè̩, nitori pe ara ni ọkàn è̩ṣẹ rè̩ n fẹ gbe ga ati lati fi iyìn fun. Lodi si iwa ti ara yii, kì i ṣe pe Onigbagbọ fẹ lati yìn Ọlọrun nikan, a maa fẹ lati kokiki ọlánlá Rè̩ fun gbogbo aye nitori o mọ pe Oun ni iyin atọkanwa yẹ fún.

Ijọsin ninu Orin ati Ohun-elo Orin

Ohun pupọ ni a le sọ nipa ijọsìn si Ọlọrun nipa orin kikọ ati ohun-elo orin -- jù bi a ti le sọ ninu ẹkọ yii. O hàn gbangba ninu Iwe Mimọ pe Ọlọrun n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ jọsìn fun Oun ninu orin ati ohun-elo orin. A kà ninu iwe ti a yàn fun ẹkọ yii pe, “Ẹ wá ti ẹnyin ti orin si iwaju rè̩” (Orin Dafidi 100:2), ati pẹlu pe “Fi ohùn ipè yìn i: fi ohun-èlo orin ati duru yin i. Fi ilu ati ijó yìn i: fi ohun ọnà orin olokùn ati fère yìn i. Ẹ yin i lara aro olohùn òke: ẹ yìn i lara aro olohùn goro” (Orin Dafidi 150:3-5). Aṣẹ ti o fi ẹsẹ mulẹ ni yii fun awọn ọmọ Ọlọrun lati maa kọrin ati lati maa lo ohun-elo orin ninu ijọsìn Ọlọrun.

A le sọ fun awọn wọnni ti wọn rò pe kò tọ lati lo ohun-elo orin ati lati maa kọrin ninu ijọsin fun Ọlọrun pe Iwe Mimọ kò lodi si i rara. Kàka bẹẹ Iwe Mimọ pa a laṣẹ fun ni lati maa sìn Ọlọrun lọna bayii. Kò si akọsilẹ kan yala ninu Majẹmu Laelae tabi Titun ti a le sọ fun ni pe o kọ fun ni lati jọsin fun Ọlọrun nipa orin, ati ohun-elo orin. Ọlọrun kò jẹ gbà fun iran kan lati fi orin ati ohun-elo orin jọsìn fun Un ki O si kọ fun awọn iran miiran lati ṣé bẹẹ. Ọkan naa ni Ọlọrun lana, loni, ati titi lae, Oun kì i yipada. (Ka Malaki 3:6).

Agbala Iyìn

Ọrọ Ọlorun kọ fun ni lati “kọ ipejọpọ ara wa silẹ” (Heberu 10:25). Ajumọ jọsin awọn ọmọ Ọlọrun ṣe pataki lọpọlọpọ. O ṣe pataki nitori pe Ọlọrun ti ṣeleri lati wà nibi ti ẹni meji tabi mẹta ba pejọ pọ si ni orukọ Rè̩. (Ka Matteu 18:20). Ọlọrun a maa sọkalẹ lati bukun awọn eniyan Rè̩; lati kọ wọn, ati lati mu wọn lọkàn le ninu oore-ofẹ Ọlọrun; awọn ẹlẹṣẹ n ri igbala, awọn olokunrun n ri imularada, a si n waasu Ihinrere.

Iwe Mimọ tẹnu mọ ọn pe Ile Ọlọrun ni ibi ti Ọlọrun fẹ ki awọn eniyan Rè̩ pẹjọ pọ si lati maa jọsin fun Un lati igba de igba, O si fi dandan le e pe ki a maa wá deedee. (Ka Orin Dafidi 65:4; 84:1-4, 10; 118:19, 26; Isaiah 2:3). A kò yọọda ki Onigbagbọ fà sẹyin lati wa jọsin fun Ọlọrun ninu ile Ọlọrun; awọn Onigbagbọ tootọ paapaa kò tilẹ ni fẹ ki a fẹ wọn kù nibẹ. Ni akoko ọlaju yii, awọn kan wà ti wọn rò pe wọn le ri ibukun ti wọn ì ba ri gba bi wọn ba lọ jọsin ninu ile Ọlọrun nipa titẹti silẹ si isin ti wọn n ṣe lori ẹrọ asọrọ-magbesi (radio). Àṣìrò gbaa ni eyi, o si ti mu ki ọpọlọpọ eniyan joro ninu ẹmi wọn nitori ti wọn kuna lati maa jọsin deedee.

Iṣẹ isìn ati isìn ori ẹrọ asọrọ-magbesi (radio) ti o dara ti o si duro gẹgẹ lori Ọrọ Ọlọrun ti jẹ ibukun fun ọpọ ọkàn ti ara wọn kò le tó lati wa jọsin pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun. Ọlọrun bukun awọn eniyan bẹẹ nitori pe wọn kò ni ipa lati ṣe ju eyi lọ. Ọlọrun kò jẹ tú ibukun Rè̩ sori awọn wọnni ti ara wọn le koko ṣugbọn ti wọn takú sile pẹlu ero yii pe wọn le joko sile lati maa sìn Ọlọrun gẹgẹ bi wọn ti le sin In ninu ile Ọlọrun. Wọn fi ifẹ wọn lati jokoo maa gbọ Ọrọ Ọlọrun lori ẹrọ asọrọ-magbesi (radio) ṣe boju-boju lati gbọ ohun miiran pẹlu, ki wọn si maa ṣe eyi ti o wu wọn ni Ọjọ Oluwa, dipo ti wọn i ba fi ya a sọtọ fun Oluwa.

Ọjọ Oluwa fun Ijọsìn

Ifẹ Ọlọrun fun wa ni pipa Ọjọ Oluwa mọ -- “Sunday” -- kò bùku nipa ti ẹmi si ofin ti Ọlọrun fi fun ni ninu Majẹmu Laelae nipa Ọjọ Isinmi. “Bi iwọ ba yi ẹsẹ rẹ kuro li ọjọ isimi, lati má ṣe afé̩ rẹ li ọjọ isimi mi; ti iwọ si pè ọjọ isimi ni adùn, ọjọ mimọ Oluwa, ọlọwọ; ti iwọ si bọwọ fun u, ti iwọ kò hù iwa rẹ, tabi tẹle afẹ rẹ, tabi sọ ọrọ ara rẹ. Nigbana ni inu rẹ yio dùn si Oluwa, emi o si mu ọ gùn ibi giga aiye, emi o si fi ilẹ nini Jakọbu baba rẹ bọ ọ: nitori ẹnu Oluwa li o ti sọ ọ” (Isaiah 58:13, 14).

Otitọ ti o ṣe pataki jù lọ ni eyi pe, ijọsìn wa fun Ọlọrun ni aye yii jẹ ipalẹmọ fun isin ti awujọ nla nì ti yoo pejọ yi ité̩ Ọlọrun ka yoo ṣe. Bi a ti n kọ lati jọsin fun Ọlọrun, lati yin In ninu orin ati ẹri ni aye yii, bakan naa ni a o maa yin In bẹẹ gẹgẹ ni ọjọ nla idande ati iṣelogo. A pa a laṣẹ fun ni lati wa si awujọ awọn olododo, lati wa fi iyin fun Ọlọrun nitori aanu Rè̩ ati lati wa san ẹjé̩ wa fun Ọlọrun niwaju awọn eniyan Rè̩.

Ninu Orin Dafidi ikejilelogun, a ka bayii pe, “Emi o sọrọ orukọ rẹ fun awọn arakọnrin mi: li awujọ ijọ li emi o ma yin ọ. Ẹnyin ti o bè̩ru Oluwa, ẹ yin i; gbogbo ẹnyin iru-ọmọ Jakọbu, ẹ yin i logo . . . Nipa tirẹ ni iyin mi yio wà ninu ajọ nla, emi o san ẹjé̩ mi niwaju awọn ti o bè̩ru rè̩” (Orin Dafidi 22:22-25). Ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wọnyi n tọka si Kristi, o sọ fun ni pe Oun yoo yin Ọlọrun Baba ninu awujọ ailonka awọn ẹni irapada Ọlọrun.

Pataki Iyìn

Episteli si awọn Heberu n tọka si Orin Dafidi ikejilelogun nigbà ti o ṣe atunwi ọrọ wọnyi, “Emi ó sọrọ orukọ rẹ fun awọn ará mi, li arin ijọ li emi o kọrin iyìn rẹ” (Heberu 2:12). Eyi pẹlu tun tọka si i pe iyìn Ọlọrun laaarin ijọ jẹ ohun pataki nitori pe Jesu, Olori Alufa ati apẹẹrẹ wa, yoo yin Ọlọrun niwaju awọn arakunrin Rè̩ laaarin Ijọ.

Jesu ko ti i yìn Baba Rè̩ ni awujọ nla awọn olododo, nitori pe ẹgbẹ yii kò ti i pejọ pọ. Ọrọ Ọlọrun ti a mẹnu kan nì fi hàn gbangba pe Oun yoo ṣe bẹẹ. Bakan naa ni o daju pe Ọlọrun fẹ ki a wá si Agbala Rè̩ ti awa ti iyìn ninu aye yii, ni imurasilẹ fun ọjọ nla ti irapada. Bi Jesu ti fi apẹẹrẹ lelẹ fun wa gẹgẹ bi Balogun igbala wa nipa mimu ọpọlọpọ ọkàn wa sinu ogo (Heberu 2:10), ati gẹgẹ bi akọbi ninu awọn ti o sùn (I Kọrinti 15:20, 23), bakan naa ni Oun yoo jẹ apẹẹrẹ wa loke Ọrun lọhun ni ti pe Oun ni Ẹni ekinni ati Ẹni iṣaaju lati fi iyin fun Ọlọrun Baba. (Ka I Kọrinti 15:25-28).

Awọn ti kò le yìn Ọlọrun nihin kò le yìn In lọhun. Ẹnikẹni kò gbọdọ bè̩ru lati duro niwaju awọn eniyan, tabi ki o tiju lati dide lori ẹsẹ rè̩ laaarin awọn eniyan mimọ Ọlọrun lati jẹwọ orukọ Kristi. A kò gbọdọ lọra ni sisan è̩jé̩ wa niwaju Ọlọrun ninu ile Ọlọrun ni aye yii, nipa bẹẹ, awa yoo le ṣe e jù bẹẹ lọ loke lọhun ni ọjọ nla Ọlọrun.

A o ṣẹgun agbara eṣu nipa ọrọ ẹri wa ati nipa È̩jẹ Ọdọ-agutan (Ifihan 12:11). A ni lati jẹri yii ni Ile Ọlọrun. Aṣẹ Ọlọrun ni.

Yiyìn Ọlọrun Logo

Ọlọrun gbà awọn eniyan Rè̩ là ki wọn le maa yìn In logo titi ayeraye. A kà á pe, “Ninu ẹniti a fi wa ṣe ini rè̩ pẹlu, awa ti a ti yan tẹlẹ, gẹgẹ bi ipinnu ẹniti nṣiṣẹ ohun gbogbo gẹgẹ bi ìmọ ifẹ rè̩: ki awa ki o le jẹ fun iyin ogo rè̩, awa ti a ti ni ireti ṣaju ninu Kristi” (Efesu 1:11, 12). A ri firifiri pe eyi ri bẹẹ nipa akọsilẹ ti o wà ninu Iwe Ifihan, ti o sọ fun ni bayii pe, “Gbogbo ẹda ti o si mbẹ li ọrun, ati lori ilẹ aiye, ati nisalẹ ilẹ, ati irú awọn ti mbẹ ninu okun, ati gbogbo awọn ti mbẹ ninu wọn, ni mo gbọ ti nwipe, Ki a fi ibukún ati ọlá, ati ogo, ati agbara, fun ẹniti o joko lori ité̩ ati fun Ọdọ-Agutan na lai ati lailai” (Ifihan 5:13). “Lẹhin na, mo ri, si kiyesi i, ọpọlọpọ eniyan ti ẹnikẹni kò le kà, lati inu orilẹ-ède gbogbo, ati ẹya, ati enia, ati lati inu ède gbogbo wá, nwọn duro niwaju ité̩, ati niwaju Ọdọ-Agutan na, a wọ wọn li aṣọ funfun, imọ-ọpẹ si mbẹ li ọwọ wọn; Nwọn si kigbe li ohùn rara, wipe, Igbala ni ti Ọlọrun wa ti o joko lori ité̩ ati ti Ọdọ-Agutan” (Ifihan 7:9, 10).

Onipsalmu gba ni niyanju pe, “Ẹ ma dupẹ fun u, ki ẹ si ma fi ibukún fun orukọ rè̩.” Psalmu ti o kẹyin ninu Orin Dafidi pari pẹlu ọrọ wọnyi, “Jẹ ki ohun gbogbo ti o li ẹmi ki o yìn OLUWA. Ẹ fi iyìn fun OLUWA.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti a fi ni lati maa yìn Oluwa?
  2. Nibo ni o tọna fun wa lati yìn Oluwa?
  3. Ki ni ṣe ti a kò gbọdọ jafara lati maa wa si Ile Ọlọrun lati jọsin fun Ọlọrun?
  4. Ta ni awọn wọnni ti yoo yin Ọlọrun ni Ọrun?
  5. Bawo ni a ṣe mọ pe Jesu yoo fi iyin fun Ọlọrun Baba?
  6. Ki ni ṣe ti a ni lati wa jọsin ni Ile Ọlọrun dipo ki a jokoo sile?