Lesson 257 - Senior
Memory Verse
“Ẹ lọ si ẹnu ọna rè̩ ti ẹnyin ti ọpẹ, ati si agbala rè̩ ti ẹnyin ti iyìn: ẹ ma dupẹ fun u, ki ẹ si ma fi ibukún fun orukọ rè̩” (Orin Dafidi 100:4).Cross References
I Awọn Eto Fun Kikọ Ile
1. Hiramu, Ọba Tire, ranṣẹ lati ki Sọlomọni, Sọlomọni naa beere iranwọ fun ipese ohun ti yoo fi kọ Ile Ọlọrun, I Awọn Ọba 5:1, 2, 6
2. Ọpọ ogun ti Israẹli ja ni akoko Dafidi kò jẹ ki Dafidi kọ Tẹmpili, ṣugbọn Sọlomọni ni isinmi niha gbogbo, I Awọn Ọba 5:3-5
3. Hiramu yọ pupọ si ibeere Sọlomọni, o si gbà lati fi ohun-elo ranṣẹ fun Tẹmpili naa, I Awọn Ọba 5:7-10
4. A ṣe awọn eto naa, ohun-elo si de si Jerusalẹmu fun kikọ ile naa, I Awọn Ọba 5:11-18
II Kikọ Ile Naa Gan an
1. Ni ọdun kẹrin ijọba Sọlomọni ni kikọ Tẹmpili bẹrẹ, I Awọn Ọba 6:1
2. Tẹmpili gan an funra rè̩ tobi to ilọpo meji Agọ-ajọ, I Awọn Ọba 6:2-6
3. A ti gbẹ awọn okuta silẹ fun kikọ ile ki a to kó wọn wa si ilu, I Awọn Ọba 6:7
4. Iṣẹ-ọna ile naa pọ pupọ, a si fi yara pupọ kún gbogbo iha Tẹmpili naa, I Awọn Ọba 6:8-10
III Tẹmpili ti a S̩eleri
1. Oluwa tun ileri Rè̩ ṣe fun Sọlomọni bi yoo ba pa ofin Oun mọ, I Awọn Ọba 6:11-13
2. A kò roju akoko tabi inawo rè̩, I Awọn Ọba 6:14-36
3. Ọdun meje ati oṣu mẹfa ni a fi kọ Tẹmpili naa, I Awọn Ọba 6:37, 38
Notes
ALAYÉAwọn Ilepa ti o Nilaari
Aṣarò lori awọn ohun ti Ọlọrun ati ti Ọrun a maa ṣiṣẹ iyanu ni igbesi aye wa. Ni ọjọ kan, ọba Israẹli ti o fẹ Ọlọrun jù lọ joko ni aafin rè̩ ti a fi igi kedari kọ, o si bẹrẹ si ronu bi aafin rè̩ ti niyi to ati bi agọ ti a gbe Apoti Ẹri sinu rè̩ kò ti jọju rara. Agọ yii ati ohun ti o wà ninu rè̩ duro fun ibujoko ati iya-ijọ isin awọn Israẹli fun Ọlọrun wọn.
Ọkàn Dafidi sọ fun un pe Ọlọrun Israẹli, ti O ṣe awọn eniyan Rè̩ loore pọ to bẹẹ ni lati ni ile ti o tọ si ọlá orukọ Rè̩ lati fi ẹwa iwa mimọ Rè̩ hàn. Dafidi sọ ohun ti o wà lọkàn rè̩ fun Natani, Woli, ọrọ naa si dara loju Woli yii to bẹẹ ti o fi gba dajudaju pe Ọlọrun yoo fọwọ si i. Ni oru ọjọ naa, iṣẹ ti Ọlọrun ran Natani si ọba yatọ. Igbesi aye Dafidi lori oye kún fun ogun jija lọpọlọpọ, Dafidi ati awọn eniyan rè̩ si ti ta è̩jè̩ silẹ pupọ; nitori naa, a kò gbà fun un lati kọ ile fun Ọlọrun. Ọlọrun sọ fun Dafidi pe Oun kò beere ile kikọ lọwọ rè̩, ṣugbọn O yin in fun ero rere ti o wà lọkàn rè̩, O si ṣeleri pe ọmọ Dafidi, ti yoo jọba lẹyin rè̩, ni yoo kọ Tẹmpili ti Dafidi n ṣe aṣarò ninu ọkàn rè̩ lati kọ.
Ileri ti a Muṣẹ
Nigba ti ọmọ eniyan ba pa majẹmu tabi adehun rè̩ pẹlu Ọlọrun mọ, ki o da wọn loju gbangba pe Ọlọrun yoo ṣe ipa ti Rè̩ pe pérepére. Bi o tilẹ jẹ pe o leke gidigidi lọkàn Dafidi lati kọ ile fun Oluwa, o jọwọ ifẹ ti rè̩ fun ifẹ pipe Ọlọrun. Sibẹ Dafidi kò kawọ gbera, ki o si maa reti ọjọ ikú rè̩. Ohun-elo ti o niyelori ti o si dara jú lọ ni a gbọdọ lo fun kikọ ile Ọlọrun ti a fẹ kọ yii; Dafidi si fi iyoku ọjọ aye rè̩ gboke gbodo lati kó awọn ohun-elo wọnyi wa si Jerusalẹmu. “Ati pẹlu gbogbo ipa mi ni mo ti fi pèse silẹ fun ile Ọlọrun mi, wura fun ohun ti wura, ati fadakà fun ti fadakà, ati idẹ fun ti idẹ, irin fun ti irin, ati igi fun ti igi; okuta oniki ti a o tè̩ bọ okuta lati fi ṣe ọṣọ, ati okuta oniruru àwọ, ati oniruru okuta iyebiye, ati okuta marbili li ọpọlọpọ” (I Kronika 29:2). Pẹlupẹlu, Dafidi rin ni ibẹru Oluwa to bẹẹ ti Ẹmi Ọlọrun fi apẹẹrẹ Ile Oluwa fun un (I Kronika 28:11, 12). Nipa bayii, iṣẹ ti Dafidi ṣe ni pipese awọn ohun-elo silẹ fẹrẹ to iṣẹ ti Sọlomọni ṣe ni kikọ ile naa gan an. Nigbà ti Sọlomọni gori oye ni Israẹli, o rii pe ilu rè̩ wa ni alaafia pẹlu gbogbo eniyan, o si ba ọpọlọpọ ohun-elo nilẹ lati le fi bẹrẹ kikọ Tẹmpili ti a ti pinnu lati kọ. Ọlọrun mu ileri Rè̩ fun Dafidi ṣẹ kinnikinni.
Ayè fun Gbogbo Eniyan
Ọlọrun ni aye ati ipe pupọ ninu eto Rè̩ fun awọn ọmọ eniyan, ayè si wà fun gbogbo ọkàn ti o ba fẹ sin In. Awọn ayè kan le má fara hàn bi awọn aye miiran, ṣugbọn isin tootọ yoo fun ni ni èrè ti o daju. Ohun ti kò jẹ ki Dafidi kọ Tẹmpili -- ọpọ ogun ti o ti ja – eyi gan an ni o si mu ki o ṣe e ṣe fun Sọlomọni lati kọ ọ ni gẹrẹ ti o gori oye ni Israẹli. Yatọ si wi pe a ti ṣe ipese ọpọlọpọ ohun elo silẹ fun un lati lò, o tun le wi pe, “Oluwa Ọlọrun mi ti fun mi ni isimi niha gbogbo, bḝni kò si si ọta tabi ibi kan ti o ṣè̩” (I Awọn Ọba 5:4).
Lotitọ, Ọlọrun alaafia ni Ọlọrun i ṣe, ṣugbọn oniruuru igbà ati akoko ipọnju ati wahala ni o pilẹ iṣẹ idagbasoke Ile Ọlọrun nipa ti Ẹmi. Awọn Apọsteli ati awọn ọmọ-ẹyin Kristi jiya ohun pupọ lẹyin ti Jesu pada lọ sọdọ Baba, ṣugbọn igbagbọ lile ati ọkàn akin wọn jẹ ogún iyebiye fun aye yii, eyi si ti rú ifẹ ọkàn awọn Onigbagbọ soke lati tẹra mọ iṣẹ idagbasoke Ijọ Ọlọrun titi di oni-oloni. Ni aipẹ jọjọ ni ọdun diẹ sẹyin, awọn ero mimọ ti Arọkuro Ojo ti la ọpọ iṣoro kọja, wọn ṣe alaini, a lù wọn, wọn si fara da isọrọ è̩gan ki awa le gbadun Ihinrere Jesu Kristi gẹgẹ bi a ti rii lọjọ oni. Awọn alabojuto ati awọn alakoso wa ti fi ọpọlọpọ ohun-elo ti o niyelori silẹ fun wa, eyi ti a le lo lati kọ Ile Ọlọrun nipa ti Ẹmi. A kọ Tẹmpili Sọlomọni ni irisi Tẹmpili ti ọrun, o si jẹ ojiji awọn ohun nla ti n bọ wa.
Onigbagbọ yoo maa ja ija ti igbagbọ titi di akoko Ipalarada, titi di igbà ti Oluwa yoo gbe Ijọba alaafia Rè̩ kalẹ ni aye. Lai pẹ jọjọ, ogun ti ẹmi yoo dopin, a o di gbogbo ohun-elo Ijọ pọ, a o si kó wọn lọ si Ọrun. A o pari kikọ Tẹmpili ti Ẹmi ninu alaafia ati isinmi ti yoo wà ni gbogbo akoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun ati titi aye ainipẹkun.
Fun Orukọ Ọlọrun
Sọlomọni jẹ ọkan ninu awọn ẹni ti o gbọn jù lọ ni aye, o si mọ daju pe bi o ti wù ki Tẹmpili yii tobi tó ki o si lẹwa tó, ki yoo le gbà ju kin-n-kin-ni ninu Ẹmi Ọlọrun Ọrun. “Wo o, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọsi ile yi ti mo kọ?” (I Awọn Ọba 8:27). Ogo ti o tobi ju lọ lati ọwọ ọmọ eniyan wá kò le fi kún un bẹẹ ni kò si le din ogo Ọlọrun kù. Agbara ati ogo kikún Rè̩ kò yipada, ohunkohun ti o wù ki eniyan ṣe tabi ki o kuna lati ṣe. S̩ugbọn o ṣe e ṣe ki eniyan mu iyin tabi è̩gan ba orukọ Ọlọrun laaarin awọn eniyan. Ohun ti o leke ọkàn Dafidi ati Sọlomọni ni pe ki Orukọ Ọlọrun le di mimọ ni gbogbo agbaye nipasẹ ile daradara yii. Ohun ti o jẹ ifẹ ọkàn wọn ni pe ki ogo ati iyin le jẹ ti Ọlọrun nipa kikọ ile yii.
Otitọ yii yẹ ki o mulẹ ṣinṣin ni ọkàn gbogbo ẹni ti n pe orukọ Kristi. Kò si ẹni ti o le bù kún ogo Kristi bi o ti wù ki ẹni naa gbe igbesi aye ododo ati iwabi-Ọlọrun to; ṣugbọn ohun ti o ṣe e ṣe ni lati bù kún ogo ati iyin Orukọ Rè̩ laaarin eniyan nipa gbigbe igbesi aye ẹni diduro ṣinṣin ati ailabawọn. Lọna miiran è̩wẹ, ẹni ti o n jẹwọ pe oun jẹ Onigbagbọ ti kò si so eso igbesi aye Onigbagbọ yoo mu abukù ba Orukọ Jesu. Iwe Mimọ sọ fun ni pe, “Ẹnyin ni tẹmpili Ọlọrun alāye” (II Kọrinti 6:16). Bi a ba kọ ile igbagbọ wa rere, gbogbo ẹni ti o ba wa pade ni yoo wi, bi ti awọn Ju igba awọn Apọsteli nì pe, “Nwọn si woye wọn pe, nwọn a ti ma ba Jesu gbé” (Iṣe Awọn Apọsteli 4:13). Ẹri ti o tobi jù lọ nipa agbara Jesu Kristi ni gbigbe igbesi aye ailẹṣẹ laaarin awọn eniyan; abukù ti o si tobi jù lọ si Orukọ Kristi ni pe ki ẹni ti o jẹwọ orukọ Kristi maa gbe igbesi aye è̩ṣẹ. Jẹ ki o da ọ loju pe iwọ n kọ ile igbagbọ rẹ gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun ti lana silẹ, bi bẹẹ kọ ile naa yoo wo lulẹ.
Ọba Tire
Sọlomọni rii daju pe awọn ohun-elo ti o dara jù lọ ni a lo lati fi kọ Tẹmpili, o si wa awọn oniṣẹ-ọnà ti o mọ iṣẹ jù lọ lati ṣe iṣẹ ọnà naa. Nigbà ti Hiramu ọba Tire ran awọn iranṣẹ rè̩ lati ki Sọlomọni nigbati o gori oye ni Israẹli, Sọlomọni ranṣẹ pada wi pe oun n fẹ ki awọn ara Sidoni mu igi fun un wa lati kọ ile Oluwa. O ṣe e ṣe ki Hiramu ti yipada si Ọlọrun Israẹli lati maa sin In, “nitori pe Hiramu ti fẹràn Dafidi.” Nigbà ti Hiramu gbọ ọrọ Sọlomọni, inu rè̩ dùn gidigidi, o si wi pe, “Olubukún li OLUWA loni, ti o fun Dafidi ni ọmọ ọlọgbọn lori awọn enia pupọ yi.” Awọn alai-wa-bi-Ọlọrun kì i saba ni ọkàn lati tete fi iyin fun Ọlọrun bẹẹ ninu ohunkohun.
Sọlomọni ati Hiramu ṣe adehun lati jumọ ṣe iṣẹ naa ni aṣepari, eyi si ṣiṣẹ ire lọpọlọpọ. Awọn iranṣẹ Sọlomọni jumọ ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ara Sidoni ninu igbo Lẹbanoni, wọn jumọ ge igi, wọn si mu igi kedari ati firi jade fun lilo lati inu igbo wa. Wọn gbe awọn igi naa lọ si ebute okun, a si wà wọn wa si ebute Palẹstini nibi ti a gbe ru wọn lọ si ibi ti a gbe n kọ Tẹmpili.
Mataka Kò Si
Ohun kan ti o tun ya ni lẹnu gidigidi nipa kikọ Ile yii fun Orukọ Ọlọrun ni pe a kò lo mataka, tabi aake tabi ohun-elo irin kan nibi ti a gbe n kọ ọ. Gbogbo igi ati okuta kọọkan ni a ti ge ti a si ti ṣe ni ọna ti olukuluku yoo fi bọ si aye ti rè̩ rẹgi ninu Ile naa ki a tilẹ to mu wọn wọ ilu, gẹgẹ bi eto ti o ya ni lẹnu. Lai si aniani, ọpọlọpọ okuta ni a fi silẹ lori awọn oke Israẹli nitori pe kò ṣe e ṣe lati ge wọn si iwọn ti a n fẹ lo.
“Ẹnyin pẹlu bi, okuta āye, li a kọ ni ile ẹmi, alufa mimọ, lati mā ru ẹbọ ẹmi, ti iṣe itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun nipa Jesu Kristi” (I Peteru 2:5). A fi Ijọ Kristi we ile ati Kristi gẹgẹ bi pataki Igun-ile, awọn ọmọ Ijọ ni a si pè ni okuta ti a kọ le Kristi. Ẹni ti o fi ipilẹ Ọrun sọlẹ ni eto ti o tayọ lati ayebaye, ẹni ti o ba si fẹ wà lara ile Rè̩ ni lati fara da gige ati fifi ayùn rẹ ki oun ba le ṣe rẹgi ni àyè ti a fẹ fi i si. Ogunlọgọ ẹlẹṣẹ ti ọkàn wọn le bi okuta ti ṣubu lu Jesu Kristi Apata, a si ti fọ lile ọkàn wọn tuutu, Oluwa si yi wọn pada, O si ti ṣe wọn yẹ rẹgi fun ile Ọlọrun. A kò fi fun eniyan lati mọ iwọn naa gan an ti a fẹ fi i si, nigba pupọ ni o si n mu irora pupọ wa lati ge ẹni naa si iwọn ti Ọlọrun n fẹ; ṣugbọn jọwọ ohun gbogbo lọwọ fun awamaridi ọgbọn Ọlọrun. Oun kò ṣina tabi ṣe aṣiṣe ri.
Iṣẹ Ti A Pari
A kò sọ pupọ fun ni nipa iyẹwu ati agbala ile naa; ṣugbọn iwọn Tẹmpili gan an ti o wà ni Esekiẹli 40 ṣe deedee pẹlu akọsilẹ ti o wà ninu Awọn Ọba Kin-in-ni; niwọn igba ti Esekiẹli paapaa ti jẹ alufa ti o si ri Tẹmpili Sọlomọni, ọpọlọpọ akẹkọọ Bibeli ati Josẹfu opitan pẹlu ni o gbagbọ pe woli yii ti sọ iwọn Tẹmpili Sọlomọni fun ni pato. Lọna bayii iwọn Tẹmpili ti a kọ si ori Oke Moria yii jẹ ẹgbẹta (600) igbọnwọ tabi ẹẹdẹgbẹrun (900) ẹsẹ ni igun mẹrẹẹrin lọgbọọgba, a si mọ ogiri ti o ga ni igbọnwọ mẹsan (9) tabi ẹsẹ mẹrinla (14) yi i ka. Ni aarin rè̩ ni agbala awọn Keferi wà, aadọta (50) igbọnwọ tabi ẹsẹ marundinlọgọrin (75) ni fifè̩. Agbala Israẹli ni o tẹle eyi, ọgọrun (100) igbọnwọ tabi aadọjọ (150) ẹsẹ ni fifẹ, a si mọ ogiri yi i ka. Nihin yii ni ọdẹdẹ daradara ti awọn alufa n yọju si lati fun wọn ni itura ati aabo kuro lọwọ ìji. Ni aarin rè̩ ni agbala awọn alufa gbe wà pẹlu pẹpẹ idẹ ati Tẹmpili gan an. Ila-oorun ni ile naa kọju si. A ṣiro wura ati iwọn ohun-elo olowo iyebiye ti a lo lati kọ Tẹmpili ati lati ṣe awọn ọṣọ rè̩ si n kan bi ẹgbaa mẹrinlelọgọrin ọkẹ naira.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti Hiramu ọba Tire fi ran awọn iranṣẹ rè̩ si Sọlomọni?
- Iṣẹ wo ni Sọlomọni ran pada si Hiramu lati ọwọ awọn iranṣẹ rè̩?
- Ki ni ṣe ti a kò gbà fun Dafidi lati kọ Tẹmpili fun Orukọ Oluwa?
- Ki ni Dafidi ṣe bi o tilẹ jẹ pe a kò gbà a laye lati kọ Tẹmpili?
- Ipa wo ni awọn ara Sidoni muṣẹ ninu kikọ Tẹmpili naa?
- Bawo ni a ṣe san owo ọya wọn fun wọn?
- Nibo ati bawo ni a ṣe ṣiṣẹ awon okuta ati igi fun kikọ ile naa?
- Ipin melo ni o wà ninu Tẹmpili naa?
- Bawo ni o ti pẹ to ki Sọlomọni ati awọn iranṣẹ rè̩ to pari kikọ ile naa?