II Kronika 5:1-14; 7:1-3; I Awọn Ọba 8:54-61; 9:1-9

Lesson 258 - Senior

Memory Verse
“Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọna; ki a si gbé nyin soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ inu ile wa” (Orin Dafidi 24:7).
Cross References

I Gbigbe Apoti - Ẹri wa si Ipo Rè̩

1. Sọlomọni mu ohun gbogbo ti Dafidi baba rè̩ ti yà sọtọ wa sinu Tẹmpili, II Kronika 5:1; I Kronika 29:2-5

2. Awọn agbà Israẹli ati awọn olori ẹya pejọ pọ ki wọṅ ba le gbé Apoti-ẹri Majẹmu wá, II Kronika 5:2, 3; II Samuẹli 6:1-15; I Awọn Ọba 8:1-4

3. Awọn ọmọ Lefi ati awọn alufa gbe Apoti-ẹri ati gbogbo ohun-elo mimọ ti Agọ-ajọ wa sinu Tẹmpili, II Kronika 5:4, 5, 7-10; I Awọn Ọba 8:6-9

4. Sọlomọni ati awọn eniyan rú ọpọlọpọ ẹbọ lakoko yii, II Kronika 5:6; I Awọn Ọba 8:5

II Ogo Oluwa Fara han

1. Nigbà ti a gbe Apoti-ẹri kalẹ ti awọn akọrin si kọrin iyin wọn si Oluwa, ogo Rè̩ kún Tẹmpili gẹgẹ bi ikuuku, II Kronika 5:11-14; Ẹksodu 40:34, 35; I Awọn Ọba 8:10, 11

2. Ni opin adura iya-si-mimọ ti Sọlomọni gbà, iná sọkalẹ lati Ọrun wa, o si jo ẹbọ sisun ati awọn ẹbọ iyoku, II Kronika 7:1-3; Lefitiku 9:24; I Awọn Ọba 18:30-39

III Ìre Sọlomọni

1. Sọlomọni sọ gbọnmọ-gbọnmọ leti awọn eniyan bi Ọlọrun ti ṣe jẹ olóòótọ si wọn, lẹyin eyi o si tu wọn ka, I Awọn Ọba 8:54-56; Orin Dafidi 36:5; Ẹkun Jeremiah 3:22, 23; I Kọrinti 1:9

2. A gbà awọn eniyan niyanju lati duro ni ihà ti Ọlọrun, I Awọn Ọba 8:57-59, 61; Deuteronomi 29:9-13; Jọṣua 23:6-8; I Kọrinti 15:58; Galatia 5:1

3. Jijẹ olóòótọ Israẹli ki ba ti fi hàn fun araye pe Oluwa ni Ọlọrun, I Awọn Ọba 8:60

IV Majẹmu Ọlọrun

1. A gbọ adura Sọlomọni, Ọlọrun si ṣeleri lati mu ibeere rè̩ ṣẹ bi ọba yoo ba pa ofin Ọlọrun mọ, I Awọn Ọba 9:1-5

2. Oluwa ṣeleri lati fi idi itẹ ijọba Sọlomọni mulẹ bi o ba jẹ olóòótọ, I Awọn Ọba 9:5

3. Aigbọran yoo mu ijiya wa sori Sọlomọni, idile rè̩ ati sori awọn Ọmọ Israẹli, I Awọn Ọba 9:6-9

Notes
ALAYÉ

Fun Okiki ati Ogo

“Bayi ni gbogbo iṣẹ ti Sọlomọni ṣe fun ile OLUWA pari” (II Kronika 5:1). Ọdun méje ọtọtọ ni a fi kọ ile daradara yii, fun ọla ati ogo Ọlọrun Israẹli. Tẹmpili yii, ti o yọri soke ni gè̩rẹgè̩rẹ Oke Moria ni awọn olugbe Jerusalẹmu ti mọ dunju-dunju ki a tilẹ to pari iṣẹ inu rè̩. Wọn rò pe yoo wà bẹẹ fun ọpọlọpọ ọdún, a si kọ ọ “tobi jọjọ, fun okiki ati ogo ka gbogbo ilẹ” (I Kronika 22:5). Iṣẹ atọkanwa li eyi, o si gbà akoko awọn Ọmọ Israẹli, lọna kan tabi lọna miiran, ni gbogbo ọdún meje yii. Lai si aniani, awọn eniyan wọnyi ti bẹrẹsi foju sọna nigba ti akoko to lati ya ile naa si mimọ.

Ibujoko Titun fun Apoti-ẹri

Ọkan ninu awọn ohun ti Sọlomọni kọ ṣe bi o ti n mura silẹ fun iya-si-mimọ Tẹmpili ni pe o lọ gbe Apoti-ẹri lati ilu Dafidi wa si ibujoko titun ti a pese fun un ninu Tẹmpili. Apoti-ẹri jẹ apẹẹrẹ pe Ọlọrun wà pẹlu awọn Ọmọ Israẹli, ohun ti o si leke ju lọ lọkàn Sọlomọni ni pe ki Ẹmi Ọlọrun le maa gbe ile ti a kọ fun ọla Orukọ Rè̩. Ifarahan Ọlọrun nikan ni o le ya ile naa si mimọ, kò si ohun miiran ti o le dipo eyi. Sọlomọni ọba mọ pe ohun danindanin ni pe ki Ọlọrun fi ibukun Rè̩ sori ohun gbogbo ti a n ṣe. Bakan naa ni o ṣe pataki fun wa lọjọ oni lati ri i pe Ẹmi Ọlọrun wà pẹlu wa ninu ohun gbogbo ti a ba dawọ le ki a ba le ṣe aṣeyọri nibẹ gẹgẹ bi Onigbagbọ.

A pe awọn agbà Israẹli, awọn olori ẹya-ẹya ati gbogbo olori awọn baba awọn Ọmọ Israẹli lati mu Apoti-ẹri goke wa. A pe awọn ọmọ Lefi lati ru Apoti-ẹri ati awọn ohun mimọ ti o wà ninu Agọ wa. Sọlomọni kò fẹ ki iru idajọ ti o wa sori Ussa nigbà ti Dafidi fẹ mu Apoti-ẹri goke wa si ilu Dafidi tun ṣẹlẹ. (Wo II Samuẹli 6:1-10). Awọn eniyan ru oniruuru ẹbọ pẹlu ayọ; Ọlọrun gbọ ẹbè̩ wọn; a gbe Apoti-ẹri wa si ibujoko rè̩ ni “ibi mimọ ju lọ, labẹ iyẹ awọn kerubu.” A ti pese kerubu nla meji lati na iyẹ wọn bò o. Kerubu wọnyi duro lori ẹsẹ wọn, wọn si na iyẹ wọn, gigun iyẹ apa kọọkan si jẹ igbọnwọ marun un. Fifẹ Ibi Mimọ julọ jẹ ogun igbọnwọ, lọna bayii, iyẹ apa kerubu kọọkan kan ogiri (nihin ati lọhun) wọn si tun kan ara wọn ni aarin meji Ibi Mimọ Julọ. Labẹ iyẹ wọnyi ni a gbe Apoti-ẹri si.

Labẹ Iyẹ-apa Rè̩

“Nibè̩ li emi o ma pade rẹ, emi o si ma bá ọ sọrọ lati oke ité̩-ānu wá, lati ārin awọn kerubu mejeji wá ti o wà lori apoti ẹri na” (Ẹksodu 25:22). A kọ fun awọn Ọmọ Israẹli lati de Ibi Mimọ Julọ, afi olori alufa ti o n wọ ibi mimọ yii lẹẹkan ṣoṣo lọdún ni Ọjọ Etutu. Bibeli tumọ ipese yi fun ni lọna bayii: “Ẹmi Mimọ ntọka eyi pé a kò ti iṣi ọna ibi mimọ yii silẹ niwọn igbati agọ ekini ba duro” (Heberu 9:8). Ofin kan naa fi ẹsẹ mulẹ ninu iṣẹ isin ninu Tẹmpili.

S̩ugbọn ni wakati naa gan an ti Jesu kú, aṣọ ikele ti o wà laaarin Ibi Mimọ Julọ ati Ibi Mimọ “ya si meji lati oke de isalẹ.” Ọna si ọdọ Ọlọrun ṣi silẹ, a ṣi i silẹ fun gbogbo eniyan nipasẹ iṣẹ etutu ti Jesu ṣe nipa ikú Rè̩. Ki a ba le de ọdọ Ọlọrun ni kikún, ọmọ eniyan ni lati tọ ọna ti O ti la silẹ -- nipasẹ igbala, eyi ti a fi pẹpẹ idẹ ti o wà ni agbala ode Tẹmpili ṣe apẹẹrẹ rè̩; nipa isọdimimọ, eyi ti a fi pẹpẹ wura ti o wà ni Ibi Mimọ ati turari ti n jo lori rè̩ tọsan toru ṣe apẹẹrẹ rè̩; ati nipasẹ ifiwọ-ni Ẹmi Mimọ ti a fi Ọrọ Ọlọrun ati Ẹmi Ọlọrun ti o wà ni Ibi Mimọ Julọ ṣe apẹẹrẹ rè̩. (Fun akaye dunju-dunju nipa Agọ-Ajọ, awọn ayè ti a pin in si, awọn ohun ti a fi ṣe e lọṣọọ ati ohun ti ọkọọkan duro fun, lọ wo Iwe Kẹfa, ẹkọ 70, 72, 73, ati 74). Ipe Ọlọrun n lọ loni jake-jado si gbogbo eniyan ni gbogbo agbaye lati wá si abẹ ojiji iyẹ apa Rè̩, ki wọn si mọ adun ti ó wà ninu idapọ pẹlu Rè̩.

Adura Iya-si-Mimọ

Gẹrẹ ti awọn alufa gbe Apoti-ẹri si aaye rè̩ ti awọn akọrin ati awọn alo-ohun elo-orin gbe ohun orin soke lati maa yin Ọlọrun, ogo Ọlọrun, bi awọsanma kún Tẹmpili. Ifarahàn Ọlọrun pọ to bẹẹ ti awọn alufa kò le ṣe iṣẹ isin wọn. Sọlomọni gun ori aga idẹ ti a ti pese silẹ fun ajọ yii. O kọkọ duro, lẹyin naa o kunlẹ lori eekun rè̩ niwaju gbogbo ijọ eniyan Israẹli, o si na ọwọ rè̩ soke Ọrun. Sọlomọni mọ pe ile yii kò le gbà ogo Ọlọrun “ti o ngbe aiyeraiye;” ṣugbọn Sọlomọni n fẹ ki Ọlọrun fi Orukọ Rè̩ sibẹ ati pe ki oju Rè̩ wà lori ile naa lọsan ati loru ati lori gbogbo awọn ti o ba wa sìn tọkan-tọkan ninu ile naa. Adura è̩bè̩ ni Sọlomọni fi pari adura iya-si-mimọ yii.

Adura Gbà

“Bi Sọlomọni si ti pari adura igbà, iná bọ lati ọrun wá, o si jo ọrẹ sisun ati ẹbọ na run; ogo Oluwa si kún ile na” (II Kronika 7:1). Nigbà ti iná lati ọdọ Ọlọrun ba bọ sori ẹbọ, kò si iyemeji wi pe Ọlọrun gbọ adura naa tabi kò gbọ. Awọn Ọmọ Israẹli yọ nigba ti wọn ri ifarahan Ọlọrun, “nwọn doju wọn bò ilẹ ti a fi okuta té̩, nwọn si tẹriba, nwọn si yin Oluwa” (II Kronika 7:3).

Ohun ribiribi ni fun awọn Ọmọ Israẹli ti akoko Sọlomọni lati ri i pe iná atọrunwa bọ sori ọrẹ sisun ati ẹbọ o si sun un jona raurau, nitori pe iru iná kan naa yii ti sọkalẹ ni akoko iya-si-mimọ Agọ ninu aginju. Ọlọrun si paṣẹ pe, “Ki iná ki o ma jó titi lori pẹpẹ na; kò gbọdọ kú lai” (Lefitiku 6:13). Awọn alufa fi ifarabalẹ pa ofin Ọlọrun mọ, wọn si n lo iná atọrunwa yii ninu gbogbo iṣẹ isin. Iná miiran gbogbo ni a kà si iná ajeji.

Gbogbo Onigbagbọ lọjọ oni ni o ni lati wà lori pẹpẹ fun Ọlọrun. Nigba ti ẹni kan ba wá iriri ibi titun si ododo ti o si ri i gba, oun yoo fi ara rè̩ rubọ -- ẹbọ kan – ni igbesi aye rè̩ fun Ọlọrun. Ẹmi Ọlọrun yoo ba ẹmi ẹni naa jẹri pe a ti gbọ adura igbala ti o gbà, iná ifẹ Ọlọrun yoo si kún ọkàn naa. Ina ifẹ yii kò gbọdọ fara sin; o ni lati maa jo geere fun gbogbo eniyan lati ri. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe “Ẹnyin ni imọlẹ aiye. Ilu ti a tè̩do lori òke ko le farasin” (Matteu 5:14). Iná Ọlọrun yoo maa jo geere lọkàn Onigbagbọ nipa pipa ofin Ọlọrun mọ, nipa ọpọ adura, nipa gbigbe igbe-aye iwa mimọ, nipa fifi aye ati ifẹ rè̩ rubọ si Ọlọrun Baba ati Jesu Kristi Ọmọ Rè̩.

Oke Moriah

Ohun nla meji ti o fi oore-ọfẹ ati agbara Ọlọrun hàn ti ṣẹlẹ ṣaaju ni gè̩rẹgè̩rẹ Oke Moriah nibi ti a gbe kọ Tẹmpili yii si. Awọn ohun mẹta ti o ṣẹlẹ yii fi ifẹ Ọlọrun lati maa fi ara Rè̩ han fun eniyan hàn. Lori Oke Moriah ni a pe Abrahamu si nigba ti Ọlọrun sọ fun un lati fi ọmọ rè̩ rubọ. Abrahamu dahun pe, “Wo o, emi niyi,” o si mu ọna ajo naa pọn lẹsẹkẹsẹ. Igbagbọ ni Abrahamu fi dahun ibeere Isaaki wi pe “Ọmọ mi, Ọlọrun tikalarè̩ ni yio pèse ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun” (Gẹnẹsisi 22:8). A de Isaaki, a si gbe e sori igi lori pẹpẹ, ṣugbọn angẹli Ọlọrun kò jẹ ki a pa ọmọ naa. Agbò ti o fi iwo há pantiri ni a fi dipo Isaaki -- apẹẹrẹ Ọmọ Ọlọrun ti i ṣe Ọdọ-agutan Ọlọrun ti a pese fun araye. Nigbà ti akoko naa to, a kò gbe E kuro lori pẹpẹ ẹbọ tabi ki O má ku ikú ori agbelebu. O ta È̩jẹ Rè̩ silẹ ki eniyan le ri idariji è̩ṣẹ gbà.

Irin-ajo Keji

Ọdún pupọ ti kọja sẹyin ki Dafidi to wa si ibi mimọ yii. Dafidi pinnu lojiji, lati kà awọn Ọmọ Israẹli lai gbà imọran lọwọ Ọlọrun, ṣugbọn ó fẹrẹ má ti i pari kikà awọn eniyan tan ti o fi di mimọ fun un pe o ti ṣe lodi si ifẹ Ọlọrun. Ọlọrun sọ fun Dafidi lati yàn ọkan ninu idajọ mẹta ti O fi siwaju rè̩. Dafidi da Woli ti o wa jiṣẹ fun un lohun pe, “Iyọnu nla ba mi: jẹ ki a fi ara wa le OLUWA li ọwọ; nitoripe ānu rè̩ pọ: ki o má si ṣe fi mi le enia li ọwọ” (II Samuẹli 24:14).

Ọlọrun ran ajakalẹ-arun wa sori Israẹli fun ọjọ mẹta. Ẹgbaa-marun-din-logoji (70,000) eniyan kú ki a to paṣẹ fun angẹli apanirun naa lati dawọ duro. Dafidi bẹ Ọlọrun fun awọn eniyan rè̩, Oluwa si gbọ, a si ran Woli nì si Dafidi pe ki o lọ si ibi ipaka Arauna lori Oke Moria, ki o tẹ pẹpẹ kan nibẹ, ki o si rubọ si Oluwa. Dafidi mu ohun ti Ọlọrun palaṣẹ ṣẹ kankan.

Arauna fẹ fun Dafidi ni ohun gbogbo ti yoo fi rubọ, ṣugbọn Dafidi kọ, o si wi pe, “Emi o rà a ni iye kan lọwọ rẹ, bi o ti wù ki o ṣe; bḝli emi ki yio fi eyiti emi kò nawo fun, rú ẹbọ sisun si OLUWA Ọlọrun mi” (II Samuẹli 24:24). Ọkàn Dafidi n wa ohun ti o niye lori ju lọ lati fi fun Oluwa.

Ki ni ohun ti o niye lori jù lọ ti Onigbagbọ le fi fun Oluwa lọjọ oni? Ẹmi ni iṣura ti o ṣọwọn jù lọ fun eniyan nitori pe “ohun gbogbo ti enia ni, on ni yio fi rà ẹmi rè̩” (Jobu 2:4). “Nitorina mo fi iyọnu Ọlọrun bè̩ nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ āye, mimọ, itẹwọgbà, eyi ni iṣẹ-isin nyin ti o tọna” (Romu 12:1). Ọkàn ati ẹmi ti a ti dalare nipa igbagbọ nikan ni o ṣe itẹwọgbà fun Ọlọrun ni ifi-ara-rubọ fun iṣẹ-isin.

Irin ajo keji si Oke Moria jẹ apẹẹrẹ isọdimimọ. Ẹnikẹni ti o ba fẹ ni isọdimimọ ti i ṣe iṣẹ oore-ọfẹ keji ti o daju, ni lati mu ẹbun ti o ṣọwọn jù lọ wa – ara rè̩, ẹbọ aaye – ni ifi-ara-rubọ ki o si jọwọ rè̩ sori pẹpẹ Ọlọrun lati ṣe e bi O ba ti fẹ.

Irin-ajo Kẹta

Irin-ajo kẹta lọ si ori Oke Moria ni ọjọ manigbagbe nì ti a ya Tẹmpili si mimọ. Eyi jẹ apẹẹrẹ Ọjọ Pẹntekọsti, o si ṣanfaani lati fi ọkàn si awọn ohun ti o fara jọ ara wọn ninu awọn iṣẹlẹ mejeeji wọnyi.

Gbogbo awọn alufa ti o ni ipin ninu iṣẹ isin iya-si-mimọ Tẹmpili ni a ti sọ di mimọ. A ti sọ awọn ọmọ-ẹyin ti o duro de agbara Ọlọrun ni Yara Oke di mimọ patapata pẹlu. Ọgọfa awọn alufa ni o fun ipe nibi iya-si-mimọ Tẹmpili, ọgọfa ọmọ-ẹyin gan an ni o wa ni Yara Oke nigba ti Ẹmi Mimọ ba le wọn. Awọn alo-ohun elo-orin ati akọrin dabi “ẹni pe ẹni-kan, bi ohùn kan lati ma yìn, ati lati ma dupẹ fun OLUWA.” Iwe Mimọ si sọ fun ni pe, “Nigbati ọjọ Pẹntekọsti si de, gbogbo nwọn fi ọkàn kan wà nibikan” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:1). Ogo Oluwa kún Tẹmpili Ọlọrun, iná si sọkalẹ lati Ọrun o si jo ọrẹ ẹbọ sisun ati ẹbọ. Nipa Pẹntekọsti a kà pe, “Lojiji iró si ti ọrun wá, gẹgẹ bi iró ẹfufu lile, o si kún gbogbo ile nibiti nwọn gbé jokoo. Ẹla ahọn bi ti iná si yọ si wọn, o pin ara rè̩ o si bà le olukuluku wọn. Gbogbo nwọn si kún fun Ẹmi Mimọ, nwọn si bè̩rẹ si ifi ède miran sọrọ, gẹgẹ bi Ẹmi ti fun wọn li ohùn” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:2-4).

Ifi Ẹmi Mimọ wọ ni ni ẹbun ti o tobi jù lọ ninu awọn ẹbun ti Ọlọrun n fi fun ọmọ eniyan. O wà fun awa ti igba Ihinrere yii. Ẹmi Mimọ yoo ba le ọkàn ti a ti sọ di mimọ ti o si wa A. “Fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jina rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pe” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:39).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Sọ ọna pupọ ti a le gba fi kikọ Tẹmpili wé imurasilẹ Onigbagbọ fun Ọrun.
  2. Ki ni ọkan ninu awọn ohun ti Sọlomọni kọ ṣe nigbà ti o n palẹmọ fun iya-si-mimọ Tẹmpili?
  3. Nibo ni ibi isinmi ikẹyin fun Apoti-ẹri?
  4. Ta ni a gbà layè lati wọ Ibi Mimọ Julọ ninu Tẹmpili? Nigbà melo?
  5. Apẹẹrẹ ki ni Ibi Mimọ Julọ jẹ?
  6. Ọna wo ni a gbà yi eto isin pada labẹ Oore-ọfẹ?
  7. Darukọ, o kere tan, mẹfa ninu ohun ti Sọlomọni beere ninu adura iya-si-mimọ ti o gbà.
  8. Ki ni ohun nla ti o ṣẹlẹ ni opin adura naa?
  9. Sọ irin-ajo mẹtẹẹta si Oke Moria ati itumọ ti Ẹmi ti o wà ninu irin-ajo kọọkan.