I Awọn Ọba 10:1-29

Lesson 259 - Senior

Memory Verse
“Ohun ti oju kò ri, ati ti eti kò gbọ, ti kò si wọ ọkàn enia lọ, ohun wọnni ti Ọlọrun ti pèse silẹ fun awọn ti o fẹ ẹ” (I Kọrinti 2:9).
Cross References

I Okiki Sọlomọni

1. Ayaba S̩eba, ni ilẹ okeere, gbọ okiki Sọlomọni nipa ti orukọ Oluwa, I Awọn Ọba 10:1; Jọṣua 6:27; I Awọn Ọba 4:29-34; Isaiah 66:18, 19; Matteu 4:23-25; 9:26, 31.

II Irin-ajo Ayaba S̩eba

1. Ayaba S̩eba wa sọdọ Sọlomọni lati fi awọn ibeere ti o ṣoro dan an wò, I Awọn Ọba 10:1; Owe 1:5, 6; Matteu 22:46; Luku 14:6

2. Ayaba S̩eba sọ gbogbo ohun ti o wà ni ọkàn rè̩ fun Sọlomọni, I Awọn Ọba 10:2; Luku 2:19; Iṣe Awọn Apọsteli 8:30, 31; 16:30

3. Sọlomọni dahun gbogbo ibeere Ayaba naa, I Awọn Ọba 10:3; Isaiah 11:2; Matteu 13:54; Romu 11:33; Johannu 2:25; Jeremiah 32:17-19

III Ogo Sọlomọni

1. Ogo ijọba Sọlomọni ya Ayaba naa lẹnu gidigidi, I Awọn Ọba 10:4, 5; Daniẹli 8:17; 10:8; Ifihan 1:17; 19:10

2. Ayaba S̩eba jẹri pé otitọ ni iroyin ti oun ti gbọ ni ti Ọlọrun Sọlomọni, o si fi ogo fun Un, I Awọn Ọba 10:6-9; Johannu 4:29; 9:38; 20:25

IV Ọpọ Ọrọ Ọba

1. Ayaba S̩eba ta Sọlomọni lọrẹ ti o ṣọwọn ti o si niye lori, I Awọn Ọba 10:2, 10-12; Orin Dafidi 72:10, 15; Matteu 2:1, 2, 11

2. Sọlomọni fun Ayaba ni ohun gbogbo ti ọkàn rè̩ n fẹ, I Awọn Ọba 10:13; Orin Dafidi 144:10; 149:4; Matteu 15:28; Johannu 14:14; Efesu 3:20

3. Ọpọ ọrọ, ọgbọn, imọ, ọlá ati ogo Sọlomọni jẹ apẹẹrẹ titobi ẹwa ati ogo Oluwa ati Ijọba Rè̩, I Awọn Ọba 10:14-29; Daniẹli 7:13, 14; Luku 1:32, 33; Orin Dafidi 145:13; Ifihan 21:1, 2, 22-26

Notes
ALAYÉ

Ipe Ọlọrun

Iwe Mimọ sọ fun ni nipa Farao ọba Egipti pe Ọlọrun ni o mu ki o wà ni ayè Farao. “Nitori eyiyi na ni mo ṣe gbé ọ dide, ki emi ki o le fi agbara mi hàn lara rẹ, ki a si le mā rohin orukọ mi ká gbogbo aiye” (Romu 9:17; Ẹksodu 9:16).

Ọlọrun gbé Sọlomọni ga gidigidi ki orukọ Ọlọrun le di mimọ ká gbogbo aye. A mọ pe otitọ ni eyi, nitori ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti a yàn fun ẹkọ wa sọ fun ni pe Ayaba S̩eba, ti o wa ni ilu ti o jinna réré, gbọ okiki Sọlomọni, nipa orukọ Oluwa. Ki i ṣe okiki Sọlomọni nikan ni o gbọ, o gbọ okiki Ọlọrun ti Sọlomọni n sin pẹlu. Eyi ni ọna ti Ọlọrun n gbà nigbà nì lati mu ki eniyan mọ pe Ọlọrun wà, kò si si ẹni ti o dabi Rè̩! (Wo Isaiah 46:9).

Sọlomọni, ti i ṣe ọdọmọde nigba ti o bẹrẹ si jọba lori Israẹli beere ọgbọn ati òye lọwọ Ọlọrun, ki o ba le ṣe akoso Israẹli ni ododo. Inu Ọlọrun dun si ibeere Sọlomọni to bẹẹ ti ki i ṣe ọgbọn nikan eyi ti ẹnikẹni kò ni iru rè̩ ri – afi Jesu Kristi – ni Ọlọrun fi fun un -- ṣugbọn a fun un ni ọrọ ati ọlá pẹlu. (Ka I Awọn Ọba 3:5-13). Ọlọrun bukun Sọlomọni gidigidi, Ọlọrun si lo eyi lati gbé Orukọ Rè̩ ga gidigidi. Lọna bayii ni Ayaba S̩eba ṣe gbọ nipa Ọlọrun, o si wá bẹ Sọlomọni wò lati fi alọ dan an wo.

Bawo ni ọpẹ wa si Ọlọrun ti ni lati pọ to fun oore Rè̩ si awọn ẹda ọwọ Rè̩, nigbà ti a ba ranti ohun nla ti Ọlọrun ṣe lati pe ẹlẹṣẹ wa si ironupiwada! A gbe odindi orilẹ-ède kan leke, a fun ẹni kan ni ọgbọn ti kò lẹgbẹ, ati ọrọ, ati ọlá, nitori ki Ọlọrun ki O le fa gbogbo eniyan sọdọ ara Rè̩.

Bi a ti ka nipa ọna ti Ayaba S̩eba gbà lati kọ gbọ nipa Oluwa, a ranti asọtẹlẹ Isaiah, “Awọn enia ti nrin li okùnkun ri imọlẹ nla: awọn ti ngbe ilẹ ojiji ikú, lara wọn ni imọlẹ mọ si” (Isaiah 9:2).

Ibeere ti o Takoko

Ki i ṣe irin ooraye ni Ayaba S̩eba rìn nigbà ti o wa bẹ Sọlomọni wò. O wá lati mọ bi otitọ ni iroyin ti o ti gbọ. Irin-ajo yii ni lati mu wahala pupọ lọwọ, lai si aniani o kún fun ọpọ iṣoro. Irin-ajo naa jin; ni ti pe obinrin yii ti o jé̩ alakoso ni ijọba ti rè̩ tilẹ daba lati mu irin-ajo bayii pọn fi hàn fun ni pe ki i ṣe ọfintoto lasan tabi ifẹ lati lọ bẹ Sọlomọni wo gẹgẹ bi ọba si ọba ni o mu ki o dide irin-ajo yii.

Lati sọ pe Ayaba yii wá bẹ Sọlomọni wò fun idi miiran yatọ si pe o n fẹ alaye nipa awọn ohun ti o jẹ mọ igbala ati alaafia ayeraye fun ọkàn rè̩, yoo jẹ abuku si iwa rere ati ninilaari obinrin yii. O n wa Otitọ, lai si aniani kò si ọna jijin, tabi iṣoro ti o le ṣe idena fun un lati má ri idahun si awọn adiitu ti o wà lọkàn rè̩ ti o dabi ẹni pe kò si ẹni ti o le yanju rè̩.

Bawo ni yoo ti dun tó bi ọpọ eniyan bẹẹ ba wa layé ode oni ti o ni oungbẹ lati ri idahun tootọ si awọn ibeere ati adiitu ti o wà ni igbesi aye wọn! Awọn eniyan n lepa ọrọ aye ti kò duro pẹ yii pẹlu gbogbo ọkàn ati agbara wọn. Iye ọkàn ti o n lepa ogo ati ọlá aye yii kò lonka. Ipa ọna aye yii kún fun ẹgbaagbeje ọkàn ti o kú sinu è̩ṣẹ bi wọn ti n lepa ohun asan aye yii ti yoo ba ayé kọja lọ.

Diẹ ni awọn wọnni ti n wa Orisun Iye – Jesu Kristi – ti wọn si n fẹ Otitọ nitori Otitọ gan an. Awọn ti o ba n fẹ tọkantọkan lati ri idahun si awọn ohun adiitu ti o wà ni igbesi aye wọn yoo ri Ẹni ti o le yanju gbogbo ọran wọn yekeyeke.

Ẹni Kan ti O Tobi Ju Sọlomọni lọ

Ayaba S̩eba kò rin irin-ajo ti o jinna yii lasan. Ọrọ Ọlọrun wi pe, “Sọlomọni si fi èsi si gbogbo ọrọ rè̩, kò si ìbèrè kan ti o pamọ fun ọba ti kò si sọ fun u” (I Awọn Ọba 10:3). Ọlọrun kò jẹ ki o pada lọ ni ọwọ ofo fun gbogbo laalaa rè̩. Ọlọrun fun Sọlomọni ni idahun si gbogbo awọn ibeere wọnni. Ọlọrun ki i fa eniyan sọdọ ara Rè̩ ki O si kọ lati feti si aroye wọn. (Ka Johannu 6:37).

Nigba ti Jesu n ba awọn Ju wi nitori aigbagbọ wọn, O yin Ayaba S̩eba gidigidi, O si fi hàn pe o yẹ ki gbogbo eniyan tẹle apẹẹrẹ rè̩. Jesu ni aworan Ọlọrun, Oun ni Imọlẹ araye; O si tobi jù Sọlomọni. Sibẹ Israẹli kọ Ọ! O wi fun wọn pe, “Ọba-birin gusù yio dide pẹlu iran yi li ọjọ idajọ, yio si da a lẹbi: nitori o ti ikangun aiyé wá ígbọ ọgbọn Sọlomọni; si wò o, ẹniti o pọ ju Sọlomọni lọ mbẹ nihinyi” (Matteu 12:42).

Ayaba S̩eba mu anfaani orisun ọgbọn ti o ṣi silẹ fun un lo, bi o tilẹ gbà pe ki o wá lati ikangun aye lati wá gbọ ọgbọn. Nitori naa yoo dide ni idajọ si awọn wọnni ti Ihinrere Kristi wà ni arọwọto wọn, ti wọn si kuna lati feti si i. Egbe ni fun aye nigba ti a ba mu idajọ yii ṣẹ! Awawi wo ni ẹnikẹni yoo ṣe fun è̩ṣẹ ti o n da nigba ti Ọlọrun ti pese ọna idariji fun è̩ṣẹ silẹ, ti ẹni naa kò fẹ ẹ, ti kò si wa a? Nigba ti Ayaba yii ba sọ ẹri rè̩ nipa irin-ajo jijin ti o rin lati kọ ọgbọn lọdọ Sọlomọni, awawi wo ni ẹnikẹni ti kò naani lati wa Kristi yoo ṣe ti yoo si jẹ itẹwogba? Jesu Kristi ni i ṣe Otitọ gan an, a si le tọ Ọ wa lati wá ọna iye ati otitọ. Ninu Kristi ni a fi gbogbo iṣura ọgbọn ati imọ pamọ si (Kolose 2:3). (Wo Johannu 14:6 pẹlu).

Yoo ṣe wa ni ire nigbà naa bi a ba tọ Jesu wa lati beere idahun tootọ si gbogbo awọn ibeere ti o wà lọkàn wa nipa ayeraye. Nigba naa a o le dide pẹlu Ayaba S̩eba ni ọjọ ikẹyin lati jẹri si i pe gbogbo ibeere wọnni ni a dahun yekeyeke.

Ihin Tootọ

“O si wi fun ọba pe, Otitọ li ọrọ ti mo gbọ ni ilẹ mi niti ìṣe rẹ ati niti ọgbọn rẹ. S̩ugbọn emi kò gba ọrọ na gbọ, titi mo fi de, ti oju mi si ti ri: si kiyesi i, a kò sọ idaji wọn fun mi: iwọ si ti fi ọgbọn ati irọra kún okiki ti mo gbọ.”

Ẹnikẹni ha le ṣe apejuwe oungbẹ ati ireti ti i maa gba ọkàn kan nigba ti eniyan ba n tọ Ọlọrun wa lati wa gba idariji fun awọn è̩ṣẹ ti o wà ni igbesi aye rè̩? Ọlọrun a maa lo okùn ireti fẹlẹfẹlẹ ti o wà lọkàn ọmọ eniyan lati fa ẹni naa lati mọ aanu ati oore-ọfẹ igbala Rè̩! O ṣe e ṣe ki Ayaba S̩eba ni aṣiro pupọ nipa bi irin-ajo rè̩ yii ti le yọri si. Lai fi gbogbo iyemeji rè̩ ti kò dẹkun pe, o dide pẹlu ireti wi pe Sọlomọni yoo le dahun awọn ibeere ti o wà ni ikọkọ ọkàn rè̩ fun un. Nigba ti o ri ohun ti o ti ọna jijin wa ri, ati lati wa gbọ gbà, kò le kó ara rè̩ nijanu mọ, o si wi pe, “A kò sọ idaji wọn fun mi.”

Ẹri ti o fara jọ eyi pe, “A kò sọ idaji wọn fun mi,” jẹ ẹri ti ọpọlọpọ awọn wọnni ti o gbọ ihin igbala, ti wọn wá ti wọn si mọ agbara irapada ni igbesi aye wọn ti sọ. Bi ọkàn eniyan ti ri nigba ti a ba dari è̩ṣẹ rè̩ ji tayọ ohun ti ahọn le royin tan lọ.

Ọlanla Jọba

“Nigbati ayaba S̩eba si ti ri gbogbo ọgbọn Sọlomọni, ati ile ti o ti kọ, ati onjẹ tabili rè̩, ati ijoko awọn ọmọ-ọdọ rè̩, ati iduro awọn iranṣẹ rè̩, ati iwọṣọ wọn, ati awọn agbọti rè̩, ati ọna ti o mba goke lọ si ile Oluwa; kò kù agbara kan fun u mọ.” Ki i ṣe Ayaba S̩eba ni ẹni akọkọ tabi ẹni ikẹyin ti iwọṣọ ati iwa awọn ọmọ Ọlọrun kún loju, ati ẹmi isin ati iyin Ọlọrun ti o n ṣakoso ohunkohun ti awọn Onigbagbọ ni tabi ti wọn n ṣe. Awọn eniyan Ọlọrun ni iwe ti awọn eniyan n ri ti wọn si n ka; ohunkohun ti wọn ba si n ṣe ati ohunkohun ti wọn ba sọ pẹlu jẹ ẹri fun awọn wọnni ti wọn wà lẹyin agbo Ijọba Ọlọrun.

Ẹwa aafin Sọlomọni kò ni àkàwé ni akoko ti rè̩, lai si aniani ogo rè̩ kò ṣe e fẹnu sọ lọnakọna. Sibẹ a gba wi pe ohun ti Ayaba S̩eba ri tayọ ohun ti a le foju ara nikan ri. Ẹwa ile, afẹfẹ-yè̩yẹ ati ariya, aṣọ igunwa ọba, awọn iranṣẹ ti o wọṣọ ti o gbamuṣe, ati adun ohun gbogbo kọ ni o n fi bi ọba ti nilaari to hàn. Ninu eniyan ni ọlanla i gbe maa fi ara hàn -- ọlanla Ọlọrun si wà ninu aafin Sọlomọni. Awọn ọba olokiki miiran wà ti wọn ni aafin ti ogo ati ẹwa rè̩ to ti Sọlomọni ni ti ayé; ṣugbọn ogo ati ọla ayé ti n bọ wa ni aafin ti Sọlomọni. Ogo Ọlọrun wà ni aafin rè̩, a si ri ẹwa Ọlọrun Ẹlẹda ninu olukuluku eniyan, ati ninu ijọsin olukuluku eniyan.

Ogo Ọlọrun ti Ayaba S̩eba ri ati imisi Ọlọrun ti o wọnu rè̩ ni o mu ki ọkàn rè̩ wolẹ fun Ọlọrun. A mọ pe eyi pẹlu ni iriri ọmọ Ọlọrun ti o ti gbadura gbigbona ti igbagbọ ti ki i tase, ani yoo mọ pe oun wà niwaju Ọlọrun, yoo si pada pẹlu imisi ati ogo ọlanla Ọlọrun ti ahọn kò le royin tan. Nigba ti eniyan ba mọ pe oun wà ninu Ẹmi niwaju Ọlọrun, ayọ kan ti a kò le fẹnu sọ yoo gba ọkàn rè̩ kan. Nipa adura oun yoo lọ si “ilu ti o jinna rere” yoo si ba Ọba awọn ọba sọrọ, a o si yanju ohunkohun ti i ṣe adiitu ni igbesi aye rè̩.

Sọlomọni ọba té̩ ifẹ ọkàn Ayaba S̩eba lọrun, pẹlupẹlu o si ta a lọrẹ lọpọlọpọ. Lai si aniani, wahala ati iṣoro irin-ajo rè̩ pada sile yoo fuyẹ nigba ti o ba ranti adun ibi ti oun ti n bọ wa, ọkàn oun paapaa ti alaafia ti wọ, ati ọgbọn ti o ti ṣe laalaa to bẹẹ lati ni.

Bakan naa ni o ri fun ẹlẹṣẹ ti o tọ Ọlọrun wa fun aanu ati idariji. O ri ifẹ ọkàn rè̩, a si tun ta a lọrẹ lati inu ini Ọba. Oun yoo pada sile pẹlu ayọ ati idariji è̩ṣẹ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni Ayaba S̩eba ṣe gbọ nipa Ọlọrun Sọlomọni?
  2. Eredi rè̩ ti Ayaba ṣe fẹ ri Sọlomọni?
  3. Njẹ iwọ rò pe o yẹ fun un lati ṣe wahala pupọ ki o to le de aafin Sọlomọni?
  4. Ki ni ṣe ti Jesu yin Ayaba S̩eba?
  5. Bawo ni Sọlomọni ṣe jẹ apẹẹrẹ Oluwa?
  6. Bawo ni a ṣe mọ pe Ayaba S̩eba ri idahun si gbogbo ibeere rè̩ gba?
  7. Eeṣe ti aafin Sọlomọni fi wu Ayaba yii to bẹẹ?
  8. Bawo ni Onigbagbọ ṣe n mọ nipa ibugbe Oluwa?