Lesson 260 - Senior
Memory Verse
“On o pọ, Ọmọ Ọgá-ogo julọ li a o si ma pè e; Oluwa Ọlọrun yio si fi ité̩ Dafidi baba rè̩ fun u” (Luku 1:32).Cross References
I Ikede Angẹli fun Sakariah
1. Ibẹrẹ ọrọ Luku fi otitọ irohin rè̩ han, Luku 1:1-4; II Timoteu 3:16
2. Ododo ati itara Sakariah ati Elisabẹti mu ki wọn le wulo fun Ọlọrun, Luku 1:5-7; I Timoteu 6:11-16; Titu 1:5-9
3. Angẹli fara hàn ni Ibi Mimọ bi Sakariah ti n sun turari, Luku 1:8-11; Ẹksodu 30:1-9; Ifihan 8:3; Orin Dafidi 141:2
4. Angẹli naa tu Sakariah ninu o si jiṣẹ Ọlọrun fun un, Luku 1:12-17; Daniẹli 8:16; 9:21-23; 10:10-12
5. Angẹli naa sọ ẹni ti oun i ṣe fun Sakariah lati mu iyemeji rè̩ kuro, o si fi ami kan fun un lati jẹri si otitọ Ọrọ Ọlọrun, Luku 1:18-20
6. A mu ọrọ Ọlọrun ṣẹ, Luku 1:21-25
II Ikede Angẹli fun Maria
1. A yàn Gabriẹli lati mu ọrọ Ọlọrun tọ Maria wa pẹlu, Luku 1:26, 27
2. Angẹli naa ki Maria o si jiṣẹ fun un, Luku 1:28-33
3. Ibeere Maria ki i ṣe ti iyemeji ṣugbọn o fẹ mọ ipa ti oun ni lati kó ninu ọran naa, Luku 1:34
4. Angẹli Gabriẹli ṣe alaye iṣẹ Ẹmi Mimọ, o ki Maria laya, o si sọ nipa ti agbara nla Ọlọrun, Luku 1:35-37; Jobu 42:2; Orin Dafidi 115:3; Matteu 19:26
5. Maria gbà tọkantọkan lati wulo fun Ọlọrun lọna bayi, Luku 1:38; Orin Dafidi 110:3; Isaiah 1:19; II Kọrinti 8:3
III Ifarahàn Angẹli fun Josẹfu
1. Ọkàn Josẹfu daru nitori o rò pe Maria ti ṣe aiṣootọ, Matteu 1:18, 19; Deuteronomi 22:22-27
2. Josẹfu jẹ oloootọ eniyan, Ọlọrun si ran angẹli kan si i lati sọ ti bibọ Kristi fun un, Matteu 1:20-23
3. Josẹfu gbọran si ọrọ Ọlọrun, Matteu 1:24, 25
Notes
ALAYÉAwọn Angẹli ati awọn Olori Angẹli
Gẹgẹ bi a ti bẹrẹ si ké̩kòọ nipa itan ayebaye ti Keresimesi ti i ṣe itan akọtun sibẹ, ẹ jẹ ki a rán ara wa leti nipa awọn nkan diẹ ti o jẹ mọ ọn.
O ti to nnkan bi irinwo ọdún sẹhin ti a sọ asọtẹlẹ ti o kẹhin lati ẹnu angẹli fun Israẹli. Ọpọlọpọ ọdun ti kọja lẹhin ti Ọlọrun ti fi ara Rè̩ hàn fun ayanfẹ orilẹ-ede Rè̩ lọna awamaridi. Ifarahan Angẹli ti a kọ silẹ kẹyin ni ti Gabriẹli, olori angẹli, nigba ti o fara han Woli Daniẹli pẹlu iroyin lati ọdọ Ọlọrun nipa ikolẹrú wọn. Gabriẹli darukọ olori angẹli miiran nigba naa ani Mikaẹli. A kò sọ iye awọn olori angẹli fun ni ṣugbọn Gabriẹli sọ wi pe oun jade wa lati iwaju Ọlọrun; a si sọ fun ni ninu iwe ti o kẹyin ninu Iwe Mimọ pe, awọn angẹli meje ni o maa n duro niwaju Ọlọrun (Ifihan 8:2). A kò mọ boya olori angẹli ni awọn meje wọnyi i ṣe, tabi boya Gabriẹli ati Mikaẹli wa ninu awọn meje wọnyii. S̩ugbọn a mọ pe awọn ẹda ọrun meji wọnyii jẹ iranṣẹ pataki lati ọdọ Ọlọrun, wọn a si maa ṣe iṣẹ iranṣẹ fun Ọlọrun lọna pataki ni jijẹ iṣẹ ti o ṣe pataki jù lọ.
A pè Mikaẹli ni ọkan ninu awọn olori balogun (Daniẹli 10:13), a si sọ fun ni pe o n gbeja awọn ọmọ eniyan Daniẹli, ani awọn Ju (Daniẹli 10:21; 12:1). Mikaẹli, nigba naa, jẹ angẹli pataki kan ti a fi iṣẹ kan le lọwọ lati ṣe nipa awọn ayanfẹ Ọlọrun. Iwe Mimọ sọ fun ni pe a n fi iṣẹ ti o ba jẹ kan-n-pa le e lọwọ lati ṣe, ani o tilẹ ba Eṣu paapaa ṣe ọpẹalaye (Juda 9; Ifihan 12:7).
S̩ugbọn a fun Gabriẹli ni anfaani ti o tobi jù eyi ti eyikeyi ninu awọn iranṣẹ lati ọrun wa le ni lọ. A n kẹkọọ nipa awọn ifarahan pataki wọnyii ninu ẹkọ yii. Igba miiran, ti a kọ silẹ ninu Bibeli wi pe Gabriẹli fara hàn ni akoko ti awọn Ọmọ Israẹli wa ni oko ẹru, nigba ti o tọ Daniẹli wa ti o wa jiṣẹ ti Ọlọrun ran an nipa ti ikẹhin ọjọ ati awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ ṣaaju ati ni akoko Ifarahan Kristi. A le ri i nigba naa wi pe iṣẹ iranṣẹ Gabriẹli ni lati wa sọ nipa Jesu Kristi, Ọba Ogo, gẹgẹ bi Olugbala araye.
Gabriẹli Tọ Sakariah Wá
O dùn mọ wa lati ri i bi gbogbo awọn ifarahan angẹli yii ti ba Eto Ọlọrun mu kin-ni-kin-ni. Gabriẹli kọ fi ara hàn fun ọkan ninu awọn alufa – Sakariah – ti o n ṣe iṣẹ isin ninu Ile Ọlọrun ni Jerusalẹmu ti i ṣe ilu Ọlọrun. Alufaa ni alarina laarin awọn eniyan ati Ọlọrun; ati pe gẹgẹ bi eto Ọlọrun, ninu wọn ni a ni lati fi iran tabi iṣipaya hàn fun. O yẹ ki a ṣe akiyesi pe Gabriẹli kò fi ara hàn fun Sakariah ni ilu oun tikara rè̩, ṣugbọn o tọ ọ wa si ibi ti o tọna lati jẹ iru iṣẹ bẹẹ fun un. O wá si Ile Ọlọrun lati wa ba aṣoju awọn eniyan pade nibẹ. Ile Ọlọrun ni a ti n gbọ Ọrọ Ọlọrun jù lọ ni ojulowo rè̩. Ni Ile Ọlọrun, ti a ya sọtọ fun isin Ọlọrun, ni Ọlọrun saba maa n fi ifẹ Rè̩ han fun awọn eniyan Rè̩ jù lọ. Ọlọrun ṣe ohun gbogbo daradara. O fi iṣẹ pataki jù lọ yii ran iranṣẹ ti o tọ si gan an, ni akoko ti o tọ, si ibi ti o tọ, si ẹni ti o tọ si lati gbọ ọ.
A ni lati tun ṣe akiyesi pe ni akoko adura ni iṣẹ ti Ọlọrun ran de ọdọ wọn. Eyi pẹlu jẹ ẹkọ fun gbogbo wa. A ki i gbọ Ohùn Ọlọrun nigba ti aniyan aye yii ba gba ẹmi wa kan, afi bi Ohùn naa ba wa kilọ fun wa nipa aṣiṣe wa. O di mimọ fun wa nipa iriri, ati nipa akọsilẹ Ọrọ Mimọ Ọlọrun pe Ọlọrun a maa sun mọ wa nigba ti a ba sun mọ Ọn. Nigba ti turari idapọ mimọ wa ba goke re ọrun sibi ité̩ nì, nigba naa, ani igba naa nikan ṣoṣo ni a le ni ireti lati gbọ ohùn lati Ọrun wa lati sọ ifẹ Ọlọrun fun ni.
Sakariah ati aya rè̩ jẹ ẹni ti Ẹmi Mimọ le sọrọ iwuri nipa wọn. “Awọn mejeji si ṣe olododo niwaju Ọlọrun, nwọn nrin ni gbogbo ofin on ilana Oluwa li ailẹgan.” Ọrọ wọnyi ti wu ni lori to nipa awọn meji ninu ọmọ eniyan.
Olododo niwaju Ọlọrun! Ọpọlọpọ eniyan ni ayé ti foju wo bi olododo niwaju eniyan gẹgẹ bi odiwọn ti eniyan. S̩ugbọn awọn meji wọnyii jẹ olododo niwaju Ọlọrun, “nwọn nrin ni gbogbo ofin on ilana Ọlọrun li ailẹgan.” Ọpọlọpọ ni o ti tẹle aṣa ati eto isin Ọlọrun, ti o ba eto isin igba ayé ofin mu kin-ni-kin-ni, ṣugbọn sibẹsibẹ è̩ṣẹ n bẹ ninu ọkàn oun aya wọn lọhun ti kò fara hàn fun awọn eniyan lati ri. S̩ugbọn awọn meji wọnyii jẹ alailẹgan ninu irin wọn. Ailẹgan wọn ki i ṣe niwaju eniyan nikan ṣoṣo bi kò ṣe niwaju Ọlọrun!
Jẹ ki gbogbo awọn wọnni ti o n wi pe awọn olufọkansin tootọ ti akoko Majẹmu Laelae kò ri iwa-bi-Ọlọrun ti o ga bi ti isisiyi gbà, gbiyanju ninu ipa ara wọn lati de odiwọn ti awọn iranṣẹ Ọlọrun meji wọnyii de ninu ododo ati iwa-bi-Ọlọrun! A ti gbà Sakariah ati Elisabẹti là kuro ninu è̩ṣẹ wọn; a si ti sọ wọn di mimọ!
Awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun ni Ọlọrun maa n ranṣẹ si. Awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun pupọ miiran le wa nigba yii ti awọn naa n reti bibọ Messia. S̩ugbọn awọn meji wọnyii ni Ọlọrun yàn lati mu eto Rè̩ ṣẹ. Sakariah jẹ ẹni ti o fara balẹ gidigidi bi o tilẹ jẹ pe ihin agbayanu yi ṣe e ni kayefi diẹ. Iyemeji ti o n bẹ lọkàn Sakariah kì i ṣe iru eyi ti o le di Ọlọrun lọwọ lati ṣe ohun ti O fẹ ṣe. Yatọ si ododo ati iwa-bi-Ọlọrun ti a ti mẹnu ba pe o wà ninu ọkàn awọn eniyan mimọ Ọlọrun meji wọnyii, wọn tun ni odiwọn igbagbọ ninu Ọlọrun ati Ọrọ Rè̩ ti o to lati mu ki Ọrọ Ọlọrun ṣiṣẹ ninu wọn.
Gẹgẹ bi aṣa, ọba kọọkan ni o ni aṣiwaju ti o n tun ọna ṣe niwaju rè̩. Ọlọrun yàn lati tun ọna ṣe niwaju Ọmọ Rè̩ nipa riran ẹni mimọ kan lati waasu Ihinrere Ijọba Ọlọrun fun awọn eniyan ayanfẹ Rè̩. A rii pe irinwo ọdún ti kọja ná ti a ti gbohùn woli kẹhin ti o gbe ohun rè̩ soke lati jiṣẹ Ọlọrun, woli naa si ni ẹni ti o ṣe apejuwe ti o yanju jù lọ nipa bibọ Woli ti yoo tun tẹle e – ani ẹni ti yoo tun ọna Jesu Kristi ṣe. (Ka Malaki 4:4-6; Luku 1:16, 17; ati Matteu 11:7-15).
Bawo ni a ba tun ṣe kede wiwa ẹni ti yoo tun ọna Oluwa ṣe? Nipa ikede lati ẹnu Angẹli. Ta ni a le fi iṣẹ pataki ti o ti Itẹ Ọlọrun wá yii ran? Gabriẹli, olori angẹli ti o duro niwaju Ọlọrun. Oun ni a fi iṣẹ yii le lọwọ lati kede rè̩ ati awọn ihin miiran nipa Kristi Ọba Ogo. A ti ri iru iwa ti awọn ẹni ti o tọ wa ni -- awọn ẹni ti a fi ọkàn tan ti a si yàn lati gbọ ihin yii ati lati mu eto Ọlọrun yii ṣẹ fun awọn ẹda ti o ti ṣubu. Iwe Mimọ si ti sọ fun ni bi a ti ṣe mu un ṣẹ kin-ni-kin-ni ni gbogbo ọjọ ayé ẹni naa ti o wa tun ọna Oluwa ṣe.
Gabriẹli Tọ Maria Wa
Angẹli kan naa ni o tun fara han lati mu ihin pataki jù lọ tọ obinrin mimọ, olufọkansin ati onirẹlẹ kan ara Galili lọ. Wundia alailabuku yii jẹ afẹsọna ọkunrin kan ti a n pe ni Josẹfu. Iṣẹ ti Ọlọrun ran si i ni pe, Oluwa kọju si i ṣe li oore ati pe Oluwa wà pẹlu rè̩. O beere bi ohun ti a sọ fun un yoo ṣe ṣẹ -- kì i ṣe pẹlu iyemeji; ṣugbọn ki o ba le mọ ifẹ Ọlọrun fun un ati ohun ti o ni lati ṣe lati mu ifẹ Ọlọrun naa ṣẹ. A sọ fun un pe Ẹmi Mimọ yoo ṣe ohun ti kò ṣe e ṣe, yoo si mu ipinnu Ọlọrun ṣẹ.
Eyii pẹlu jẹ ẹkọ fun wa. A mọ pe Ọlọrun yoo fun ni ni agbara lati ṣe ohun ti O ba palaṣẹ fun ni lati ṣe. Nigba ti Ọlọrun ba n tọ wa, Oun yoo mu ki ohun ti O beere ṣe e ṣe. Kì i ṣe ti wa lati ja A niyan tabi ki a ṣiyemeji si ipese Rè̩ fun wa bi a ti n tọ ọna ti O la silẹ fun wa. A le beere ọna, akoko tabi ibi ti Ọlọrun yàn gẹgẹ bi Maria ti ṣe. S̩ugbọn a kò gbọdọ ṣiyemeji tabi ki a maa ṣe ọfintoto ti kò nilaari. Ibukun wà fun wa bi a ba gbọran. A o kó sinu wahala bi a ba ṣaigbọran.
Angẹli Tọ Josẹfu Wa
Josẹfu paapaa n fẹ idaniloju. Ọlọrun kò jẹ fi ọkan ninu awọn ti Rè̩ silẹ lai ni itunu tabi ikiya ti o tọ. Oun ni lọwọlọwọ iranlọwọ, lati ki ni laya ati lati tọ wa sọna nigba ti a kò ba mọ ọna ti o yẹ ki a tọ.
A kò darukọ angẹli ti o fara han Josẹfu. Kì i ṣe ohun danindanin lati mọ orukọ rè̩, bi bẹẹ kọ Ẹmi Mimọ i ba sọ fun ni. Ohun ti o ṣe pataki fun wa lati mọ ni pe Ọlọrun ranṣẹ ti o tọ si Josẹfu, Oun yoo si ṣe ohun kan naa fun ni nigba ti a ba wà ninu iṣoro ti a si n fẹ iranwọ ati itọni. Ọlọrun le ṣe eyii lọnakọna ti O ba yàn, ṣugbọn ni akoko Ihinrere yii, Ọrọ Rè̩ ni O n lo jù lọ lati mu ki ifẹ tabi aṣẹ Rè̩ di mimọ fun ni. Ikiyà ati imisi lati mu aṣẹ wọnni ṣẹ si n bẹ fun ni ninu Iwe Mimọ. Oore ati aanu Ọlọrun wa ti pọ to!
Angẹli naa tọka Josẹfu, ọkunrin oloootọ nì si Ọrọ Ọlọrun fun ifidimulẹ iṣẹ ti o mu wa lati ọdọ Ọlọrun. Alaye ohun ti o jẹ adiitu fun Josẹfu n bẹ ninu ọrọ awọn woli nipa Jesu. Eyii pẹlu si jẹ ẹkọ fun ni. “Si ofin ati si ẹri,” ni lati jẹ akọmọna wa nigba gbogbo. Bi a ba ri ohunkohun ti a ro pe iṣẹ tabi aṣẹ lati ọdọ Ọlọrun wa ni a ni lati lọ sinu Ọrọ Ọlọrun lati ṣe ayẹwo bi iṣẹ tabi aṣẹ naa ba ṣe deedee pẹlu Ọrọ Ọlọrun. Lọna bayii ni a le ni idaniloju pe ohùn Ọlọrun ni a n gbọ nitori pe ifẹ Ọlọrun kò ni tako Ọrọ Rè̩.
Wiwá Ọmọ Ọlọrun
Bayii ni a ṣe ni awọn alaye ṣoki ṣoki nipa ifarahàn awọn angẹli ṣaaju ibi Kristi, ninu eyii ti a le ri ẹkọ iyebiye kọ. Akoko pataki ni yii ni igbesi aye awọn Ọmọ Israẹli. Akoko pataki ni fun gbogbo agbaye pẹlu. Ọmọ Ọlọrun n bọ wa di Ọmọ Dafidi. A o bi I lati jiya ati lati kú fun wa, lati gbà wa là kuro ninu è̩ṣẹ wa. Wiwa si aye Rè̩ kì i ṣe ohun ti o kan ṣẹlẹ ṣa lọna ti ohun gbogbo n gba ṣẹlẹ lọjọọjọ ninu ayé yii. Ohun ti o ṣẹlẹ yii ṣe pataki jù lọ ninu awọn ohun ti o ti ṣẹlẹ, nitori pe lai si ibi Rè̩, kò le kú lati fi ara Rè̩ rubọ. Lai jẹ pe O kú, kì yoo si ajinde. Lai jẹ pe O jinde, asan ni igbagbọ wa, a o si wa ninu è̩ṣẹ wa sibẹ.
S̩ugbọn ọpẹ ni fun Ọlọrun fun ibi Kristi ti o mu ikú ati ajinde Rè̩ fun idalare wa ṣe e ṣe! A tun dupẹ lọwọ Ọlọrun ti O fun wa ni otitọ ti o daniloju nipa iṣẹlẹ wọnyii nitori pe a ti sọ asọtẹlẹ wọn lati ẹnu awọn woli nipasẹ imisi Ẹmi Mimọ, O si mu wọn ṣẹ nipasẹ isin atọkanwa awọn eniyan mimọ lọkunrin ati lobinrin, awọn eniyan bi Sakariah, Elisabẹti ati Maria. A fọpẹ fun Ọlọrun ti O kede ti O si fidi awọn iṣẹlẹ pataki wọnyii mulẹ nipa ifarahàn awọn olori angẹli giga ju lọ ni Ọrun, ifarahan eyii ti o ti di otitọ ti o fidi mulẹ. Ọpẹ ni fun Ọlọrun pe O mu awọn asọtẹlẹ wọnyii ṣẹ -- ti awọn angẹli ati ti awọn woli – ni kikún ati ni kin-ni-kin-ni, nipasẹ eyi ti O jẹri si otitọ ati pipe eto Rè̩ fun wa.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni eredi ti a fi kọ Ihinrere ti Luku gẹgẹ bi ẹni ti o kọ iwe naa ti fi hàn ninu awọn ẹsẹ ti o ṣaaju?
- Ki ni ohun ti iwọ le ranti pe Iwe Mimọ sọ fun ni nipa iwa aye Sakariah ati Elisabẹti nipa ti Ẹmi?
- Nibo ni Sakariah wà nigba ti angẹli yọ si i?
- Sọ igba miiran gbogbo ti angẹli Gabriẹli fi ara hàn fun awọn ọkunrin tabi obinrin.
- Ki ni iṣẹ ti angẹli naa jẹ fun Sakariah? ihà wo ni o kọ si iṣẹ naa?
- Iṣẹ wo ni Gabriẹli jé̩ fun Maria?
- Ki ni iṣẹ naa ti a ran si Josẹfu?
- Sọ diẹ ninu awọn ẹkọ ti o ri kọ ninu ẹkọ yii.
- Njẹ Maria ṣiyemeji ọrọ angẹli nì bi?
- S̩e atunwi Luku 1:37 ati awọn ọrọ miiran ti o fara jọ ọ ninu Iwe Mimọ.