Orin Dafidi 37:1-40

Lesson 261 - Senior

Memory Verse
“Ma kiyesi ẹni pipé, ki o si ma wò ẹni diduro ṣinṣin: nitori alafia li opin ọkọnrin na” (Orin Dafidi 37:37).
Cross References

I Iyatọ ti o Wà Laaarin Ọnà Ẹni Iwa-bi-Ọlọrun ati ti Alaiwa-bi Ọlọrun

1. Olododo kò ni lati binu nitori ọpọ ọrọ eniyan buburu, Orin Dafidi 37:1, 2, 7-10, 20, 27, 28, 35, 36, 38; Owe 23:17

2. A gba olododo niyanju lati fi ọna wọn le Oluwa lọwọ, Orin Dafidi 37:3, 4, 5, 23, 24, 27, 34; I Samuẹli 2:9; Isaiah 58:14

3. Awọn onirẹlẹ ni yoo jogun aye, Orin Dafidi 37:11, 18, 22, 29, 34

4. Oluwa yoo rẹrin awọn eniyan buburu nitori O rii pe idajọ n bọ, Orin Dafidi 37:17, 32, 33; 2:4; Jobu 38:15

5. Olododo le ni ohun diẹ, ṣugbọn a o tẹ wọn lọrun ni igba ìyàn, Orin Dafidi 37:16, 19, 21, 25, 26; Jobu 5:20; Owe 15:16; Deuteronomi 15:8

6. Ẹsẹ olododo kì yoo yè̩, Orin Dafidi 37:30, 31; Deuteronomi 6:6

7. Eniyan buburu gbilẹ, lẹyin naa o kọja lọ, a kò si ri i mọ, Orin Dafidi 37:35, 36; Jobu 5:3

8. Alaafia ni opin ẹni pipe ati ẹni diduro ṣinṣin, Orin Dafidi 37:37-40; I Kronika 5:20; Isaiah 32:17

Notes
ALAYÉ

Psalmu yii ga lọla ni tootọ. Orin igbẹkẹle Ọlọrun ni. O gba awọn olododo niyanju lati ni igbagbọ ati igbẹkẹle ninu Ọlọrun. Ikiya tootọ ni o jé̩ fun awọn olododo, ikilọ ni o si jé̩ fun awọn alaiṣododo. O si ti jẹ orisun itunu fun ogunlọgọ awọn ti o ba Ọlọrun rin ti wọn si ti ru è̩gan Agbelebu. O si ṣe iyebiye lọpọlọpọ nitori pe o ṣe afiwe ipo awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun ati ti awọn alaiwa-bi-Ọlọrun layé isisiyi, o si tun n ṣe afiwe ere ati idajọ ayeraye ti o wà fun wọn pẹlu.

Ni akoko ti a wa yii, o rọrun fun awọn olododo lati maa ṣe aniyan bi wọn ba fi oju ara wo awọn ohun ti o n ṣẹlẹ. A ni lati maa wo awọn ohun ti o ba ni ninu jẹ ti n ṣẹlẹ wọnyi pẹlu oju igbagbọ ati igbẹkẹle ninu Ọlọrun, pẹlu igbagbọ pipe ninu agbara nla Ọlọrun ati itọju Rè̩. Bi a ba ṣe inudidùn ninu Oluwa, a o le gba ohunkohun ti O ba ran si wa bi lati ọwọ Rè̩ wa. Bi o ba ṣe ibukun ni, a ni lati fọpé̩ fun Un. Bi o ba ṣe iṣoro, a le yin In fun eyi naa pẹlu nitori pe a mọ pe fun ire wa ni, ki a si yẹ inu ara wa wò lati mọ bi a ba ti ya kuro ninu ifẹ Rè̩ lọnakọna.

Aabò Wa lati Ọwọ Ọlọrun

Sisinmi le Oluwa ni gbigbe ibi ikọkọ Ọga Ogo (Orin Dafidi 91:1, 2). Ogo Ọlọrun ni o bo Ibi Mimọ Julọ ninu Tẹmpili, ẹnikẹni ti o ba si wọ ibi mimọ wọnni wà labẹ aabò Ọlọrun. Olori alufa nikan ni o ni ẹtọ lati wọ Ibi Mimọ Julọ ni ọjọ wọnni, ṣugbọn ni akoko Ihinrere yii, gbogbo awọn Onigbagbọ ni o ni ẹtọ si Ibi Mimọ Julọ wọnni nipa itoye È̩jẹ Jesu. Nitori naa a wà lai lewu bi a ba ti fi È̩jẹ Jesu wọn ọkàn wa ti È̩jẹ Rè̩ si wẹ wa nù kuro ninu è̩ṣẹ gbogbo. Awọn wọnni ti o wà labẹ È̩jẹ Jesu lọna bayii ni o wà nibi aabò ti o daju.

Igba Ikẹyìn

Psalmu yii ṣe deedee pẹlu ohun ti yoo ṣẹlẹ ni igba ikẹyin. Nihin a ṣe apejuwe awọn eniyan buburu gẹgẹ bi wọn ti n gbimọ si awọn olododo ati lati sọ awọn talaka ati alaini kalẹ, ti wọn si n ṣe inunibini si awọn ẹni diduro ṣinṣin. Eyi jẹ apejuwe pipe nipa agbara ibi ti o n ṣiṣẹ ninu aye lọjọ oni -- ẹmi Aṣodisi-Kristi ti o wà ninu awọṅ alaiwa-bi-Ọlọrun. S̩ugbọn akoko wọn kuru. Ọlọrun yoo rẹrin wọn, nitori pe O mọ pe ọjọ idajọ wọn n bọ. Ọlọrun sọ fun ni pe, “Egbé ni fun aiye ati fun okun! nitori Èṣu sọkalẹ tọ nyin wá ni ibinu nla, nitori o mọ pe ìgba kukuru ṣá li on ni” (Ifihan 12:12). Ọlọrun si tun sọ ninu Ọrọ Rè̩ bayii pe, “Nitori pe nigba diẹ, awọn enia buburu kì yio si: nitotọ iwọ o fi ara balẹ wò ipò rè̩, kì yio si si.”

Awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wọnyi fi hàn fun ni pe ọta ọkàn ọmọ eniyan yoo duu lati bi awọn olododo ṣubu. Eyi ni ero awọn asẹ-Ọlọrun, ati awọn ti o doju kọ Igbagbọ, ti wọn n fẹ ṣe akoso aye loni. Ifẹ wọn ni lati pa gbogbo Onigbagbọ run kuro lori ilẹ alaaye ki wọn mu iranti orukọ Ọlọrun kuro lọkàn ọmọ eniyan.

Akoko ti o ṣoro ni ayé wà nisisiyi. Bi a ba fi ọmọ eniyan silẹ lati té̩ ifẹ ọkàn rè̩ lọrun, eniyan kò ni pẹ parun kuro lori ilẹ. Agbara okunkun yoo gbilẹ bi o ba ri ayè lati ṣe bẹẹ. S̩ugbọn Oludena kan wà ti O n ṣe idena laye sibẹ. Ẹmi Ọlọrun ti O n ṣiṣẹ ninu aye ati nipasẹ Iyawo Kristi ni. A dupẹ lọwọ Ọlọrun nitori awọn ẹni diduro ṣinṣin diẹ ti wọn n doju kọ agbara ati ogun eṣu! Agbara ti o tayọ ti ọta ọkàn ọmọ eniyan yoo gbe wọn ro. “Oluwa fẹ idajọ, kò si kọ awọn enia mimọ rè̩ silẹ; a si pa wọn mọ lailai: ṣugbọn iru-ọmọ awọn enia buburu li a o ke kuro.”

Igberaga ati Ijọra-ẹni-loju awọn Eniyan Buburu

Ni igba ti wa yii, a ti rii ti awọn oluṣe-buburu gba agbara, wọn si gbilẹ ninu igberaga ati irera, wọn n sọrọ ibi ati ibajẹ ni gbogbo ọna. A si ti rii ti a ke wọn lulẹ bi koriko, wọn rọ bi eweko tutu. Wọn ti di rikiṣi si olóòótọ, wọn si payin keke si awọn olododo, ida wọn si wọ aya awọn tikara wọn lọ. Ọpọlọpọ ninu wọn ni o ti fi ọwọ ara wọn pa ara wọn, ninu ọtẹ ati orikunkun ni wọn lọ si ayeraye lati duro niwaju Ọlọrun olotitọ ati alagbara.

Nebukadnessari, ninu igberaga ati ijọra-ẹni-loju rè̩ ni a fi wé igi kan ti o ga de Ọrun ti o si gbilẹ de opin aye. A kilọ fun un ninu àlá, nipa idajọ Ọlọrun ti o n bọwa, nigba ti o gbọ ti oluṣọ lati ọrun kigbe wi pe, “Ke igi na lulẹ, ki o si ke awọn ẹka rè̩ kuro, gbọn ewe rè̩ danu; ki o si fọn eso rè̩ ka” (Daniẹli 4:14). Daniẹli, eniyan Ọlọrun rọ Nebukadnessari pe, “Fi ododo ja è̩ṣẹ rẹ kuro, ati aiṣedde rẹ nipa fifi ānu hàn fun awọn talaka” (Daniẹli 4:27). S̩ugbọn kò fetisi ikilọ yii. Bi Nebukadnessari si ti n ṣogo ninu ọla ati agbara rè̩, ohun kan fọ lati Ọrun wa wi pe “A gba ijọba kuro lọwọ rẹ.” Igberaga Babiloni wọmi “bi eweko tutu.”

Bẹlṣassari mọ nipa idajọ Ọlọrun ti o ba Nebukadnessari, baba nla rè̩, ṣugbọn oun naa pẹlu kuna lati gbà ikilọ. Ni alẹ ọjọ kan, bi Bẹlṣassari ti n jẹ igbadun è̩ṣẹ, ọwọ kan kọwe si ara ogiri ninu gbọngan apejẹ bayii pe, “Ọlọrun ti ṣirò ijọba rẹ, o si pari rè̩.” “Loru ijọ kanna li a pa Bẹlṣassari, ọba awọn ara Kaldea” (Daniẹli 5:26, 30). Eyi jẹ apẹẹrẹ miiran nipa otitọ Ọrọ Ọlọrun ti o dojukọ awọn oluṣe-buburu. “A o ke wọn lulẹ laipẹ.”

Idajọ

“Gbogbo wa kò le ṣaima fi ara hàn niwaju ité̩ idajọ Kristi; ki olukuluku ki o le gbà nkan wọnni ti o ṣe ninu ara, gẹgẹ bi eyi ti o ti ṣe, ibā ṣe rere ibā ṣe buburu” (II Kọrinti 5:10). Awọn eniyan buburu le maa gbilẹ ninu aye yii fun igba diẹ, ṣugbọn bawo ni yoo ti ri ni ọjọ nì ti wọn yoo duro niwaju Onidajọ ti o joko lori Ité̩? Bawo ni yoo ti ri nigba ti Onidajọ ododo ba boju wo inu ọkàn ẹni naa ti O si ri è̩ṣẹ nibẹ? Ọpọlọpọ è̩ṣẹ ni eniyan bò mọlẹ nisisiyi, ṣugbọn ire wo ni eyi yoo ṣe ni ọjọ nì nigba ti a o da “ori awọn enia buburu si ọrun apadi” (Orin Dafidi 9:17). “Máṣe ikanra nitori awọn oluṣe-buburu;” nitori pe idajọ wọn n bọ wa nigba ti “ḝfin oró wọn si n lọ soke titi lailai, nwọn kò si ni isimi li ọsán ati li oru” (Ifihan 14:11). Ọpọlọpọ loni ni kò naani aanu Ọlọrun, ṣugbọn ọjọ n bọ ti yoo di mimọ fun wọn wi pe, “ninu adagun ti nfi iná ati sulfuru jó: eyiti iṣe ikú keji” (Ifihan 21:8) ni wọn o gbe lo ayeraye. Bawo ni o ti buru tó lati taku sinu è̩ṣẹ nigba ti Ọlọrun n fi idariji ati iye ainipẹkun lọ gbogbo awọn ti o fẹ rin lọna Rè̩!

Ifẹ Ọlọrun

A sọ fun ni lati duro de Ọlọrun ati lati maa rin ni ọna Rè̩. Ọpọlọpọ eniyan ni o n duro de Oluwa ṣugbọn ti wọn n tọ ọna ara wọn lẹyin naa. Iwe Mimọ pa a laṣẹ fun wa lati maa tọ ọna Ọlọrun nigba gbogbo ki a si ni ẹmi igbọran pẹlu.

Ọgbẹni Heberu ọjọgbọn kan sọ fun ni wi pe ni ede Heberu, itumọ diduro ni pe, afárá -- kì i ni ibẹrẹ ki o má ni opin. O ṣe alaye ọrọ ijinlẹ ti o sọ naa bayii pe, ibẹrẹ afárá naa ni ọkàn eniyan, afárá naa gan an ni ifẹ ọkàn wa; opin afárá naa ni Ọlọrun. A mọ daju pe afárá ti o ba lọ taara lati ọkàn sọdọ Ọlọrun, pẹlu ifẹ atọkan wa lati ṣe gbogbo ifẹ Ọlọrun, yoo pa Onigbagbọ mọ, ẹsẹ rè̩ kò si ni yẹ.

Ọkan-tutu, Apẹẹrẹ Iwa-bi-Ọlọrun

Ninu Iwaasu lori Oke, Jesu sọ fun ni wi pe awọn ọlọkan tutu ni yoo jogun aye. Igba pupọ ni a sọ ohun kan naa fun ni ninu Psalmu yii. Ẹmi ọkan-tutu lodi si ẹmi ti ayé yii. Iwa tutu lodi si ọna ati iṣe awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ninu aye yii. O lodi si ẹmi satani. Ọlọrun ni o n fun ni ni ọkan-tutu; ipá, agbara ati okiki pupọ si wà ninu rè̩.

Mose jẹ ọlọkan tutu, sibẹsibẹ akinkanju ati alakoso ti o gbamuṣe ni oun i ṣe, gbogbo Israẹli ni o si fẹran rè̩. Dafidi ni ẹmi iwa tutu tootọ, sibẹsibẹ ọba pataki ati alakoso tootọ ni oun i ṣe ni Israẹli, ẹni ti ogunlọgọ eniyan fẹran ti wọn si n tẹle. Elijah ni ọkàn tutu, kò jẹ lo anfaani kan rara lati ni ere tabi iyi aye yii; sibẹ nipa iranlọwọ Ọlọrun, o mu gbogbo orilẹ-ède kan tọ Ọlọrun ni akoko kan, o si mu ki awọn ọmọ-ogun ati awọn ara ilu ki o yọwọ kuro ninu eto ti wọn ti ṣe lati ṣe awọn eniyan Ọlọrun ni ibi. “Awọn ọlọkàn-tutù ni yio jogun aiye; nwọn o si ma ṣe inu didun ninu ọpọlọpọ alafia.”

A sọ ohun miiran ti a ni lati ṣe fun ni. A ni lati kuro ninu ibi ki a si maa ṣe rere. Kì i ṣe pe ki a sa kuro ninu ibi nikan, a ni lati maa sa ipá wa lati mu awọn ẹlomiran mọ ọna otitọ. Eyi ni itumọ kikún fun ṣiṣe rere. Ki a bọ talaka tabi ki a ṣaanu fun awọn olupọnju nikan, ki a si jẹ ki wọn lọ lai si ounjẹ ẹmi, kò ṣe wọn ni ire rara. Lati inu ọkàn rere ni iṣẹ rere ti n jade wa.

Ounjẹ Lakoko Ìyan

Iriri Dafidi ti fun un ni ifọkanbalẹ pe Ọlọrun yoo boju to awọn ti Rè̩ ni akoko iyàn. Dafidi ti di arugbo nigba ti o kọ Psalmu yii. Ni igba ọdọ rè̩, o ti la idanwo ati aini ti kò lẹgbẹ kọja. O ti rin kiri è̩gbé̩ oke pẹlu awọn agutan ati ewurẹ, boya ọpọlọpọ igba ni ó wà lai ni ounjẹ. S̩ugbọn bi Dafidi ti boju wò è̩yìn wo ọjọ wọnni, o lé wi pe, “Ohun diẹ ti olododo ni sanju ọrọ ọpọ enia buburu.”

Dafidi di akikanju ọmọ-ogun fun ododo ati fun Israẹli pẹlu nitori ti o ti la iṣoro kọja nigba ewe rè̩. O da a loju pe bi eniyan ba gbẹkẹ le Oluwa ti o si n ṣe rere, Oluwa yoo pese fun aini rè̩. Igbagbọ ati igbẹkẹle rè̩ ninu Oluwa da a loju ti o fi sọ pe, “Emi ti wà li ewe, emi si dagba; emi kò ti iri ki a kọ olododo silẹ, tabi ki iru ọmọ rè̩ ki o ma ṣagbe onjẹ.” Ilana ati ileri Ọlọrun lati ayeraye ni eyi. Ọlọrun a maa pese nigba gbogbo – ati lọna gbogbo – fun awọn ti Rè̩ gẹgẹ bi o ti tọ.

Ofin Igbesi-aye Rere

Dafidi bẹrẹ Psalmu yii pẹlu ikilọ pe, “Máṣe ikanra nitori awọn oluṣe buburu.” Akoko awọn eniyan buburu kuru a o si ke wọn lulẹ ni aipẹ. O sọ fun ni pe, “O kọja lọ, si kiyesi i; kò si mọ: lõtọ emi wá a kiri, ṣugbọn a kò le ri i.”

A fun ni ni ofin igbesi aye alaafia ati itọni lati gbà wa kuro lọwọ aniyan ati hilahilo ti kò nilaari. A sọ fun ni ki a “gbẹkẹle OLUWA,” eyi nì ni pe ki a má ṣe gbẹkẹ le apa ẹran fun iranwọ. O tun sọ fun ni pe ki a “S̩e inu-didùn si OLUWA pẹlu.” Eyi yii ni pe a o ni inu didùn si ọna Ọlọrun. Lẹyìn eyi a tun sọ fun ni pe, “Fi ọna rẹ le OLUWA lọwọ.” Eyi fi hàn gbangba kedere wi pe a ni lati jẹ ki Ọlọrun mu ọna ati ifẹ Rè̩ ṣẹ ni igbesi aye wa. Lopin gbogbo rè̩, a ni lati “Simi ninu OLUWA,” ki a si fi suuru duro de E. Eto Ọlọrun kò ni ariwisi! Ifẹ Ọlọrun ni o dara jù lọ!

Iyatọ gedegbe ni o wà laaarin ogún ologo ti i ṣe ti awọn olododo ati ibi ti yoo gbẹyin eniyan buburu. Oluwa ni agbara awọn ẹni rere, ẹni diduro ṣinṣin ati olododo ni akoko iṣoro, ṣugbọn olurekọja ni a o parun, nikẹyin a o ke eniyan buburu kuro.

“Ma kiyesi ẹni pipé, ki o si ma wò ẹni diduro ṣinṣin: nitori alafia li opin ọkọnrin na.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Iru awọn eniyan meji wo ni a sọ iyatọ ti o wà laaarin wọn ninu Psalmu yii?
  2. Ki ni ṣe ti a kò fi ni lati kanra nitori awọn oluṣe buburu?
  3. S̩e apejuwe igbẹyin olododo.
  4. S̩e apejuwe igbẹyin eniyan buburu.
  5. Ki ni a sọ fun ni nipa awọn ọlọkàn tutu?
  6. Lori adehun wo ni a ṣeleri lati fi ounjẹ bọ wa?
  7. Ki ni Dafidi sọ fun ni pe oun kò i ti ri ri?
  8. Apa Keji
  9. FUN AWỌN ỌDỌ