Lesson 249 - Junior
Memory Verse
“Egbé ni fun ọkọnrin na, lọdọ ẹniti a gbé ti fi Ọmọ-enia hàn!” (Marku 14:21).Notes
Apọsteli
Lara awọn ti a yàn lati maa ṣe ọmọ-ẹyin Jesu ni ọkunrin kan wà ti orukọ rè̩ n jẹ Judasi Iskariọtu. A kò mọ nnkankan nipa igbesi-aye rè̩ ki o to di ọmọ-ẹyin. Orukọ baba Judasi ni Simoni (Johannu 6:71). Nigba ti Jesu pe awọn eniyan lati maa tẹle Oun, kò beere boya awọn obi wọn jẹ ẹni iwa-bi-Ọlọrun tabi boya ati kọ wọn ni ilana ẹsìn.
Bakan naa ni ipe Ihinrere loni, o si n jade lọ sọdọ gbogbo eniyan. Kì i ṣe ọranyan pe ki a wá lati idile ti n gbadura tabi ki a ni òye Bibeli ki ipe Ọlọrun to le kàn wa. Bi Oluwa ti n pe awọn ti o ti ile Onigbagbọ jade wa, bakan naa ni O n pe awọn ti kò mọ nnkankan nipa Bibeli ati adura. “Ẹnikẹni ti o ba si fẹ, ki o gbà omi iye na lọfẹ” (Ifihan 22:17). “Kiyesi i, mo duro li ẹnu ilẹkun, mo si nkànkun, bi ẹnikẹni ba gbọ ohùn mi, ti o si ṣí ilẹkun, emi o si wọle tọ ọ wá” (Ifihan 3:20).
Kò si akọsilẹ ninu Bibeli nipa bi Judasi ṣe jé̩ ipe Kristi. Kò si idi kankan lati rò pe bi a ti ṣe pe Judasi yatọ si bi a ti ṣe pe awọn ọmọ-ẹyin iyoku. Judasi wà ninu awọn ọmọ-ẹyin mejila ti a yàn ṣe Apọsteli. Jesu pè wọn jade laaarin awọn ọmọ-ẹyin iyoku “nwọn si tọ ọ wa” (Marku 3:13). Judasi jé̩ ipe naa, a si yàn an pẹlu awọn mọkanla iyoku, lati maa ba Jesu gbe ati lati maa jade lọ i waasu Ihinrere.
Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe: “Gbogbo enia yio si korira nyin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà” (Matteu 10:22). Judasi gbọ nigba ti Jesu n sọ ohun ti O n fẹ lọwọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩: “Ẹnikẹni ti kò ba rù agbelebu rè̩, ki o si ma tọ mi lẹhin, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi” (Luku 14:27). A ka Judasi mọ awọn Apọsteli wọnni ti wọn jade lọ waasu pe “Ki awọn enia ki o le ronupiwada.” Judasi jẹ ọkan ninu awọn Apọsteli mejila ti wọn “lé ọpọ awọn ẹmi èṣu jade, nwọn si fi oróro kùn ọpọ awọn ti ara wọn ṣe alaida, nwọn si mu wọn larada” (Marku 6:12, 13).
Akapò
Jesu maa n ran awọn ọmọ-ẹyin lati lọ ra ounjẹ nigba miiran, bi iru ti Samaria nigba ti Jesu n ba obinrin nì sọrọ ni ẹba kanga (Johannu 4:8). Judasi ni a fi ṣọ owo awọn Apọsteli (Johannu 13:29). Ipo rè̩ ni ti ẹni ti a maa n pe ni akapò. Judasi ni olutọju àpò-owo, oun a si maa gbe owo ti awọn Apọsteli ni kiri.
Judasi ti gbọ awọn ikilọ ti Jesu fun wọn. Nigbà ti awọn Apọsteli mejila beere pe ki Jesu ṣe alaye owe afunrugbin, a sọ fun wọn pe “aniyan aiye yi, ati itanjẹ ọrọ si fún ọrọ na pa,” bẹẹ ni a si jẹ ki eniyan di alaileso (Matteu 13:22). Jesu sọ fun wọn nipa aṣiwere ọlọrọ ti a beere ẹmi rè̩ ki o to ni anfaani ati sinmi, ati maa jẹ, ati maa mu, ati maa yọ. Jesu wi pe “Bḝ li ẹniti o tò iṣura jọ fun ara rè̩, ti ko si li ọrọ lọdọ Ọlọrun” (Luku 12:21).
Judasi kò fi ọkàn si awọn ikilọ ti o ti gbọ. O wa di anikanjọpọn, o si lodi si Maria nigba ti o mu ororo ikunra nardi, oṣuwọn litra kan, ailabula, olowo iyebiye, ti o si n fi kùn Jesu. Judasi wi pe: “ṣe ti a kò tà ororo ikunra yi ni dunrun owo idẹ ki a si fifun awọn talakà?” (Johannu 12:4, 5). Jesu dahun pe: “Ẹ jọwọ rè̩ si: ṣe ti ẹnyin fi mba a wi? iṣẹ rere li o ṣe si mi lara. Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin, ẹnyin le ma ṣore fun wọn nigbakugba ti ẹnyin fẹ; ṣugbọn emi li ẹnyin kò ni nigbagbogbo. O ṣe eyi ti o le ṣe” (Marku 14:6-8).
Ọkàn ẹtan ati agabagebe ti o si kún fun ojukokorò ni o mu Judasi sọrọ bayii. O ṣiro rè̩ pe n ṣe ni a fi ororo naa ti a fi kùn Jesu ṣòfo, ati pe i ba sàn ki a ta ororo ikunra naa, ṣugbọn ki i ṣe fun anfaani awọn talakà. Judasi kò bikita fun awọn alaini. ánu wọn kò ṣe e. O ti di olojukokorò ati alaiṣoootọ (Johannu 12:6).
Tita Kristi
Awọn olori alufa kò lọ ba Judasi lati bè̩ ẹ pe ki o ba wọn lọwọ si ero wọn. Satani ni o kó sinu Judasi lati gbimọ ibi si Jesu ati lati lọ ba awọn olori alufa (Luku 22:3, 4). Kì i ṣe pe o yọọda lati lọ jẹri tako Jesu, bi o tilẹ jẹ pe wọn n wa ẹsùn si Kristi lẹsẹ. Ohun ti Judasi ṣe buru jù eyi lọ - o tà Jesu fun wọn.
Ifẹ Owo
Judasi kò si ninu aini. Kì i ṣe pe owo ni o té̩ Judasi ti o fi ba awọn olori alufa ṣe adehùn iye owo. O ni lati jẹ ifẹ owo ni o mu ki o fi Kristi hàn. Judasi ni o funra rè̩ yọọda lati fi Kristi le wọn lọwọ. Dajudaju, Judasi ni ireti ati gbà owo. Bibeli sọ fun ni pe “ifẹ owo ni gbòngbo ohun buburu gbogbo” (I Timoteu 6:10).
Judasi wi pe, “Kili ẹnyin o fifun mi, emi o si fi i le nyin lọwọ?” Wọn ṣe adehùn pe iye owo naa yoo jẹ ọgbọn ṣekeli fadaka, iye owo ti a n san lé ẹrú kan lori gẹgẹ bi Ofin ti palaṣẹ (Ẹksodu 21:32).
Judasi fẹran owo naa – nnkan bi pọun meje -- jù bi o ti fẹ Kristi lọ. Loni awọn eniyan maa n digbà jẹ ki owo gbà ipo kin-in-ni ninu aye wọn dipo pe ki wọn fi gbogbo ọkàn wọn fẹran Kristi. Kì i ṣe ohun ajeji pe awọn miiran ti fi ohun ti kò to pọun meje ṣe paṣipaarọ Kristi, nitori pe wọn jẹ ki Satani wọ inu ọkàn wọn.
Bi iwọ kò ba ni igbala, ki ni n ṣe idena laaarin rẹ ati Kristi? Ki ni n gba ipo kin-in-ni dipo Kristi ninu ọkàn rẹ? Iye owo wo ni o n tà ọkàn rẹ? “Ère kini fun enia, bi o jère gbogbo aiye, ti o si sọ ẹmi rè̩ nù?” (Marku 8:36).
Ibè̩ru awọn Eniyan
Awọn olori alufa, awọn akọwe ati awọn agba awọn eniyan péjọ ni aafin olori alufa lati gbero bi wọn yoo ti ṣe le mu Jesu. Ihùmọ wọn si Jesu jẹ eyi ti o kún fun ikà ati ọgbọn arekereke. Wọn gbimọ lati fi ọgbọn ẹwẹ pa A. Nitori ibè̩ru awọn eniyan, wọn kò to ẹni ti i gbe ọwọ le E nigba ti O n kọ ni ni gbangba, bẹẹ ni wọn kò mọ bi wọn ti ṣe le dá Jesu nikan rí. Wọn wi pe awọn kò ni mu Jesu ni ọjọ ase Irekọja, kì i ṣe nitori pe wọn bọwọ fun ọjọ naa tabi pe wọn bù ọlá fun Ọlọrun. Ohun ti wọn n dù ni bi awọn o ti ṣe wà lai lewu, ki o má ba si ariwo laaarin awọn eniyan. Wọn kò bikita lati ṣe ifé̩ Oluwa ṣugbọn wọn fẹ wu awọn eniyan.
Judasi lọ ba awọn eniyan wọnyi ti wọn ni ọkàn buburu ati ete ipaniyan. O sọ fun wọn bi oun ti ṣe le fi Kristi hàn. Judasi tilẹ buru jù bi wọn ti rò lọ. O yà wọn lẹnu pe ọkan ninu awọn ọmọ-ẹyin Jesu le ràn awọn lọwọ. Inu wọn dùn lati ba Judasi ṣe adehùn nigba ti o ṣeleri lati fi Jesu le wọn lọwọ “laisi ariwo.”
Ẹni ti Jesu ti yàn lati jẹ ọmọ-ẹyin, yọọda lati lọwọ ninu àbá ati pa Jesu. Oun, ti i ṣe ọmọ-ẹyin wa di ọdalẹ. Judasi gbiyanju lati bò iwa ọtẹ rè̩. Ni akọkọ, kò fi Kristi silẹ ni gbangba. Judasi kò wi pe oun kò jẹ Apọsteli mọ, ṣugbọn o ba awọn Apọsteli ṣe pọ bi o ti n ṣe tẹlẹtẹlẹ. O wa lọdọ wọn nigba ti wọn jọ jẹ ase Irekọja pẹlu Jesu. Judasi bá awọn Apọsteli iyoku pejọ pọ lati ṣe ọdun ẹsin nigba ti o jẹ pe ni akoko kan naa ọkàn rè̩ buru jai. O fara hàn bi ọrẹ ati ọmọ-ẹyin. O mọ ibi ti Jesu maa n saba kó awọn Apọsteli Rè̩ lọ lati gbadura. O pinnu lati fi Jesu hàn fun awọn ọpọ eniyan ti wọn ti ọdọ awọn olori alufa wá nipa kiki Jesu pẹlu ifẹnukonu. Judasi fi ami fun wọn, wi pe, ”Ẹnikẹni ti mo ba fi ẹnu kò li ẹnu, on na ni” (Marku 14:44).
Anfaani lati Dẹṣè̩
Ni gbogbo akoko yii o ti n wa anfaani ti yoo ni lati fi Jesu le ọwọ awọn ti n wa ẹmi Rè̩. Judasi fi ara balẹ di akoko ti oun le ri “ọna bi yio ti ṣe fi i le wọn lọwọ.” Satani ti sin Judasi jinna kuro lọdọ Ọlọrun to bẹẹ ti oun kò fi ṣiro ki ni ere è̩ṣẹ oun yoo jasi. O ti buru to fun Judasi, tabi ẹnikẹni, lati wá aye ati ṣe ibi! Judasi pinnu, o ṣafẹri, o si gbimọ ki o ba le dẹṣẹ. Ọkan ninu awọn woli ti wi pe, “Egbe ni fun awọn ti ngbìmọ aiṣedede” (Mika 2:1).
Jesu mọ wi pe lai pẹ Judasi yoo fi Oun hàn. Nigba ase Irekọja, Jesu wi pe, “Ọkan ninu nyin yio fi mi hàn” Jesu mọ ero ọkàn Judasi, O si sọ fun Judasi pe, “Ohun ti iwọ nṣe nì, yara ṣe e kánkan.” Judasi fi ẹgbẹ wọn silẹ. “Oru si ni.” Fun Judasi, o jẹ okunkun ti ẹmi ati okunkun ti ara pẹlu, nitori Satani ti wọ inu Judasi Iskariọtu. Ọrọ ti Jesu sọ ti ba ni ninu jẹ to nigba ti O wi pe iba san fun Judasi bi o ṣe pe a kò bi i! (Matteu 26:24).
Ninu Ọgbà
Jesu, pẹlu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lọ sinu ọgbà kan lati gbadura. O jẹ ibi ti Jesu ti kó wọn lọ ni ìgbà pupọ, Judasi si mọ ibẹ (Johannu 18:1, 2). Eniyan i ba rò pe iru ibi bayii yoo jẹ ilẹ ọwọ fun awọn ọmọ-ẹyin. Lai ṣe aniani wọn ti gbadura papọ nibẹ, wọn si ti ba ara wọn ni idapọ didùn pẹlu Jesu. Sinu ọgbà yii nibi ti o yẹ ki alaafia ati idakẹjẹ wà ni Judasi kó ẹgbẹ ọmọ-ogun kan wá ti awọn ti fitila ati idà lọwọ. Judasi ni o ṣamọna awọn ti o wa mu Jesu. Wọn wá bi ẹni pe wọn wa mu ole -- pẹlu ọpọlọpọ eniyan ati ohun-ijà. Wọn wa bi ẹni ti o n reti idojukọ ati ijakadi -- wọn mura lati gbe ọwọ le Jesu ati lati “di I mu ṣinṣin.” Judasi bọ siwaju pẹlu ifẹnukonu ibi ati ọrọ è̩tan. O wi pe, “Alafia, Olukọni.” Judasi ki Jesu pẹlu ifẹnukonu eyi ti o fi I hàn fun awọn ẹni ibi; wọn si mu Jesu lọ. Jesu kò jà fitafita lati gbà ara Rè̩ silẹ, ṣugbọn O yọọda funra Rè̩ lati jẹ Ẹbọ fun è̩ṣẹ wa. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe ki wọn fi ida wọn si ipo rè̩. O ran wọn leti wi pe Oun le pe legioni angẹli mejila lati Ọrun wá, ṣugbọn Oun yọọda ara Oun ki Iwe Mimọ ki o ba le ṣẹ.
Ọmọ Ègbé
Nigba ti Judasi gbà ọgbọn owo fadaka naa, kò ri igbadun kankan ninu rè̩. Ẹpa kò ba oró mọ nigba ti oju rè̩ la si iwa ti o buru jai ti o ti hu! Judasi “ri pe a da a lẹbi.” Ani rironupiwada ati didá owo naa pada, pẹlu ijẹwọ pe oun ti fi “è̩jẹ alaiṣè̩ hàn” kò pa idalẹbi ré̩ kuro ninu ẹri-ọkàn rè̩, o jade o si lọ i so. O gbà orukọ “ọmọ egbé” fun ara rè̩ (Johannu 17:12) itumọ eyi ti i ṣe “ọmọ ọrun apaadi.” Nipa irekọja Judasi, o lọ “si ipo ti ara rè̩” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:25), ipo iparun patapata, ibanujẹ, ati iku ayeraye.
Fifi Ara fun Idanwo
Judasi yii kan naa ni o jẹ ipe Kristi, ti o ti wà pẹlu Jesu, ti o si ti ṣe rere fun saa kan (Iṣe Awọn Apọsteli 1:17). O bè̩rẹ daradara ṣugbọn o fi ara fun idanwo, o si gbà Satani láyè lati wọ inu igbesi-aye rè̩. Lati ri igbala ati lati di ọmọlẹyin Jesu jẹ iriri ribiribi, ṣugbọn o ti ṣe pataki jù bẹẹ lọ to lati ṣe olóòótọ de opin igbesi-aye wa!
Nitori pe ẹni kan ri igbala ni akoko kan kò sọ ọ di dandan gbọn pe nigba gbogbo ni oluwarè̩ yoo fi maa wà ninu igbala. Bi kò ba ṣe pe o n gbe igbesi-aye rè̩ fun Jesu, ki o má si gbà è̩ṣẹ láyè lati bọ sinu aye rè̩, oun yoo kuna anfaani ati ni iye ainipẹkun (Esekiẹli 18:26). Agbara wà ninu È̩jẹ Jesu lati gbala, ati lati pamọ, ti eniyan ba n fẹ wà ninu ipamọ Oluwa.
Kikọ Oju Ija si Idanwo
Kì i ṣe Judasi nikan ni a ti danwo ri. Fifi ara fun idanwo ni è̩ṣẹ Judasi. Ki ni eniyan le ṣe lati doju ija kọ idanwo nigbà ti o ba de ba a? Jesu fun wa ni apẹẹrẹ. Satani gbiyanju lati dán Jesu Ọmọ Ọlọrun paapaa wò. Ọrọ Ọlọrun ni Jesu fi kọ oju ija si Satani. Jesu wi pe, “A ti kọwe rè̩ pe . . .” O si fi Bibeli gbe ara Rè̩ lẹsẹ (Matteu 4:4, 7, 10). Awa naa le ni iṣẹgun lori Satani nipa Ọrọ Ọlọrun. Bi a ba gbọran si Jesu lẹnu bi a ba si n pa Ọrọ naa mọ, a le reti pe Jesu yoo pa wa mọ ni akoko idanwo. A ka wi pe: “Nitoriti iwọ ti pa ọrọ sru mi mọ, emi pẹlu yio pa ọ mọ kuro ninu wakati idanwo ti mbọwa de ba gbogbo aiye, lati dán awọn ti ngbe ori ilẹ aiye wo” (Ifihan 3:10).
Oluwa kò ṣe ileri lati mu idanwo jinna kuro lọdọ wa, ṣugbọn O ṣe ileri lati ṣe ọna fun wa lati bọ ninu idanwo. “Kò si idanwò kan ti o ti ibá nyin, bikoṣe irú eyiti o mọ niwọn fun enia: ṣugbọn olododo li Ọlọrun, ẹniti ki yio jẹ ki a dan nyin wò jù bi ẹnyin ti le gbà; ṣugbọn ti yio si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwò na, ki ẹnyin ki o ba le gbà a” (I Kọrinti 10:13).
Nigba ti Satani ba de lati dan ọ wò, kọ oju ija si i pẹlu Ọrọ Ọlọrun: beere pe ki Oluwa ran ọ lọwọ; ki o si fi ara rẹ le ọwọ “ẹniti o le pa nyin mọ kuro ninu ikọsẹ” (Juda 24). Nipa ti-tẹra mọ adura ati ifararubọ, nipa ṣiṣọra ati gbigbọran si ikilọ, a le gbe igbesi-aye ti o jẹ olóòótọ si Kristi. Nipa oore-ọfẹ Ọlọrun, a le gbe igbesi-aye wa lọna ti a o fi le sọ pẹlu Paulu pe, “Emi ti jà ija rere, emi ti pari ire-ije mi, emi ti pa igbagbọ mọ” (II Timoteu 4:7).
Questions
AWỌN IBEERE- Ta ni Judasi Iskariotu?
- Apọsteli melo ni Jesu yàn?
- Ta ni akapo fun awọn Apọsteli?
- Ki ni ṣe ti Judasi fi fẹ ta ororo ikunra nardi naa?
- Ki ni ṣẹlẹ nigba ti Satani kó sinu Judasi?
- Ki ni ṣe ti Judasi fi tọ awọn olori alufa lọ?
- Ki ni ṣe ti wọn kò mu Jesu nigba ti O n kọ awọn eniyan?
- Elo ni Judasi yoo gbà?
- Bawo ni a ṣe fi Jesu hàn?
- Bawo ni a ṣe le kọju ija si idanwo?