Johannu 21:1-25; I Kọrinti 15:6, 7

Lesson 251 - Junior

Memory Verse
“Emi li ẹniti o mbẹ lāye, ti o si ti kú; si kiyesi i, emi si mbẹ lāye si i titi lai” (Ifihan 1:18).
Notes

Pipada si Iṣẹ Ẹja Pipa

Awọn Apọsteli ti rii pe Jesu wa laaye, wọn si gbagbọ dajudaju pe O ti jinde kuro ninu oku ninu ara. S̩ugbọn kò duro sọdọ wọn. Ki ni ohun ti wọn le ṣe nisisiyi?

Ni ọjọ kan, meje ninu awọn Apọsteli (Peteru, Jakọbu, Johannu, Tọmasi, Natanaẹli, ati awọn meji miiran), pade ni eti okun, Peteru daba pe ki wọn pada si iṣẹ wọn atijọ ti i ṣe ẹja pipa. Awọn iyoku ba a lọ, wọn si fi gbogbo oru naa dẹ ẹja. Awọn wọnyi ni awọn ti yoo “yi aiye po” nipa iwaasu wọn nipa Kristi naa ti o jinde; kò si yẹ ki wọn tun ni ayè fun iṣẹ miiran. Iṣẹ wọn ni lati sọ fun awọn eniyan pe Jesu yoo gba wọn kuro ninu è̩ṣẹ wọn. “Apẹja eniyan” ni wọn yoo jẹ.

S̩ugbọn a kò i ti fi Ẹmi Mimọ wọ awọn eniyan wọnyi, wọn kò si ni agbara naa ti wọn o fi jade lọ lati waasu. Wọn ti lọ waasu diẹ nigba ti Jesu wà pẹlu wọn, ṣugbọn nisisiyi, O ti lọ, wọn si dabi alailagbara. Kò si ẹni ti yoo maa tọ wọn sọna.

Jesu ti ṣeleri pe nigba ti Oun ba lọ tan, Oun yoo ran Olutunu, ti i ṣe Ẹmi Mimọ, lati tọ wọn si ọna otitọ gbogbo; ṣugbọn Olutunu naa kò i ti i de.

Ọkunrin ti O wa ni Eti Okun

Nigba ti ilẹ bẹrẹsi i mọ, awọn Apọsteli ri ọkunrin kan ni eti okun ti o n beere ounjẹ lọwọ wọn. Wọn sọ fun un pe awọn kò ti ri ẹja pa. Wọn kò fi àwọn wọn mu ẹyọ ẹja kan ni gbogbo oru naa. Ọkunrin naa gbà wọn niyanju lati sọ awọn si apa ọtun ọkọ; nigba ti wọn si ṣe bẹẹ wọn kó ẹja mẹtalelaadọjọ (153) – lati inu omi kan naa ninu eyi ti wọn ti dẹ titi ni gbogbo oru ti wọn kò si ri nnkankan!

Wọn Mọ Ọn

Johannu ayanfẹ ni o kọkọ mọ pe Jesu ni Ọkunrin naa. Kò si ẹlomiran ti o le ṣe iru iṣẹ-iyanu bẹẹ. Peteru, ẹni ti o kọkọ fẹ lati lọ pẹja, n fẹ nisisiyi lati jẹ ẹni akọkọ lati lọ ki Olugbala; nitori naa o fò sinu omi o si n luwẹ lọ si ebute. Awọn Apọsteli iyoku mu ọpọ ẹja ti wọn kó wa si eti òkun.

Jesu mọ pe ebi yoo maa pa wọn lẹyin ti wọn ti ṣiṣẹ pupọ ni gbogbo oru, nitori naa O ti pese ina ti n jo silẹ ati ẹja ti a ti se fun wọn lati jẹ, ati akara pẹlu. Eyi jẹ ohun idaniloju kan sii pe Jesu ti jinde kuro ninu okú, O si wa laaye ninu ara.

Ifẹ Peteru si Jesu

Ki Ọjọ Pẹntekọsti to de, Peteru a maa yara sọ ọrọ nla nla nipa ohun ti o n fẹ ṣe, ṣugbọn o ti kùna pupọpupọ nigba miiran lati mu wọn ṣẹ. Jesu wa doju ọrọ kọ oun nikan ṣoṣo, O si bi i leere pe, “Iwọ fẹ mi ju awọn wọnyi lọ bi?” N jẹ Peteru fẹran Jesu ju awọn ẹja wọnni lọ? N jẹ yoo ha yàn lati waasu Jesu ju lati pada si idi òwò rè̩ atijọ gẹgẹ bi apẹja? Peteru yara dahun, “Bḝni Oluwa; iwọ mọ pe, mo fẹran rẹ.” Jesu ni “Mā bọ awọn ọdọ-agutan mi.” S̩ugbọn eyi kọ ni opin ọrọ naa. Jesu tun beere ibeere kan naa lọwọ Peteru: “Iwọ fẹ mi bi?” Peteru si dahun gẹgẹ bi igba akọkọ, “Bḝni Oluwa, iwọ mọ pe, mo fẹran rẹ.” Jesu ni, “Mā bọ awọn agutan mi.”

Lẹẹkan sii Jesu tun beere ibeere kan naa. Peteru kò mọ ohun ti oun lè rò. Kò ha ti fi hàn to pe oun fẹran Jesu? S̩ugbọn Jesu n fẹ ki o ni idaniloju ohun ti o n sọ ni akoko yii. Kò fẹ ki o gbagbe titi lae ohun ti o n sọ ni ọjọ yii. Peteru n ṣeleri lati di oniwaasu ti yoo fi igboya jẹwọ pe Jesu ni Ọmọ Ọlọrun ati wi pe O ti jinde kuro ninu oku.

Lẹyin eyi Jesu mu ki Peteru ri diẹ nipa ọjọ ti n bọ. O wi fun un pe nisisiyi, o jé̩ ọdọ o si le yàn ohunkohun ti o ba fẹ ṣe; ṣugbọn nigba ti o ba dagba tan, awọn ẹlomiran yoo mu ki o ṣe ohun ti kò fẹ lati ṣe. Lọna bayii, Jesu n sọ fun Peteru pe yoo jẹ ajẹriku, yoo si kú fun igbagbọ rè̩ dipo ti i ba fi dakẹ lati maa waasu pe Jesu ni Kristi naa.

Peteru n fẹ mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn Apọsteli iyoku, ṣugbọn Jesu wi fun un pe iṣẹ ti o ni i ṣe ni ọna ti rè̩ to fun un, ki o má ṣe wahala nipa awọn ẹlomiran.

Eyi ni igba kẹta ti Jesu fara hàn fun awọn Apọsteli ni apapọ.

Akọsilẹ Paulu nipa Ifarahàn Jesu

Paulu sọ fun wa pe Jesu tun fara hàn fun awọn eniyan ti o le ni ẹẹdẹgbẹta (500). Paulu n sọ eyi ni ọpọlọpọ ọdun lẹyin igoke-re-ọrun, ṣugbọn o ni diẹ ninu awọn ti o ri Jesu wa laaye nigba naa. Wọn jẹ ẹlẹri tootọ pe Jesu jinde kuro ni isa-okú.

Jakọbu (ẹniti o ṣe e ṣe ki o jẹ arakunrin Jesu ti kò si gbagbọ ni akọṣe pe Ọmọ Ọlọrun ni) ni ẹni ti o ri Jesu lẹyin eyi; lẹyin naa awọn mọkanla lẹẹkan si i.

Ni ikẹyin gbogbo wọn, Paulu tikara rè̩ ti ri Jesu. Lẹyin igoke-re-ọrun ni eyi. Tẹlẹ ri Paulu kò gbà iwaasu awọn Apọsteli gbọ pe Jesu ni Ọmọ Ọlọrun ati wi pe O jinde kuro ninu okú. Ninu ijọra-ẹni-loju iwa mimọ rè̩ ati itara rè̩, Paulu rò pe oun n ṣe rere fun Ọlọrun nigba ti o n ṣe inunibini si awọn ijọ titun naa ti o gbà ajinde gbọ. O fi awọn eniyan sinu tubu o si mu ki a pa wọn nitori igbagbọ wọn pe Jesu ti jinde kuro ninu okú ninu ara Rè̩.

Ni ọjọ kan nigba ti Paulu n lọ ninu ọkan ninu irin-ajo rè̩ lati lọ ṣe inunibini, Jesu tikara Rè̩ fara hàn fun Paulu. Paulu ri I. Lati igba naa lọ Paulu mọ pe Jesu wà laaye: oun paapaa mura tan pe ki a ṣe inunibini si oun ki a tilẹ pa oun nitori igbagbọ naa. Paulu ni idaniloju gbangba nipa igbagbọ rè̩ pe Jesu ti jinde kuro ninu okú.

Ireti wa Nipasẹ Ajinde

Ki ni ṣe ti o ṣe ohun pataki to bẹẹ pe ki a gbagbọ pe Jesu jinde kuro ninu okú? Idi rè̩ ni pe bi a kò ba gbagbọ, a kò ni igbala. Jesu nikan ni Ẹni ti o le dari è̩ṣẹ jì; Oun nikan ṣoṣo ni O le dari è̩ṣẹ jì nitori pe Ọmọ Ọlọrun ni I ṣe. Bi kò ba jinde kuro ninu okú, ki I ṣe Ọmọ Ọlọrun.

O jẹ iyalẹnu fun Paulu pe awọn eniyan kò gbagbọ pe Jesu ti jinde. Bi Kristi kò ba jinde, asan ni gbogbo iwaasu wọn, wọn si jẹ ẹlé̩ṣè̩ sibẹ, lai ni ireti. S̩ugbọn bi O ba ti jinde ti O si wà laaye, nigba naa O ni agbara lati dari è̩ṣẹ jì; nitori pe O wa laaye, awa ti a ti tunbi yoo wà laaye pẹlu Rè̩.

Paulu sọ pe bi a kò ba ni ireti lati gbe ni ayé miiran ti o si dara jù eyi lọ, awa ni a jẹ aboṣi jù lọ ninu gbogbo eniyan. Ki ni ṣe ti o ni lati jiya ninà, ati iku ajẹriku bi kò ba mọ pe oun yoo gbadun iye ainipẹkun pẹlu Kristi lẹyin aye yii? Peteru kọ akọsilẹ pe: “Ẹ mā yọ, ki ẹnyin ki o le yọ ayọ pipọ nigbati a ba fi ogo rè̩ hàn” (I Peteru 4:13).

Igbagbọ awọn Baba Igbagbọ

Abrahamu gba ajinde gbọ. O jẹ ọlọrọ lọpọlọpọ, o si le yàn ilẹ ti o dara jù lọ lati maa gbe; ṣugbọn o n ṣe atipo ninu agọ. Ọkàn rè̩ wa ni ilu miiran, “ti o ni ipilè̩, eyiti Ọlọrun tè̩do ti o si kọ” (Heberu 11:10). Nitori pe oun ati awọn ẹlomiran bi ti rè̩ ni ireti wọn ninu ilẹ ti o dara jù, “Oju wọn kò ti Ọlọrun, pe ki a mā pe On ni Ọlọrun wọn; nitoriti o ti pèse ilu kan silẹ fun wọn” (Heberu 11:16).

Jobu ni igbagbọ kan naa. O mọ pe oun ni lati kú, ṣugbọn o tun mọ, pe oun yoo tun wa laaye ati wi pe ninu ara ni oun yoo ri Jesu. O kọ akọsilẹ pe: “Ati lẹhin igba awọ ara mi, ti a ti ke e kuro bi iru eyi, ati laili ẹran ara mi li emi o ri Ọlọrun” (Jobu 19:26). O tilẹ tun mọ pe Jesu yoo wá ninu ara Rè̩ lẹẹkeji, nitori pe o kọ akọsilẹ pe: “Emi mọ pe Oludande mi mbẹ li āyè, ati pe on bi Ẹni-ikẹhin ni yio dide soke lori erupẹ ilẹ” (Jobu 19:25).

Dafidi Ọba nla nì, ẹni ti o ni ohun gbogbo ni ayé yii ti o le fun eniyan ni itẹlọrun, kọ akọsilẹ yii: “Bi o ṣe ti emi ni emi o ma wò oju rẹ li ododo: àworan rẹ yio tẹ mi lọrun nigbati mo ba ji” (Orin Dafidi 17:15).

Isaiah sọ asọtẹlẹ: “Awọn okú rẹ yio yè, okú mi, nwọn o dide. Ẹ ji, ẹ si kọrin, ẹnyin ti ngbe inu ekuru: nitori ìri rẹ ìri ewebè̩ ni, ilẹ yio si sọ awọn okú jade” (Isaiah 26:19).

Bi awọn woli ọlọla wọnni ba le wò rekọja ki wọn si ri ajinde ki Jesu to kú ki O si to jinde, melomelo ni o yẹ ki awa, ẹni ti o mọ pe O jinde kuro ninu okú, gbagbọ pe a o pa wa lara da, a o si dabi Rè̩ ninu ara ologo titi lae.

Iye lati inu Okú

Awọn kan gbagbọ pe Onigbagbọ yoo gbe ni Ọrun gẹgẹ bi ẹmi, ṣugbọn Paulu fi ye ni yekeyeke pe a o ni ara. Ajinde jẹ iye lati inu okú, pipadabọ si aayè lẹyin kikú. Nigba ti eniyan ba kú ẹmi rè̩ yoo lọ taara pada sọdọ Ọlọrun Ẹni ti o fi i fun ni (Oniwasu 12:7). Kì i kú. Iwọ kò le sin ẹmi sinu ilẹ. Nitori naa, bi ajinde yoo ba wà, o ni lati jẹ ajinde ara.

Iyatọ wà laaarin ara ti a ni nisisiyi ati eyi ti a o fi jinde: “Ara ti oke ọrun mbẹ, ara ti aiye pẹlu si mbẹ.” Ara ti oke ọrun ni ara ti a o fi ba Kristi jọba titi ayeraye. A o le fara han ki a si tun lọ, gẹgẹ bi Jesu ti ṣe nigba ti O jinde. Ohun gbogbo ti ara naa yoo fẹ ti o si tọ fun un yoo jẹ ti ọrun. Ara ti aye ti aye yii ni, o kun fun igbokegbodo ti ounjẹ oojọ. S̩ugbọn awọn mejeeji jẹ ara.

Wiwo-ọna fun Idande

A gba wa là kuro ninu è̩ṣẹ, a ra wa pada nipa È̩jẹ Jesu. A n gbe igbesi-aye titun ninu Kristi. S̩ugbọn a n wọna fun ọjọ naa ti a o sọ ara wa di titun. “Nitori awa mọ pe gbogbo ẹda li o jumọ nkerora ti o si nrọbi pọ titi di isisiyi. Ki si iṣe awọn nikan, ṣugbọn awa tikarawa pẹlu, ti o ni akọso Ẹmi, ani awa tikarawa nkerora ninu ara wa, awa nduro dè isọdọmọ, ani idande ara wa” (Romu 8:22, 23).

Awọn Onigbagbọ ti o ti kú ni a o jinde pẹlu ara ologo nigba ti Jesu ba de, awọn Onigbagbọ ti o wa laaye ni a o pa lara dà, “lọgan, ni iṣé̩ju, nigba ipè ikẹhin: nitori ipè yio dún, a o si jí awọn okú dide li aidibajẹ, a ó si pawalara dà” (I Kọrinti 15:52).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Lẹyin ti awọn mọkanla naa ti ri Kristi laayè lẹẹmeji, nibo ni wọn tun lọ?
  2. Ki ni yoo jẹ iṣẹ wọn ni gbogbo ọjọ aye wọn lati igba yii lọ?
  3. Ki ni ohun ti awọn Apọsteli yi ṣe alai ni ninu igbesi-aye wọn fun iṣẹ titun yii?
  4. Nigba ti wọn pada bọ lẹyin iṣẹ wọn ni gbogbo oru, ki ni wọn ri ni eti-okun?
  5. Bawo ni wọn ti ri ṣe to ni gbogbo oru?
  6. Ki ni Alejo wọn ni ki wọn ṣe?
  7. Bawo ni wọn ṣe mọ pe Jesu ni Alejo wọn yii?
  8. Sọ ọrọ ti o waye laaarin Jesu ati Peteru.
  9. Bawo ni Paulu ṣe wa gba Jesu gbọ?
  10. Bawo ni a ṣe mọ pe ara wa ni a o ji dide, kì i ṣe ẹmi wa?