Lesson 253 - Junior
Memory Verse
“Bi nwọn ti nwò, a gbé e soke; awọsanma si gbà a kuro li oju wọn” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:9).Notes
Iṣe Awọn Apọsteli
Awọn Iwe mẹrin akọkọ ninu Majẹmu Titun ni a n pe ni Ihinrere. Wọn sọ ti ihin rere ti igbala. Wọn sọ nipa Jesu ati igbesi-aye Rè̩. Ni akoko ti Jesu wà ni aye, O yàn awọn ọmọ-ẹyin O si kọ wọn ni ilana Rè̩ fun igbesi-aye Onigbagbọ. Jesu kò kọ ni ni ohun kan ki O si tun maa ṣe ohun ti o yatọ si i. O kọ ni, O si ṣe gẹgẹ bi ohun ti O sọ, lati fi hàn pe otitọ ni Ọrọ Rè̩. O kọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ nipa wiwa lọdọ wọn, ati nipa fifihàn wọn bi a ti ṣe le di Onigbagbọ.
Jesu fi owe kọ ni, ni ọna ti o rọrun lati ye ni to bẹẹ ti o fi le ye gbogbo eniyan ati awọn ọmọde paapaa. “Jesu si rìn ni gbogbo ẹkùn Galili, o nkọni ni sinagọgu wọn, o si nwasu ihinrere ijọba, o si nṣe iwosàn gbogbo àrun ati gbogbo àisan li ara awọn enia” (Matteu 4:23). Jesu ṣe awọn iṣẹ-iyanu nla, ti o n fi agbara Rè̩ hàn lori ohun gbogbo. “Awọn afọju nriran, awọn amọkun si nrìn, a nwè̩ awọn adẹtè̩ mọ, awọn aditi ngbọràn, a njí awọn okú dide, a si nwasu ihinrere fun awọn òtoṣi” (Matteu 11:5).
Iwe karun un ninu Majẹmu Titun ni a n pè ni “Iṣe Awọn Apọsteli.” O n sọ nipa iṣẹ awọn ọmọ-ẹyin Jesu ati igbọran wọn nipa kikọ ni ni awọn ofin Jesu. Jesu n kọ ni lẹkọọ, O si n ṣiṣẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ “titi o fi di ọjọ ti a gbà a lọ soke.” Ni ọjọ naa O goke re Ọrun. Igoke-re-Ọrun Rè̩ ni fifi awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ silẹ ati lilọ si Ọrun, gẹgẹ bi O ti sọ fun wọn pe Oun yoo ṣe. Jesu wi pe, “Emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin … pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu” (Johannu 14:2, 3).
Ajinde
Lẹyin ti Jesu jinde kuro ninu okú ni owurọ ọjọ Ajinde kin-in-ni, O fi ara hàn fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni oriṣiriṣi igbà fun ogoji ọjọ. Laaarin akoko yii, O fi hàn pe Oun ti jinde kuro ninu okú. Awọn nnkan ti Jesu ṣe lẹyin ajinde Rè̩ fi hàn pe O wà laaye. Idaniloju wà nipa ajinde Rè̩, Jesu kò si fi aye silẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lati ṣe aṣiṣe nipa wiwà laaye Rè̩.
Awọn ọmọ-ẹyin mọ pe Jesu wà laaye nitori pe O fara hàn O si sọ ara rè̩ di mimọ fun wọn. Kì i ṣe lẹẹkan, ṣugbọn nigba pupọ! Kì i ṣe fun ẹni kan ṣoṣo, ṣugbọn O fara hàn fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni apapọ! (I Kọrinti 15:5-7). Jesu ba wọn rìn O si ba wọn sọrọ pẹlu (Luku 24:13-27). O ba wọn jẹun (Luku 24:41-43). O fi àpá iṣo ti o wà ni ọwọ Rè̩ hàn wọn, ati ibi ti a ti fi ọkọ gun Un lẹgbẹ (Johannu 20:20). Jesu ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ sọrọ nipa iṣẹ wọn fun Ijọba Ọlọrun (Luku 24:44-49; Matteu 28:16-20; Marku 16:14-18). Gbogbo nnkan wọnyi fun ni ni ẹri pe Jesu wà laaye.
Olutunu
Ki a to kàn Jesu mọ agbelebu, O ti ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ sọrọ pe Oun yoo fi wọn silẹ. O tù wọn ninu nipa sisọ fun wọn pe Oun yoo tun pada wá lati wa mu wọn lọ (Johannu 14:2-4). Jesu sọ pe Olutunu naa, ti i ṣe Ẹmi Mimọ, ni a o rán si awọn ọmọ-ẹyin. Lẹyin ti Jesu ba ti lọ, wọn kì yoo da nikan wà nitori pe Olutunu naa yoo maa ba wọn gbe yoo si maa gbe inu wọn (Johannu 14:16, 17, 26). Jesu sọ diẹ ninu awọn nnkan ti Olutunu naa yoo ṣe: yoo maa kọ awọn ọmọ-ẹyin (Johannu 14:26), yoo maa tọ wọn (Johannu 16:13), yoo jẹri nipa Kristi (Johannu 15:26), yoo fi oye yé araye ni ti è̩ṣẹ, ati ododo, ati idajọ (Johannu 16:8).
Lẹyin eyi Jesu sọ ohun ti iṣẹ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ yoo jé̩ fun wọn. Wọn yoo waasu Ihinrere ni gbogbo aye. Ninu ẹkọ wa ti a ṣe kọja a kà nipa iṣẹ-iranṣẹ ti Jesu fi le awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lọwọ. S̩ugbọn ki wọn to jade lọ sinu aye lati waasu, a paṣẹ fun wọn lati gba Olutunu nì, eyi ti i ṣe ileri Baba (Luku 24:49). Akoko to nisisiyi fun lilọ Jesu. O ti fi aṣẹ fun awọn ọmọ-ẹyin nipa ohun ti wọn o ṣe pẹlu ileri lati wà pẹlu wọn (Matteu 28:20).
Oke Olifi
Ni Bẹtani, ni ori oke Olifi ni Jesu bá awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ sọrọ kẹyin (Marku 11:1; Luku 19:29; 24:50). Awọn ọmọ-ẹyin beere lọwọ Jesu boya Oun yoo mu ijọba pada fun Israẹli ni akoko yii? Ọlọrun ti ṣeleri pe a o mu ijọba awọn Ju pada fun wọn. “Emi o si mu awọn onidajọ rẹ pada bi igbà iṣāju, ati awọn igbìmọ rẹ bi igbà akọbè̩rẹ” (Isaiah 1:26). “Sa wò o, ọjọ mbọ, li OLUWA wi, ti emi o gbe Ẹka ododo soke fun Dafidi, yio si jẹ Ọba, yio si ṣe rere, yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na” (Jeremiah 23:5).
Ni akoko yii wọn wà labẹ akoso ijọba Romu. Wọn n wọna fun ọjọ naa ti a o mu ileri naa ṣẹ. Awọn ọmọ-ẹyin n reti pe ki Jesu gbe ijọba aye kalẹ nigba ti O wà ni aye. Wọn lero pe yoo mu ijọba awọn Ju pada nigba naa (Luku 24:21). Jesu kò sọ pe Oun ki yoo jẹ alakoso gbogbo eniyan naa. Titi di ọjọ oni a ko i ti mu ileri naa ṣẹ; ṣugbọn awa paapaa n wọna fun akoko naa nigba ti “Ijọba aiye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rè̩; on o si jọba lai ati lailai” (Ifihan 11:15).
Ko si ẹni ti o mọ igba ti Jesu yoo gbà ipo Rè̩ gẹgẹ bi “ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA” (Ifihan 19:16). Ọlọrun Baba nikan ni o mọ akoko naa. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin, ninu awọn ti awa paapaa wà, pe ki i ṣe ti wọn “lati mọ akoko tabi igba.” Wọn ni iṣẹ lati ṣe. Ti wọn ni lati mura silẹ fun bibọ Jesu ati lati tan Ihinrere kalẹ. Jesu paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lati duro de “ileri Baba” eyi ti O ti sọ fun wọn nipa rè̩. A paṣẹ fun awọn Apọsteli pe ki wọn má ṣe kuro ni Jerusalẹmu, nitori pe ibukun iyanu kan wà ni ipamọ fun wọn. Jesu sọ fun wọn pe wọn o gba iribọmi miiran lẹyin iribọmi ti Johannu Baptisi. Ni ọjọ diẹ sii a o fi Ẹmi Mimọ baptisi wọn.
Iribọmi ti Omi
Johannu Baptisi ṣe iribọmi fun awọn eniyan ninu omi o si n waasu “baptismu ironupiwada fun idariji è̩ṣẹ” (Marku 1:4). Nigba ti awọn eniyan tọ Johannu wa lati ṣe iribọmi, o wi fun wọn pe wọn ni lati kọkọ ronupiwada, lẹyin naa a le ṣe iribọmi fun wọn. Johannu wi pe, “Nitorina, ẹ so eso ti o yẹ fun ironupiwada” (Matteu 3:8).
Awọn miiran bẹrẹ si i ro o pe Johannu Baptisi ni Kristi ati Messia ti a ṣeleri. Johannu ki i ṣe Kristi. Johannu ni aṣaaju naa ti o wa tun ọna ṣe fun Kristi. Johannu jẹri nipa Kristi pe: “Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin; ṣugbọn ẹniti o lagbara ju mi lọ mbọ, okùn bàta ẹsẹ ẹniti emi kò to itú: on ni yio fi Ẹmi Mimọ ati iná baptisi nyin” (Luku 3:16).
Awọn Ẹlẹri
Bi eniyan ba n fẹ di ọmọ-ẹyin Jesu, ẹni naa ni lati ronupiwada ni tootọ gẹgẹ bi Johannu ti kọ ni, ati gẹgẹ bi Jesu naa ti kọ ni (Luku 13:3). Nigba ti eniyan ba ronupiwada ti o si mọ pe a ti dari è̩ṣẹ oun ji, o ti ri igbala. O ni lati wa fi aye rè̩ rubọ fun Oluwa ki o si gbadura pe ki Ọlọrun mu gbongbo è̩ṣẹ kuro ninu igbesi-aye oun ki a ba le sọ ọ di mimọ. “Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimọ nyin” (I Tẹssalonika 4:3). Jesu jiya O si ta È̩jẹ Rè̩ silẹ ki a ba le sọ awọn eniyan Rè̩ di mimọ -- ki a sọ wọn di mimọ lọwọ è̩ṣẹ abinibi (Heberu 13:12). Jesu gbadura pe ki a sọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ di mimọ. O wi pe, “Sọ wọn di mimọ ninu otitọ: otitọ li ọrọ rẹ” (Johannu 17:17).
Ki awọn ọmọ-ẹyin Jesu ba le ṣe ẹlẹri fun Un bi o ti tọ, a paṣẹ fun wọn lati gba Ẹmi Mimọ. Wọn o gba agbara ti yoo sọ wọn di ẹlẹri ti yoo si fun wọn ni agbara lati “wasu ihinrere fun gbogbo ẹda” gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun wọn.
Lẹyin ti a fi Ẹmi Mimọ baptisi wọn eyi ti o fun wọn ni agbara, wọn yoo jẹ ẹlẹri fun Jesu. Wọn yoo bẹrẹ lati Jerusalẹmu, nibi ti wọn o ti gbà ileri Ọlọrun. Lati ibẹ lọ ni wọn o ti maa ṣe ẹlẹri ni gbogbo ilẹ ayika, ni Judea, ati ni Samaria. Wọn o ṣe ẹlẹri kì i ṣe ni ilẹ wọn ati ipinlẹ wọn lori ilẹ aye nikan, ṣugbọn awọn eniyan Ọlọrun yoo tàn Ihinrere kalẹ, wọn o si jẹri titi de opin ayé.
Gigoke Re Ọrun
Bi Jesu ti n ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ sọrọ, O gbé ọwọ Rè̩ soke O si sure fun wọn (Luku 24:50, 51). Bi O ti n ṣe eyi lọwọ O bẹrẹ si gbera nilẹ, O si n lọ soke ju bẹẹ lọ sinu awọsanma. Bi awọn ọmọ-ẹyin ti n wò, awọsanma yi Jesu ka -- wọn ko si ri I mọ. Jesu ti goke re Ọrun. Kì i ṣe awọn angẹli ni o ji I gbe lọ bẹẹ ni kì i si ṣe kẹkẹ ni o gbe E lọ. Kì i ṣe pe O nu mọ wọn loju nigba ti awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pẹyinda. Wọn ri I nigba ti O n goke lọ si Ọrun. Nibẹ ni O joko ni ọwọ ọtun Ọlọrun Baba (Marku 16:19; I Peteru 3:22), nibẹ Jesu n bẹbẹ fun awọn eniyan (Romu 8:34; Heberu 7:25).
Bi awọn ọmọ-ẹyin ti té̩ju mọ awọsanma, awọn ọkunrin meji ti o wà ninu aṣọ àlà yọ si wọn. Wọn n beere lọwọ awọn ọmọ-ẹyin pe: “Ẹnyin ará Galili, ṣe ti ẹ fi duro ti ẹ nwò oju ọrun? Jesu na yi ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bḝ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si ọrun.” Awọn ọmọ-ẹyin rii pe Jesu ti lọ. Nisisiyi wọn ni iṣẹ lati ṣe lati tàn Ihinrere kalẹ, ṣugbọn wọn fi i sọkan lati tẹle awọn aṣẹ Jesu. Wọn lọ si yara oke kan ni Jerusalẹmu. Wọn duro nibẹ, wọn fi ọkàn kan wà nibẹ wọn si n gbadura. Iwọn ọgọfa ninu awọn ọmọ-ẹyin Jesu, ninu awọn ẹni ti iya Rè̩ ati awọn arakunrin Rè̩ wà, ni o pejọ pọ lati gbadura.
Mattia
Peteru mu un wa si iranti wọn pe wọn ni lati yàn ẹni kan lati di ipo ti Judasi fi silẹ, ẹni ti o ti fi Kristi hàn. Judasi ti jẹ ọkan ninu awọn ọmọ-ẹyin (Matteu 10:4; Luku 6:16). O kọ Kristi ati awọn ọmọ-ẹyin iyoku silẹ. O dẹṣẹ nipa tita Kristi fun ọgbọn owo fadaka. S̩ugbọn o da owo naa silẹ ninu Tẹmpili, o ni “Emi ṣè̩ li eyiti mo fi è̩jẹ alaiṣè̩ hàn” (Matteu 27:4). Niwọn igba ti o si lodi si ofin lati fi owo è̩jẹ sinu apoti iṣura, wọn pinnu lati fi owo naa ra ilẹ kan. Wọn si pè e ni “ilẹ amọkoko,” o si jẹ ibi kan ti wọn n sinku awọn alejo si. Didá owo naa pada kò mu è̩ṣẹ Judasi kuro bẹẹ ni kò si mu un pada si ipo rè̩ laaarin awọn ọmọ-ẹyin.
Lai pẹ jọjọ a fi ẹlomiran si aye nla ti iṣẹ ati anfaani eyi ti Judasi fi silẹ nigba ti o kọ Jesu silẹ. A ka Mattia mọ awọn mọkanla iyoku. Mattia ti wà pẹlu awọn iyoku ni gbogbo akoko ti Jesu wà pẹlu wọn, lati igba baptismu Johannu titi di akoko igoke-re-ọrun Jesu. Awọn ọmọ-ẹyin gbadura pe ki Oluwa yàn ẹni naa, ibo si mu Mattia. Lẹyin eyi a pe Paulu lati jẹ ọkan ninu awọn Apọsteli (Romu 1:1; Galatia 1:1).
Wiwo Ọna fun Bibọ Jesu
Jesu ti fi awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ silẹ, gẹgẹ bi O ti wi tẹlẹ. Wọn duro ni ibi ti a ti paṣẹ fun wọn fun Olutunu naa. Lai si aniani, ayọ nla gbà ọkàn wọn kan nitori pe wọn yoo tun ri Jesu. Jesu wi pe: “Bi mo ba lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu” (Johannu 14:3).
A ti sọ fun awọn ọmọ-ẹyin pe ki wọn maa ṣọna ki wọn si maa gbadura nitori pe kò si ẹni kan ti o mọ ọjọ tabi wakati ti Jesu yoo tun pada wa (Matteu 25:13; Marku 13:32, 33). A sọ fun wọn pe ki wọn ṣọra ki ọjọ bibọ Jesu má ba de ba wọn lai ro tẹlẹ (Luku 21:34-36). Jesu wi pe, “Ohun ti mo wi fun nyin, mo wi fun gbogbo enia, Ẹ mā ṣọna” (Marku 13:37). Ki ni itumọ pe ki a maa “ṣọna”? Ẹni kan ti wi pe: “Lati maa ṣọna ni lati gbagbọ pe O mbọ, lati fẹ ifarahan Rè̩, lati maa ro nipa bibọ Rè̩ nigbagbogbo ati lati mọ pe akoko naa sun mọ tosi.” Iwọ ha n ṣọna? Iwọ ha ti mura tan o si n duro de bibọ Jesu bi? Bibọ Jesu yoo jẹ ayọ nla fun awọn ti o n ṣọna, yoo si jé̩ ọjọ ibanujẹ fun awọn ti kò mura silẹ.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni iṣẹ Johannu Baptisti?
- Ki ni Jesu n ṣe lẹyin kikọni?
- Ami wo ni Jesu fi hàn pe Oun wà laaye lẹyin ti O jinde kuro ninu okú?
- Ki ni ṣe ti Jesu kò gbé ijọba kan kalẹ ni ayé ni akoko naa?
- Ki ni iyatọ laaarin iribọmi ti omi ati baptismu ti Ẹmi Mimọ?
- Ki ni ileri Baba?
- Nibo ati bawo ni awọn ọmọ-ẹyin ṣe duro de ileri Baba?
- Sọ nipa igoke-re-Ọrun Jesu.
- Ki ni ọrọ awọn ọkunrin meji nì ti o wà ninu aṣọ funfun?
- Ta ni a yàn lati dipo Judasi?