I Awọn Ọba 1:5-53; 2:1-12

Lesson 254 - Junior

Memory Verse
“Ẹnyin mu ara le, ki ẹ má si dẹ ọwọ nyin: nitori iṣẹ nyin yio ni ère” (II Kronika 15:7).
Notes

Ọtè̩

Dafidi ti jọba lori Israẹli fun ogoji ọdun, o si ti di arugbo ati alailera nisisiyi. Wahala awọn ọta orilẹ-ède rè̩, iwa owu Saulu, ati iṣọtẹ ọmọ oun tikara rè̩, ti mu iyọnu ba igbesi-aye rè̩. Nisisiyi paapaa, ti ọjọ aye rè̩ fẹrẹ de opin, a kò jẹ ki ọkàn rè̩ sinmi.

Adonijah ọmọ rè̩ ọkunrin miiran, fẹ jọba; kò si le ṣe suuru di igba ti Dafidi yoo kú ki o to bẹrẹ si du ìté̩ Israẹli. O mọ dajudaju wi pe Ọlọrun ti yan Sọlomọni bi ọba ti oye kan; ṣugbọn o hàn gbangba pe nigba ti o ti n dagba ni a kò ti du u ni ohunkohun ti ọkàn rè̩ ba n fẹ, o si rò pe oun le mu ifẹ inu oun ṣẹ ninu ọran yii bakan naa.

O yẹ ki ohun ti o ṣẹlẹ si Absalomu arakunrin rè̩ nigba ti o pinnu lati ti baba rè̩ kuro lori oye ti jẹ ikilọ fun Adonijah. A ti pa Absalomu ki iditẹ rè̩ to fidi mulẹ; bẹẹ ni kò si jé̩ anfaani kankan ninu ọlá ati ogo ti o ti jijakadi gidigidi to bẹẹ fún. Eniyan kò le mọọmọ pa aṣẹ ati ifẹ Ọlọrun tì lai jiya fun un. Ọlọrun tikara Rè̩ ni O ti fi itẹ naa le Dafidi lọwọ, Ọlọrun kò si jẹ ki ọlọtè̩ Absalomu ja a gba mọ ọn lọwọ. Bakan naa ni Adonijah kò ni le bori ninu ilepa rè̩ fun okiki ati agbara.

Ọdọmọkunrin ọmọ-ọba ti o jẹ arẹwa yii ni idaniloju pe oun le funra oun fa ọkàn awọn eniyan sọdọ ara rè̩. Boya kò si ẹni ti o lodi si ipinnu rè̩ ri, bẹẹ ni kò si wọ inu ọkàn rè̩ lọ ri pe, ni akoko yii, a o du oun ni ifẹ ọkàn oun. O ti pinnu eto rè̩ lé̩sọlẹsọ -- ki ni ṣe ti wọn kò fi ni yọri si rere?

Okiki Adonijah

Adonijah ṣe gẹgẹ bi Absalomu ti ṣe. O gun kẹkẹ kaakiri ilu, aadọta awọn eniyan si n sare niwaju rè̩ lati fi ọdọmọkunrin ti a fẹ fi jọba lai pẹ hàn. Ọmọ-ọba naa ti lẹwa to, ti o wà ninu aṣọ ọba, ti o si dide duro ṣánṣán ninu kẹkẹ rè̩ bi o ti n fi ọgbọn dari awọn ẹṣin alagbara rè̩ laaarin awọn ogunlọgọ eniyan ti wọn ti pejọ pọ lati kokiki rè̩!

Adonijah ti se àsè nla kan eyi ti o ti pe awọn ọmọ-alade iyoku si, pẹlu awọn alufa, ati olori ẹgbẹ-ogun Dafidi pẹlu. Awọn ti o fẹ fà oju wọn mọra ni olukuluku ẹni ti o le ṣe iranwọ fun un lati gba agbara ijọba. S̩ugbọn a kò pe Sọlomọni, ẹni ti o ni ẹtọ si ade naa gan an, ati Natani Woli, ati Sadoku olori alufa. Adonijah mọ pe wọn o duro niha ti Dafidi.

Nibẹ, laaarin jijẹ ati mimu, a kede pe Adonijah jọba ni Israẹli. Awọn eniyan kigbe pé, “Ki Adonijah ọba ki o pẹ.” Bayii ni Adonijah ṣe si baba rè̩ ti o ti di arugbo ati alailera – o ji ité̩ rè̩ gbà lọwọ rè̩.

Dajudaju Adonijah mọ ofin Ọlọrun, “Bọwọ fun baba on iya rẹ” (Ẹksodu 20:12). Siwaju sii Ofin Lefi wi pe bi ọmọkunrin kan ba ṣe agidi, ki a sọ ọ ni okuta (Deuteronomi 21:18), ati pe pipa ni ki a pa awọn ọmọ ti o ba fi awọn obi wọn ré (Lefitiku 20:9). Ro ìyà ti Adonijah n fà wa sori ara rè̩ nipa lile baba rè̩ kuro lori ité̩.

A Mu Ihin naa wa ba Ọba

Ni gbogbo akoko yii ti Adonijah mu ki a fi oun jọba, Dafidi wà ninu aisan lori akete rè̩. Kò gbọ nnkankan rara nipa ọtẹ naa. Sọlomọni ati iya rè̩ Batṣeba, mọ pe bi Adonijah ba le fi idi ara rè̩ kalẹ bi ọba, yoo pa wọn. Dafidi kò ha ti ṣeleri pe Sọlomọni ni yoo jọba?

Natani gbà Batṣeba ni imọran lati lọ ba Dafidi lati sọ ọrọ ibanujẹ naa fun un. Natani wi pe oun naa yoo wa, oun o si fi idi ọrọ rè̩ mulẹ ki Dafidi ba le mọ bi ọrọ naa ti wuwo to. Batṣeba wọ iyara ọba lọ o si tẹriba o si dojubolẹ niwaju rè̩. Dafidi ṣakiyesi aibalẹ ọkàn rè̩, o si beere ohun ti oun le ṣe fun un. O dahun bayii, “Oluwa mi, iwọ fi Oluwa Ọlọrun rẹ bura fun ọmọ-ọdọ rẹ obirin pe nitõtọ Sọlomọni, ọmọ rẹ yio jọba lẹhin mi, on o si joko lori itẹ mi. Sa wò o, nisisiyi, Adonijah jọba.” Yoo ti yà Dafidi lẹnu pọ to! Yoo si ti dun un pupọ to, pe ọmọ ti oun fẹran to bẹẹ hu iru iwa bayii si oun! Awọn obi ẹni-iwa-bi-Ọlọrun ti kò ba kọ ọmọ wọn lati maa gbọ ti wọn yoo jẹ ìyà rè̩.

Batṣeba sọ siwaju sii fun Dafidi pe Adonijah ti kó awọn alagbara ati onipo eniyan mọra, awọn ti yoo ran an lọwọ, ṣugbọn kò pe ọmọ oun Sọlomọni sibi àsè nla naa. Oju gbogbo eniyan Israẹli si n wo lati ri ohun ti Dafidi yoo ṣe. Inu rè̩ yoo ha dùn pe ki ọmọ rẹ àké̩bàjẹ joko sori itẹ? tabi oun yoo ha mu è̩jé̩ ti o ti jé̩ ṣẹ ki o si mu ifẹ Ọlọrun ṣẹ?

Nigba gbogbo ni Natani ti wà nitosi ọba timọtimọ o si ti jẹ iṣẹ fun un lati ọdọ Ọlọrun wá. O wá beere pe: “Nkan yi ti ọdọ oluwa mi ọba wá bi? iwọ kò si fi ẹniti yio joko lori itẹ oluwa mi ọba lẹhin rè̩ hàn iranṣẹ rè̩?”

Bẹẹ kọ, Dafidi kò ni ọwọ ninu ọran yii. O pe Batṣeba o si tun ileri naa ṣe fun un, pe Sọlomọni ni yoo jọba ni tootọ.

A Gbe Sọlomọni Sipo

Dafidi rii pe oun ni lati ṣe kánkán lati gbe Sọlomọni ka ori itẹ rè̩. O wi pe ki Sadoku alufa, ati Natani, awọn mejeeji ti Ọlọrun bu ọlá fun ti awọn Ọmọ Israẹli si yẹ si, ki wọn gbe Sọlomọni ka ori ibaka Dafidi ki wọn si mu un kaakiri ilu ki gbogbo awọn eniyan ba le mọ ẹni ti Dafidi yàn ṣe ọba. Ni aye atijọ ibaka ni awọn ọba maa n gun, a kò si kà wọn si ẹranko yẹpẹrẹ bi a ti n ka wọn si loni. A saba maa n ṣiro bi ọba ti ni ọrọ to nigba naa nipa kika iye ibaka ti o ni.

Ogo Sọlomọni ti bẹrẹ niyii. Lati opopo kan de ekeji ni ẹgbẹ-ogun awọn ti n daabo bo Dafidi tò ninu ọla-nla --awọn ara Kereti ati Peleti -- ati Sadoku alufa, ati Natani woli, pẹlu Sọlomọni niwaju. Gbogbo awọn Ọmọ Israẹli ti wọn fẹran Ọlọrun ati ọba wọn, ti wọn si gbọ iroyin naa, to sẹyin awọn ero naa.

Nigba ti awọn ero naa de Gihoni, Sadoku mu iwo ororo o si da ororo sori Sọlomọni lati kede rè̩ pe o jọba. A fun ipe lati kede ọba titun naa pe: “Ki Sọlomọni ọba ki o pẹ.”

N ṣe ni ero naa n pọ sii. Nibi gbogbo ni awọn eniyan gbọ ihin ayọ ti fifijọba naa, wọn si wá lati yọ. Ilẹ paapaa mi titi fun iro ayọ wọn.

A mu Ifẹ Ọlọrun S̩ẹ

Lẹẹkan sii a ti mu ifẹ Ọlọrun ṣẹ. A ti fi Sọlomọni jọba gẹgẹ bi Ọlọrun ti palaṣẹ. Ijoloootọ Dafidi si Oluwa ti yọri si imuṣẹ ifẹ Ọlọrun si anfaani ti Sọlomọni.

Awọn eniyan gbadura pe ki ijọba Sọlomọni ki o pọ ju ti baba rè̩ lọ. Bẹẹ naa ni yoo si ri, ni ti pe yoo jẹ akoko alaafia ati ibukun lọpọlọpọ.

O ti jẹ ojuṣe Dafidi lati ṣẹgun awọn orilẹ-ède ti o yi Jerusalẹmu ká ki Israẹli ba le ni gbogbo Ilẹ-Ileri. Nitori bẹẹ nigba gbogbo ni ogun fi wà ni gbogbo ogoji ọdun ti Dafidi fi jọba. Bayii iṣẹ naa ti pari. Sọlomọni si ni anfaani lati ṣe akoso ninu alaafia ki o si gbadun ibukun ijọba nla naa.

Ni iyàrá aisan Dafidi ni a ti mu ihin fifi Sọlomọni jọba wa ba a. Inu Dafidi yoo ti dun to pe a ti yanju gbogbo rogbodiyan naa ni alaafia ti kò fi si ẹni ti o kú ni ọjọ ayọ yii!

Ibẹru Adonijah

Adonijah ati gbogbo awọn eniyan ti wọn wà lọdọ rẹ gbọ pe a ti fi Sọlomọni jọba, è̩rù si ba wọn fun ẹmi wọn. Wọn mọ pe awọn ti jẹbi iṣọtẹ; ati pe ti o ba wu Sọlomọni, o le mu ki a pa Adonijah.

Adonijah sa lọ sibi pẹpẹ lati gbadura ki a má ba pa a. O dabi ọpọlọpọ awọn ẹlẹṣẹ ti n ke abamọ pe è̩ṣẹ wọn ti kó wọn sinu wahala, ṣugbọn ti wọn kò ronupiwada. Wọn fẹ bọ lọwọ iya, nitori bẹẹ wọn a gbadura; ṣugbọn wọn kì i mu ileri ti wọn ṣe fun Ọlọrun ṣẹ.

O tọ ki Adonijah jiya fun ṣiṣaigbọ ti Ọlọrun ati didojuti baba rè̩, ṣugbọn Ọlọrun ṣaaanu fun un. Sọlomọni ranṣẹ si i pe bi o ba tẹriba fun ọba titun ibi kan ki yoo ba a. Adonijah tọ Sọlomọni wa o si fori balẹ fun un, o si pinnu lati wà niha ti ọba. Sọlomọni dariji i o si ran an lọ si ile.

Ọrọ Ikẹyin Dafidi

Nisisiyi ijọba Israẹli ti fidi mulẹ labẹ akoso Sọlomọni, ọkàn Dafidi si balẹ pe oun le kú ni alaafia. Inu Dafidi dun pe ifẹ Ọlọrun ti ṣẹ. O ti maa n dun mọ ọmọ Ọlọrun tó lati mọ pe ọna oun ṣe itẹwọgba loju Ọlọrun!

Aaro yoo sọ Sọlomọni pupọ nigba ti baba rè̩ bá lọ, oun yoo si ni lati fi ara rè̩ hàn bi ọkunrin. Dafidi sọ fun Sọlomọni bi o ti ṣe le di alagbara: “Pa ilana Oluwa, Ọlọrun rẹ mọ, lati ma rin li ọna rè̩, lati pa aṣẹ rè̩ mọ, ati ofin rè̩, ati idajọ rè̩ ati ẹri rè̩ gẹgẹ bi ati kọ ọ ni ofin Mose, ki iwọ ki o lè ma pọ si i ni ohun gbogbo ti iwọ o ṣe, ati nibikibi ti iwọ ba yi ara rẹ si.”

A le mu ọrọ yii wálé fun ara wa. Bi a ba pa gbogbo aṣẹ Ọlọrun mọ, awa naa yoo jẹ alagbara ninu Oluwa. A n fẹ Ẹmi Rè̩ lori iṣẹ wa ki a ba le jere ọkàn fun Ijọba Ọlọrun. Kò si ẹni ti n ṣe rere bi ẹni ti n gbẹkẹle Ọlọrun. O le má ni ọrọ ati okiki ninu aye yii, ṣugbọn o ni iye-ainipẹkun, eyi ti o niyelori jù ohunkohun ti a le ni nihin yii lọ. Ọgbàra ojo tabi ọdá le pa ohun-ọgbin wa, ina le jo ile wa, bẹẹ ni ọlọṣa le ji owo wa; ṣugbọn iṣura ẹni ti n gbẹkẹle Ọlọrun wà ni Ọrun ti ẹnikẹni kò le gba lọwọ rè̩. Iṣura wa ti o niyelori ju lọ ni awọn ìtí ti a ba ri mu wa si ẹsẹ Olugbala wa.

Dafidi ran Sọlomọni leti ileri kan ti Ọlọrun ti ṣe fun un: “Bi awọn ọmọ rẹ ba kiyesi ọna wọn, lati mā fi gbogbo aiya wọn, ati gbogbo ọkàn wọn, rìn niwaju mi li otitọ, (O wipe), a ki yio fẹ ọkọnrin kan kù fun ọ lori itẹ Israẹli” (I Awọn Ọba 2:4). Ileri iyanu! bi Sọlomọni ba si gbọran si aṣẹ Oluwa, a le mu ileri naa ṣẹ nipasẹ rè̩.

Ere fun Iṣẹ

Dafidi tun sọ awọn nnkan miiran ti Sọlomọni gbọdọ ṣe gẹgẹ bi ọba. O ni lati ṣe oore fun awọn ọmọ Barsillai nitori pe wọn wà lẹyin rè̩ nigba ti Absalomu ṣọtè̩. A o fun wọn ni ere fun iranlọwọ ti wọn ṣe fun ọba. Iwa buburu awọn miiran ni a kò le ṣai mu wa si iranti pẹlu, ki a si san ẹsan iyà fun wọn.

Ẹ jẹ ki a ranti pe gbogbo ohun ti a ṣe ni a o mu wa sinu idajọ, ti a o si gba ere fun – yala rere tabi buburu. Awọn olododo yoo bọ sinu iye-ainipẹkun, nigba ti awọn oluṣe-buburu yoo jiya oró lae ati laelae.

Bi Ijọba ologo Sọlomọni Ọba ti bẹrẹ ni yii: o si wà fun nnkan bi ogoji ọdun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni Adonijah fẹ dà?
  2. Ki ni ṣe ti eyi kò fi tọna?
  3. Awọn wo ni Adonijah pè si ibi ase rè̩? Awọn wo ni kò pè?
  4. Ki ni ṣẹlẹ nibi ase naa?
  5. Ki ni Dafidi ṣe nigba ti o gbọ nipa rè̩?
  6. Ki ni ṣe ti Dafidi fi ṣe e ni ọranyan pe Sọlomọni ni ọba ti o gbọdọ jẹ?
  7. Ki ni Adonijah ṣe nigba ti o gbọ pe a ti fi Sọlomọni jọba?
  8. Ki ni awọn ojuṣe ti Dafidi ti ṣe gẹgẹ bi ọba?
  9. Bawo ni ijọba Sọlomọni yoo ti ri?
  10. Ọna wo ni Sọlomọni yoo gba fi di alagbara ti yoo si fi ara rè̩ hàn bi ọkunrin?