I Awọn Ọba 10:1-29

Lesson 259 - Junior

Memory Verse
“Si kiyesi i, a kò sọ idaji wọn fun mi” (I Awọn Ọba 10:7).
Notes

Ọbabinrin Kan

Sọlomọni ni alejo kan. Alejo naa ni Ọbabinrin S̩eba, ẹni ti Jesu tọka si gẹgẹ bi “ọba-binrin gusù.” O wa lati “ikangun aiye wá igbọ ọgbọn Sọlomọni” (Matteu 12:42). Ohun ti o maa n ṣẹlẹ ni pe nigba ti alakoso orilẹ-ède kan ba lọ bẹ alakoso orilẹ-ède miiran wò, wọn a maa ṣe bẹẹ lati ṣe adehun tabi ibadọrẹ nipa majẹmu, lati yanju ọrọ nipa àala ilẹ wọn, lati ṣeto nipa iṣowo ati ìtajà, tabi lati ṣeto bi awọn eniyan orilẹ-ède mejeeji ṣe le ni oye ju bẹẹ lọ nipa ara wọn. Ọbabinrin S̩eba kò wá si ọdọ Sọlomọni nitori eyikeyi ninu awọn eredi ti a sọ yii. Kì i si ṣe pe o deedee n rin irin-ajo la ilẹ naa ja! O ni idi kan fun ibẹwo rè̩ -- lati fi oju ara rè̩ ri ohun ti a ti sọ fun un nipa Sọlomọni, lati gbọ nipa orukọ Oluwa, ki o si té̩ ara rè̩ lọrùn niti mimọ ti o fẹ mọ nipa ọrọ ati ọgbọn Sọlomọni.

Wiwa ọbabinrin yii dabi ẹlẹṣẹ ti o tọ Oluwa wá. Awọn igbesẹ kan wà ti o gbe ti o dabi awọn iṣisẹ ti ẹni ti o n wá Ọlọrun maa n gbe. Awọn iwa kan wà ninu rè̩ ti o dabi eyii ti o wà ninu igbesi-aye awọn ọkunrin, obinrin ati awọn ọmọde ti o gbà Ihinrere.

Gbigbọ Iroyin

Ọbabinrin yii ti gbọ iroyin nipa Sọlomọni ati ọgbọn rè̩. A kò sọ fun wa nipa ọna ti o gba fi gbọ, tabi ẹni ti o sọ fun un, tabi ibi ti o wà nigba ti o gbọ iroyin naa. Lọna kan ihin naa de eti ìgbọ rè̩. Iṣisẹ kin-in-ni niyii fun ẹlẹṣẹ paapaa. O ni lati gbọ nipa igbala ki a ba le gba ọkàn rè̩ là, ati wi pe Jesu kú fun è̩ṣẹ rè̩.

Gbogbo eniyan kọ ni o n gbọ nipa Ihinrere ni ọna kan naa. Awọn miiran maa n gbọ nipa igbala ni ipade iwaasu ode gbangba, a si n fun awọn ẹlomiran ni iwe Ihinrere nigba ti wọn ba wà ni idubulẹ aisan ni ile itọju awọn alaisan. Sibẹsibẹ n ṣe ni a pè awọn ẹlomiiran wá si ipade, tabi wọn gbọ ẹri aladugbo tabi ibatan ti o ti ri igbala. Ọlọrun a maa ṣiṣẹ lọna àrà lati mu ki awọn eniyan gbọ nipa igbala. A ti gbọ iroyin kan pe ẹni kan ri ajáku iwe itankalẹ Ihinrere ti Ijọ Igbagbọ Apọsteli ni oju ọna kan ti o jinna réré si ibi ti eniyan n gbe; o ka ajaku iwe naa o si gbọ iroyin nipa igbala. O gbagbọ o si wá Ọlọrun titi o fi ni idaniloju pe a ti gba oun là. Ọlọrun nikan ṣoṣo ni o mọ bi àjákú iwe Ihinrere naa ti ṣe dé ọna adádo yii.

Ọpọlọpọ ninu awọn ti n sin Ọlọrun nisisiyi gbọ iroyin nipa Ihinrere ni ọna ti o yatọ patapata -- ṣugbọn wọn gbọ! Oluwa jẹ olóòótọ si olukuluku eniyan. Jesu ni i ṣe “Imọlẹ otitọ …. ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye” (Johannu 1:9).

Lati fi Oju Ara Rè̩ Ri i

Lẹyin ti ọbabinrin yii ti gbọ iroyin, kò ni itẹlọrun titi o fi rin irin-ajo lati tọ Sọlomọni wá ki o ba le fi ibeere ṣe iwadi lẹnu rè̩. Boya ọpọlọpọ ohun ni o yi i ká ninu aafin daradara rè̩ bi ọpọlọpọ awọn ọrẹ ati awọn iranṣẹ, idaraya oriṣiriṣi, ounjẹ daradara, ati ọpọlọpọ aṣọ ti o niyelori; ṣugbọn kò ni itẹlọrun. Ọba ni, o si lọrọ, ṣugbọn o ni awọn iṣoro ti o nira.

Ẹnikẹni ti kò ba ti i mọ Ọlọrun kò ni itẹlọrun bẹẹ gẹgẹ. O le jẹ ẹni ti o wà ni ipo giga ninu aye, ki o si ni awọn ohun ini aye yii lọpọlọpọ, sibẹsibẹ o ni awọn iṣoro kò si ni itẹlọrun.

Gẹgẹ bi ọba, Ọbabinrin S̩eba yẹ ki o ni awọn ọjọgbọn eniyan ni ayika rè̩ ti oun le ran si Sọlomọni. Kò rán ẹlomiiran lati lọ ṣe iwadi lẹnu Sọlomọni. Ọbabinrin yii kò ni itẹlọrun titi o fi ri Sọlomọni ẹni nla nì tikara rè̩.

Pe ki ẹlomiiran lọ wo ẹwa Oluwa fun wa tabi lati mọ pe awọn ẹlomiran n ni iriri igbala kò to. Olukuluku eniyan ni o gbọdọ wá sọdọ Ọlọrun ki o si ni iriri igbala tikara rè̩. Nitori pe awọn obi eniyan ti ri igbala kò wi pe awọn ọmọ paapaa ti ri igbala. Awọn ọmọ ni lati gbadura tikara wọn ki wọn si mọ pe a ti gbà wọn la. Bi eniyan tilẹ ni awọn arakunrin, awọn arabinrin, awọn obi, awọn ibatan miiran, ati awọn ọrẹ ti o ti ri igbala, kò le ni itẹlọrun titi yoo fi ni iriri naa tikara rè̩.

Awọn Ibakasiẹ ti o Tò Lọwọọwọ

Ọbabinrin yii ti ọna jijin réré wá si Jerusalẹmu. Ninu awọn ẹgbẹ nla rè̩ ni ọpọlọpọ ibakasiẹ wà ti wọn ru awọn ẹbun ti o niyelori ti o si ṣe iyebiye. Lai si aniani o ni ọpọlọpọ awọn iranṣẹ ati ounjẹ pupọ. Boya irin-ajo naa tilẹ ṣoro ti o si lewu pẹlu. Boya ọbabinrin yii ati awọn ẹgbẹ ero rè̩ ni lati fi ọpọlọpọ ọjọ rìn laaarin aṣalẹ nibi ti kò si ẹnikẹni ati lọna tooro laaarin awọn oke giga nibi ti awọn ọlọṣa ti le gba ẹrù wọn lọ. S̩ugbọn kò si ifi ẹmi wewu ti o pọ jù! O ti pinnu lati ri ọba. O ni lati jẹ pe o fi ẹni kan sori ijọba rè̩ lati maa dele de e, ṣugbọn o ti pinnu tan lati ri Sọlomọni ati lati beere awọn ibeere rè̩ ti o takoko.

Nigba ti ẹlẹṣẹ ba n fi gbogbo ọkàn rè̩ wa Ọlọrun, o ṣetan lati ṣaapọn. Oun a wa sọdọ Jesu, o si n fẹ lati ṣe ohunkohun ti Jesu ba beere lọwọ rè̩, o si ti mura tan lati fi aye rè̩ ati ifẹ rè̩ fun Oluwa. Kò si wahala tabi iṣoro ti o pọ jù lati la kọja lati le ni igbala.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni alejo Sọlomọni?
  2. Ki ni ṣe ti o tọ Sọlomọni wa?
  3. Ki ni o mu lọ si Jerusalẹmu pẹlu rè̩?
  4. Ki ni ohun ti o beere lọwọ Sọlomọni?
  5. Ki ni ohun ti o n sọ nigba ti o wi pe, “A kò sọ idaji wọn fun mi”?
  6. Ki ni ohun ti ọbabinrin naa ri gbà lọwọ Sọlomọni?
  7. Ki ni ohun ti o fun Sọlomọni?
  8. Ki ni ṣe ti Ọbabinrin S̩eba fi ibukun fun Ọlọrun?
  9. Awọn wo ni o dabi Ọbabinrin S̩eba lọjọ oni?
  10. Ta ni Ẹni ti o pọ jù Sọlomọni lọ?