Johannu 20:19-31; Luku 24:36-49

Lesson 250 - Junior

Memory Verse
“Ki iwọ ki o máṣe alaigbagbọ mọ, ṣugbọn jẹ onigbagbọ” (Johannu 20:27).
Notes

Oluwa lati Ọrun

Jesu Kristi Oluwa wá si aye yii lati gbe laaarin awọn eniyan ati lati kọ wọn nipa Ọrun. Kò si ẹni ti o ti fi oju ara rè̩ ri itẹ Ọlọrun ri; kò si ẹni ti o le pada lati ipo òkú lati sọ fun ni bi aye ti n bọ ti ri. Nitori naa Jesu gbe ara eniyan wọ, ani ara ati è̩jẹ, O si wá lati Ọrun lati maa ba wa gbe lati ṣe alaye bi o ti yẹ ki a mura silẹ fun Ile nì loke.

Nigba ti Jesu wà ninu aye, O sọ fun awọn eniyan pe Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe. Iba eniyan diẹ ni o gba eyi gbọ. S̩ugbọn awọn ti o gbagbọ ni Jesu gbà là. Nigba ti Peteru dahun ibeere Oluwa bayii pe, “Kristi, Ọmọ Ọlọrun alāye ni iwọ iṣe” (Matteu 16:16), Jesu sọ fun un wi pe kì i ṣe ẹran ara ati è̩jẹ (tabi eniyan nipa ti ara) ni o fi otitọ naa hàn an, bi kò ṣe Baba ti o wà ni Ọrun.

Jesu pẹlu wá lati fi ara Rè̩ ṣe Ẹbọ fun è̩ṣẹ. Eyi ni pe Oun kò ni ṣai má kú nitori è̩ṣẹ ti wa -- kì i ṣe nitori è̩ṣẹ ti Rè̩, nitori Oun kò ni è̩ṣẹ -- ki O si ji dide lati sọ igbala wa di dajudaju.

O Fi Hàn pe Oun jẹ Ọmọ Ọlọrun

Bawo ni Jesu ṣe le fi hàn pe Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe? Ni tootọ O jẹ Olukọni nla, ṣugbọn bakan naa ni awọn olukọni nla ati oniwaasu ti wà, awọn ti o ti kọ awọn eniyan ni ofin pupọ nipa iwa rere. Bawo ni Jesu ṣe yatọ? Ọlọrun ti sọrọ niye igba lati Ọrun wá O si ti wi pe, “Eyi ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi;” ṣugbọn iba awọn eniyan diẹ kinun ni wọn gbọ Ohùn naa, ninu awọn ti o gbọ tilẹ rò wi pe aara ni o kàn sán.

Paulu ṣe alaye fun wa bi Jesu ti fi hàn pe Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe: Oun ni “a pinnu rè̩ lati jẹ pẹlu agbara Ọmọ Ọlọrun -- nipa ajinde kuro ninu okú” (Romu 1:4). Jesu ti wi pe, “Mo li agbara lati fi i (ẹmi Rè̩) lelẹ, mo si li agbara lati tun gbà a” (Johannu 10:18). Nipa jijinde ninu ara kuro ninu oku – jijade lati inu iboji pẹlu ara Rè̩ -- O fi han pe Oun jẹ Ọmọ Ọlọrun.

Wọn Kò Tete Gbagbọ

Ni tootọ Jesu jinde kuro ninu okú, ṣugbọn njẹ awọn eniyan ha gbagbọ? O ṣoro fun awọn ti wọn tẹle E timọtimọ ninu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lati gbagbọ pe Jesu wà laaye ninu ara. Jesu ti sọ fun wọn niye igba pe Oun kò le ṣai má jiya, ki a si ti ọwọ awọn eniyan buburu pa Oun. Eyi le ye awọn ọmọ-ẹyin, nitori pe awọn woli nlanla miiran ni igba atijọ ti kú ikú ajẹriku. Awọn ọmọ-ẹyin “kānu gidigidi” nigba ti wọn gbọ pe Ọrẹ wọn rere ati Aṣiwaju wọn kò le ṣai má kú bẹẹ.

Nigba ti Jesu sọ fun wọn nipa iku Rè̩, O fi kún un pe, “Ati ni ọjọ kẹta on o si ji dide.” Awọn ọrọ wọnyi kò le ye awọn Apọsteli. Nigba kan Peteru, Jakọbu ati Johannu n ba ara wọn jiroro, wọn n woye pe ki ni itumọ ohun ti O n sọ nipa jiji dide kuro ninu oku. Kò si ninu ero wọn rara pe Jesu yoo tun pada wa sọdọ wọn ninu ara lẹyin ti O ti kú.

O tun Wa Laaye

Akoko de ti wọn pa Jesu. Ijatilẹ naa ti pọ to fun awọn ọmọ-ẹyin! Ọrẹ wọn ti kọja lọ, bẹẹ ni ireti wọn fun ijọba ododo ninu aye pẹlu si fo lọ.

S̩ugbọn owurọ Ajinde de nigbà ti a já ide ikú, ti Kristi, ninu ara, si fi iboji silẹ. Ninu ara ologo O kọja lara okuta iboji Rè̩, O ṣẹgun gbogbo agbara ti o ti de E. Angẹli wá lati yi okuta kuro, lati fi hàn awọn obinrin pe ofifo ni iboji naa wà. A ri awọn aṣọ isinku olowo iyebiye ti o gùn gbọọrọ gbọọrọ nibẹ, eyi ti a ti wé mọ Ọn lara; aṣọ ọgbọ ti a fi bo ori Rè̩ si wà nibi ti ori Rè̩ ti wà. S̩ugbọn ara Jesu kò si nibẹ mọ!

Awọn alufa fun awọn ọmọ-ogun ni abẹtẹlè̩ ki wọn wi pe nigba ti awọn sùn ẹni kan ti ji ara Rè̩ lọ. (Wo iru oluṣọ yẹpẹrẹ ti wọn ni lati jẹ, bi o ba ṣe pe otitọ ni ọrọ wọn.) Bi o ba ṣe pe ẹni kan ti ji ara naa lọ, wọn kò ha ti ni mu aṣọ isinku naa lọ pẹlu? Ohun kan ti o daju gbangba ni pe ara Jesu kò si nibẹ. Nibo ni o wa?

Maria Magdalene ni o kọ mọ. Jesu fara hàn an, O si ba a sọrọ. Lẹyin naa awọn obinrin iyoku ri I; ati Peteru pẹlu, ati awọn ọmọ-ẹyin ni ọna Emmausi. Iri Rè̩ ko yatọ si ti eniyan. O kún fun agbara ati ilera, pẹlu iye titun ninu Rè̩ -- yatọ si Ẹni ti irora ori igi agbelebu ti sọ di olokunrun lẹyin ti È̩jẹ Rè̩ ti ṣan danu kuro lara Rè̩. Irin ọpọlọpọ ibusọ ni O fi ẹsẹ rin lọna Emmausi bi O ti n tumọ ohun ti iwe Majẹmu Laelae sọ nipa Rè̩ fun awọn ọmọ-ẹyin. Wọn rọ Ọ pe ki O wọle wa ba awọn jẹun; bi O si ti mu akara ti O sure si i, oju wọn ṣi wọn si mọ pe Jesu ni – Jesu kan naa, laaye ati ninu ara, sibẹ ninu ara ologo eyi ti o nù mọ wọn loju.

Laaarin awọn Mọkanla

Wọn sare pada si Jerusalẹmu sibi ipade awọn Apọsteli lati sọ ihin rere naa fun wọn. S̩ugbọn bi wọn ti n fi titara-titara sọ nipa ohun abami ti o ṣẹlẹ yii, Jesu duro saaarin wọn, O si sọ fun wọn wi pe: “Alafia fun nyin.” Lara awọn ọrọ ikẹyin ti Jesu ti sọ fun wọn ni yi ki a to kan An mọ agbelebu! “Alafia ni mo fi silẹ fun nyin, alafia mi ni mo fifun nyin” (Johannu 14:27). Kò si ẹlomiran ti i ba lo awọn ọrọ wọnyi. Jesu fẹ ki inu awọn eniyan Rè̩ maa dùn, O si mọ wi pe Oun nikan ṣoṣo ni olufunni ni alaafia. Eniyan kò le ri alaafia nipasẹ ọrọ nla, ara lile, jijẹ olokiki, tabi nipasẹ afẹ aye. Awọn angẹli ti kede nigba ibi Rè̩ wi pe Oun ni Ẹni ti yoo mu alaafia wa. S̩ugbọn awọn ti n beere alaafia lọwọ Rè̩ ti kere niye to!

Jinnijinni mú awọn Apọsteli nigbà ti wọn ri Jesu – ani lẹyin ti a ti sọ fun wọn pe O wà laaye ati pe awọn kan ti ri I, wọn si ti da A mọ gedegbe. Wọn rò wi pe iwin ni wọn ri.

O dùn Jesu pe igbagbọ wọn kere to bẹẹ; ṣugbọn bi o tilẹ jé̩ pe O ba wọn wi nitori aigbagbọ wọn, O sa ipa Rè̩ lati fi hàn wọn wi pe Oun naa ni Ẹni ti wọn ri, ati pe ara gan an ni Oun gbe wọ bi Oun ti duro niwaju wọn. O ni ki wọn di Oun mu, “Iwin kò li ẹran oun egungun lara, bi ẹnyin ti ri ti mo ni.” O fi àpá iṣo ọwọ ati ẹsẹ Rè̩ hàn wọn. A, ohun iyanu: pe Jesu olufẹ ti wọn gan an tun wa laaye! Eyi ha le ri bẹẹ! Ayọ wọn ti pọ jù -- sibẹ ẹnu yà wọn. Iru nnkan bayii kò ṣẹlẹ ri. Jesu fẹ ki o dá wọn loju pe Oun wà laaye, nitori naa eyi fi hàn wi pe Ọmọ Ọlọrun ni O jẹ. Ipilẹ lori eyi ti O n kọ Ijọ Rè̩ niyii.

Ireti Wa

A fẹ rii daju pe a mọ wi pe Jesu jinde kuro ninu okú. Ọpọlọpọ awọn ẹlẹsìn ode-oni ni kò gbagbọ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe. Wọn wi pe Oun kò jinde ninu ara, wi pe nipa ti ẹmi nikan ni O wà laaye gẹgẹ bi olukuluku ẹlomiran ti o ti kú -- awọn miiran wi pe ninu ero ọkàn awọn ti o gba A gbọ nikan ni O wà laaye. S̩ugbọn kì i ṣe bayii ni Bibeli ṣe kọ ni. A fẹ mọ otitọ, nitori pe otitọ ni n sọ ni di ominira: “Bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú, a o gbà ọ là” (Romu 10:9).

Ibanujẹ Di Ayọ

Jesu tun ṣe ohun kan si i lati fi hàn wi pe Oun wà ninu ara: O beere fun ounjẹ; nibẹ loju wọn gan an O si jẹ ẹja bibu ati afara oyin diẹ. Ohun iyanu! Ẹmi tabi iwin kankan kò le jẹun. Òye diẹ ninu awọn ohun ti Jesu ti sọ fun wọn ki a to kan An mọ agbelebu wa bẹrẹ si ye wọn wayii. “Nitorina ẹnyin ni ibinujẹ nisisiyi: ṣugbọn emi o tún ri nyin, ọkàn nyin yio si yọ, kò si si ẹniti yio gbà ayọ nyin lọwọ nyin” (Johannu 16;22). Ọjọ okunkun wà niwaju fun awọn Apọsteli. A o ṣe inunibini si wọn nitori ti Jesu, wọn o si jiya bi ajẹrikú; ṣugbọn ayọ ati alaafia ti Jesu fifun wọn yoo maa wà ninu ọkàn wọn titi.

A Pa Iyemeji Tọmasi Run

Tọmasi kò si nibẹ nigba ti Jesu fi ara hàn ni akọkọ fun awon mọkanla. Nigba ti a sọ ohun ti o ti ṣẹlẹ fun un, oun kò jẹ gbagbọ. A maa n pe e ni Tọmasi Oniyemeji; ṣugbọn iyemeji ti rè̩ ha ju ti awọn iyoku lọ bi? Kò si ẹni kan ninu wọn ti o gbagbọ titi wọn fi fi oju ara wọn ri Jesu.

Ni alẹ ọjọ ọsẹ ti o tẹle e, awọn Apọsteli tun pejọ pọ ninu yara ti a ti ilẹkun rè̩. Ni akoko yii Tọmasi wa laaarin wọn nigba ti Jesu yọ si wọn. Jesu ki wọn bi O ti ṣe ni ọsẹ ti o ṣiwaju: “Alafia fun nyin.” O wa kọju si Tọmasi O wi pe: “Mu ika rẹ wá nihin ki o si wò ọwọ mi; si mu ọwọ rẹ wa nihin ki o si fi si iha mi.” O mọ gbogbo ọrọ ti Tọmasi ti sọ, gẹgẹ bi O si ti mọ gbogbo ọrọ ti awa ba sọ. Ọrọ Tọmasi funra rè̩ ni O fi dahun si iyemeji rè̩. Tọmasi kò le sọrọ ju pe: “Oluwa mi ati Ọlọrun mi.” Jesu wi fun Tọmasi pe: “Nitoriti iwọ ri mi ni iwọ ṣe gbagbọ: alabukun-fun li awọn ti kò ri, ti nwọn si gbagbọ.”

Awa ti o gbagbọ loni pe Jesu jinde kuro ninu okú jẹ alabukun-fun. A kò i ti fi oju wa ri I, ṣugbọn a mọ Ọn nitori pe O ti fi è̩ṣẹ wa jì wa, iye-ainipẹkun si ti bẹrẹ ninu wa.

Ẹlẹri Otitọ

Awọn eniyan ti Jesu ba pade ti O si ba jẹun ni Peteru, Jakọbu, Johannu, Tọmasi, ati awọn iyokù ti yoo jẹ oniwaasu ni ilẹ gbogbo lati sọ itàn ti Jesu. O da wọn loju gidigidi pe Jesu ti ji dide ninu ara to bẹẹ ti o fi jẹ pe lori rè̩ ni gbogbo iṣẹ-iranṣẹ wọn duro le.

Ninu iwaasu kin-in-ni ti Peteru ṣe o sọ fun awọn ẹlẹsin Ju, awọn ẹni ti wọn mọ Iwe Mimọ, wi pe Ọlọrun ti ṣe ileri fun Dafidi pe oun yoo ni “iru-ọmọ inu rẹ,” ti yoo joko lori itẹ rè̩. Peteru wi pe Dafidi n sọ nipa ajinde Kristi, o fi kun un pe: “Jesu na yi li Ọlọrun ti ji dide, ẹlẹri eyiti gbogbo wa iṣe” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:32).

Ni ọdún mẹjọ lẹyin naa Peteru waasu nipa Jesu fun Kọrneliu ati awọn miiran: “On li Ọlọrun jinde ni ijọ kẹta, o si fi i hàn gbangba: kì iṣe fun gbogbo enia, bikoṣe fun awọn ẹlẹri ti a ti ọwọ Ọlọrun yàn tẹlẹ, fun awa, ti a ba a jẹ, ti a si ba a mu lẹhin igbati O jinde kuro ninu okú” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:40)

Peteru ati Johannu yọọda lati lọ sinu tubu nitori pe wọn waasu nipa ajinde. Nigba ti a kilọ fun wọn nipa kóko-ọrọ iwaasu wọn, wọn dahun wi pe, “Awa kò sá le ṣaima sọ ohun ti awa ti ri, ti a si ti gbọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 4:20).

Akọso

Jesu fi hàn nipa ajinde Rè̩ pe Ọmọ-Ọlọrun ni Oun i ṣe. O tun jẹ “akọbi ninu awọn ti o sùn,” tabi awọn ti ara wọn ti kú.

Akọso ti a sọ nipa rè̩ ninu Iwe Lefitiku jẹ àkọpọn gbogbo eso ati ọkà. Wọn maa n ṣe ariya kan ni ibẹrẹ akoko ikore, lati dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ibukun Rè̩; wọn si maa n ya akọso naa sọtọ fun Oluwa. Iru kan naa ni awọn ọkà ati eso iyoku, ṣugbọn a maa n fi eyi silẹ fun ilo awọn eniyan.

Jesu ni ẹni kin-in-ni ti O kọ jinde kuro ninu oku ninu ara ologo. Nigba ajinde kin-in-ni, gbogbo awọn eniyan mimọ Rè̩ yoo jade wa lati inu iboji. “Nigbana li a o si gbà awa ti o wà lāye ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun: bẹli awa o si mā wa titi lai lọdọ Oluwa” (I Tẹssalonika 4:17).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ nipa iku Rè̩?
  2. Ki ni O wi pe yoo ṣẹlẹ lẹyin ti Oun ba ti kú?
  3. Ki ni ṣẹlẹ si ara Jesu lẹyin ti a gbe E sinu iboji?
  4. Nigba wo ni Jesu fi ara hàn awọn mọkanla?
  5. Ki ni ọrọ ti O kọ sọ fun wọn?
  6. Bawo ni O ṣe fi hàn wọn pe Oun ki i ṣe iwin?
  7. Ki ni Jesu fi han nipa ajinde kuro ninu okú?
  8. Ki ni koko ọrọ iwaasu awọn Apọsteli lẹyin Pẹntekọsti?
  9. Anfaani wo ni o jẹ fun wa pe Kristi jẹ “akọbi ninu awọn ti o sùn?”