Luku 24:49-53; Matteu 28:16-20; Marku 16:15-20

Lesson 252 - Junior

Memory Verse
“Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ” (Matteu 28:19).
Notes

Ni Galili

Laaarin ogoji ọjọ ti Jesu lo ninu aye lẹyin ti O jinde kuro ninu okú, O fara hàn awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ niye ìgbà. A ti kà nipa diẹ ninu awọn akoko wọnyi. Loni ẹkọ wa jẹ lori ọrọ ti Jesu ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ sọ nigba ti wọn pade ni Galili, gẹgẹ bi Jesu ti sọ fun wọn.

Jesu ti sọ fun awọn ọmọ-ẹyin mọkanla wi pe Oun o “ṣaju” wọn lọ si Galili lẹyin ti Oun ba jinde (Matteu 26:32). Angẹli nì nibi iboji ofifo sọ fun awọn obinrin wọnnì lati ran awọn ọmọ-ẹyin leti pe wọn le ri Jesu ni Galili (Matteu 28:7). Ki awọn obinrin naa to de ọdọ awọn ọmọ-ẹyin, Jesu ti pade wọn O si wi pe: “Ẹ má bè̩ru: ẹ lọ isọ fun awọn arakọnrin mi pe, ki nwọn ki o lọ si Galili, nibè̩ ni nwọn o gbé ri mi” (Matteu 28:10).

Nigbà ti awọn ọmọ-ẹyin ri Jesu, wọn fori balẹ fun Un, ṣugbọn awọn kan ṣiyemeji. Wọn kò ni igbagbọ to lati mọ daju pe Jesu yii kan naa ni Ẹni ti a ti kan mọ agbelebu ni oju wọn. Jesu kò ha ti wi pe, “O pari,” nigba ti O tẹ ori Rè̩ ba ti O si kú? Ọkan ninu awọn ọmọ-ogun kò ha ti gún iha Jesu ni ọkọ, ti è̩jẹ ati omi si tu jade? A kò ha ti sin olori wọn sinu iboji Josẹfu, ninu ọgbà? Ninu awọn ọmọ-ẹyin ṣiyemeji pe boya kì i ṣe Jesu kan naa ni Ẹni ti O duro niwaju wọn.

Ji dide kuro ninu Okú

Awọn ọmọ-ẹyin ti ri bi Jesu ti ji awọn ẹlomiran dide kuro ninu okú. Wọn ti ri Lasaru (Johannu 11:43, 44) ati ọmọkunrin opo Naini (Luku 7:12-15), awọn ti Jesu ji dide kuro ninu okú. Wọn mọ pe ọmọbinrin Jairu ti kú ṣugbọn Jesu sọ ọ di alaaye (Marku 5:35-42). Bi o tilẹ jẹ pe wọn jẹ ẹlẹri awọn iṣẹ-ami wọnyi, ninu wọn kọ lati gbà pe Jesu tikara Rè̩ ti jinde kuro ninu iboji. Iyanu ni ajinde Jesu jẹ. S̩iwaju akoko yii, ati titi di isisiyi, a kò ri ohunkohun ti o jọ ọ; ṣugbọn Jesu Ọmọ Ọlọrun jade wa lati inu iboji nipa agbara Rè̩ ati ni akoko ti a ti sọ té̩lè̩.

Iyemeji

Ọlọrun ti kọ akọsilẹ nipa iyemeji Tọmasi silẹ fun wa. Nigba ti awọn ọmọ-ẹyin iyoku sọ fun un pe awọn ti ri Jesu, Tọmasi wi pe: “Bikoṣepe mo ba ri àpá iṣó li ọwọ rè̩ ki emi ki o si fi ika mi si àpá iṣó na, ki emi ki o si fi ọwọ mi si ìha rè̩, emi ki yio gbagbọ” (Johannu 20:25). Nigbà ti o ri Jesu ti Jesu si ba a sọrọ, kò ṣanfaani fun Tọmasi lati fi ọwọ rè̩ si iha Jesu tabi ki o fi ika rè̩ sinu àpá iṣo ọwọ Jesu. Tọmasi gbagbọ. Jesu wi pe: “Nitoriti iwọ ri mi ni iwọ ṣe gbagbọ: alabukun-fun li awọn ti kò ri, ti nwọn si gbagbọ.”

A ri awọn ẹlomiran ti o ṣiyemeji pẹlu (Marku 16:11; Luku 24:11). Bi o tilẹ jẹ pe wọn kò sọ ni pato gẹgẹ bi Tọmasi, sibẹ ninu ọkàn wọn o ṣoro fun wọn lati gba iroyin naa gbọ pe Jesu ti jinde kuro ninu okú.

Ibawi

Jesu ba awọn ọmọ-ẹyin wi nitori aigbagbọ ati lile aya wọn. Kò si eyikeyi ninu awọn nnkan meji wọnyi ti aye wà fun ninu ọkàn ati igbesi-aye awọn ọmọ-ẹyin Jesu. O ṣe danindanin pe ki igbagbọ dipo iyemeji. Eniyan ni lati ni igbagbọ ki o ba le ri igbala (Marku 16:16). Eniyan ni lati ni igbagbọ ki o to le maa wà ninu igbala, nitori olododo yoo wà nipa igbagbọ rè̩ (Habakkuku 2:4; Heberu 10:38). Li aisi igbagbọ kò ṣe iṣe lati wu Ọlọrun (Heberu 11:6). Eniyan ni lati ni igbagbọ ki adura rè̩ to le gbà (Marku 11:24; Matteu 21:22). Awọn ti o ba gbà Jesu gbọ yoo ni iye ainipẹkun (Johannu 3:36; 6:47). S̩ugbọn awọn alaigbagbọ yoo jẹ iya ayeraye (Marku 16:16; Ifihan 21:8).

Jesu fẹran awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ṣugbọn O kilọ fun wọn pe pẹlu aigbagbọ ati lile aya, wọn kò le ṣe ọmọ-ẹyin Oun, wọn kò le tan Ihinrere kalẹ, wọn kò si le ṣe iṣẹ-ami lorukọ Jesu.

Agbara Jesu

Lati ki awọn ọmọ-ẹyin laya ati lati ran igbagbọ wọn lọwọ, Jesu wi pe, “Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi” (Matteu 28:18). Kristi ti a n sìn ti li agbara to! Agbara kan kò tun le ju agbara ti Ọrun ati ti aye lọ. Jesu lagbara lori ohun ti aye ati ohun ti ara, bẹẹ ni O si ni lori ohun ti Ọrun ati ti ẹmi pẹlu. Jesu kò gbe agbara yii wọ ara Rè̩; gbogbo agbara ni Ọrun ati ni aye ni a fi fun Jesu, Ọmọ Ọlọrun.

Jesu paapaa ni aṣẹ, O si ni anfaani lati rán awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ jade. Jesu jẹ Olori wọn, Oun ni Ọmọ Ọlọrun. O pa aṣẹ fun awọn ọmọ-ẹyin pe ki wọn tan Ihinrere kalẹ. Iṣẹ ti a fi le wọn lọwọ ni yii. Eto Rè̩ ni eyi fun iṣẹ ti wọn o maa ṣe.

Itọni

Ni ọrọ kukuru Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ bi iṣẹ wọn yoo ti jẹ. Jesu wi pe, “Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ orilẹ-ede gbogbo.” Ni akoko miiran ti a tun ran awọn ọmọ-ẹyin mejila jade, a kilọ fun wọn pe awọn Ọmọ Israẹli nikan ni ki wọn tọ lọ (Matteu 10:5, 6). Ni akoko yii Jesu pa aṣẹ pe ki wọn lọ si gbogbo aye, ki wọn si kọ orilẹ-ède gbogbo. Gbogbo aye ni ibi ti awọn ọmọ-ẹyin yoo ti ṣiṣẹ - ki i ṣe iba apa kan ilẹ aye.

O ni lati jẹ gbogbo awọn ti o n tẹle Jesu ni O pa aṣẹ yii fun. Kò ṣe e ṣe fun iba awọn ọmọ-ẹyin mọkanla pere lati tàn Ihinrere yii kaakiri gbogbo aye, ṣugbọn eyi ni awọn ti n tẹle Kristi n gbiyanju lati ṣe. Nisisiyi a ti tumọ odidi Bibeli ati awọn apa kan lati inu rè̩ si ẹẹdẹgbè̩fà (1,100) ahọn ati ède. Ijọ Igbagbọ Apọsteli (Apostolic Faith) ti tẹ awọn iwe itankalẹ Ihinrere ati awọn iwe kékèke si aadọta ède, wọṅ si ti fi wọn ṣọwọ si igba (200) orilẹ-ède ati erekuṣu.

Lati Kọ Ni ati lati Waasu

Lati rin ká gbogbo ilẹ aye kò to. Jesu wi pe wọn ni lati kọ ni ki wọn si waasu. Jesu kò wi pe ki awọn ọmọ-ẹhin yàn ohun ti wọn o kọ ni. O wi pe, “Ki ẹ ma kọ wọn lati ma kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin.” Wọn ni lati kọ ni ni Ihinrere -- kì i ṣe lara rè̩, ṣugbọn ohun gbogbo ti Jesu ti kọ ni, ani gbogbo Ọrọ Ọlọrun.

Awọn Onigbagbọ

Kì i ṣe gbogbo eniyan ni o gbà Ihinrere Jesu gbọ. Awọn ti kò ba gbagbọ “yio jẹbi,” ṣugbọn awọn ti wọn ba gbagbọ ti wọn si n fiyesi -- awọn oluṣe gẹgẹ bi wọn ti jẹ olugbọ Ọrọ naa – yoo ni igbala.

O jẹ ojuṣe ati anfaani gbogbo awọn ti o ba gbagbọ lati ṣe iribọmi. A ni lati ri wọn bọmi “li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ.” Jesu fi apẹẹrẹ silẹ, O si tun fi aṣẹ lelẹ fun ilana iribọmi. Lati ọwọ Johannu Baptisi ni a ti ṣe iribọmi fun Jesu ninu odo Jọrdani (Marku 1:9). Nibi iribọmi Jesu “Ẹmi nsọkalẹ bi àdaba” le E lori (Marku 1:10), Ọlọrun si sọrọ lati Ọrun wá: “Eyí ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi” (Matteu 3:17).

Lati ṣe iribọmi ni lati tẹ ni bọ omi. Awọn akọsilẹ inu Bibeli fi hàn bi awọn eniyan ti wọ inu omi lọ ti wọn si tun jade (Marku 1:9, 10; Iṣe Awọn Apọsteli 8:38). Ninu awọn iwe Paulu, a fi iribọmi wé sisin ni pẹlu Kristi ati jijinde pẹlu Rè̩ (Kolosse 2:12).

Kì i ṣe pe iribọmi gan an ni o n wẹ è̩ṣẹ eniyan nù. O jẹ ami ode lati fi ohun ti o ti ṣẹlẹ ninu ọkàn hàn. Kiki awọn ti wọn ti ri igbala ni iribọmi wà fun. Fun awọn ti wọn ba gbagbọ ni. (Ka Iṣe Awọn Apọsteli 2:41; 8:12; 18:8; 19:5). Gbogbo awọn ti awọn Apọsteli ṣe iribọmi fun ni wọn jẹ Onigbagbọ. Filippi gbiyanju lati rii daju wi pe iwẹfa nì jẹ Onigbagbọ ki oun Filippi to ṣe iribọmi fun un. Bi wọn ti n gun kẹkẹ lọ, Filippi waasu Jesu fun iwẹfa naa. Iwẹfa naa si wi pe, “Wò o, omi niyi; kili o dá mi duro lati baptisi?” Filippi dahun wi pe: “Bi iwọ ba gbagbọ tọkàntọkan, a le baptisi rẹ” (Iṣe Awọn Apọsteli 8:36, 37). Nigba ti iwẹfa naa jẹwọ igbagbọ rè̩ ninu Jesu gẹgẹ bi Ọmọ Ọlọrun, Filippi ri ọkunrin naa bọmi. Lati ṣe iribọmi gẹgẹ bi ilana ti Bibeli a maa mu ibukun nla wa. Nipa ṣiṣe iribọmi ni igbọran si aṣẹ Jesu, eniyan a maa fi hàn pe oun fẹ wa pẹlu awọn ọmọlẹyin Jesu.

Agbara

Iṣẹ Nla ti Jesu fi le awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lọwọ jẹ aṣẹ, ifọkàntánni ati iranni-niṣẹ. Pẹlu iṣẹ yii, O fun wọn ni aṣẹ ati agbara lati le ṣe e. Jesu sọ fun wọn pe Oun o ran ileri Baba si wọn, ati pe ki wọn joko ni Jerusalẹmu titi a o fi fi agbara wọ wọn “lati oke ọrun wa” (Luku 24:49). Agbara yii yoo mu ki wọn le maa ṣe iṣẹ iyanu ni orukọ Jesu.

Awọn ami kan wà ti yoo maa ba awọn ti o gbagbọ lọ. Ami wọnyii ti Jesu darukọ ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lọ ni tootọ. “Li orukọ mi ni nwọn o ma lé awọn ẹmi èṣu jade.” Paulu dá ọmọbinrin kan silẹ lọwọ ẹmi buburu (Iṣe Awọn Apọsteli 16:18), bẹẹ ni Peteru wo awọn ti ara kan fun ẹmi aimọ san (Iṣe Awọn Apọsteli 5:16).

“Nwọn o si ma fi ède titun sọrọ.” A fi Ẹmi Mimọ wọ wọn, wọn si fi ède miran sọrọ gẹgẹ bi Ẹmi ti fun wọn ni ohun ni Ọjọ Pẹntekọsti (Iṣe Awọn Apọsteli 2:4), awọn Onigbagbọ ti akoko miiran si ni ẹri kan naa nigba ti a fi Agbara Ẹmi Mimọ wọ wọn (Iṣe Awọn Apọsteli 10:46; 19:6).

“Nwọn o gbé ọwọ le awọn olokunrun, ara wọn ó da.” Ọkunrin arọ kan ni a mu lara da ni ẹnu-ọna daradara ti Tẹmpili nigba ti Peteru ati Johannu lọ gbadura, bi Peteru ti wi pe: “Li orukọ Jesu Kristi ti Nasarẹti, dide ki o si mā rin” (Iṣe Awọn Apọsteli 3:1-8). Ọpọlọpọ awọn olokunrun miiran ni a ti wosan nigba ti awọn ti o gbagbọ gbadura ni orukọ Jesu.

“Nwọn o si ma gbé ejò lọwọ.” Paulu kò ni ipalara rárá nigbà ti ejo oloro kan di mọ ọn ni ọwọ bi o ti n ṣa igi fun idana (Iṣe Awọn Apọsteli 28:3-6). Paulu kò mọ-ọ-mọ ṣe eleyi bẹẹ ni kì i ṣe wi pe o dán aanu Ọlọrun wò. O jẹ ajálù,nitori bẹẹ Ọlọrun si daabo bo Paulu.

“Bi wọn ba si mu ohunkohun ti o li oró, ki yio pa wọn lara rara.” Kò si akọsilẹ kankan ninu Bibeli nibi ti awọn ti o gbagbọ ti “mu ohunkohun ti o li oró.” Bi o ti ye wa, itumọ eyi ni pe bi a ba ṣèeṣì mu un ki yoo pa wa lara. Ni aipẹ jọjọ a royin pe Ọlọrun ti daabo bo awọn eniyan Rè̩ nigba ti wọn ṣeeṣi mu ohun ti o ni oró.

Ami wọnyi si ti maa n ba awọn ti o gbagbọ lọ, a si n ri agbara Ọlọrun yì loni laaarin awọn ti wọn gba gbogbo Ọrọ Ọlọrun gbọ. Igba iṣẹ iyanu kò i ti kọja. A n da awọn eniyan silẹ kuro lọwọ agbara èṣu. Nigba ti a ba gba adura igbagbọ ni Orukọ Jesu, è̩ṣẹ maa n sa jade kuro ninu igbesi-aye awọn eniyan, ara awọn olokunrun si maa n da. N jẹ iwọ ti i ri eyikeyi ninu ami wọnyi ti Jesu wi pe yoo maa ba awọn ti o gbagbọ lọ? N jẹ o mọ ẹnikẹni ti a ti wosan nipa agbara Ọlọrun nigba ti a fi ami ororo sii lori ti a si gbadura fun un? (Ka Jakọbu 5:14, 15).

Lati ni agbara Ọlọrun ati pe ki awọn ami wọnyi si maa ba wọn lọ jẹ aṣẹ ati ifi iṣẹ le ni lọwọ gẹgẹ bi jijade lọ waasu Ihinrere. Kì i ṣe gbogbo wa ni a le jẹ ojiṣẹ Ọlọrun ni ilẹ okeere, ṣugbọn a le ṣe iranwọ lati tan Ihinrere kalẹ. Awọn kan gbọdọ sọ fun awọn ara ilu ti wa naa.

Titàn Ihinrere Kalẹ

N jẹ ọmọde le ṣe ohunkohun bi? Ọmọde le ri ṣe ninu Aṣẹ Nla ti Jesu pa nipa pipe aladugbo ati ọrẹ rè̩ wa si ṣọọṣi ati Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi. Ọmọde ti o ti ri igbala le sọ fun awọn ẹlẹgbẹ rè̩ bi a ṣe n ri igbala. Ọmọde le jẹ apẹẹrẹ Onigbagbọ rere ki o si jẹ ki imọlẹ rè̩ tàn. Ọmọde le gbadura fun awọn ẹgbẹ Ajihìnrere ni ile ati ni ilẹ okeere. Ọmọde le gbadura fun awọn iwe Ihinrere ti a n fi ṣọwọ si gbogbo orilẹ-ède aye. Lẹyin ti ọmọde ba ti gbadura, o le ná owo rè̩ fun itakanlẹ Ihinrere.

“Yala ni lilọ tabi ni diduro n go sọ itan ifẹ,

Lo mi, Oluwa, jọwọ lo mi.”

A ha n sa gbogbo ipa wa lati jẹ iṣẹ Jesu? S̩e a n gbọran si aṣẹ Jesu? Ki a ba le ṣe eyi, a ni lati sun mọ Jesu nigba gbogbo. O wi pe, “Ni yiyara nyin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kan” (Johannu 15:5). Jesu ti ṣeleri lati wà pẹlu awọn ọmọlẹhin Rè̩, ati awa loni pẹlu. Awọn ọmọ-ẹhin mọkanla kò gbe layé titi fi de opin aye. Ohun ti Jesu sọ ni pe Oun yoo wà pẹlu gbogbo awọn eniyan Rè̩, ni gbogbo ilẹ ati akoko, ti wọn ba gbọran si Ọrọ Rè̩. Jesu wi pe: “Kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti awọn ọmọ-ẹyin fi lọ si Galili?
  2. Báwo ni wọn ṣe mọ pe Jesu yoo pade wọn nibẹ?
  3. Ki ni ṣe ti Jesu fi bá awọn ọmọ-ẹyin wi?
  4. Ibi wo ni iyemeji n ṣe?
  5. Bawo ni agbara Jesu ti pọ to?
  6. Nibo ni awọn ọmọlẹyin Jesu ni lati waasu?
  7. Ki ni wọn o waasu?
  8. Sọ nipa iribọmi.
  9. Ami wo ni yoo maa tẹle awọn ti o ba gbagbọ?
  10. Ta ni ṣe ileri lati maa wà pẹlu awọn ti o ba gbagbọ?