Iṣe Awọn Apọsteli 1:1-26

Lesson 253 - Junior

Memory Verse
“Bi nwọn ti nwò, a gbé e soke; awọsanma si gbà a kuro li oju wọn” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:9).
Notes

Iṣe Awọn Apọsteli

Awọn Iwe mẹrin akọkọ ninu Majẹmu Titun ni a n pe ni Ihinrere. Wọn sọ ti ihin rere ti igbala. Wọn sọ nipa Jesu ati igbesi-aye Rè̩. Ni akoko ti Jesu wà ni aye, O yàn awọn ọmọ-ẹyin O si kọ wọn ni ilana Rè̩ fun igbesi-aye Onigbagbọ. Jesu kò kọ ni ni ohun kan ki O si tun maa ṣe ohun ti o yatọ si i. O kọ ni, O si ṣe gẹgẹ bi ohun ti O sọ, lati fi hàn pe otitọ ni Ọrọ Rè̩. O kọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ nipa wiwa lọdọ wọn, ati nipa fifihàn wọn bi a ti ṣe le di Onigbagbọ.

Jesu fi owe kọ ni, ni ọna ti o rọrun lati ye ni to bẹẹ ti o fi le ye gbogbo eniyan ati awọn ọmọde paapaa. “Jesu si rìn ni gbogbo ẹkùn Galili, o nkọni ni sinagọgu wọn, o si nwasu ihinrere ijọba, o si nṣe iwosàn gbogbo àrun ati gbogbo àisan li ara awọn enia” (Matteu 4:23). Jesu ṣe awọn iṣẹ-iyanu nla, ti o n fi agbara Rè̩ hàn lori ohun gbogbo. “Awọn afọju nriran, awọn amọkun si nrìn, a nwè̩ awọn adẹtè̩ mọ, awọn aditi ngbọràn, a njí awọn okú dide, a si nwasu ihinrere fun awọn òtoṣi” (Matteu 11:5).

Iwe karun un ninu Majẹmu Titun ni a n pè ni “Iṣe Awọn Apọsteli.” O n sọ nipa iṣẹ awọn ọmọ-ẹyin Jesu ati igbọran wọn nipa kikọ ni ni awọn ofin Jesu. Jesu n kọ ni lẹkọọ, O si n ṣiṣẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ “titi o fi di ọjọ ti a gbà a lọ soke.” Ni ọjọ naa O goke re Ọrun. Igoke-re-Ọrun Rè̩ ni fifi awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ silẹ ati lilọ si Ọrun, gẹgẹ bi O ti sọ fun wọn pe Oun yoo ṣe. Jesu wi pe, “Emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin … pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu” (Johannu 14:2, 3).

Ajinde

Lẹyin ti Jesu jinde kuro ninu okú ni owurọ ọjọ Ajinde kin-in-ni, O fi ara hàn fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni oriṣiriṣi igbà fun ogoji ọjọ. Laaarin akoko yii, O fi hàn pe Oun ti jinde kuro ninu okú. Awọn nnkan ti Jesu ṣe lẹyin ajinde Rè̩ fi hàn pe O wà laaye. Idaniloju wà nipa ajinde Rè̩, Jesu kò si fi aye silẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lati ṣe aṣiṣe nipa wiwà laaye Rè̩.

Awọn ọmọ-ẹyin mọ pe Jesu wà laaye nitori pe O fara hàn O si sọ ara rè̩ di mimọ fun wọn. Kì i ṣe lẹẹkan, ṣugbọn nigba pupọ! Kì i ṣe fun ẹni kan ṣoṣo, ṣugbọn O fara hàn fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni apapọ! (I Kọrinti 15:5-7). Jesu ba wọn rìn O si ba wọn sọrọ pẹlu (Luku 24:13-27). O ba wọn jẹun (Luku 24:41-43). O fi àpá iṣo ti o wà ni ọwọ Rè̩ hàn wọn, ati ibi ti a ti fi ọkọ gun Un lẹgbẹ (Johannu 20:20). Jesu ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ sọrọ nipa iṣẹ wọn fun Ijọba Ọlọrun (Luku 24:44-49; Matteu 28:16-20; Marku 16:14-18). Gbogbo nnkan wọnyi fun ni ni ẹri pe Jesu wà laaye.

Olutunu

Ki a to kàn Jesu mọ agbelebu, O ti ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ sọrọ pe Oun yoo fi wọn silẹ. O tù wọn ninu nipa sisọ fun wọn pe Oun yoo tun pada wá lati wa mu wọn lọ (Johannu 14:2-4). Jesu sọ pe Olutunu naa, ti i ṣe Ẹmi Mimọ, ni a o rán si awọn ọmọ-ẹyin. Lẹyin ti Jesu ba ti lọ, wọn kì yoo da nikan wà nitori pe Olutunu naa yoo maa ba wọn gbe yoo si maa gbe inu wọn (Johannu 14:16, 17, 26). Jesu sọ diẹ ninu awọn nnkan ti Olutunu naa yoo ṣe: yoo maa kọ awọn ọmọ-ẹyin (Johannu 14:26), yoo maa tọ wọn (Johannu 16:13), yoo jẹri nipa Kristi (Johannu 15:26), yoo fi oye yé araye ni ti è̩ṣẹ, ati ododo, ati idajọ (Johannu 16:8).

Lẹyin eyi Jesu sọ ohun ti iṣẹ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ yoo jé̩ fun wọn. Wọn yoo waasu Ihinrere ni gbogbo aye. Ninu ẹkọ wa ti a ṣe kọja a kà nipa iṣẹ-iranṣẹ ti Jesu fi le awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lọwọ. S̩ugbọn ki wọn to jade lọ sinu aye lati waasu, a paṣẹ fun wọn lati gba Olutunu nì, eyi ti i ṣe ileri Baba (Luku 24:49). Akoko to nisisiyi fun lilọ Jesu. O ti fi aṣẹ fun awọn ọmọ-ẹyin nipa ohun ti wọn o ṣe pẹlu ileri lati wà pẹlu wọn (Matteu 28:20).

Oke Olifi

Ni Bẹtani, ni ori oke Olifi ni Jesu bá awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ sọrọ kẹyin (Marku 11:1; Luku 19:29; 24:50). Awọn ọmọ-ẹyin beere lọwọ Jesu boya Oun yoo mu ijọba pada fun Israẹli ni akoko yii? Ọlọrun ti ṣeleri pe a o mu ijọba awọn Ju pada fun wọn. “Emi o si mu awọn onidajọ rẹ pada bi igbà iṣāju, ati awọn igbìmọ rẹ bi igbà akọbè̩rẹ” (Isaiah 1:26). “Sa wò o, ọjọ mbọ, li OLUWA wi, ti emi o gbe Ẹka ododo soke fun Dafidi, yio si jẹ Ọba, yio si ṣe rere, yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na” (Jeremiah 23:5).

Ni akoko yii wọn wà labẹ akoso ijọba Romu. Wọn n wọna fun ọjọ naa ti a o mu ileri naa ṣẹ. Awọn ọmọ-ẹyin n reti pe ki Jesu gbe ijọba aye kalẹ nigba ti O wà ni aye. Wọn lero pe yoo mu ijọba awọn Ju pada nigba naa (Luku 24:21). Jesu kò sọ pe Oun ki yoo jẹ alakoso gbogbo eniyan naa. Titi di ọjọ oni a ko i ti mu ileri naa ṣẹ; ṣugbọn awa paapaa n wọna fun akoko naa nigba ti “Ijọba aiye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rè̩; on o si jọba lai ati lailai” (Ifihan 11:15).

Ko si ẹni ti o mọ igba ti Jesu yoo gbà ipo Rè̩ gẹgẹ bi “ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA” (Ifihan 19:16). Ọlọrun Baba nikan ni o mọ akoko naa. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin, ninu awọn ti awa paapaa wà, pe ki i ṣe ti wọn “lati mọ akoko tabi igba.” Wọn ni iṣẹ lati ṣe. Ti wọn ni lati mura silẹ fun bibọ Jesu ati lati tan Ihinrere kalẹ. Jesu paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lati duro de “ileri Baba” eyi ti O ti sọ fun wọn nipa rè̩. A paṣẹ fun awọn Apọsteli pe ki wọn má ṣe kuro ni Jerusalẹmu, nitori pe ibukun iyanu kan wà ni ipamọ fun wọn. Jesu sọ fun wọn pe wọn o gba iribọmi miiran lẹyin iribọmi ti Johannu Baptisi. Ni ọjọ diẹ sii a o fi Ẹmi Mimọ baptisi wọn.

Iribọmi ti Omi

Johannu Baptisi ṣe iribọmi fun awọn eniyan ninu omi o si n waasu “baptismu ironupiwada fun idariji è̩ṣẹ” (Marku 1:4). Nigba ti awọn eniyan tọ Johannu wa lati ṣe iribọmi, o wi fun wọn pe wọn ni lati kọkọ ronupiwada, lẹyin naa a le ṣe iribọmi fun wọn. Johannu wi pe, “Nitorina, ẹ so eso ti o yẹ fun ironupiwada” (Matteu 3:8).

Awọn miiran bẹrẹ si i ro o pe Johannu Baptisi ni Kristi ati Messia ti a ṣeleri. Johannu ki i ṣe Kristi. Johannu ni aṣaaju naa ti o wa tun ọna ṣe fun Kristi. Johannu jẹri nipa Kristi pe: “Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin; ṣugbọn ẹniti o lagbara ju mi lọ mbọ, okùn bàta ẹsẹ ẹniti emi kò to itú: on ni yio fi Ẹmi Mimọ ati iná baptisi nyin” (Luku 3:16).

Awọn Ẹlẹri

Bi eniyan ba n fẹ di ọmọ-ẹyin Jesu, ẹni naa ni lati ronupiwada ni tootọ gẹgẹ bi Johannu ti kọ ni, ati gẹgẹ bi Jesu naa ti kọ ni (Luku 13:3). Nigba ti eniyan ba ronupiwada ti o si mọ pe a ti dari è̩ṣẹ oun ji, o ti ri igbala. O ni lati wa fi aye rè̩ rubọ fun Oluwa ki o si gbadura pe ki Ọlọrun mu gbongbo è̩ṣẹ kuro ninu igbesi-aye oun ki a ba le sọ ọ di mimọ. “Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimọ nyin” (I Tẹssalonika 4:3). Jesu jiya O si ta È̩jẹ Rè̩ silẹ ki a ba le sọ awọn eniyan Rè̩ di mimọ -- ki a sọ wọn di mimọ lọwọ è̩ṣẹ abinibi (Heberu 13:12). Jesu gbadura pe ki a sọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ di mimọ. O wi pe, “Sọ wọn di mimọ ninu otitọ: otitọ li ọrọ rẹ” (Johannu 17:17).

Ki awọn ọmọ-ẹyin Jesu ba le ṣe ẹlẹri fun Un bi o ti tọ, a paṣẹ fun wọn lati gba Ẹmi Mimọ. Wọn o gba agbara ti yoo sọ wọn di ẹlẹri ti yoo si fun wọn ni agbara lati “wasu ihinrere fun gbogbo ẹda” gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun wọn.

Lẹyin ti a fi Ẹmi Mimọ baptisi wọn eyi ti o fun wọn ni agbara, wọn yoo jẹ ẹlẹri fun Jesu. Wọn yoo bẹrẹ lati Jerusalẹmu, nibi ti wọn o ti gbà ileri Ọlọrun. Lati ibẹ lọ ni wọn o ti maa ṣe ẹlẹri ni gbogbo ilẹ ayika, ni Judea, ati ni Samaria. Wọn o ṣe ẹlẹri kì i ṣe ni ilẹ wọn ati ipinlẹ wọn lori ilẹ aye nikan, ṣugbọn awọn eniyan Ọlọrun yoo tàn Ihinrere kalẹ, wọn o si jẹri titi de opin ayé.

Gigoke Re Ọrun

Bi Jesu ti n ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ sọrọ, O gbé ọwọ Rè̩ soke O si sure fun wọn (Luku 24:50, 51). Bi O ti n ṣe eyi lọwọ O bẹrẹ si gbera nilẹ, O si n lọ soke ju bẹẹ lọ sinu awọsanma. Bi awọn ọmọ-ẹyin ti n wò, awọsanma yi Jesu ka -- wọn ko si ri I mọ. Jesu ti goke re Ọrun. Kì i ṣe awọn angẹli ni o ji I gbe lọ bẹẹ ni kì i si ṣe kẹkẹ ni o gbe E lọ. Kì i ṣe pe O nu mọ wọn loju nigba ti awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pẹyinda. Wọn ri I nigba ti O n goke lọ si Ọrun. Nibẹ ni O joko ni ọwọ ọtun Ọlọrun Baba (Marku 16:19; I Peteru 3:22), nibẹ Jesu n bẹbẹ fun awọn eniyan (Romu 8:34; Heberu 7:25).

Bi awọn ọmọ-ẹyin ti té̩ju mọ awọsanma, awọn ọkunrin meji ti o wà ninu aṣọ àlà yọ si wọn. Wọn n beere lọwọ awọn ọmọ-ẹyin pe: “Ẹnyin ará Galili, ṣe ti ẹ fi duro ti ẹ nwò oju ọrun? Jesu na yi ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bḝ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si ọrun.” Awọn ọmọ-ẹyin rii pe Jesu ti lọ. Nisisiyi wọn ni iṣẹ lati ṣe lati tàn Ihinrere kalẹ, ṣugbọn wọn fi i sọkan lati tẹle awọn aṣẹ Jesu. Wọn lọ si yara oke kan ni Jerusalẹmu. Wọn duro nibẹ, wọn fi ọkàn kan wà nibẹ wọn si n gbadura. Iwọn ọgọfa ninu awọn ọmọ-ẹyin Jesu, ninu awọn ẹni ti iya Rè̩ ati awọn arakunrin Rè̩ wà, ni o pejọ pọ lati gbadura.

Mattia

Peteru mu un wa si iranti wọn pe wọn ni lati yàn ẹni kan lati di ipo ti Judasi fi silẹ, ẹni ti o ti fi Kristi hàn. Judasi ti jẹ ọkan ninu awọn ọmọ-ẹyin (Matteu 10:4; Luku 6:16). O kọ Kristi ati awọn ọmọ-ẹyin iyoku silẹ. O dẹṣẹ nipa tita Kristi fun ọgbọn owo fadaka. S̩ugbọn o da owo naa silẹ ninu Tẹmpili, o ni “Emi ṣè̩ li eyiti mo fi è̩jẹ alaiṣè̩ hàn” (Matteu 27:4). Niwọn igba ti o si lodi si ofin lati fi owo è̩jẹ sinu apoti iṣura, wọn pinnu lati fi owo naa ra ilẹ kan. Wọn si pè e ni “ilẹ amọkoko,” o si jẹ ibi kan ti wọn n sinku awọn alejo si. Didá owo naa pada kò mu è̩ṣẹ Judasi kuro bẹẹ ni kò si mu un pada si ipo rè̩ laaarin awọn ọmọ-ẹyin.

Lai pẹ jọjọ a fi ẹlomiran si aye nla ti iṣẹ ati anfaani eyi ti Judasi fi silẹ nigba ti o kọ Jesu silẹ. A ka Mattia mọ awọn mọkanla iyoku. Mattia ti wà pẹlu awọn iyoku ni gbogbo akoko ti Jesu wà pẹlu wọn, lati igba baptismu Johannu titi di akoko igoke-re-ọrun Jesu. Awọn ọmọ-ẹyin gbadura pe ki Oluwa yàn ẹni naa, ibo si mu Mattia. Lẹyin eyi a pe Paulu lati jẹ ọkan ninu awọn Apọsteli (Romu 1:1; Galatia 1:1).

Wiwo Ọna fun Bibọ Jesu

Jesu ti fi awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ silẹ, gẹgẹ bi O ti wi tẹlẹ. Wọn duro ni ibi ti a ti paṣẹ fun wọn fun Olutunu naa. Lai si aniani, ayọ nla gbà ọkàn wọn kan nitori pe wọn yoo tun ri Jesu. Jesu wi pe: “Bi mo ba lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu” (Johannu 14:3).

A ti sọ fun awọn ọmọ-ẹyin pe ki wọn maa ṣọna ki wọn si maa gbadura nitori pe kò si ẹni kan ti o mọ ọjọ tabi wakati ti Jesu yoo tun pada wa (Matteu 25:13; Marku 13:32, 33). A sọ fun wọn pe ki wọn ṣọra ki ọjọ bibọ Jesu má ba de ba wọn lai ro tẹlẹ (Luku 21:34-36). Jesu wi pe, “Ohun ti mo wi fun nyin, mo wi fun gbogbo enia, Ẹ mā ṣọna” (Marku 13:37). Ki ni itumọ pe ki a maa “ṣọna”? Ẹni kan ti wi pe: “Lati maa ṣọna ni lati gbagbọ pe O mbọ, lati fẹ ifarahan Rè̩, lati maa ro nipa bibọ Rè̩ nigbagbogbo ati lati mọ pe akoko naa sun mọ tosi.” Iwọ ha n ṣọna? Iwọ ha ti mura tan o si n duro de bibọ Jesu bi? Bibọ Jesu yoo jẹ ayọ nla fun awọn ti o n ṣọna, yoo si jé̩ ọjọ ibanujẹ fun awọn ti kò mura silẹ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni iṣẹ Johannu Baptisti?
  2. Ki ni Jesu n ṣe lẹyin kikọni?
  3. Ami wo ni Jesu fi hàn pe Oun wà laaye lẹyin ti O jinde kuro ninu okú?
  4. Ki ni ṣe ti Jesu kò gbé ijọba kan kalẹ ni ayé ni akoko naa?
  5. Ki ni iyatọ laaarin iribọmi ti omi ati baptismu ti Ẹmi Mimọ?
  6. Ki ni ileri Baba?
  7. Nibo ati bawo ni awọn ọmọ-ẹyin ṣe duro de ileri Baba?
  8. Sọ nipa igoke-re-Ọrun Jesu.
  9. Ki ni ọrọ awọn ọkunrin meji nì ti o wà ninu aṣọ funfun?
  10. Ta ni a yàn lati dipo Judasi?