I Awọn Ọba 3:5-15; 4:21-34

Lesson 255 - Junior

Memory Verse
“Fi aiya si ẹkọ, ati eti rẹ si ọrọ imọ” (Owe 23:12).
Notes

Wọn gba Ilẹ Palẹstini

Ẹrù nla ni o wà fun Sọlomọni nigba ti o jọba. Awọn ilu ti o wà labẹ akoso rè̩ pọ ju eyikeyi ti Israẹli ti n ṣakoso nigba kan ri lọ. Dafidi, baba rè̩ ti ṣẹgun ọpọlọpọ orilẹ-ède ti o yi wọn ka, bẹẹ ni eyi si jẹ igba kin-in-ni ti Israẹli ṣakoso gbogbo ilẹ naa ti Ọlọrun ti ṣeleri fun Abrahamu ati iran rè̩ lati iwọn ẹẹdẹgbẹrun (900) ọdun sẹyin.

Ki ni Sọlomọni yoo ti ṣe ijọba nlá nlà yii si? Ọmọ ọdun mọkandinlogun tabi ogun ọdun pere ni, o si gbọdọ ni ọgbọn lati ṣakoso awọn eniyan ti o pọ lọpọlọpọ to bayii. Sọlomọni ti kọ ẹkọ ni akoko ijọba baba rè̩ pe nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ba tẹle ofin Ọlọrun, wọn maa n ṣe rere; Sọlomọni si n fẹ ni tootọ pé ki orilẹ-ède naa ṣe rere ni akoko ijọba rè̩. Oun pinnu ninu ọkàn rè̩ lati tẹle aṣẹ Ọlọrun, lati mu ojurere Rè̩ wa sori ilẹ naa. Ọlọrun bu ọlá fun un, Sọlomọni si le kọ akọsilẹ lẹyin eyi pe: “Ododo ni igbé orilẹ-ède leke; ṣugbọn è̩ṣẹ li è̩gan orilẹ-ède” (Owe 14:34).

Isin ni Ibi Giga

Ni akoko ti Sọlomọni jọba, Apoti Majẹmu wà ni Jerusalẹmu, ṣugbọn Agọ-Ajọ wà ni Gibeoni sibẹ. A kò i ti kọ Tẹmpili nigba naa, kò si ti si ibi apejọpọsi kan lati maa jọsin. Wọn ti tẹ pẹpẹ si ọpọlọpọ ibi giga lati jọsin si Ọlọrun, ṣugbọn wọn dabi awọn pẹpẹ awọn abọriṣa, ewu ti o wà ninu eyi ni pe ọkàn awọn Ọmọ Israẹli le yipada si awọn oriṣa. Iṣẹ nla ti Sọlomọni ni lati ṣe ni lati kọ Tẹmpili ni Jerusalẹmu, ki gbogbo awọn Ọmọ Israẹli ba le ni anfaani lati jọsin pọ ni ibi kan naa, ni iṣọkan igbagbọ. Iṣẹ yii yoo gba ọpọlọpọ ọdun ni igba ijọba rè̩.

Wọn n Fẹ Iranlọwọ Ọlọrun

Sọlomọni woye pe oun ni lati ni iranlọwọ Ọlọrun lati le ṣakoso orilẹ-ède nla yii, nitori naa o lọ si Agọ-Ajọ ni Gibeoni lati gbadura. Ọkàn rè̩ ṣe deedee pẹlu Ọlọrun, nitori naa Ọlọrun le ba a sọrọ. Ni oru ọjọ naa Ọlọrun fara hàn an ni oju ala, O si beere ohun ti Sọlomọni n fẹ ki a fi fun oun lati Ọrun wá. Sọlomọni mọ pe Ọlọrun yoo dahun adura oun, nitori pe Onipsalmu ti wi pe, “Kò si ohun rere ti yio fà sẹhin lọwọ awọn ti nrìn dede” (Orin Dafidi 84:11). Baba rè̩ paapaa ti wi pe, “Ma kiyesi ẹni pipé, ki o si ma wò ẹni diduro ṣinṣin: nitori alafia li opin ọkọnrin na” (Orin Dafidi 37:37). Sọlomọni n fẹ alaafia o si mọ pe Ọlọrun yoo fi i fun oun.

Sọlomọni sọ ti ibukun nla ti Dafidi ti ri gba, ninu eyi ti jijọba Sọlomọni jẹ eyi ti o tobi ju lọ. Ọlọrun ti ṣeleri pe a o fi idi itẹ Dafidi kalẹ titi lae, Sọlomọni si ti bẹrẹ imuṣẹ ileri naa. Ọlọrun si ti ba Dafidi sọrọ ju bẹẹ lọ nipa Sọlomọni pẹlu; “On o si kọ ile fun orukọ mi, emi o si fi idi itẹ ijọba rè̩ kalẹ lailai. Emi o ma ṣe baba fun u, on o si ma jẹ ọmọ mi ... ānu mi ki yio yipada kuro lọdọ rè̩, gẹgẹ bi emi ti mu u kuro lọdọ Saulu, ti emi ti mu kuro niwaju rẹ. A o si fi idile rẹ ati ijọba rẹ mulẹ niwaju rẹ titi lai” (II Samuẹli 7:13-16). Ni oru ọjọ yii Sọlomọni n ṣe ifara-rubọ rè̩ lati tẹ siwaju ki o si gba Ọlọrun laye lati tipasẹ rè̩ ṣiṣẹ fun ilọsiwaju Ijọba Rè̩.

Awọn obi a maa gba ibukun nigba ti wọn ba ya ọmọ wọn sọtọ fun Oluwa. S̩ugbọn wo iru ibukun ti yoo jẹ ti awọn ọmọ ti yoo tè̩ siwaju ninu ifararubọ naa ki wọn si jọwọ aye wọn patapata fun ifẹ Oluwa! Ọpọlọpọ ibukun ti kò lopin ni o wà ni ipamọ fun awọn ọdọ ti yoo fi ohun gbogbo ti i ṣe ti wọn fun Jesu fun isin Rè̩. Ọlọrun yoo yẹ ifararubọ Sọlomọni si pẹlu ibukun nlá nlà ti o tilẹ tobi ju eyi ti Dafidi ti jẹ igbadun rè̩ lọ.

Bi Irawọ Oju Ọrun

Ọlọrun ti ṣeleri fun Abrahamu pe iru-ọmọ rè̩ yoo dabi awọn irawọ oju ọrun ni iye. Ni oju Sọlomọni o dabi ẹni pe akoko naa ti dé. Awọn ẹya Israẹli ti pọ to bẹẹ ti o fi jé̩ pé awọn eniyan ti o pọ lọpọlọpọ niye ni o n gbe ni gbogbo Ilẹ Mimọ yii; ni oju Sọlomọni, ninu ailera rè̩, o dabi ẹni pe a kò tilẹ le kà wọn tan. Bawo ni oun yoo ti ṣe akoso awọn ogunlọgọ eniyan bayii? O fẹ ki wọn fẹran Oluwa; o si fẹ ki awọn eniyan naa layọ ki wọn si ṣe rere ni ilẹ naa. Iwuwo bi awọn eniyan rè̩ yoo ṣe wà ni alaafia kún ọkàn rè̩ ju ti ohunkohun nipa ti ara rè̩ lọ.

O mọ pe wahala yoo wa laaarin awọn eniyan naa ti oun yoo ni lati pari rè̩. O wo ara rè̩ pe ọmọde ni oun i ṣe; bawo ni oun ṣe le tọ awọn agba sọna ki oun si sọ ohun ti o tọ ati ohun ti kò tọ fun wọn? Ọlọrun nikan ṣoṣo ni o le ran an lọwọ lati ṣe ipinnu wọnyi. Jakọbu Apọsteli kọ akọsilẹ pe: “Bi o ba kù ọgbọn fun ẹnikẹni, ki o bère lọwọ Ọlọrun, ẹniti ifi fun gbogbo enia li ọpọlọpọ, ti ki isi iba-ni-wi; a o si fifun u” (Jakọbu 1:5).

Ohun ti Sọlomọni gbagbọ ni eyi, o si beere pé: “Nitorina fi ọkàn imoye fun iranṣẹ rẹ lati ṣe idajọ awọn enia rẹ, lati mọ iyatọ rere ati buburu; nitori tali o le ṣe idajọ awọn enia rẹ yi ti o pọ to yi?”

Inu Ọlọrun dun si adura yii. Inu Rè̩ dun pe Sọlomọni jẹ alaimọ ti ara rè̩ nikan bẹẹ. Nitori ibeere rè̩ ti kò ni imọ-ti-ara-ẹni nikan ninu, Ọlọrun yoo tilẹ fun un ni ọrọ ati okiki pẹlu, eyi ti kò beere.

Ifẹ Kan

Bi a ba sọ fun ọ pe ki o beere ohun kan, ki ni iwọ yoo beere? Yoo ha jẹ fun ohun-ini aye yii? Bi o ba ni in, owo kò le mu inu rẹ dùn. O lè jẹ igbadun nina owo naa fun igbà diẹ, ṣugbọn bi iwọ kò ba lo o fun Oluwa, lai pẹ jọjọ yoo mu ibanujẹ wá. Tabi bi o ba beere fun okiki, bi gbogbo eniyan ti o ka orukọ rẹ ninu iwe-iroyin mọ iṣẹ pataki ti o ṣe, ere wo ni yoo jẹ bi o ba duro niwaju Oluwa ti o si gbọ ti O wi pe, “Emi kò mọ ọ ri”? Lati jé̩ ọmọ Ọlọrun ni ohun ti o ṣe pataki jù lọ ni gbogbo aye yii. “Oluwa mọ awọn ti iṣe tirè̩” (II Timoteu 2:19).

Ọba ti o Lọgbọn Jù Lọ

Sọlomọni beere fun ọgbọn, Ọlọrun si fi i fun un. Ibukun ijọba rè̩ yoo si jẹ eyi ti “ki yio si ọkan ninu awọn ọba ti yio dabi rẹ.” Ro o wo! Yoo jẹ ọba ti o kún fun ọgbọn pupọ jù lọ, ti o ni ọrọ pupọ jù lọ, ti o si ni agbara pupọ jù lọ ni gbogbo aye. Bi o ba si n rin ninu ọna rere ti o yan yìí yoo lo ọpọlọpọ ọdun lori ilẹ aye.

Àlá ni eyi, ṣugbọn o ju àlá kan lasan lọ. Nigba laelae, igba pupọ ni Ọlọrun maa n lo ala lati fi sọ iṣẹ ti O n ran si awọn eniyan fun wọn. Tọkàntọkàn ni Sọlomọni fi pinnu lati ṣe ohun gbogbo ti o ba Ọlọrun sọ ninu ala. Ohun kin-in-ni ti o ṣe lẹyin naa ni lati lọ si Jerusalẹmu lati jọsin niwaju Apoti Majẹmu, ati lati ru ẹbọ iyin si Ọlọrun fun awọn ibukun ti o n ri gbà.

Ni igba laelae, Ọlọrun ba awọn woli sọrọ nipa àlá ati iran, ṣugbọn O ti fun awa ni Bibeli. A le mọ ifẹ Ọlọrun nipa kikà Ọrọ Rè̩. Oun kò ni yi Ọrọ Rè̩ pada. Eniyan le lá àlá ti o ti ọdọ Ọlọrun wá; ṣugbọn yoo ṣe deedee pẹlu ohun ti Bibeli wi. Ọlọrun kò ni fun eniyan ni àlá kan ti o lodi si ohun ti O ti kọ silẹ. A o ri gbogbo itọsọna ti o yẹ fun igbesi-aye wa ojoojumọ, ati imurasilẹ wa fun Ọrun ninu Bibeli.

Okiki

Okiki Sọlomọni kàn ni gbogbo orilẹ-ède aye igba naa. Awọn eniyan nla ati awọn ọba mú iṣura wọn wá fun Sọlomọni. A mu turari oloorun didun ati awọn nnkan iyebiye miiran ti wọn ki i gbin ni Palẹstini wá lati ilu okeere; a fun Sọlomọni ni wura ati okuta iyebiye lọpọlọpọ, to bẹẹ ti ilẹ rè̩ fi di orilẹ-ède ti o lọrọ jù lọ ni gbogbo ayé. Bayii ni Ọlọrun bukun Sọlomọni.

Gbogbo awọn eniyan naa ni o jẹ igbadun ibukun naa, pẹlu. Kò si ogun, nitori naa gbogbo awọn ọdọmọkunrin ni anfaani lati wà ni ile pẹlu awọn ẹbi wọn. Wọn ni oko ti wọn ti o mu eso pupọ wá, kò si si ẹni kan ti ebi n pa.

Sọlomọni tikara rè̩ ni ọrọ lọpọlọpọ. O ni ọkẹ meji (40,000) ẹṣin, ati ile-ẹṣin fun gbogbo wọn. Awọn iranṣẹ ati ọmọ-ogun ti n gbé ni aafin pọ to bẹẹ ti ounjẹ oojọ kọọkan fi jé̩ ọgbọn malu, ati ọgọrun agutan ati ọpọlọpọ ẹranko miiran ati ẹyẹ.

Ọgbọn

Kò si ẹni kan ti o ni ọgbọn tó Sọlomọni ni akoko rè̩. O kọ ọpọlọpọ iwe ki awọn ẹlomiran ba le jere nipasẹ ọgbọn rè̩. O kọ ẹgbẹẹdogun (3,000) owe, ọpọlọpọ ninu eyi ti o wà ninu Bibeli ninu Iwe Owe; o si kọ orin ẹgbẹrun o le marun un (1,005). O kọ iwe nipa ẹda pẹlu – nipa ẹja ninu okun, awọn kokoro, ati awọn ẹranko ninu igbo ati pápá; ati nipa awọn igi ati ajara. Gbogbo wọnyi jé̩ iṣẹ ọwọ Ọlọrun, Sọlomọni si fẹran lati ronu nipa awọn nnkan ti Ọlọrun dá.

Gbogbo ijọba aye ni o ran eniyan lọ sọdọ Sọlomọni lati kọ ninu ọgbọn rè̩ -- ọgbọn ti o ti ọdọ Ọlọrun wá. Daniẹli kọ akọsilẹ pe: “Awọn ọlọgbọn yio si ma tàn bi imọlẹ ofurufu” (Daniẹli 12:3). Ọgbọn ti Ọlọrun fun Sọlomọni tàn jade si gbogbo aye. Niwọn igba ti Sọlomọni tẹle Ọlọrun ti o si gbọran si aṣẹ Rè̩, ogo ati agbara rè̩ tubọ n tè̩ siwaju.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni ilẹ Israẹli ti tobi tó nigba ti Sọlomọni n ṣakoso?
  2. Ta ni Ọlọrun ṣeleri ilẹ naa fun tẹlẹ ri?
  3. Bawo ni Sọlomọni ti dagba tó nigba ti o bẹrẹ si jọba?
  4. Bawo ni oun ti rò pe awọn eniyan ti n gbe ilẹ Israẹli ti pọ tó?
  5. Bawo ni o ṣe ni ọgbọn ti o fi n ṣakoso wọn?
  6. Nibo ni Sọlomọni ti lá àlá iyanu ti o lá?
  7. Ki ni Sọlomọni beere nigba ti Ọlọrun ni ki o beere ohun ti o n fẹ ki Oun fi fun un?
  8. Ki ni Ọlọrun fun Sọlomọni?
  9. S̩e alaye ọgbọn Sọlomọni nipa awọn nnkan ti o ṣe.
  10. Iru ọgbọn wo ni o ṣe pataki jù lọ?