Orin Dafidi 100:1-5; 150:1-6; Heberu 10:23-25

Lesson 256 - Junior

Memory Verse
“OLUWA jọba; ki aiye ki o yọ; jẹ ki inu ọpọlọpọ erekuṣu ki o dùn” (Orin Dafidi 97:1).
Notes

Igbala ti O ni Ayọ Ninu

Ayọ ninu ọkàn jẹ apa kan iṣẹ ti igbala nla Ọlọrun maa n ṣe fun ni. Nigba ti eniyan ba mọ pe a dari è̩ṣẹ oun ji, alaafia kan maa n wà ni inu odo ọkàn rè̩; idunnu kan si maa n hàn ni oju rè̩ pẹlu itanṣan ẹwa Ọrun ti ohunkohun ninu aye yii kò le fun un. Lai ro tẹlẹ ni orin yoo kàn maa bú jade lati inu ọkàn ti o ni iru ayọ bayii.

Ọlọrun kò wa fun eniyan tabi orilẹ-ède kan pato. Onipsalmu kọrin pe, “Ẹ ho iho ayọ si OLUWA, ẹnyin ilẹ gbogbo.” Gbogbo agbaye ni ki o yọ ninu igbala ti Jesu n fun ni lọfẹ fun awọn ti wọn n fẹ igbala.

Peteru Apọsteli kọwe pe: “Nitõtọ mo woye pe, Ọlọrun kì iṣe ojusaju enia: ṣugbọn ni gbogbo orilẹ-ède, ẹniti o ba bè̩ru rè̩, ti o si nṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rè̩” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:34, 35).

“Ẹ ho iho ayọ si OLUWA.” Ẹ kọrin iyin si Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ. Ẹ gbé Kristi ti yoo ra awọn eniyan Rè̩ pada ga. Ẹ yin Ẹni ti yoo yọọda lati lọ kú fun ẹlẹṣè̩. Jesu kò ti i wá lati maa gbé ninu aye ni akoko naa, ṣugbọn nipa igbagbọ awọn woli ri I dajudaju bi ẹni pe ni tootọ O ti de ná.

“Ẹ fi ayọ sin OLUWA.” Igbala Oluwa Jesu Kristi ni o maa n fun ni ni ayọ naa. Oun a maa rù è̩ṣẹ wa ati aniyan wa ati ibanujẹ wa, Oun a si sọ ni di ominira. Oun a maa gba ẹrù wa rù, Oun a si fi wa silẹ pẹlu orin.

Ninu Ile-Isìn

“Ẹ wá ti ẹnyin ti orin si iwaju rè̩.” Nigba ti a bá wa si ile Ọlọrun lati jọsin, iwaju Rè̩ ni a wà. Oun a maa kiyesi ìwọntúnwọnsì wa nipa aṣọ wiwọ, bi a ṣe n huwa, ati ju gbogbo rè̩ lọ, ohun ti a n rò. Bi a ba wa siwaju rè̩ pẹlu iyin ninu ọkàn wa, kò ni ṣoro fun wa lati bá gbogbo ijọ eniyan iyoku kọ awọn orin ti o kún fun ogo Oluwa. Bi a ti n kọrin to bẹẹ ni ayọ wa yoo maa pọ si i.

O le maa dà a rò pe, n jẹ yoo ṣe e ṣe fun ọ lati le kọrin nigba ti ibanujẹ ba wà ninu ọkàn rẹ? Dajudaju iwọ le ṣe e bi o ba jẹ Onigbagbọ. Nigba ti okunkun bo ọ mọlẹ biribiri Jesu yoo fun ọ ni orin. Nigba ti o ba rò pe gbogbo eniyan kọ ọ silẹ Oun yoo kọrin ninu ọkàn rẹ.

Kọrin nigba ti ẹrù ba n bà ọ, è̩rù rẹ yoo si fo lọ. Kọrin nigba ti o ba ni iwuwo ọkàn, aniyan rẹ yoo si fuyẹ. Kọrin nipa Jesu ati ifẹ Rè̩. Kọ orin ifararubọ, ki o pinnu ọkàn ati ayé rẹ fun Un. Kọrin nipa ipadabọ Rè̩. Iru orin bẹẹ ti a kọ lati inu ọkàn wá jé adura ti Oluwa yoo gbọ ti yoo si dahun. Iwọ yoo mọ pe o ti ni idapọ pẹlu Rè̩, ati pe pẹkipẹki ni Oun wà ni tosi rẹ lati ran ọ lọwọ lati iṣisẹ rẹ kan de ekeji igbesi-aye rẹ.

Ọlọrun Ẹlẹda Kan S̩oṣo

“Ki ẹnyin ki o mọ pe OLUWA, on li Ọlọrun.” Kò si ẹlomiran. Ọlọrun kan ṣoṣo ni o wà, Oun ni O si da awọn ọrun, ati aye ati ohun gbogbo ti o wà ninu rè̩. Awa kọ lo da ara wa – a kò le ṣe e. Oun ni O da gbogbo wa. Iṣẹ ọwọ Rè̩ ni a jé̩, a si jẹ Ẹ ni igbese eemi kọọkan ti a n mí. Ọlọrun ti o dá ti O si n ṣe akoso gbogbo ohun ti o wà ni Oluṣọ-agutan wa. Awa ni agutan papa Rè̩, O si n fi ifẹ ṣe itọju wa. O n mu wa lọ sibi papa oko tutu. A jẹ ẹni pataki loju Rè̩. O fẹran wa bi ẹni kọọkan, O si ti ṣeleri pe Oun ki yoo fi wa silẹ tabi kọ wa silẹ lae.

Iwọ mọ bi ọdọ-agutan kekere ti jẹ alai le gba ara rè̩ silẹ nigba ti ikooko ba kì i mọlẹ kuro ninu agbo. O mọ bi o ti rọrun to fun agutan lati sọnu lai tun mọ ọna pada sinu agbo. Bi gbogbo wa ti jẹ alailera to niyii nigba ti a kò ba ni Oluwa. S̩ugbọn ti Oluṣọ-agutan tootọ ti O n ṣaniyan lori awọn agutan Rè̩ ni a jẹ. Oun mura tan lati rin ọna ti o ṣoro jù lọ ninu oru ti o ṣokunkun dudu ju lọ lati wa agutan ti o ti nù. Eyi kò ha to ohun ti a gbọdọ yin Ọlọrun fun, ki a si juba Ẹni ti a jẹ ti Rè̩? Leke eyi, Oluṣọ-agutan Rere ti fi ẹmi Rè̩ lelẹ nitori awọn agutan Rè̩. Eyi yẹ ki o mu ọkàn wa kún fun ẹmi imoore! Agutan Rè̩ ni wa! O kú ki awa ba le ye! O rù è̩ṣẹ wa ki awa ba le lọ lọfẹ!

Ohun ti o kere jù ti a le ṣe lati fi imoore wa hàn ni lati wa si ile Ọlọrun pẹlu ijọsìn tootọ ninu ọkàn wa. Bi a ti n ronu ifẹ nla Jesu fun wa, a ni iranwọ lati “Lọ si ẹnu ọna rè̩ ti awa ti ọpẹ, ati si agbala rè̩ ti awa ti iyìn.”

Ẹbọ Iyìn

Awọn Ọmọ Israẹli wá lati sìn Ọlọrun ninu Agọ pẹlu ọrẹ-ẹbọ ti a fi ọdọ-agutan, ewurẹ ati malu ṣe. Irubọ ẹran kò ṣanfaani fun wa. Iyìn lati inu ọkàn wá ni ẹbọ ti wa. Paulu Apọsteli kọwe bayii: “Ẹ jẹ ki a mā ru ẹbọ iyin si Ọlọrun nigbagbogbo, eyini ni eso ète wa, ti njẹwọ orukọ rè̩” (Heberu 13:15).

Orin kikọ wa kò gbọdọ jé̩ ni ile Ọlọrun nikan, ṣugbọn o yẹ ki iyin maa wa ninu ọkàn wa nigba gbogbo. Boya ohùn wa kò dara tó fun kikọrin -- ohùn ọrọ sisọ wa paapaa le má dara. Sibẹ a le hó iho ayọ si Oluwa. Nigba miiran è̩wè̩, a le má tilẹ pariwo, ṣugbọn iyìn yoo sa maa wà lọkàn wa. A le mí adura ọpẹ si Jesu.

Pipejọpọ lati Jọsin

Paulu Apọsteli mọ iru anfaani ti a le jẹ -- ẹni kin-in-ni fun ẹni keji – nipa biba ara wa sọ nipa ifẹ Ọlọrun. O dara fun wa lati jọ jumọ kọrin; o si maa n rú igbagbọ wa soke lati gbọ ohun ti Ọlọrun ti ṣe fun awọn ẹlomiran. Paulu kọwe pe ki a maa rú ara wa si ifẹ, “ki a má mā kọ ipejọpọ ara wa silẹ, gẹgẹ bi àṣa awọn ẹlomiran; ṣugbọn ki a mā gbà ara ẹni niyanju.” A maa n ni okun nipa pipade ati biba ara wa sọrọ nipa awọn nnkan ti Ọlọrun. Oluwa a si maa tẹti sii, inu Rè̩ a si maa dùn si iru ijiroro bayii.

Malaki Woli kọwe pe: “Nigbana li awọn ti o bè̩ru OLUWA mba ara wọn sọrọ nigbakugba; OLUWA si tẹti si i, o si gbọ, a si kọ iwe-iranti kan niwaju rè̩, fun awọn ti o bè̩ru OLUWA, ti wọṅ si nṣe aṣaro orukọ rè̩” (Malaki 3:16). Eyi ni pe o tilẹ maa n fa ibukun wa sinu ọkàn wa lati maa ṣe aṣaro orukọ Oluwa! Nipa awọn ti n ṣe aṣaro nipa Oluwa ti wọn si n sọ nipa iṣeun aanu Rè̩, Oluwa wi pe, “Nwọn o si jẹ temi ni ini kan, li OLUWA awọn ọmọ-ogun wi, li ọjọ na ti emi o dá” (Malaki 3:17). Ini kan, ọṣọ iyebiye fun Oluwa! Gbogbo awa ti a n yọ ninu Rè̩ ti a si n kọrin iyin Rè̩ lati inu ọkàn wa yoo jé̩ ti Rè̩ nigba ti O ba de lati mu awọn ti Rè̩ lọ.

Titi Lae

Oore ati aanu Ọlọrun wa titi laelae. Oun ko jẹ fi awọn ti Rè̩ silẹ. Bi o tilẹ jẹ pe nigba miiran a le ṣiyemeji, tabi ki a rò pe a dá nikan wà ki ẹrù si ba wa, oore ati aanu nì yoo wà sibẹsibẹ; nigba ti igbagbọ wa ba si tun sọji lati rii, awa yoo tun yọ lẹẹkan sii. “Otitọ rè̩ lati iran-diran.” Olukuluku eniyan ni igbakigba ni o ni anfaani ati sin Ọlọrun bi o ba fẹ.

Iyìn pẹlu Orin

Ni ọjọ miiran, Onipsalmu tun bẹrẹ si ronu nipa yiyin Oluwa. Ohun ti o fi bẹrẹ ni pe, “Ẹ fi iyìn fun OLUWA. Ẹ fi iyìn fun Ọlọrun ninu ibi mimọ rè̩.” Itumọ eyi ni pe, ni ile-isin Rè̩. S̩ugbọn n jẹ ile-isin kankan ha wà ti o le gba ogo Ọlọrun? Ninu ẹsẹ kan naa, Onipsalmu fi kun un pe, “Yin i ninu ofurufu oju-ọrun agbara rè̩.” Gbogbo aye kò le gba iyìn Ọlọrun. Gbogbo ọrun gbọdọ kún fun iyin Rè̩. Eniyan pupọ loni ni ki i yìn Oluwa, ṣugbọn ọjọ n bọ nigba ti iyìn Rè̩ yoo gba gbogbo aye kan. Ni ọjọ naa Oun yoo jọba awọn orilẹ-ède. Iru orin eyi ti Dafidi kọ ni a o maa gbọ: “Ẹnyin enia gbogbo, ẹ ṣapẹ; ẹ fi ohùn ayọ hó ihó iṣẹgun si Ọlọrun. Ẹ kọrin iyìn si Ọlọrun, ẹ kọrin iyìn: ẹ kọrin iyin si Ọba wa, ẹ kọrin iyìn. Nitori Ọlọrun li Ọba gbogbo aiye: ẹ fi oye kọrin iyìn” (Orin Dafidi 47:1, 6, 7).

Ogunlọgọ ẹgbẹ awọn akọrin ati alo-ohun -èlo orin ni o wà ni Tẹmpili Sọlomọni lati ṣe iranwọ lati kọ orin iyìn si Ọlọrun. Ọna gbogbo ti awọn akewi orin ti ẹmí mọ ni wọn fẹ fi gbe orukọ Oluwa ga, eyi ti o mu ki ọkan kọwe pe: “Fi ohùn ipè yìn i: fi ohun-èlo orin ati duru yìn i. Fi ilu ati ijó yìn i: fi ohun ọnà orin olokùn ati fère yìn i. Ẹ yin i lara aro olohùn òke.”

Kì i ṣe gbogbo ohun-èlo orin ti a darukọ ni a mọ, ṣugbọn ẹ jẹ ki a wo ẹgbẹ awọn alo-ohun-èlo orin iru eyi ti a mọ. Boya awọn gòje olohùn oke ti obinrin ni o kọkọ bẹrẹ orin iyìn kan si Ọlọrun, ti awọn gòje olohùn isalẹ ti obinrin si fi iro ti wọn kun un. Awọn gòje olohùn oke ti ọkunrin ati olohùn isalẹ ti ọkunrin yoo gbọ ìró ayọ naa; lai pẹ wọn a gbe orin naa wọn a si kọ orin ijọsin ti wọn. Ni isalẹ lọhun ni awọn gòje nla olohùn bè̩mbé̩ yoo dahun wi pe, “Amin.” Iro aladùn ti awọn ohun-èlo orin olokun wọnyi n kọ yoo ta awọn ohun-èlo orin onigi ti n fi afẹfẹ kọrin ji, awọn fere ati ipe yoo si pin ninu iyìn naa. Ohun wọn yoo dún gooro a o si gbọ wọn ni ọna jijin. Awọn ipe ti a n fi ọwọ fà siwaju sẹyin ati awọn ipe olohun bi aara ni yoo tun fẹ fi iyin ti wọn kun un. A le gbọ ohun duru bi odò ṣiṣan; nigba miiran ohùn rè̩ a bẹrẹ si i ga diẹdiẹ siwaju ati siwaju, nigba miiran è̩wè̩, ohùn rè̩ a rọra maa lọ silẹ diẹdiẹ, lati fi itumọ ọrọ orin naa hàn. Nigba ti iyin naa ba de ògógóró a le gbọ bi kimbali ti n gbá ara wọn. Bayii ni awọn ẹgbẹ alo-ohun-èlo orin yoo papọ gbe orin wọn de opin nigba ti wọn ba n fi ọla nla fun Ọlọrun ti O da wa, Ọba wa, Ẹni ti aanu Rè̩ wà titi.

Nigba ti gbogbo ohun-èlo orin ati gbogbo ẹgbẹ akọrin ba n yìn Oluwa, ki ohun gbogbo ti o ni ẹmi ki o yin Oluwa pẹlu. Ẹ fi iyìn fun ỌLUWA!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni maa n mu ki inu eniyan dùn ni tootọ?
  2. Ta ni yẹ lati kọrin iyin si Ọlọrun?
  3. Nibo ni ki a ti yin In logo?
  4. Bawo ni a ṣe le fi iyìn fun Un?
  5. Nitori ki ni a ṣe ni lati yìn In?
  6. Ki ni ẹbọ wa si Ọlọrun?
  7. Ni akoko wo ni o yẹ ki a yìn In?