I Awọn Ọba 5:1-18; 6:1-38

Lesson 257 - Junior

Memory Verse
“Bikoṣepe OLUWA ba kọ ile na, awọn ti n kọ ọ nṣiṣẹ lasan: bikoṣepe OLUWA ba pa ilu mọ, oluṣọ ji lasan” (Orin Dafidi 127:1).
Notes

Eto Ọlọrun

Bi Oluwa ba paṣẹ pe ki a ṣe iṣẹ kan, yoo fun wa ni ọgbọn ti a o fi mu aṣẹ naa ṣẹ pẹlu. Nigba ti Ọlọrun sọ fun Noa pe ki o kan ọkọ kan, O fi eto fun kikan ọkọ nla yii fun un pẹlu. Nigba ti Ọlọrun paṣẹ fun Mose pe ki o kọ Agọ kan ni aginju, O fi gbogbo eto lelẹ lẹsẹẹsẹ fun eyi naa pẹlu. Nisisiyi ti a o kọ Tẹmpili kan ni Jerusalẹmu, Ọlọrun kan naa fi apẹẹrẹ rè̩ fun Dafidi, ẹni ti o wi pe, “Gbogbo eyi wà ninu iwe lati ọwọ OLUWA ẹniti o kọ mi niti gbogbo iṣẹ apẹrẹ wọnyi” (I Kronika 28:19).

Awọn Ọjọ Ikẹyin Dafidi

Ni ọjọ kan Dafidi sọ fun Sọlomọni ọmọ rè̩ pe, “O ti wà li ọkàn mi lati kọle kan fun orukọ OLUWA Ọlọrun mi” (I Kronika 22:7). Lẹyin eyi o sọ nipa wura, fadaka, idẹ, irin, igi ati okuta ti o ti pese silẹ. O si wi pe, “Iwọ si le wá kún u.” Gẹgẹ bi baba ti o bè̩ru Ọlọrun, o wi pe, “Nitorina dide ki o si ma ṣiṣẹ, ki OLUWA ki o si pẹlu rẹ” (I Kronika 22:14, 16).

Dafidi mọ pe iṣẹ naa kì i ṣe iṣẹ kekere. O beere lọwọ awọn eniyan naa pe, “Tani si nfẹ loni lati yà ara rè̩ si mimọ fun OLUWA?” Dajudaju awọn ọjọ ikẹyin Dafidi ni o dara jù lọ. Wò o bi ayọ rè̩ yoo ti pọ to “nitori pẹlu ọkàn pipe ni nwọn fi tinutinu ṣe iranlọwọ fun OLUWA: pẹlupẹlu Dafidi ọba si yọ gidigidi” (I Kronika 29:5, 9). Ẹ jẹ ki a tẹti si awọn ọrọ diẹ lati inu adura Dafidi ṣaaju akoko ikú rè̩: “Tirẹ OLUWA ni titobi, ati agbara, ati ogo, ati iṣẹgun, ati ọlá-nla: . . . ijọba ni tirẹ, OLUWA, . . . gbogbo ohun ọpọlọpọ yi ti awa ti pèse silẹ lati kọ ile fun ọ fun orukọ rẹ mimọ, lati ọwọ rẹ wá ni, ati gbogbo rè̩ jẹ tirẹ” (I Kronika 29:11, 16). Eyi kò ha ran ọ leti adura ti Olugbala wa kọ wa pe ki a maa gbà?

Ni idahun si adura Dafidi pe ki Oluwa fun Sọlomọni ni ọkàn pipe, “lati pa ofin rẹ mọ . . . ati lati kọ āfin, fun eyi ti mo ti pèse silẹ” (I Kronika 29:19) ati ni idahun si ibeere Sọlomọni lọdọ Oluwa, Ọlọrun fun Sọlomọni ni ọgbọn, imọ, ọrọ ati ọlá.

Akoko ati Ibì kan

Lẹyin ikú Dafidi, ni ọdun kẹrin ijọba Sọlomọni, ni oṣu keji ni o bẹrẹ si i kọ Ile Oluwa ni Jerusalẹmu lori Oke Moriah.

Bi o ba ṣe pe a wà ni ayé ni ọjọ wọnni ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin, ki a si duro lori ọkan ninu awọn oke mẹrin lori eyi ti a tè̩ Jerusalẹmu dò si, ki a si wo apa ila-oorun, awa i ba ri gẹgẹ bi Odo Jọrdani ti wọ kọrọkọrọ bi a ba wo o lati okeere rere ati Okú Okun ti àwọ rè̩ dabi eeru. Bi a ba wo iha gusu, awa i ba ri ilẹ oloke Judea ati Bẹtlẹhẹmu; bi a ba si wo iha iwọ-oorun a le ri ikuuku kan ni oju sanma ni okeere ti o sami àgbègbè Okun Nla. Gẹrẹ ni isalẹ ni afonifoji ti Odo Kidroni là kọja lọ, eyi ti Olugbala wa rekọja rè̩ ni alẹ ọjọ ti a fi I hàn ninu Ọgbà.

Awọn Oniṣẹ-ọnà ti o Yọọda Ara Wọn

N jẹ ki a yipada si itan atijọ ki a si ṣe afiyesi kikọ Tẹmpili Sọlomọni? Kò si wahala nipa iṣẹ ṣiṣe -- iṣẹ kan fun ẹni kọọkan ati ẹni kọọkan fun iṣẹ ti rè̩. Gẹgẹ bi Dafidi ti sọ, “Iwọ ni pẹlu rẹ oniruru enia, ọlọkàn fifẹ, ẹniti o ni oye gbogbo iṣẹ fun oniruru iṣẹ . . .” (I Kronika 28:21). Wọn wa okuta nlá nla lati inu okuta ẹfun wá, wọn si fi ohun ti a fi n tọju ara okuta ṣe e, wọn si gé e si iwọn ki wọn to gbe e wa si ibi ti wọn ti n kọ Tẹmpili. Wọn ti ri awọn okuta miiran nibi ìkọlé Tẹmpili naa ti o gùn to ogoji ẹsẹ ti o si nipọn to ẹsẹ bata marun un ati abọ ti o si wuwo ju ọgọrun iwọn (100 tọns) lọ. Wọn ṣe ori-oke naa ki o fẹ lọpọlọpọ ki o ba le gba Tẹmpili naa ati awọn agbala ti o wa ni ayika rè̩, nipa gbigbe okuta wọnyi si ẹgbẹ oke wọnyi yika ati fifi opo ile ti o tobi lọpọlọpọ gbe wọn ró. Bẹẹ ni wọn té̩ wọn ni atẹgun atẹgun pẹlu iho abẹlẹ ti o tobi lọpọlọpọ nisalẹ ilẹ. A kà a pe Sọlomọni ni ọkẹ meji (40,000) ẹṣin. Awọn oluwadi ti hú awọn afọkù ile-ẹṣin ati ibi ti a n fi kẹkẹ-ẹṣin si jade lati inu ilẹ. Ilẹkun awé̩ meji ni o jẹ ẹnu-ọna abawọle lati ọna opópó ilu wá si awọn ibuso ẹṣin, eyi ti a fi okuta yangiyangi ṣe ilẹ rè̩ ki awọn ẹṣin má ba le yọ ṣubu. Awọn eniyan si ti ri iho ibuso ẹṣin, ati awọn opó fun ijánu ẹṣin ati ibujẹ ẹran ti a fi okuta ṣe.

Igi Kedari ti Lẹbanọni

Awọn agegi lọ si igbó Lẹbanọni. Nibẹ ni wọn ge igi Kedari ti o tobi lọpọlọpọ, iru igi ti o niye lori lọpọlọpọ ti a le fi ṣe iṣẹ-ọnà alarabara ti o dara pupọ. Kò si è̩rọ lati lò, nitori naa ọwọ ni wọn fi ṣe iṣẹ yii, nitori idi iṣẹ naa gba ọpọlọpọ eniyan lati ṣe e. O daju pe ayọ nla ni yoo kún inu ọkàn awọn agegi naa bi ẹgbaa marun un (10,000) aake ti n lọ soke ti o n lọ sodo; ẹgbaa marun un ọkunrin ti ọkàn wọn n ṣiṣẹ bi ẹni kan ṣoṣo, pẹlu ilepa kan ṣoṣo – lati kọ ile Oluwa. Bi igi kedari nla kan ba ti ṣubu lulẹ gbogbo wọn a kigbe pe “Gẹdu!” – igi miiran fun ile Oluwa. Lẹyin ti wọn ṣe iṣẹ aṣekara fun oṣu kan wọn pada sile fun oṣu meji, awọn ẹgbaa marun un ọkunrin miiran si tun lọ gba ipo wọn. Lọna bayii ọkẹ mẹrin (80,000) oṣiṣẹ ati ọọdunrun le ni ẹgbẹdogun (3,300) awọn alabojuto iṣẹ ni o wà nidi ẹka iṣẹ yii. Lẹyin naa ninu awọn ọkẹ mẹta aabọ (70,000) awọn arẹrù rù awọn igi kedari naa lọ si ebute Okun Mẹditerranean. Asopọ igi nla lefo, wọn si n wọ lọ loju okun si Jopa, lati ibi ti a o ti mu igi kedari wọnyi la ilẹ kọja si Jerusalẹmu. Nibẹ, lai si aaké, oolu, tabi ohun-èlo iṣẹ kan, a fi olukuluku si ipo ti rè̩ (I Awọn Ọba 6:7). Ọpọlọpọ igi firi ni wọn n fẹ pẹlu, nitori pe igi firi ni wọn fi tẹ ilẹ ile naa.

Awọn oṣiṣẹ Sọlomọni lori òkun ti mu wura wa lati Ofiri ni ọna jijin réré, eyi ti yoo gba ọkọ-oju-omi igba naa ni irin ọdun mẹta, nitori pe àbùjá Ọna Suez kò i ti si nigba naa.

Ibi Mimọ

Tẹmpili tikara rè̩ jé̩ adọrun (90) ẹsẹ bata ni gigun, ọgbọn (30) ẹsẹ bata ni fifẹ ati ọgbọn (30) ẹsẹ bata ni giga, gbogbo rè̩ ni a si fi wura bò. A fi aṣọ iboju alaro, ati elese-aluko ati ododo ati ọgbọ ya Ibi Mimọ Julọ sọtọ si Ibi Mimọ (II Kronika 3:14). Ibi Mimọ Julọ jé̩ ọgbọọgba ni gigun, ibu ati giga, ọgbọọgbọn ẹsẹ bata niha gbogbo. Ninu yara yii ni awọn kerubu meji wà ti a fi igi olifi ṣe, ti a si fi wura bò, ọkọọkan jẹ ẹsẹ bata mẹẹdogun ni giga, ati ṣonṣo iyẹ apa kan si iyẹ apa ekeji ọkọọkan kerubu si jẹ ẹsẹ bata mẹẹdogun. Njẹ o le fi oju-inu wo agbayanu ẹwa ibi yii, iyẹ awọn mejeeji kan ara wọn, iyẹ ekinni nihin ati ekeji lọhun si kan ogiri, oju wọn si n wò ibi ti a o gbé Apoti nì si? A ṣe iṣẹ-ọnà awọn kerubu, igi ọpẹ, ati itànná, ti a fi wura bò si ara ogiri. Wura alailabula ni a fi bo ilẹ paapaa, gẹgẹ bi a ti ṣe pẹpẹ kedari, ni Ibi Mimọ. Dafidi ti pese wura alailabula fun Tẹmpili naa; n jẹ ohun ti o wu ni lori ha kọ ni lati mọ pe wura daradara, eyi ti i ṣe apẹẹrẹ isọdimimọ, ni o pese silẹ fun pẹpẹ turari? (I Kronika 28:18).

Gẹgẹ bi Ilana

Sọlomọni kọ agbala ti pẹpẹ idẹ wà ninu rè̩ eyi ti i ṣe apẹẹrẹ igbala. A ṣe ohun gbogbo gẹgẹ bi eto Ọlọrun, o si dabi Agọ ti aginju. Owo ti a ná le Tẹmpili pọ lọpọlọpọ jù ti Agọ o si tobi to ilọpo meji Agọ. A ti wadii iye owo rè̩ pé ẹgbẹẹgbè̩rún ọna ẹgbẹrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun ọkẹ pọun – 700,000,000,000 si 1,700,000,000,000 – (N1,400,000,000,000 si N3,400,000,000,000).

Awọn araba opo nla meji ni o duro niwaju ode Tẹmpili, pẹlu è̩wọn ni oke wọn ti a fi so pomegranate idẹ ọgọrun (100) rọ. Ẹ jẹ ki a ronu fun igba diẹ nipa iloro ti o wà niwaju Tẹmpili naa. Ọgbọn ẹsẹ bata ni ni gigun o si ga soke to ọgọsan (180) ẹsẹ bata, a si fi wura alailabula bo inu rè̩. Rò o wo ki ile aago ile-isin kan ga to pẹtẹsi mẹẹdogun soke – ki a si fi wura bo gbogbo inu rè̩!

Tẹmpili yii kì i ṣe ile kan bi awọn ile-isin wa isisiyi ti awọn eniyan n pejọ sinu rè̩, ṣugbọn a gbe e kalẹ fun ṣiṣe eto ilana isin; awọn ti o wa jọsin yoo si wà ni ode. (Wo Ẹkọ 70, Iwe Kẹfa fun eto isin). Ọdun meje ati aabọ ni a fi pari Tẹmpili tikara rè̩ ṣugbọn o gba ọdun mẹtala sii lati pari ile Sọlomọni, awọn ọdẹdẹ oke ti o lẹwa lọpọlọpọ, awọn agbala, awọn iloro, ati awọn gbọngàn. Bi a ba wà ni aye ni ọjọ Sọlomọni, gẹgẹ bi Ọbabinrin S̩eba, ki a ri Ile Oluwa naa nikan ni a le mọ ẹwa Tẹmpili yii, titobi awọn okuta nì, ọpọlọpọ iṣẹ-ọnà gbigbé̩ ati awọn ọṣọ wura.

Jerusalẹmu Laelae ati Titun

Kì i ṣe ni Palẹstini nikan, ṣugbọn jakejado ayé igba naa ni Tẹmpili Jerusalẹmu ti jẹ ibi pataki jù lọ fun ijọsin awọn Ju; gbogbo sinagọgu ni o kọju si Tẹmpili. Ni ọpọlọpọ ọdun lẹyin naa, nigba ti Daniẹli wà ni oko-ẹrú, o ṣi ferese rè̩ si iha Jerusalẹmu o si gbadura, bi o tilẹ jẹ pe a ti wo Tẹmpili naa palẹ tuutu ni akoko naa.

Loni, ferese ọkàn rẹ ha ṣi si iha Jerusalẹmu bi? Kì i ṣe si iha ilu ti a ti parun ti a si ti tun kọ lẹẹmẹta, ṣugbọn si iha Jerusalẹmu ti Ọrun? Iwọ ha n reti, gẹgẹ bi Abrahamu ni igba nì, “ilu ti o ni ipilè̩; eyiti Ọlọrun tè̩do ti o si kọ” (Heberu 11:10)? O ha n foju sọna lati ri Ilu wura didan nì eyi ti Johannu ri, “Ilu mimọ nì, Jerusalẹmu titun nti Ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá” (Ifihan 21:2)? Bi o ba ri bẹẹ, o ni lati mura silẹ fun ibẹ. Bi o ba ni ireti lati jé̩ apa kan ti o ṣe deedee lara Tẹmpili daradara nì loke, a ni lati tun ọ ṣe si titọ, ki a fi ohun-èlo tun ọ ṣe ki a ba le fi ọ si ara ile nì lai si iro oolù. Bawo ni a ṣe n gba titunṣe, gígé ati titunda naa? “Ọrọ mi kò ha dabi iná? li OLUWA wi; ati bi òlu irin ti nfọ apata tútu?” (Jeremiah 23:29). Ọrọ Ọlọrun le jó gbogbo ohun ti kò tọ kuro ninu ọkàn; òlu rè̩ si le gé diẹ kuro nihin diẹ kuro lọhun, bi eniyan ba le jọwọ ara rè̩ fun un.

Ile Wa

Ọrọ apẹẹrẹ kan ti a ri ninu Bibeli n fi han pe iwọ ati emi n kọ ile kan. Kò ṣẹṣẹ tọ pe ki a lọ si igbó Lẹbanọni fun kedari, tabi ibi didá okuta fun okuta, pẹtẹlẹ Jọrdani fun idẹ, tabi lilọ si Ofiri fun wura. Dipo eyi, a o walẹ jin ninu Ọrọ Ọlọrun. Nibẹ ni a ti ri awọn ohun-elo fun ikọle wa, Ọlọrun yoo si fun wa ni ohun ti a n fẹ ni ibi pẹpẹ adura.

Iṣisẹ kin-in-ni ninu kikọ Tẹmpili wa ni lati tọ Jesu Kristi lọ, Ẹni ti i ṣe Ipilẹ: “S̩ugbọn ki olukuluku kiyesara bi o ti nmọ le e. Nitori ipilẹ miran ni ẹnikan kò le fi lelẹ jù eyiti a ti fi lelẹ lọ, ti iṣe Jesu Kristi” (I Kọrinti 3:10, 11). Nipasẹ Ọrọ Rè̩ a mọ pe awọn ti o ṣe pataki jù lọ lara Tẹmpili naa ni iriri mẹta ti Idalare, Isọdimimọ ati fifi Ẹmi Mimọ wọ ni. Awọn nnkan ti o ṣe apẹẹrẹ awọn iriri wọnyi ninu Tẹmpili Sọlomọni ni pẹpẹ idẹ ti o wa ni agbala ita, pẹpẹ wura ni Ibi Mimọ, ati Ibi Mimọ Julọ lẹyin aṣọ ikele tabi ìbòjú.

Nigba ti a ba ri awọn iriri wọnyi gba, ẹ jẹ ki a ṣọra gidigidi lati yan awọn ohun-èlo ti o dara jù lọ fun ọṣọ ti inu. Gẹgẹ bi Sọlomọni ti wá wura daradara fun Tẹmpili Jerusalẹmu, a ni lati fi awọn ohun-èlo ti o dara ju lọ sinu ile wa. A n fẹ ọpọlọpọ adura ati ifi-ara-rubọ fun ile naa, ati igbọran ati ifẹ, ki o dapọ mọ igbagbọ. A kẹkọọ pe idanwo igbagbọ niye lori ju wura lọ (I Peteru 1:7), a o si fi ọṣọ wọnyi sinu Tẹmpili wa “ọṣọ aidibajẹ ti ẹmi irẹlẹ ati ẹmi tutu.” Itẹsiwaju kan sii ni ọgbọn, ti a pe ní “ohun ọṣọ daradara” (Owe 4:9).

Ẹ jẹ ki a maa tun ọkàn wa ṣe, ki a maa mu un dán ki a si fi awọn ohun-elo ti a kò le parun ṣe e lọṣọ. Nigba naa bi ina ba dé ti yoo dan iṣẹ olukuluku wò iru eyi ti i ṣe, “ile” wa yoo si duro, kì i ṣe bi ti Tẹmpili Jerusalẹmu ti a wó lulẹ lẹẹmẹta, a o si gba ere ti o pọ (I Kọrinti 3:13, 14).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Dafidi kò fi le kọ Ile Oluwa?
  2. N jẹ Ọba Hiramu sowọ pọ pẹlu Sọlomọni?
  3. Bawo ni Sọlomọni ọba ṣe sanwo fun awọn eniyan Hiramu?
  4. Awọn gbẹnagbẹna melo ni ọba ni lori oke?
  5. Ọdun melo ni Sọlomọni ti n jọba ki o to bẹrẹ si i kọ Tẹmpili?
  6. Bawo ni Tẹmpili ti tobi tó?
  7. S̩e apejuwe Ibi Mimọ Julọ, ibi ti a gbé Apoti Majẹmu si.
  8. N jẹ o rò pe Sọlomọni lo ohun-èlo ti kò ni laari?
  9. Ki ni ohun ti a le ri kọ ninu eyi?
  10. Bawo ni Sọlomọni ti pẹ to nidi kikọ Tẹmpili yii?