Lesson 258 - Junior
Memory Verse
“Emi o ma gbadura siha tẹmpili mimọ rẹ, emi o si ma yin orukọ rẹ nitori iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ; nitori iwọ gbé ọrọ rẹ ga jù gbogbo orukọ rẹ lọ” (Orin Dafidi 138:2).Notes
Oke Moriah
Bi o ba ṣe pe a le rin irin-ajo lọ si ilẹ Palẹstini loni, ki a si bẹ ilu Jerusalẹmu wò, ara ibi ti yoo wù wá lati de ni Ibi-Ọwọ Ọlọla, ni aarin eyi ti Ibi-Abo Apata wà. S̩ugbọn, fun Onigbagbọ, kì i ṣe ile ti a kọ sibẹ bi kò ṣe ilẹ ti a kọ ile naa le ni o jẹ ohun ọwọ, nitori pe lori ilẹ ọwọ yii ni iṣẹlẹ nla mẹta ti ṣẹlẹ.
Oke Moriah ni orukọ ilẹ naa. Bi a ti n ṣe aṣaro nipa oke yii o yẹ ki ọkàn wa lọ sọdọ Abrahamu olóòótọ. Ta ni kò i ti fi oju inu ri Abrahamu bi o ti jẹ pe ni ijọ kẹta ti o ti n rin lọ si ori oke yii, o “gbé oju rè̩ soke, o ri ibè̩ na li okere.” Taara niwaju rè̩ ni oke ti yoo ti fi ọmọ rè̩ rubọ gbe wà. Ta ni ti ka itan naa ninu Gẹnẹsisi 22 lai fi ọkàn maa ba eniyan Ọlọrun yii, ati Isaaki ọmọ rè̩, pada sọkalẹ oke naa lọ si ibi ti wọn ti fi awọn iranṣẹ wọn silẹ. Abrahamu yeje ninu idanwo ti o ba pade lori oke Oluwa naa. Nipa iṣẹlẹ yii a ri apẹẹrẹ igbala. (Tun ka Ẹkọ 11 ninu Iwe Kin-in-ni). Ibi ti a gbe fi Ọmọ Ọlọrun, Jesu Kristi, rubọ lati kó è̩ṣẹ araye lọ kò jinna sibẹ.
Ohun keji ti o ṣẹlẹ lori Oke Moriah ṣẹlẹ ni igba aye Dafidi. Lẹyin ti Dafidi ti kà awọn eniyan, gẹgẹ bi ijiya, ajakalẹ-arun buburu pa ẹgbaa-marun-din-logoji (70,000) eniyan run, Ọlọrun sọ pé ki Dafidi tẹ pẹpẹ kan nibi ilẹ ipaka Ornani lori Oke Moriah. Nigba ti Dafidi bi Ornani (ẹni ti a tun n pe ni Arauna) (II Samuẹli 24:21) boya oun le ra ilẹ ipaka naa, Ornani wi pe oun o fi i fun Dafidi, pẹlu malu ati igi. O wi pe “Mo fi gbogbo rè̩ fun ọ” (I Kronika 21:23). S̩ugbọn Dafidi wi pe oun o ra a ni iye owo rè̩ pipe nitori pe oun kì yoo ru ẹbọ-ọrẹ sisun si Oluwa lai ṣe inawo. Ẹbọ ikeji yii ti a ru lori Oke Moriah jẹ apẹẹrẹ isọdimimọ. (Ka Ẹkọ 247).
Iṣẹlẹ pataki kẹta ti o ṣẹlẹ lori oke Oluwa naa ni yiya Tẹmpili Sọlomọni si mimọ.
Wọn S̩etan lati Bẹrẹ Isin
Ẹ jẹ ki a fi oju inu wo agbegbe ti nnkan yii ti ṣẹlẹ. Ohun gbogbo ti ṣetan. Awọn ọpa fitila mẹwaa ti ọkọọkan wọn ni fitila meje, tabili lori eyi ti akara-ifihan wà, awọn ohun-èlo idẹ, awọn awo wura, awọn alumọgaji, awọn awo kòtò, awọn ife ati awọn ṣibi; gbogbo wọn ni wọn wà ni àyèe wọn. Awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi ni wọn kó awọn ohun-èlo mimọ naa wá lati inu Agọ. Sọlomọni ti mu awọn ohun-èlo ti fadaka ati ti wura ti Dafidi baba rè̩ ti ya si mimọ, o si kó wọn mọ awọn ohun iṣura.
Ọba ti papejọ awọn agba Israẹli ati gbogbo awọn olori awọn è̩ya, ati awọn olori awọn baba awọn Ọmọ Israẹli, ki wọn ki o le gbé Apoti-ẹri Majẹmu wá sinu Tẹmpili. Awọn ọmọ Lefi ti gba Apoti-ẹri naa wọn si ti gbe e wá sinu Tẹmpili titun nibi ti awọn alufa ti gbe e wọ Ibi Mimọ Julọ wọn si ti gbe e kalẹ labẹ iyẹ awọn kerubu. Ni akoko yii kò si nnkankan ninu Apoti-ẹri naa bi kò ṣe awọn wala okuta meji wọnnì.
Isin Bẹrẹ
Sọlomọni Ọba ati gbogbo awọn eniyan n fi agutan ati malu ti o pọ jù eyi ti eniyan le ka rubọ si Ọlọrun -- wọn n fi tọkantọkan rubọ si Ọlọrun wa titobi. Bi a ba duro lode lẹba Tẹmpili, a le ri awọn alufa bi wọn ti n jade lati Ibi Mimọ. Gbogbo awọn ọkunrin wọnyi ni a yà si mimọ ti a si wọ ni aṣọ ọgbọ funfun. Ni apa ila-oorun pẹpẹ naa ni a ti ri awọn akọrin ati awọn alo-ohun-èlo orin ti a wọ ni aṣọ ọgbọ funfun bakan naa. Pẹlu ìró kan awọn ogọfa (120) alufa naa fun ipè wọn ni akoko kan naa ti awọn harpu, kimbali ati duru dun. Orin ti ẹgbẹ akọrin nla naa n kọ ni pe “O ṣeun; ānu rè̩ si duro lailai.” Nnkan kan ṣẹlẹ! N ṣe ni ogo Oluwa kun Tẹmpili naa bi awọsanma, to bẹẹ ti awọn alufa kò fi le duro lati ṣiṣẹ isin wọn mọ.
Nigba ti gbogbo awọn ohun-èlo orin ti a n lo ninu ile-isin ba n dún bi ẹni pe ohun-èlo orin kan ṣoṣo ni o wà nibẹ, a maa n gbadun rè̩, bẹẹ gẹgẹ ni a maa n gbadun orin awọn akọrin ti ohùn wọn ṣupọ gẹgẹ bi ohun eniyan kan. S̩ugbọn kiki igba ti gbogbo ọkàn ati àyà ba jẹ ọkan, ti iṣọkan si wà ninu ijọ iru eyi ti isọdimimọ maa n fun ni, kiki igba naa ni o maa n ṣe e ṣe fun ogo Oluwa lati kún inu ile. Nigba naa nikan ṣoṣo ni o maa n ṣe e ṣe fun “awọsanma” lati kún inu ile. Bawo ni iru ijọsin bẹẹ ti maa n wú ni lori to loni!
Adura Ọba
Nisisiyi a ri Sọlomọni Ọba o duro lori pẹpẹ kekere kan ti giga rè̩ to nnkan bi ẹsẹ mẹrin aabọ. O bá awọn eniyan sọrọ. O wá kunlẹ, o si té̩ ọwọ rè̩ si Ọrun o si n gbadura. Bi iṣẹ-ọnà ti pọ to ni Tẹmpili naa ti awọn agbala rè̩ si tobi pupọ nì, sibẹ Sọlomọni mọ pe a kò le há Ọlọrun mọ ile kan. Lati ẹnu ẹni ti o ṣe amoye jù lọ naa ni a si ti gbọ ọrọ ti o mu ni lọkan wọnyi. “Kiyesi i, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọsi ile yi ti emi kọ!” (II Kronika 6:18). Sibẹ o gbadura pe ki oju Ọlọrun ki o maa ṣi si Ile yii lọsan ati loru.
Ina lati Ọrun
Nigba ti adura naa pari, jinnijinni ti mu ni lọkàn to lati rii pe iná ti Ọrun sọkalẹ wa o si jo ọrẹ sisun ati ẹbọ naa run, ati pe ogo Oluwa si kún ile naa! Buruburu ni gbogbo awọn eniyan doju wọn bo ilẹ ti a fi okuta té̩ naa, wọn si tẹriba, wọn si yin Oluwa. Lẹẹkan sii orin dun jade lati inu awọn ohun-èlo orin ti Dafidi ti ṣe fun idi eyi gan an; awọn alufa pẹlu si fun ipe nigba ti awọn eniyan naa dide duro.
Ibẹwo Miiran lati Ọdọ Oluwa
Ni oru kan lẹyin ti a ti pari yiya Tẹmpili naa si mimọ ti Sọlomọni si ti rán awọn eniyan pada lọ si agọ wọn, Oluwa tun fi ara han an, O si wi fun un pe adura rè̩ ti jẹ itẹwọgbà. Ayọ Sọlomọni kò ni ṣai kún nigba ti o gbọ ti ohùn Ọlọrun wi pe: “Njẹ nisisiyi emi ti yàn, emi si ti yà ile yi si mimọ, ki orukọ mi ki o le ma wà nibẹ lailai: ati oju mi ati ọkàn mi yio ma wà nibẹ nigbagbogbo” (II Kronika 7:16).
Eto Ọlọrun
Iṣẹlẹ akoko ti a yà Tẹmpili yii si mimọ fi ara jọ ti Ọjọ Pẹntikọsti; ṣugbọn ṣa a kò fi Ẹmi Mimọ baptisi awọn ti o wà ni igba ti Sọlomọni, nitori pe a kò i ti ran Ẹmi Mimọ wá si aye ni akoko naa. Iṣẹlẹ yii ninu Majẹmu Laelae kọ ni pe a fi awọn nnkan ribiribi pamọ de awa ti Igba Ifiwọni Ẹmi Mimọ yii. Ọlọrun ṣe ilana naa ninu Majẹmu Laelae O si mu un ṣẹ ninu Majẹmu Titun.
Akorọ Ojo
O ju nnkan bi ẹgbẹrun ọdun lọ lẹyin ti a ti yà Tẹmpili naa si mimọ, ni ọjọ iyanu kan ti ọgọfa (120) eniyan pejọ pọ si Jerusalẹmu. Agbegbe ibẹ kò fi bẹẹ lọla rara bi agbegbe ibi ti a kọ Tẹmpili si. Boya a kò fi aṣọ ọgbọ funfun wọ awọn eniyan naa gẹgẹ bi a ti fi wọ awọn alufa Tẹmpili naa, ṣugbọn wọn wọ aṣọ ododo ti iwa-mimọ, nitori gbogbo wọn jẹ mimọ, wọn si wa ni ọkàn kan. Awọn Apọsteli mọkanla ati iya Jesu pẹlu awọn arakunrin Rè̩ wà nibẹ. Kò pẹ ṣaaju akoko yii ni a ti gba Jesu soke Ọrun ninu awọsanma; ṣugbọn O ti sọ fun awọn eniyan wọnyi pe, “A o fi Ẹmi Mimọ baptisi nyin, ki iṣe ọjọ pupọ lati oni lọ.” Nibẹ ni yàra oke ni awọn ọgọfa (120) eniyan yii duro de ileri Baba naa, ni igbọran si aṣẹ Jesu. A ha ja wọn tilẹ? Rara o! “Lojiji iró si ti ọrun wá, gẹgẹ bi iró ẹfufu lile, o si kún gbogbo ile . . . Gbogbo nwọn si kún fun Ẹmi Mimọ, nwọn si bè̩rẹ si ifi ède miran sọrọ, gẹgẹ bi Ẹmi ti fun wọn li ohùn” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:2-4). Itujade Ẹmi yii ni a n pè ni “Akọrọ Ojo.”
Arọkuro Ojo
O tun ṣe, ni nnkan bi ẹgbaa (2,000) ọdun lẹyin iṣẹlẹ iyàra oke nì, ni ilu Los Angeles, ti Kalifornia, a ri awọn ẹgbẹ kekere miiran ti wọn gbagbọ. Bakan naa, ọkàn wọn jẹ mimọ ati funfun, nitori pe wọn ti ri isọdimimọ. Kò si ẹgbẹ awọn alo-ohun-èlo orin, bẹẹ ni kò si si ohun-ọṣọ wura kankan ni ibi irẹlẹ naa.
Ni Ọjọ Kẹfa Oṣu April, 1906, gẹge bi Ọrọ Ọlọrun, a tun tú Ẹmi Mimọ olubukun yii jade bi o ti ri ni Ọjọ Pẹntekọsti. Eyi ni “Arọkuro Ojo Ẹmi” ti iṣe itujade Ẹmi, ogunlọgọ awọn eniyan ni o si ti ri Ẹbun kan naa gbà lati igba naa.
Ifi-ara-rubọ Ailoṣuwọn
O ha ti ni iriri yii ninu ọkàn rẹ? O ha ti beere ṣugbọn sibẹ o kò i ti ri idahun si adura rẹ? Yẹ “tẹmpili” rẹ wò. Rii pe o ti kọle sori Jesu Kristi, Apata ti o duro ṣinṣin. S̩e o ti rin irin-ajo akọkọ lọ sori Oke Moria, a ha si ti fi È̩jẹ ni wẹ ọkàn rẹ? Lẹyin naa ṣe o ti pada si Oke Oluwa naa lati ṣe irubọ ti o ná ọ ni ohun kan? S̩e ina ti sọkalẹ sori ẹbọ rẹ? A ha ti fun ọ ni aṣọ funfun nì, aṣọ ododo ati iwa-mimọ -- isọdimimọ? O ha ti kó awọn ohun-èlo wura ati fadaka wá sinu iṣura Oluwa? O maa n gba ni ni ifararubọ ti o jinlẹ ki a to le ri iriri yii gbà. S̩e o ti fi ọrẹ-sisun ati ẹbọ silẹ lai lonkà, gẹge bi Ọba Sọlomọni ti ṣe?
Nigba ti anfaani ba ṣi silẹ lati fi fun Ọlọrun o ha n fẹ lati yọọda tọkàntọkàn lati ṣe e fun Ọlọrun? O le jẹ iṣẹ kekere bi ninu awọn ijoko inu ile-isin, tabi inira diẹ nipa gbigba ọmọ Ọlọrun kan ti n rin irin-ajo la ilu rẹ kọja ni alejo sinu yará ti o n gbe. Boya Ọlọrun n fẹ ki o fi akoko silẹ sii fun gbigba adura ki o to sare lọ si ile-ẹkọ rẹ ni owurọ. Tabi, alejo ti o ṣẹṣẹ kó de adugbo rẹ n kọ -- o ha ti pe e lati wa bẹ Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi rẹ wo? Ki ni ṣe ti o kò fi wi pe: “Emi ki yio ru ẹbọ si Ọlọrun lai ṣe inawo. Mo fi gbogbo rè̩ silẹ. Ohun gbogbo ti Ọlọrun ba ni ki n ṣe ni n o ṣe.” Ti ifararubọ rẹ ba peye, duro de ifi wọni Ẹmi Mimọ, kọrin iyin Rè̩, “O ṣeun; ānu rè̩ si duro lailai,” titi ogo Oluwa yoo fi kun inu ile rẹ ti Olutunu yoo si wọle lati maa gbe ninu tẹmpili rẹ.
Questions
AWỌN IBEERE- S̩e alaye irin-ajo mẹtẹẹta si Oke Moria.
- Ki ni irin-ajo kọọkan duro fún?
- Awọn wo ni o ru Apoti-ẹri?
- Nibo ni a gbé Apoti-ẹri naa si ninu Tẹmpili?
- Awọn ohun-èlo orin wo ni a lo nibi iyasimimọ naa?
- Ọlọrun ha dahun adura Sọlomọni bi?
- Ki ni ṣẹlẹ nigba ti iro orin dún ti awọn eniyan si kọrin?
- Sọ nipa igba keji ti Oluwa fi ara han Sọlomọni ni oru.
- Sọ awọn nnkan ti awọn ọmọde ati awọn ọdọ le ṣe fun Jesu.
- Ki ni ijiyà ti Ọlọrun ni Oun yoo mu ba Israẹli bi wọn ba yi pada kuro lẹyin Oun?