I Awọn Ọba 10:1-29

Lesson 259 - Junior

Memory Verse
“Si kiyesi i, a kò sọ idaji wọn fun mi” (I Awọn Ọba 10:7).
Notes

Ọbabinrin Kan

Sọlomọni ni alejo kan. Alejo naa ni Ọbabinrin S̩eba, ẹni ti Jesu tọka si gẹgẹ bi “ọba-binrin gusù.” O wa lati “ikangun aiye wá igbọ ọgbọn Sọlomọni” (Matteu 12:42). Ohun ti o maa n ṣẹlẹ ni pe nigba ti alakoso orilẹ-ède kan ba lọ bẹ alakoso orilẹ-ède miiran wò, wọn a maa ṣe bẹẹ lati ṣe adehun tabi ibadọrẹ nipa majẹmu, lati yanju ọrọ nipa àala ilẹ wọn, lati ṣeto nipa iṣowo ati ìtajà, tabi lati ṣeto bi awọn eniyan orilẹ-ède mejeeji ṣe le ni oye ju bẹẹ lọ nipa ara wọn. Ọbabinrin S̩eba kò wá si ọdọ Sọlomọni nitori eyikeyi ninu awọn eredi ti a sọ yii. Kì i si ṣe pe o deedee n rin irin-ajo la ilẹ naa ja! O ni idi kan fun ibẹwo rè̩ -- lati fi oju ara rè̩ ri ohun ti a ti sọ fun un nipa Sọlomọni, lati gbọ nipa orukọ Oluwa, ki o si té̩ ara rè̩ lọrùn niti mimọ ti o fẹ mọ nipa ọrọ ati ọgbọn Sọlomọni.

Wiwa ọbabinrin yii dabi ẹlẹṣẹ ti o tọ Oluwa wá. Awọn igbesẹ kan wà ti o gbe ti o dabi awọn iṣisẹ ti ẹni ti o n wá Ọlọrun maa n gbe. Awọn iwa kan wà ninu rè̩ ti o dabi eyii ti o wà ninu igbesi-aye awọn ọkunrin, obinrin ati awọn ọmọde ti o gbà Ihinrere.

Gbigbọ Iroyin

Ọbabinrin yii ti gbọ iroyin nipa Sọlomọni ati ọgbọn rè̩. A kò sọ fun wa nipa ọna ti o gba fi gbọ, tabi ẹni ti o sọ fun un, tabi ibi ti o wà nigba ti o gbọ iroyin naa. Lọna kan ihin naa de eti ìgbọ rè̩. Iṣisẹ kin-in-ni niyii fun ẹlẹṣẹ paapaa. O ni lati gbọ nipa igbala ki a ba le gba ọkàn rè̩ là, ati wi pe Jesu kú fun è̩ṣẹ rè̩.

Gbogbo eniyan kọ ni o n gbọ nipa Ihinrere ni ọna kan naa. Awọn miiran maa n gbọ nipa igbala ni ipade iwaasu ode gbangba, a si n fun awọn ẹlomiran ni iwe Ihinrere nigba ti wọn ba wà ni idubulẹ aisan ni ile itọju awọn alaisan. Sibẹsibẹ n ṣe ni a pè awọn ẹlomiiran wá si ipade, tabi wọn gbọ ẹri aladugbo tabi ibatan ti o ti ri igbala. Ọlọrun a maa ṣiṣẹ lọna àrà lati mu ki awọn eniyan gbọ nipa igbala. A ti gbọ iroyin kan pe ẹni kan ri ajáku iwe itankalẹ Ihinrere ti Ijọ Igbagbọ Apọsteli ni oju ọna kan ti o jinna réré si ibi ti eniyan n gbe; o ka ajaku iwe naa o si gbọ iroyin nipa igbala. O gbagbọ o si wá Ọlọrun titi o fi ni idaniloju pe a ti gba oun là. Ọlọrun nikan ṣoṣo ni o mọ bi àjákú iwe Ihinrere naa ti ṣe dé ọna adádo yii.

Ọpọlọpọ ninu awọn ti n sin Ọlọrun nisisiyi gbọ iroyin nipa Ihinrere ni ọna ti o yatọ patapata -- ṣugbọn wọn gbọ! Oluwa jẹ olóòótọ si olukuluku eniyan. Jesu ni i ṣe “Imọlẹ otitọ …. ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye” (Johannu 1:9).

Lati fi Oju Ara Rè̩ Ri i

Lẹyin ti ọbabinrin yii ti gbọ iroyin, kò ni itẹlọrun titi o fi rin irin-ajo lati tọ Sọlomọni wá ki o ba le fi ibeere ṣe iwadi lẹnu rè̩. Boya ọpọlọpọ ohun ni o yi i ká ninu aafin daradara rè̩ bi ọpọlọpọ awọn ọrẹ ati awọn iranṣẹ, idaraya oriṣiriṣi, ounjẹ daradara, ati ọpọlọpọ aṣọ ti o niyelori; ṣugbọn kò ni itẹlọrun. Ọba ni, o si lọrọ, ṣugbọn o ni awọn iṣoro ti o nira.

Ẹnikẹni ti kò ba ti i mọ Ọlọrun kò ni itẹlọrun bẹẹ gẹgẹ. O le jẹ ẹni ti o wà ni ipo giga ninu aye, ki o si ni awọn ohun ini aye yii lọpọlọpọ, sibẹsibẹ o ni awọn iṣoro kò si ni itẹlọrun.

Gẹgẹ bi ọba, Ọbabinrin S̩eba yẹ ki o ni awọn ọjọgbọn eniyan ni ayika rè̩ ti oun le ran si Sọlomọni. Kò rán ẹlomiiran lati lọ ṣe iwadi lẹnu Sọlomọni. Ọbabinrin yii kò ni itẹlọrun titi o fi ri Sọlomọni ẹni nla nì tikara rè̩.

Pe ki ẹlomiiran lọ wo ẹwa Oluwa fun wa tabi lati mọ pe awọn ẹlomiran n ni iriri igbala kò to. Olukuluku eniyan ni o gbọdọ wá sọdọ Ọlọrun ki o si ni iriri igbala tikara rè̩. Nitori pe awọn obi eniyan ti ri igbala kò wi pe awọn ọmọ paapaa ti ri igbala. Awọn ọmọ ni lati gbadura tikara wọn ki wọn si mọ pe a ti gbà wọn la. Bi eniyan tilẹ ni awọn arakunrin, awọn arabinrin, awọn obi, awọn ibatan miiran, ati awọn ọrẹ ti o ti ri igbala, kò le ni itẹlọrun titi yoo fi ni iriri naa tikara rè̩.

Awọn Ibakasiẹ ti o Tò Lọwọọwọ

Ọbabinrin yii ti ọna jijin réré wá si Jerusalẹmu. Ninu awọn ẹgbẹ nla rè̩ ni ọpọlọpọ ibakasiẹ wà ti wọn ru awọn ẹbun ti o niyelori ti o si ṣe iyebiye. Lai si aniani o ni ọpọlọpọ awọn iranṣẹ ati ounjẹ pupọ. Boya irin-ajo naa tilẹ ṣoro ti o si lewu pẹlu. Boya ọbabinrin yii ati awọn ẹgbẹ ero rè̩ ni lati fi ọpọlọpọ ọjọ rìn laaarin aṣalẹ nibi ti kò si ẹnikẹni ati lọna tooro laaarin awọn oke giga nibi ti awọn ọlọṣa ti le gba ẹrù wọn lọ. S̩ugbọn kò si ifi ẹmi wewu ti o pọ jù! O ti pinnu lati ri ọba. O ni lati jẹ pe o fi ẹni kan sori ijọba rè̩ lati maa dele de e, ṣugbọn o ti pinnu tan lati ri Sọlomọni ati lati beere awọn ibeere rè̩ ti o takoko.

Nigba ti ẹlẹṣẹ ba n fi gbogbo ọkàn rè̩ wa Ọlọrun, o ṣetan lati ṣaapọn. Oun a wa sọdọ Jesu, o si n fẹ lati ṣe ohunkohun ti Jesu ba beere lọwọ rè̩, o si ti mura tan lati fi aye rè̩ ati ifẹ rè̩ fun Oluwa. Kò si wahala tabi iṣoro ti o pọ jù lati la kọja lati le ni igbala.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. A ki ọbabinrin yii kaabọ. A fun un ni àye lati ba Sọlomọni, ọba sọrọ. Ki ba ti tẹ ẹ lọrun lati ba ọkan ninu awọn eniyan Sọlomọni sọrọ. O n fẹ lati ri Sọlomọni. Gbogbo awọn ibeere rè̩ ti o takoko ni o mu wa siwaju rè̩. O sọ ohun gbogbo ti o wà ninu ọkàn rè̩ fun Sọlomọni, kò si pa ohunkohun mọ fun un.

  2. Ọbabinrin naa dan Sọlomọni ati ọgbọn ti Ọlọrun fun un wo, nipa bibeere awọn ibeere ti o takoko lọwọ rè̩. Sọlomọni sọ idahun wọn fun un. Bi kò ba ti mura tan lati sọ awọn iṣoro rè̩, ki ba ti ṣe e ṣe fun un lati ri idahun wọn gbà.

  3. Sọlomọni jẹ apẹẹrẹ Kristi ẹni ti o ni idahun fun gbogbo ibeere ati agbara lati dá ni silẹ ninu gbogbo iṣoro. Ọpọlọpọ eniyan ni kì i dan Jesu wò. Wọn kì i tọ Ọ lọ fun idasilẹ ninu iṣoro wọn. Wọn kò mura tan lati gbà pe wọn ni iṣoro. Bi Ọbabinrin S̩eba ba tọ Sọlomọni lọ pẹlu ọkàn pe oun mọ ohun gbogbo ati pe oun kò ni ibeere lati beere, oun i ba pada si ile lai ri idasilẹ ninu awọn iṣoro rè̩. Ọbabinrin yii beere o si ri gbà (Matteu 7:7).

  4. Ọrọ Sọlomọni

  5. O jé̩ iyanu fun Ọbabinrin naa nigba ti o gbọ ọgbọn Sọlomọni ti o si ri ile daradara rè̩. Ẹnu yà a si eto ati iṣakoso rè̩, ọpọlọpọ awọn iranṣẹ ati oluranlọwọ rè̩, si ọrọ ti iwọṣọ ati ounjẹ wọn fi hàn, ati si ọwọ ti Sọlomọni fi n lọ sinu Tẹmpili lati jọsin.

  6. Ọpọlọpọ nnkan ni o wà lati ri, bi a ti n mu eniyan lọ yika ibi ti a kọ aafin Sọlomọni si. Atè̩gun mẹfa ni o wà ati apoti itisẹ wura kan ti o wà ni abagunkè si ité̩ ehin-erin, ti a fi wura alailabula bò (II Kronika 9:17). Ni iha kọọkan ité̩ yii ati ni apa kọọkan awọn akasọ wọnni ni awọn kiniun ti a fi wura ṣe duro si, iru ité̩ bayii kò tun si ninu ijọba miiran.

  7. Ninu ile igbo Lẹbanoni yii boya a ba fun eniyan layè lati mu omi lati inu ife wura, nitori pe gbogbo ohun-èlo ile naa wura alailabula ni a fi ṣe wọn. Awọn àgbala ati ọdẹdẹ wà nibẹ eyii ti ipilẹ wọn jẹ okuta iyebiye (I Awọn Ọba 7:9). Hiramu ara Tire, ẹni ti o “kún fun ọgbọn, ati oye, ati ìmọ lati ṣe iṣẹkiṣẹ ni idẹ” ṣe awọn ọwọn nla fun iloro Tẹmpili (I Awọn Ọba 7:14, 21). Awọn ọwọn idẹ naa lẹwa pẹlu aworan lili ati pomegranate ti a ṣe si ara wọn.

  8. Awọn ẹyẹ-ologe ti o ni àwọ daradara ati awọn inaki ti ọkọ Tarṣiṣi mu lati ọna jijin wá wà nibẹ. Ọpọlọpọ kẹkẹ-ẹṣin ati awọn ẹṣin ati ibakasiẹ ti a ti fi ta Sọlomọni lọrẹ wà nibẹ pẹlu. Ọpọlọpọ ẹbun ni a fi fun Sọlomọni lati “gbogbo aiye” lati ọwọ awọn ti wọn n fẹ ki ìṣọrẹ wọn ba le wà pẹ -- kì i ṣe nitori pe wọn bè̩ru Sọlomọni ṣugbọn nitori pe wọn fẹran rè̩, ọkàn wọn si bu ọlá fun un.

  9. Ni ọdun kan wura ti Sọlomọni ri gbà ju ó lé ni biliọni mẹta naira (3,040,000,000) lọ, lai ka owo ti o tun n wọle nipa ṣiṣowo pẹlu awọn oniṣowo ti n ta turari oloorun didun ati awọn miiran pẹlu. “Sọlomọni ọba si pọ jù gbogbo awọn ọba aiye lọ li ọrọ ati li ọgbọn.” Abajọ ti o fi kún Ọbabinrin S̩eba ni àya rekọja to bẹẹ ti “kò kù agbara kan fun u mọ.”

  10. Ihin Otitọ

  11. Ọrọ ti ọbabinrin nì sọ dàbi ẹri. O ni otitọ ni awọn ohun ti oun ti gbọ, ṣugbọn a kò tilẹ ti i sọ idaji nipa ti ogo rè̩ fun oun. Ọgbọn ati ọrọ Solomọni pọ lọpọlọpọ ju awọn ohun ti oun ti gbọ lọ. Ọpọlọpọ ni o ti ro pe iroyin ti awọn kọkọ gbọ nipa ogo igbala, ati agbara ti Jesu n fun ni lati gbe igbesi-aye ailẹṣẹ ti dara ju eyi ti o le jé̩ otitọ lọ. S̩ugbọn bi wọn ba ti gbadura ti wọn si ti ri ayọ igbala tikara wọn, wọn le sọ bi ti Ọbabinrin S̩eba pe, “Si kiyesi i, a kò sọ idaji wọn fun mi.”

  12. Boya ọbabinrin yii ti n ṣiyemeji nipa ọgbọn ati ọrọ Sọlomọni gẹgẹ bi o ti gbọ, pe boya ni o le to bẹẹ ṣugbọn nisisiyi o mọ pe otitọ ni – nitori pe oun tikara rè̩ ti rii. Lai si aniani yoo rò pe wiwa oun ni ere ti o tọ, nitori pe otitọ naa gan an tilẹ tobi ju okiki Sọlomọni lọ. Ẹri rè̩ dàbi ti ẹnikẹni ti o ti ri Ọlọrun ti o le sọrọ pẹlu idaniloju pe otitọ ni awọn ileri Ọlọrun. Ẹni ti o ti ri igbala mọ pe Ọlọrun a maa dahun adura.

  13. Anfaani awọn Iranṣẹ

  14. Ọbabinrin S̩eba fi ibukun fun Oluwa fun inurere ati inudidun ti O fi hàn fun Sọlomọni, ati fun ifẹ Rè̩ si awọn eniyan naa. O jẹwọ pe Oluwa ni o fi ọgbọn naa fun Sọlomọni. Nigba ti a ṣè̩ṣè̩ fi Sọlomọni jọba, Sọlomọni ti beere fun “ọkàn imoye lati ṣe idajọ” awọn eniyan naa (I Awọn Ọba 3:9). Nitori pe ibeere Sọlomọni kò ni imọ-ti-ara-ẹni-nikan ninu ti o si té̩ Oluwa lọrun, Ọlọrun sọ pe kì i ṣe ọgbọn nikan ni Oun yoo fun Sọlomọni ṣugbọn ati ọrọ ati ọlá ati ẹmi gigun bi o ba gbọran si aṣẹ Ọlọrun (I Awọn Ọba 3:10-14).

  15. Ọbabinrin naa wi pe awọn iranṣẹ Sọlomọni ni lati jẹ ẹni-ibukun nitori pe wọn ni anfaani lati maa gbọ awọn ọrọ ọba nigba gbogbo. Boya awọn iranṣẹ rè̩ kò tilẹ mọ riri anfaani wọn lati maa ba Sọlomọni gbe lati maa gbọ ọrọ ọgbọn rè̩. O yẹ ki awa gẹgẹ bi iranṣẹ Kristi mọ riri awọn anfaani wa. A ni Bibeli, pẹlu ọrọ ọgbọn rè̩ eyii ti yoo mu iye-ainipẹkun wá fun wa bi a ba gbọran. A le maa ba Kristi gbe titi pẹlu awọn eniyan Rè̩. N jẹ o le darukọ diẹ ninu awọn ibukun miiran ti a maa n fi fun awọn ti o n sin Oluwa?

  16. Ọrẹ fun Sọlomọni

  17. Ki Ọbabinrin S̩eba to pada si ile rè̩, o fi ọrẹ fun Sọlomọni. Ẹbun ti o niye lori ni wọn – wura ati okuta iyebiye. O fun un ni turari lọpọlọpọ ju iye turari ti Sọlomọni ti ri gba lọwọ eniyan kan ṣoṣo lọ. O n fẹ lati fun Sọlomọni ni awọn è̩bun wọnyi. Kò ha ti gbọ ọgbọn ti Ọlọrun fi sinu Sọlomọni? Sọlomọni kò ha ti dahun awọn ibeere rè̩ ti o takoko? Ni mimọ riri ati ọkàn imoore o fi ẹbun wọnyi fun Sọlomọni. Sọlomọni ni ọrọ. Kì i ṣe pe Sọlomọni n fẹ ọrẹ rè̩, ṣugbọn o gba wọn lọwọ rè̩. Oun paapaa naa si tun gba “ohunkohun ti o bre, li aika eyiti a fifun u lati ọwọ Sọlomọni ọba wá.” O pada si ilu rè̩ pẹlu gbogbo ẹbun wọnyi, lẹyin riri Sọlomọni ati gbigbọ ọgbọn rè̩! Gbogbo nnkan wọnyi ni o ri gbà yatọ si pe a dahun gbogbo ibeere rè̩! O si tun ti ri itẹlọrun gbà pẹlu!

  18. Ẹni ti o Tobi jù Sọlomọni Lọ

  19. Wò o bi eyi ti dabi iwa ẹni ti o ri igbala! Awọn ti o ri igbala kò ha n fi ayé wọn rubọ fun Ọlọrun gẹgẹ bi ọbabinrin nì ti fi wura lelẹ? N jẹ awọn ti o ti ri igbala kò ha n fi talẹnti wọn fun Ọlọrun gẹgẹ bi oun ti fi ọpọlọpọ turari ati okuta iyebiye lelẹ? Bi ẹnikẹni ba fi aye rè̩ rubọ fun Ọlọrun yoo ri gba ninu ọpọlọpọ iṣura ti Oluwa ni. A o dahun awọn ibeere rè̩ ti o takoko. Yoo ni itẹlọrun. A o mu ifẹ-inu rè̩ ṣẹ; ohunkohun ti o ba beere ni orukọ Jesu (Johannu 14:14) ati pẹlu igbagbọ (Matteu 21:22; Marku 11:24) yoo rii gba (Matteu 7:7).

  20. Wò o bi i ba ti jẹ ohun iyanu to lati ri Sọlomọni! S̩ugbọn a le mọ Ẹni ti o “pọ jù Sọlomọni lọ.” Sọlomọni kò le fi igbala fun eniyan; ṣugbọn Jesu, Ọmọ Ọlọrun ni o n gbà wa là kuro ninu è̩ṣẹ wa. Nipasẹ adura a le ba A sọ gbogbo eyi ti o wà ninu ọkàn wa, lai fi ohunkohun pamọ. A ni anfaani ti o tobi ju ti Ọbabinrin S̩eba lọ -- a le tọ Jesu Kristi lọ, Ọmọ Ọlọrun, Ẹni ti o pọ jù Sọlomọni lọ.