Lesson 260 - Junior
Memory Verse
“Nwọn o mā pè orukọ rè̩ ni Emmanuẹli, itumọ eyi ti iṣe, Ọlọrun wà pẹlu wa” (Matteu 1:23).Notes
Oorun Ododo
Lati igba de igba ni awọn woli Majẹmu Laelae ti n kede nipa ọjọ naa ti Olurapada Israẹli, ani Messia nla nì, yoo dé lati ṣé̩ agbara awọn ọta wọn. Nipa imisi Ọlọrun, Malaki, ẹni ti o kẹyin ninu awọn woli kọwe bayii: “run ododo yio là, ti on ti imularada ni iyé̩-apá rè̩, fun ẹnyin ti o bè̩ru orukọ mi” (Malaki 4:2). Òórọ titun fẹrẹ de nigba ti itanṣan imọlẹ didan yoo bo okunkun è̩ṣẹ mọlẹ, ti Oluwa yoo si ti inu Ogo wá lati fi igbala fun Israẹli awọn eniyan Rè̩.
S̩ugbọn nigba ti o ṣe a kò gbọ ohun awọn woli mọ. Fun odidi irinwo (400) ọdun gbako a kò gbọ ọrọ kankan lati Ọrun wá. N ṣe ni okunkun ti ẹmi bo ilẹ ti o si n buru sii lati ọjọ de ọjọ. Afi iba iranti ohun ti awọn woli iṣaaju ti kọ silẹ nikan ni kò jẹ ki ireti pin. Dajudaju Messia naa kò le ṣai de!
Awọn Olóòótọ Diẹ
S̩ugbọn laaarin okunkun naa a ri awọn eniyan diẹ kaakiri lọkunrin ati lobinrin ti wọn gbagbọ pe Ọlọrun kò jẹ kọ awọn eniyan Rè̩ silẹ. Wọn kò dẹkun lati maa sin Ọlọrun Israẹli – lati maa gbadura ati lati maa ṣe ireti.
Lode oni, pupọ Onigbagbọ ni a n pọn loju nibi ti ijọba orilẹ-ède wọn kò ti gbagbọ pe Ọlọrun wà. S̩ugbọn bi o tilẹ jẹ pe okunkun nipa ti ẹmi yi wọn ká, igbagbọ wọn kò yè̩ pe Jesu n pada bọ sibẹ. Ọlọrun kò jẹ ki ireti kú ninu ọkàn awọn wọnni ti wọn ti pinnu lati wà ni imurasilẹ nigba ti Jesu ba de.
Iru igbagbọ bayi ni Sakariah ati Elisabẹti ni. Lati inu iran olori alufa kin-in-ni, Aarọni, ni wọn ti wá; o wa jé̩ anfaani Sakariah ni akoko yii lati maa ṣe iṣẹ-isin ninu Tẹmpili, ati lati maa wọna fun bibọ Jesu.
Awọn obi Sakariah ti di igbagbọ wọn ninu ileri Ọlọrun mu ṣinṣin, itumọ orukọ ti wọn si ti yàn fun ọmọ wọn ni pe, “Ọlọrun ranti.” Ọkàn wọn balẹ wi pe Ọlọrun kò gbagbe ileri Rè̩, eyi ti a kọkọ ṣe fun Efa ninu Ọgba, pe Oun o fun ni ni Olurapada kan. Kò le ṣai ri bẹẹ! S̩e Ọlọrun ti tun ṣe ileri kan naa fun Abrahamu, O si ti fi idi rè̩ mulẹ pẹlu ibura. A kò le ṣai mu un ṣẹ. Gbogbo orilẹ-ède aye ni a o bukun fún lati inu Iru-ọmọ Abrahamu, eyi kò si le jẹ ẹlomiran bi kò ṣe Kristi, Olugbala. Dajudaju, O n bọ!
S̩ugbọn ọjọ pẹ, ọdun si gori ọdun, sibẹ iranwọ kò de. Kaka bẹẹ, o dabi ẹni pe okunkun naa tubọ n ṣu sii ninu aye. Ninu awọn Ọmọ Israẹli ti pada si Jerusalẹmu kuro ninu isinru Babiloni pẹlu ireti pe òórọ titun naa kù si dè̩dè̩, ṣugbọn wọn kò ri iyipada si igba atẹyinwa.
Hẹrọdu Nla ti tun Tẹmpili Ọlọrun kọ ni Jerusalẹmu. Ni tootọ okuta funfun ni a fi kọ aafin daradara naa. Ni apa ila-oorun a tilẹ fi wura pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ té̩ ojude rè̩, eyi ti o fi ìtanṣan oorun owurọ hàn. S̩ugbọn korofo lasan ti a fi ọwọ eniyan kọ ni. Apoti-ẹri ti Majẹmu ti sọnu nigba ti wọn ti lọ si oko-ẹrú, okuta kan lasan ni o wà ni ipo rè̩ mimọ ninu Ibi Mimọ Julọ -- apẹẹrẹ pe ogo Oluwa ti fi wọn silẹ.
A kò dí awọn Ọmọ Israẹli lọwọ lati maa ba eto isin wọn lọ, awọn alufa si maa n ṣiṣẹ isin nigba ti o ba kan idile ti wọn gẹgẹ bi Sọlomọni ti lana silẹ ni ọpọlọpọ ọdun ṣiwaju akoko yii. Loorọ ati lalẹ awọn eniyan a pejọ pọ sẹyin odi Tẹmpili naa lati gbadura, nigba ti awọn alufa ba n sun turari si Oluwa ninu ile. Wọn a sọkun nitori ogo ti wọn ti sọnu, wọn a si gbadura fun Messia ti n bọ pe, Oluwa, yoo ti pẹ to?
Iṣẹ-alufa Sakariah
O wa kan idile Abia lati ṣiṣẹ isin ninu Tẹmpili, Sakariah si ni alufa wọn. Oun ati iyawo rè̩ jẹ ẹni-iwa-bi-Ọlọrun, wọn fẹran ofin wọn si n ṣe wọn. O ni inudidun ninu iṣẹ-isin rè̩ fun Ọlọrun.
Bi Sakariah ti n bọ sinu aṣọ oye alufa, ti o si mu turari lọ si Ibi Mimọ lati sun un lori pẹpẹ wura, gẹgẹ bi awọn alufa bi Aarọni ti ṣe ni ẹẹdẹgbẹjọ (1,500) ọdun ṣiwaju rè̩, ọkàn rè̩ yọ si iṣẹ rè̩. Nibo ni o tun ti le sun mọ Oluwa ju Ibi Mimọ Rè̩ lọ? Lai ṣe aniani, Ọlọrun yoo gbọ adura rè̩. Sakariah kọ ha ni orukọ rè̩ -- “Ọlọrun ranti.”
Wọn n Fẹ Ọmọkunrin Kan
Sakariah ati iyawo rè̩ jé̩ arugbo. Nigba ti ọjọ-ori wọn kò i ti pọ to bẹẹ wọn ti maa n gbadura fun ọmọ, pẹlu adura wọn fun alaafia lori Israẹli: ṣugbọn Ọlọrun kò mu ibeere wọn ṣẹ.
Nigba ti Sakariah pari iṣẹ-isin rè̩ ni Ibi Mimọ, jinnijinni mu un bi o ti ri alejo ode-ọrun kan. Lojiji laaarin ọpa fitila ati pẹpẹ turari, angẹli Oluwa kan fara hàn. Ifarahàn lati Ọrun wa! O ha le jẹ pe opin de si idakẹrọrọ irinwo (400) ọdun atẹyinwa ni? Ọlọrun yoo ha tun ti ẹnu woli kan ba awọn eniyan Rè̩ sọrọ? S̩e Sakariah si ni woli naa? Tabi angẹli naa fẹ kede bibọ Messiah ni? S̩e ohun ti Sakariah ti n duro de ti o ti n reti ti o si ti n gbadura fun ni yii? S̩ugbọn sibẹ, ẹrù ba Sakariah.
Má ṣe bẹru, Sakariah. Oluwa ti gbọ adura rẹ. O ti jẹ iyanu tó, pe angẹli duro niwaju rè̩ pẹlu iṣẹ lati oke Ọrun wá! Ọlọrun ti gbọ adura rè̩ Oun yoo si fi ọmọkunrin kan fun un.
O ti pẹ ti Sakariah ti ṣiwọ lati maa gbadura lati bi ọmọ. O rò pe akoko ti kọja -- ṣugbọn Ọlọrun kì i pẹ jù. Ọlọrun ni o n san ere ijoloootọ Sakariah ati Elisabẹti fun wọn. Nisisiyi ayọ wọn yoo di kíkún. Sakariah, a o bi ọmọkunrin kan fun ọ! Iru ọmọ wo! A gbọdọ pe orukọ rè̩ ni Johannu, itumọ eyi ti i ṣe “Ẹbun-ọfẹ Ọlọrun.”
Ọjọ ti a o bi ọmọ fun Sakariah ati Elisabẹti yoo jé̩ ọjọ ayọ fun wọn, ṣugbọn ọmọ naa kò ni wà fun anfaani awọn nikan. Angẹli naa ti wi pe: “Enia pupọ yio yọ si ibi rè̩ . . . On o si pa pipọ da ninu awọn ọmọ Israẹli si Oluwa Ọlọrun wọn.”
Ọrọ Awọn Woli
Gbogbo awọn olufọkansin Ju ni wọn ti kà awọn asọtẹle Isaiah, ti n kede onṣẹ kan ti yoo wa ṣiwaju Messia. Oun yoo lọ ṣaaju lati pese ọkàn awọn eniyan silẹ lati gbà Jesu nigba ti O ba de. Onṣẹ yii kò ni ju ohùn lọ, ti n kigbe ni aginju; ṣugbọn ọrọ iwaasu rè̩ ni yoo bẹrẹ igbà titun. “On ki iṣe Imọlẹ na, ṣugbọn a rán a wá lati ṣe ẹlẹri fun Imọlẹ na” (Johannu 1:8). Johannu ni akede ti o sọ ti dide owurọ titun.
Iṣẹ ti Johannu Baptisti yoo jẹ ni pe: “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dè̩dè̩” (Matteu 3:2). Imuṣẹ gbogbo asọtẹlẹ awọn woli nipa wiwa Messia lẹẹkinni kù si dẹdẹ. Nigba gbogbo ni wọn ti n sọ nipa ọjọ kan ti o n bọ. Nisisiyi ọjọ naa de wayii. Ọjọ ti a ti n foju sọna fun lati igba pipẹ naa ni yii! Johannu Baptisti ni o ni anfaani aláyọ yii lati fi ọwọ rè̩ tọka si Jesu, Ọdọ-agutan Ọlọrun.
Aigbagbọ Sakariah
Ihin ti angẹli naa mu wá ti tobi pupọ fun Sakariah lati gbagbọ. Eyi yoo ti ṣe ri bẹẹ? Nigba ti kò i ti dagba to eyi, kò ri ọmọ ti o n fẹ bi. O wa rò pe, bayii, kò le ṣe e ṣe mọ. S̩ugbọn ki ha i ṣe angẹli Gabriẹli ti n duro niwaju Ọlọrun gan an ni ẹni ti n ba a sọrọ? Ọlọrun tikara Rè̩ ni O ti rán angẹli naa lati mu ihin ayọ naa wá fun Sakariah. Ki ni ṣe ti o fi ni lati ṣiyemeji?
Ki ni ṣe ti a fi maa n ṣiyemeji awọn ileri Ọlọrun? Ọrọ Rè̩ daju gẹgẹ bi ọsan ati alẹ ti daju. A sọ pe a gbà Ọlọrun gbọ, ṣugbọn wo bi igbagbọ wa ti kere to nigba pupọ! Ẹ jẹ ki a gbadura pe ki Ọlọrun ran wa lọwọ ki a le gbẹkẹle E ki a si le gba gbogbo ileri Rè̩ gbọ.
Sakariah beere àmì, a si fi fun un. Oun kò ni le sọrọ titi a o fi mu ileri naa ṣẹ. Fun oṣu mẹsan gbako, kò ni le sọrọ rara, nitori pe kò gba ọrọ angẹli naa gbọ. Nigba ti o ba le fi oju rè̩ ri pe oun ti bi ọmọ kan, a o tu u ni ahọn.
Ọrọ Angẹli Naa si Maria
Iṣẹ yii nikan kọ ni Gabriẹli ni lati jé̩. Lẹyin oṣu marun un o tun wa si ayé. Ni akoko yii o fara hàn wundia Ju kan lati inu ẹya Juda. A, wo iru iṣẹ ti o wa jé̩ fun un! Oun ni yoo jé̩ iya Messia naa! Lati ọdunmọdun ti wọn ti fi n duro de imuṣẹ ileri Ọlọrun yii, olukuluku ọmọbinrin Ju ni o ti n reti pe o le ṣe oun ni yoo jé̩ iya Ọba Israẹli ti yoo joko lori itẹ Dafidi. Maria ni a fi ọlá yii fun. O wá lati idile ọba Dafidi; ṣugbọn gbogbo ogo eto ijọba Israẹli ti parẹ ninu ọpọlọpọ ọdun isinru labẹ Babiloni ati ipọnju labẹ ijọba Romu. Iya Oluwa wa kò ni ọrọ tabi òkìki ninu aye yii, ṣugbọn o jé̩ ọlọrọ sipa ti Ọlọrun. O fi igbesi-aye rè̩ wu Ọlọrun; angẹli naa wa sọ bayii fun un pe: “Alafia, iwọ ẹniti a kọjusi ṣe li ore, Oluwa pẹlu rẹ: alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin. . . iwọ ti ri ojurere lọdọ Ọlọrun.”
Ro bi inu Maria yoo ti dùn to lati gbọ iru ọrọ bayii ni ẹnu angẹli Ọlọrun! Ọlọrun ti ri awọn ọdun ti o ti fi sin tọkantọkan, iwa pipe rè̩ ati iwa mimọ rè̩. Ọlọrun ti n kiyesi i boya nigba ti oun kò tilẹ rò pe O n wo oun. Ọlọrun ti ri gbogbo iwa ti o ti hù -- oun si ri ojurere lọdọ Rè̩.
Gbogbo iwa wa i ba le jé̩ iru eyi ti inu Ọlọrun yoo dùn si! O yẹ ki a maa ranti nigba gbogbo pe Jesu n ri gbogbo nnkan ti a n ṣe. Nigba ti O ba ni iṣẹ pataki kan lati ṣe, O mọ ẹni ti o yẹ ki Oun yàn, ẹni ti yoo wa ni imurasilẹ lati ṣe iṣẹ naa.
Nitori pe igbesi-aye Maria wu Ọlọrun, O yàn an lati jé̩ ìyá Messia. Ọrun rè̩ ara rè̩ silẹ, ani Ọmọ Maria jé̩ Ọmọ Ọlọrun. Ọlọrun rán Ọmọ Rè̩ si aye ninu ẹran-ara.
Alejo Josẹfu
Angẹli naa tun bẹ ẹni kan wò. O fara hàn Josẹfu o si sọ fun un pe Jesu ni a o pe orukọ Ọmọ Maria. “Nitori on ni yio gbà awọn enia rè̩ là kuro ninu è̩ṣẹ wọn.” A o si tun pe E ni Emmanuẹli, itumọ eyi ti i ṣe “Ọlọrun wà pẹlu wa.” Ọlọrun yoo bẹ awọn eniyan Rè̩ wò ni ọna ti o jù ti atẹyinwa lọ. Ni ìrí eniyan, Oun yoo maa ba awọn eniyan gbe.
Imọlẹ naa ti n là. Oorọ titun bu wọle tan. A o ti ipasẹ Jesu, Imọlẹ aye, bori okunkun è̩ṣẹ. Lai pẹ mọ a o bi Oorun Ododo ti alagba Woli Malaki ti kọwe nipa Rè̩. Yoo ṣe awotan awọn onirobinujẹ ọkàn, yoo wo awọn alaisan sàn, yoo mu ki awọn afọju riran, yoo si waasu pe gbogbo eniyan nibi gbogbo (yala Ju tabi Keferi) ni àyè wà fun lati wá ati lati ri igbala kuro ninu è̩ṣẹ wọn.
Questions
AWỌN IBEERE- Ta ni kẹyin ninu awọn woli Majẹmu Laelae?
- Bawo ni o ti pẹ to lati igba ti o ti sọrọ si akoko ti a bi Jesu?
- Ki ni itumọ orukọ Sakariah?
- Idile wo ni Sakariah? Ki si ni iṣẹ rè̩?
- Ta ni fara hàn an ninu Tẹmpili? Ki ni iṣẹ ti o jẹ?
- Ki ni ami pe ọrọ naa yoo ṣẹ dandan?
- Ki ni Johannu Baptisti yoo fi ọjọ aye rè̩ ṣe?
- Iṣẹ wo ni Gabriẹli jé̩ fun Maria?
- Bawo ni iṣẹ naa ti ṣe pataki to?