Orin Dafidi 37:1-40

Lesson 261 - Junior

Memory Verse
“Máṣe ikanra nitori awọn oluṣe-buburu, ki iwọ ki o máṣe ilara nitori awọn oniṣẹ è̩ṣẹ” (Orin Dafidi 37:1).
Notes

A Ke Awọn Oluṣe-buburu kuro Lai Pẹ

Dafidi kọ akọsilẹ bayii: “Máṣe ikanra nitori awọn oluṣe-buburu, ki iwọ ki o máṣe ilara nitori awọn oniṣẹ è̩ṣẹ. Nitori ti a o ke wọn lulẹ laipẹ bi koriko, nwọn o si rọ bi eweko tutu.” A o ké wọn lulẹ lai pẹ!

Ilọsiwaju awọn oluṣe-buburu le jẹ iyalẹnu fun awọn ẹlomiran. Ki ni ṣe ti wọn n jẹ ere ti o pọ to bẹẹ ninu iwa-buburu wọn? Ọkan ninu awọn woli kọ akọsilẹ nigba kan pe: “Nitori ti emi ṣe ilara si awọn aṣefefe; nigbati mo ri alafia awọn enia buburu . . . titi mo fi lọ sinu ibi-mimọ Ọlọrun; nigbana ni mo mọ igbẹhin wọn. Nitõtọ iwọ gbé wọn ka ibi yiyọ: iwọ ti wọn ṣubu sinu iparun” (Orin Dafidi 73:3, 17, 18).

Bibeli sọ fun wa pé, “Ohunkohun ti enia ba funrugbin on ni yio si ka” (Galatia 6:7); nitori naa bi o tilẹ jẹ pe a ri awọn eniyan buburu ti wọn n di ọlọrọ ti ọwọ wọn si n tẹ gbogbo anfaani aye yii, nigba ti o jẹ wi pe agbara káká ni olóòótọ Onigbagbọ fi n ri diẹ, a ni lati ranti pe igba kan n bọ ti a o mu ohun gbogbo wá si iṣiro. A o jẹ olukuluku oluṣe buburu ni iyà -- bi kò ba jẹ ẹ ni aye yii yoo jẹ ẹ ni aye ti o n bọ.

Dafidi paapaa wi pe: “Emi ti nri enia buburu, ẹni iwa-ika, o si fi ara rè̩ gbilẹ bi igi tutu nla.” O le fi hàn ni gbogbo ọna pe oun n ṣe rere, ki o si dara lati wò, “ṣugbọn o kọja lọ, si kiyesi i, kò si mọ.”

Ọpọlọpọ awọn eniyan buburu ni o n di alagbara lọpọlọpọ, nigba miiran wọn a tilẹ wi pe kò si Ọlọrun. Ọlọrun, ninu aanu Rè̩ le ṣe alai ke wọn kuro lojiji, ṣugbọn igbà n bọ ti a o pa awọn olurekọja run papọ.

Awọn Ajogun Ọlọrun

Ki ni opin Onigbagbọ? Ajogun Ọlọrun ni, yoo si bá Ọlọrun gbe titi lae. Paulu Apọsteli ni ọpọlọpọ iṣoro lẹyin ti o fi ọkàn rè̩ fun Jesu, ṣugbọn kò si igbà kan ti o rẹwẹsi ninu ọkàn rè̩. Nigba gbogbo ni oun i maa wò rekọja èrè ti o mọ daju pe oun o ri gba lọwọ Oluwa. A maa yọ nigba ti o ba n ranti pe awọn Onigbagbọ jé̩ ọmọ Ọlọrun. “Bi awa bá si jẹ ọmọ, njẹ ajogun li awa; ajogun Ọlọrun, ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi; biobaṣepe awa bá a jiya, ki a si le ṣe wa logo pẹlu rè̩” (Romu 8:17).

Oluwa ṣeleri pe, “S̩e inu-didùn si Oluwa pẹlu, on o si fi ifẹ inu rẹ fun ọ.” Bi ọna wa ba té̩ Oluwa lọrùn, Oun a maa ni inu didun lati san ere fun wa. Adura wa yoo maa jẹ didun-inu fun Un. “Kò si ohun rere ti yio fà sẹhin lọwọ awọn ti nrin dede” (Orin Dafidi 84:11).

Awọn Ajẹrikú

Awọn wọnyii jẹ ileri iyanu ti Ọlọrun ti ṣe; sibẹsibẹ akoko wà ti o dàbi ẹni pe Ọlọrun kò dahun awọn adura Onigbagbọ ki O si fun wọn ni ifẹ ọkàn wọn. Ki ni a le sọ nipa ẹgbẹrun ọna ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan ti wọn ti fi ẹmi wọn lelẹ nitori igbagbọ wọn, ti wọn jiya ọpọlọpọ ìwà-ika ti o buru jai lọwọ awọn eniyan buburu? Wọn ṣe inudidun ninu Oluwa, sibẹsibẹ ni oju wọn ni a gbà ohun gbogbo ti wọn ni lọ lọwọ wọn, ati ẹmi wọn paapaa. N jẹ wọn fẹ iyà ati irobinujẹ wọnyii?

Bi eniyan ba kọkọ wò o le rò pe Ọlọrun ti kọ wọn silẹ. S̩ugbọn ṣe akiyesi wọn bi wọn ti n lọ lati fi ẹmi wọn lelẹ. Imọlẹ wo ni o wà ni oju wọn nì? N jẹ wọn ri Jesu ni? Paulu Apọsteli kọ akọsilẹ nipa Mose pe o duro ṣinṣin “bi ẹniti o nri ẹni airi” (Heberu 11:27). Tẹti silẹ si awọn orin ti awọn ajẹriku wọnyi n kọ bi a ti n sọ wọn si awọn kiniun lati jẹ wọn. Inu wọn dun pe a kà wọn yẹ lati jiya fun Olugbala wọn.

Ade Iye

Ifẹ inu wọn ni pe ki a dé wọn ni ade pẹlu Olurapada wọn, a si ti mu ifẹ wọn yii ṣẹ. Loni wọn n kọ orin iṣẹgun yi itẹ Ọlọrun ká. “Ibukún ni fun ọkunrin ti o fi ọkàn rán idanwò: nitori nigbati o ba yeje, yio gbà ade ìye, ti Oluwa ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ ẹ” (Jakọbu 1:12). Ade iye ni ere wọn. Ireti lati gba ade yii ni o ran wọn lọwọ lati fara dà akoko irora nla ti a pe wọn lati fara dà.

Nigba ti a lu awọn Apọsteli nitori wiwaasu nipa Jesu, “nwọn si lọ kuro niwaju ajọ igbimọ: nwọn nyọ nitori ti a kà wọn yẹ si ìya ijẹ nitori orukọ rè̩” (Iṣe Awọn Apọsteli 5:41).

Agbara lati Ọrun

Satani n gbá awọn ogun buburu rè̩ jọ si awọn Onigbagbọ. A kò mọ akoko ti yoo kàn wa lati jiya fun Kristi. S̩ugbọn awa ti a fẹran Rè̩ pẹlu gbogbo ọkàn wa yoo ri agbara gbà lati Ọrun ti yoo ràn wa lọwọ lati fara dà ohunkohun nitori ti Rè̩. Bi a ba ri inunibini ti o nira ninu aye yii, a mọ pe lai pẹ jọjọ yoo dopin. Nigba ti a ba si mi eemi ikẹyin, a o wà ninu Ogo pẹlu Jesu. Ni iṣẹju kan a o rekọja lati aye yii lọ si iye-ainipẹkun, nibi ti ayọ wa ki yoo lopin.

Awọn Ọlọkan-tutu

Ninu Iwaasu Kristi ni ori Oke, O ni “Alabukún-fun li awọn ọlọkàn-tutù: nitori nwọn o jogún aiye” (Matteu 5:5). Oluwa fi otitọ yii hàn fun Dafidi ni akoko ti rè̩. O kọ akọsilẹ pe, “Awọn ọlọkàn-tutù ni yio jogun aiye; nwọn o si ma ṣe inu didùn ninu ọpọlọpọ alafia.” Dafidi tun wi pe, “Awọn olupọnju yio jẹ, yio té̩ wọn lọrun” (Orin Dafidi 22:26).

“Yio té̩ wọn lọrun.” Wò o bi awọn ọrọ wọnni ti ṣe pataki to! A ri ọpọlọpọ eniyan ni aye ti wọn ni ju bi wọn ti n fẹ lọ, ṣugbọn wọn kò ni itẹlọrun. Wọn sa n fẹ lati ni sii ṣaa ni. Kò si ẹni ti o le ni itẹlọrun lai ni Jesu ninu ọkàn rè̩. S̩ugbọn nigba ti o ba ni ifẹ Ọlọrun, yoo ni itẹlọrun, oun i baa ni nnkan miiran lẹyin eyii tabi ki o má tilẹ ni nnkankan. “Diẹ pẹlu ibè̩ru Oluwa san jù iṣura pupọ ti on ti iyọnu ninu rè̩” (Owe 15:16). Paulu wi pe, “ipòkipo ti mo ba wà, mo ti kọ lati ni itẹlọrun ninu rè̩” (Filippi 4:11).

Paulu ti kọ lati ni itẹlọrun. A maa n kọ itẹlọrun nigba ti a ba ro ifẹ Ọlọrun si wa. Onigbagbọ jé̩ iṣura ọwọn fun Ọlọrun. Jesu ti fi È̩jẹ Oun tikara Rè̩ rà wa, O si ti fi ọrọ idaniloju fun wa pe: “irun-yirun” ori wa ni a kà pe ṣánṣán. “Ki ọkàn nyin ki o maṣe fa si ifẹ owo, ki ohun ti ẹ ni ki o to nyin; nitori on tikalarè̩ ti wipe, Emi kò jẹ fi ọ silẹ, bẹni emi kò jẹ kọ ọ silẹ” (Heberu 13:5).

Ọna ti awọn eniyan n gbà ni ayé lati ṣe aṣeyọri ni fifi ijakadi rọ awọn ẹlomiran sẹyin, nipa lilàkàka lati tayọ ẹnikeji, ati nipa ṣiṣe ara wọn ni ẹni ti o jáfáfá jù ẹni ti wọn n ba du ipo lọ. S̩ugbọn n ṣe ni ofin Oluwa kuku lodi si eyi gan an. Bi a ti tubọ n rè̩ ara wa silẹ sii tó niwaju Rè̩, ti a si n jọwọ ifẹ wa fun Un, bẹẹ ni a o maa ni aṣeyọri ju bẹẹ lọ ninu ọna wa gẹgẹ bi Onigbagbọ. O le jẹ pe a kò ni ni ohun ini aye tó ti awọn ọrẹ wa ti o kún fun ohun ilepa aye yii, ṣugbọn ọjọ naa n bọ nigba ti a o jogun aye yí ti a o si maa ṣe akoso pẹlu Kristi. Paapaa, Oluwa sọ fun Johannu ni Erekuṣu Patmo pé ẹni ti o ba ṣẹgun ni “yio jogun ohun gbogbo.”

Ayọ gba ọkàn Paulu Apọsteli kan nitori ogún ti o ni idaniloju pe oun yoo ni lẹyin aye yii ti o fi kọ akọsilẹ yii: “Mo ṣiro rè̩ pe, iya igba isisiyi kò yẹ lati fi ṣe akawe ogo ti a o fihàn ninu wa” (Romu 8:18).

Agbara awọn Ọlọkàn-tutù

Bi awọn eniyan buburu tilẹ n ṣe rere ninu aye yii eyii ki i ṣe pe wọn pọ ni ipa ju agbara ti n ṣakoso fun rere. Gbogbo agbara Ọrun ni o n ti Jesu lẹyin, sibẹsibẹ O jọwọ ara Rè̩ fun ikú ori igi agbelebu lati ọwọ awọn ika eniyan. O ni Oun le pe legioni angẹli mejila, awọn ti i ba pa gbogbo awọn ara Romu ati awọn Ju ti o dide si I run patapata -- ṣugbọn kò ṣe bẹẹ. Akoko idajọ kò i ti de. Nitori pe a kò dá awọn alufa ati awọn ọmọ-ogun duro ninu sisa ipa wọn lati pa Jesu, wọn ro pe awọn ni agbara ati pe kò si ẹni ti o le di wọn lọwọ ninu sisa gbogbo ipa wọn gẹgẹ bi ẹni ti gbogbo agbara wa lọwọ rè̩.

Oluwa yoo rẹrin nigba ti iparun awọn eniyan buburu ba de. Ni igba laelae ni Enọku ti sọ asọtẹle nipa ọjọ ti Oluwa yoo wá pẹlu awọn eniyan mimọ Rè̩ lati ṣe idajọ aye, “lati dá gbogbo awọn alaiwabi-Ọlọrun lẹbi niti gbogbo iṣe aiwabi-Ọlọrun wọn,” paapaa fun “gbogbo ọrọ lile ti awọn ẹlẹṣẹ alaiwabi-Ọlọrun ti sọ si i” (Juda 15). Ọlọrun sọ pe nitori pe awọn ẹlẹṣè̩ kọ lati feti si ọrọ Oun, Oun yoo rẹrin idaamu wọn, Oun O si ṣe è̩fẹ nigba ti ibè̩ru wọn ba de (Owe 1:26). Nisisiyi gan an ni akoko lati wa Oluwa ki a si rí idariji è̩ṣẹ wa gbà. Yoo ti pẹ jù nigba ti idajọ ba dé.

“Ma kiyesi ẹni pipé, ki o si ma wò ẹni diduro ṣinṣin: nitori alafia li opin ọkọnrin na.” Ọjọ aye wa kukuru yii kò ni pẹ buṣe. Ohun ti Ọlọrun yoo ri ninu igbesi-aye wa nigba ti aye wa ba dopin ni o ṣe pataki jù lọ. Opin yii ni yoo ṣẹṣẹ jẹ ibẹrẹ fun awọn ọmọ Ọlọrun tootọ. O n mura silẹ nisisiyi fun ayé ti o n bọ, nibi ti ohun gbogbo yoo jẹ kiki ayọ ati alaafia; nibi ti yoo gbe jọba pẹlu Kristi gẹgẹ bi ọba ati alufa fun Ọlọrun. Yoo ri opin awọn eniyan buburu, yoo si maa fi ogo fun Olugbala rè̩, Ẹni ti o gbà ọkàn rè̩ la kuro ni ọna awọn eniyan buburu, ti o si sọ ọ di aṣẹgun lati wà pẹlu Jesu titi ayeraye.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni yoo ṣẹlẹ si eniyan buburu?
  2. Ki ni ere Onigbagbọ?
  3. S̩e apejuwe bi ọkàn awọn ajẹrikú ti ri gẹgẹ bi wọn ti n lọ kú.
  4. Ta ni yoo jogún aye?
  5. Ki ni n mu itẹlọrun wá sinu aye eniyan?
  6. Bawo ni a ṣe le ni itẹlọrun?
  7. Ki ni opin “ẹni pipé”?