Lesson 262 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa, ati ifẹ Ọlọrun, ati idapọ ti Ẹmi Mimọ, ki o wà pẹlu gbogbo nyin” (2Kọrinti 13:14).Cross References
I “Ọlọrun Mẹtalọkan, Lae Olubukun”
1. Ọlọrun, Baba Ayeraye
(a) Ọlọrun Baba jẹ Ẹni kan – ani Ẹmi kan – Ọrọ Rè̩ ati awọn iṣẹ Rè̩ fi han pe O ti wà ati pe yoo si wà titi ayeraye, Ẹksodu 3:13-15; Deuteronomi 4:35-39; 2Kronika 6:14-18; Nehemiah 9:6; Orin Dafidi 19:1, 7, 8; 90:1, 2; 97:6; Malaki 3:6; Johannu 4:24; Iṣe Awọn Apọsteli 14:15-17; Romu 1:19, 20; 2Peteru 1:16-21; Ifihan 4:8-11; 7:12
(b) Ọla Ọlọrun kò ṣe e diwọn, ailopin ni gẹgẹ bi Ọlọrun paapaa, Job 42:2; Orin Dafidi 33:6-11; Isaiah 40:28; Matteu 19:26; Iṣe Awọn Apọsteli 17:27, 28; Romu 11:33-36; 1Timoteu 6:15, 16; Heberu 4:12, 13
2. Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun lati Ayeraye
(a) Iwe Mimọ fi han pe Jesu jẹ Ẹni kan pato, O ba Ọlọrun dọgba O si wà ni iṣọkan pipe pẹlu Ọlọrun, Orin Dafidi 2:2, 7, 11, 12; 110:1; Owe 30:4; Isaiah 6:1-5, 9, 10; pẹlu Johannu 12:37-41; Isaiah 48:16; Matteu 3:13-17; 28:19; Luku 1:30-35; Johannu 1:1-3, 10; 6:32, 33, 38, 50, 51, 58, 62; 8:58; 14:26; 15:26; 16:28; Romu 1:1-4; Filippi 2:5-11; 1Timoteu 2:5; Heberu 1:1-4; 13:8; 1Peteru 1:2; Ifihan 1:4, 5
(b) A fi orukọ Ọlọrun fun Kristi, a si ri gbogbo ọla ati pipe Ọlọrun lara Rè̩, Isaiah 9:6, 7; Matteu 7:29; 18:20; 28:18; Johannu 1:1; 5:26, 27; 6:64; 14:8-11; 16:15; 20:28; Iṣe Awọn Apọsteli 20:28; Efesu 1:22; Kolosse 1:13-19; 2:9; 1Timoteu 3:16; Heberu 1:8; 2Peteru 1:1
(d) Kristi ṣe iṣẹ Ọlọrun, Matteu 9:2-7; 25:31, 32; Marku 2:7-10; L0uku 10:22; Johannu 1:3, 10. 5:22, 25-30; Iṣe Awọn Apọsteli 2:21; Romu 14:10; Efesu 3:9; Kolosse 1:16; Heberu 1:2, 10; Ifihan 21:5
(e) Kristi tẹwọ gba ijuba, Luku 24:51, 52; Iṣe Awọn Apọsteli 1:24; 7:59, 60; 2Kọrinti 12:8, 9; 1Tẹssalonika 3:11-13; 2Tẹssalonika 2:16, 17
(f) Kristi mu asọtẹlẹ ṣẹ, Gẹnẹsisi 3:15 pẹlu Galatia 4:4; Mika 5:2 pẹlu Matteu 2:1; Isaiah 7:14 pẹlu Matteu 1:18 ati Luku 1:26, 35; Isaiah 9:1, 2 pẹlu Matteu 4:12-16; Deuteronomi 18:15 pẹlu Johannu 6:14 ati Iṣe Awọn Apọsteli 3:19-26; Sekariah 9:9 pẹlu Johannu 12:13, 14; Orin Dafidi 41:9 ati Sekariah 11:13 pẹlu Marku 14:10 ati Matteu 26:15; Isaiah 53:7 pẹlu Matteu 26;62, 63; Orin Dafidi 16;10 ati 68:18 pẹlu Matteu 28:9 ati Luku 24:50, 51
3. Ẹmi Mimọ, Ẹni Kẹta ninu Mẹtalọkan
(a) Iwe Mimọ fi han pe Ẹmi Mimọ jẹ Ẹni kan pato ti Baba ati Ọmọ ran wa, Johannu 14:16, 17, 26; 15:26; 16:13-15; Romu 8:9; 1Kọrinti 2:10-12; Galatia 4:6
(b) Lai si aniani, Ẹmi Mimọ jẹ Ọlọrun nitori a fi orukọ Ọlọrun fun Un, a fi ọla Ọlọrun fun Un, iṣẹ Ọlọrun si ti ọwọ Rè̩ ṣe, a si n juba Rè̩, Gẹnẹsisi 1:2; Orin Dafidi 104:30; 139:7-10; Isaiah 6:3-9 pẹlu Iṣe Awọn Apọsteli 28:25, 26; Matteu 28:19; Johannu 3:5, 6; Iṣe Awọn Apọsteli 5:3, 4; Romu 8;11, 26, 27; 1Kọrinti 2:10, 11; 3:16; 12:11; 2Kọrinti 13:14; Titu 3:5; Heberu 9:14; 1Peteru 3:18
(d) Ẹmi Mimọ ni Aṣoju Ọlọrun ti O wà ninu aye lati dari awọn eniyan wá sọdọ Kristi, lati mu awọn Onigbagbọ lọ jinlẹ ninu imọ Ọlọrun ati lati pe awọn ọmọ-ẹyin lati fi agbara wọ wọn fun iṣẹ isin, Gẹnẹsisi 6:3; Johannu 6:44, 65 pẹlu 16:7, 8; Johannu 14:16, 17, 26; 16:13; Iṣe Awọn Apọsteli 1:8; 6:3; 13:2-4; 1Kọrinti 2:9-16; 6:11; 12:4-11
II Iṣọkan Mẹtalọkan
1. A fi otitọ yii hàn gbangba pe Ọlọrun jẹ Mẹtalọkan, Gẹnẹsisi 1:1, 26; Numeri 6:24-27; Isaiah 6:1-5; 48:16; Matteu 3:13-17; 28:19; Johannu 14:26; 15:26; Efesu 2:18; 4:4-6; 1Johannu 5:7; Ifihan 1:4, 5; 4:8
2. A tun fi han gbangba pẹlu pe awamaridi iṣọkan pipe wà ninu Mẹtalọkan, Deuteronomi 6:4; 2Samuẹli 7:22; Isaiah 43:10-13; 44:6; Marku 12:29; Johannu 10:30-38; 14:8-11; 15:26; 16:15; 17:10, 11, 21-23
Notes
ALAYÉOtitọ Mẹtalọkan jé̩ ohun awamaridi ṣugbọn ti o niyelori lọpọlọpọ fun awọn Onigbagbọ tootọ -- otitọ ti o jinlẹ ti kò si loṣuwọn. Otitọ ti ẹnikẹni kò le mọ jijin rè̩ tan ni otitọ Mẹtalọkan, nitori naa, a ni lati rii daju pe nigba gbogbo ti a ba fẹ kẹkọọ nipa Rè̩ ki a ṣe e tọwọtọwọ. A kò gbọdọ rii fin tabi ki a fi ọwọ yẹpẹrẹ mu un nitori pe ọkan ninu otitọ ọlọwọ ninu Ọrọ Ọlọrun paapaa ni i ṣe. Otitọ Ọlọrun gan an ni.
Ọrọ Ọlọrun ati Ọlọrun paapaa jé̩ ọkan naa, ikilọ kan naa ti a si fun ni nipa pipa Ọrọ Ọlọrun mọ jẹwọ iru iha ti a ni lati kọ si Ọlọrun wa paapaa ati igbagbọ wa ninu Rè̩. A mọ daju pe bi a ba rú ọkan ninu ofin Ọlọrun, a jẹbi gbogbo rè̩; otitọ si ni pẹlu pé bi a ba sẹ Ẹni kan ninu Mẹtalọkan, a sẹ Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ ni apapọ. Bi a ba tabuku si ọkan a tabuku si gbogbo wọn. Bi a ba diwọn agbara ọkan a diwọn agbara gbogbo wọn. Bi a ba si ṣe alaibọwọ fun ọkan, gbogbo wọn ni a ṣe alaibọwọ fun.
Awọn ẹlomiran gbagbọ pe niwọn bi Mẹtalọkan Mimọ ti jẹ awamaridi o ni lati jẹ pe ki i ṣe otitọ. Wọn sẹ Ẹni kan tabi ju bẹẹ lọ ninu Mẹtalọkan nitori pe wọn kò mọ, bẹẹ ni wọn kò si ni oye nipa aṣiiri idipọ awamaridi ti ó wà ninu Mẹtalọkan. S̩ugbọn iwọn iba ohun ti a ṣipaya fun ni lati mọ tó fún wa. Nitori naa bi a ti n ṣe aṣaro ninu otitọ Ọrọ Ọlọrun lori ẹkọ yii, o ṣanfaani lati fi ọkàn otitọ ati aiṣè̩tan gba ohun ti Iwe Mimọ kọ wa ki a si pa ironu asan, igbekalẹ ọmọ eniyan ati ọfin-toto ti kò nilaari tì si apa kan.
“OLUWA On Li Ọlọrun”
Mose sọ fun ijọ awọn Ọmọ Israẹli pe, “OLUWA On li Ọlọrun” (Deuteronomi 4:35). A le ri ninu iwọn-iba ọrọ yii pe a fun ni ni ẹri ti o daniloju nipa Mẹtalọkan. A mọ pe ẹri ti o duro ṣinṣin ni eyi nitori awọn ọrọ ti Ẹmi Mimọ yàn lati lo lati ṣi ilana Ọlọrun payá fun ni jé̩ pipe, a si mọ pe Ọlọrun a maa sọ ohun ti O fẹ sọ gan an, ohun ti O ba si sọ naa gan an ni O n fẹ lati sọ.
Nigba ti Ẹmi Mimọ ti ipasẹ Mose pe Ọlọrun ni Jehofa ninu ẹsẹ kukuru yii, ki i ṣe pe o ṣeeṣi pe E bẹẹ. (Jehofa ni orukọ ti a tumọ si OLUWA ninu Iwe Mimọ, lati inu ede Heberu wa). Jehofa ni orukọ ti Ọlọrun yàn pe ki a fi mọ Oun ni gbogbo ibalo Rè̩ pẹlu awọn eniyan Rè̩ -- awọn eniyan ti i ṣe ti Rè̩ nipa Majẹmu ti O ba wọn dá. Eyi yii ni orukọ Ọlọrun gan an, oun ni o leke ninu orukọ Rè̩. A ki i fi orukọ yii pe Ọlọrun nigba ti a ba n jiṣẹ ti O ran si awọn wọnni ti kò ni ipin ninu awọn ileri ti Majẹmu. Ẹmi Mimọ a maa kiyesara gidigidi lati lo orukọ yii pẹlu iṣọra.
O tun han gbangba pe Ẹmi Mimọ kò ṣe aṣiṣe nigba ti o pe Ọlọrun ni Elohim ni ede Heberu ninu ẹsẹ kukuru yii. (Elohim ni awọn atumọ ede tumọ si Ọlọrun lati inu ede Heberu wa). Awọn olufọkansin lati ayebaye ti gbiyanju lati ṣe apejuwe orukọ ti a pe ni Elohim, ṣugbọn gẹgẹ bi Ọlọrun ti kara Rè̩, bakan naa ni kò ṣe e ṣe fun ẹnikẹni lati ṣe alaye rè̩, ni kikún. Orukọ yii jẹ ọkan ninu awọn orukọ ti Ẹmi Mimọ fi maa n pe Ọlọrun nigba ti iṣẹ ti Ọlọrun ran ba jé̩ ti gbogbo aye lapapọ. O n fi ohun ti Ọlọrun jẹ ati ohun gbogbo ti O n ṣe, ohun gbogbo ti O ti ṣe ati eyi ti yoo ṣe han. Ọgbẹni kan ti o jafafa ninu imọ ede ti a fi kọ Bibeli ṣe alaye yii fun ni nipa orukọ Elohim bayii pe:
“Ẹni ayeraye, ti o dá wà gedegbe, ti a kò dá; Oun paapaa ni i ṣe orisun ero ati iṣe Rè̩ lai si iranlọwọ lati ọdọ ẹnikẹni, Adanikan paṣẹ; Ẹni-Mimọ julọ; Ọlọkan-rirọ julọ; Olorisun ẹmi; ifẹ Rẹ lati ṣoore kò loṣuwọn, ifẹ Rẹ lati ṣe-ni loore kò loṣuwọn, Oloootọ ati Ẹni pipe julọ, Ẹlẹda ohun gbogbo, Olugbéró ohun gbogbo; Ẹni ti ayọ Rè̩ ko lopin nitori ti pipe Rè̩ kò loṣuwọn; Ẹni ti o to tan titi ayeraye, ti ko si ni fi ohunkohun ti o da ṣe; Ẹni ti a ko le diwọn titobi Rè̩, Awamaridi Olodumare; Oun nikan ṣoṣo ni O mọ ara Rẹ tán, nitori pe Ẹni ti titobi Rè̩ jẹ awamaridi nikan ni o le mọ ara Rè̩ tán. Ni kukuru Oun ni Ẹni ninu awamaridi ijinlẹ ọgbọn Rè̩ ti ko le ṣe aṣiṣe tabi ki a tan An jẹ, Ẹni ninu ailoṣuwọn inu rere Rè̩ ti ko le ṣe ohunkohun yatọ si eyi ti o jẹ ododo, eyi ti o tọna, ati eyi ti o jẹ inu rere titi ayeraye.”
Bi Ẹmi Mimọ ṣe yan awọn orukọ meji ti a fi pe Ọlọrun ninu ẹsẹ kukuru yii, “OLUWA Oun ni Ọlọrun” jé̩ ohun ti o jọ ni loju. S̩ugbọn awọn ohun pataki miiran wa ti awọn orukọ naa fi ye wa yékéyéké ninu ẹkọ ti a n kọ yii.
Ninu ẹkọ ede Heberu a ri i pe a fi orukọ Jehofa pe ẹni kan ṣoṣo ṣugbọn Elohim ju ẹyọ ẹni kan ṣoṣo lọ. Eyi fi han wa pe Ọlọrun wa jẹ ọkan lọna kan, O si tun ju bẹẹ lọ. Bi a ba fi eyi sọkan bi a ti n ṣe ayẹwo Iwe Mimọ a o ri i pe ẹni ti o ju ọkan ni Ọlọrun ṣugbọn ọkan ṣoṣo ni ní iwa. Nitori pe bi Ẹmi Mimọ ti ṣe yan awọn orukọ wọnyi ko ni abuku, o fi han fun ni pe ẹkọ Mẹtalọkan jé̩ otitọ, nitori bi ẹkọ yii bá jé̩ èké, awọn orukọ naa yoo tako ara wọn. Nitori naa a le ri i ninu ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun kukuru yii pe ọkan ni Ọlọrun wa i ṣe ṣugbọn ẹni mẹta ninu ọkan ni.
Ẹri nipa Mẹtalọkan
Awọn ẹri miiran ti o daju wà ti o fi otitọ nla ti Mẹtalọkan Mimọ han fun ni lai si tabitabi. Ni ẹsẹ kin-in-ni ninu Bibeli, Elohim ti a lo nibẹ fi han pe Jesu Kristi ati Ẹmi Mimọ wa ni iṣọkan pẹlu Ọlọrun Baba ninu iṣẹ dida aye (Johannu 1:3; Kolosse 1:16; 1Kọrinti 8:6; Efesu 3:9; Heberu 1:1, 2). A tun kà pe ni atetekọṣe Elohim wi pe, “Jẹ ki a dá enia li aworan wa” (Gẹnẹsisi 1:26). Ẹmi Mimọ kò le ṣe aṣiṣe ninu ọrọ sisọ, nitori naa a le rii nipa eyi pe Mẹtalọkan ki i ṣe ẹni kan ṣoṣo pere.
Ninu iran Isaiah nipa Oluwa Jehofa, o gbọ ti serafu n kigbe ekinni si ekeji wi pe, “Mimọ, mimọ, mimọ li OLUWA awọn ọmọ-ogun” (Isaiah 6:3). Awọn akẹkọọ ati ìjìmì ninu ẹkọ Bibeli fi ye ni wi pe iyin ilọpo mẹta ni iyin yii jẹ.
Nihin yii a tun ri i pe orukọ Jehofa ni a lo; nitori nibikibi ti gbogbo lẹta ti a fi tẹ orukọ OLUWA tabi ỌLỌRUN ninu Bibeli ti ede oyinbo (gẹgẹ bi ọba Jakọbu ti fi aṣẹ sii) ba jẹ lẹta nla gàdàgbà-gàdàgbà, Jehofa ni eyi duro fun ni ede Heberu. Bi o ba jẹ pe lẹta iṣaaju nikan ni a lo lẹta gàdàgbà fun, fun apẹẹrẹ Oluwa ninu Isaiah 6:1, Adonai ni eyi duro fun ni ede Heberu. Nigba ti a ba fi Adonai tabi Oluwa pe ẹnikẹni tabi ẹni kan ninu Mẹtalọkan, o fi han pe ẹni ti a pe bẹẹ jẹ olohun tabi oluwa ẹlomiiran. Ohun miiran ti o jọ ni loju ti a kò si gbọdọ gbagbe ni pe a saba maa n fi Adonai pe ẹni ti o ju ẹyọ kan lọ, gẹgẹ bi olohun tabi oluwa ohun kan, o si fi han wi pe Ẹni ti o ju ẹyọ kan ni oluwa ohun naa, eniyan tabi orilẹ-ede.
Iyin ilọpo mẹta kan naa ti Isaiah gbọ lati ẹnu awọn ẹda Ọrun wọnni ni o tun ti ẹnu awọn ẹda alaaye ti o wà niwaju Itẹ Ọlọrun jade (Ifihan 4:6-11). A ri i pe awọn ẹda alaaye wọnyi ati awọn agbaagba mẹrinlelogun ti Johannu Ayanfẹ ri, jẹ ẹgbẹ awọn ẹni irapada tabi awọn eniyan mimọ ti a ti palarada (Ifihan 5:9). Lakotan a le ri i pe awọn angẹli ati awọn ẹda Ọrun ati awọn ẹni irapada -- awọn ti o ni ipin ninu Ajinde Kin-in-ni – gbogbo wọn ni o jumọ yin iyin ilọpo mẹta yii ninu ijọsin wọn. Dajudaju ohun pataki kan wà nidi yiyan iru ọna bayii lati maa fi iyin hàn lati ẹnu gbogbo awọn ti yoo yin Ọlọrun ni Ọrun!
Bi kò ba si Mẹtalọkan Mimọ, Ẹmi Mimọ kò ni ṣe aapọn lati fara balẹ yan iru ọna iyin bayii ti eniyan le gba fi wi pe, a n fi iyin fun Mẹtalọkan. Iyin ẹẹkan ṣoṣo to bi kò ba si Mẹtalọkan. Bi iruju ba wa pe ohun iyin kan ṣoṣo kò to, a le beere nigba naa pe eredi rè̩ ti a fi yan mẹta? Bi ẹyọ kan kò ba to, n jẹ a le gba pe mẹta tó? Idahun wa ni pe, meje kò ha ni dara ju lọ nitori pe meje ni a n lo ninu Iwe Mimọ lati fi ohun pipe han? Bi o ba ṣe pe a lo iyin ilọpo mẹta nitori pe ẹyọ kan ṣoṣo kò to, awọn ti o n ṣiyemeji ẹkọ Mẹtalọkan ha n wi fun ni nipa eyii pe Ọlọrun kò ni ẹtọ si iyin wa ni ẹkunrẹrẹ?
S̩ugbọn ni ṣiṣe aṣaro lori iran Isaiah, ki i ṣe kiki pé ọrọ yii mu ọgbọn wá nikan ni a rọ mọ lati kọ wa ni ẹkọ pe Mẹtalọkan ju Ẹni kan ṣoṣo lọ. Johannu Ayanfẹ ṣe atunwi ọrọ kan naa ti a sọ fun Isaiah o si fi eyi kun un pe, “Nkan wọnyi ni Isaiah wi, nitori o ti ri ogo rè̩, (Jesu) o si sọrọ rè̩ (Jesu)” (Johannu 12:37-41). Ati pẹlu ninu Iṣe Awọn Apọsteli a ka a pe Ẹmi Mimọ ni o sọ awọn ọrọ ti Isaiah gbọ (Iṣe Awọn Apọsteli 28:25-27). Nitori naa a le ri i pe nigba ti Isaiah “ri Oluwa” o ri Ọlọrun Mẹtalọkan; nitori o ri Ọlọrun lori Itẹ Rè̩, o si ri Jesu ninu ọlanla ogo Rẹ, o si gbọ ohun Ẹmi Mimọ. Pẹlupẹlu Ọlọrun sọrọ ni ipari iran naa o si beere ibeere yii pe, Tali Emi o rán, ati tani o si lọ fun wa?” Bi o ba jẹ pe Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà ninu Ọlọrun eyii yoo jẹ pe a mọọmọ ṣi wa lọna nipa yiyan ọrọ ti o n sọ nipa eniyan pupọ ati ẹni kan ṣoṣo ninu gbolohun ọrọ kan naa. Aṣiṣe kò si nihin nitori Ẹni Mẹtalọkan ni Isaiah ri ti o si gbọ ohun Rẹ.
Ẹri Miiran si i ninu Majẹmu Laelae
A tọka si awọn ẹri miiran lati fi han wa pe yiyan iyin ilọpo mẹta ko ṣeeṣi ri bẹẹ, ko si ohun miiran ti o si n fi han fun ni yatọ si wi pe Ẹni Mẹta ni o papọ ninu Mẹtalọkan.
Ire ti Ọlọrun fi fun Mose, lati fi le awọn olori alufa lọwọ jé̩ ilọpo mẹta ninu igbekalẹ rè̩. Eyi jẹ ohun ti o jọ ni loju pẹlu. Ọlọrun sọ bayii pe, “Bayi li ẹnyin o ma sure fun awọn ọmọ Israẹli; ki ẹ ma wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o busi i fun ọ, ki o si pa ọ mọ: Ki OLUWA ki o mu oju rè̩ mọlẹ si ọ lara, ki o si ṣānu fun ọ: Ki OLUWA ki o ma bojuwò ọ, ki o si ma fun ọ ni alafia” (Numeri 6:23-26). A le ṣe akiyesi pe igba mẹta ni a darukọ Jehofa, otitọ yii, pẹlu otitọ pe Jehofa jẹ orukọ ti a n lo fun Ẹni kan ṣoṣo fi han pe Ẹni Mẹta ni o wa ninu Ọlọrun Mẹtalọkan. Nitori Ẹni kọọkan ninu Mẹtalọkan sure ti o yatọ si ara wọn fun awọn eniyan Ọlọrun nipa lilo orukọ Majẹmu ni.
Ẹri Mẹtalọkan lati inu Majẹmu Titun
S̩e aṣaro lori awọn wọnyi pẹlu, ninu eyi ti a tun lo anfaani yii lati tẹ orukọ Ẹni mẹtẹẹta ti ó wà ninu Mẹtalọkan Mimọ pẹlu tadawa dudu ranran: Bi awọn Apọsteli ti n ṣe oore-ọfẹ fi Ẹni Mẹta han kedere, nitori o lọ bayii, “Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa ati ifẹ Ọlọrun, ati idapọ ti Ẹmi Mimọ, ki o wà pẹlu gbogbo nyin” (2 Kọrinti 13:14). Ọna ṣi silẹ fun awọn eniyan mimọ Ọlọrun, nipasẹ Kristi, “nipa Ẹmi kan sọdọ Baba” (Efesu 2:18); a si n fun wa ni ibukun oore-ọfẹ ati alaafia “lati ọdọ ẹniti o mbẹ, ti o si ti wà, ti o si mbọwá; ati lati ọdọ awọn Ẹmí meje ti mbẹ niwaju ité̩ rè̩; ati lati ọdọ Jesu Kristi; ẹlẹri olõtọ, akọbi ninu awọn okú” (Ifihan 1:4, 5). A kò si gbọdọ gboju fo ẹsẹ ọrọ Ọlọrun nì ti o rọrun lati ye ni ti o sọ bayii pe, “ẹni mẹta li o njẹri li ọrun, Baba, Ọrọ ati Ẹmi Mimọ: awọn mẹtẹta yi si jasi ọkan” (1Johannu 5:7). A fi ọrọ yii ye ni kedere ni ibomiiran ninu Iwe Mimọ, nibi ti a gbe fi iṣọkan pipe ti ó wà laarin Mẹtalọkan han fun ni ati pe Jesu Kristi tikara Rẹ ni Ọrọ naa (Ka Johannu 1:1-34).
Bakan naa ni awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wọnyi rọrun lati ye ni: Jesu wi pe, “Bi ẹnyin ba fẹran mi ẹ ó pa ofin mi mọ. Emi ó si bère lọwọ Baba on ó si fun nyin li Olutunu miran, ki o le mā ba yin gbé titi lailai” “Olutunu naa . . . ni Ẹmi Mimọ” (Johannu 14:15, 16, 26). Ki Kristi to wa si aye o wi bayii pe “Ẹ sunmọ ọdọ mi, ẹ gbọ eyi; lati ipilè̩ṣẹ Emi ko sọrọ ni ikọkọ; lati igbati o ti wà, nibẹ ni Mo wà; ati nisisiyi Oluwa Jehofa, (Adonai Jehofa) on Ẹmi rè̩ li o ti rán mi” (Isaiah 48:16). Onipsalmu sọ bayii pe, “Iwọ li Ọmọ mi; loni ni mo bi ọ” (Orin Dafidi 2:7), ati pe “OLUWA wi fun Oluwa mi” (Orin Dafidi 110:1). A sọ fun wa ninu Majẹmu Titun pe awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti ó wà ninu Psalmu yii tọka pato si Ọlọrun Baba ati Jesu Kristi Ọmọ Rè̩ (Matteu 24:41-45; Heberu 1:1-5).
Ẹri lati inu Akọsilẹ awọn Woli
Ọkunrin ọlọgbọn nì ni imọ nipa ijinlẹ Mẹtalọkan, nitori ti o wi pe “Tali o ti gòke lọ si ọrun, tabi ti o si sọkalẹ wá? tali o kó afẹfẹ jọ li ọwọ rè̩? tali o di omi sinu aṣọ; tali o fi gbogbo opin aiye le ilẹ? Orukọ rè̩ ti ijẹ, ati orukọ ọmọ rè̩ ti ijẹ bi iwọ ba le mọ ọ?” (Owe 30:4). Dafidi sọ bayii pe, “Kọ mi lati ṣe ohun ti o wù ọ: nitori iwọ li Ọlọrun mi: jẹki ẹmi rẹ didara ...” (Orin Dafidi 143:10). A sọ fun wa pe Ẹmi Ọlọrun nràbàbà loju omi ni atetekọṣe ati pe Oun si n ba eniyan jà nitori è̩ṣẹ wọn ni kutukutu ọjọ igba nì (Gẹnẹsisi 1:2; 6:3).
Awọn ẹlomiiran ti o ni imisi Ọlọrun ti kọ akọsilẹ nipa Ẹni kọọkan ninu Mẹtalọkan ati iṣẹ wọn. “Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ki iṣe ẹlomiràn ... Emi o tú ẹmi mi jade si ara enia gbogbo” (Joẹli 2:27, 28). “Kì iṣe nipa ipá, kì iṣe nipa agbara, bikoṣe nipa Ẹmi mi, ni OLUWA awọn ọmọ-ogun wi” (Sekariah 4:6).
Ẹri nipa Ilana Iribọmi
A o fi ọpọlọpọ ẹri ti o daniloju wọnyii ati awọn asọtẹlẹ ti a ti mẹnukan ati awọn miiran ti a kò ni aye to lati mẹnukan nihin silẹ ni apa kan lati ṣe ayẹwo awọn iṣẹlẹ kan ninu Bibeli fun awọn ẹri diẹ siwaju sii. S̩e aṣaro nipa iribọmi Jesu, nigba ti Ẹmi Ọlọrun ba le E, Ọlọrun Baba si sọrọ lati Ọrun wa wi pe “Eyi ni ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dun si gidigidi” (Matteu 3:16, 17). Aṣẹ ikẹyin ti Jesu pa fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ ni pe, “Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ” (Matteu 28:19).
Awọn miiran ṣi ilana iribọmi ti Kristi fi lelẹ tumọ nitori pe wọn gba pe ilana naa kò fi Ẹni Mẹta han bi kò ṣe Ẹni kan ṣoṣo ẹni ti o n jẹ orukọ Mẹtẹẹta ti a dá wọnyii. Wọn fi idi ọrọ wọn mulẹ nipa didá awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun kan tumọ, lai mu wọn lo pẹlu awọn ẹsẹ ọrọ ti o ṣiwaju ati eyi ti o tẹle e, lati ni oye kikun nipa ohun ti a n sọ nibẹ; wọn si wi pe orukọ Jesu nikan ni a gbọdọ maa fi ṣe iribọmi. Awọn miiran jẹwọ pe wọn gba ẹkọ Mẹtalọkan, wọn si gba a gbọ, ṣugbọn nitori awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wọnyi, wọn wi pe a gbọdọ maa ṣe iribọmi ni orukọ Jesu Kristi Oluwa nikan. Awọn ijiyan wọnyii já si lilọ Ọrọ Ọlọrun, wọn si lodi si ẹkunrẹrẹ ẹkọ ti o yè kooro ti o si já gaara.
Ni fifi ilana iribọmi ti Kristi fi lelẹ ati awọn ẹri miiran gbogbo ninu Ọrọ Ọlọrun we ara wọn, a rii gbangba pe o kọ ni ni Mẹtalọkan. Awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun miiran ti o sọ wi pe ki a maa baptisi ni orukọ Jesu Kristi Oluwa kò lodi rara si awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun iyoku bi a ba tumọ rè̩ lai gboju fo ohun ti o mu ki a sọ ọ ni akoko ti a sọ ọ. Ayẹwo Iṣe Awọn Apọsteli 2:38 ati 10:48 fi han pe awọn Apọsteli nipa imisi Ẹmi Mimọ, n kọ ni pe Ọlọrun ni Kristi i ṣe, o si jẹ ohun pataki ti wọn fẹ ki o fidi mulẹ ṣinṣin lọkàn awọn ti wọn n waasu fun nigba naa.
Baptismu ti Johannu Baptisti jẹ baptismu fun ironupiwada. Baptismu ti Jesu fi ilana rè̩ lelẹ yatọ si eyi. O jẹ ẹri si igbagbọ awọn ti o gba Kristi gbọ nigba majẹmu titun o si jẹ apẹẹrẹ didi okú si è̩ṣẹ ati ajinde wa lati maa rin ninu ọtun iwa. O jẹ apẹẹrẹ ikú, isinku ati ajinde Jesu. Nitori eyi, awọn Apọsteli tẹnumọ iribọmi ti Kristi palaṣẹ gbọnmọ-gbọnmọ yatọ si baptismu ti Johannu. Ni akoko iribọmi Johannu Baptisti, awọn onirobinujẹ-ọkan ti ó fẹ ni igbala a maa wa fun iribọmi fun ironupiwada. S̩ugbọn ni igbọran si aṣẹ Jesu, a n ṣe iribọmi fun awọn ti o ti ri igbala ni ijẹrisi iṣẹ igbala ti o ti ṣe ninu ọkan wọn: eyii si tun jẹ apẹẹrẹ iku ati ajinde Oluwa wọn. Nigba ti awọn Aposteli si sọ pe ki a maa ṣe iribọmi fun awọn wọnyii ni orukọ Jesu Kristi Oluwa, wọn kò pa ilana iribọmi ti Kristi fi lelẹ fun wọn tì si apa kan. Kókó ohun ti awọn Apọsteli n sọ ni pe ki awọn ti wọn n waasu fún ṣe iribọmi ti Jesu, ki i si ṣe iribọmi fun ironupiwada gẹgẹ bi eyi ti Johannu Baptisti n ṣe fun ni.
Ọpọlọpọ ẹsẹ miiran ni a gbe le ri ibi ti Kristi gbe sorọ nigba ti O wà ni aye, nipa Baba Rè̩ ti o wà ni Ọrun, iha ti wọn kọ si ara wọn, nipa irẹpọ ati iṣọkan ti o wà laarin wọn ati nipa ti Ẹmi Mimọ ti o ti ọdọ wọn sọkalẹ wá.
Iṣọkan Mẹtalọkan
Lẹyin ti a ti ṣe ayẹwo awọn ẹri Ọrọ Ọlọrun ti o fi idi otitọ ti a ko le jiyàn nipa Mẹtalọkan mulẹ ṣinṣin, nisisiyi a o tun ṣe aṣaro lori iṣọkan Mẹtalọkan, nitori pe kò tọna lati lero pe Mẹtalọkan jẹ Ọlọrun mẹta ti o da duro gedegbe gẹgẹ bi o ti lodi lati lero pe Ọlọrun Mẹtalọkan jẹ Ẹni kan ṣoṣo pere.
Ijinlẹ awamaridi ni eyi jẹ. Nihin ni òye kukuru ẹda gbe kuna lati le mọ gbogbo awọn otitọ ti a gbe kalẹ niwaju rè̩. Nihin ni igbagbọ ati igbẹkẹle gbọdọ dipo alaye nitori bi o tilẹ jẹ pe “ohun rè̩ ti o farasin .... a ri wọn gbangba, a nfi oye ohun ti a da mọ ọ, ani agbara ati iwa-Ọlọrun rè̩ aiyeraiye” (Romu 1:20), a ko ti i fun wa ni agbara lati ridi tabi lati ṣe awari ohun pupọ ninu nnkan wọnni ti a n ri loju kòrókòró. Eyi jẹ otitọ ti awa ẹda faramọ nipa awọn ohun ti ara ninu aye. Ki ni ṣe ti ki yoo ri bẹẹ nipa awọn ohun wọnni ti i ṣe ti ẹmi?
Kò ṣe e ṣe lati sọ nipa iṣọkan Mẹtalọkan ni kikun. Bi a ba tilẹ kó gbogbo ọrọ w nni ninu ede wa ti o n sọ nipa irẹpọ ati iṣọkan papọ, wọn yoo fétè pupọ lati ṣe apejuwe iṣọkan ti ó wà laaarin awọn Ẹni Mẹta Mimọ. Gbogbo ohun ti awọn ọjọgbọn ni iwọn bi ọgọrun iran sẹyin sọ lati ṣe apejuwe iṣọkan yii kò tayọ iriran baibai ninu awojiji.
Ninu aṣaro tabi igbekalẹ miiran gbogbo a le ri awọn ohun ti o fara jọ ara wọn ti o le la wa lóye lati ni imọ ohun ti a fi siwaju wa. S̩ugbọn kò si ohun ti o dabi Ọlọrun. Bẹẹ ni kò si ṣe e ṣe lati ri ohun ti a le foju ri ti o le fi awamaridi iṣọkan Ọlọrun tabi ti Mẹtalọkan yé ẹda, nitori ninu Rè̩ nikan ṣoṣo ni pipe ti ko lẹgbẹ wà. Kò si ohun kan ni gbogbo agbaye ti o dá yatọ gedegbe bayii, ti ẹwa yii n gbe inu rè̩ ti o si jẹ awamaridi bayii. Eyi pẹlu jé̩ ẹri nipa agbara Ọlọrun.
Apẹẹrẹ Iṣọkan Ọlọrun lati Inu Bibeli
Nigba ti a n kọ awọn ara Efesu nipa ifẹ ti awa ẹda ni lati ni si ara wa, paapaa ju lọ iru ifẹ atinuwa ati ẹmi ibanikẹdun ti o gbọdọ wà, ani ti o si maa n wà laaarin ọkọ ati aya Onigbagbọ, Paulu Apọsteli fi iru iṣọkan yii wé iṣọkan iyanu ti o wà laaarin Kristi ati Ijọ Rè̩. Johannu Apọsteli paapaa tun kọ ni ni ẹkọ ti o fara jọ eyi nipa ifẹ ti o gbọdọ wà ani ti o maa n wà laaarin awọn ọmọ Ijọ Kristi; nitori ti o sọ fun wa pe Jesu gbadura pe “ki gbogbo wa ki o le jẹ ọkan” – Ki a le “ṣe wa pe li ọkan” -- gẹgẹ bi Oun ti wà ninu Baba ti Baba si wà ninu Rè̩. S̩ugbọn a le rii pe Ẹmi Mimọ paapaa, nipa lilo apẹẹrẹ tabi apejuwe, kò le kọ ni ni gbogbo ẹkọ iṣọkan Mẹtalọkan ni ẹkunrẹrẹ; nitori pe kò le ri ohunkohun ni aye yii ti o le lò gẹgẹ bi apẹẹrẹ lati mu ki gbogbo otitọ naa ye ọkàn ope wa ni kikun.
Ẹmi Mimọ fi iṣọkan ti o wà laaarin ọkọ ati aya Onigbagbọ ṣe apẹẹrẹ lati fun wa ni oye ati imọlẹ diẹ kinun nipa awamaridi ohun ijinlẹ yii nipa fifi iṣọkan Ọlọrun ati ti Kristi wé iṣọkan ati irẹpọ ti o wa laarin ẹda, eyi ti awa tikara wa ko ni oye rè̩ ni kikun. Njẹ bi a kò ba ni imọ tabi òye kikun nipa ohun wọnni ti o ti di ara fun ẹni kọọkan wa, ani ti o yi wa ka ni iha gbogbo, bawo ni a ha ṣe le ni ero pe a le ni òye tabi imọ pipe nipa ohun ijinlẹ awamaridi ti o tayọ imọ tabi awari ẹda lọ? Kò ṣe e ṣe. S̩ugbọn ọpẹ ni fun Ọlọrun pe kò di igba ti a ba ni iru imọ ijinlẹ yii ki a to le jẹ alabapin ibukun wọnni ti a n fi fun ni nipasẹ rè̩ ati nitori rè̩.
O tó fun wa lati mọ pe ni ọjọ kan, nigba ti a ba ká iboju ni kuro, awọn awamaridi ohun ijinlẹ wọnyii yoo ṣipaya fun wa kedere. Nigba naa ni awa yoo mọ gẹgẹ bi a ti mọ wa, a o si dabi Rè̩, Ẹni ti O fi ara rè̩ fun wa ki awa ki o le ni iye, ki a si ni i lọpọlọpọ.
Questions
AWỌN IBEERE- Sọ diẹ ninu awọn orukọ ti a fi n pe Kristi ninu Bibeli.
- Tọka si diẹ ninu awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti o fi idi rẹ mulẹ pé Ọmọ Ọlọrun ni Kristi i ṣe.
- Tọka si awọn ẹri diẹ lati inu Ọrọ Ọlọrun ti o fi han pe Ọlọrun ju Ẹni kan ṣoṣo lọ.
- Ki ni ṣe ti ọmọ-eniyan fi gba ẹkọ ti o sé̩ Mẹtalọkan Mimọ gbọ?
- Sọ ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti o fun ọ ni aṣẹ lati sọ pe Ẹmi Mimọ jẹ Ẹni kan ninu Mẹtalọkan.
- Ki ni ilana iribọmi ti Kristi fi lelẹ? Ki ni o n tọka si?
- S̩e alaye ni ọrọ ara rẹ ohun ti o ṣe pataki ninu iran ti Isaiah ri, awọn ẹkọ Bibeli wo ni o kọ ni, idi ẹkọ wo ni o fi mulẹ.
- Sọ nipa iribọmi Jesu, ati bi a ti fi idi ẹkọ Mẹtalọkan mulẹ nipasẹ rè̩.
- Ipo nla wo ni a fi fun Kristi ninu aṣekadii eto irapada? Àyè wo ni O ti lo sẹyin? Àyè wo ni O nlo lọwọlọwọ? Àyè wo ni o kù fun Un lati bọ si?
- Ki ni iṣẹ Ẹmi Mimọ? Ọna wo ni iṣẹ Rè̩ fi jẹ mọ eto irapada?