Lesson 263 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ore-ọfẹ Ọlọrun ti nmu igbala fun gbogbo enia wá ti farahan, O nkọ wa pe, ki a sé̩ aiwa-bi-Ọlọrun ati ifẹkufẹ aiye, ki a si mā wà li airekọja, li ododo, ati ni iwa-bi-Ọlọrun ni aiye isisiyi” (Titu 2:11, 12).Cross References
I Isọdimimọ Patapata
1 Isọdimimọ a maa fa iṣọkan wá saarin awọn Onigbagbọ, Johannu 17:21-23; Heberu 2:11
2 Kristi kú lati sọ Ijọ di mimọ, Efesu 5:25-27; Johannu 17:9, 16, 17, 20; Heberu 13:12
3 Isọdimimọ wà fun awọn Onigbagbọ ni aye isisiyi, Titu 2:11-14; Luku 1:75
II Igbesi-aye Mimọ
1 Awọn eso Ẹmi a maa fara han ni igbesi-aye ti a sọ di mimọ, Galatia 5:22, 23; Efesu 5:9; 2 Peteru 1:5-7
2 Bọ “ogbologbo ọkunrin ni” silẹ, Efesu 4:17-22; Kolosse 3:5-9
3 Gbe “ọkunrin titun” ni wọ, Efesu 4:23-32; Kolosse 3:1-4, 10-15
Notes
ALAYÉẸṣẹ
Nigba ti a dá Adamu ni Ọgba Edẹni, a dáa ni aworan Ọlọrun. O jẹ ẹni pipe, ero tabi ifẹ lati ṣe ibi kò si ninu rè̩. Gbogbo ero ati ete rè̩ ni o jẹ mimọ ati pipe. A da a “li ododo ati li iwa mimọ otitọ” (Efesu 4:24). Ki i ṣe idibajẹ ọkàn bi kò ṣe idanwo ti ode ara ni o mu un ṣe ifẹ inu ara rè̩ lati ṣe aigbọran si aṣẹ Ọlọrun.
Ikú
Nigba ti Adamu ṣè̩, o kú ikú ẹmi: o wà ni iyapa si Ọlọrun: ilepa rè̩ gẹgẹ bi eniyan di idibajẹ, ero rè̩ ati ifẹ rè̩ si di ẹgbin. Lati igba naa lọ ni gbogbo iru ọmọ Adamu ti gbé aworan obi wọn iṣaaju wọ. Kaka ki a bi wọn ni ẹni mimọ ati olododo a bi wọn ninu ẹṣẹ. “Kiyesi i, ninu aiṣedede li a gbe bi mi: ati ninu è̩ṣẹ ni iya mi si loyun mi” (Orin Dafidi 51:5). “Nitori gẹgẹ bi è̩ṣẹ ti ti ipa ọdọ enia kan (Adamu) wọ aiye, ati ikú nipa è̩ṣẹ: bḝni ikú si kọja sori enia gbogbo, lati ọdọ ẹniti gbogbo enia ti dè̩ṣẹ” (Romu 5:12).
Iṣẹ Ara ati Isọdimimọ
Ẹda ẹṣẹ, eyi ti gbogbo wa jogun lati ọdọ Adamu, a maa sún eniyan lati dẹṣẹ ati lati huwa ẹṣẹ. Nitori naa ẹṣẹ pin si ipa meji: irugbin ẹṣẹ, eyi ti a bi wa bi, ati ẹṣẹ dida, ani awọn ẹṣẹ wọnni ti a da lẹyin ti a ba ti dagba tó ẹni ti o ni òye ẹṣẹ. Irugbin ẹṣẹ yii ni a saba maa n pe ni “ẹda Adamu,” “ẹṣẹ abinibi,” “ogbologbo ọkunrin nì,” “ara ẹṣẹ,” ati “ọkunrin ti ara.” Nigba ti ẹlẹṣẹ ba wá sọdọ Ọlọrun pẹlu ironupiwada tootọ, ti ó si ri igbala, a o si dari ẹṣẹ rè̩ ji i, eyi yii ni pe a dari gbogbo iwa ẹṣẹ ti o ti hù ji i nipasẹ Ẹjẹ Jesu, a si ti sọ ogbologbo ọkunrin nì di alailagbara. Bi o tilẹ ti jẹ pe a de e ni igbekun – a kan an mọ agbelebu – ogbologbo ọkunrin yii kò le parun afi nipa ibuwọn Ẹjẹ Jesu lẹẹkeji. A kan “ogbologbo ọkunrin nì” mọ agbelebu nigba ti a ba ri igbala, ṣugbọn yoo wa laaye lori agbelebu titi isọdi-mimọ yoo fi pa ara ẹṣẹ run ti yoo si sọ ọ di okú. “A kàn ogbologbo ọkunrin wa mọ agbelebu pẹlu rè̩, ki a le pa ara è̩ṣẹ run” (Romu 6:6).
Isọdi-mimọ ni iwẹnumọ ọkàn ati inu nipa Ẹjẹ Jesu. Ẹṣẹ abinibi yoo parun a o si wẹ ọkàn mọ kuro ninu ipo ibajẹ, ọkàn yoo si pada bọ si mimọ ti a daa mọ eniyan ni atetekọṣe. Sibẹsibẹ ara kò bọ lọwọ ailera ẹda, ero wa pẹlu kò bọ lọwọ aṣiṣe ati idanwo, ṣugbọn a ti sọ ọkàn di mimọ laulau, o si ni ipa lati kọjuja si ẹṣẹ. Nihinyii a le ri iyatọ ti o wa laaarin pipe Adamu ati pipe Onigbagbọ. Ki awọn obi wa iṣaaju to ṣubu, ọkan, ẹmi, èrò ati ara wọn jẹ pipe. A kò sọ ẹda wọn di eeri ati idibajẹ lọnakọna gẹgẹ bi ara wa. S̩ugbọn nigba ti a ba sọ wa di mimọ ẹda wa a di mimọ, ọkàn wa a si di funfun ati mimọ. A kò di pipe ni iru ọna kan naa ti Adamu gba jé̩ pipe ṣaaju iṣubu ti kò mọ ẹṣẹ rara. Dipo eyi, a wa ni pipe ti a n pe ni pipe Onigbagbọ.
Bibeli fi ye wa kedere pe isọdi-mimọ ki i ṣe fun ẹlẹṣẹ. Isọdi-mimọ wà fun awọn ẹni-irapada --Ijọ. “Ẹnyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya nyin, gẹgẹ bi Kristi si ti fẹran Ijọ, ti o si fi ara rè̩ fun u; ki on ki o le sọ ọ di mimọ lẹhin ti a ti fi ọrọ wẹ ẹ mọ ninu agbada omi. Ki on ki o le mu u wá sọdọ ara rè̩ bi ìjọ ti o li ogo li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni; ṣugbọn ki o le jẹ mimọ ati alaini àbuku” (Efesu 5:25-27). Jesu gbadura fun isọdi-mimọ awọn ọmọ-ẹhin Rè̩. “Emi kò gbadura fun araiye, ṣugbọn fun awọn ti iwọ ti fifun mi, . . . Nwọn ki iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi ki ti iṣe ti aiye. Sọ wọn di mimọ ninu otitọ: otitọ li ọrọ rẹ” (Johannu 17:9, 16, 17). Eyi fi han fun ni nigba naa pe, isọdi-mimọ jé̩ iriri ti o tẹle igbala.
Ifararubọ
Pẹlu iriri isọdi-mimọ ninu ọkàn ati ọkunrin ti inu ti o mọ ti o si bọ lọwọ ẹṣẹ, Onigbagbọ ni anfaani lati fi ara rè̩ rubọ “fun Ọlọrun li ẹbọ āye, mimọ, itẹwọgbà,” eyi ti i ṣe iṣẹ-isin rè̩ ti o tọna (Romu 12:1). Bi o tilẹ jẹ pe ohun ti o rọrun ni fun ẹni ti a sọ ọkàn rè̩ di mimọ lati sin Ọlọrun, ailera ara wà sibẹ, o si n gbe inu aye ti o kun fun ẹṣẹ, nitori naa o di dandan fun un lati maa fi aye rè̩ rubọ ati lati maa jọwọ ara rè̩ lọwọ fun Ọlorun ki o le wà “ni mimọ iwa, ati li ododo niwaju rè̩” (Luku 1:75) ni ọjọ aye rè̩ gbogbo. “Nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti nmu igbala fun gbogbo enia wá ti farahan, o nkọ wa pe, ki a sé̩ aiwa-bi-Ọlọrun ati ifẹkufẹ aiye, ki a si mā wa li airekọja, li ododo, ati ni iwa-bi-Ọlọrun ni aiye isisiyi” (Titu 2:11, 12).
Idanwo
Sibẹsibẹ o ṣe e ṣe fun Eṣu lati gba ibode oju ati ero-ọkàn dán ẹni ti o ni isọdi-mimọ wò. O fi gbogbo ijọba aye yii han Jesu, ati gbogbo ogo rè̩, ṣugbọn Jesu kọjuja si i. Awa pẹlu ni agbara lati kọjuja si Eṣu, “Nitoripe bi awa tilẹ nrìn ni ti ara, ṣugbọn awa kò jagun nipa ti ara: (nitori ohun ija wa ki iṣe ti ara, ṣugbọn o li agbara ninu Ọlọrun lati wó ibi giga palẹ;) awa nsọ gbogbo ero kalẹ, ati gbogbo ohun giga ti ngbé ara rè̩ ga si ìmọ Ọlọrun, awa si ndi gbogbo ero ni igbekun wá si itẹriba fun Kristi” (2Kọrinti 10:3-5).
Satani a maa lo ero-ọkàn lati mú ọmọ Ọlọrun ṣina. Nigba pupọ ni Satani n gbe ero buburu wá sinu ọkàn lati dá ede-aiye-de ati aidọgba silẹ laaarin awọn ara. Isọdi-mimọ a maa fun ni ni iṣọkan ati irẹpọ eyi ti èṣu korira ti o si n sa gbogbo ipa rè̩ lati wo palẹ. Awọn ohun ija wa nipa ti ẹmi a maa fun wa ni agbara lati sọ gbogbo ero wọnyi kalẹ ati lati di awọn ero wa ni igbekun; nipa bayii ni a n kọjuja si eṣu.
Iṣọkan
“Ki nwọn ki o le jẹ ọkan ani gẹgẹ bi awa.” “Ki gbogbo nwọn ki o le jẹ ọkan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o le jẹ ọkan ninu wa.” “Ki nwọn ki o le jẹ ọkan gẹgẹ bi awa ti jẹ ọkan.” “Emi ninu wọn, ati iwọ ninu mi, ki a le ṣe wọn pe li ọkan.” Gbogbo ọrọ wọnyi ti o duro lori irẹpọ ati iṣọkan wà ninu adura ti Jesu gbà fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ (Johannu 17). Ẹ wo bi o ti ṣe pataki fun wa tó ni ode oni, lati jẹ mimọ, ki awa ki o le ni ihamọra lati kọjuja si ipinnu eṣu lati dá ipinya silẹ ki oun ba le ṣẹgun!
Idariji
“Ẹ mā farada a fun ara nyin, ẹ si mā dariji ara nyin bi ẹnikẹni bá ni è̩sun si ẹnikan: bi Kristi ti dariji nyin, gẹgẹ bḝni ki ẹnyin ki o mā ṣe pẹlu” (Kolosse 3:13). Bawo ni yoo ti dun tó bi gbogbo awọn ti n pe ara wọn ni eniyan Ọlọrun ba le ni iru oore-ọfẹ idariji yii ni kikún ninu ọkan wọn: ẹjọ wẹwẹ, ọrọ-ké̩lé̩ ati rogbodiyan kò ni si laaarin awọn eniyan Ọlọrun. Ronu nipa idariji Ọlọrun ati titobi oore-ọfẹ Ọlọrun ti o mu ki a dari ẹṣẹ wa ji wa ki a si pa gbese ti a jẹ Ọlọrun ré̩ fun wa! Kò ha tọ fun awa naa lati dariji ọmọnikeji wa! “Ati bori gbogbo nkan wọnyi, ẹ gbé ifẹ wọ, ti iṣe àmure iwa pipé. Ẹ si jẹ ki alafia Ọlọrun ki o mā ṣe akoso ọkàn nyin” (Kolosse 3:14, 15).
Paulu sọ fun awọn Heberu pe, “Ẹ mā lepa alafia pẹlu enia gbogbo, ati iwa mimọ, li aisi eyini kò si ẹniti yio ri Oluwa.” Ohun iṣoro ni fun awọn miiran lati fi alaafia bá gbogbo eniyan gbe. O rọrun fun awọn miiran lati fi alaafia bá awọn eniyan kan gbé, ṣugbọn o ṣoro fun wọn lati fi alaafia bá awọn miiran gbe. Nigba miiran o n gba pe ki a ni suuru ati ẹbun oore-ọfẹ ti o pọ jọjọ ki a tó le gbé ni alaafia pẹlu awọn miiran. Awọn kan wa ti o kún fun ija ati asọ, wọn si le sọrọ pupọ. Igba pupọ ni o jé̩ pé ohun ti kò tọ ni iru awọn eniyan bẹẹ ma n sọ. Bi ohunkohun ba wà ti wọn le sọ ni aidara nipa ẹni kan tabi ti o le jé̩ idẹkun fun un lati kó wahala baa, wọn yoo sọ ọ. Wọn yoo ṣe àyínsí, nigba pupọ wọn a si gbee gba ọna miiran. O gba pe ki a kún fun ọpọ oore-ọfẹ ati ẹbun Ọlọrun lati bá awọn eniyan bẹẹ lò. S̩ugbọn Ọrọ Ọlọrun sọ pe, “Ẹ mā lepa alaafia pẹlu gbogbo enia” – ki i ṣe eniyan diẹ, bi kò ṣe gbogbo eniyan.
Imọ-ti-ara-ẹni-nikan
Bi a ba sa ipa wa lati pa iṣọkan Ẹmi mọ ti a si n rin ni irẹlẹ ati iwa tutu pẹlu ipamọra, ti a si n fara daa fun ẹni keji wa, a o pa ninu awọn ero wa ati ọna wa tì si apa kan ki a ba le fi ọmọnikeji wa ṣaaju, nipa bẹẹ ki a le jẹ oloootọ si Ọrọ Ọlọrun.
A kò le maa gbe igbesi-aye imọti-ara-ẹni-nikan ki a si ni ifororoyan Ọlọrun ni igbesi-aye wa. A kò gbọdọ mọ ti ara wa nikan. Abuku awọn eniyan pupọ ni pé wọn jẹ anikan-jọpọn, ti ara wọn nikan ni wọn n rò, bi ohun ti wọn n fẹ kò ba si tè̩ wọn lọwọ yoo di wahala. Iru igbesi-aye bayii yatọ si igbesi-aye ti a sọ ọkàn rè̩ di mimọ, tabi ti ẹni ti o tilẹ ni idalare, ṣugbọn iṣẹ ara ati ti ẹni ti kò ni iyipada ọkàn ni yii.
Ifẹ-ọkan ti a Jọwọ Rẹ
Ẹni ti a ti rapada a maa gbe igbesi-aye ailẹṣẹ. Ikoro, irunu, ibinu, ọrọ buburu, arankan, ojukokoro, ati eke ṣiṣe yoo kuro nigba ti Kristi ba wọ inu ọkàn naa nigba ti o ri igbala. Ibinu kò ni si mọ lẹyin ti eniyan ba ri igbala. Gbongbo ẹṣẹ le fẹ maa gbe fúké̩ ninu ṣugbọn ibinu tabi irunu kò ni fara han lẹyin ti a ba ti ni idalare. Isọdi-mimọ yoo hú gbongbo ẹṣẹ yoo si wẹ ọkàn mọ. Nigba ti a ba ni isọdi-mimọ, gbogbo iṣẹ ti ara ni a n parun, a si n wẹ ọkàn ati ara mọ kuro ninu iwa ibajẹ ati ohun ti o n ṣiṣẹ ibi. S̩ugbọn ifẹ ọkàn tabi (tinu-mi-ni-n-o-ṣe) wà ti o jẹ mimọ ti kò si ni è̩ṣẹ, a si ni lati maa jọwọ rè̩ lọwọ fun Ọlọrun lojoojumọ nipa ifararubọ. A ni lati gbadura bi ti Jesu pe, “Ifẹ ti emi kọ, bikoṣe tirẹ ni ki a ṣe” (Luku 22:42). A ni lati di okú si ohun ti i ṣe ti ara ki a ba le wà laaye si Ọlọrun. Paulu wi pe, “Emi npọn ara mi loju, mo si nmu u wá sabẹ itẹriba: pe lẹhin ti mo ti wasu fun awọn ẹlomiran, nitori ohunkohun, ki emi tikarami máṣe di ẹni itanù” (1Kọrinti 9:27). “Nitori bi ẹnyin ba wà ni ti ara, ẹnyin ó kú: ṣugbọn nipa Ẹmi bi ẹnyin ba npa iṣe ti ara run, ẹnyin ó yè” (Romu 8:13). Pẹlu jijọwọ ifẹ ọkàn ẹni, pipa ohun ti a fẹ tì sapa kan ati nipa fifi ara ẹni rubọ, ọkan ti a sọ di mimọ le wi bayii pe, “A ti kàn mi mọ agbelebu pẹlu Kristi: ṣugbọn mo wà lāye, sibẹ ki iṣe emi mọ, ṣugbọn Kristi wà lāye ninu mi: wiwà ti mo si wa lāye ninu ara, mo wa lāye ninu igbagbọ Ọmọ Ọlọrun, ẹniti o fẹ mi, ti o si fi on tikararè̩ fun mi” (Galatia 2:20).
Yiyẹ Ara Ẹni Wò
Bi a ba n yẹ ara wa wò nigbakuugba ti a si n ri ikuna ara wa, ti a si sa ipa wa nipa igbagbọ ninu Ọlọrun ati Ọrọ Rè̩ lati bori awọn ikuna wa, ailera ati ainilaari wa gbogbo, Ọlọrun yoo fi ohun kan sinu wa ti yoo mu ki a di alagbara ninu Rè̩. Ohun ti o n ṣe awọn ẹlomiiran ni pe wọn kò fi ipinnu dojukọ ailera wọn ṣugbọn wọn fi aye gba a, ohun ti wọn yoo ri ni pe awọn ailera naa n gbilẹ siwaju si i. Ọlọrun kò fẹ ki a ṣe eyi. O fẹ ki a bori awọn ailera wa ni. Nipa didoju ija kọ awọn ailera wa ni a o fi ṣẹgun wọn – nipa pipa awọn ohun ti ara tì sapa kan ati jijọwọ ara wa lọwọ fun ohun ti Ẹmi – gbigbe ọkàn iyọnu wọ, iṣeun, irẹlẹ, inu tutu ati bori nkan wọnyi, ifẹ, ti i ṣe àmure iwa pipé (Kolosse 3:14).
Iwa Mimọ ti Inu
Idagbasoke igi ọpẹ bẹrẹ lati inu wá; awọn ewe ti o wà lode yoo kọ kú ki awọn ti o wà ninu ki o tó yọ jade pẹlu ẹwa. Gbongbo rè̩ yoo wọ inu ilẹ lọ titi yoo fi kan omi nisalẹ ilẹ. Eyi jé̩ apẹẹrẹ ọmọ Ọlọrun tootọ. Oun yoo maa dagba si i ninu ẹmi nipa iṣẹ ti o ti ṣe ninu ọkàn rè̩, eyi yoo si jẹ yọ sode fun ni lati ri.
Awọn ẹlomiiran a maa di kúnkún pẹlu adabọwọ irẹlẹ lati fi han pe wọn jẹ mimọ. Eyi kò lere. Ohun ti o jẹ dandan lati ni, ti a kò si gbọdọ fi falẹ, ni pe ki a pinnu lati ni isọdi-mimọ ti inu ati ifararubọ ti inu, ki a si jé̩ ki eyi fi idi mulẹ ṣinṣin ninu Ọrọ Ọlọrun. Nigba naa ni yoo hu jade, yoo so eso pipe. Bi o ba n gbiyanju lati fi ara ṣe e ni ode ara, eso kikan ni yoo so; ṣugbọn bi o ba jẹ lati inu wa ni o ti jẹ jade, eso yoo jé̩ pipe, iṣẹ-isin rẹ si Ọlọrun yoo si jé̩ pipe.
“Si jẹ ki alafia Ọlọrun ki o mā ṣe akoso ọkàn nyin, sinu eyiti a pè nyin pẹlu ninu ara kan; ki ẹ si ma dupẹ” (Kolosse 3:15).
Questions
AWỌN IBEERE- Sọ diẹ ninu awọn orukọ ti Bibeli pe ẹṣẹ abinibi.
- Fi Bibeli gbe e lẹsẹ pe isọdi-mimọ jẹ iriri ti a n ri lẹyin ti a ba ti ri igbala.
- Sọ diẹ ninu iṣẹ ti isọdi-mimọ n ṣe.
- Ki ni awọn aleebu ti a jogun nipa iṣubu ọkunrin iṣaaju nì ti a kò mu kuro nigba ti a ba ti sọ ọkàn wa di mimọ?
- Njẹ a n pa aworan Adamu run ni tabi a n tẹ ori rè̩ ba nigba ti a ba sọ wa di mimọ?
- Fi Bibeli gbe e lẹsẹ pe isọdi-mimọ wà fun awa ti ode oni.
- Darukọ awọn eso ti Ẹmi.
- Ki ni awọn nnkan ti a n parun tabi ti a n mu kuro nigba ti a ba di Onigbagbọ?
- Ki ni awọn ohun ti a paṣẹ fun Onigbagbọ lati “gbé wọ”?