Lesson 264 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Li ọjọ ikini ọsẹ, ki olukuluku nyin fi sinu iṣura lọdọ ara rè̩ li apakan, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe rere fun u” (1Kọrinti 16:2).Cross References
I Idamẹwaa Ekinni
1. Idamẹwaa kin-in-ni ti a kọ silẹ ninu Bibeli ni eyi ti Abrahamu san fun Mẹlkisedeki, Gẹnẹsisi 14:18-20
2. Jakọbu jé̩ ẹjẹ lati fi idamẹwaa fun Oluwa, Gẹnẹsisi 28:20-22
II Idamẹwaa awọn Ọmọ Israẹli
1. Gbogbo idamẹwaa ni a kà si ohun iyasi-mimọ, ti a si maa n fi fun awọn ọmọ Lefi ati awọn alufa, Lefitiku 27:30-32; Numeri 18:21, 24, 26-32
2. A mu idamẹwaa wá si ibi ti Ọlọrun funra Rè̩ yàn, Deuteronomi 12:5, 6; 16:16, 17
3. Ibukun Ọlọrun a maa tẹle sisan idamẹwaa, 2Kronika 31:4-10; Nehemiah 12:43, 44; Owe 3:9, 10; Malaki 3:10
4. A fi awọn ọmọ Israẹli sùn nitori è̩ṣẹ ole jija, nitori wọn kuna lati mú idamẹwaa wọn wá fun Ọlọrun, Malaki 3:8, 9
III Ofin Majẹmu Titun
1. Jesu sọrọ rere nipa dídá idamẹwaa, Matteu 23:23; Luku 18:12
2. Owo idẹ wé̩wé̩ obinrin opo ni ṣe pataki fun Ọlọrun ju ọpọ owo awọn ọlọrọ lọ, Luku 21:1-4; Marku 12:41-44
3. Apọsteli nì, nipa imisi Ẹmi Ọlọrun fi ilana silẹ bi o ti yẹ lati ran Ijọ lọwọ nipa idawo, 1Kọrinti 16:2; Heberu 7:2-8
Notes
ALAYÉOjuṣe ti o Dọgba
Ohun ti o ga ju lọ ti o le ṣẹlẹ si eniyan ẹlẹran ara ni lati ri ẹbun ọfẹ ti igbala Jesu Kristi gba sinu ọkàn ati ayé rè̩. Gbogbo owo aye kò to lati fi ra igbala yii – a n ri i gbà nipa igbagbọ ninu Ọlọrun ati fifi ọkàn ati aye ẹni rubọ fun Ọlọrun. A ri i pe bi a kò ba fẹ ki ẹbun iyebiye yii fi wa silẹ, a ni lati fi itara jẹ alabapin ninu iṣẹ itankalẹ Ihinrere lọna kan tabi lọna miiran. Olukuluku ẹni irapada ni Ọlọrun paṣẹ fun lati lọ ati lati maa “kọ orilẹ-ède gbogbo” (Matteu 28:19). Ki a to le mu aṣẹ yii ṣẹ yoo gba inawo ati igbesi-aye ti a ti yà sọtọ fun Ọlọrun. Fun idi ti o hàn si gbogbo wa kò ṣe e ṣe fun gbogbo eniyan lati di ajihinrere ti yoo maa lọ si ilu ti o jinna réré lati kede ihinrere ti igbala; sibẹ Ọlọrun ṣe ilana fun titan Ihinrere ká gbogbo aye, O si ti pin inawo iṣẹ yii dọgbadọgba fun olukuluku awọn ọmọ Rè̩. Ilana Ọlọrun fun eto inawo ninu Ijọ Rè̩ ni a n pe ni idamẹwa, nitori pe olukuluku Onigbagbọ tootọ a maa san idamẹwa owo ti o wọle fún un fun iṣẹ Ọlọrun ki a ba le tan Ihinrere ká gbogbo aye.
Ilana ti ki i ṣe Titun
Lati ayebaye ni awọn Ọmọ Ọlọrun ti maa n san idamẹwa, nitori naa ilana yii ki i ṣe titun, bẹẹ ni kò si iran ti o ṣajeji fun. Itọka kin-in-ni ti a ri ninu Bibeli nipa ilana yii wà ninu Gẹnẹsisi 14:18-20, nibi ti a gbe kà pe Abramu san idamẹwaa fun Mẹlkisekedi ọba Salẹmu ati alufa Ọlọrun Ọga Ogo. Abramu n pada bọ sile pẹlu ikogun lẹyin iṣẹgun nla ti o ni lori awọn ọba marun un ti o ti kó Lọti lẹru lati ilẹ Sodomu. Melkisedeki pade Abramu ni afonifoji S̩afe pẹlu ibukun Ọlọrun, nibẹ ni Abramu ti san “idamẹwa ohun gbogbo fun u.” Bi o tilẹ jẹ pe eyi ni akọsilẹ kin-in-ni ti a ri kà nipa idamẹwaa, o daju pe Abramu ṣe eyi, nitori idi pataki kan ti o ti di mimọ fun un ṣaaju, nitori o mọ ohun ti o yẹ ki o ṣe. Olupilẹṣẹ igbala ayeraye ni o mi si i lati ṣe bẹẹ.
S̩aaju Ofin
Awọn miiran n jiyan pe ilana idamẹwaa jé̩ ti igba Ofin Mose nikan. Wọn n sọ fun ni pe niwọn igba ti awọn Onigbagbọ wà labẹ Majẹmu ti Oore-ọfẹ, ofin ti idamẹwaa ti kọja lọ, ki i si i ṣe fun wọn mọ. Boya iru ariyanjiyan yii ta si Paulu Apọsteli leti, nitori pe ninu Episteli rè̩ si awọn Heberu o fi han fun wọn pe a ti n dá idamẹwaa lati nnkan bi irinwo ọdun ṣaaju Ofin Mose. Apọsteli yii sọ bi iṣẹ alufaa Mẹlkisedeki ati iṣẹ alufaa Jesu ti jọ ara wọn. O ṣe e ṣe ki Mẹlkisedeki jé̩ Ẹnikeji ninu Mẹtalọkan ti o gbe awọ eniyan wọ fun igba diẹ ni akoko Majẹmu Laelae – “laini baba, laini iyá, laini ìtan iran, bḝni kò ni ibẹrẹ ọjọ tabi opin ọjọ aiye, ṣugbọn a ṣe e bi Ọmọ Ọlọrun” (Heberu 7:3).
A mọ Abrahamu gẹgẹ bi ọré̩ Ọlọrun nitori igbagbọ rè̩ ninu Ọlọrun, o si san idamẹwaa fun ẹni ti a “ṣe bi Ọmọ Ọlọrun.” Gbogbo Onigbagbọ tootọ di alabapin ninu majẹmu Abrahamu nipa igbagbọ ninu Ọlọrun ati nipa oore-ọfẹ; nitori naa ilana kan naa ti o wà fun Abrahamu ni o wà fun Onigbagbọ lọjọ oni. Abrahamu ba Ọlọrun rin, o si ri ibukun gba lati ọdọ Ọlọrun gẹgẹ bi o ti san idamẹwa fun aṣoju Ọlọrun tootọ. Ọlọrun kò yipada, bẹẹ ni ọna Rè̩ pẹlu kò yipada. Ni akoko oore-ọfẹ paapaa, bi ẹnikẹni ba n fẹ ẹkunrẹrẹ ibukun Ọlọrun, yoo ri ibukun naa gba bi o ba tọ iṣisẹ Abrahamu oloootọ.
Ni ọjọ pupọ ṣaaju Ofin, Jakọbu jé̩jẹ fun Ọlọrun pe, “ninu ohun gbogbo ti iwọ o fi fun mi emi o si fi idamẹwa rè̩ fun ọ” (Gẹnẹsisi 28:22). Bi a kò ba fara balẹ yẹ ẹjẹ yii wò, yoo dabi ẹni pe Jakọbu fẹ lati ba Ọlọrun dunadura, ṣugbọn eyi kò ri bẹẹ rara. Nigba ti Jakọbu sùn, Ọlọrun fi han fun Jakọbu loju ala, iru ibukun ti o wà fun un bi o ba jẹ oloootọ. Nigba ti Jakọbu ji o rọ mọ ileri Ọlọrun o si ṣeleri pe bi Ọlọrun ba mu Ọrọ Rè̩ ṣẹ oun (Jakọbu) yoo ṣe ohun ti oun mọ pe o tọ. Lai si aniani Jakọbu ti kẹkọọ lati ọdọ Abrahamu baba nla rè̩ pe idamẹwaa tọna. Lẹyin eyi, Ọlọrun yi orukọ Jakọbu pada si Israẹli wi pe, “Iwọ ti ba Ọlọrun ati enia jà, iwọ si bori” (Gẹnẹsisi 32:28). Jakọbu ki ba ti le bori pẹlu Ọlọrun bi o ba ti kuna lati mu ẹjé̩ rè̩ ṣẹ.
Fun Ire Israẹli
Ọrọ Ọlọrun fi han gbangba pe ohun ti Ofin ṣe ni pe o fara mọ ilana ti o ti wà tẹlẹ o si mu un lagbara. Ọlọrun kò beere idamẹwaa lati ọdọ awọn Ọmọ Israẹli nitori idi kan ti o fara sin, ṣugbọn a n gba a, a si n lo o fun ire awọn Ọmọ Israẹli. Ni akoko igbà nì paapaa ile isin Ọlọrun n fẹ awọn alabojuto ati awọn alufaa, a si n lo awọn ọmọ Aarọni ati ẹya Lefi fun iṣẹ yi. Awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi fi gbogbo akoko ati igba wọn fun iṣẹ-isin ni ile Oluwa. Wọn kò ni ini laaarin awọn Ọmọ Israẹli; nitori naa Ọlọrun fi idamẹwaa ti awọn Ọmọ Israẹli n da fun awọn iranṣẹ ibi pẹpẹ wọnyi fun jijẹ ati mimu wọn.
Igba gbogbo ni a n ran awọn Ọmọ Israẹli leti pe Ọlọrun ni o fi ilẹ ti wọn n gbe fun wọn ni ini. Pẹlupẹlu, wọn ni lati ranti pe Oluwa ni o fun wọn ni ibisi oko, ti O “fun ọ li agbara lati li ọrọ” (Deuteronomi 8:18). Ohun ti awọn Ọmọ Israẹli n ṣe nigba ti wọn ba san idamẹwaa wọn ni pe wọn n dá iba diẹ ninu ohun ti Oluwa ti fi fun wọn pada fun Un. Bakan naa ni o ri fun olukuluku ọkunrin tabi obinrin ti o ba n san idamẹwaa fun Oluwa.
Ole!
Ọkan ninu awọn è̩sùn ti o wuwo ti a fi awọn Ọmọ Israẹli sùn ni pe wọn n ja Ọlọrun ni ole. O jẹ iyalẹnu fun awọn eniyan wọnyi, esi wọn si fi igberaga han: “Nipa bawo li awa fi jà ọ li olè?” Lai si aniani wọn n ṣe isin ode ara, wọn si n pa ofin atọwọdọwọ mọ finnifinni pẹlu ero pe iṣẹ ọwọ wọn ati ilana ti wọn ti to lati mu wọn yẹ dipo ki wọn pa gbogbo Ọrọ Ọlọrun mọ. Lọgan, esi de fun ibeere wọn: “Nipa idamẹwa ati ọrẹ. Riré li a o fi nyin ré: nitori ẹnyin ti jà mi li olè, ani gbogbo orilẹ-ède yi” (Malaki 3:8, 9). È̩sùn nla yii fi han fun ni bi Ọlọrun ti fi ọwọ danindanin mu gbogbo Ọrọ Rè̩ to. Ohun ewu ni lati fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ofin Ọlọrun. Anania ati Safira sọ ẹmi wọn nu, wọn si di ẹni egbe nitori ti wọn san apakan ninu iye ti o yẹ lati san, wọn si ṣeke si Ọlọrun ati eniyan nipa rè̩. “Ki a máṣe tàn nyin jẹ: a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká” (Galatia 6:7).
Ẹkọ Majẹmu Titun
Nigba ti Oluwa ba ri ohun rere ni igbesi-aye ẹni kan, Oun yoo ṣe apọnle ohun rere naa; bakan naa ni Oun ki i jafara lati bu è̩té̩ lu ohunkohun ti i ṣe buburu. Eyi gan an ni ohun ti Jesu sọ nipa idamẹwaa ti awọn Farisi n san. Wọn bojuto ilana yii kinnikinni to bẹẹ ti wọn fi n dá idamẹwaa lori awọn ohun ti kò niyelori gẹgẹ bi eweko minti, anise ati kumini. Jesu wi fun wọn pe, wọn ki ba fi eyi silẹ lai ṣe; lọna miiran ẹwẹ, O fi idi ofin idamẹwaa mulẹ, O si mu un lati inu Majẹmu Laelae wa si inu Majẹmu Titun fun Ijọ Rè̩. Jesu ṣe apọnle ire ti o wà ninu sisan idamẹwaa, ṣugbọn O dá awọn Farisi lẹbi pe wọn gbojufo awọn ohun ti o tobi ju ninu Ofin dá -- idajọ, aanu ati igbagbọ. Kò si ẹni ti yoo wọ Ọrun nitori pe o n dá idamẹwaa nikan, bẹẹ ni kò si ẹni ti o mọọmọ kọ lati fi apa kan ohun ti i ṣe ti Ọlọrun fun Un ti yoo de ilu Ọlọrun.
Gẹgẹ bi a ti fi han ninu Episteli Apọsteli nì si awọn Heberu, a rii pe o fi idi sisan idamẹwaa mulẹ. O tun ba awọn Ijọ Kọrinti sọrọ siwaju sii nipa ọrẹ atinuwa. Aníyàn wọ inu ọkàn awọn Keferi wọnyi ti o di Onigbagbọ nipa awọn arakunrin ti o wà ninu aini ni Jerusalẹmu. Paulu sọ fun wọn bi wọn ti ṣe le fi itara wọn han nipa iṣẹ. “Li ọjọ ikini ọsẹ, ki olukuluku nyin fi sinu iṣura lọdọ ara rè̩ li apakan, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe rere fun u, ki o máṣe si ikojọ nigba ti mo ba de” (1Kọrinti 16:2). Idawo yii jé̩ ọrẹ atinuwa ti awọn ara Kọrinti mu wá lẹyin ti wọn ti dá idamẹwaa wọn, nitori pe Paulu pe idawo yii ni ẹbun tabi ọrẹ atinuwa.
O wà ni ipa ẹnikẹni ti o ba fẹ bun ẹbun lati sọ ohun ti a o fi ẹbun naa ṣe. Nipa idawo ti a sọrọ nipa rè̩ yi, awọn ara Kọrinti fi han pe wọn fẹ lati fi ran awọn ara wọn lọwọ. Lọna miiran ẹwẹ, Oluwa le fi iwuwo si ọkàn ẹni kan lati fi owo ṣe iranwọ fun ojiṣẹ Ọlọrun, tabi lati ṣe iranwọ fun kikọ ile Ọlọrun tabi lati dá owo fun titẹ iwe itankalẹ Ihinrere. Ẹbun tootọ ni ọrẹ atinuwa yii jé̩.
Idamẹwaa ki i ṣe ọrẹ fun Ọlọrun; ojuṣe wa fun Ọlọrun ni – ti Ọlọrun ni wọn i ṣe. Ọlọrun ni o pese gbogbo ohun rere ti awọn Ọmọ Israẹli ni fun wọn. O si n beere pe ki wọn san idamẹwaa rè̩ pada. Bakan naa ni Ọlọrun fun Onigbagbọ ni “gbogbo ẹbun rere ati gbogbo è̩bun pipe”, nitori naa idamẹwaa ki i ṣe ohun ti o pọju lati san pada fun Un. A n yọ idamẹwaa kuro ninu iye owo ti eniyan ba ri nipa iṣowo tabi owo ọya ti a gba. Lori ere ti a ba jẹ nipa iṣowo ni a gbe n san idamẹwaa. Lori owo ọya (tabi owo oṣù) ti a gba ni a gbe n san idamẹwaa ki a to yọ iye ti a o san ni owo ori, ati awọn inawo pé̩pè̩pé̩ miiran kuro.
Ibukun Ọlọrun
Kò si Onigbagbọ ti o gbọdọ ro ara rè̩ si alaini to bẹẹ ti kò fi ni san idamẹwaa. Ọpọlọpọ eniyan ti wọn kò ni lọwọ ni gbogbo ọjọ aye wọn ni o ti di ẹni ibukun nipa ti ara lẹyin ti wọn bẹrẹsi san idamẹwaa. Ileri Ọlọrun ni eyi: “Ẹ mu gbogbo idamẹwa wá si ile iṣura, ki onjẹ ba le wà ni ile mi, ẹ si fi eyi dán mi wò nisisiyi, bi emi ki yio ba ṣi awọn ferese ọrun fun nyin, ki nsi tú ibukún jade fun nyin, tobḝ ti ki yio si aye to lati gbà a” (Malaki 3:10). Siwaju si i, “Fi ohun-ini rẹ bọwọ fun Oluwa; ati lati inu gbogbo akọbi ibisi- oko rẹ: Bḝni aká rẹ yio kún fun ọpọlọpọ, ati agbá rẹ yio si kún fun ọti waini titun” (Owe 3:9, 10). Oluwa fẹ ki awọn ọmọ eniyan mu iduro wọn lori Ọrọ Rè̩, ki wọn si fi bayi dan An wò. O ṣetan lati mu Ọrọ Rè̩ ṣẹ ni gbogbo igba. Lọna miiran ẹwẹ awọn ẹlomiiran ti Ọlọrun bukun fun nipa ti ara nigba ti wọn n san idamẹwaa ni o tun pada di alaini nigba ti wọn kò san idamẹwaa wọn fun Ọlọrun mọ. “Riré li a o fi nyin ré: nitori ẹnyin ti jà mi li olè.”
Ọlọrun a maa yé̩ ẹnikẹni ti o ba gbẹkẹle E si. Jesu yin talaka obinrin opo nì ti o da owo idẹ wẹwẹ meji sinu apoti iṣura. Bi o tilẹ jẹ pe ẹbun rè̩ kere ṣugbọn Oluwa ka ẹbun rè̩ si ju owo nla nla ti awọn ọlọrọ dá nitori pe obinrin opo yii mu ọrẹ rè̩ wá pẹlu igbagbọ pe Ọlọrun yoo pese fun aini oun. Opo naa mu gbogbo ohun ti o ni wá -- “ani gbogbo ohun ini rè̩” ti o ni. Oluwa kan naa kò ha ri idamẹwa awọn eniyan Rè̩ ti o gba wọn ni ohun pupọ lati san an? Bi wọn ba le san an pẹlu igbagbọ, Oluwa yoo ka a si, yoo si bukun fun ẹni ti o mu un wa.
Gbese n kọ? Awọn ẹlomiiran le beere pe, njẹ kò ni dara lati san gbese tan ki a to san idamẹwaa? Itumọ ibeere yii ni pe Ọlọrun ni ki a jẹ ni gbese ni tabi eniyan? Ọlọrun fi ègún le awọn ti o ba kọ lati dá idamẹwaa wọn. Laakaye kò ha fi ye ni pe bi a ba ni ibukun Ọlọrun ni igbesi-aye wa dipo ègún kò ni ṣoro lati san gbese ti a jẹ?
Fun Ta Ni?
“Ẹnyin kò mọ pe awọn ti nṣiṣẹ nipa ohun mimọ, nwọn a mā jẹ ninu ohun ti tẹmpili? ati awọn ti nduro ti pẹpẹ nwọn ama ṣe ajọpin pẹlu pẹpẹ? Gẹgẹ bḝli Oluwa si ṣe ilana pe, awọn ti nwasu ihinrere ki nwọn o si ma jẹ nipa ihinrere” (1Kọrinti 9:13, 14). Jesu sọ fun awọn aadọrin ti O yàn pe, “Ọyà alagbaṣe tọ si i” (Luku 10:7). Nitori naa awọn ti wọn fi akoko wọn, talẹnti wọn, ati laalaa wọn fun iṣẹ iwaasu ati itankalẹ Ihinrere tootọ ni ẹtọ lati gba idamẹwaa awọn Onigbagbọ iyoku. A n lo idamẹwa fun kikọ ati itọju Ile Ọlọrun pẹlu.
Onigbagbọ ni lati ṣọra nipa ẹni ti o n san idamẹwaa rè̩ fun. Jesu ṣe ikilọ pe, “Ẹ mā kiyesi awọn eke woli ti o ntọ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõkò ni nwọn ninu . . . nipa eso wọn li ẹnyin o fi mọ wọn” (Matteu 7:15, 20). Kiyesi ijọ ati ẹkọ rè̩, ki o si mọ daju pe ẹkọ rè̩ duro lori ododo Ọrọ Ọlọrun ki o to da idamẹwaa rẹ sibẹ. “Ẹ máṣe gbà gbogbo ẹmi gbọ, ṣugbọn ẹ dán awọn ẹmí wò bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ ti jade lọ sinu aiye” (1Johannu 4:1). Ẹnikẹni ti o ba n ṣe iranlọwọ lati tan ẹkọ eke kalẹ nipa dida idamẹwaa tabi owo sinu ẹgbẹ bẹẹ jẹ alabapin ninu iṣẹ ibi wọn.
Aṣeyọri
Ijọ Ọlọrun ha le fi ohun miiran dipo ilana Ọlọrun fun eto idawo? Ọpọlọpọ ilana idawo ni awọn eniyan ti ṣe yatọ si eto ti Ọlọrun, ṣugbọn ijatilẹ ni gbogbo rè̩ yọri si. S̩ugbọn gbogbo awọn ti o fẹ lati gbọran si Ọrọ Ọlọrun ti rii pe otitọ ni awọn ileri Rè̩.
Ninu Ijọ Igbagbọ Apọsteli, a maa n fi apoti kekere kan kọ si ẹgbè̩ ogiri ni abawọle ile Ọlọrun ki awọn enia baa le ni anfaani lati fi idamẹwa ati ọrẹ wọn sibẹ. A ki i kọ orukọ awọn ẹni ti o dá owo. Kò si ẹni ti o n mọ iye owo ti ẹni kọọkan dá sinu apoti iṣura afi ẹni ti o dá a ati Ọlọrun; ṣugbọn ibukun Ọlọrun n tẹle ileri Rè̩ bi awọn eniyan ti n fi igbọran wọn si Ọrọ Ọlọrun han lati igba-de-igba. Awọn eniyan ti mu idamẹwa wá sinu ile iṣura, ferese Ọrun si ti ṣi silẹ, Ọlọrun si ti ṣi ibukun Rè̩ jade titi Ihinrere fi tan kalẹ yi gbogbo aye ká. “Bi ẹnyin ba mọ nkan wọnyi, alabukun-fun ni nyin, bi ẹnyin ba nṣe wọn” (Johannu 13:17).
Questions
AWỌN IBEERE- Ta ni ọkunrin kin-in-ni ti o san idamẹwaa? Ta ni o si san an fun?
- Iha wo ni Jakọbu kọ si sisan idamẹwaa?
- Ki ni Ofin Mose sọ si ilana idamẹwaa?
- Njẹ awọn Ọmọ Israẹli n san idamẹwaa bi o ti tọ ati bi o ti yẹ nigba gbogbo?
- Ki ni iha ti Ọlọrun kọ si awọn ti n fa sẹyin lati san idamẹwaa wọn fun Un?
- Ki ni Jesu sọ nipa idamẹwaa?
- Ẹnikẹni ha gbọdọ ka ara wọn si alaini to bẹẹ ti wọn kò ni fun Oluwa ni ohun ti i ṣe ti Rè̩?
- Bawo ni Ẹmi Ọlọrun, lati ẹnu Paulu, ṣe fi ilana lelẹ fun Ijọ nipa idawo?
- Ki ni a n lo idamẹwaa fun?