1Johannu 2:15, 16; Johannu 15:19; Romu 12:2; 1Kọrinti 10:23, 24, 31-33; 14:26; Titu 2:6-10

Lesson 265 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitorina bi ẹnyin ba njẹ, tabi bi ẹnyin ba nmu, tabi ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mā ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun” (1Kọrinti 10:31).
Cross References

I Ifẹ Aye

1. Ọrọ Ọlọrun paṣẹ fun gbogbo eniyan pe ki wọn má ṣe fẹ aye tabi ohun ti o wà ninu aye, 1Johannu 2:15; Romu 12:2; Kolosse 3:1, 2

2. A paṣẹ fun gbogbo eniyan lati fẹ Ọlọrun ati lati kọ ọrọ ati ere aye silẹ, I Timoteu 6:6-12; Haggai 1:6; Owe 23:5; 27:24; Oniwasu 2:18, 26; Matteu 6:19; Luku 12:20, 21

3. Ifẹkufẹ ara, ti aye ni, I Johannu 2:16; Numeri 11:4, 34; Orin Dafidi 78:18, 30; Matteu 5:27-30; Romu 13:14; 1Kọrinti 10:6-10; Galatia 5:16; Efesu 2:3; Titu 2:12, 13; 1Peteru 1:14; 2:11; 4:2, 3; 2Peteru 2:10; Juda 16-18

4. Ifẹkufẹ oju ti aye ni, Gẹnẹsisi 3:6; 13:10; Joṣua 7:21; Orin Dafidi 119:37; Oniwasu 5:10, 11; Luku 4:5

5. Irera aye ti aye ni, Ẹsteri 1:3-7; Orin Dafidi 73:6-9; Daniẹli 4:30; Esekiẹli 28:12-17; Iṣe Awọn Apọsteli 12:20-23; Ifihan 3:17; 18:11-16

II Igbadun Aye

1. A ya Onigbagbọ kuro ninu aye, wọn si jẹ ẹni ọtọ kuro ninu awọn ti ero ati ifẹ ọkàn wọn jẹ ti aye, Romu 12:2; Titu 2:6-12; Johannu 15:19

2. Onigbagbọ ni lati wu Ọlọrun, ki i si ṣe eniyan; wọn si ni lati gbe igbesi-aye ti o ran ni lọwọ, ki i ṣe eyi ti yoo mu ki arakunrin wọn kọsẹ, 1Kọrinti 10:23, 24, 31-33; 14:26

3. Ariya ti i ṣe ti ara jé̩ irira si Ọlọrun, Ẹksodu 32:6, 7; 1Peteru 4:3, 4; Galatia 5:21; Isaiah 1:14; Daniẹli 5:1-5; Luku 15:13

Notes
ALAYÉ

Ifẹ Aye

Ọrọ ti Ẹmi Mimọ gba ẹnu Johannu Apọsteli sọ pe, “Ẹ máṣe fẹran aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye,” ki i ṣe ọrọ yẹpẹrẹ kan lasan. Aṣẹ Ọlọrun yii ti o kun fun imisi Ọlọrun, jẹ ti gbogbo eniyan, nibi gbogbo, awọn ti o ni ireti tabi ifẹ lati ba Ọlọrun gbe ni ibi alaafia ayeraye. Ifẹ aye jẹ iṣọta Ọlọrun! Ninu Episteli ti Jakọbu a kà bayii pe, “Ẹ kò mọ pe ìbaré̩ aiye iṣọtá Ọlọrun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jé̩ ọrẹ aiye di ọtá Ọlọrun” (Jakọbu 4:4). Ẹnikẹni, lọkunrin tabi lobinrin ti o ba ṣe aigbọran si ikilọ yii, ṣe bẹẹ si iparun ara rè̩. Ọpọ ẹsin ni o wà ni ode oni ti ẹkọ wọn ati ilana wọn yọọda ibarẹ ati ibalo pẹlu aye. Ti aye ni awọn ẹsin bẹẹ. Irin, ilepa, ifẹ, ati igbesi-aye awọn ti o gba iru ẹsin bẹẹ jẹ ọkan naa pẹlu aye, a kò si le pin wọn niya. Ihinrere Jesu Kristi kò gbà fun ni lati ni irẹpọ tabi ibarẹ pẹlu aye. Ọmọ lẹyin Jesu Kristi a maa pa aṣẹ Oluwa rè̩ mọ, a si maa ya ara rè̩ kuro ninu aye.

Bi ẹni kan ba gba ifẹ aye pẹlu gbogbo ifẹkufẹ rè̩ láyè ninu ọkàn rè̩, iru ẹni bẹẹ kò le ṣe ọmọ-lẹyin Jesu. Bibeli fi ohun ti aye jẹ han fun ni kedere; o sọ fun ni ni oriṣiriṣi ọna nibi pupọ pe aye kún fun è̩tàn, ifẹkufẹ, ẹmi eṣu, yoo si parun ni aipẹ jọjọ. (Ka Jakọbu 3:15; 1Johannu 2:17; Luku 21:34; Matteu 24:38).

Ọpọlọpọ eniyan lero pe bi ogunlọgọ awọn aladugbo wọn ba n fi ara fun iwa kan ti o lumọ è̩ṣẹ tabi iwa buburu kan awọn naa jare lati ṣe bẹẹ pẹlu. Bi gbogbo aye ba tilẹ lodi si ifẹ Ọlọrun, kò si ẹni kan ti o le da ara rè̩ lare ni ṣiṣe bẹẹ pẹlu. Ọlọrun ni agbara lati mu gbogbo aye wá si idajọ nitori è̩ṣẹ wọn, O si ti ṣeleri lati ṣe bẹẹ ni akoko ti o wọ. Lati jingiri sinu è̩ṣẹ ati lati jẹ alabapin ninu ifẹkufẹ aye yoo fa ibinu Ọlọrun sori ẹlẹṣẹ naa.

Ọgọọrọ eniyan ninu aye ti kọ Kristi silẹ wọn kò si naani ilana Rè̩. Awọn wọnyi ni a n pe ni aye. Gbogbo iṣe wọn, ero wọn ati ọna wọn ni o yapa si Ọlọrun, opin aye wọn paapaa lodi si ohun ti i ṣe mimọ ati ododo. Ẹgbẹ ati ọgba wọn, iṣẹ wọn, ati gbogbo ilana igbesi-aye wọn ni lati té̩ ara wọn lọrun nipa ifẹkufẹ ati afẹ aye. Nitori naa eniyan ni lati gbe igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun tabi ki a ka oluwarẹ pọ mọ aye, eyi ti opin rè̩ i ṣe egbé ayeraye.

Ki i ṣe ti Aye

Onigbagbọ wà ninu aye, ṣugbọn ki i ṣe ti aye. Ki i ṣe pe yoo fi ara pamọ si ile ahamọ ki o má baa fi oju ri gbogbo ibi ati iwa buburu ti o wa ninu aye; nitori pe a ni lati waasu ihinrere fun gbogbo eniyan ki a si sọ fun wọn nipa agbara Ọlọrun ti o n gba ni kuro ninu è̩ṣẹ. Onigbagbọ le ṣiṣẹ ki o si gbe igbesi-aye ti o wu Ọlọrun laaarin iran alarekereke ati wíwọ yii, ki o si jẹri fun Ọlọrun. Kò si awawi fun ẹnikẹni pe oun kò le gbe igbesi-aye Onigbagbọ ni ibi iṣẹ oun tabi ninu igbesi-aye rè̩ lojoojumọ nitori ẹri gbogbo eniyan Ọlọrun ni ibi gbogbo ni pe, o ṣe e ṣe, wọn si n gbe igbesi-aye iṣẹgun. Ninu iṣẹ ologun, ni ibi òwò, nile, nibikibi ati ni ibi gbogbo, awọn eniyan Ọlọrun a maa gbe igbesi-aye ti o wu Ọlọrun. (Wo Daniẹli 1:8; Heberu 11:24-26).

“Njẹ bi a ba ti ji nyin dide pẹlu Kristi, ẹ mā ṣafẹri awọn nkan ti mbẹ loke, nibiti Kristi gbé wà ti o joko li ọwọ ọtun Ọlọrun. Ẹ mā ronu awọn nkan ti mbẹ loke ki iṣe awọn nkan ti mbẹ li aiye” (Kolosse 3:1, 2). Bi a ba n ṣe afẹri ohun wọnni ti i ṣe ti Ọlọrun ati ijọba Ọlọrun, a le ni ifayabalẹ pe awa ki i ṣe ti aye. Awọn ti i ṣe ti aye a maa to iṣura wọn jọ sinu aye, Jesu wi pe, nibikibi ti iṣura yin ba gbe wà nibẹ ni ọkàn yin yoo wà pẹlu (Matteu 6:21).

Olufẹ Faaji

Ọkan ninu awọn ami ikẹyin aye ni pe awọn eniyan yoo jẹ olufẹ fāji jù olufẹ Ọlọrun lọ” (2Timoteu 3:4). Gbogbo ọna ti aye n gba ṣe faaji ni o mu ifẹkufẹ ti o buru jai, ati aiwa-bi-Ọlọrun lọwọ. Dajudaju Ọlọrun n fẹ ki inu awọn eniyan Rè̩ dùn ki wọn si ni ayọ tootọ. Ninu Ọrọ Ọlọrun ni a gbe ti le ri orisun tootọ yii. “Iwọ o fi ipa ọna iye hàn mi; ni iwaju rẹ li ẹkún ayọ wà: li ọwọ ọtún rẹ ni didùn-inu wà lailai” (Orin Dafidi 16:11).

Nigba ti eniyan pupọ súà laarin orilẹ-ede ba dide ni Ọjọ Oluwa lati ṣafẹ, lai fi ti Ọlọrun pè, bi kò ṣe lati ṣe ohunkohun ti wọn ro pe yoo té̩ ọkàn wọn lọrùn, iyè wọn ti ra bi orilẹ-ede, ifẹkufẹ aye ti kò ṣee fẹnu sọ si ti kó wọn lẹru. Kò si orilẹ-ede ọlaju kan lode oni ti kò ti i di oniwọra nibi ohun jijẹ, mimu ati ninu faaji titi o fi di è̩ṣẹ. Jesu sọ nipa awọn bẹẹ pe, “nitori bi ọjọ wọnni ti wà ṣiwaju kikún omi, ti nwọn njẹ, ti nwọn nmu, ti nwọn ngbé iyawo, ti a si nfa iyawo funni, titi o fi di ọjọ ti Noa fi bọ sinu ọkọ, nwọn kò si mọ titi omi fi de, ti o gbá gbogbo wọn lọ; gẹgẹ bḝni wiwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu” (Matteu 24:38, 39).

Bibeli tun sọ pẹlu nipa awọn ti n jẹ, ti wọn n ṣe faaji, lai si idi miiran ju pe ki wọn té̩ ifẹkufẹ ọkàn wọn lọrùn, “Nitori ọpọlọpọ ni nrìn, nipasẹ awọn ẹniti mo ti nwi fun nyin nigbakugba, ani, ti mo si nsọkun bi mo ti nwi fun nyin nisisiyi, pe, ọtá agbelebu Kristi ni wọn: igbẹhin ẹniti iṣe iparun, ikùn ẹniti iṣe ọlọrun wọn ati ogo ẹniti o wà ninu ititju wọn, awọn ẹniti ntọju ohun aiye” (Filippi 3:18, 19). Ọlọrun fi ajẹkì si ipo kan naa pẹlu oti mimu, è̩ṣẹ si ni. (Ka Owe 23:21; Isaiah 56:12; Luku 12:19; 1Timoteu 5:6).

Titọ si Iwa-bi-Ọlọrun

Onigbagbọ ki i ba wọn ṣe eto idije ere-idaraya, tabi ijo jijo, tabi iru erekere miiran, bẹẹ ni oun ki i ba awọn ti n ṣe nnkan wọnyii kẹgbẹ rara, nitori, lọna kin-in-ni, ayika ibi ti a ti n ṣe iru nnkan bẹẹ ati iru ọkàn ti a fi n ṣe wọn, lodi si Ẹmi Kristi. Ẹlẹṣẹ ni gbogbo awọn alabapin ninu ere wọnyi ati awọn ti o n wo o pẹlu. Ohun ti ere idaraya wọnyi wà fun ni lati té̩ ifẹkufẹ ara ati ọkàn è̩ṣẹ lọrùn. Ọpọlọpọ ibi ti o wà nibẹ tayọ ire diẹ ti a le ri ninu rè̩. Ẹrọ awo ti n fi aworan han (sinima) ti di ohun ti o yara sọ awọn ọdọ di ọdáràn ju ohunkohun lọ ni gbogbo agbaye. Awọn ẹlẹrọ sinima mọ pe ọkàn awọn eniyan tè̩ si iwa buburu ati è̩ṣẹ, wọn si ti lo ìmọ yii lati fi iwa è̩ṣẹ ati ibi kún gbogbo orilẹ-ede. Aworan ti a n fi han ninu rè̩ ti kọ gbogbo eniyan bi a ti n hu iwa buburu. Ohunkohun ti i ṣe ti iwa ika ni a n gbe ga, a si maa tẹmbẹlu ohun wọnni ti o dara ti o si tọ.

Awọn eniyan sọ pe awari ẹrọ tẹlifiṣọn ninu eyi ti a n ri awọn eniyan ti a si n gbọ ọrọ ti wọn n sọ jẹ itẹsiwaju kan pataki ninu ọna ọlaju aye ode oni. Boya eyi iba jẹ otitọ bi a ba lo o fun ire eniyan ati igbeleke ogo Ọlọrun. Lai si aniani, o ti di mimọ pe iṣẹ ibi ti ẹrọ yi n ṣe ti tayọ eyi ti sinima ati ẹrọ redio n ṣe ni apapọ nitori pe a n fi oju ri a si n fi eti gbọ ohun ti wọn n ṣe ninu ẹrọ tẹlifiṣọn, ọna mejeeji wọnyi si jẹ ọna pataki ti eniyan n gba kẹkọọ. Kò si ohun rere pataki kan ti a nri wò ninu tẹlifiṣọn bi kò ṣe aworan è̩ṣẹ ati ti awọn ọdáràn. Onigbagbọ ti o ba n fetisi, ti o si n wo ọpọlọpọ ninu awọn eto ti wọn n gbe jade ninu tẹlifiṣọn n ṣe alabapin ninu rè̩ nitori pe o ni inudidun si ohun ti o n ri ati eyi ti o n gbọ. Awọn igi lẹyin ọgba meji ti i ṣe alatilẹyin iṣẹ tẹlifiṣọn ni awọn oniṣẹ-ọti ati awọn onitaba, awọn oniṣowo ohun mejeeji yii si n ná ẹgbẹẹgbẹrun ọkẹ naira lọdọọdun lati kọ awọṅ eniyan lẹkọọ nipa bi a ṣe n mu taba ati ọti. Ohun meji wọnyi nikan, taba ati ọti, ti ṣe iranwọ lati sọ aimoye eniyan di ero ọrun apaadi; ani lati fetisi ipolowo ọja wọn nikan to lati fa ibinu Ọlọrun wá sori ẹni naa gẹgẹ bi awọn olupolowo yii paapaa.

Awọn obi ni lati kilọ fun awọn ọmọ wọn nipa awọn iwe iroyin ati awọn iwe ti n sọ itan arosọ, awọn wọnni ti o le mu ki wọn maa ro erokero lọkan wọn ati lati ṣe ibi.

Awọn ẹlomiiran a maa beere pe, “Ki ni buru ninu ki awọn Onigbagbọ lọwọ ninu idije ere idaraya?” Paulu sọ fun Timoteu alufaa kekere pe: “Titọ si ohun ti ara, ère fun ohun diẹ ni, ṣugbọn iwa-bi-Ọlọrun li ère fun ohun gbogbo, o ni ileri ti aiye isisiyi ati ti eyi ti mbọ” (I Timoteu 4:8). Diẹ ni eto idije ere idaraya ti wọn n ṣe lode oni fi yatọ si ijakadi ti awọn ara Romu maa n ja ni ajaku-akata ni igba atijọ. Ijadu ipo ni ẹmi ere idaraya ode oni duro le lori. Kò si ohun miiran ti o wa lọkàn wọn ju pe ki wọn bori, a si maa n kọ wọn lọna ti yoo sọ wọn di alagbara gidigidi to bẹẹ ti wọṅ yoo fi le bori gbogbo awọn iyoku. Ohun ti o lodi si Ihinrere Kristi gidigidi ni pe ki a ni ifẹ pe ki a le ni agbara ati ipa lati bori awọn ẹlomiran. (Ka Sekariah 4:6; 1Samuẹli 2:9). Onigbagbọ a maa lepa lati leke ninu iwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn o n du u lati leke fun ogo Ọlọrun; ki i ṣe lati gbe ara rẹ ga.

Ọrọ Ọlọrun sọ fun Onigbagbọ pe, “Niti ifẹ ará, ẹ mā fi iyọnu fẹran ara nyin: niti ọlá, ẹ mā fi ẹnikeji nyin ṣaju” (Romu 12:10). Iru iwa bayii kò si ninu idije ere idaraya. Wọn a maa yin ẹni ti o ba bori nitori agbara ati ipa rè̩. Wọn kò ranti lati fi ọla fun Ọlọrun ti o da ara, ninu ẹni ti awa gbe wa ni aaye, ti awa n rin kiri, ti awa si ni ẹmi wa. Ọlọrun kọ fun ni lati gbe ara wa ga nitori imisi eṣu ni. (Wo Owe 25:27; Matteu 23:12; Gẹnẹsisi 3:5; Isaiah 14:14). Kristi kú lati gba araye là kuro ninu èrè è̩ṣẹ, O si fun eniyan ni agbara lati bori agbara ibi ati ara.

Lai pẹ yii o de eti gbogbo eniyan bi abẹtẹlẹ ati iwa ọdaran ti gbilẹ to ninu idije ere idaraya awọn ọmọ ile-ẹkọ giga. Ọpọlọpọ ọdọmọkunrin ni o ti ba aye ara wọn jẹ nipa iwa ọdaran, ọpọlọpọ ni o si ti di ero ẹwọn nitori pe wọn mọọmọ kùnà lati bori ki wọn ba le jẹ ère tẹtẹ ti wọn ti ta. Idije ere idaraya laaarin awọn akẹkọọ ti di ohun ibajẹ to bẹẹ ti awọn alakoso ile-ẹkọ giga fi gbero gidigidi lati mu idije ere ajọṣe laaarin awọn ile-ẹkọ kuro ninu eto ẹkọ wọn. Njẹ Onigbagbọ a maa lọwọ ninu iru awọn nnkan bawọnyi?

Ki ni ohun rere ti o wà ninu è̩ṣé̩-jija ati ijakadi? Leralera ni ọpọ ẹmi n bọ sinu ere buburu yii ti n fi ẹmi awọn ti a pa danu ṣofo. Ọlọrun nikan ni o mọ bi ibajẹ ti a mu ba ọkàn eniyan ti pọ to nipa ifẹ ti ayé ni si è̩ṣẹ jija, ijakadi, fifi ẹṣin sare ati awọn ere miiran ti wọn n pe ni “ere idaraya ti kò buru.”

Ere idaraya pupọ ti kò buru ti o si nilaari ni o wà ti Onigbagbọ le ṣe alabapin ninu wọn fun anfaani ọkàn ati ilera, awọn ere idaraya gẹgẹ bi wiwa ọkọ oju-omi kékèké, ẹja pipa, ọdẹ ṣiṣe ati liluwẹ. Ihinrere mu ki o ṣe e ṣe fun ni lati gbadun oriṣiriṣi ere idaraya wọnyi lọpọlọpọ tayọ eyikeyi, nitori pe o n fun ni ni itẹlọrun ati ibalẹ ọkàn. Ki i ṣe igba ti Onigbagbọ ba lọwọ ninu ohun ti aye ati ere idaraya ti o léwu ni o ṣẹṣẹ le layọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni a n pe ni ifẹ aye?
  2. Ọna wo ni è̩rọ redio, sinima ati tẹlifiṣọn n gba ṣe ibi ninu eto ti wọn n gbe kalẹ?
  3. Ki ni ṣe ti Onigbagbọ kò fi ni lati lọwọ ninu eto idije ati eré idaraya ti aye?
  4. Sọ oriṣiriṣi ere ti o lero pe Onigbagbọ le ṣe fun ilera ara ati igbadun.
  5. Ki ni ṣe ti Onigbagbọ kò fi gbọdọ fé̩ aye tabi awọn ohun ti o wà ninu aye?