Isaiah 3:16-24; 55:2; 1Peteru 3:3-5; 1Kọrinti 6:19, 20; 9:25; 10:31

Lesson 266 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “A ti rà nyin ni iye kan: nitorina ẹ yin Ọlọrun logo ninu ara nyin, ati ninu ẹmi nyin, ti iṣe ti Ọlọrun” (1Kọrinti 6:20).
Cross References

I Idajọ fun Irera awọn Obinrin

1. Nitori ti awọn ọmọbinrin Sioni gberaga, Oluwa wi pe Oun yoo fi eepá lu wọn, Isaiah 3:16, 17

2. A o gba ohun ọṣọ wọn kuro ati oorun didun wọn pẹlu, ẹwà wọn ni a o si mu kuro, Isaiah 3:18-24

3. A ni lati ná owo fun ohun ti yoo fi itura fun ara ti yoo si ṣe rere fun ọkàn, Isaiah 55:2

II Ọṣọ ti Onigbagbọ

1. Ọṣọ ti inu ni o ṣe iyebiye loju Ọlọrun, ki i ṣe ti ode, 1Peteru 3:3-5

2. A ni lati yin Ọlọrun logo ninu ara wa, ati ninu ẹmi wa, 1Kọrinti 6:19, 20; 10:31

3. A ni lati wa ni iwọntúnwọnsi ninu ohun gbogbo, 1Kọrinti 9:25

Notes
ALAYÉ

Ọkan Mimọ

Otitọ ti o wà ninu owe igba nì ti o wi pe, “aṣọ nla kọ ni eniyan nla” kò yipada. Ohunkohun ti o wu ki eniyan ṣe lati ṣe ode ara lọṣọ kò le yi ohun ti o wà ninu pada. Jesu sọ fun awọn Farisi ti igba ayé Rè̩ pe ode ara wọn lẹwa lọpọlọpọ ṣugbọn ninu “wọn kún fun egungun okú.” O wi pe, “Iwọ afọju Farisi, tetekọ fọ eyi ti mbẹ ninu ago ati awopọkọ mọ na, ki ode wọn ki o le mọ pẹlu” (Matteu 23:26, 27).

Eniyan a maa wo oju ṣugbọn Ọlọrun n wo ọkàn. Kò si ọṣọ ode ara ti o le ṣe ọkàn lọṣọ. Nitori naa iṣisẹ kin-in-ni ti ẹnikẹni ni lati gbe lati wà ni alaafia pẹlu Ọlọrun ati lati ri ojurere Rè̩ ni pe ki o gba iwẹnumọ ọkàn rè̩ nipa Ẹjẹ Jesu, ati lati ṣe ẹni ti inu nì lọṣọ nipa iṣẹ Ẹmi Mimọ. Nigba ti iṣẹ kin-in-ni yii ba ti ṣe, igbesi-aye ẹni naa yoo yipada nitori pe ọkàn ni orisun iwa ati iṣe wà. Nigba ti a ba sọ eniyan di “ẹda titun” awọn “ohun atijọ ti kọja lọ.” Ifẹ rè̩ kò ni fa si awọn ohun ti kò nilaari ti o ti ni ifẹ si tẹlẹ ri mọ. Igberaga ti o n jọba ninu awọn ti i ṣe ti aye ki yoo jọba lori rè̩ mọ. Gbogbo ilepa rè̩ ti yipada nitori ọkàn rè̩ n ṣe afẹri nnkan wọnni ti o wà ni Ọrun.

Ẹni ti o da ijọ yii silẹ a saba maa fi ohun kan ti o mu ni lọkàn gidigidi ṣe apejuwe nigba ti o ba n kọ ni lẹkọọ lori ohun pataki yii. A maa sọ iran kan ti o ri ninu eyi ti o ri okiti kan ti itanna pupọ hu si lori. Bi o ti n wo o lati ọna jijin rere o lẹwa pupọ, ṣugbọn bi o ti n sun mọ tosi, o ri i pe ibi idalẹnu ti o kún fun agolo lasan ni, erupẹ diẹdiẹ si wà nihin ati lọhun lori eyi ti itanna gbe hù jade. Oun a maa lo apejuwe yii lati fi han bi awọn ẹsin eke ti wọn wà lode oni ti fara jọ okiti idalẹnu nì, nitori ti ẹsin wọnyi a maa ni ifarajọ iwa rere diẹ lode ṣugbọn wọn kò ṣe ohunkohun lati mu ki ọkàn yipada kuro ninu è̩ṣẹ.

Awọn ara Jẹriko sọ fun Eliṣa pe itẹdo ilu wọn dara, ṣugbọn omi ti o wà nibẹ buru, nitori eyi, ilẹ naa ṣa. Eliṣa si mu awokoto titun kan, o fi iyọ sinu rè̩, o si da iyọ si orisun omi naa, a si ṣe awotan omi naa. O lọ si orisun ibi ti wahala naa gbé bẹrẹ. Bakan naa ni a ni lati yẹ ọkàn wa wò lati rii pe orisun gbogbo iwa ati iṣe wa jẹ mimọ. Bibeli paṣẹ fun ni pe, “Jù gbogbo ohun ipamọ, pa aiya rẹ mọ; nitoripe lati inu rè̩ wá ni orisun ìye” (Owe 4:23). Bi ọkàn wa ba jẹ mimọ a o ri i pe lẹsẹkẹsẹ ni igbesi-aye wa yoo dọgba pẹlu Ọrọ Ọlọrun ati Ihinrere.

Aṣeju

A kò sọ ohun pupọ ninu Ọrọ Ọlọrun nipa ọna ti o yẹ ti a ba fi maa wọ aṣọ, ṣugbọn iwọn iba ti a kọ silẹ tó lati fi ẹsẹ wa le ọgangan ọna, ki a má ba yà si ọtun tabi si osi lati ṣe aṣeju. Imọran pataki nipa aṣọ wiwọ ni pe aṣọ wa gbọdọ mọ ki o si bode mu, ṣugbọn a kò gbọdọ fi aṣa ti o ṣẹṣẹ wọlu rán an, bẹẹ ni a kò gbọdọ ran an lọna ti igba ti lo.

Bi awọn oṣiṣẹ Ihinrere kan ti n kọja lọ ni igboro ilu kan, wọn ri ọdọmọbinrin kan ti o wọṣọ ti a ran ni aṣa ti o ṣẹṣẹ yọju. Gbogbo awọn ti n kọja ni o n wo o ni a-wo-boju-wẹyin. Ni irin nnkan bi opo waya meji lẹyin eyi, wọn tun ri ọdọmọbinrin miiran ti kaba rè̩ gun gẹrẹjẹ, igba ti lo ibọsẹ rè̩, gbogbo iwọṣọ rè̩ si fi i han gẹgẹ bi ara oko. Gbogbo eniyan ni o tun n wo o ni a-wo-tunwo. Aṣeju fara han ninu iwọṣọ awọn mejeeji wọnyi. Kò si ninu awọn obinrin mejeeji wọnyi ti o wọṣọ niwọntunwọnsi gẹgẹ bi ẹkọ Ọrọ Ọlọrun. Koko gbogbo ọrọ yii ni pe iru iwọṣọ ti o dara fun Onigbagbọ lọkunrin tabi lobinrin ni eyi ti o bo itiju, ti a si rán daradara; ti o mọ tonitoni, ti a lọ kunna mọránmọrán. Opin gbogbo rè̩ ni pe iwọṣọ kò gbọdọ mu aṣeju lọwọ lọnakọna ni ti pe a kò gbọdọ rán an ni aṣa afẹfẹ-yẹyẹ, bẹẹ ni a kò si ni lati rán an ni aṣa ti igba ti lo tipẹtipẹ. A maa n sọ bayii pe, “Má ṣe jẹ balogun nidi ohunkohun ti o ṣẹṣẹ yọju, má si ṣe jẹ ẹni ikẹyin lati kọ ohun atijọ silẹ.”

Ohunkohun ti a ba n ṣe, a ni lati ṣe e fun ọla ati ogo Ọlọrun (1Kọrinti 10:31). Awọn ẹni ti aye ni lati maa bu ọla fun Ihinrere, o si yẹ ki wọn ni ero rere nipa rè̩ lori ọna iwọṣọ wa ati awọn iṣe wa miiran gbogbo. A ni lati “mā takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi” (1Tẹssalonika 5:22). A kò gbọdọ wọ aṣọ ti yoo mu ki oju maa ti awa paapaa laaarin awọn ti o wọṣọ daradara. Lọna keji ẹwẹ, a kò gbọdọ ni ifẹ lati wọṣọ lati mu ki awọn eniyan tẹjumọ wa lati maa wò wa.

Igberaga

“Igberaga ni iṣaju iparun, agidi ọkàn ni iṣaju iṣubu”(Owe 16:18). Iṣẹ ara ni igberaga, o si jẹ ohun irira loju Ọlọrun. Oun ni o pilẹ ọpọlọpọ è̩ṣẹ ti o wà ninu aye. Igberaga ni o mu ki Lusiferi ṣe afẹri ipo giga “kọja ìràwọ Ọlọrun” (Isaiah 14:13). Igberaga lodi patapata si irẹlẹ. Ọkàn irẹlẹ ki i ṣe afẹri iyẹsi aye. Ọkàn bẹẹ a maa ṣe afẹri ojurere Ọlọrun ju ohunkohun lọ. Nigba ti è̩ṣẹ ba wọ inu ọkàn ọkunrin tabi obinrin ni igberaga ati iwa buburu n jọba lori ọkàn naa.

Igberaga ti o wà ninu ọkàn awọn afasẹyin ọmọbinrin Sioni ni o mu ki Ọlọrun ti ẹnu Woli Isaiah sọ ti ibinu Ọlọrun ti o n bọ wá sori wọn. Ẹṣẹ n pa orilẹ-ède naa run; Isaiah si kigbe mọ è̩ṣẹ náà. Nigba ti è̩ṣẹ ba n jọba iwa buburu gbogbo ni yoo tẹle e. Awọn ọmọbinrin Sioni gberaga. Wọn n fi ẹwọn, jufu; iboju, akẹtẹ; oruka eti, oruka, ọṣọ imú, aṣọ ileke, ibori ati ipaarọ aṣọ wiwọ ṣe ara wọn lọṣọ -- ani gbogbo ohun wọnni ti wọn fi n ṣe afé̩ ni akoko ti wọn. Wọn “n rọ gbọdọ” bi wọn ti n rin. Wọn n fi aṣọ ati awọn ohun ọṣọ ṣe àṣehàn. Wọn fẹ lati maa dan ki wọn si lẹwa loju awọn ọkunrin. Owe atijọ kan sọ bayii pe, “Ẹni daradara ni ẹni ti o ba n ṣe ohun daradara.” S̩ugbọn eyi kò ri bẹẹ nipa awọn ọmọbinrin Israẹli. Wọn dara lode ara, ṣugbọn eyi ki i ṣe ẹwa tootọ ti o yẹ ki wọn ni -- ọṣọ ti inu ati iwa-bi-Ọlọrun.

Ainitiju

Bi orilẹ-ede kan ba ti n fa sẹyin kuro lọdọ Ọlọrun, aṣọ ti kò nilaari ni wọn yoo maa wọ. Nigba ti awọn eniyan ba gbagbe Ọlọrun, wọn a di agberaga, alainitiju ati ọdájú. Awọn ti n pe ara wọn ni orilẹ-ede ọlaju lọjọ oni kò naani aṣọ wíwọ bi kò ṣe lati maa rin ni ihoho. Gbogbo awọn ṣokoto gbọọrọ, ṣokoto penpe, ẹwu ti kò lapa, ẹwu ti o fàyà silẹ, aṣọ ti o há gágá lọna ti o fi aṣiiri ara han ati fífé̩rè̩ẹ wa ni ihoho ninu eyi ti awọn obinrin n rin kaakiri laaarin igboro lọjọ oni jẹ ohun itiju ati irira niwaju Ọlọrun.

Oluwa pa ẹran O si fi awọ rè̩ dá aṣọ fun Adamu ati Efa nigba ti wọn dẹṣẹ, oju Ọlọrun si kan si è̩ṣẹ bakan naa nisisiyi pẹlu. “Obirin kò gbọdọ mú ohun ti iṣe ti ọkunrin wọ; bḝli ọkunrin kò gbọdọ mú aṣọ obirin wọ: nitoripe gbogbo ẹniti o ba ṣe bḝ irira ni nwọn si Ọlọrun rẹ” (Deuteronomi 22:5).

Nigba ti a ba fi aṣọ òdodo wọ ọkàn wa ọna ti a o gba wọṣọ lati bo ode ara wa yoo dọgba pẹlu ọkunrin ti inu nì. Awọn “adalu eniyan” tabi awọn ti kò fẹ lati takete si aye, ni o n fẹ lati wọ aṣọ ti o bá ti aye dọgba. Ọkàn ti ebi Ọlọrun n pa -- ọkàn ti o n ṣafẹri ododo ati iwa mimọ tootọ -- kò ni àkókáyà aṣọ wiwọ lọkan lati rii pe oun ranṣọ oun ni aṣa ti o ṣẹṣẹ yọju, bi kò ṣe pe ki o maa ṣọ aṣọ ati ọṣọ ti ọkunrin ti inu nì. Awọn ẹni ti ebi ẹmi n pa kò ni fi afẹfẹyẹyẹ ati aṣa aye ṣe. Ki i ṣe lati té̩ eniyan lọrun ni o leke ọkàn wọn bi kò ṣe lati tẹ Ọlọrun lọrun.

Ọṣọ ti a Pọnle

Ẹmi Mimọ sọ lati ẹnu Peteru pe: “Ọṣọ ẹniti ki o má jẹ ọṣọ ode, ti irun didì, ati ti wura lilo, tabi ti aṣọ wiwọ; ṣugbọn ki o jẹ ti ẹniti o farasin li ọkàn, ninu ọṣọ aidibajẹ ti ẹmí irẹlẹ ati ẹmí tutù, eyiti iṣe iyebiye niwaju Ọlọrun” (1Peteru 3:3, 4). Ninu ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii ni kókó gbogbo ọrọ naa gbe wa. Nigba ti ẹwa ẹni ti inu nì ba bé̩ yọ lati inu wa, ẹwa tootọ yoo fara han lode. Aṣọ ti ẹni ti o ni ẹmi irẹlẹ ati ẹmi tutu fi sara le jé̩ olowo pọọku, aṣọ naa le jẹ eyi ti a kò ṣe lọṣọ rara, ṣugbọn ẹmi irẹlẹ ati ti iwa-bi-Ọlọrun yoo bé̩ jade pẹlu ogo ti ẹwa rè̩ tayọ didan ọṣọ ti o niyelori ju lọ ti a le fi si ara aṣọ.

Irun didi ti a sọrọ bá ninu Iwe Mimọ jẹ eyi ti a di pẹlu aṣeju ati igberaga ọkàn ati ifẹ lati fa oju eniyan mọra lọna ti o lodi si iwa Onigbagbọ tootọ. Iwe Mimọ sọ fun wa gbangba pe ohun itiju ni fun obinrin lati ré̩ irun rè̩ (1Kọrinti 11:6). Ọlọrun sọ wipe Oun yoo ran ori pipá ati awọn idajọ miiran wá sori awọn ti o kọ lati gbọran ati lati bu ọlá fun Ọrọ Rè̩ ati awọn ti o mọọmọ n rin nipa ọna igberaga ati ainitiju. Ẹwa iwa mimọ ti o n tan jade ni oju awọn Ọmọ-lẹyin Kristi, awọn ti o ni ẹmi-tutu ati ẹmi irẹlẹ eyi ti o n mu ki wọn fara balẹ wọṣọ ni iwọntunwọnsi gẹgẹ bi ẹmi Ihinrere ati ni ọna ti ki yoo mu ẹgan ba orukọ Kristi, yoo fi ara rè̩ han ninu ọna ti a gba n bojuto irun wa pẹlu.

Niwọn igba ti o jẹ pe ode ara nikan ni eniyan n wo, ẹni ti o fi ara balẹ ju lọ ninu wa le ṣe aṣiṣe ninu idajọ. Ninu Ọrọ Ọlọrun a fi han fun ni bi oye ẹda ti kuru to nigba ti Oluwa sọ fun Samuẹli lati fi ororo yan ọkan ninu awọn ọmọ Jesse lọba lori Israẹli. Nigba ti akọbi fara han niwaju Samuẹli, iwo oju rè̩ ati sisin-gbọnlẹ rè̩ fa ọkàn Samuẹli mọra to bẹẹ ti o fi wi pe, “Nitotọ, ẹni-àmi-ororo Oluwa mbẹ niwaju rè̩” (1Samuẹli 16:6). Samuẹli faramọ Oluwa timọtimọ to bẹẹ ti Ọlọrun fi le ba a sọrọ. Oluwa wipe, “Máṣe wo oju rè̩, tabi giga rè̩: nitoripe emi kọ ọ: nitoriti Oluwa ki iwò bi enia ti nwò; enia a ma wò oju, Oluwa a ma wò ọkàn.” Oluwa ti yan ọdọmọde pupa kan ti a mu tọ Samuẹli wá lati inu papa nibi ti o gbe n ṣọ agbo-ẹran. Ijoloootọ si Ọlọrun ti gba ookan àya ọdọmọkunrin yii kan.

Nigba miiran o maa n yẹ ki a lo awọn ẹmú tabi abẹrẹ diẹ pẹlu ẹwu wa nitori ilo wọn nibẹ, tabi lati fi mu ki imura wa pe de oju ami, ṣugbọn kò si igba ti ọṣọ aṣeju tabi eyi ti o dan mọnọmọnọ yẹ ọmọ Ọlọrun, bẹẹ ni ki i bukun é̩wa tabi ìwa eniyan. Ero ti a ni lọkan lati fẹ lo awọn ohun kan to lati fi han fun ni boya awọn ohun ti a fẹ lo naa yẹ ni wiwọ tabi bẹẹ ko. I ha ṣe fun ọṣọ ṣiṣe nikan ni, tabi dandan ni ki a lo o, ati pe kò si ohun miiran ti a le lo dipo rè̩, bẹẹ ni lilo rè̩ paapaa kò si lodi si iwa-bi-Ọlọrun ati iwa mimọ? Eyi kan ọkunrin ati obinrin nitori bi igberaga ninu ọkàn yoo ti sọ obinrin di ẹni egun ati ẹni egbe bẹẹ gẹgẹ ni yoo ri fun ọkunrin pẹlu. Bi ọṣọ aye yii kò ti tọna fun obinrin bẹẹ ni kò tọna fun ọkunrin pẹlu. Bibeli sọ fun wa pe, “Ẹ máṣe fẹran aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye. Bi ẹnikẹni ba fẹran aye, ifẹ ti Baba, kò si ninu rè̩. Nitori ohun gbogbo ti mbẹ li aiye, ifẹkufẹ ara ati ifẹkufẹ oju, ati irera aiye, ki i ṣe ti Baba, bikoṣe ti aiye. Aiye si nkọja lọ, ati ifẹkufẹ rè̩: ṣugbọn ẹniti o ba n ṣe ifẹ Ọlọrun ni yio duro lailai” (I Johannu 2:15-17).

Awọn ẹlẹsin miiran a maa wọ aṣọ oye lati fi ipo wọn han. A mọ awọn Onigbagbọ igba nì nipa iwaasu wọn, igbesi-aye ti wọn n gbe ati ẹni ti wọn n tọ lẹyin – ki i ṣe nipa iru aṣọ ti wọn wọ. Awa ni odiwọn, odiwọn wa wi pe a kò gbọdọ wọṣọ lọna ti a o fi dabi awọn ti aye, ṣugbọn ki a wọṣọ gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun – ki i ṣe pẹlu aṣeju, bikoṣe ni iwọntunwọnsi.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ọṣọ ti o dara ju lọ ti ọmọ Ọlọrun le ni?
  2. Ki ni Onigbagbọ fi n ṣe odiwọn ọṣọ ode ara rè̩?
  3. Iru ipo wo ni awọn obinrin Israẹli wà ni akoko ti Woli Isaiah sọ asọtẹlẹ rè̩?
  4. Ki ni odiwọn wa lọjọ oni nipa aṣọ wiwọ ati ọṣọ ṣiṣe?
  5. Aṣọ wo ni a o fi wọ Iyawo Kristi?
  6. Ki ni ṣe ti a fi ni lati maa wà ni iwọntunwọnsi ninu ohun gbogbo?