Gẹnẹsisi 18:23-32; 32:9-12, 24-28; Isaiah 58:1-11; Daniẹli 9:3; 10:1-3, 10-12; Joẹli 1:13-15; 2:1-17; Matteu 6:16-18; Luku 18:1-14

Lesson 267 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹnikẹni ti o ba gbé ara rè̩ ga, on li a o rè̩ silẹ; ẹniti o ba si rè̩ ara rè̩ silẹ on li a o gbéga” (Luku 18:14).
Cross References

I Ẹbẹ Abrahamu

1. Abrahamu bẹbẹ fun Sodomu ati Gomorra, o n bẹ Oluwa lati da wọn si, bi a ba ri aadọta olododo ninu wọn, Gẹnẹsisi 18:13-26; Jakọbu 5:16-18

2. Abrahamu bẹbẹ siwaju si i titi a fi din iye olododo kù si mẹwaa, Gẹnẹsisi 18:27-33

II Adura agbayọri Jakọbu

1. Jakọbu rẹ ara rè̩ silẹ niwaju Ọlọrun, o si gbadura fun idande, Gẹnẹsisi 32:9-12

2. Jakọbu jijakadi ninu adura ni gbogbo oru pẹlu angẹli o si bori, Gẹnẹsisi 32:24-28; Efesu 6:12

III Adura Daniẹli fun Israẹli

1. Ifẹ ọkàn Daniẹli ni pe ki a mu Israẹli pada bọ sipo, Daniẹli 9:1-3; Jeremiah 29:10; 2Kronika 36:21

2. Daniẹli gbadura, o gba aawẹ, o si ri idaniloju pe a ti gbọ adura oun, Daniẹli 10:1-3, 10-12; Romu 8:16; 1Johannu 3:24; 5:6

IV Aawẹ

1. Oluwa fi iyatọ ti o wà laaarin aawẹ agabagebe ati iru aawẹ ti Oun yàn hàn, Isaiah 58:1-11; Matteu 6:16-18

2. A ni lati wá igbala Ọlọrun fun ọkàn wa, ki i ṣe ododo ara wa, Joẹli 1:13-15; 2:1-17; Luku 18:9-14

3. Oluwa yoo gbẹsan awọn ayanfẹ Rè̩, Luku 18:1-8

4. Ijọ Ọlọrun ni aye igba nì a maa gba aawẹ ni akoko ti wọn ba n beere itọni Ọlọrun ati ifiwọni akanṣe agbara Ẹmi Mimọ, Iṣe Awọn Apọsteli 13:2, 3; 14:23

5. Paulu a maa gbaawẹ nigbakuugba, 2Kọrinti 6:5; 11:27

Notes
ALAYÉ

Aawẹ

Lati ayebaye ni orilẹ-ede gbogbo ni a ti maa n yan aawẹ ni akoko ọfọ, ibanujẹ ati ipọnju. Eredi ti a fi n ṣe eyi ni lati pọn ara ẹni loju ati lati rẹ ọkàn ẹni silẹ, ati lati sun mọ Ọlọrun ju ti atẹyinwa, nipa bẹẹ, ki a ba le ri idahunsi ibeere kan pato gbà tabi ki a le ri ojurere Ọlọrun (Orin Dafidi 35:13; 69:10). A kò fi ilana aawẹ lelẹ ninu ofin Mose; ninu Iwe Mimọ pẹlu a le ri i wi pe aawẹ gbigba ni lati jé̩ pẹlu iyọọda ọkàn ẹni kọọkan gẹgẹ bi Ọlọrun ba ti fi i si ẹni naa lọkan lati ṣe.

Pupọ awọn eniyan Ọlọrun ni wọn ti gbaawẹ nigba ti iwuwo fun ohun pataki kan gba ọkàn wọn kan. Nitori naa a le rii pe akoko ọfọ, ipọnju tabi igba ti iwuwo fun ohun ti i ṣe ti ẹmi ba gba ọkàn kan ni aawẹ yẹ fun. Iru eyi ṣẹlẹ nigba ti awọn ara ilu kekere Ai ṣẹgun awọn Ọmọ Israẹli. Bi Joṣua ti mọ pe inu Ọlọrun kò dun si wọn, niti pe O ti fi aye silẹ fun ẹgbẹ ogun kekere ti Ai lati bori ẹgbẹ ogun nla ti awọn Ọmọ Israẹli, Jọṣua fa aṣọ rè̩ ya; oun ati awọn agbagba Israẹli si dojubolẹ niwaju Apoti-ẹri Oluwa lati owurọ titi di aṣalẹ lai jẹ ohunkohun.

Ni ti pe awọn keferi paapaa a maa gbaawẹ nigba mìíràn fi han pe òye ye awọn eniyan pe aawẹ jẹ ọna lati sun mọ Ọlọrun. Ẹru ba ọba Ninefe nigba ti o gbọ iwaasu Jona, o si kede aawẹ o si fi aṣọ ọfọ bora, o si joko ninu eeru. O kede jakejado ilu naa pe ki eniyan ati ẹranko, ọwọ ẹran ati agbo-ẹran má ṣe tọ ohunkohun wò. O paṣẹ pe, “Má jẹ ki wọn jẹun, má jẹ ki wọn mu omi. S̩ugbọn jẹ ki enia ati ẹranko fi aṣọ ọfọ bora, ki nwọn si kigbe kikan si Ọlọrun: si jẹ ki nwọn yipada, olukuluku kuro li ọna ibi rè̩, ati kuro ni iwa agbara ti o wà lọwọ wọn. Tani le mọ bi Ọlọrun yio yipada ki o si ronupiwada, ki o si yipada kuro ni ibinu gbigbona rè̩, ki awa má ṣegbe?” (Jona 3:5-9).

Oluwa si ronupiwada, O si da ilu Ninefe si ati gbogbo awọn eniyan inu rè̩ nitori pe ọba lori itẹ rè̩ ati awọn ara ilu naa gbaawẹ, wọn si gbadura. Awọn eniyan wọnyi “so eso ti o yẹ fun ironupiwada” (Matteu 3:7-12). Wọn gbadura tọkantọkan. Wọn kò gbaawẹ ki eniyan ba le ri wọn. Wọn fẹ ki Ọlọrun ri wọn ki O si ṣe iyọnu si wọn. Ọlọrun gbọ adura wọn O si da wọn lohun nitori pe oun “kò ni inu-didun ni ikú enia buburu” (Esekiẹli 33:11).

Ni akoko iṣẹ iranṣẹ Jesu lori ilẹ aye, baba kan mu ọmọ rè̩ tọ awọn ọmọ-ẹyin Jesu wá fun iwosan. Arun warapa ni o n ba ọmọ naa ja, awọn ọmọ-ẹyin Jesu kò si le wo o san bi o tilẹ jẹ pe wọn gbadura tọkantọkan ki aisan naa le kuro. S̩ugbọn nigba ti baba ọmọ naa gbe e tọ Jesu wa, O le ẹmi eṣu naa jade, a si mu ọmọ naa lara da. Awọn ọmọ-ẹyin si bi Jesu leere eredi rẹ ti wọn kò fi lè lé ẹmi eṣu naa jade kuro lara ọmọ naa. Jesu dahun wi pe, nitori aigbagbọ wọn ni, ṣugbọn o fi eyi kun un fun iṣiri ati ẹkọ fun wọn pe: “S̩ugbọn ìrú eyi ki ijade lọ bikoṣe nipa adura ati àwẹ.” Eyi fi han wa bi aawẹ ti niyelori to, nigba ti a ba ṣe e ni ọna ẹtọ ati ni ọna ti o wu Ọlọrun.

Aawẹ Agabagebe

Awọn Farisi gbaawẹ lati fi han fun awọn eniyan pe wọn jé̩ olufọkansin. Wọn fẹ ki awọn eniyan ri wọn. Ẹmi ironupiwada ati irobinujẹ ọkàn ti wọn kò ni kò jamọ nnkankan loju wọn. Igbesi-aye ti wọn n gbe lojoojumọ lodi si ijẹwọ igbagbọ wọn. Wọn kò yẹ iru ipo ti ọkàn wọn wà nipa ti ẹmi wò, nitori ti wọn kún fun oriṣiriṣi è̩ṣẹ ati aiṣododo. Sibẹ wọn n gbaawẹ wọn si n gbadura gigun ni ẹba ọna ni gbangba ita ki awọn eniyan ti o ba ri wọn le ro pe wọn jẹ ẹni mimọ ati olufọkansin.

Jesu tẹmbẹlu aawẹ agabagebe o si ba awọn ti n gbaawẹ lọna bẹẹ wi nigba ti o sọ bayii pe: “Ẹ máṣe dabi awọn agabagebe ti nfajuro; nwọn a ba oju jẹ, nitori ki nwọn ki o ba le farahàn fun enia pe nwọn ngbàwẹ.” Aawẹ ti a gba lọna bayii kò mu ire kan wá nipa ti ẹmi. Jesu wi pe awọn wọnyi ti gba ere wọn ná. Wọn n wá ogo ati iyin eniyan, wọn kò si wa ogo ti o ti ọdọ Ọlọrun nikan ṣoṣo wá (Johannu 5:44). Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe nigba ti wọn ba n gbaawẹ, wọn kò gbọdọ fara han fun eniyan pe wọn n gbaawẹ bi kò ṣe fun Ọlọrun nikan. Nigba naa ni ere wọn yoo pọ ni Ọrun.

Isaiah bá awọn Ọmọ Israẹli ti o gbẹkẹle ẹsin ode ara nikan wi lọna kan naa. O fi han wọn pe wọn ni itara pupọ fun ẹsin ode ara ju iwa mimọ lati inu ọkàn wá lọ, ti o yẹ ki iṣẹ-isin wọn yii mu jade ninu igbesi-aye wọn. Wọn n gbaawẹ wọn si n fara hàn bi ẹni ti n gbadura, ṣugbọn wọn kò yipada kuro lọna è̩ṣẹ wọn. Nigba ti wọn kò si ri idahun si adura wọn, wọn wi pe, “Nitori kini awa ṣe n gbàwẹ . . . ti iwọ kò si ri i?” Ọlọrun sọ ohun ti aawẹ jẹ ninu idahun Rè̩ nigba ti O wi pe, “wè̩ iru eyi ni mo yàn bi? ọjọ ti enia njẹ ọkàn rè̩ ni ìya? lati tẹ ori rè̩ ba bi koriko odo? ati lati té̩ aṣọ ọfọ ati ẽru labẹ rè̩? iwọ o ha pe eyi ni āwè̩, ati ọjọ itẹwọgba fun Oluwa? Awẹ ti mo yàn kọ eyi? lati tú ọja aiṣododo, lati tú ẹrù wiwo, ati lati jẹ ki aninilara lọ lọfẹ, ati lati já gbogbo ajàga. Kì ha ṣe lati fi onjẹ rẹ fun awọn ti ebi npa, ati ki iwọ ki o mu awọn otòṣi ti a tì sode wá si ile rẹ? nigbati iwọ ba ri arinhòho, ki iwọ ki o bò o?” (Isaiah 58:5-7). Oluwa fi iru aawẹ ti o ṣe itẹwọgba niwaju rè̩ yé awọn Ọmọ Israẹli ati awa naa pẹlu, O si ṣe ileri pe bi awọn tabi awa ba gbaawẹ lọna bayii, Oun yoo gbọ, Oun yoo si dahun.

Igba ti o Yẹ lati Gbaawẹ

Eṣu kò sùn tọsan toru ninu igboke-gbodo rè̩ lati wá ọna lati bi igbagbọ ọkàn awọn oloootọ wó. Nigba mìíràn eṣu a maa ti awọn eniyan lati gbaawẹ fun ọpọlọpọ ọjọ, nipa bayi wọn a di alailera nipa fifi ilera ti Ọlọrun fun wọn wewu. Iru aawẹ bayìí ki i ṣe ifẹ Ọlọrun. Awọn miiran tilẹ n fẹ gbaawẹ nigba ti okun kò si ninu wọn nitori ti wọn ti ṣaisan, tabi pe wọn tilẹ wà ninu aisan ni lọwọlọwọ, ti wọn kò si le fara da wahala ti aijẹun yoo mu ba agọ ara wọn. Dajudaju Ọlọrun kò ni inudidun si eyi. Bibeli sọ fun wa pe ohunkohun ti a ba n ṣe a ni lati ṣe e fun ogo ati ọla Ọlọrun. Itara fun ẹsìn lọna aṣerege ẹsìn kò le mu iyin ba Ọlọrun. Iwa ti o ba le mu è̩gan ba ilana ati orukọ Ọlọrun kò le yin In logo. Aibikita fun ilera ti Ọlọrun fi fun ni, nigba ti a ba ṣe eyi nitori igberaga tabi ijọ-ara-ẹni-loju kò le mu iyin ba Ọlọrun.

Jesu kò pa a laṣẹ pato fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lati gbaawẹ ṣugbọn o wi bayii, nigba ti o n sọ asọtẹlẹ, pe nigba ti Oun ba lọ, wọn yoo gbaawẹ (Matteu 9:15). Aawẹ yoo mu idahunsi ohun ti a n beere wa gẹgẹ bi o ba ti tọ loju Ọlọrun, bi a ba ṣe e lọna ti kì yoo fi pa wa lara; bi a ba si ṣe e lọna ti o tọ -- fun ọla ati ogo Ọlọrun; ni akoko ti o tọ -- gẹgẹ bi Ẹmi Mimọ ba ti dari wa; ti a si fi ọkàn otitọ ṣe e pẹlu adura ninu ẹmi (Romu 8:26, 27). Awọn mìíràn gbà pe Ọrọ Jesu fi hàn pe aawẹ ọjọ mẹta tó (Matteu 15:32).

Adura È̩bẹ Abrahamu

Nigba ti Ọlọrun fẹ pa Sodomu ati Gomorra run, O wi pe Oun kì yoo pa ohun ti Oun fẹ lọ ṣe mọ fun oloootọ Abrahamu iranṣẹ Oun. Abrahamu duro niwaju Oluwa pẹlu igbẹkẹle pé Oluwa kì yoo ṣe ohun ti kò tọ. Abrahamu fi igbagbọ sun mọ Ọlọrun, pẹlu irẹlẹ ati biba buruburu, o n bẹbẹ fun awọn olododo ti wọn wà ni ilu naa.

Abrahamu beere lọwọ Ọlọrun boya Oun yoo run ilu naa bi O ba ri aadọta olododo nibẹ. Oluwa wi pe Oun yoo dá ilu naa si bi aadọta olododo ba wà nibẹ. Ni ibẹru boya a kì yoo ri to eyi ni, Abrahamu din in kù si marun-un-din-laadọta, Oluwa si wi pe oun yoo dawọ idajọ duro nitori olododo marun-un-din-laadọta. Ifẹ ti o wà lọkàn Abrahamu si Lọti arakunrin rè̩ mu ki o tun bẹbẹ sii lọdọ Ọlọrun. O bẹbẹ ki Ọlọrun din in kù si ogoji, si ọgbọn, ati ni opin rè̩ si mẹwaa. Ni idahun si ibeere ikẹyin Abrahamu, Oluwa wi pe Oun yoo dá awọn ilu naa si bi Oun ba ri olododo mẹwaa. Si kiyesi bi Abrahamu ti n bẹbẹ to, bẹẹ ni Oluwa n dahun adura eniyan Ọlọrun ti o ni igbagbọ yìí. Ẹmi Mimọ sọ lati ẹnu Jakọbu bayii pe, “Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ” (Jakọbu 5:16).

Awọn È̩bẹ Daniẹli

Daniẹli jẹ ẹni iwa-bi-Ọlọrun – onitara ninu adura gbigba – nigba ti o si n ka è̩dà iwe asọtẹlẹ Jeremiah ti a gbe le e lọwọ, o ri i pe akoko ti a ṣeleri lati dá awọn Ju ti a kó lẹru silẹ, sun mọ tosi. Sibẹ kò ri ohunkohun lati fi hàn pe a o mu ileri yìí ṣẹ kánkán. Kò si apẹẹrẹ ti a le fi oju ri lati fi hàn wi pe a o dá awọn eniyan rè̩ silẹ. S̩ugbọn Daniẹli bẹrẹsi fi itara ati igbona ọkàn wá oju Ọlọrun ki a le dá awọn Ọmọ Israẹli silẹ kankan, “nipa adura ati è̩bẹ, pẹlu àwẹ, ninu aṣọ-ọfọ, ati ẽru” (Daniẹli 9:3). A sọ fun wa pe lati ọjọ kin-in-ni ti Daniẹli ti bẹrẹsi gbadura ni Oluwa ti gbọ ti O si ti fi esi adura rè̩ ṣọwọ si i (Daniẹli 10:1-3, 12).

Nigba ti Sọlomọni n ya Tẹmpili si mimọ, o gbadura pe bi a ba kó awọn Ọmọ Israẹli lẹru lọ si ilẹ ajeji, bi wọn ba gbadura, ti wọn si jẹwọ è̩ṣẹ wọn, ti wọn si yipada kuro ni ọna buburu wọn, ti wọn si wá oju Oluwa, ki Oluwa gbọ adura ki O si mu wọn pada si ilẹ wọn, ki O si dari è̩ṣẹ wọn ji wọn (1Awọn Ọba 8:33, 34; 2Kronika 6:34-39). Gbogbo ọna ni Daniẹli gbà lati rẹ ara rè̩ silẹ, nipa wiwọ aṣọ ọfọ, dida eeru sori, nipa gbigba aawẹ ati fifi gbogbo itara ọkàn rè̩ gbadura. O fi tinutinu gbadura, ani fun ogo Ọlọrun nikan, Ọlọrun si gbọ, O si ran idande ti O ti ṣeleri.

Awọn Ẹkọ Jesu

Jesu wi pe, “O yẹ ki a mā gbadura nigbagbogbo, ki a má si ṣārẹ.” Bi o tilẹ jẹ pe Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe, Jesu mọ pe o tọ fun Oun lati ba Baba sọrọ. Oun a si maa gbadura ni gbogbo oru nigba pupọ. O kọ wa ni adura awiiyannu nipa owe talaka opo ati alaiṣootọ onidajọ. O fun wa ni apẹẹrẹ adura ẹbẹ nigba ti o gbadura ni oru ọjọ nì ki o to ta È̩jẹ Rè̩ silẹ fun igbala aye è̩ṣẹ yii. Jesu mu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lọ si Ọgba Gẹtsemane; O si fi wọn silẹ fun igba diẹ ki O ba le nikan wà, O rin siwaju diẹ sii, O si bẹrẹsi i gbadura. Ọkàn Rè̩ kerora gidigidi “õgùn rè̩ si dabi iro è̩jẹ nla, o nkán silẹ” (Luku 22:39-46). Igba mẹta ni Jesu lọ ti O si n gbadura, igba kọọkan ti O si n pada bọ ni O ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ti wọn n sùn, ṣugbọn O ti pinnu ninu ọkàn Rè̩ pe ifẹ Baba ni ṣiṣe.

Kò si ohun ti eṣu korira bi adura. A n sọ lọrọ bayii pe, “eṣu a maa wariri bi o ba ri Onigbagbọ ti i ṣe alailera ju lọ lori eekun rè̩.” Adura ni okùn iye Onigbagbọ. Nigba ti okùn yii ba já, ọkàn yoo di okú. Ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe adura awọn eniyan mimọ a maa goke bi turari lọ siwaju Ọlọrun.

Agbara wà ninu adura. Nipa apẹẹrẹ ati ilana, a n fi eyi kọ wa ninu Majẹmu Laelae ati Titun. Jakọbu fi gbogbo oru wọ ijakadi adura pẹlu angẹli nì, oun kò si jẹ ki o lọ titi o fi ri ibukun gba.

“Ọlọrun n fọpọ enia fadura,

Adura lo n le iṣoro lọ;

Gbogbo iyemeji rẹ yo si fo lọ,

Arakunrin bo ba gbadura.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti a fi kó adura ati aawẹ pọ?
  2. Ki ni o n rú ifẹ eniyan soke lati gbadura tabi lati gbaawẹ?
  3. Njẹ awọn ọmọ-ẹyin Jesu gbaawẹ nigba gbogbo? Bawo ni Jesu ṣe ni ki wọn maa fara hàn nigba ti wọn ba n gbaawẹ?
  4. Ki ni ṣe ti Daniẹli fi gbaawẹ?
  5. S̩e alaye ohun ti a n pe ni adura è̩bẹ.
  6. Njẹ Jesu kọ wa pe a ni lati maa gbadura è̩bẹ? Sọ ohun ti Jesu sọ nipa adura ni ọrọ ara rẹ?
  7. Awọn ta ni n gbadura ki eniyan ba le ri wọn? Ki ni ere wọn yoo jẹ? Nigba wo ni awọn eniyan wọnyi gbà ere wọn? Ki ni ere ti wọn yoo ri gbà ni Ọrun?