Ẹksodu 20:8; 34:21; Lefitiku 26:1, 2; Isaiah 58:13, 14; Nehemiah 10:31; Matteu 12:1-8; Marku 2:27

Lesson 268 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ni ọjọ ikini ọsẹ nigbati awọn ọmọ-ẹhin pejọ lati bù akara, Paulu si wasu fun wọn, o mura ati lọ ni ijọ keji: o si fà ọrọ rè̩ gùn titi di arin ọganjọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 20:7).
Cross References

I Pipa Ọjọ Isinmi Mọ

1. Ọlọrun paṣẹ fun Israẹli lati ya Ọjọ Isinmi si mimọ, Ẹksodu 20:8; 16:23-30; 31:12-17; 34:21; Gẹnẹsisi 2:3; Lefitiku 19:3; 26:1, 2; 23:3

2. Nigba aye Ofin, kò si ẹni ti o gbọdọ ba Ọjọ Isinmi jé̩, Ẹksodu 31:14; Numeri 15:32-36; Deuteronomi 5:12-15; Nehemiah 9:14; 10:31; 13:15; Esekiẹli 20:13; 22:8

3. Ọlọrun ṣeleri ibukun fun gbogbo awọn Ju ti o ba pa Ọjọ Isinmi mọ, Isaiah 56:2; 58:13, 14; Jeremiah 17:20-27; Esekiẹli 20:12, 20

4. A dá Ọjọ Isinmi fun eniyan, a kò dá eniyan fun Ọjọ Isinmi, Matteu 12:1-8; Marku 2:27; Luku 6:1-5

II Bi Onigbagbọ ṣe ni lati Pa Ọjọ Oluwa Mọ

1. Ọlọrun fọwọ si pipa ọjọ kin-in-ni ọsẹ mọ ni mimọ fun Un, paapaa ju lọ nipa ọpọ ifarahan Rè̩ fun awọn eniyan Rè̩ ni ọjọ naa, Matteu 28:1, 2; Johannu 20:17-27; Luku 24:1-45; Iṣe Awọn Apọsteli 2:1-4; 20:6, 7; I Kọrinti 16:2; Ifihan 1:10

Notes
ALAYÉ

Lilo Ọjọ Isinmi ni Mimọ

Lati igba dida aye ni awọn ọmọ-eniyan ti mọ otitọ nipa Ọjọ Isinmi. Ninu Gẹnẹsisi a ka nipa Ọjọ Isinmi kin-in-ni pe, “Ni ijọ keje Ọlọrun si pari iṣẹ rè̩ ti o ti nṣe; o si simi ni ijọ keje kuro ninu iṣẹ rè̩ gbogbo ti o ti nṣe. Ọlọrun si busi ijọ keje, o si yà a si mimọ: nitori pe, ninu rè̩ li o simi kuro ninu iṣẹ rè̩ gbogbo ti o ti bè̩rẹ si iṣe” (Gẹnẹsisi 2:2, 3).

Aṣẹ Ọlọrun fun awọn Ọmọ Israẹli nipa irin wọn niwaju Rè̩, sọ pupọ nipa pipa Ọjọ Isinmi mọ, ani ọjọ keje ninu ọsẹ, fun Oluwa. A paṣẹ fun Israẹli lati pa Ọjọ Isinmi mọ: idajọ ikú si wà fun rírú ofin yii. S̩ugbọn a ko fi ipa mu awọn Ọmọ Israẹli lati pa Ọjọ Isinmi mọ ni tipátipá. Ni Oke Sinai, gbogbo Israẹli fi ohun ṣọkan pe ohun gbogbo ti Ọlọrun ba palaṣẹ ni awọn yoo ṣe (Ka Ẹksodu 19:8). Lẹyin naa ni a fi Ọjọ Isinmi fun wọn ni majẹmu laaarin awọn ati Ọlọrun, gẹgẹ bi ami ileri ti wọn ṣe lati sin In. (Wo Ẹksodu 31:17). A tọka si majẹmu yìí ni ibi pupọ ninu Bibeli nitori ikuna awọn ọmọ Israẹli lati pa ileri wọn mọ.

Ibukun Ọjọ Isinmi

Bi o tilẹ jẹ pe a kò fi le awọn Ọmọ Israẹli lọwọ lati yan lati pa Ọjọ Isinmi mọ, sibẹ ibukun pupọ ni a ṣeleri fun wọn bi wọn ba gbọran. Fun apẹẹrẹ: “Bi iwọ ba yi ẹsẹ rẹ kuro li ọjọ isimi, lati má ṣe afé̩ rẹ li ọjọ isimi mi; ti iwọ si pè ọjọ isimi ni adùn, ọjọ mimọ Oluwa, ọlọwọ; ti iwọ si bọwọ fun u, ti iwọ kò hù iwa rẹ, tabi tẹle afẹ rẹ, tabi sọ ọrọ ara rẹ. Nigbana ni inu rẹ yio dùn si Oluwa, emi o si mu ọ gún ibi giga aiye, emi o si fi ilẹ nini Jakọbu baba rẹ bọ ọ: nitori ẹnu Oluwa li o ti sọ ọ” (Isaiah 58:13, 14).

Ọjọ Kin-in-ni Ọsẹ

Isin Ọlọrun gẹgẹ bi ilana Ofin kọja lọ pẹlu ikú ati ajinde Kristi. Lati igba naa ni isin Ọlọrun ti di isin ni ẹmi ati ni otitọ gẹgẹ bi Jesu ti sọ fun obinrin nì ni eti kanga Samaria (Wo Johannu 4:23, 24). Nigba ti ijọsin fun Ọlọrun nipa irubọ ti Agọ dopin, bakan naa ni pipa ọjọ keje mọ bi Ọjọ Isinmi wá si opin.

Ni ọdun diẹ lẹyin eyii, awọn Apọsteli kọ iwe si awọn Ijọ nipa ọran pipa Ọjọ Isinmi ati ilana isin gẹgẹ bi aṣa awọn Ju mọ. “Niwọnbi awa ti gbọ pe, awọn kan ti o ti ọdọ wa jade lọ fi ọrọ yọ nyin li ẹnu, ti nwọn nyi nyin li ọkàn po, wipe, Ẹnyin kò gbọdọ ṣaima kọ ilà ati ṣaima pa ofin Mose mọ: ẹniti awa kò fun li aṣẹ: . . . Nitori o dara loju Ẹmi Mimọ, ati loju wa, ki a máṣe di ẹrù kà nyin, jù nkan ti a ko le ṣe alaiṣe wọnyi lọ: ki ẹnyin ki o fà sẹhin kuro ninu ẹran apabọ oriṣa, ati ninu è̩jẹ ati ninu ohun ilọlọrun-pa, ati ninu àgbere: ninu ohun ti, bi ẹnyin ba pa ara nyin mọ kuro, ẹnyin o ṣe rere” (Iṣe Awọn Apọsteli 15:24, 28, 29).

Lati igba ti a ti da Ijọ Majẹmu Titun silẹ ni awọn ọmọ-lẹyin Jesu ti n pa ọjọ kin-in-ni ọsẹ mọ bi ọjọ mimọ si Oluwa. Aṣẹ ati idaniloju ti o fẹsẹ mulẹ wà lati fi han pe pipa ọjọ yii mọ tayọ aṣa lasan; nitori bẹrẹ lati igba ajinde Kristi, ni Ọlọrun ti fọwọ si ọjọ yii ni ọna pupọ.

Ajinde Kristi fi han gedegbe bi o ti tọ pe ki a yipada kuro ninu pipa ọjọ isinmi awọn Ju mọ ki a si fara mọ pipa Ọjọ Oluwa mọ gẹgẹ bi Onigbagbọ. Kristi jinde ni ọjọ kin-in-ni ọsẹ. Gẹgẹ bi akọsilẹ inu Bibeli, Jesu fi ẹsẹ isin ni ọjọ kin-in-ni ọsẹ mulẹ nipa ifarahan Rè̩ nigbakuugba ni ọjọ yii. Ninu ọpọlọpọ ọdun ti o ti tẹle akoko yii ni Ọlọrun ti n fi ojurere Rè̩ han si ọjọ yii nipa riran ibukun nla si awọn eniyan Rè̩ bi wọn ti n pejọ pọ lati sin In ni ọjọ kin-in-ni ọsẹ. Gbogbo ọjọ ti eniyan ba pejọ lati sin Ọlọrun ni Oun i maa tu ibukun Rè̩ jade, ṣugbọn Oun a maa ṣe bẹẹ gidi ni ọjọ kin-in-ni ọsẹ. Ọlọrun kì i fi ibukun Ẹmi Rè̩ fun awọn eniyan Rè̩ bi iṣe wọn kò ba tẹ Ẹ lọrun. Jé̩ ki ẹnikẹni tabi gbogbo awọn ti o lodi si eyii fi han nipa iyipada igbesi-aye wọn pe Ọlọrun ni inu didun si iru isin miiran tabi ọjọ miiran. Ibikibi ti ibukun Ọlọrun ba wà, awọn ẹlẹṣẹ yoo ri igbala, igbesi-aye wọn yoo si di ọtun.

Biba Ọjọ Isinmi Jé̩

Ninu itan iran awọn Ọmọ Israẹli, igba pupọ ni wọn kuna nitori pe wọn kò naani Ọjọ Isinmi. Ni akoko Oore ọfẹ yii, ohun ti o wọpọ laarin awọn eniyan ni ṣiṣe ainaani ojuṣe wọn si Ọlọrun ni ti ọjọ kin-in-ni ọsẹ. Bi o tilẹ jẹ pe a kò kede fun wọn pe ijiya ikú yoo wá sori wọn bi wọn kò ba pa Ọjọ Oluwa mọ, sibẹ pipa ọjọ yii mọ jé̩ ẹtọ wọn; ẹni ti o ba si ṣe alaibikita yoo ni idalẹbi ninu ọkàn rè̩, yoo si maa joro ninu ẹmi.

Ohunkohun ti o wu ki awọn ẹlomiiran ṣe tabi ki wọn kuna lati ṣe, pipa ọjọ kin-in-ni ọsẹ mọ ni mimọ fun Oluwa jẹ ohun dandan fun Onigbagbọ. Ibukun ti Ọlọrun ti ṣe ileri fun awọn Ọmọ Israẹli bi wọn ba pa Ọjọ Isinmi mọ wà fun awọn Onigbagbọ loni bi wọn ba gbọran ni pipa ọjọ Oluwa mọ.

Ki ni a n pe ni lilo ọjọ kin-in-ni ọsẹ ni mimọ fun Oluwa? Itumọ rè̩ pataki ni pe ki a ya ọjọ naa sọtọ fun ohun ti i ṣe ti ẹmi. Dajudaju kò si Onigbagbọ ti o n ṣe iṣẹ ara ni Ọjọ Oluwa niwọn igba ti o ba ṣe e ṣe rara lati má ṣe e. Ekukáká ni a le fi ri idi kankan ti o fidimulẹ eyi ti yoo té̩ ẹri ọkàn rere lọrun pe iṣẹ ara kan jé̩ ohun aigbọdọmaṣe ni Ọjọ Oluwa. Bi o ba yè̩ ni ohun aigbọdọ-maṣe bi ọran ounjẹ ati aabo fun eniyan ati ẹranko, eyi ti o pọ ju ninu iṣẹ ni a le ṣe alaiṣe, ni a si gbọdọ fi silẹ lai ṣe ni ọjọ kin-in-ni ọsẹ.

Ofin sọ bayii pe, “Ni igba ifunrugbìn, ati ni igba ikore ni ki iwọ ki o simi” (Ẹksodu 34:21). Aṣẹ Ọlọrun fun Israẹli ni eyii pe ki wọn pa iṣẹ oojọ wọn tì ni akoko ti iṣẹ pọ ju lọ laarin ọdun, lati wa sin Ọlọrun. Ọlọrun kò yipada, bi o tilẹ jẹ pe oju ti la ju ti igba nì lọ, afo kò si fun ni rara lati ro pe ilana Ọlọrun ti yipada nipa eyi. Bi o ba paṣé̩ fun Israẹli ni igba nì, ki o da wa loju pe aṣẹ yii wà bakan naa fun awọn eniyan Rè̩, wọn si ni lati gbọran ki wọn si maa pa a mọ.

Mimọ si Oluwa

Pẹlu ikiyesara diẹ, olukuluku eniyan le pese silẹ fun aini wọn ṣaaju Ọjọ Oluwa; igbokegbodo iṣẹ ile pé̩pè̩pé̩ yoo si dinku gidigidi. A ki i pa ọjọ yii mọ gẹgẹ bi ero tabi ifẹ ọkàn awọn aladugbo nipa ọjọ yii, ṣugbọn a gbọdọ sa ipa wa lati wà ninu ẹmi ati ipo ti o wu Ọlọrun. Akoko pupọ ninu ọjọ yii ni a n lo ni ile Ọlọrun fun isin, tabi ni ṣiṣiṣẹ fun Ọlọrun. Nigba pupọ, awọn Onigbagbọ a maa pejọ pọ fun adura ni owurọ pe ki Ọlọrun le fi ibukun sori ọjọ yii fun ara Rè̩ ati ogo Rè̩. Eyi jẹ ọna ti o dara lọpọlọpọ lati bẹrẹ ọjọ kin-in-ni ọsẹ ni bibeere pe ki ibukun Oluwa le wà lori wa ati awọn ẹlomiiran laarin gbogbo ọsẹ.

Ọpọlọpọ awọn ile iṣẹ ti o tobi ati oriṣiriṣi ile itaja ni a n ṣi lode oni fun ọja tita ni gbogbo ọjọ meje laaarin ọsẹ nitori ki wọn ba le jere pupọ. Aṣa ti o tun n gbeeran laaarin awọn ile-itaja ni lati ṣilẹkun ọja tita ni Ọjọ Oluwa ati lati ti i ni ọjọ kan laaarin ọsẹ. Ohun ti ọgọọrọ eniyan n lo Ọjọ Oluwa fun ni lati maa ṣafẹ ati lati maa ṣe itura to bẹẹ ti Ọjọ Oluwa di ọjọ ti ọja n ta ju gbogbo ọjọ lọ laaarin ọsẹ fun awọn oniṣowo pupọ. Onigbagbọ kò gbọdọ ṣe iranlọwọ fun iru igbekalẹ bẹẹ ni Ọjọ Oluwa. Awọn ile itaja ounjẹ ni o jẹ ẹlẹbi ju lọ nipa eyi, awọn ẹni ti o ba si ba wọn ra ọja ni Ọjọ Oluwa n ṣe iranlọwọ lati ba Ọjọ Oluwa jé̩. Gbogbo ohun elo fun opin ọsẹ ni a le rà silẹ fun ilo ẹbí ni ọjọ Satide. O san ki Onigbagbọ wà lai ni awọn ohun elo diẹ ju pe ki o jẹ alabapin ninu biba Ọjọ Oluwa jẹ ati ẹgbẹ awọn ẹni ti akọle wọn fara jọ eyi pe, “Iṣẹ ṣaaju ohunkohun – paapaa ni Ọjọ Oluwa.”

Onigbagbọ kì i ṣe iṣẹ oojọ rè̩ ni Ọjọ Oluwa, bẹẹ ni kò si ni ifẹ lati fi ṣe ọjọ afẹ. Ifẹ rè̩ ni lati maa ṣe ohun ti inu Oluwa rè̩ dun si, yala igba gbogbo ni ṣiṣe eyi bá oun paapaa laradé tabi ki o má bá a laradé. Awọn mìíràn lero pe wọn ni ẹtọ lati maa lo Ọjọ Oluwa ni eti okun, labẹ igi, ati ni ibi igbadun, tabi ni ṣiṣe ere idaraya, lai bikita fun isin Ọlọrun. Biba Ọjọ Oluwa jé̩ ni eyii jasi! Ọkan ninu è̩sùn ti Ọlọrun fi iran ikẹyin yii sùn ni pe wọn jẹ “Olufẹ fāji jù olufẹ Ọlọrun lọ” (2Timoteu 3:4). Oluwa kì i gboju fo awọn nnkan bẹẹ da. Ifẹ ọmọ Ọlọrun ni lati wà ninu ile Ọlọrun lọjọ Oluwa lati gbadun ati lati ṣe alabapin ninu isin Ọlọrun. Olori ayọ rè̩ ati ẹmi rè̩ paapaa wà ninu isin Ọlọrun. Gbogbo awọn ti o n lepa ohun ti wọn n pe ni idaraya ni Ọjọ Oluwa, lai bikita fun isin Ọlọrun, kò ni igbala; tabi ti wọn ba ti ni in ri, wọn ti sọ ọ nu kuro ninu ọkàn wọn.

A kò gbọdọ rin irin ajo ni Ọjọ Oluwa afi bi o ba jẹ pe ọran karangida bá bá wa ni ojiji. Lati mọọmọ fi isin ati ile Ọlọrun silẹ lati mu ọna ajo pọn, jẹ iwa ti o buru jai. Inu Ọlọrun kò le dun si iru nnkan bẹẹ. Nigba miiran a le ni iṣoro bi a ba duro pe ki gbogbo isin pari ki a to mu ọna ajo pọn; ṣugbọn a ni lati fi tayọtayọ gba iru idaduro ati inira bẹẹ gẹgẹ bi isin atọkanwa ati ijolootọ wa si Ọlọrun. A ni lati gbiyanju lati wà nibi ti a ti le ṣe alabapin ninu isin ni Ọjọ Oluwa. A ni lati sùn si ibi ti a ba wà ni Ọjọ Oluwa; ki a má ṣe maa ṣí kiri sihin tabi sọhun lasan lati té̩ ifẹ ọkàn wa lọrun, ki a ba le wà ni ibi kan ki ilẹ to ṣu tabi ni owurọ. A n fẹ aabo Ọlọrun ni oju ọna ti o kún fun ọpọ eniyan ti o n ṣe afẹ kiri ni Ọjọ Oluwa. Lati rin irin ajo lai si idi miiran pataki ju pe o jẹ ifẹ ọkàn wa lati ṣe bẹẹ yoo mu ki o dabi ẹni pe a n ka aabo Ọlọrun si yẹpẹrẹ.

A kò fi agbara isinru mu Onigbagbọ lati ya Ọjọ Oluwa si mimọ fun Oluwa; ṣugbọn oun a maa ṣe bẹẹ gẹgẹ bi ọna kan lati fi ifẹ ti o ni si Ọlọrun han ati ni bibu ọlá fun ojuṣe ti o gbọdọ ṣe fun Ọlọrun. Onigbagbọ a maa fẹ sun mọ Oluwa nipa isin; didun inu rè̩ si ni lati lo ọjo kin-in-ni ọsẹ ni mimọ fun Ọlọrun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nigba wo ni Ọjọ Isinmi akọkọ? Ta ni o si pa a mọ?
  2. Ki ni itumọ Ọjọ Isinmi?
  3. Ki ni ṣe ti awọn Ọmọ Israẹli fi n pa a mọ?
  4. Ki ni ṣe ti pipa Ọjọ Isinmi iṣaaju mọ fi jé̩ ohun ti awọn Ọmọ Israẹli tikara wọn yan lati odo ọkàn wọn wá?
  5. Nigba wo ni a ṣiwọ lati maa pa Ọjọ Isinmi awọn Ju mọ?
  6. Bawo ni a ṣe mọ pe Ọlọrun n fẹ ki awa ti ode oni lo ọjọ kin-in-ni ọsẹ ni mimọ fun Oluwa?
  7. Ọna wo ni o tọ lati fi maa pa Ọjọ Oluwa mọ?